Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Joṣua 7-9

Ẹ̀ṣẹ̀ Akani

Ṣùgbọ́n àwọn ará Israẹli ṣe àìṣòótọ́ nípa ohun ìyàsọ́tọ̀, Akani ọmọ Karmi, ọmọ Sabdi, ọmọ Sera, ẹ̀yà Juda, mú nínú wọn. Bẹ́ẹ̀ ni ìbínú Olúwa ru sí àwọn ará Israẹli.

Joṣua rán àwọn ọkùnrin láti Jeriko lọ sí Ai, tí ó súnmọ́ Beti-Afeni ní ìlà-oòrùn Beteli, ó sì sọ fún wọn pé, “Ẹ gòkè lọ kí ẹ sì ṣe ayọ́lẹ̀wò.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn arákùnrin náà lọ, wọ́n sì yọ́ Ai wò.

Nígbà tí wọ́n padà sí ọ̀dọ̀ Joṣua, wọ́n wí pé, “Kì í ṣe gbogbo àwọn ènìyàn ni ó ni láti gòkè lọ bá Ai jà. Rán ẹgbẹ̀rún méjì tàbí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọkùnrin láti gbà á, kí ó má ṣe dá gbogbo àwọn ènìyàn ní agara, nítorí ìba ọkùnrin díẹ̀ ní ó wà níbẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ní àwọn bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọkùnrin lọ; ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Ai lé wọn sá, Àwọn ènìyàn Ai sì pa àwọn bí mẹ́rìn-dínlógójì nínú wọn. Wọ́n sì ń lépa àwọn ará Israẹli láti ibodè ìlú títí dé Ṣebarimu, wọ́n sì pa àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀. Àyà àwọn ènìyàn náà sì já, ọkàn wọn sì pami.

Joṣua sì fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì dojúbolẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa títí di àṣálẹ́. Àwọn àgbà Israẹli sì ṣe bákan náà, wọ́n ku eruku sí orí wọn. Joṣua sì wí pé, “Háà, Olúwa Olódùmarè, nítorí kín ni ìwọ ṣe mú àwọn ènìyàn yìí kọjá Jordani, láti fi wọ́n lé àwọn ará Amori lọ́wọ́, láti pa wọn run? Àwa ìbá mọ̀ kí a dúró ní òdìkejì Jordani? Olúwa, kín ni èmi yóò sọ nísinsin yìí tí Israẹli sì ti sá níwájú ọ̀tá a rẹ̀? Àwọn Kenaani àti àwọn ènìyàn ìlú tí ó kù náà yóò gbọ́ èyí, wọn yóò sì yí wa ká, wọn yóò sì ké orúkọ wa kúrò ní ayé. Kí ni ìwọ ó ha ṣe fún orúkọ ńlá à rẹ?”

10 Olúwa sì sọ fún Joṣua pé, “Dìde! Kín ni ìwọ ń ṣe tí ó fi dojúbolẹ̀? 11 Israẹli ti ṣẹ̀; Wọ́n sì ti ba májẹ̀mú mi jẹ́, èyí tí mo pàṣẹ fún wọn pé kí wọn pamọ́. Wọ́n ti mú nínú ohun ìyàsọ́tọ̀, wọ́n ti jí, wọ́n pa irọ́, Wọ́n ti fi wọ́n sí ara ohun ìní wọn. 12 Ìdí nì èyí tí àwọn ará Israẹli kò fi lè dúró níwájú àwọn ọ̀tá wọn; wọ́n yí ẹ̀yìn wọn padà, wọ́n sì sálọ níwájú ọ̀tá a wọn nítorí pé àwọn gan an ti di ẹni ìparun. Èmi kì yóò wà pẹ̀lú u yín mọ́, bí kò ṣe pé ẹ̀yin pa ohun ìyàsọ́tọ̀ run kúrò ní àárín yín.

13 “Lọ, ya àwọn ènìyàn náà sí mímọ́. Sọ fún wọn pé, ‘Ẹ ya ara yín sí mímọ́ fún ọ̀la, nítorí báyìí ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli wí: Ohun ìyàsọ́tọ̀ kan ń bẹ ní àárín yín, Israẹli. Ẹ̀yin kì yóò lè dúró níwájú àwọn ọ̀tá a yín títí ẹ̀yin yóò fi mú kúrò.

14 “ ‘Ní òwúrọ̀, kí ẹ mú ará yín wá síwájú ní ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan. Ẹ̀yà tí Olúwa bá mú yóò wá sí iwájú ní agbo ilé kọ̀ọ̀kan, agbo ilé tí Olúwa bá mú yóò wá sí iwájú ní ìdílé kọ̀ọ̀kan, ìdílé tí Olúwa bá sì mú yóò wá sí iwájú ní ẹni kọ̀ọ̀kan. 15 Ẹnikẹ́ni tí a bá ká mọ́ pẹ̀lú ohun ìyàsọ́tọ̀ náà, a ó fi iná pa á run, pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ní. Ó ti ba májẹ̀mú Olúwa jẹ́, ó sì ti ṣe nǹkan ìtìjú ní Israẹli!’ ”

16 Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, Joṣua mú Israẹli wá síwájú ní ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, a sì mú ẹ̀yà Juda. 17 Àwọn agbo ilé e Juda wá sí iwájú, ó sì mú agbo ilé Sera. Ó sì mú agbo ilé Sera wá síwájú ní ìdílé kọ̀ọ̀kan, a sì mú ìdílé Sabdi. 18 Joṣua sì mú ìdílé Simri wá síwájú ní ọkùnrin kọ̀ọ̀kan, a sì mú Akani ọmọ Karmi, ọmọ Sabdi, ọmọ Sera ti ẹ̀yà Juda.

19 Nígbà náà ní Joṣua sọ fún Akani pé, “Ọmọ mi fi ògo fún Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, kí o sì fi ìyìn fún un. Sọ fún mi ohun tí ìwọ ti ṣe, má ṣe fi pamọ́ fún mi.”

20 Akani sì dáhùn pé, “Òtítọ́ ni! Mo ti ṣẹ̀ sí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli. Nǹkan tí mo ṣe nìyìí: 21 Nígbà tí mo rí ẹ̀wù Babeli kan tí ó dára nínú ìkógun, àti igba ṣékélì fàdákà àti odindi wúrà olóṣùnwọ́n àádọ́ta ṣékélì, mo ṣe ojúkòkòrò wọn mo sì mú wọn. Mo fi wọ́n pamọ́ ní abẹ́ àgọ́ mi àti fàdákà ní abẹ́ rẹ̀.”

22 Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua ran àwọn òjíṣẹ́, wọ́n sì sáré wọ inú àgọ́ náà, ó sì wà níbẹ̀, a sì fi pamọ́ nínú àgọ́ ọ rẹ̀, àti fàdákà ní abẹ́ ẹ rẹ̀. 23 Wọ́n sì mú àwọn nǹkan náà jáde láti inú àgọ́ rẹ̀, wọ́n mú wọn wá fún Joṣua àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì fi wọ́n lélẹ̀ níwájú Olúwa.

24 Nígbà náà ni Joṣua pẹ̀lú gbogbo Israẹli, mú Akani ọmọ Sera, fàdákà, ẹ̀wù àti wúrà tí a dà, àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin àti obìnrin, màlúù rẹ̀, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti àgùntàn àgọ́ rẹ̀ àti gbogbo ohun tí ó ni, wọ́n sì kó wọn lọ sí ibi Àfonífojì Akori. 25 Joṣua sì wí pé, “Èéṣe tí ìwọ mú wàhálà yìí wá sí orí wa? Olúwa yóò mú ìpọ́njú wá sí orí ìwọ náà lónìí.”

Nígbà náà ni gbogbo Israẹli sọ ọ́ ní òkúta pa, lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n sọ àwọn tókù ní òkúta pa tán, wọ́n sì jó wọn níná. 26 Wọ́n sì kó òkìtì òkúta ńlá lé Akani lórí títí di òní yìí. Nígbà náà ní Olúwa sì yí ìbínú gbígbóná rẹ̀ padà. Nítorí náà ni a ṣe ń pe orúkọ ibẹ̀ ní Àfonífojì Akori láti ìgbà náà.

Ìparun Ai

Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Joṣua pé, “Má ṣe bẹ̀rù, kí àyà kí ó má ṣe fò ọ́. Kó gbogbo àwọn ọmọ-ogun pẹ̀lú rẹ, kí ẹ gòkè lọ gbógun ti Ai. Nítorí mo ti fi ọba Ai, àwọn ènìyàn rẹ̀, ìlú u rẹ̀ àti ilẹ̀ ẹ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́. Ìwọ yóò sì ṣe sí Ai àti ọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti ṣe sí Jeriko àti ọba rẹ̀, ohun ìkógun wọn àti ohun ọ̀sìn wọn ni kí ẹ̀yin mú fún ara yín. Rán ènìyàn kí wọ́n ba sí ẹ̀yìn ìlú náà.”

Bẹ́ẹ̀ ní Joṣua àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun jáde lọ láti dojúkọ Ai. Ó sì yan ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àwọn ọkùnrin ogun rẹ̀ ti ó yakin, ó sì rán wọn lọ ní òru. Pẹ̀lú àwọn àṣẹ wọ̀nyí: “Ẹ fi etí sílẹ̀ dáradára. Ẹ ba sí ẹ̀yìn ìlú náà. Ẹ má ṣe jìnnà sí i púpọ̀. Kí gbogbo yín wà ní ìmúrasílẹ̀. Èmi àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú mi yóò súnmọ́ ìlú náà; Nígbà tí àwọn ọkùnrin náà bá jáde sí wa, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní ìṣáájú, àwa yóò sì sá kúrò níwájú u wọn. Wọn yóò sì lépa wa títí àwa ó fi tàn wọ́n jáde kúrò ní ìlú náà, nítorí tí wọn yóò wí pé, wọ́n ń sálọ kúrò ní ọ̀dọ̀ wa gẹ́gẹ́ bí wọ́n tí ṣe ní ìṣáájú. Nítorí náà bí a bá sá kúrò fún wọn, ẹ̀yin yóò dìde kúrò ní ibùba, ẹ ó sì gba ìlú náà. Olúwa Ọlọ́run yín yóò sì fi lé e yín lọ́wọ́. Nígbà tí ẹ bá ti gba ìlú náà, kí ẹ sì ti iná bọ̀ ọ́. Kí ẹ ṣe ohun tí Olúwa pàṣẹ. Mo ti fi àṣẹ fún un yín ná.”

Nígbà náà ni Joṣua rán wọn lọ. Wọ́n sì lọ sí ibùba, wọ́n sì sùn ní àárín Beteli àti Ai, ní ìwọ̀-oòrùn Ai. Ṣùgbọ́n Joṣua wá dúró pẹ̀lú àwọn ènìyàn ní òru ọjọ́ náà.

10 Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì Joṣua kó àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, òun àti àwọn olórí Israẹli, wọ́n wọ́de ogun lọ sí Ai. 11 Gbogbo àwọn ọmọ-ogun tí ó wà pẹ̀lú u rẹ̀ sì gòkè lọ, wọ́n sì súnmọ́ tòsí ìlú náà, wọ́n sì dé iwájú u rẹ̀. Wọ́n sì pàgọ́ ní ìhà àríwá Ai. Àfonífojì sì wà ní agbede-méjì wọn àti ìlú náà. 12 Joṣua sì ti fi bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún ọmọ-ogun pamọ́ sí àárín Beteli àti Ai, sí ìwọ̀-oòrùn ìlú náà. 13 Wọ́n sì yan àwọn ọmọ-ogun sí ipò wọn, gbogbo àwọn tí ó wà ní ibùdó lọ sí àríwá ìlú náà àti àwọn tí ó sápamọ́ sí ìwọ̀-oòrùn rẹ̀. Ní òru ọjọ́ náà Joṣua lọ sí àfonífojì.

14 Nígbà tí ọba Ai rí èyí, òun àti gbogbo ọkùnrin ìlú náà yára jáde ní òwúrọ̀ kùtùkùtù láti pàdé ogun Israẹli ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ aginjù. Ṣùgbọ́n kò mọ̀ pé àwọn kan wà ní ibùba ní ẹ̀yìn ìlú náà. 15 Joṣua àti gbogbo àwọn Israẹli sì ṣe bí ẹni tí a lé padà níwájú wọn, wọ́n sì sá gba ọ̀nà aginjù. 16 A sì pe gbogbo àwọn ọkùnrin Ai jọ láti lépa wọn, wọ́n sì lépa Joṣua títí wọ́n fi tàn wọ́n jáde nínú ìlú náà. 17 Kò sì ku ọkùnrin kan ní Ai tàbí Beteli tí kò tẹ̀lé Israẹli. Wọ́n sì fi ìlẹ̀kùn ibodè ìlú náà sílẹ̀ ní ṣíṣí, wọ́n sì ń lépa àwọn ará Israẹli.

18 Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Joṣua pé, “Na ọ̀kọ̀ tí ó wà lọ́wọ́ rẹ sí Ai, nítorí tí èmi yóò fi ìlú náà lé ọ ní ọwọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua sì na ọ̀kọ̀ ọwọ́ rẹ̀ sí Ai. 19 Bí ó ti ṣe èyí tán, àwọn ọkùnrin tí ó ba sì dìde kánkán kúrò ní ipò wọn, wọ́n sáré síwájú. Wọn wọ ìlú náà, wọ́n gbà á, wọ́n sì yára ti iná bọ̀ ọ́.

20 Àwọn ọkùnrin Ai bojú wo ẹ̀yìn, wọ́n rí èéfín ìlú náà ń gòkè lọ sí ọ̀run, ṣùgbọ́n wọn kò rí, ààyè láti sá àsálà lọ sí ibìkan kan, nítorí tí àwọn ará Israẹli tí wọ́n tí ń sálọ sí aginjù ti yípadà sí àwọn tí ń lépa wọn. 21 Nígbà tí Joṣua àti gbogbo àwọn ará Israẹli rí i pé àwọn tí ó bá ti gba ìlú náà, tí èéfín ìlú náà sì ń gòkè, wọ́n yí padà wọ́n sì kọlu àwọn ọkùnrin Ai. 22 Àwọn ọmọ-ogun tí ó ba náà sì yípadà sí wọn láti inú ìlú náà, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n wà ní agbede-méjì àwọn ará Israẹli ní ìhà méjèèjì. Israẹli sì pa wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì jẹ́ kí ọ̀kan kí ó yè tàbí kí ó sálọ nínú wọn. 23 Ṣùgbọ́n wọ́n mú ọba Ai láààyè, wọ́n sì mu un tọ Joṣua wá.

24 Nígbà tí Israẹli parí pípa gbogbo àwọn ìlú Ai ní pápá àti ní aginjù ní ibi tí wọ́n ti lépa wọn lọ, tí gbogbo wọ́n sì ti ojú idà ṣubú, tí a fi pa gbogbo wọn tan, gbogbo àwọn Israẹli sì padà sí Ai, wọ́n sì fi ojú idà kọlù ú. 25 Ẹgbẹ̀rún méjìlá ọkùnrin àti obìnrin ni ó kú ní ọjọ́ náà—gbogbo wọn jẹ́ àwọn ènìyàn Ai. 26 Nítorí tí Joṣua kò fa ọwọ́ rẹ̀ tí ó di ọ̀kọ̀ mú sí ẹ̀yìn, títí ó fi pa gbogbo àwọn tí ń gbé ìlú Ai run. 27 Ṣùgbọ́n Israẹli kó ẹran ọ̀sìn àti ìkógun ti ìlú yìí fún ara wọn, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Joṣua.

28 Joṣua sì jó Ai, ó sì sọ ọ́ di ààtàn, àní ahoro di òní yìí. 29 Ó sì gbé ọba Ai kọ́ orí igi, ó sì fi kalẹ̀ síbẹ̀ títí di ìrọ̀lẹ́. Bí oòrùn sì ti wọ̀ ni Joṣua pàṣẹ fún wọn láti sọ òkú rẹ̀ kalẹ̀ kúrò ní orí igi, kí wọn sì wọ́ ọ jù sí àtiwọ ẹnu ibodè ìlú náà. Wọ́n sì kó òkìtì òkúta ńlá lé e ní orí, èyí tí ó wà títí di òní yìí.

Májẹ̀mú tí a sọ di ọ̀tun ní orí òkè Ebali

30 (A)Nígbà náà ni Joṣua mọ pẹpẹ kan fún Olúwa Ọlọ́run Israẹli, ní òkè Ebali, 31 gẹ́gẹ́ bí Mose ìránṣẹ́ Olúwa ti pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli. Ó sì kọ́ ọ́ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ nínú Ìwé Òfin Mose, pẹpẹ odindi òkúta, èyí tí ẹnìkan kò fi ohun èlò irin kàn rí. Wọ́n sì rú ọrẹ ẹbọ sísun àti ọrẹ àlàáfíà ní orí rẹ̀ sí Olúwa. 32 Níbẹ̀, ní ojú àwọn ará Israẹli, Joṣua sì ṣe àdàkọ òfin Mose èyí tí ó ti kọ sí ara òkúta náà. 33 Gbogbo Israẹli, àjèjì àti ọmọ ìlú, pẹ̀lú àwọn àgbàgbà, olórí àti onídàájọ́ dúró ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì àpótí ẹ̀rí Olúwa tí ó kọjú sí àwọn àlùfáà tí ó rù ú, tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi. Ìdajì àwọn ènìyàn náà dúró ní Òkè Gerisimu, àwọn ìdajì si dúró ni òkè Ebali, gẹ́gẹ́ bí Mose ìránṣẹ́ Olúwa ti pàṣẹ rí, pé kí wọn súre fún àwọn ènìyàn Israẹli.

34 Lẹ́yìn èyí, Joṣua sì ka gbogbo ọ̀rọ̀ inú òfin, ìbùkún àti ègún, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú Ìwé Òfin. 35 Kò sí ọ̀rọ̀ kan nínú gbogbo èyí tí Mose pàṣẹ tí Joṣua kò kà ní iwájú gbogbo àjọ Israẹli, títí fi kan àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ wọn, àti àwọn àjèjì tí ń gbé ní àárín wọn.

Ìwà àrékérekè Gibeoni

Nísinsin yìí, nígbà tí gbogbo ọba tó wà ní ìwọ̀-oòrùn Jordani gbọ́ nípa nǹkan wọ̀nyí, àwọn náà tí ó wà ní orí òkè àti àwọn tí ó wà ní ẹsẹ̀ òkè, àti gbogbo àwọn tí ó wà ní agbègbè Òkun ńlá títí ó fi dé Lebanoni (àwọn ọba Hiti, Amori, Kenaani, Peresi, Hifi àti Jebusi) wọ́n sì kó ara wọn jọ láti bá Joṣua àti Israẹli jagun.

Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ènìyàn Gibeoni gbọ́ ohun tí Joṣua ṣe sí Jeriko àti Ai, wọ́n dá ọgbọ́n ẹ̀tàn. Wọ́n lọ gẹ́gẹ́ bí aṣojú tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn kún fún ẹrù tí a fi àwọn àpò tó ti gbó dì, àti àwọn awọ ọtí wáìnì tó ti gbó tí a tún rán. Àwọn ọkùnrin náà sì wọ bàtà àti aṣọ tí ó ti gbó. Gbogbo oúnjẹ tí wọ́n pèsè fún ara wọn sì bu. Wọ́n sì tọ Joṣua lọ ní ibùdó ní Gilgali, wọ́n sì sọ fún òun àti àwọn ọkùnrin Israẹli pé, “Ìlú òkèrè ní àwọn ti wá, ẹ ṣe àdéhùn àlàáfíà pẹ̀lú wa.”

Àwọn ọkùnrin Israẹli sọ fún àwọn ará Hifi pé, “Ṣùgbọ́n bóyá tòsí wa ni ẹ ń gbé. Báwo ni a ó ṣe lè ṣe àdéhùn pẹ̀lú yín?”

“Ìránṣẹ́ rẹ ní àwa í ṣe.” Wọ́n sọ fún Joṣua.

Ṣùgbọ́n Joṣua béèrè, “Ta ni yín àti pé níbo ni ẹ̀yin ti wá?”

Wọ́n sì dáhùn pé: “Ní ilẹ̀ òkèèrè ní àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí wá, nítorí orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ. Nítorí tí àwa ti gbọ́ òkìkí rẹ àti ohun gbogbo tí ó ti ṣe ní Ejibiti, 10 àti ohun gbogbo tí ó ti ṣe sí ọba àwọn Amori méjèèje tí ń bẹ ní òkè Jordani, sí Sihoni ọba Heṣboni, àti Ogu ọba Baṣani, tí wọ́n jẹ ọba ní Aṣtarotu. 11 Àwọn àgbàgbà wa àti gbogbo àwọn tí ń gbé ìlú wa sọ fún wa pé, ‘Ẹ mú oúnjẹ lọ́wọ́ fún ìrìnàjò yín, ẹ lọ pàdé wọn, kí ẹ sì sọ fún wọn pé, “Àwa ni ìránṣẹ́ yín, ẹ dá àdéhùn pẹ̀lú wa.” ’ 12 Gbígbóná ní a mú oúnjẹ wa wá, nígbà tí a dì í ní ilé ní ọjọ́ tí à ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ yín. Ṣùgbọ́n ẹ wò ó bí ó ṣe gbẹ àti bí ó sì ṣe bu nísinsin yìí. 13 Àti ìgò wáìnì wọ̀nyí, tí àwa rọ kún tuntun ni, ṣùgbọ́n ẹ wò ó bí wọ́n ti sán. Aṣọ àti bàtà wa ni ó sì ti gbó nítorí ìrìnàjò ọ̀nà jíjìn.”

14 Àwọn ọkùnrin Israẹli sì yẹ oúnjẹ wọn wò, wọn kò sì wádìí ní ọwọ́ Olúwa. 15 Nígbà náà ni Joṣua ṣe àdéhùn àlàáfíà pẹ̀lú wọn láti dá wọn sí, àti àwọn olórí ìjọ ènìyàn fi ọwọ́ sí àdéhùn náà nípa ṣíṣe ìbúra.

16 Ní ẹ̀yìn ọjọ́ mẹ́ta tí wọ́n ti ṣe àdéhùn pẹ̀lú àwọn ará Gibeoni, àwọn ọmọ Israẹli gbọ́ pé aládùúgbò wọn ni wọ́n, tí ń gbé ní tòsí wọn. 17 Bẹ́ẹ̀ ní àwọn ọmọ Israẹli jáde, wọ́n sì dé ìlú wọn ní ọjọ́ kẹta: Gibeoni, Kefira, Beeroti àti Kiriati-Jearimu. 18 Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Israẹli kò si kọlù wọ́n, nítorí pé àwọn àgbàgbà ìjọ ènìyàn ti búra fún wọn ní orúkọ Olúwa Ọlọ́run Israẹli.

Gbogbo ènìyàn sì kùn sí àwọn àgbàgbà náà, 19 ṣùgbọ́n gbogbo àwọn olórí dáhùn pé, “Àwa ti búra fún wọn ní orúkọ Olúwa Ọlọ́run Israẹli, a kò sì lè fọwọ́ kàn wọ́n nísinsin yìí. 20 Èyí ní àwa yóò ṣe sí wọn, àwa yóò dá wọn sí, kí ìbínú kí ó má ba à wá sórí wa, nítorí ìbúra tí a búra fún wọn.” 21 Wọ́n tẹ̀síwájú, “Ẹ dá wọn sí, ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí wọn jẹ́ gégigégi àti apọnmi fún gbogbo ìlú.” Àwọn àgbàgbà náà sì mú ìlérí wọn ṣẹ fún wọn.

22 Nígbà náà ni Joṣua pe àwọn ọmọ Gibeoni jọ pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi tàn wá wí pe, ‘Àwa gbé ní ibi tí ó jìnnà sí yín,’ nígbà tí ó jẹ́ pé tòsí wa ní ẹ̀yin ń gbé? 23 Nísinsin yìí, ẹ̀yin di ẹni ègún: Ẹ̀yin kò sì ní kúrò ní gégigégi àti apọnmi fún ilé Ọlọ́run mi.”

24 Wọ́n sì dá Joṣua lóhùn pé, “Nítorí tí a sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ dájúṣáká bí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti pàṣẹ fún Mose ìránṣẹ́ rẹ̀, láti fún yín ní gbogbo ilẹ̀ náà, kí ó sì pa gbogbo olùgbé ilẹ̀ náà run kúrò ní iwájú yín. Nítorí náà, àwa bẹ̀rù ẹ̀mí wa nítorí yín, èyí sì ni ìdí tí a fi ṣe bẹ́ẹ̀. 25 Nísinsin yìí, àwa wà ní ọwọ́ yín. Ohunkóhun tí ẹ bá rò pé ó yẹ ó si tọ́ lójú yín ní kí ẹ fi wá ṣe.”

26 Bẹ́ẹ̀ ní Joṣua sì gbà wọ́n là kúrò ní ọwọ́ àwọn ọmọ Israẹli. Wọn kò sì pa wọ́n. 27 Ní ọjọ́ náà ni ó sọ àwọn Gibeoni di aṣẹ́gi àti apọnmi fún àwọn ará ìlú àti fún pẹpẹ Olúwa ní ibi tí Olúwa yóò yàn. Báyìí ni wọ́n wà títí di òní yìí.

Luku 1:21-38

21 Àwọn ènìyàn sì ń dúró de Sekariah, ẹnu sì yà wọ́n nítorí tí ó pẹ́ nínú tẹmpili. 22 Nígbà tí ó sì jáde wá, òun kò le bá wọn sọ̀rọ̀. Wọn sì kíyèsi wí pé ó ti rí ìran nínú tẹmpili, ó sì ń ṣe àpẹẹrẹ sí wọn, nítorí tí ó yadi.

23 Ó sì ṣe, nígbà tí ọjọ́ iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ pé, ó lọ sí ilé rẹ̀. 24 Lẹ́yìn èyí ni Elisabeti aya rẹ̀ lóyún, ó sì fi ara rẹ̀ pamọ́ ní oṣù márùn-ún, 25 Ó sì wí pé “Báyìí ni Olúwa ṣe fún mi ní ọjọ́ tí ó ṣíjú wò mí, láti mú ẹ̀gàn mi kúrò láàrín àwọn ènìyàn.”

Ìsọtẹ́lẹ̀ ibi Jesu

26 Ní oṣù kẹfà Ọlọ́run sì rán angẹli Gabrieli sí ìlú kan ní Galili, tí à ń pè ní Nasareti, 27 sí wúńdíá kan tí a ṣèlérí láti fẹ́ fún ọkùnrin kan, tí a ń pè ní Josẹfu, ti ìdílé Dafidi; orúkọ wúńdíá náà a sì máa jẹ́ Maria. 28 Angẹli náà sì tọ̀ ọ́ wá, ó ní, “Àlàáfíà fun ọ, ìwọ ẹni tí a kọjú sí ṣe ní oore, Olúwa ń bẹ pẹ̀lú rẹ.”

29 Ṣùgbọ́n ọkàn Maria kò lélẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ náà, ó sì rò nínú ara rẹ̀ pé, irú kíkí kín ni èyí. 30 (A)Ṣùgbọ́n angẹli náà wí fún un pé, “Má bẹ̀rù, Maria: nítorí ìwọ ti rí ojúrere lọ́dọ̀ Ọlọ́run. 31 (B)Ìwọ yóò lóyún nínú rẹ, ìwọ ó sì bí ọmọkùnrin kan, ìwọ ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jesu. 32 Òun ó pọ̀, Ọmọ Ọ̀gá-ògo jùlọ ni a ó sì máa pè é: Olúwa Ọlọ́run yóò sì fi ìtẹ́ Dafidi baba rẹ̀ fún: 33 (C)Yóò sì jẹ ọba lórí ilé Jakọbu títí láé; ìjọba rẹ̀ kì yóò sì ní ìpẹ̀kun.”

34 (D)Nígbà náà ni Maria béèrè lọ́wọ́ angẹli náà pé, “Èyí yóò ha ti ṣe rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí èmi kò tí ì mọ ọkùnrin.”

35 (E)Angẹli náà sì dáhùn ó sì wí fún un pé, “Ẹ̀mí Mímọ́ yóò tọ̀ ọ́ wá, agbára Ọ̀gá-ògo jùlọ yóò ṣíji bò ọ́. Nítorí náà ohun mímọ́ tí a ó ti inú rẹ bí, Ọmọ Ọlọ́run ni a ó máa pè é. 36 Sì kíyèsi i, Elisabeti ìbátan rẹ náà yóò sì ní ọmọkùnrin kan ní ògbólógbòó rẹ̀. Èyí sì ni oṣù kẹfà fún ẹni tí à ń pè ní àgàn. 37 (F)Nítorí kò sí ohun tí Ọlọ́run kò le ṣe.”

38 Maria sì dáhùn wí pé, “Wò ó ọmọ ọ̀dọ̀ Olúwa; kí ó rí fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.” Angẹli náà sì fi í sílẹ̀ lọ.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.