Old/New Testament
Àsè ìpè
29 (A)“ ‘Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù keje, kí ẹ ní àpéjọ mímọ́, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan. Ọjọ́ ìfùnpè ni ó jẹ́ fún yín. 2 Gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn sí Olúwa, ẹ pèsè ẹgbọrọ akọ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan aláìlábùkù, kí ẹ fi ẹbọ sísun. 3 Pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ wọn, ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò, ìdámẹ́ta nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n fún akọ màlúù kan, àti ìdá méjì nínú mẹ́wàá, òṣùwọ̀n fún àgbò kan, 4 àti ìdámẹ́wàá òṣùwọ̀n fún ọ̀dọ́-àgùntàn kan, àti fún ọ̀dọ́-àgùntàn méje. 5 Àti òbúkọ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣètùtù fún yín. 6 Pẹ̀lú ẹbọ sísun oṣù àti ẹbọ ohun jíjẹ rẹ̀ àti ẹbọ sísun ìgbà gbogbo àti ẹbọ mímu wọn gẹ́gẹ́ bí ìlànà wọn. Fún òórùn dídùn, ẹbọ tí a fi iná ṣe sí Olúwa.
Ọjọ́ ẹbọ ètùtù
7 (B)“ ‘Ní ọjọ́ kẹwàá nínú oṣù keje, kí ẹ ṣe àpéjọ mímọ́. Kí ẹ̀yin kí ó sẹ́ ara yín, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan. 8 Kí ẹ̀yin kí ó rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí Olúwa, ẹgbọrọ akọ màlúù kan, àgbò kan, àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn méje ọlọ́dún kan, kí wọn kí ó sì jẹ́ aláìlábùkù fún yín. 9 Pẹ̀lú akọ màlúù, pèsè ọrẹ ìdámẹ́wàá mẹ́ta, òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun tí a fi òróró pò àti ìdámẹ́wàá méjì òṣùwọ̀n fún àgbò kan, 10 àti fún ọ̀dọ́-àgùntàn kọ̀ọ̀kan, ìdámẹ́wàá òṣùwọ̀n. 11 Pẹ̀lú akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, pẹ̀lú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ètùtù àti ẹbọ sísun gbogbo ìgbà àti ẹbọ jíjẹ rẹ̀ àti ẹbọ mímu wọn.
Àpèjẹ Àgọ́
12 (C)“ ‘Ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù keje, kí ẹ̀yin kí ó ní àpéjọ mímọ́, ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan. Kí ẹ̀yin kí ó sì ṣe àjọyọ̀ fún Olúwa fún ọjọ́ méje. 13 Kí ẹ sì rú ẹbọ sísun kan, ẹbọ tí a fi iná ṣe, tí ó ní òórùn dídùn sí Olúwa, ẹbọ tí ẹgbọrọ akọ màlúù mẹ́tàlá, àgbò méjì àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́rìnlá tí ó jẹ́ ọdún kan, tí gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ aláìlábùkù. 14 Àti ẹbọ ohun jíjẹ wọn, ìyẹ̀fun tí a fi òróró pò, ìdámẹ́wàá mẹ́ta òṣùwọ̀n fún akọ màlúù kan, bẹ́ẹ̀ ni fún akọ màlúù mẹ́tẹ̀ẹ̀tàlá, ìdámẹ́wàá méjì òṣùwọ̀n fún àgbò kan, bẹ́ẹ̀ ni fún àgbò méjèèjì, 15 àti fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀dọ́-àgùntàn kan. Bẹ́ẹ̀ ni fún ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́rẹ̀ẹ̀rìnlá. 16 Àti akọ ewúrẹ́ kan gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu rẹ̀.
17 “ ‘Àti ní ọjọ́ kejì ni kí ẹ̀yin kí ó fi ẹgbọrọ akọ màlúù méjìlá, àgbò méjì àti ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́rìnlá ọlọ́dún kan aláìlábùkù rú ẹbọ. 18 Pẹ̀lú fún akọ màlúù, fún àgbò, àti fún ọ̀dọ́-àgùntàn kí ẹ pe ẹbọ ohun jíjẹ, àti ẹbọ ohun mímu, kí ó jẹ́ bí iye wọn, gẹ́gẹ́ bí ìlànà. 19 Àti òbúkọ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà pẹ̀lú ẹbọ jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.
20 “ ‘Ní ọjọ́ kẹta, pèsè akọ màlúù mọ́kànlá, àgbò méjì, akọ àgùntàn mẹ́rìnlá ti ọdún kan tí kò ní àbùkù. 21 Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò, àti akọ àgùntàn, pèsè ọrẹ ohun jíjẹ àti ohun mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn. 22 Pẹ̀lú akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àti ẹbọ sísun ìgbà gbogbo pẹ̀lú ẹbọ jíjẹ àti ẹbọ mímu.
23 “ ‘Ní ọjọ́ kẹrin, pèsè akọ màlúù mẹ́wàá, àgbò méjì, àti ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́rìnlá ti ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbùkù. 24 Àti akọ màlúù, àgbò àti àgùntàn, pèsè ẹbọ jíjẹ àti ẹbọ mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn, gẹ́gẹ́ bí ìlànà. 25 Àti akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà, pẹ̀lú ẹbọ jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.
26 “ ‘Àti ní ọjọ́ karùn-ún, pèsè akọ màlúù mẹ́sàn-án, àgbò méjì àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́rìnlá ti ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, tí gbogbo rẹ̀ kò ní àbùkù. 27 Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò àti ọ̀dọ́-àgùntàn, pèsè ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn sí ìlànà. 28 Àti akọ ewúrẹ́ kan gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ẹbọ sísun ìgbà gbogbo pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.
29 “ ‘Ní ọjọ́ kẹfà, pèsè akọ màlúù mẹ́jọ, àgbò ọlọ́dún kan tí gbogbo rẹ̀ kò ní àbùkù. 30 Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò, àti ọ̀dọ́-àgùntàn, pèsè ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn. 31 Pẹ̀lú akọ ewúrẹ́ kan gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.
32 “ ‘Àti ní ọjọ́ keje, pèsè akọ màlúù méje, àgbò méjì, àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́rìnlá ti ọlọ́dún kan, tí gbogbo rẹ̀ kò sì ní àbùkù. 33 Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò, àti ọ̀dọ́-àgùntàn, pèsè ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu fún wọn gẹ́gẹ́ bí iye wọn. 34 Pẹ̀lú akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà, pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.
35 (D)“ ‘Àti ní ọjọ́ kẹjọ kí ẹ̀yin kó ní àpéjọ, kí ẹ má sì ṣe iṣẹ́ kankan. 36 Kí ẹ̀yin ṣe ìgbékalẹ̀ ẹbọ tí a fi iná ṣe tí ó ní òórùn dídùn sí Olúwa, ẹbọ sísun ti akọ màlúù kan, àgbò ọlọ́dún kan àti ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan méje, gbogbo rẹ̀ tí kò ní àbùkù. 37 Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò, àti ọ̀dọ́-àgùntàn, pèsè fún wọn ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn. 38 Àti akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà àti ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.
39 “ ‘Pẹ̀lú ẹ̀jẹ́ yín, àti ẹbọ àtinúwá yín, kí ẹ̀yin kí o pèsè fún Olúwa ní àjọ̀dún tí a yàn yín, ẹbọ sísun, ẹbọ ohun jíjẹ, ẹbọ ohun mímu àti ẹbọ ìkẹ́gbẹ́ yín.’ ”
40 Mose sì sọ fún àwọn ọmọ Israẹli gbogbo ohun tí Olúwa ti pàṣẹ fún un.
Ẹ̀jẹ́
30 Mose sì sọ fún olórí àwọn ẹ̀yà ọmọ Israẹli pé: “Èyí ni ohun tí Olúwa pàṣẹ: 2 (E)(F)Nígbà tí ọkùnrin kan bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ sí Olúwa tàbí búra láti fi de ara rẹ̀ ní ìdè kí òun má bà ba ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ kí ó ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sọ.
3 “Nígbà tí ọmọbìnrin kan bá sì wà ní ilé baba rẹ̀ tó bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa tàbí búra láti fi de ara rẹ̀ 4 tí baba rẹ̀ bá sì gbọ́ ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tàbí ìdè rẹ̀ tí kò sì sọ nǹkan kan sí i, kí gbogbo ẹ̀jẹ́ rẹ̀ kí ó dúró àti gbogbo ìdè tí ó fi de ara rẹ̀ yóò sì dúró. 5 Ṣùgbọ́n tí baba rẹ̀ bá kọ̀ fun un ní ọjọ́ tí ó gbọ́, kò sí ọ̀kan nínú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tàbí nínú ìdè tí ó fi de ara rẹ̀ tí yóò dúró; Olúwa yóò sì tú u sílẹ̀ nítorí baba rẹ̀ kọ̀ fún un.
6 “Tí ó bá sì ní ọkọ lẹ́yìn ìgbà tí ó jẹ́ ẹ̀jẹ́ tàbí lẹ́yìn ìgbà tí ó sọ ọ̀rọ̀ kan láti ẹnu rẹ̀ jáde nínú èyí tí ó fi de ara rẹ̀ ní ìdè, 7 Tí ọkọ rẹ̀ sì gbọ́ nípa èyí ṣùgbọ́n tí kò sọ nǹkan kan, nígbà náà ni ẹ̀jẹ́ tàbí ìdè tí ó fi de ara rẹ̀ tó dúró. 8 Ṣùgbọ́n tí ọkọ rẹ̀ bá kọ̀ nígbà tí ó gbọ́, ǹjẹ́ òun yóò mú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tí ó jẹ́ àti ohun tí ó ti ti ẹnu rẹ̀ jáde, èyí tí ó fi de ara rẹ̀ dasán, Olúwa yóò sì dáríjì í.
9 “Ṣùgbọ́n ẹ̀jẹ́ kí ẹ̀jẹ́ tàbí ìdè kí ìdè tí opó tàbí obìnrin tí a kọ̀sílẹ̀ bá ṣe yóò wà lórí rẹ̀.
10 “Bí obìnrin tí ó ń gbé pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ tàbí de ara rẹ̀ ní ìdè lábẹ́ ìbúra, 11 tí ọkọ rẹ̀ bá sì gbọ́, ṣùgbọ́n tí kò sọ̀rọ̀, tí kò sì kọ̀, nígbà náà ni ẹ̀jẹ́ rẹ̀ yóò dúró. 12 Ṣùgbọ́n tí ọkọ rẹ̀ bá sọ wọ́n dasán, nígbà tí ó gbọ́, nígbà náà kò sí ẹ̀jẹ́ tàbí ìdè tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde tí yóò dúró, ọkọ rẹ̀ ti sọ wọ́n dasán, Olúwa yóò tú u sílẹ̀. 13 Ọkọ rẹ̀ lè ṣe ìwádìí tàbí sọ ọ́ dasán ẹ̀jẹ́ tàbí ìbúra ìdè tí ó ti ṣe láti fi de ara rẹ̀. 14 Ṣùgbọ́n tí ọkọ rẹ̀ kò bá sọ nǹkan kan sí í nípa rẹ̀ ní ọjọ́ dé ọjọ́, nígbà náà ni ó ṣe ìwádìí nípa ẹ̀jẹ́ àti ìbúra ìdè tí ó dè é. Kí ọkùnrin náà ṣe ìwádìí lórí rẹ̀ láìsọ nípa rẹ̀ si nígbà tí ó gbọ́ nípa rẹ̀. 15 Bí ó ti wù kí ó rí, bí ọkùnrin náà bá sọ ọ́ dasán, ní àkókò kan lẹ́yìn tí ó ti gbọ́ wọn, nígbà náà ó jẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà.”
16 Èyí ni ìlànà tí Olúwa fún Mose nípa ìbátan láàrín ọkùnrin àti obìnrin àti láàrín baba àti ọ̀dọ́mọbìnrin rẹ̀ tí ó sì ń gbé ní ilé rẹ̀.
Gbígbẹ̀san lára àwọn ọmọ Midiani
31 Olúwa sọ fún Mose pé, 2 “Gbẹ̀san lára àwọn Midiani fún àwọn ọmọ Israẹli. Lẹ́yìn ìgbà náà a ó kó ọ jọ pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ.”
3 Mose sì sọ fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ wọ ogun fún àwọn kan nínú yín láti lọ da ojú ìjà kọ àwọn ọmọ Midiani láti gba ẹ̀san Olúwa lára wọn. 4 Rán ẹgbẹ̀rún (1,000) ọmọ-ogun láti ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ní Israẹli.” 5 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì yan nínú àwọn ẹgbẹgbẹ̀rún ènìyàn Israẹli, ẹgbẹ̀rún (1,000) ènìyàn láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, ẹgbàá-mẹ́fà (12,000) ènìyàn tí ó wọ ìhámọ́ra ogun. 6 Mose rán wọn lọ sí ogun, ẹgbẹ̀rún (1,000) láti ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú Finehasi ọmọ Eleasari, ti ó jẹ́ àlùfáà, ti òun ti ohun èlò ibi mímọ́ àti ìpè wọ̀n-ọn-nì ní ọwọ́ rẹ̀.
7 Wọ́n dojú ìjà kọ Midiani gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose, kí wọn sì pa gbogbo wọn. 8 Wọ́n sì pa àwọn ọba Midiani pẹ̀lú: àwọn ìyókù tí wọ́n pa lára wọn ni Efi, Rekemu, Suri àti Huri, àti Reba: ọba Midiani márùn-ún, wọ́n sì fi idà pa Balaamu ọmọ Beori. 9 Àwọn ọmọ Israẹli sì mú gbogbo obìnrin Midiani ní ìgbèkùn àti àwọn ọmọ kékeré wọn, wọ́n sì kó gbogbo ohun ọ̀sìn wọn àti gbogbo agbo ẹran wọn àti gbogbo ẹrù wọn. 10 Wọ́n finá jó gbogbo ìlú wọn àti ibùdó wọn. 11 Wọ́n sì kó gbogbo ìní wọn, àti ènìyàn àti ẹran. 12 Wọ́n sì kó gbogbo ohun tí wọ́n bàjẹ́ àti ènìyàn àti ẹran wá sọ́dọ̀ Mose àti Eleasari àlùfáà, àti sọ́dọ̀ ìjọ àwọn ọmọ Israẹli ní ibùdó àgọ́ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu tí ń bẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jordani létí Jeriko.
13 Mose, Eleasari àlùfáà àti gbogbo olórí ìgbèríko lọ láti lọ bá wọn ní ìta ibùdó. 14 Inú bí Mose sí àwọn olórí ọmọ-ogun, pẹ̀lú àwọn olórí ẹgbẹ̀rún (1,000) àti olórí ọ̀rọ̀ọ̀rún (1,000) tí wọ́n ti ogun dé.
15 Mose sì béèrè wí pé, “Ẹ̀yin ha dá gbogbo àwọn obìnrin sí bí? 16 (G)Àwọn ni wọ́n tẹ̀lé ìmọ̀ràn Balaamu, àwọn ní ó ṣe okùnfà yíyí àwọn ọ̀mọ̀ Israẹli padà kúrò ní ọ̀dọ̀ Olúwa nínú èyí tí ó ṣẹlẹ̀ ní Peori, níbi tí àjàkálẹ̀-ààrùn ti kọlu ìjọ Olúwa. 17 Nísinsin yìí, pa gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin àti àwọn obìnrin tí ó ti súnmọ́ ọkùnrin, 18 Ṣùgbọ́n kí o dá obìnrin tí kò bá tí ì súnmọ́ ọkùnrin sí fún ara yín.
19 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ti pa ènìyàn tàbí fọwọ́ kan ẹni tí a pa gbọdọ̀ dúró ní ìta ibùdó àgọ́ fún ọjọ́ méje, Ní ọjọ́ kẹta àti ọjọ́ keje ẹ gbọdọ̀ ya ara yín àti ẹni tí ẹ kó lẹ́rú sí mímọ́. 20 Kí ẹ̀yin kí ó ya aṣọ yín sí mímọ́ àti gbogbo ohun tí a fi awọ ṣe àti gbogbo iṣẹ́ irun ewúrẹ́ àti ohun tí a fi igi ṣe.”
21 Eleasari àlùfáà sì wí fún àwọn olórí ogun náà pé, “Èyí ní ìlànà òfin tí Olúwa fi lélẹ̀ ní àṣẹ fún Mose. 22 Kìkì i wúrà, fàdákà, idẹ, irin, idẹ àti òjé. 23 Ohunkóhun tí ó lè la iná ni kí ẹ̀yin ó mú la iná, nígbà náà ni yóò jẹ́ mímọ́. Ṣùgbọ́n ẹ yóò fi omi ìyàsímímọ́ sọ ọ́ di mímọ́. Àti gbogbo ohun tí kò lè la iná kọjá ni kí a mú la inú omi. 24 Ní ọjọ́ keje, ẹ fọ aṣọ yín, ẹ̀yin yóò sì mọ́, nígbà náà ní ẹ̀yin yóò lè wọ inú ibùdó àjọ.”
Pínpín ogún
25 Olúwa sọ fún Mose pé, 26 “Ìwọ àti Eleasari àlùfáà àti àwọn olórí ilé baba ìjọ ni kí o ka iye àwọn ènìyàn àti ẹranko tí a kó ní ìgbèkùn. 27 Pín ohun ìní àti ìkógun náà láàrín àwọn ọmọ-ogun náà tí ó kópa nínú ogun náà àti láàrín gbogbo ìjọ. 28 Kí o sì gba ìdá ti Olúwa lọ́wọ́ àwọn ológun tí wọn jáde lọ sí ogun náà: ọ̀kan nínú ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta nínú àwọn ènìyàn àti nínú màlúù àti nínú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àti nínú agbo ẹran. 29 Gba ìdá yìí lára ààbọ̀ ìpín tiwọn, kí o sì fún Eleasari àlùfáà, fún ẹbọ ìgbésókè Olúwa. 30 Lára ààbọ̀ ti Israẹli, yan ọ̀kan kúrò nínú àádọ́ta, (50) yálà ènìyàn, ẹran ọ̀sìn, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àgùntàn, ewúrẹ́ tàbí ẹ̀yà ẹranko mìíràn. Kó wọn fún àwọn Lefi, tí ó dúró fún olùtọ́jú àgọ́ Olúwa.” 31 Nígbà náà Mose àti Eleasari àlùfáà ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.
32 Èrè tí ó kù lára ìkógun tí àwọn ọmọ-ogun kó jẹ́, ọ̀kẹ́ mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n (675,000) ó dín ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n àgùntàn. 33 Ẹgbàá-mẹ́rìn-dínlógójì (72,000) màlúù 34 ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó lé ẹgbẹ̀rin (61,000) kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, 35 Pẹ̀lú obìnrin ẹgbàá-mẹ́rìn-dínlógún, (32,000) ni kò ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin rí.
36 Ìpín ààbọ̀ àwọn tí ó jáde lọ sí ogun sì jẹ́:
ẹgbàáméjì-dínláàdọ́san (337,500) ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ àgùntàn. 37 Tí ìdá ti Olúwa sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó-dínmẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (675) àgùntàn;
38 ẹgbọrọ màlúù jẹ́ ẹgbàáméjì-dínlógún, (36,000) tí ìdá Olúwa sì jẹ́ méjìléláàdọ́rin (72);
39 kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì jẹ́ ẹgbàámẹ́ẹ̀ẹ́dógún ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta, (30,500) tí ìdá ti Olúwa sì jẹ́ mọ́kànlélọ́gọ́ta; (61).
40 Àwọn ènìyàn sì jẹ́ ẹgbàámẹ́jọ (16,000) ìdá ti Olúwa sì jẹ́ méjìlélọ́gbọ̀n. (32).
41 Mose fi ìdá náà fún Eleasari, àlùfáà gẹ́gẹ́ bí ìdá ti Olúwa, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mose.
42 Ààbọ̀ tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ Israẹli, tí Mose yà sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ọkùnrin tí ó ja ogun. 43 Ààbọ̀ tí ìjọ jẹ́ ẹgbàá-méjì-dínláàdọ́sàn-án ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (337,500) àgùntàn, 44 pẹ̀lú ẹgbàáméjì-dínlógún (36,000) màlúù 45 tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì jẹ́ ẹgbàámẹ́ẹ̀ẹ́dógún ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta. (30,500) 46 Àwọn ènìyàn sì jẹ́ ẹgbàámẹ́jọ; (16,000). 47 Lára ààbọ̀ ti àwọn ọmọ Israẹli, Mose yan ọ̀kan lára àádọ́ta (50) ènìyàn àti ẹranko gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún un. Ó sì fi wọ́n fún àwọn ọmọ Lefi, tí ń ṣe olùtọ́jú àgọ́ Olúwa.
48 Pẹ̀lú àwọn olórí tí ó wà lórí ẹgbẹẹgbẹ̀rin ogun náà, àti àwọn balógun ọ̀rọ̀ọ̀rún wá sọ́dọ̀ Mose. 49 Wọ́n sì sọ fún un pé, “ìránṣẹ́ rẹ ti ka àwọn ọmọ-ogun náà tí ó wà lábẹ́ ìtọ́jú wa, kò sì sí ọ̀kọ̀ọ̀kan tó dín. 50 Nítorí náà làwa ṣe mú ọrẹ ẹbọ wá fún Olúwa, gbogbo ọrẹ wíwà tí a ní, wúrà, ẹ̀wọ̀n, àti júfù, àti òrùka-àmi, àti òrùka etí, àti ìlẹ̀kẹ̀ láti fi ṣe ètùtù fún ọkàn an wa níwájú Olúwa.”
51 Mose àti Eleasari àlùfáà, gba wúrà náà lọ́wọ́ wọn pẹ̀lú gbogbo ohun iṣẹ́ ọ̀ṣọ́. 52 Gbogbo wúrà tí àwọn balógun ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti àwọn balógun ọ̀rọ̀ọ̀rún mú wá fún Mose àti Eleasari, èyí tí ó jẹ́ ẹbọ ìgbésókè fún Olúwa jẹ́ ẹgbàá-mẹ́jọ ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó lé àádọ́ta (16,750) ṣékélì. 53 Nítorí ológun kọ̀ọ̀kan ti kó ẹrù fún ara rẹ̀. 54 Mose àti Eleasari àlùfáà gba wúrà náà lọ́wọ́ àwọn balógun ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti lọ́wọ́ balógun ọ̀rọ̀ọ̀rún wọ́n sì ko wá sínú àgọ́ ìpàdé fún ìrántí àwọn Israẹli níwájú Olúwa.
9 (A)Ó sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín àwọn mìíràn wa nínú àwọn tó dúró níhìn-ín yìí, tí kì yóò tọ́ ikú wò, títí yóò fi rí ìjọba Ọlọ́run tí yóò fi dé pẹ̀lú agbára.”
Ìparadà
2 (B)(C) Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́fà tí Jesu sọ̀rọ̀ yìí, Jesu mú Peteru, Jakọbu àti Johanu lọ sí orí òkè gíga ní apá kan. Kò sí ẹlòmíràn pẹ̀lú wọn, ara rẹ̀ sì yípadà níwájú wọn. 3 (D)Aṣọ rẹ̀ sì di dídán, ó sì funfun gbòò, tí alágbàfọ̀ kan ní ayé kò lè sọ di funfun bẹ́ẹ̀. 4 Nígbà náà ni Elijah àti Mose farahàn fún wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Jesu.
5 Peteru sì wí fún Jesu pé, “Rabbi, ó dára fún wa láti máa gbé níhìn-ín, si jẹ́ kí a pa àgọ́ mẹ́ta, ọ̀kan fun ọ, ọ̀kan fún Mose, àti ọ̀kan fún Elijah.” 6 Nítorí òun kò mọ ohun tí òun ìbá sọ, nítorí ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi.
7 (E)Ìkùùkuu kan sì bò wọ́n, ohùn kan sì ti inú ìkùùkuu náà wá wí pé: “Èyí ni àyànfẹ́ ọmọ mi: Ẹ máa gbọ́ ti rẹ̀!”
8 Lójijì, wọ́n wo àyíká wọn, wọn kò sì rí ẹnìkankan mọ́, bí kò ṣe Jesu nìkan ṣoṣo ni ó sì wà pẹ̀lú wọn.
9 (F)(G) Bí wọ́n ti ń sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, Jesu kìlọ̀ fún wọn kí wọ́n má ṣe sọ ohun tí wọ́n ti rí fún ẹnikẹ́ni títí Ọmọ Ènìyàn yóò fi jíǹde kúrò nínú òkú. 10 Nítorí náà, wọ́n pa nǹkan náà mọ́ ní ọkàn wọn. Ṣùgbọ́n wọ́n ń béèrè lọ́wọ́ ara wọn ohun tí àjíǹde kúrò nínú òkú túmọ̀ sí.
11 (H)Nísinsin yìí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, èéṣe tí àwọn olùkọ́ òfin ń sọ wí pé, “Elijah ní yóò kọ́kọ́ dé.”
12 (I)Ó sì dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni Elijah yóò kọ́kọ́ dé yóò sì mú nǹkan gbogbo padà bọ̀ sípò. Àní gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ nípa ti Ọmọ Ènìyàn pé kò le ṣàìmá jìyà ohun púpọ̀ àti pé a ó sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀. 13 Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé, Elijah ti wa ná, wọ́n sì ti ṣe ohunkóhun tí ó wù wọ́n sí i, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé nípa rẹ̀.”
Ìwòsàn ọmọkùnrin ẹlẹ́mìí èṣù
14 (J)Nígbà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ pátápátá sí ẹsẹ̀ òkè náà, wọ́n bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí wọ́n yí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́sàn-án ìyókù ká. Àwọn olùkọ́ òfin díẹ̀ sì ń bá wọn jiyàn. 15 Bí Jesu ti ń súnmọ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn wọ̀nyí ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í wò ó pẹ̀lú ìbẹ̀rù, nígbà náà ni wọ́n sáré lọ kí i.
16 Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Kí ló fa àríyànjiyàn?”
17 Ọkùnrin kan láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn dáhùn pé, “Olùkọ́, èmi ni mo mú ọmọ yìí wá fún ọ láti wò ó sàn. Kò lè sọ̀rọ̀ rárá, nítorí tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́. 18 Àti pé, nígbàkúgbà tí ó bá mú un, á gbé e ṣánlẹ̀, a sì máa hó itọ́ lẹ́nu, a sì máa lọ́ eyín rẹ̀. Òun pàápàá a wá le gbàgìdì. Mo sì bẹ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kí wọn lé ẹ̀mí àìmọ́ náà jáde, ṣùgbọ́n wọ́n kò lè ṣe é.”
19 Ó sì dá wọn lóhùn, ó wí pé, “Ẹ̀yin ìran aláìgbàgbọ́ yìí, Èmi yóò ti bá a yín gbé pẹ́ tó? Èmi yóò sì ti mú sùúrù fún un yín pẹ́ tó? Ẹ mú ọmọ náà wá sọ́dọ̀ mi.”
20 Wọ́n sì mú un wá sọ́dọ̀ rẹ̀: nígbà tí ó sì rí i, lójúkan náà ẹ̀mí náà nà án tàntàn ó sì ṣubú lu ilẹ̀, ó sì ń fi ara yílẹ̀, ó sì ń yọ ìfófó lẹ́nu.
21 Jesu béèrè lọ́wọ́ baba ọmọ náà pé, “Ó tó ìgbà wo tí ọmọ rẹ̀ ti wà nínú irú ipò báyìí?”
Baba ọmọ náà dáhùn pé, “Láti kékeré ni.” 22 Nígbàkúgbà ni ó sì máa ń gbé e sínú iná àti sínú omi, láti pa á run, ṣùgbọ́n bí ìwọ bá lè ṣe ohunkóhun, ṣàánú fún wa, kí o sì ràn wá lọ́wọ́.
23 (K)“Jesu sì wí fún un pé, ‘Bí ìwọ bá le gbàgbọ́: ohun gbogbo ni ó ṣe é ṣe fún ẹni tí ó bá gbàgbọ́.’ ”
24 Lójúkan náà baba ọmọ náà kígbe ní ohùn rara, ó sì wí pé, “Olúwa, mo gbàgbọ́, ran àìgbàgbọ́ mi lọ́wọ́.”
25 Nígbà tí Jesu rí i pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ń péjọ sọ́dọ̀ wọn, ó bá ẹ̀mí àìmọ́ náà wí pé, “Ìwọ ẹ̀mí àìmọ́, adití àti odi, mo pàṣẹ fún ọ, kí ó jáde kúrò lára ọmọ yìí, kí ó má ṣe padà sí ibẹ̀ mọ́.”
26 Òun sì kígbe ńlá, ó sì nà án tàntàn, ó sì jáde kúrò lára rẹ̀: ọmọ náà sì dàbí ẹni tí ó kú tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ké wí pé, “Hé è, ọmọ náà ti kú.” 27 Ṣùgbọ́n Jesu fà á lọ́wọ́, ó sì ràn án lọ́wọ́ láti dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀. Ó dìde dúró.
28 Nígbà tí ó sì wọ ilé, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bi í léèrè níkọ̀kọ̀ wí pé, “Èéṣe tí àwa kò fi lè lé e jáde?”
29 Ó sì wí fún wọn pé, “Irú èyí kò le ti ipa ohun kan jáde, bí kò ṣe nípa àdúrà.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.