Old/New Testament
32 Fetísílẹ̀, Ẹ̀yin ọ̀run, èmi yóò sọ̀rọ̀;
ẹ gbọ́, ìwọ ayé, ọ̀rọ̀ ẹnu mi.
2 Jẹ́ kí ẹ̀kọ́ ọ̀ mi máa rọ̀ bí òjò,
kí àwọn ọ̀rọ̀ mi máa sọ̀kalẹ̀ bí ìrì,
bí òjò wíníwíní sára ewéko tuntun,
bí ọ̀wààrà òjò sára ohun ọ̀gbìn.
3 Èmi yóò kókìkí orúkọ Olúwa,
Háà, ẹ yin títóbi Ọlọ́run wa!
4 Òun ni àpáta, iṣẹ́ ẹ rẹ̀ jẹ́ pípé,
gbogbo ọ̀nà an rẹ̀ jẹ́ òdodo.
Ọlọ́run olóòtítọ́ tí kò ṣe àṣìṣe kan,
Ó dúró ṣinṣin, òdodo àti òtítọ́ ni òun.
5 (A)Wọ́n ti ṣe iṣẹ́ ìbàjẹ́ sọ́dọ̀ ọ rẹ̀;
fún ìtìjú u wọn, wọn kì í ṣe ọmọ rẹ̀ mọ́,
ṣùgbọ́n ìran tí ó yí sí apá kan tí ó sì dorí kodò.
6 Ṣé báyìí ni ẹ̀yin yóò ṣe san an fún Olúwa,
Háà, ẹ̀yin aṣiwèrè àti aláìgbọ́n ènìyàn?
Ǹjẹ́ òun kọ́ ni baba yín, Ẹlẹ́dàá yín,
tí ó dá a yín tí ó sì mọ yín?
7 Rántí ìgbà láéláé;
wádìí àwọn ìran tí ó ti kọjá.
Béèrè lọ́wọ́ baba à rẹ yóò sì sọ fún ọ,
àwọn àgbàgbà rẹ, wọn yóò sì ṣàlàyé fún ọ.
8 Nígbà tí Ọ̀gá-ògo fi ogún àwọn orílẹ̀-èdè fún wọn,
nígbà tí ó pín onírúurú ènìyàn,
ó sì gbé ààlà kalẹ̀ fún àwọn ènìyàn
gẹ́gẹ́ bí iye ọmọkùnrin Israẹli.
9 Nítorí ìpín Olúwa ni àwọn ènìyàn an rẹ̀,
Jakọbu ni ìpín ìní i rẹ̀.
10 Ní aginjù ni ó ti rí i,
ní aginjù níbi tí ẹranko kò sí.
Ó yíká, ó sì tọ́jú rẹ̀,
ó pa á mọ́ bí ẹyin ojú u rẹ̀.
11 Bí idì ti í ru ìtẹ́ rẹ̀ ti ó sì ń
rábàbà sórí ọmọ rẹ̀,
tí ó na ìyẹ́ apá rẹ̀ láti gbé wọn ki ó sì
gbé wọn sórí ìyẹ́ apá rẹ̀.
12 Olúwa ṣamọ̀nà;
kò sì sí ọlọ́run àjèjì pẹ̀lú rẹ̀.
13 Ó mú gun ibi gíga ayé
ó sì fi èso oko bọ́ ọ.
Ó sì jẹ́ kí ó mú oyin láti inú àpáta wá,
àti òróró láti inú akọ òkúta wá,
14 Pẹ̀lú u wàràǹkàṣì àti wàrà àgùntàn
àti ti àgbò ẹran
àti pẹ̀lú ọ̀rá ọ̀dọ́-àgùntàn àti ewúrẹ́,
pẹ̀lú àgbò irú u ti Baṣani
tí ó sì mu ẹ̀jẹ̀ èso àjàrà, àní àti wáìnì.
15 Jeṣuruni sanra tán ó sì tàpá;
ìwọ sanra tán, ìwọ ki tan, ọ̀rá sì bò ọ́ tán.
O kọ Ọlọ́run tí ó dá ọ
o sì kọ àpáta ìgbàlà rẹ.
16 Wọ́n sì fi òrìṣà mú un jowú,
ohun ìríra ni wọ́n fi mú un bínú.
17 Wọ́n rú ẹbọ sí iwin búburú, tí kì í ṣe Ọlọ́run,
ọlọ́run tí wọn kò mọ̀ rí,
ọlọ́run tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ farahàn láìpẹ́,
ọlọ́run tí àwọn baba yín kò bẹ̀rù.
18 Ìwọ kò rántí àpáta, tí ó bí ọ;
o sì gbàgbé Ọlọ́run tí ó dá ọ.
19 Olúwa sì rí èyí ó sì kọ̀ wọ́n,
nítorí tí ó ti bínú nítorí ìwà ìmúnibínú àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin rẹ.
20 Ó sì wí pé, “Èmi yóò pa ojú mi mọ́ kúrò lára wọn,
èmi yóò sì wò ó bí ìgbẹ̀yìn in wọn yóò ti rí;
nítorí wọ́n jẹ́ ìran alágídí,
àwọn ọmọ tí kò sí ìgbàgbọ́ nínú wọn.
21 (B)Wọ́n fi mí jowú nípa ohun tí kì í ṣe Ọlọ́run,
wọ́n sì fi ohun asán an wọn mú mi bínú.
Èmi yóò mú wọn kún fún ìlara láti ọ̀dọ̀ àwọn tí kì í ṣe ènìyàn;
èmi yóò sì mú wọn bínú láti ọ̀dọ̀ aṣiwèrè orílẹ̀-èdè.
22 Nítorí pé iná kan ràn nínú ìbínú mi,
yóò sì jó dé ipò ikú ní ìsàlẹ̀.
Yóò sì run ayé àti ìkórè e rẹ̀
yóò sì tiná bọ ìpìlẹ̀ àwọn òkè ńlá.
23 “Èmi yóò kó àwọn ohun búburú lé wọn lórí
èmi ó sì na ọfà mi tán sí wọn lára.
24 Èmi yóò mú wọn gbẹ,
ooru gbígbóná àti ìparun kíkorò ni a ó fi run wọ́n.
Pẹ̀lú oró ohun tí ń rákò nínú erùpẹ̀.
25 Idà ní òde, àti ẹ̀rù nínú ìyẹ̀wù,
ni yóò run ọmọkùnrin àti wúńdíá.
Ọmọ ẹnu ọmú àti arúgbó eléwú irun pẹ̀lú.
26 Mo ní èmi yóò tú wọn ká
èmi yóò sì mú ìrántí i wọn dà kúrò nínú àwọn ènìyàn,
27 nítorí bí mo ti bẹ̀rù ìbínú ọ̀tá,
kí àwọn ọ̀tá a wọn kí ó má
ba à wí pé, ‘Ọwọ́ wa lékè ni;
kì í sì í ṣe Olúwa ni ó ṣe gbogbo èyí.’ ”
28 Wọ́n jẹ́ orílẹ̀-èdè tí kò ní ìmọ̀,
bẹ́ẹ̀ ni kò sí òye nínú wọn.
29 Bí ó ṣe pé wọ́n gbọ́n, kí òye yìí sì yé wọn
kí wọn ro bí ìgbẹ̀yìn wọn yóò ti rí!
30 Báwo ni ẹnìkan ṣe lè lé ẹgbẹ̀rún,
tàbí tí ẹni méjì sì lè lé ẹgbàárùn-ún sá,
bí kò ṣe pé àpáta wọn ti tà wọ́n,
bí kò ṣe pé Olúwa wọn ti fi wọ́n tọrẹ?
31 Nítorí pé àpáta wọn kò dàbí àpáta wa,
àní àwọn ọ̀tá wa tìkára wọn ń ṣe onídàájọ́.
32 Igi àjàrà a wọn wá láti igi àjàrà Sodomu
àti ti ìgbẹ́ ẹ Gomorra.
Èso àjàrà wọn kún fún oró,
Ìdì wọn korò.
33 Ọtí wáìnì wọn ìwọ ti dragoni ni,
àti oró mímú ti ejò paramọ́lẹ̀.
34 “Èmi kò to èyí jọ ní ìpamọ́
èmi kò sì fi èdìdì dì í ní ìṣúra mi?
35 Ti èmi ni láti gbẹ̀san; Èmi yóò san án fún wọn
ní àkókò tí ẹ̀ṣẹ̀ wọn yóò yọ;
ọjọ́ ìdààmú wọn súnmọ́ etílé
ohun tí ó sì ń bọ̀ wá bá wọn yára bọ̀.”
36 Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn an rẹ̀
yóò sì ṣàánú fún àwọn ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀
nígbà tí ó bá rí i pé agbára wọn lọ tán
tí kò sì sí ẹnìkan tí ó kù, ẹrú tàbí ọmọ.
37 Yóò wí pé: “Òrìṣà wọn dà báyìí,
àpáta tí wọ́n fi ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé e wọn,
38 ọlọ́run tí ó jẹ ọ̀rá ẹran ẹbọ wọn
tí ó ti mu ọtí i wáìnì ẹbọ ohun mímu wọn?
Jẹ́ kí wọn dìde láti gbà wọ́n!
Jẹ́ kí wọn ṣe ààbò fún un yín!
39 “Wò ó báyìí pé: èmi fúnra à mi, èmi ni!
Kò sí ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn mi.
Mo sọ di kíkú mo sì tún sọ di ààyè,
Mo ti ṣá lọ́gbẹ́ Èmi yóò sì mu jiná,
kò sí ẹni tí ó lè gbà kúrò lọ́wọ́ ọ̀ mi.
40 Mo gbé ọwọ́ mi sókè ọ̀run mo sì wí pé:
Èmi ti wà láààyè títí láé,
41 nígbà tí mo bá pọ́n idà dídán mi
àti tí mo bá sì fi ọwọ́ mi lé ìdájọ́,
Èmi yóò san ẹ̀san fún àwọn ọ̀tá mi
Èmi kò sì san fún àwọn tí ó kórìíra à mi.
42 Èmi yóò mú ọfà mu ẹ̀jẹ̀,
nígbà tí idà mi bá jẹ ẹran:
ẹ̀jẹ̀ ẹni pípa àti ẹni ìgbèkùn,
láti orí àwọn aṣáájú ọ̀tá.”
43 (C)Ẹ yọ̀ ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀
nítorí òun yóò gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀;
yóò sì gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá a rẹ̀
yóò sì ṣe ètùtù fún ilẹ̀ àti ènìyàn rẹ̀.
44 Mose sì wá ó sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí ní etí àwọn ènìyàn náà, òun, àti Hosea ọmọ Nuni. 45 Nígbà tí Mose parí i kíka gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí Israẹli. 46 Ó sọ fún un pé, “Ẹ gbé ọkàn an yín lé gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ láàrín yín lónìí, kí ẹ̀yin lè pàṣẹ fún àwọn ọmọ yín láti gbọ́rọ̀ àti láti ṣe gbogbo ọ̀rọ̀ inú òfin yìí. 47 Wọn kì í ṣe ọ̀rọ̀ asán fún ọ, ìyè e yín ni wọ́n. Nípa wọn ni ẹ̀yin yóò gbé pẹ́ lórí ilẹ̀ tí ẹ̀yin ń gòkè e Jordani lọ láti gbà.”
Ikú Mose lórí òkè Nebo
48 Ní ọjọ́ kan náà, Olúwa sọ fún Mose pé, 49 “Gòkè lọ sí Abarimu sí òkè Nebo ní Moabu, tí ó kọjú sí Jeriko, kí o sì wo ilẹ̀ Kenaani, ilẹ̀ tí mo ń fi fún àwọn ọmọ Israẹli, bí ìní i wọn. 50 Ní orí òkè tí ìwọ ń gùn lọ ìwọ yóò kùú níbẹ̀, kí a sì sin ọ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ, gẹ́gẹ́ bí arákùnrin in rẹ Aaroni ti kú ní orí òkè Hori tí a sì sin ín pẹ̀lú àwọn ènìyàn an rẹ̀. 51 Ìdí ni pé ẹ̀yin méjèèjì ṣẹ̀ sí mi láàrín àwọn ọmọ Israẹli ní ibi omi Meriba Kadeṣi ní aginjù Sini àti nítorí ẹ̀yin kò yà mí sí mímọ́ láàrín àwọn ọmọ Israẹli. 52 Nítorí náà, ìwọ yóò rí ilẹ̀ náà ní ọ̀kánkán, o kì yóò wọ inú rẹ̀ ilẹ̀ ti mo ti fi fún àwọn ọmọ Israẹli.”
Mose bùkún fún àwọn ẹ̀yà
33 Èyí ni ìbùkún tí Mose ènìyàn Ọlọ́run bùkún fún àwọn ọmọ Israẹli kí ó tó kú. 2 Ó sì wí pé:
“Olúwa ti Sinai wá,
ó sì yọ sí wọn láti Seiri wá
ó sì tàn án jáde láti òkè Parani wá.
Ó ti ọ̀dọ̀ ẹgbẹgbàarùn-ún àwọn mímọ́ wá
láti ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni òfin kan a mú bí iná ti jáde fún wọn wá.
3 Nítòótọ́, ó fẹ́ràn àwọn ènìyàn an rẹ̀,
gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ wà ní ọwọ́ rẹ̀.
Ní ẹsẹ̀ rẹ̀ ni wọ́n ti foríbalẹ̀,
àti lọ́dọ̀ rẹ̀ ni wọ́n ti ń gba ọ̀rọ̀,
4 òfin tí Mose fi fún wa,
ìní ti ìjọ ènìyàn Jakọbu.
5 Òun ni ọba lórí Jeṣuruni
ní ìgbà tí olórí àwọn ènìyàn péjọpọ̀,
pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà Israẹli.
6 “Jẹ́ kí Reubeni yè kí ó má ṣe kú,
tàbí kí ènìyàn rẹ mọ níwọ̀n.”
7 Èyí ni ohun tí ó sọ nípa Juda:
“Olúwa gbọ́ ohùn Juda
kí o sì mú tọ àwọn ènìyàn rẹ̀ wá.
Kí ọwọ́ rẹ̀ kí ó tó fún un,
kí ó sì ṣe ìrànlọ́wọ́ fún lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀!”
8 Ní ti Lefi ó wí pé:
“Jẹ́ kí Tumimu àti Urimu rẹ kí ó wà
pẹ̀lú ẹni mímọ́ rẹ.
Ẹni tí ó dánwò ní Massa,
ìwọ bá jà ní omi Meriba.
9 Ó wí fún baba àti ìyá rẹ pé,
‘Èmi kò buyì fún wọn.’
Kò mọ àwọn arákùnrin rẹ̀,
tàbí mọ àwọn ọmọ rẹ̀,
ṣùgbọ́n ó dúró lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀,
ó sì pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́.
10 Ó kọ́ Jakọbu ní ìdájọ́ rẹ̀
àti Israẹli ní òfin rẹ̀.
Ó mú tùràrí wá síwájú rẹ̀
àti ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ẹbọ sísun sórí i pẹpẹ rẹ̀.
11 Bùsi ohun ìní rẹ̀, Olúwa,
kí o sì tẹ́wọ́gbà iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.
Lu ẹgbẹ́ àwọn tí ó dìde sí i;
àwọn tí ó kórìíra rẹ̀,
kí wọn kí ó má ṣe dìde mọ́.”
12 Ní ti Benjamini ó wí pé:
“Jẹ́ kí olùfẹ́ Olúwa máa gbé ní àlàáfíà lọ́dọ̀ rẹ̀,
òun a máa bò ó ní gbogbo ọjọ́,
ẹni tí Olúwa fẹ́ràn yóò máa sinmi láàrín èjìká rẹ̀.”
13 Ní ti Josẹfu ó wí pé:
“Kí Olúwa bùkún ilẹ̀ rẹ,
fún ohun iyebíye láti ọ̀run pẹ̀lú ìrì
àti ibú tí ó ń bẹ níṣàlẹ̀;
14 àti fún èso iyebíye tí ọ̀run mú wá
àti ti ohun iyebíye tí ń dàgbà ní oṣooṣù;
15 pẹ̀lú ohun pàtàkì òkè ńlá ìgbàanì
àti fún ohun iyebíye ìgbà ayérayé;
16 Pẹ̀lú ohun iyebíye ayé àti ẹ̀kún un rẹ̀
àti fún ìfẹ́ ẹni tí ó ń gbé inú igbó.
Jẹ́ kí gbogbo èyí sinmi lé orí Josẹfu,
lórí àtàrí ẹni tí ó yàtọ̀ láàrín àwọn arákùnrin rẹ̀.
17 Ní ọláńlá ó dàbí àkọ́bí akọ màlúù;
ìwo rẹ̀, ìwo àgbáǹréré ni.
Pẹ̀lú wọn ni yóò fi ti àwọn orílẹ̀-èdè,
pàápàá títí dé òpin ayé.
Àwọn ní ẹgbẹẹgbàárùn-ún (10,000) Efraimu,
àwọn sì ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún (1,000) Manase.”
18 Ní ti Sebuluni ó wí pé:
“Yọ̀ Sebuluni, ní ti ìjáde lọ rẹ,
àti ìwọ Isakari, nínú àgọ́ rẹ.
19 Wọn yóò pe àwọn ènìyàn sórí òkè
àti níbẹ̀ wọn yóò rú ẹbọ òdodo,
wọn yóò mu nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ Òkun,
nínú ìṣúra tí ó pamọ́ nínú iyanrìn.”
20 Ní ti Gadi ó wí pé:
“Ìbùkún ni ẹni tí ó mú Gadi gbilẹ̀!
Gadi ń gbé níbẹ̀ bí kìnnìún,
ó sì fa apá ya, àní àtàrí.
21 Ó sì yan ilẹ̀ tí ó dára jù fún ara rẹ̀;
ìpín olórí ni a sì fi fún un.
Nígbà tí ó rí tí gbogbo àwọn ènìyàn péjọ,
ó mú òdodo Olúwa ṣẹ,
àti ìdájọ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ Israẹli.”
22 Ní ti Dani ó wí pé:
“Ọmọ kìnnìún ni Dani,
tí ń fò láti Baṣani wá.”
23 Ní ti Naftali ó wí pé:
“Ìwọ Naftali, kún fún ojúrere Ọlọ́run
àti ìbùkún Olúwa;
yóò jogún ìhà ìwọ̀-oòrùn àti gúúsù.”
24 Ní ti Aṣeri ó wí pé:
“Ìbùkún ọmọ ni ti Aṣeri;
jẹ́ kí ó rí ojúrere láti ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀
kí ó sì ri ẹsẹ̀ rẹ̀ sínú òróró.
25 Bàtà rẹ̀ yóò jẹ́ irin àti idẹ,
agbára rẹ̀ yóò sì rí bí ọjọ́ rẹ̀.
26 “Kò sí ẹlòmíràn bí Ọlọ́run Jeṣuruni,
ẹni tí ń gun ọ̀run fún ìrànlọ́wọ́ rẹ
àti ní ojú ọ̀run nínú ọláńlá rẹ̀.
27 Ọlọ́run ayérayé ni ibi ìsádi rẹ,
àti ní ìsàlẹ̀ ni apá ayérayé wà.
Yóò lé àwọn ọ̀tá rẹ níwájú rẹ,
ó sì wí pé, ‘Ẹ máa parun!’
28 Israẹli nìkan yóò jókòó ní àlàáfíà,
orísun Jakọbu nìkan
ní ilẹ̀ ọkà àti ti ọtí wáìnì,
níbi tí ọ̀run ti ń sẹ ìrì sílẹ̀.
29 Ìbùkún ni fún ọ, Israẹli,
ta ni ó dàbí rẹ,
ẹni tí a gbàlà láti ọ̀dọ̀ Olúwa?
Òun ni asà àti ìrànwọ́ rẹ̀
àti idà ọláńlá rẹ̀.
Àwọn ọ̀tá rẹ yóò tẹríba fún ọ,
ìwọ yóò sì tẹ ibi gíga wọn mọ́lẹ̀.”
Ikú Mose
34 Nígbà náà ni Mose gun òkè Nebo láti pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu sí orí Pisga tí ó dojúkọ Jeriko. Níbẹ̀ ni Olúwa ti fi gbogbo ilẹ̀ hàn án láti Gileadi dé Dani, 2 gbogbo Naftali, ilẹ̀ Efraimu àti Manase, gbogbo ilẹ̀ Juda títí dé Òkun ìwọ̀-oòrùn, 3 gúúsù àti gbogbo Àfonífojì Jeriko, ìlú ọlọ́pẹ dé Soari. 4 Nígbà náà ní Olúwa sọ fún un pé, “Èyí ni ilẹ̀ tí mo ṣèlérí lórí ìbúra fún Abrahamu, Isaaki, àti Jakọbu nígbà tí mo wí pé, ‘Èmi yóò fi fún irú-ọmọ rẹ.’ Mo ti jẹ́ kí o rí i pẹ̀lú ojú rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò dé bẹ̀.”
5 Bẹ́ẹ̀ ni Mose ìránṣẹ́ Olúwa kú ní ilẹ̀ Moabu, bí Olúwa ti wí. 6 Ó sì sin ín nínú àfonífojì ní ilẹ̀ Moabu, ní òdìkejì Beti-Peori, ṣùgbọ́n títí di òní yìí, kò sí ẹnìkan tí ó mọ ibi tí ibojì i rẹ̀ wà. 7 Mose jẹ́ ẹni ọgọ́fà ọdún nígbà tí ó kú, síbẹ̀ ojú rẹ̀ kò ṣe bàìbàì bẹ́ẹ̀ ni agbára rẹ̀ kò dínkù. 8 Àwọn ọmọ Israẹli sọkún un Mose ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu ní ọgbọ̀n ọjọ́ títí di ìgbà tí ọjọ́ ẹkún àti ọ̀fọ̀ Mose parí.
9 Joṣua ọmọ Nuni kún fún ẹ̀mí ọgbọ́n nítorí Mose ti gbọ́wọ́ ọ rẹ̀ lé e lórí. Àwọn ọmọ Israẹli sì fetí sí i wọ́n sì ṣe ohun tí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún Mose.
10 (D)Láti ìgbà náà kò sì sí wòlíì tí ó dìde ní Israẹli bí i Mose, ẹni tí Olúwa mọ̀ lójúkojú, 11 tí ó ṣe gbogbo iṣẹ́ ààmì àti iṣẹ́ ìyanu tí Olúwa rán an láti lọ ṣe ní Ejibiti sí Farao àti sí gbogbo àwọn ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀ àti sí gbogbo ilẹ̀ náà. 12 Nítorí kò sí ẹni tí ó tí ì fi gbogbo ọ̀rọ̀ agbára hàn, tàbí ṣe gbogbo ẹ̀rù ńlá tí Mose fihàn ní ojú gbogbo Israẹli.
26 Àkọlé ìfisùn tí wọ́n kọ sókè orí rẹ̀ ni:
ọba àwọn júù.
27 Wọ́n sì kan àwọn olè méjì mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀, ọ̀kan lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀, èkejì lọ́wọ́ òsì rẹ̀. 28 Eléyìí mú àsọtẹ́lẹ̀ ìwé Mímọ́ ṣẹ wí pé, “Wọ́n kà á pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn búburú.” 29 (A)Àwọn tí ń kọjá lọ sì ń fi ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n ń mi orí wọn pẹ̀lú, wọ́n sì ké pé, “Háà! Ìwọ tí yóò wó tẹmpili tí yóò sì tún un kọ́ láàrín ọjọ́ mẹ́ta, 30 sọ̀kalẹ̀ láti orí àgbélébùú wá, kí o sì gba ara rẹ là!” 31 (B)Bákan náà ni àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin fi í ṣẹ̀sín láàrín ara wọn, wọ́n wí pé, “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là ṣùgbọ́n, ara rẹ̀ ni kò lè gbàlà. 32 Jẹ́ kí Kristi, ọba Israẹli, sọ̀kalẹ̀ láti orí igi àgbélébùú wá nísinsin yìí kí àwa kí ó lè rí i, kí àwa kí ó sì lè gbàgbọ́.” Bákan náà, àwọn ti a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀ sì ń kẹ́gàn rẹ̀.
Ikú Jesu
33 (C)Nígbà tí ó di wákàtí kẹfà, òkùnkùn bo gbogbo ilẹ̀ títí di wákàtí kẹsànán. 34 (D)Ní wákàtí kẹsànán ni Jesu kígbe sókè ní ohùn rara, ó ní, “Eli, Eli, Lama Sabakitani?” (ìtumọ̀ èyí tí í ṣe, “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀?”).
35 Nígbà tí àwọn kan nínú àwọn tí wọ́n dúró níbẹ̀ gbọ́, wọ́n sì wí pé, “Wò ó ó ń pe Elijah.”
36 (E)Nígbà náà ni ẹnìkan sáré lọ ki kànìnkànìn bọ inú ọtí kíkan, ó fi lé orí ọ̀pá, ó sì nà án sí Jesu kí ó lè mu ún. Ó wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a máa wò ó, bóyá Elijah yóò wá sọ̀ ọ́ kalẹ̀ wa.”
37 Jesu sì tún kígbe sókè ni ohùn rara, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́.
38 (F)Aṣọ ìkélé tẹmpili sì fàya sí méjì láti òkè dé ìsàlẹ̀. 39 (G)Nígbà tí balógun ọ̀rún tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ ọ̀dọ̀ Jesu rí i tí ó kígbe sókè báyìí, tí ó sì jọ̀wọ́ èmí rẹ̀ lọ́wọ́, ó wí pé, “Lóòótọ́ Ọmọ Ọlọ́run ni ọkùnrin yìí í ṣe.”
40 (H)Àwọn obìnrin kan wà níbẹ̀ pẹ̀lú, tí wọ́n ń wò ó láti òkèèrè. Maria Magdalene wà lára àwọn obìnrin náà, àti Maria ìyá Jakọbu kékeré àti ti Jose, àti Salome. 41 (I)Àwọn wọ̀nyí, nígbà tí ó wà ní Galili máa ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, wọ́n a sì máa ṣe ìránṣẹ́ fún un àti ọ̀pọ̀ obìnrin mìíràn tí wọ́n sì bá a gòkè wá sí Jerusalẹmu.
Ìsìnkú Jesu
42 (J)(K) Ọjọ́ yìí jẹ́ ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ (èyí tí ṣe, ọjọ́ tó ṣáájú ọjọ́ ìsinmi). Nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ náà sì ṣú, 43 Josẹfu ará Arimatea wá, ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn ọmọ ìgbìmọ̀, ẹni tí ń retí ìjọba Ọlọ́run, ó fi ìgboyà lọ sí iwájú Pilatu láti tọrọ òkú Jesu. 44 Ẹnu ya Pilatu láti gbọ́ pé Jesu ti kú. Nítorí náà ó pe balógun ọ̀rún, ó sì bí i léèrè bóyá Jesu ti kú nítòótọ́. 45 Nígbà tí balógun ọ̀rún náà sì fún Pilatu ni ìdánilójú pé Jesu ti kú, Pilatu jọ̀wọ́ òkú rẹ̀ fún Josẹfu. 46 Josẹfu sì ti ra aṣọ ọ̀gbọ̀ wá. Ó sọ òkú Jesu kalẹ̀: ó sì fi aṣọ ọ̀gbọ̀ náà dì í. Ó sì tẹ́ ẹ sí inú ibojì, tí wọ́n gbẹ́ sí ara àpáta. Ó wá yí òkúta dí ẹnu ibojì náà. 47 Maria Magdalene àti Maria ìyá Jose ń wò ó bi Josẹfu ti n tẹ́ Jesu sí ibojì.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.