Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Deuteronomi 10-12

Wàláà òfin bí i ti ìṣáájú

10 Nígbà náà ni Olúwa wí fún mi pé, “Gbé wàláà òkúta méjì bí i ti àkọ́kọ́ kí o sì gòkè tọ̀ mí wá. Kí o sì tún fi igi kan àpótí kan. Èmi yóò sì kọ ọ̀rọ̀ tí ó wà lára wàláà àkọ́kọ́ tí ìwọ fọ́, sára wàláà wọ̀nyí. Ìwọ yóò sì fi wọ́n sínú àpótí náà.”

Mo sì kan àpótí náà pẹ̀lú igi kasia, mo sì gbẹ́ wàláà òkúta méjì náà jáde bí i ti ìṣáájú. Mo sì gòkè lọ pẹ̀lú wàláà méjèèjì lọ́wọ́ mí. Olúwa tún ohun tí ó ti kọ tẹ́lẹ̀ kọ sórí wàláà wọ̀nyí. Àwọn òfin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí ó ti sọ fún un yín lórí òkè, láàrín iná, ní ọjọ́ ìpéjọpọ̀. Olúwa sì fi wọ́n fún mi. Mo sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà, mo sì ki àwọn wàláà òkúta náà sínú àpótí tí mo ti kàn, bí Olúwa ti pàṣẹ fún mi, wọ́n sì wà níbẹ̀ di ìsinsin yìí.

(Àwọn ará Israẹli sì gbéra láti kànga àwọn ará Jaakani dé Mosera. Níbí ni Aaroni kú sí, tí a sì sin ín, Eleasari ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ bí i àlùfáà. Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti rìn lọ sí Gudgoda, títí dé Jotbata, ilẹ̀ tí o kún fún odò tí ó ń sàn. Ní ìgbà yìí ni Olúwa yan àwọn ẹ̀yà Lefi láti máa ru àpótí ẹ̀rí Olúwa, láti máa dúró níwájú Olúwa láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́, àti láti fi orúkọ Olúwa súre bí wọ́n ti ń ṣe títí di òní yìí. Ìdí nìyí tí àwọn ẹ̀yà Lefi kò fi ní ìpín tàbí ogún kan láàrín àwọn arákùnrin wọn. Olúwa ni ogún wọn gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run ti sọ fún un yín.)

10 Mo tún dúró ní orí òkè náà fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, bí mo ti ṣe ní ìgbà àkọ́kọ́, Olúwa sì gbọ́ tèmi ní àkókò yìí bákan náà. Kì í ṣe ìfẹ́ rẹ̀ láti run yín. 11 Olúwa sọ fún mi pé, “Lọ darí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní ọ̀nà wọn, kí wọn bá à lè wọ ilẹ̀ náà, kí wọn sì gba ilẹ̀ tí mo ti búra fún àwọn baba wọn láti fún wọn.”

Ẹ bẹ̀rù Olúwa

12 Nísinsin yìí ìwọ Israẹli, kín ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run rẹ béèrè lọ́wọ́ rẹ? Bí kò ṣe kí ìwọ bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run rẹ àti láti máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀, láti fẹ́ràn rẹ̀, láti fi gbogbo ọkàn rẹ sin Olúwa Ọlọ́run rẹ ọkàn àti àyà rẹ, 13 àti láti máa kíyèsi àṣẹ àti ìlànà Olúwa tí mo ń fún ọ lónìí, fún ìre ara à rẹ.

14 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé Olúwa Ọlọ́run yín ni ó ni ọ̀run àní àwọn ọ̀run tó ga ju ayé àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀. 15 Síbẹ̀ Olúwa sì tún fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn fún àwọn baba ńlá a yín, Ó sì fẹ́ wọn Ó sì yan ẹ̀yin ọmọ wọn láti borí gbogbo orílẹ̀-èdè títí di òní. 16 Ẹ kọ ọkàn yín ní ilà, (Ẹ wẹ ọkàn ẹ̀ṣẹ̀ yín mọ́) kí ẹ má sì ṣe jẹ́ olórí kunkun mọ́ láti òní lọ. 17 (A)Torí pé Olúwa Ọlọ́run yín, ni Ọlọ́run àwọn ọlọ́run àti Olúwa àwọn olúwa. Ọlọ́run alágbára, tí ó tóbi tí ó sì lẹ́rù, tí kì í ṣe ojúsàájú kì í sì í gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀. 18 Ó máa ń gbẹjọ́ aláìní baba àti opó rò, Ó fẹ́ràn àjèjì, Òun fi aṣọ àti oúnjẹ fún wọn. 19 (B)Ẹ gbọdọ̀ fẹ́ràn àwọn àjèjì, torí pé ẹ̀yin pẹ̀lú ti jẹ́ àjèjì rí ní Ejibiti. 20 Ẹ bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run yín, ẹ sì máa sìn ín. Ẹ dìímú ṣinṣin, kí ẹ sì búra ní orúkọ rẹ̀. 21 Òun ni ìyìn in yín, Òun sì ni Ọlọ́run yín, tí ó ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu ńlá àti ohun ẹ̀rù, tí ẹ fojú ara yín rí. 22 (C)Àádọ́rin (70) péré ni àwọn baba ńlá a yín tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti, ṣùgbọ́n Olúwa Ọlọ́run yín ti mú un yín pọ̀ sí i ní iye bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run.

Fẹ́ràn Olúwa kí o sì gbọ́ tirẹ̀

11 Ẹ fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run yín, kí ẹ sì pa ìfẹ́ rẹ̀, ìlànà rẹ̀, òfin rẹ̀ àti àṣẹ rẹ̀ mọ́ ní ìgbà gbogbo. Ẹ rántí lónìí pé, kì í ṣe àwọn ọmọ yín, ni ó rí ìbáwí Olúwa Ọlọ́run yín; títóbi rẹ̀, ọwọ́ agbára rẹ̀, nína ọwọ́ rẹ̀; iṣẹ́ ààmì rẹ̀ àti ohun tí ó ṣe ní àárín àwọn ará Ejibiti: Sí Farao ọba Ejibiti àti gbogbo orílẹ̀-èdè rẹ̀. Ohun tí ó ṣe sí àwọn jagunjagun Ejibiti, sí kẹ̀kẹ́ ogun àti ẹlẹ́ṣin rẹ̀: bí ó ṣe rì wọ́n sínú Òkun pupa, bí wọ́n ṣe ń lé e yín tí Olúwa fi pa wọ́n run pátápátá títí di òní olónìí yìí. Kì í ṣe àwọn ọmọ yín ni ó rí ohun tí ó ṣe fún un yín ní aginjù, títí ẹ fi dé ìhín yìí, (D)ohun tí ó ṣe sí Datani àti Abiramu, àwọn ọmọ Eliabu, ẹ̀yà Reubeni, bí ilẹ̀ ti lanu ní ojú gbogbo ará Israẹli tí ó sì gbé wọn mì pẹ̀lú gbogbo ìdílé wọn, gbogbo àgọ́ ọ wọn àti gbogbo ohun alààyè tí ó jẹ́ tiwọn. Ṣùgbọ́n ojú u yín gan an ni ó rí gbogbo nǹkan ńlá wọ̀nyí tí Olúwa ti ṣe.

Nítorí náà, ẹ kíyèsi gbogbo àṣẹ tí mo ń fún yín lónìí, kí ẹ ba à lè lágbára àti lọ, kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà tí ẹ ó la Jordani kọjá lọ. Kí ẹ ba à lè pẹ́ ní orí ilẹ̀ tí Olúwa ti búra fún àwọn baba ńlá a yín, láti fún àwọn àti àwọn ọmọ wọn: ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin. 10 Ilẹ̀ tí ẹ̀ ń wọ̀ lọ láti gbà kò rí bí ilẹ̀ Ejibiti, níbi tí ẹ ti wá, níbi tó jẹ́ wí pé ẹsẹ̀ yín ni ẹ fi ń rìn lọ bomirin irúgbìn tí ẹ gbìn bí oko ẹ̀fọ́. 11 Ṣùgbọ́n ilẹ̀ tí ẹ ó la Jordani kọjá láti gbà, jẹ́ ilẹ̀ olókè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀ tí òjò ń rọ̀ sí latọ̀run. 12 Ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run yín ń mójútó ni, ojú Olúwa Ọlọ́run yín sì ń fi ìgbà gbogbo wà lórí rẹ̀, láti ìbẹ̀rẹ̀ ọdún dé òpin ọdún.

13 (E)Nítorí náà, bí ẹ bá gbọ́rọ̀ sí àṣẹ tí mo fún un yín lónìí tọkàntọkàn: tí ẹ fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run yín, tí ẹ sì sìn ín, pẹ̀lú gbogbo àyà yín àti gbogbo ọkàn yín: 14 nígbà náà, èmi yóò rọ òjò sórí ilẹ̀ ẹ yín lákòókò rẹ̀, àti òjò àkọ́rọ̀ àti ti àrọ̀kẹ́yìn, kí ẹ ba à lè kórè oúnjẹ yín wọlé àní wáìnì tuntun àti òróró. 15 Èmi yóò mú kí koríko hù lórí ilẹ̀ yín fún àwọn ohun ọ̀sìn in yín, ẹ ó sì jẹ, ẹ ó sì yó.

16 Ẹ ṣọ́ra, kí a má ba à tàn yín jẹ láti yípadà kí ẹ sì sin ọlọ́run mìíràn àti láti máa foríbalẹ̀ fún wọn. 17 Nígbà náà ni ìbínú Olúwa yóò sì ru sí i yín, Òun yóò ti ìlẹ̀kùn ọ̀run kí òjò má ba à rọ̀, ilẹ̀ kì yóò sì so èso kankan, ẹ ó sì ṣègbé ní ilẹ̀ rere tí Olúwa fi fún un yín. 18 Ẹ fi gbogbo ọ̀rọ̀ mi wọ̀nyí sí àyà a yín, àti ọkàn an yín, ẹ so wọ́n bí ààmì sórí ọwọ́ yín, kí ẹ sì so wọ́n mọ́ iwájú orí yín. 19 Ẹ máa fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ yín, ẹ máa sọ̀rọ̀ nípa wọn bí ẹ bá jókòó nínú ilé, àti ní ojú ọ̀nà bí ẹ bá ń rìn lọ, bí ẹ bá sùn àti bí ẹ bá jí. 20 Kí ìwọ kí ó kọ wọ́n sára òpó ilé rẹ̀, àti sí ara ìlẹ̀kùn ọ̀nà òde rẹ. 21 Kí ọjọ́ ọ yín àti ti àwọn ọmọ yín lè pọ̀ ní ilẹ̀ tí Olúwa ti búra láti fi fún àwọn baba ńlá a yín, ní ìwọ̀n ìgbà tí ọ̀run wà lókè tí ayé sì ń bẹ ní ìsàlẹ̀.

22 Bí ẹ bá fi ara balẹ̀ kíyèsi àwọn òfin tí mo ń fún un yín, láti tẹ̀lé: Láti fẹ́ Olúwa Ọlọ́run yín, láti máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀ àti láti dìímú ṣinṣin: 23 Olúwa yóò sì lé gbogbo orílẹ̀-èdè wọ̀nyí kúrò níwájú u yín. Ẹ ó sì gba orílẹ̀-èdè tí ó lágbára tí ó sì tóbi jù yín lọ. 24 Gbogbo ibi tí ẹ bá fi ẹsẹ̀ ẹ yín tẹ̀ ni yóò jẹ́ tiyín, ilẹ̀ ẹ yín yóò gbilẹ̀ láti aginjù dé Lebanoni, àti láti odò Eufurate dé Òkun ìwọ̀-oòrùn. 25 Kò sí ẹni náà tí yóò lè kò yín lójú ìjà, Olúwa Ọlọ́run yín yóò fi ẹ̀rù àti ìwárìrì i yín sórí gbogbo ilẹ̀ náà bí ó ti ṣèlérí fún un yín ní gbogbo ibi tí ẹ bá lọ.

26 Ẹ kíyèsi i, mo fi ìbùkún àti ègún lélẹ̀ níwájú u yín lónìí: 27 ìbùkún ni, bí ẹ bá pa òfin Olúwa Ọlọ́run yín, tí mo ń fún un yín lónìí mọ́. 28 Ègún ni, bí ẹ bá ṣàìgbọ́ràn, sí òfin Olúwa Ọlọ́run yín, tí ẹ sì yapa kúrò ní ọ̀nà tí mo ti là sílẹ̀ fún yín lónìí, nípa títẹ̀lé ọlọ́run mìíràn, tí ẹ kò tí ì mọ̀. 29 Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run yín bá ti mú un yín dé ilẹ̀ náà tí ẹ ń wọ̀ láti gbà, kí ẹ kéde àwọn ìbùkún náà ní orí òkè Gerisimu, kí ẹ sì kéde àwọn ègún ní orí òkè Ebali. 30 Bí ẹ ti mọ̀ pé àwọn òkè wọ̀nyí wà ní ìkọjá a Jordani ní apá ìwọ̀-oòrùn lójú ọ̀nà lọ sí ìhà ìlà-oòrùn, ní ẹ̀gbẹ́ igi ńlá igbó More, ní ilẹ̀ àwọn ará a Kenaani, tí wọ́n ń gbé ní aginjù, ni agbègbè Gilgali. 31 Ẹ ti ṣetán láti la Jordani kọjá láti lè gba ilẹ̀ náà tí Olúwa Ọlọ́run yín ń fún un yín. Nígbà tí ẹ bá gbà á, tí ẹ bá sì ń gbé ibẹ̀, 32 ẹ rí i dájú pé ẹ̀ ń gbọ́rọ̀ sí gbogbo ìlànà àti òfin tí mo ń gbé kalẹ̀ fún un yín lónìí.

Ibi ìsìn kan ṣoṣo

12 (F)Wọ̀nyí ni àwọn ìlànà àti òfin tí ẹ gbọdọ̀ ṣọ́ra láti máa tẹ̀lé, ní ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín, fi fún un yín láti gbà: ní gbogbo ìgbà tí ẹ bá fi wà lórí ilẹ̀ náà. Gbogbo ibi gíga àwọn òkè ńlá, àti òkè kéékèèkéé àti lábẹ́ gbogbo igi tí ń gbilẹ̀ níbi tí àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ ó lé jáde, tí ń sin òrìṣà wọn ní kí ẹ mú kúrò pátápátá. Ẹ wó àwọn pẹpẹ wọn, ẹ bi òpó ìsìn wọn ṣubú, kí ẹ sì sun òpó Aṣerah wọn ní iná. Ẹ gé gbogbo ère òrìṣà wọn lulẹ̀, kí ẹ sì pa orúkọ wọn rẹ́ ní gbogbo ààyè wọn.

Ẹ kò gbọdọ̀ sin Olúwa Ọlọ́run yín bí i tiwọn. Ṣùgbọ́n ẹ wá ibi tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò yàn láàrín àwọn ẹ̀yà yín, láti fi orúkọ rẹ̀ síbẹ̀ bí i ibùgbé rẹ̀. Ibẹ̀ ni kí ẹ lọ. Níbẹ̀ ni kí ẹ mú ẹbọ sísun àti ẹbọ yín wá, ìdámẹ́wàá yín àti ọrẹ àkànṣe, àwọn ẹ̀jẹ́ yín, ọrẹ àtinúwá yín, àti àwọn àkọ́bí gbogbo màlúù yín àti ewúrẹ́ ẹ yín. Níwájú Olúwa Ọlọ́run yín níbẹ̀, kí ẹ̀yin àti ìdílé yín jẹun kí ẹ sì yó, nínú gbogbo ìdáwọ́lé e yín, torí pé Olúwa Ọlọ́run yín ti bùkún un yín.

Kí ẹ̀yin kí ó má ṣe ṣe gẹ́gẹ́ bí a tí ṣe níhìn-ín lónìí yìí, tí olúkúlùkù ń ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú ara rẹ̀. Níwọ́n ìgbà tí ẹ ti dé ibi ìsinmi, àti ibi ogún tí Olúwa Ọlọ́run yín fún un yín. 10 Ṣùgbọ́n ẹ ó la Jordani kọjá, ẹ ó sì máa gbé ní ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run yín fún un yín bí ìní, yóò sì fún un yín ní ìsinmi, kúrò láàrín àwọn ọ̀tá a yín, tí ó yí i yín ká, kí ẹ ba à lè máa gbé láìléwu. 11 Níbi tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò yàn bí ibùgbé fún orúkọ rẹ̀. Níbẹ̀ ni kí ẹ mú gbogbo ohun tí mo pàṣẹ fún un yín wá: àwọn ọrẹ ẹ yín àti àwọn ẹbọ sísun, ìdámẹ́wàá yín àti ọrẹ àkànṣe, àti gbogbo ohun ìní yín tí ẹ ti yàn, èyí tí ẹ ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa. 12 Kí ẹ máa yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run yín níbẹ̀, ẹ̀yin, àwọn ọmọkùnrin yín, àwọn ọmọbìnrin yín, ìránṣẹ́bìnrin àti ìránṣẹ́kùnrin yín, àti àwọn Lefi láti ìlú u yín, tí wọn kò ní ìpín tàbí ogún tiwọn. 13 Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má ṣe rú ẹbọ sísun yín ní ibikíbi tí ẹ̀yin fẹ́. 14 Ibi tí Olúwa yóò yàn láàrín àwọn ẹ̀yà a yín nìkan ni kí ẹ ti máa rú ẹbọ sísun yín, kí ẹ sì máa kíyèsi ohun gbogbo tí mo pàṣẹ fún un yín níbẹ̀.

15 Síbẹ̀síbẹ̀, ẹ lọ pa àwọn ẹran yín ní èyíkéyìí nínú àwọn ìlú u yín, kí ẹ sì jẹ ẹran náà tó bí ẹ ti fẹ́, bí ẹ ti ń ṣe sí àgbọ̀nrín àti èsúró, gẹ́gẹ́ bí ìbùkún Olúwa Ọlọ́run yín tí ó fi fún un yín, àti ẹni mímọ́ àti aláìmọ́ ni ó lè jẹ nínú àwọn ẹran náà. 16 (G)Ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ wọn, ẹ dà á sílẹ̀ bí omi. 17 Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ìdámẹ́wàá oúnjẹ yín, wáìnì tuntun, òróró, àkọ́bí àwọn màlúù yín, tàbí ti ewúrẹ́ ẹ yín, ohunkóhun tí ó jẹ́ ẹ̀jẹ́, ọrẹ àtinúwá, tàbí ẹ̀bùn pàtàkì ní ìlú ẹ̀yin tìkára yín. 18 Bí kò ṣe kí ẹ jẹ ẹ́ níwájú Olúwa Ọlọ́run yín, níbi tí Olúwa Ọlọ́run yín, yóò yàn: ìwọ, àwọn ọmọkùnrin rẹ, àwọn ọmọbìnrin rẹ, àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin rẹ àti àwọn ọmọ Lefi láti ìlú u yín: kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run yín, nínú gbogbo ìdáwọ́lé e yín. 19 Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má ṣe gbàgbé àwọn Lefi, ní gbogbo ìgbà tí ẹ bá ń gbé ní ilẹ̀ ẹ yín.

20 Olúwa Ọlọ́run yín bá ti fẹ́ agbègbè e yín bí ó ti ṣe ìlérí, fún un yín, tí ẹ sì wí pé, àwa yóò jẹ ẹran, nítorí tí ọkàn wa fẹ́ jẹran. Ẹ jẹ ẹran náà bí ẹ tí fẹ́. 21 Bí ibi tí Olúwa Ọlọ́run yín bá yàn fún orúkọ rẹ̀ bá jìnnà sí i yín, kí ẹ pa màlúù tàbí ewúrẹ́ tí Olúwa Ọlọ́run yín tí fún un yín, bí mo ti pàṣẹ fún un yín ní ìlú u yín, ẹ lè jẹ ẹ́ bí ẹ ti fẹ́. 22 Ẹ jẹ wọ́n bí ẹ ó ti jẹ èsúró tàbí àgbọ̀nrín, ẹni tí a kà sí mímọ́ àti aláìmọ́ ni ó lè jẹ ẹ́. 23 Ṣùgbọ́n ẹ rí i dájú pé ẹ kò jẹ ẹ̀jẹ̀ wọn, nítorí pé ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí, ẹ kò sì gbọdọ̀ jẹ ẹ̀mí pọ̀ mọ́ ẹran. 24 Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀, ẹ dà á sílẹ̀ bí omi. 25 Ẹ má ṣe jẹ ẹ́, kí ó bá à lè dára fún ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín, tí ń bọ̀ lẹ́yìn in yín. Nígbà yí ní ẹ tó ń ṣe ohun tí ó tọ̀nà lójú Olúwa.

26 Ẹ mú àwọn ohun tí ẹ yà sọ́tọ̀ àti àwọn ẹ̀jẹ́ yín, kí ẹ sì lọ sí ibi tí Olúwa yóò yàn. 27 Ẹ fi ẹbọ sísun yín kalẹ̀ lórí i pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run yín, àti ẹran àti ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Ẹ̀jẹ̀ ọrẹ yín ni ki ẹ dà sí pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run yín, ṣùgbọ́n ẹ lè jẹ ẹran. 28 Ẹ kíyèsára láti máa gbọ́rọ̀ sí gbogbo ìlànà tí mò ń fún un yín, kí o bá à dára fún ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín nígbà gbogbo, nítorí pé nígbà náà ní ẹ tó ń ṣe ohun tí ó dára tí ó sì tọ̀nà níwájú Olúwa Ọlọ́run yín.

29 (H)Olúwa Ọlọ́run yín yóò gé àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ fẹ́ lé kúrò tí ẹ sì fẹ́ gba ilẹ̀ wọn kúrò níwájú u yín. Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ bá ti lé wọn jáde tí ẹ sì ń gbé ilẹ̀ wọn. 30 Lẹ́yìn ìgbà tí a bá ti pa wọ́n run níwájú u yín, ẹ ṣọ́ra kí ẹ má ba à bọ́ sínú àdánwò nípa bíbéèrè nípa àwọn òrìṣà wọn wí pé, “Báwo ni àwọn orílẹ̀-èdè yìí ṣe ń sin àwọn òrìṣà wọn? Àwa náà yóò ṣe bẹ́ẹ̀” 31 Ẹ kò gbọdọ̀ sin Olúwa Ọlọ́run yín bí àwọn, torí pé, nípa sínsin ọlọ́run wọn, wọ́n ń ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìríra tí Ọlọ́run kórìíra. Wọ́n ń dáná sun àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọn láti fi rú ẹbọ sí ère òrìṣà wọn.

32 (I)Ẹ rí i pé ẹ̀ ń ṣe gbogbo ohun tí mo ti pàṣẹ fún un yín. Ẹ má ṣe fi kún un, ẹ má sì ṣe yọ kúrò níbẹ̀.

Marku 12:1-27

Òwe àwọn ayálégbé

12 (A)Lẹ́yìn ìgbà tí Jesu pa àwọn olórí ẹ̀sìn lẹ́nu mọ́: ó bẹ̀rẹ̀ sí í fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ pé, “Ọkùnrin kan gbin ọgbà àjàrà kan. Ó ṣe ọgbà yìí ká, ó sì wá ibi ìfúntí wáìnì, ó sì kọ́ ilé ìṣọ́ sí i ó sì fi ṣe àgbàtọ́jú fún àwọn olùṣọ́gbà, ó sì lọ sí ìrìnàjò tí ó jìnnà. Lákokò ìkórè, ọkùnrin náà rán ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ sí àwọn olùṣọ́gbà náà, kí ó gbà nínú èso ọgbà àjàrà náà lọ́wọ́ àwọn olùṣọ́gbà. Ṣùgbọ́n àwọn àgbẹ̀ wọ̀n-ọn-nì lu ìránṣẹ́ ọkùnrin náà, wọ́n sì rán an padà lọ́wọ́ òfo. Ó sì tún rán ọmọ ọ̀dọ̀ mìíràn sí wọn. Bí àwọn àgbẹ̀ ti tún rí ọmọ ọ̀dọ̀ tí ó rán sí wọn; wọ́n lù ú. Àní, wọ́n tilẹ̀ dá ọgbẹ́ sí i lórí, wọn rán an lọ ni ìtìjú. Ó sì tún rán òmíràn, èyí n nì wọ́n sì pa, àti ọ̀pọ̀ mìíràn, wọ́n lu òmíràn wọ́n sì pa òmíràn.

“Ìránṣẹ́ kan ṣoṣo ló kù tí Baba olóko kò ì tí ì rán níṣẹ́, èyí ni ọmọ òun tìkára rẹ̀. Níkẹyìn ó ran an sí àwọn olùṣọ́gbà náà, pẹ̀lú èrò pé, ‘Wọn yóò bu ọlá fún ọmọ òun.’

“Ṣùgbọ́n àwọn olùṣọ́gbà wọ̀n-ọn-nì wí fún ara wọn pé, ‘Èyí yìí ni àrólé. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á, ogún rẹ̀ yóò sì jẹ́ tiwa.’ Báyìí ni wọ́n mú ọmọ náà tí wọ́n pa á. Wọ́n sì wọ́ òkú rẹ̀ jáde kúrò nínú ọgbà àjàrà náà.

“Kí ni olúwa ọgbà àjàrà yóò ṣe nígbà tí ó bá gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Dájúdájú yóò pa àwọn ẹni ibi wọ̀nyí. Yóò sì gba àwọn olùtọ́jú mìíràn sínú oko rẹ̀. 10 (B)Tàbí ẹ̀yin kò ì tí ka ẹsẹ yìí nínú ìwé mímọ́:

“ ‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀
    òun náà ni ó di pàtàkì igun ilé.
11 Èyí ni iṣẹ́ Olúwa
    ó sì jẹ́ ìyàlẹ́nu lójú tiwa’?”

12 (C)Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin pẹ̀lú àwọn àgbàgbà fẹ́ mú Jesu lákokò náà. Nítorí tí wọ́n mọ̀ pé àwọn ló ń pòwe mọ́ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀. Àwọn ni alágbàtọ́jú búburú nínú ìtàn rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹ̀rù ń bà wọ́n láti fọwọ́ kàn án nítorí pé wọ́n bẹ̀rù ìhùwàsí ọ̀pọ̀ ènìyàn tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Nítorí náà wọ́n fi í sílẹ̀ lọ.

Sísan owó orí fún Kesari

13 (D)(E) Ṣùgbọ́n wọ́n rán àwọn Farisi pẹ̀lú àwọn kan tí í ṣe ọmọ-ẹ̀yìn Herodu wá sọ́dọ̀ Jesu, láti fi ọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò, títí yóò fi sọ ohun kan kí wọn lè rí fi mú. 14 Bí wọn ti dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n wí pé: “Olùkọ́, àwa mọ̀ pé ìwọ máa ń sọ òtítọ́ láìsí ìbẹ̀rù ẹnikẹ́ni. Ṣùgbọ́n òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ìwọ máa ń kọ́ni. Nísinsin yìí, sọ fún wa, ó tọ́ tàbí kò tọ́ láti máa san owó orí fún Kesari?” 15 Kí àwa kí ó fi fún un, tàbí kí a máa fi fún un?

Ṣùgbọ́n Jesu mọ ìwà àgàbàgebè wọn. Ó sì wí pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi n fi èyí dán mi wo? Ẹ mú owó idẹ kan wá kí n wò ó.” 16 Nígbà tí wọ́n mú owó idẹ náà fún un, ó bi wọ́n léèrè pé, “Ẹ wò ó! Àwòrán àti orúkọ ta ni ó wà níbẹ̀?”

Wọ́n dáhùn pé, “Àwòrán àti orúkọ Kesari ni.”

17 (F)Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ fi ohun tí ó bá jẹ́ ti Kesari fún Kesari. Ṣùgbọ́n ẹ fi ohun gbogbo tí í ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”

Ẹnu sì yà wọ́n gidigidi sí èsì rẹ̀.

Ìgbéyàwó ní àjíǹde

18 (G)Àwọn Sadusi tún wá sọ́dọ̀ rẹ̀, àwọn wọ̀nyí kò gbàgbọ́ pé àjíǹde ń bẹ. Ìbéèrè wọn ni pé, 19 (H)“Olùkọ́, Mose fún wa ní òfin pé: Nígbà tí ọkùnrin kan bá kú láìbí ọmọ, arákùnrin rẹ̀ gbọdọ̀ ṣú ìyàwó náà lópó kí wọn sì bímọ ní orúkọ ọkọ tí ó kú náà. 20 Ǹjẹ́ àwọn arákùnrin méje kan wà, èyí tí ó dàgbà jùlọ gbéyàwó, ó sì kú ní àìlọ́mọ. 21 Arákùnrin rẹ̀ kejì ṣú obìnrin tí ó fi sílẹ̀ lópó, láìpẹ́, òun pẹ̀lú tún kú láìbímọ. Arákùnrin kẹta tó ṣú obìnrin yìí lópó tún kú bákan náà láìbímọ. 22 Àwọn méjèèje sì ṣú u lópó, wọn kò sì fi ọmọ sílẹ̀. Ní ìkẹyìn gbogbo wọn, obìnrin náà kú pẹ̀lú. 23 Ǹjẹ́ ní àjíǹde, nígbà tí wọ́n bá jíǹde, aya ta ni yóò ha ṣe nínú wọn? Àwọn méjèèje ni ó sá ni ní aya?”

24 Jesu dáhùn ó wí fún wọn pé, “Kì í há ṣe nítorí èyí ni ẹ ṣe ṣìnà, pé ẹ̀yin kò mọ ìwé Mímọ́, tàbí agbára Ọlọ́run. 25 Nítorí pé, nígbà tí àwọn arákùnrin méje yìí àti obìnrin náà bá jí dìde nínú òkú, a kò ní ṣe ìgbéyàwó fún wọn. Wọn yóò dàbí àwọn angẹli tí ń bẹ ní ọ̀run. 26 (I)Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, nípa bóyá àjíǹde yóò wà. Àbí ẹ̀yin kò ì tí ka ìwé Eksodu, nípa Mose àti pápá tí ń jó? Ọlọ́run sọ fún Mose pé, ‘Èmi ni Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki àti Ọlọ́run Jakọbu.’ 27 Òun kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú bí kò ṣe Ọlọ́run àwọn alààyè: nítorí ẹ̀yin ṣe àṣìṣe gidigidi.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.