Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

M’Cheyne Bible Reading Plan

The classic M'Cheyne plan--read the Old Testament, New Testament, and Psalms or Gospels every day.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
1 Ọba 9

Olúwa farahan Solomoni

(A)Nígbà tí Solomoni sì parí kíkọ́ ilé Olúwa àti ààfin ọba, tí ó sì ti ṣe gbogbo nǹkan tí ó ń fẹ́ láti ṣe, Olúwa sì farahàn Solomoni ní ìgbà kejì, bí ó ti farahàn án ní Gibeoni. Olúwa sì wí fún un pé:

“Èmi ti gbọ́ àdúrà rẹ àti ẹ̀bẹ̀ rẹ tí ìwọ ti bẹ̀ níwájú mi, mo ti ya ilé yìí sí mímọ́, tí ìwọ ti kọ́, nípa fífi orúkọ mi síbẹ̀ títí láé. Ojú mi àti ọkàn mi yóò wà níbẹ̀ nígbà gbogbo.

“Bí ìwọ bá rìn níwájú mi ní ọkàn òtítọ́ àti ìdúró ṣinṣin, bí i Dafidi baba rẹ ti rìn, kí o sì ṣe gbogbo èyí tí mo ti paláṣẹ fún ọ àti kí o sì pa àṣẹ mi àti òfin mi mọ́, Èmi yóò fi ìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ múlẹ̀ lórí Israẹli títí láé, bí mo ti ṣe ìlérí fún Dafidi baba rẹ nígbà tí mo wí pé, ‘Ìwọ kì yóò kùnà láti ní ọkùnrin kan lórí ìtẹ́ Israẹli.’

“Ṣùgbọ́n tí ìwọ tàbí àwọn ọmọ rẹ bá yípadà kúrò lọ́dọ̀ mi, tí ẹ kò sì pa òfin mi mọ́ àti àṣẹ mi tí mo ti fi fún ọ, tí ẹ sì lọ láti sin ọlọ́run mìíràn, tí ẹ sì ń sìn wọ́n, nígbà náà ni èmi yóò ké Israẹli kúrò ní ilẹ̀ tí èmi fi fún wọn, èmi yóò sì kọ ilé yìí tí èmi ti yà sí mímọ́ fún orúkọ mi. Nígbà náà ni Israẹli yóò sì di òwe àti ìmúṣẹ̀sín láàrín gbogbo orílẹ̀-èdè. Àti ilé yìí tí ó ga, ẹnu yóò sì ya olúkúlùkù ẹni tí ó kọjá lẹ́bàá rẹ̀, yóò sì pòṣé, wọn ó sì wí pé, ‘Èéṣe tí Olúwa fi ṣe irú nǹkan yìí sí ilẹ̀ yìí àti ilé yìí?’ Àwọn ènìyàn yóò sì dáhùn wí pé, ‘Nítorí tí wọ́n ti kọ̀ Olúwa Ọlọ́run wọn sílẹ̀, tí ó mú àwọn baba wọn jáde láti Ejibiti wá, wọ́n sì ti gbá ọlọ́run mìíràn mú, wọ́n ń bọ wọ́n, wọ́n sì ń sìn wọ́n, ìdí nìyìí tí Olúwa ṣe mú gbogbo ìjàǹbá yìí wá sórí wọn.’ ”

Ojúṣe Solomoni mìíràn

10 Lẹ́yìn ogún ọdún, nígbà tí Solomoni kọ́ ilé méjèèjì yìí tan: ilé Olúwa àti ààfin ọba. 11 Solomoni ọba sì fi ogún ìlú ní Galili fún Hiramu ọba Tire, nítorí tí Hiramu ti bá a wá igi kedari àti igi firi àti wúrà gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìfẹ́ rẹ̀. 12 Ṣùgbọ́n nígbà tí Hiramu sì jáde láti Tire lọ wo ìlú tí Solomoni fi fún un, inú rẹ̀ kò sì dùn sí wọn. 13 Ó sì wí pé, “Irú ìlú wo nìwọ̀nyí tí ìwọ fi fún mi, arákùnrin mi?” Ó sì pè wọ́n ní ilẹ̀ Kabulu títí fi di òní yìí. 14 Hiramu sì ti fi ọgọ́fà (120) tálẹ́ǹtì wúrà ránṣẹ́ sí ọba.

15 Ìdí àwọn asìnrú ti Solomoni ọba kójọ ni èyí; láti kọ́ ilé Olúwa àti ààfin òun tìkára rẹ̀; Millo, odi Jerusalẹmu, Hasori, Megido àti Geseri. 16 Farao ọba Ejibiti sì ti kọlu Geseri, ó sì ti fi iná sun ún, ó sì pa àwọn ará Kenaani tí ń gbé ìlú náà, ó sì fi ta ọmọbìnrin rẹ̀, aya Solomoni lọ́rẹ. 17 Solomoni sì tún Geseri kọ́, àti Beti-Horoni ìsàlẹ̀, 18 Àti Baalati àti Tadmori ní aginjù, láàrín rẹ̀, 19 Àti gbogbo ìlú ìṣúra tí Solomoni ní, àti ìlú kẹ̀kẹ́ rẹ̀, àti ìlú fún àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀, àti èyí tí ó ń fẹ́ láti kọ́ ní Jerusalẹmu, ní Lebanoni àti ní gbogbo ilẹ̀ ìjọba rẹ̀ tí ó ń ṣe àkóso.

20 Gbogbo ènìyàn tí ó kù nínú àwọn ará Amori ará Hiti, Peresi, Hifi àti Jebusi, àwọn ènìyàn wọ̀nyí kì í ṣe ará Israẹli, 21 ìyẹn ni pé àwọn ọmọ wọn tí ó kù ní ilẹ̀ náà, tí àwọn ọmọ Israẹli kò le parun pátápátá, àwọn ni Solomoni bu iṣẹ́ ẹrú fún títí di òní yìí. 22 Ṣùgbọ́n, Solomoni kò fi ẹnìkankan ṣe ẹrú nínú àwọn ọmọ Israẹli; àwọn ni ológun rẹ̀ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àti àwọn ìjòyè rẹ̀, àti àwọn balógun rẹ̀, àti àwọn olórí kẹ̀kẹ́ rẹ̀ àti ti àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀. 23 Àwọn sì tún ni àwọn olórí olùtọ́jú tí wọ́n wà lórí iṣẹ́ Solomoni, àádọ́ta-dín-lẹ́gbẹ̀ta (550), ní ń ṣe àkóso lórí àwọn ènìyàn tí ń ṣe iṣẹ́ náà.

24 Lẹ́yìn ìgbà tí ọmọbìnrin Farao ti gòkè láti ìlú Dafidi wá sí ààfin tí Solomoni kọ́ fún un, nígbà náà ni ó kọ́ Millo.

25 Nígbà mẹ́ta lọ́dún ni Solomoni ń rú ẹbọ sísun àti ẹbọ àlàáfíà lórí pẹpẹ tí ó tẹ́ fún Olúwa, ó sì sun tùràrí níwájú Olúwa pẹ̀lú wọn, bẹ́ẹ̀ ni ó parí ilé náà.

26 Solomoni ọba sì túnṣe òwò ọkọ̀ ní Esioni-Geberi, tí ó wà ní ẹ̀bá Elati ní Edomu, létí Òkun Pupa. 27 Hiramu sì rán àwọn ènìyàn rẹ̀, àwọn atukọ̀ tí ó mọ Òkun, pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ Solomoni. 28 Wọ́n sì dé ofiri, wọ́n sì mú irínwó ó lé ogún (420) tálẹ́ǹtì wúrà, tí wọ́n ti gbà wá fún Solomoni ọba.

Efesu 6

Àwọn ọmọ àti àwọn òbí

Ẹ̀yin ọmọ, ẹ máa gbọ́ tí àwọn òbí i yín nínú Olúwa: nítorí pé èyí ní ó tọ́. (A)“Bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ,” èyí tí í ṣe òfin kìn-ín-ní pẹ̀lú ìlérí, (B)“ki ó lé dára fún ọ, àti kí ìwọ lè wà pẹ́ ní ayé.”

Àti ẹ̀yin baba, ẹ má ṣe mú àwọn ọmọ yín bínú, ṣùgbọ́n ẹ máa tọ́ wọn nínú ẹ̀kọ́ àti ìkìlọ̀ Olúwa.

Àwọn ẹrú àti olówó wọn

Ẹ̀yin ọmọ ọ̀dọ̀, ẹ máa gbọ́ ti àwọn olúwa yín nípá ti ara, pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì, nínú òtítọ́ ọkàn yín, bí ẹni pé sí Kristi. Gbọ́ ọ̀rọ̀ sí wọn lẹ́nu kì í ṣe láti rí ojúrere wọn nígbà tí ojú wọn bá ń bẹ lára rẹ, ṣùgbọ́n bí ẹrú Kristi, ní ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run láti inú ọkàn rẹ. Ẹ máa fi gbogbo ọkàn yin ṣe iṣẹ́ ìsìn bí sí Olúwa, kì í sí ṣe sí ènìyàn. Bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé ohun rere tí olúkúlùkù bá ṣe òun náà ní yóò sí gbà padà lọ́dọ̀ Olúwa, ìbá à ṣe ẹrú, tàbí òmìnira.

Àti ẹ̀yin ọ̀gá, ẹ máa ṣe irú ìtọ́jú kan náà sí àwọn ẹrú yin, ẹ máa dín ìbẹ̀rù yín kù bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé Olúwa ẹ̀yin tìkára yín ń bẹ ní ọ̀run; kò sì ṣí ojúsàájú ènìyàn lọ́dọ̀ rẹ̀.

Ìhámọ́ra Ọlọ́run

10 Ní àkótán, ara mí, ẹ jẹ́ alágbára nínú Olúwa, àti nínú agbára ipá rẹ̀. 11 Ẹ gbé gbogbo ìhámọ́ra Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ̀yin lè kọ ojú ìjà sí àrékérekè èṣù. 12 Nítorí pé kì í ṣe ẹ̀jẹ̀ àti ẹran-ara ní àwa ń bá jìjàkadì, ṣùgbọ́n àwọn ìjòyè, àwọn ọlọ́lá, àwọn aláṣẹ ìbí òkùnkùn ayé yìí, àti àwọn ẹ̀mí búburú ní ojú ọ̀run. 13 Nítorí náà, ẹ gbé gbogbo ìhámọ́ra Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ̀yin lè dúró tiiri sí ọjọ́ ibi, nígbà tí ẹ̀yin bá sì ti ṣe ohun gbogbo tan kí ẹ sì dúró. 14 (C)Ẹ dúró nítorí náà lẹ́yìn tí ẹ fi àmùrè òtítọ́ dì ẹ̀gbẹ́ yin, tí ẹ sì ti di ìgbàyà òdodo mọ́ra. 15 (D)Tí ẹ sì ti fi ìmúra ìhìnrere àlàáfíà wọ ẹsẹ̀ yín ní bàtà. 16 Ní àfikún, ẹ mú apata ìgbàgbọ́, nípa èyí tí ẹ̀yin lè máa fi paná gbogbo ọfà iná ẹni ibi náà. 17 Kí ẹ sì mú àṣíborí ìgbàlà, àti idà ẹ̀mí, tí í ṣe ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

18 Pẹ̀lú gbogbo àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ ni kí ẹ máa gbàdúrà nígbà gbogbo nínú Ẹ̀mí, kí ẹ sì máa ṣọ́ra sí i nínú ìdúró ṣinṣin gbogbo àti ẹ̀bẹ̀ fún gbogbo ènìyàn mímọ́. 19 Kí ẹ sì máa gbàdúrà fún mí pẹ̀lú, kí Ọlọ́run lè fún mí ní ọ̀rọ̀ tí ó yẹ kí èmi lè máa fì ìgboyà sọ àwọn ohun ìjìnlẹ̀ ìhìnrere náà. 20 Nítorí èyí tí èmí jẹ́ ikọ̀ nínú ẹ̀wọ̀n: kí èmi lè máa fi ìgboyà sọ̀rọ̀ nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ fún mí láti máa sọ.

Àwọn ìkíni ìkẹyìn

21 (E) Tikiku, arákùnrin olùfẹ́ àti ìránṣẹ́ olóòtítọ́ nínú Olúwa yóò sọ ohun gbogbo dí mí mọ̀ fún yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú lè mọ̀ bí nǹkan ti rí fún mí àti bí mo tí ń ṣe sí. 22 Ẹni tí mo rán sí yín nítorí èyí náà, kí ẹ lè mọ̀ bí a tí wà, kì òun lè tu ọkàn yín nínú.

23 Àlàáfíà fún àwọn ará, àti ìfẹ́ pẹ̀lú ìgbàgbọ́, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wà, àti Olúwa wà Jesu Kristi.

24 Kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó fẹ́ Olúwa wa Jesu Kristi ni àìṣẹ̀tàn.

Esekiẹli 39

39 “Ọmọ ènìyàn, sọtẹ́lẹ̀ sí Gogu, kí ó sì wí pé: ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Èmi lòdì sí ọ, Ìwọ Gogu, olórí ọmọ-aládé ti Meṣeki àti Tubali. Èmi yóò dá ọ padà, èmi yóò sì darí rẹ. Èmi yóò mú ọ wá láti jìnnàjìnnà ìhà àríwá, Èmi yóò rán ọ lòdì sí orí àwọn òkè gíga Israẹli. Nígbà náà èmi yóò lu ọrùn awọ rẹ ní ọwọ́ òsì rẹ, èmi yóò sì mú kí àwọn ọfà rẹ jábọ́ ni ọwọ́ ọ̀tún rẹ. (A)Ìwọ yóò sì ṣubú ní orí àwọn òkè Israẹli, ìwọ àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ àti gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà pẹ̀lú rẹ. Èmi yóò fi ọ ṣe oúnjẹ fún àwọn onírúurú ẹyẹ àti fún àwọn ẹranko igbó. Ìwọ yóò ṣubú ní gbangba pápá, nítorí tì mo ti sọ̀rọ̀, ni Olúwa Olódùmarè wí. Èmi yóò fi iná sí Magogu àti sí àwọn tí ń gbé ní agbègbè ilẹ̀ ibẹ̀ ní àìléwu, wọn yóò sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa.

“ ‘Èmi yóò sọ orúkọ mímọ́ mí di mí mọ̀ láàrín àwọn ènìyàn mì Israẹli. Èmi ki yóò jẹ́ kí orúkọ mímọ́ mi di aláìmọ́ àwọn orílẹ̀-èdè yóò mọ̀ pé èmi Olúwa, èmi ni ẹni mímọ́ ní Israẹli. Ó ń bọ̀! Ó dájú pé yóò ṣẹlẹ̀, ni Olúwa Olódùmarè. Èyí yìí ni ọjọ́ tí mo sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.

“ ‘Nígbà náà, àwọn ti ó ń gbé nì àárín àwọn ìlú tí ó wà ni Israẹli yóò jáde, wọn yóò sì lo àwọn ohun ìjà bi epo ìdáná yóò sì jó wọ́n kanlẹ̀—àpáta kéékèèkéé àti àpáta ńlá, àwọn ọfà, àwọn kùmọ̀ ogun àti ọ̀kọ̀ fún ọdún méje wọn yóò lò wọ́n bi epo ìdáná. 10 Wọn kò ní nílò láti kó igi jọ láti inú pápá, tàbí gé e láti inú igbó, nítorí pé wọ́n yóò lo òhun ìjà ogun bi epo ìdáná. Wọn yóò sì kógun àwọn tí ó ṣe ìgárá sí wọn, wọn yóò sì bo ilé àwọn tí ó bo ilé wọn, ni Olúwa Olódùmarè.

11 “ ‘Ní ọjọ́ náà èmi yóò sì fi ibi ìsìnkú fún Gogu ní Israẹli, ni àfonífojì àwọn ti ó rìn ìrìnàjò lọ sí agbègbè ilà oòrùn Òkun. Yóò di ojú ọ̀nà àwọn arìnrìn-àjò, nítorí Gogu àti gbogbo ìjọ rẹ̀ ni àwa yóò sin síbẹ̀. Nítorí náà, a yóò pè é ní Àfonífojì tí Ammoni Gogu.

12 “ ‘Fún oṣù méje ní ilé Israẹli yóò fi máa sìn wọ́n láti ṣe àfọ̀mọ́ ilẹ̀ náà. 13 Gbogbo ènìyàn ilẹ̀ náà yóò sìn wọ́n, ọjọ́ tí a yìn mi lógo yóò jẹ́ ọjọ́ ìrántí, ní Olúwa Olódùmarè wí.

14 “ ‘Wọn yóò gbà àwọn ènìyàn ṣiṣẹ́ lóòrèkóòrè láti ṣe àfọ̀mọ́ náà. Ọ̀pọ̀ yóò lọ káàkiri ilẹ̀ náà, ní àfikún pẹ̀lú wọn, àwọn tókù yóò sìn àwọn tí ó kú lórí ilẹ̀: Ní ìparí oṣù keje wọn yóò bẹ̀rẹ̀ wíwá kiri wọn. 15 Bí wọ́n n lọ káàkiri ilẹ̀ náà ọ̀kan nínú wọn rí egungun ènìyàn, òun yóò gbé ààmì ńlá kalẹ̀ ni ẹ̀gbẹ́ rẹ títí àwọn asìnkú yóò fi sìn ín ní Àfonífojì Hamoni Gogu. 16 (Bákan náà ìlú kan tí a ń pè ni Hamona yóò wà níbẹ̀). Nítorí náà wọn yóò wẹ ilẹ̀ náà:’

17 “Ọmọ ènìyàn èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí pé: Pe gbogbo oríṣìíríṣìí ẹyẹ àti gbogbo àwọn ẹranko igbó jáde: ‘Kí wọn péjọpọ̀ láti gbogbo agbègbè sí ìrúbọ tí mó ń múra rẹ̀ fún ọ, ìrúbọ ńlá náà ní orí òkè gíga tí Israẹli. Níbẹ̀ ẹ̀yin yóò jẹ ẹran, ẹ̀yin yóò sì mú ẹ̀jẹ̀. 18 Ẹ̀yin yóò jẹ ẹran-ara àwọn ènìyàn ńlá, ẹ o sì mú ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọ-aládé ayé bí ẹni pé wọn jẹ́ àgbò àti ọ̀dọ́-àgùntàn, ewúrẹ́ àti akọ màlúù gbogbo wọn jẹ́ ẹran ọlọ́ràá láti Baṣani 19 Níbi ìrúbọ tí mo ń múra kalẹ̀ fún yín, ẹ̀yin yóò jẹ ọ̀rá títí ẹ̀yin yóò fi jẹ àjẹkì, ẹ̀yin yóò sì mú ẹ̀jẹ̀ títí ẹ̀yin yóò fi yó. 20 Ní orí tábìlì mi ni àwa yóò ti fi ẹṣin àti ẹlẹ́ṣin bọ yín yó, pẹ̀lú àwọn alágbára ńlá àti oríṣìíríṣìí jagunjagun,’ ni Olúwa Olódùmarè wí.

21 “Èmi yóò ṣe àfihàn ògo mi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì rí ìyà tí mo fi jẹ wọ́n. 22 Láti ọjọ́ náà lọ, ilé Israẹli yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn. 23 Àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì mọ̀ pé àwọn ènìyàn Israẹli lọ sí ìgbèkùn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, nítorí pé wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ sí mi. Nítorí náà mo mú ojú mi pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn, mo sì fi wọn lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́, gbogbo wọn sì ṣubú nípasẹ̀ idà. 24 Mo ṣe sí wọn gẹ́gẹ́ bí àìmọ́ àti àìṣedéédéé wọn, mo sì mú ojú mi pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn.

25 “Nítorí náà èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Èmi yóò mú Jakọbu padà kúrò ní oko ẹrú, èmi yóò ní ìyọ́nú si gbogbo ènìyàn Israẹli, èmi yóò sì ní ìtara fún orúkọ mímọ́ mi. 26 Wọn yóò gbàgbé ìtìjú wọn àti gbogbo àìṣòdodo tí wọ́n fihàn sí mi nígbà tí wọn ń gbé ni àìléwu ni ilẹ̀ wọn níbi tí kò ti sí ẹnikẹ́ni láti dẹ́rùbà wọ́n. 27 Nígbà tí mo ti mú wọn padà kúrò ní àwọn orílẹ̀-èdè, tí mo sì kó wọn jọ pọ̀ kúrò ni ìlú àwọn ọ̀tá wọn, èmi yóò fi ara mi hàn ni mímọ́ nípasẹ̀ wọn ní ojú àwọn orílẹ̀-èdè púpọ̀. 28 Nígbà náà, wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn nítorí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo rán wọn lọ sí ìgbèkùn láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, èmi yóò kó wọn jọ sí orí ilẹ̀ wọn, láìfi nǹkan kan sẹ́yìn. 29 Èmi kì yóò sì fi ojú mi pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn mọ nítorí èmi yóò tú èémí mi jáde sí ilé Israẹli, ní Olúwa Olódùmarè wí.”

Saamu 90

ÌWÉ KẸRIN

Saamu 90–106

Àdúrà Mose ènìyàn Ọlọ́run

90 Olúwa, ìwọ ti jẹ́ ibùgbé wa ní gbogbo ìran dé ìran.
Kí a tó bí àwọn òkè ńlá
    àti kí ìwọ tó dá ilẹ̀ àti ayé,
láti ayérayé dé ayérayé ìwọ ni Ọlọ́run.

Ìwọ yí ènìyàn padà sí erùpẹ̀,
    wí pé “Padà sí erùpẹ̀, ìwọ ọmọ ènìyàn.”
(A)Nítorí pé ìgbà tí ẹgbẹ̀rún ọdún bá kọjá lójú rẹ,
    bí àná ni ó rí, bí ìgbà ìṣọ́ kan lóru.
Ìwọ gbá ènìyàn dànù nínú oorun ikú;
    wọ́n dàbí koríko tuntun ní òwúrọ̀.
Lóòtítọ́, ní òwúrọ̀, ó yọ tuntun
    ní àṣálẹ́ ni yóò gbẹ, tí yóò sì rẹ̀ dànù.

A pa wá run nípa ìbínú rẹ
    nípa ìbínú rẹ ara kò rọ̀ wá.
Ìwọ ti gbé ẹ̀ṣẹ̀ wa ka iwájú rẹ,
    àti ohun ìkọ̀kọ̀ wa nínú ìmọ́lẹ̀ iwájú rẹ,
Gbogbo ọjọ́ wa ń kọjá lọ lábẹ́ ìbínú rẹ;
    àwa ń lo ọjọ́ wa lọ bí àlá tí à ń rọ́.
10 Àádọ́rin ọdún ni iye ọjọ́ ọdún wá,
    bi ó sì ṣe pé nípa agbára
tí wọn bá tó ọgọ́rin ọdún,
    agbára nínú làálàá pẹ̀lú ìbànújẹ́ ni,
nítorí pé a kò ní pẹ́ gé e kúrò,
    àwa a sì fò lọ.
11 Ta ni ó mọ agbára ìbínú rẹ?
    Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rù rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ìbínú rẹ.
12 Kọ́ wa bí a ti ń kaye ọjọ́ wa dáradára,
    kí àwa ba à lè fi ọkàn wa sípa ọgbọ́n.

13 Yípadà, Olúwa! Yóò ti pẹ́ tó?
    Ṣàánú fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ.
14 Tẹ́ wa lọ́rùn ní òwúrọ̀ nínú ìṣeun ìfẹ́ rẹ,
    kí àwa kí ó lè kọrin fún ayọ̀
    kí inú wa sì dùn ní gbogbo ọjọ́.
15 Mú inú wa dùn bí ọjọ́ tí ìwọ ti pọ́n wa lójú,
    fún ọjọ́ púpọ̀ tí àwa ti rí wàhálà.
16 Jẹ́ kí a fi iṣẹ́ rẹ̀ han àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀,
    ògo rẹ̀ sí àwọn ọmọ wọn.

17 Jẹ́ kí ẹwà Olúwa Ọlọ́run wa wà lára wa;
    fi ìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀ lára wa
    bẹ́ẹ̀ ni, kí ó sì fi ìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.