Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

M’Cheyne Bible Reading Plan

The classic M'Cheyne plan--read the Old Testament, New Testament, and Psalms or Gospels every day.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
1 Ọba 14

Ahijah sọtẹ́lẹ̀ fún Jeroboamu

14 Ní àkókò náà Abijah ọmọ Jeroboamu sì ṣàìsàn, Jeroboamu sì wí fún aya rẹ̀ pé, “Lọ, sì pa ara rẹ dà, kí wọn kí ó má ba à mọ̀ ọ́n ní aya Jeroboamu. Nígbà náà ni kí o lọ sí Ṣilo. Ahijah wòlíì wà níbẹ̀; ẹni tí ó sọ fún mi pé, èmi yóò jẹ ọba lórí àwọn ènìyàn yìí. Mú ìṣù àkàrà mẹ́wàá pẹ̀lú rẹ̀, àti àkàrà wẹ́wẹ́ àti ìgò oyin, kí o sì lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Òun yóò sì sọ fún ọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ọmọkùnrin náà.” Bẹ́ẹ̀ ni aya Jeroboamu sì ṣe bí ó ti wí, ó sì lọ sí ilé Ahijah ní Ṣilo.

Ahijah kò sì ríran; ojú rẹ̀ ti fọ́ nítorí ogbó rẹ̀. Ṣùgbọ́n Olúwa ti sọ fún Ahijah pé, “Kíyèsi i, aya Jeroboamu ń bọ̀ wá béèrè nípa ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ, nítorí tí ó ṣàìsàn, báyìí báyìí ni kí ìwọ kí ó wí fún un. Nígbà tí ó bá dé, yóò ṣe ara rẹ̀ bí ẹlòmíràn.”

Bẹ́ẹ̀ ni ó sì rí, nígbà tí Ahijah sì gbọ́ ìró ẹsẹ̀ rẹ̀ ní ẹnu-ọ̀nà, ó sì wí pé, “Wọlé wá, aya Jeroboamu. Kí ló dé tí ìwọ fi ṣe ara rẹ bí ẹlòmíràn? A ti fi iṣẹ́ búburú rán mi sí ọ. Lọ, sọ fún Jeroboamu pé báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí; Èmi sì gbé ọ ga láti inú àwọn ènìyàn, mo sì fi ọ́ jẹ olórí lórí Israẹli ènìyàn mi. Mo fa ìjọba náà ya kúrò ní ilé Dafidi, mo sì fi fún ọ ṣùgbọ́n, ìwọ kò dàbí Dafidi ìránṣẹ́ mi, tí ó pa àṣẹ mi mọ́, tí ó sì tọ̀ mí lẹ́yìn tọkàntọkàn rẹ̀, láti ṣe kìkì èyí tí ó tọ́ ní ojú mi. Ìwọ sì ti ṣe búburú ju gbogbo àwọn tí ó ti wà ṣáájú rẹ lọ. Ìwọ sì ti ṣe àwọn ọlọ́run mìíràn fún ara rẹ, àwọn òrìṣà tí a gbẹ́; o sì ti mú mi bínú, o sì ti gbé mi sọ sí ẹ̀yìn rẹ.

10 “ ‘Nítorí èyí, Èmi yóò mú ibi wá sí ilé Jeroboamu. Èmi yóò ké gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin kúrò lọ́dọ̀ Jeroboamu, àti ọmọ ọ̀dọ̀ àti òmìnira ní Israẹli. Èmi yóò mú ilé Jeroboamu kúrò bí ènìyàn ti ń kó ìgbẹ́ kúrò, títí gbogbo rẹ̀ yóò fi tán. 11 Ajá yóò jẹ ẹni Jeroboamu tí ó bá kú ní ìlú, àti ẹni tí ó bá kú ní igbó ni àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run yóò jẹ. Olúwa ti sọ ọ́!’

12 “Ní ti ìwọ, padà lọ ilé, nígbà tí o bá sì fi ẹsẹ̀ rẹ tẹ ìlú, ọmọ náà yóò kú. 13 Gbogbo Israẹli yóò sì ṣọ̀fọ̀ fún un, wọn yóò sì sin ín. Òun nìkan ni a ó sì sin nínú ẹni tí ń ṣe ti Jeroboamu, nítorí lọ́dọ̀ rẹ̀ nìkan ni a ti rí ohun rere díẹ̀ sípa Olúwa Ọlọ́run Israẹli, ní ilé Jeroboamu.

14 Olúwa yóò gbé ọba kan dìde fúnrarẹ̀ lórí Israẹli tí yóò ké ilé Jeroboamu kúrò. Ọjọ́ náà nìyìí! Kí ni? Àní nísinsin yìí. 15 Olúwa yóò kọlu Israẹli, yóò sì dàbí koríko ti ń mì nínú omi. Yóò sì fa Israẹli tu kúrò ní ilẹ̀ rere yìí, tí ó ti fi fún àwọn baba wọn, yóò sì fọ́n wọn ká kọjá odò Eufurate, nítorí wọ́n ti rú ìbínú Olúwa nípa ṣíṣe ère Aṣerah. 16 Yóò sì kọ Israẹli sílẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí Jeroboamu ti ṣẹ̀ àti tí ó mú Israẹli ṣẹ̀.”

17 Nígbà náà ni aya Jeroboamu sì dìde, ó sì lọ, ó sì lọ sí Tirsa. Bí ó sì ti fi ẹsẹ̀ tẹ ìloro ilé, ọmọdé náà sì kú. 18 Wọ́n sì sin ín, gbogbo Israẹli sì ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti wí láti ẹnu ìránṣẹ́ rẹ̀, Ahijah wòlíì.

19 Ìyókù ìṣe Jeroboamu, bí ó ti jagun, àti bí ó ti jẹ ọba, ni a kọ sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Israẹli. 20 Jeroboamu sì jẹ ọba fún ọdún méjìlélógún, ó sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. Nadabu ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

Rehoboamu ọba Juda

21 Rehoboamu ọmọ Solomoni sì jẹ ọba ní Juda. Ó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélógún nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ ọba, ó sì jẹ ọba ní ọdún mọ́kànlélógún ní Jerusalẹmu, ìlú tí Olúwa ti yàn nínú gbogbo ẹ̀yà Israẹli láti fi orúkọ rẹ̀ síbẹ̀. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Naama, ará Ammoni.

22 Juda sì ṣe búburú níwájú Olúwa nípa ẹ̀ṣẹ̀ wọn tí wọ́n ti dá, wọ́n sì mú u jowú ju gbogbo èyí tí baba wọn ti ṣe lọ. 23 Wọ́n sì tún kọ́ ibi gíga fún ara wọn, àti ère òkúta àti òpó Aṣerah lórí gbogbo òkè gíga, àti lábẹ́ gbogbo igi tútù. 24 Àwọn tí wọn jẹ́ ọkùnrin alágbèrè ojúbọ òrìṣà wà ní ilẹ̀ náà, àwọn ènìyàn náà sì ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun ìríra àwọn orílẹ̀-èdè tí Olúwa ti lé jáde kúrò níwájú àwọn ọmọ Israẹli.

25 (A)Ó sì ṣe ní ọdún karùn-ún Rehoboamu, Ṣiṣaki ọba Ejibiti kọlu Jerusalẹmu. 26 Ó sì kó ìṣúra ilé Olúwa lọ àti ìṣúra ilé ọba. Gbogbo rẹ̀ ni ó kó lọ, pẹ̀lú asà wúrà tí Solomoni ti ṣe. 27 Rehoboamu ọba sì ṣe asà idẹ ní ipò wọn, ó sì fi wọ́n sí ọwọ́ olórí àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ́ ìlẹ̀kùn ilé ọba. 28 Nígbàkígbà tí ọba bá sì lọ sí ilé Olúwa Wọ́n á rù wọ́n, wọ́n á sì mú wọn padà sínú yàrá olùṣọ́.

29 Ní ti ìyókù ìṣe Rehoboamu, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ǹjẹ́ a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Juda bí? 30 Ogun sì wà láàrín Rehoboamu àti Jeroboamu ní ọjọ́ wọn gbogbo. 31 Rehoboamu sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín pẹ̀lú wọn ní Ìlú Dafidi. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Naama; ará Ammoni. Abijah ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

Kolose 1

Paulu, aposteli Jesu Kristi nípa ìfẹ́ Ọlọ́run àti Timotiu arákùnrin wa.

(A)Sí àwọn ẹni mímọ́ àti àwọn arákùnrin àti arábìnrin nínú Kristi tí wọ́n ń gbé ní ìlú Kolose.

Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún un yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa.

Àwọn ọpẹ́ àti àdúrà

(B)Nígbàkúgbà tí a bá ń gbàdúrà fún un yín ni a máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run Baba Olúwa wa Jesu Kristi. Nítorí a ti gbúròó ìgbàgbọ́ yín nínú Jesu Kristi, àti bí ẹ ti ṣe fẹ́ràn gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́. Ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ tí ń sàn nínú ìrètí tí a gbé pamọ́ fún un yín ní ọ̀run èyí tí ẹ̀yin sì ti gbọ́ tẹ́lẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ òtítọ́ ìhìnrere náà, èyí tí ó ti dé ọ̀dọ̀ yín. Káàkiri àgbáyé ni ìhìnrere yìí ń so èso tí ó sì ń dàgbà, gẹ́gẹ́ bí ó ti ń ṣe láàrín yín láti ọjọ́ náà tí ẹ ti gbọ́ ọ, tí ẹ sì ní ìmọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run nínú gbogbo òtítọ́ rẹ̀. (C)Ẹ̀yin ti kọ́ ọ lọ́dọ̀ Epafira, ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wa olùfẹ́, ẹni tí ó jẹ́ olóòtítọ́ ìránṣẹ́ Kristi ní ipò wa. Ẹni ti ó sọ fún wa nípa ìfẹ́ yín nínú ẹ̀mí.

(D)Nítorí ìdí èyí, láti ọjọ́ tí a ti gbọ́ nípa yín, a kò sinmi láti máa gbàdúrà fún yin, tí a sì ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fi ìmọ̀ ìfẹ́ rẹ̀ kún yín nípasẹ̀ ọgbọ́n àti òye gbogbo tí ń ṣe ti Ẹ̀mí. 10 Àwa sì ń gbàdúrà yìí kí ẹ lè gbé irú ìgbé ayé tó yẹ fún Olúwa kí ẹ sì máa wu ú ní gbogbo ọ̀nà, kí ẹ sì máa so èso rere gbogbo, kí ẹ sì máa dàgbà nínú ìmọ̀ Ọlọ́run, 11 pé kí a lè fi ipa gbogbo sọ yín di alágbára gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ àti ògo rẹ̀, kí ó lè ṣe é ṣe fún un yín láti máa tẹ̀síwájú nínú sùúrù àti ìpamọ́ra pẹ̀lú ayọ̀. 12 Kí a máa dúpẹ́ nígbà gbogbo lọ́wọ́ Baba, ẹni tí ó kà yín láti jẹ́ alábápín nínú ogún àwọn ẹni mímọ́ nínú ìjọba ìmọ́lẹ̀. 13 (E)Nítorí tí ó ti já wa gbà kúrò nínú agbára òkùnkùn ó sì mú wa wá sí ìjọba Ọmọ tí ó fẹ́ràn. 14 Nínú ẹni tí a ní ìràpadà, àti ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀.

Títóbi Kristi

15 (F)Kristi ni àwòrán Ọlọ́run tí a kò le rí, àkọ́bí gbogbo ẹ̀dá. 16 Nítorí nípa rẹ̀ ní a dá ohun gbogbo: àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run àti ní ayé, ohun tí a rí àti èyí tí a kò rí, wọn ìbá ṣe ìtẹ́, tàbí agbára, tàbí àṣẹ, nípasẹ̀ rẹ̀ ni a dá ohun gbogbo àti fún un. 17 (G)Ó ti wà ṣáájú kí ohunkóhun tó wà, nínú rẹ̀ ni a sì so ohun gbogbo papọ̀ ṣọ̀kan. 18 (H)Òun ni orí fún ara, èyí tí í ṣe ìjọ; òun ni ìbẹ̀rẹ̀ àti àkọ́bí nínú àwọn òkú, pé nínú ohun gbogbo kí òun lè ní ipò tí ó ga jùlọ nínú ohunkóhun. 19 Nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òun tìkára rẹ̀ lè máa gbé nínú rẹ̀. 20 Àti nípasẹ̀ rẹ̀ láti bá ohun gbogbo làjà àwọn nǹkan tí ń bẹ láyé àti èyí tí ń bẹ ní ọ̀run, nípa mímú àlàáfíà wá nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, tí a ta sílẹ̀ lórí igi àgbélébùú.

21 Ẹ̀yin ya ara yín nípá kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run nígbà kan rí, ẹ jẹ́ ọ̀tá nínú ọkàn yín nítorí ìwà búburú yín. 22 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó ti bá yín làjà nípa ara Kristi nípa ikú láti mú un yín lọ sí iwájú rẹ̀ ní mímọ́, aláìlábàwọ́n àti kúrò nínú ìdálẹ́bi, 23 bí ẹ̀yin bá dúró nínú ìgbàgbọ́ yín, tí ẹ fi ẹsẹ̀ múlẹ̀, tí ẹ sì dúró ṣinṣin, láláìyẹsẹ̀ kúrò nínú ìrètí ti ìhìnrere ti ẹ̀yin ti gbọ́, èyí tí a ti wàásù rẹ̀ fún gbogbo ẹ̀dá lábẹ́ ọ̀run, àti èyí ti èmi Paulu ṣe ìránṣẹ́ fún.

Iṣẹ́ Paulu ṣíṣe fún àwọn ìjọ

24 Nísinsin yìí èmi ń yọ̀ nínú ìjìyà fún un yín. Inú mi sì dùn, nítorí mo ń ṣe ìrànlọ́wọ́ láti jẹ ìyà tó ṣẹ́kù nínú ìyà Kristi fún ara rẹ̀, èyí tí ì ṣe ìjọ. 25 (I)Nínú èyí tí a fi ṣe ìránṣẹ́ fún gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ìríjú Ọlọ́run tí a fi fún mi fún yín láti mú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣẹ. 26 (J)Ó ti pa àṣírí ìjìnlẹ̀ yìí mọ́ fún ayérayé àti láti ìrandíran. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀, ó ti fihàn fún àwọn ẹni mímọ́. 27 Àwọn ẹni tí Ọlọ́run yàn láti fihàn láàrín àwọn aláìkọlà nípa ọ̀rọ̀ ògo ohun ìjìnlẹ̀ yìí, èyí tí í ṣe Kristi ìrètí ògo nínú yín.

28 Àwa ń wàásù rẹ̀, a ń gbani níyànjú a sì ń kọ olúkúlùkù ènìyàn ní ọgbọ́n gbogbo, kí a lè mú olúkúlùkù dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ní pípé nínú Kristi. 29 Sí èyí sì ni èmi ń ṣe làálàá, ti mo sì ń làkàkà pẹ̀lú gbogbo agbára rẹ̀, èyí tó ń ṣiṣẹ́ nínú mi.

Esekiẹli 44

Àwọn ọmọ ọba, àwọn Lefi àti àwọn àlùfáà

44 Lẹ́yìn náà ni ọkùnrin náà mú mi padà lọ sí ibi mímọ́, èyí tí ó kọjú sí ìhà ìlà-oòrùn, ó sì wà ní títì. Olúwa sọ fún mi, “Ẹnu-ọ̀nà yìí ni kí ó wà ní títì. A kò gbọdọ̀ ṣí i sílẹ̀; kò sí ẹni tí o gbọdọ̀ gba ibẹ̀ wọlé. Ó gbọdọ̀ wà ní títì nítorí pé Olúwa Ọlọ́run Israẹli tí gbà ibẹ̀ wọlé. Ọmọ-aládé fúnrarẹ̀ ní o lè jókòó ní ẹnu-ọ̀nà náà kí o sì jẹun níwájú Olúwa. Ó gbọdọ̀ gba ọ̀nà ìloro ẹnu-ọ̀nà wọlé kí ó sì gba ibẹ̀ jáde.”

(A)Lẹ́yìn náà, ọkùnrin náà mú mi gba ẹnu-ọ̀nà àríwá lọ sí iwájú ilé Ọlọ́run. Mo wò ó mo sì rí ògo Olúwa tí ó kún inú ilé Olúwa, mo sì dojúkọ ilẹ̀.

Olúwa sì sọ fún mì pé, “Ọmọ ènìyàn, wò dáradára, fetísílẹ̀ dáradára kí o sì fiyèsí ohun gbogbo tí mo sọ fún ọ nípa òfin lórí ilé Olúwa náà. Fiyèsí ẹnu-ọ̀nà ilé Ọlọ́run náà àti gbogbo àbájáde ibi mímọ́. Sọ fún ọlọ̀tẹ̀ ilé Israẹli pé, ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Ìwà ìríra rẹ tí tó gẹ́ẹ́, ìwọ ilé Israẹli! Ní àfikún pẹ̀lú gbogbo àwọn ìwà ìríra rẹ tí ó kù, ìwọ mú àwọn àjèjì aláìkọlà àyà àti ara wá sí inú ibi mímọ́ mi, ní lílo ilé mi ní ìlòkulò nígbà tí ìwọ fi oúnjẹ fún mi, ọ̀rá àti ẹ̀jẹ̀, ìwọ sì ba májẹ̀mú mi jẹ́. Dípò kí ìwọ pa òfin mi mọ́, ìwọ fi àwọn mìíràn sí ibi mímọ́ mi. Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Àjèjì aláìkọlà àyà àti ara kò gbọdọ̀ wọ ibi mímọ́ mi, àti pẹ̀lú àwọn àjèjì tí ń gbé ní àárín àwọn ọmọ Israẹli.

10 “ ‘Àwọn Lefi tí wọn rìn jìnnà kúrò lọ́dọ̀ mi nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ṣìnà, ti wọ́n sì ṣáko kúrò lọ́dọ̀ mi láti tọ àwọn ère wọn lẹ́yìn gbọdọ̀ jèrè ẹ̀ṣẹ̀ wọn. 11 Wọn le sìn mi ní ibi mímọ́ mi, kí wọn ṣe ìtọ́jú àwọn ẹnu-ọ̀nà ilé Ọlọ́run, kí wọn sì ṣe ìránṣẹ́ nínú rẹ̀; wọn le pa ẹbọ sísun, ki wọn sì rú ẹbọ fún àwọn ènìyàn, kí wọn sì dúró níwájú àwọn ènìyàn, kí wọ́n sì ṣe ìránṣẹ́ fún wọn. 12 Ṣùgbọ́n nítorí pé wọn ṣe ìránṣẹ́ fún wọn níwájú àwọn ère wọn, tí wọn sì mu ilé Israẹli ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀, nítorí náà, Èmi tí búra nípa nína ọwọ́ sókè pé, wọn gbọdọ̀ jèrè ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ní Olúwa Olódùmarè wí. 13 Wọn kò gbọdọ̀ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi láti ṣe ìránṣẹ́ fún mi, gẹ́gẹ́ bí àlùfáà tàbí súnmọ́ nǹkan kan nínú àwọn ohun mímọ́ mi tàbí ẹbọ mi mímọ́ jùlọ; wọn gbọdọ̀ gba ìtìjú ìwà ìríra wọn. 14 Síbẹ̀ èmi yóò mu wọn sí ìtọ́jú ilé Ọlọ́run àti gbogbo iṣẹ́ tí a gbọdọ̀ ṣe níbẹ̀.

15 “ ‘Ṣùgbọ́n àwọn àlùfáà, tí ó jẹ́ Lefi àti àwọn ìran Sadoku tí fi tọkàntọkàn ṣe iṣẹ́ ibi mímọ́ mi nígbà tí àwọn Israẹli ṣáko lọ kúrò lọ́dọ̀ mi, wọn gbọdọ̀ súnmọ́ iwájú láti ṣe ìránṣẹ́ ní iwájú mi, láti rú ẹbọ ọ̀rá àti ẹ̀jẹ̀, ni Olúwa Olódùmarè wí. 16 Àwọn nìkan ni ó gbọdọ̀ wọ ibi mímọ́ mi; àwọn nìkan ní o gbọdọ̀ súnmọ́ tábìlì mi láti ṣe ìránṣẹ́ ni iwájú mi, ki wọn sì ṣe iṣẹ́ ìsìn mi.

17 “ ‘Nígbà ti wọ́n wọ àwọn ẹnu-ọ̀nà àgbàlá ti inú, wọn yóò wọ ẹ̀wù ọ̀gbọ̀, wọn kò gbọdọ̀ wọ aṣọ onírun nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ ní àwọn ẹnu-ọ̀nà àgbàlá ti inú tàbí ni inú ilé Ọlọ́run. 18 Wọ́n yóò sì dé fìlà ọ̀gbọ̀ sí orí wọn àti ṣòkòtò ọ̀gbọ̀ sí ìdí wọn. Wọn kò sì gbọdọ̀ wọ ohunkóhun tí yóò mú wọn làágùn. 19 Nígbà tí wọ́n bá lọ sì àgbàlá òde níbi tí àwọn ènìyàn wà, wọn gbọdọ̀ bọ́ ẹ̀wù tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́, ki wọn sì fi wọn sílẹ̀ sí àwọn yàrá mímọ́ náà, kí wọn kí ó sì wọ ẹ̀wù mìíràn, wọn kì yóò sì fi ẹ̀wù wọn sọ àwọn ènìyàn di mímọ́.

20 “ ‘Wọn kò gbọdọ̀ fá irun, wọn kò sì gbọdọ̀ jẹ́ kí irun wọn gùn, ṣùgbọ́n wọn gbọdọ̀ jẹ́ kí irun orí wọn wà ní gígẹ̀. 21 Àlùfáà kankan kò gbọdọ̀ mu ọtí nígbà tí ó bá wọ àgbàlá tí inú. 22 Wọn ko gbọdọ̀ fẹ́ opó ni ìyàwó, wọn kò sì gbọdọ̀ kọ ìyàwó wọn sílẹ̀; Wọ́n lè fẹ́ àwọn ọmọbìnrin ti kò tí i mọ ọkùnrin rí, tí ó sì jẹ́ ìran àwọn ọmọ Israẹli, tàbí kí wọn fẹ́ àwọn opó àlùfáà. 23 Wọn yóò sì fi ìyàtọ̀ tí ó wà láàrín mímọ́ àti àìmọ́ kọ́ àwọn ènìyàn mi, wọn yóò sì fihàn wọ́n bi wọn yóò ṣe dá aláìmọ́ mọ̀ yàtọ̀ sí mímọ́.

24 “ ‘Nínú èyíkéyìí èdè-àìyedè, àwọn àlùfáà ní yóò dúró gẹ́gẹ́ bí onídàájọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin mi. Wọ́n ní láti pa àwọn òfin àti àṣẹ mi mọ́ ní gbogbo àjọ̀dún tí a yàn, wọn sì gbọdọ̀ ya ọjọ́ ìsinmi mi ní mímọ́.

25 “ ‘Àlùfáà kò gbọdọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ nípa sísún mọ́ òkú ènìyàn; ṣùgbọ́n ti òkú ènìyàn yẹn bá jẹ́ baba tàbí ìyá rẹ̀, àbúrò rẹ̀ ọkùnrin tàbí àbúrò rẹ̀ obìnrin ti kò i ti lọ́kọ, nígbà náà o le sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́. 26 Lẹ́yìn ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀, ki òun kí ó dúró fún ọjọ́ méje. 27 Ní ọjọ́ ti yóò wọ àgbàlá ti inú ni ibi mímọ́ láti ṣe ìránṣẹ́ ibi mímọ́, ni kí òun kí ó rú ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni Olúwa Olódùmarè wí.

28 “ ‘Èmi ni yóò jẹ́ ogún kan ṣoṣo tí àwọn àlùfáà yóò ní. Ẹ kì yóò fún wọn ni ìpín kankan ní Israẹli; Èmi ni yóò jẹ́ ìní wọn. 29 Wọn yóò jẹ ọrẹ ẹbọ jíjẹ, ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ọrẹ ẹbọ ìrékọjá; gbogbo ohun tí a bá yà sọ́tọ̀ fún Olúwa ni Israẹli ni yóò jẹ́ tiwọn. 30 Èyí tí ó dára jùlọ nínú gbogbo àkọ́so èso àti ọrẹ yín yóò jẹ́ ti àwọn àlùfáà. Ẹ ó sì fi àkọ́pò ìyẹ̀fun yín fún wọn kí ìbùkún lè wà lórí gbogbo ilé yín. 31 Àwọn àlùfáà kì yóò jẹ́ ohunkóhun bí i ẹyẹ tàbí ẹranko, tí ó ti kú fúnrarẹ̀ tàbí èyí ti ẹranko ńlá fàya.

Saamu 97-98

97 Olúwa jẹ ọba, jẹ́ kí ayé kí ó yọ̀
    jẹ́ kí inú ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù kí ó dùn
Ojú ọ̀run àti òkùnkùn yíká
    òdodo àti ìdájọ́ ni ó ṣe ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìtẹ́ rẹ̀.
Iná ń jó níwájú rẹ̀. Ó sì ń jó àwọn ọ̀tá rẹ̀ yíkákiri
Ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tàn ó sì kárí ayé
    ayé rí i ó sì wárìrì
Òkè gíga yọ́ gẹ́gẹ́ bí ìda níwájú Olúwa,
    níwájú Olúwa gbogbo ayé.
Àwọn ọ̀run ròyìn òdodo rẹ̀, gbogbo ènìyàn sì rí ògo rẹ̀.

(A)Gbogbo àwọn tí ń sin ère fínfín ni ojú yóò tì,
    àwọn tí ń fi ère gbéraga,
    ẹ máa sìn ín, gbogbo ẹ̀yin ọlọ́run!

Sioni gbọ́, inú rẹ̀ sì dùn
    inú àwọn ilé Juda sì dùn
    Nítorí ìdájọ́ rẹ, Olúwa
Nítorí pé ìwọ, Olúwa, ni ó ga ju gbogbo ayé lọ
    ìwọ ni ó ga ju gbogbo òrìṣà lọ.
10 Jẹ kí gbogbo àwọn tí ó fẹ́
    Olúwa, kórìíra ibi, ó pa ọkàn àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ mọ́
    ó gbà wọ́n ní ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú.
11 Ìmọ́lẹ̀ tàn sórí àwọn olódodo
    àti ayọ̀ nínú àlàyé ọkàn
12 Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ olódodo,
    kí ẹ sì yin orúkọ rẹ̀ mímọ́.
98 Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa,
    nítorí tí ó ṣe ohun ìyanu;
ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti apá mímọ́ rẹ̀
    o ṣe iṣẹ́ ìgbàlà fún un
Olúwa ti sọ ìgbàlà rẹ̀ di mí mọ̀
    o fi òdodo rẹ̀ han àwọn orílẹ̀-èdè.
Ó rántí ìfẹ́ rẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ fún àwọn ará ilé Israẹli;
    gbogbo òpin ayé ni ó ti rí
    iṣẹ́ ìgbàlà Ọlọ́run wa.

Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Olúwa, gbogbo ayé,
    ẹ bú sáyọ̀, ẹ kọrin ìyìn
Ẹ fi dùùrù kọrin sí Olúwa, pẹ̀lú dùùrù àti ìró ohùn orin mímọ́,
Pẹ̀lú ìpè àti fèrè
    ẹ hó fún ayọ̀ níwájú Olúwa ọba.

Jẹ́ kí Òkun kí ó hó pẹ̀lú gbogbo
    ohun tí ó wà nínú rẹ̀,
Gbogbo ayé àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.
Ẹ jẹ́ kí odo kí ó ṣápẹ́,
    ẹ jẹ́ kí òkè kí ó kọrin pẹ̀lú ayọ̀;
Ẹ jẹ́ kí wọn kọrin níwájú Olúwa
    Nítorí tí yóò wá ṣèdájọ́ ayé
bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè nínú òdodo
    àti àwọn ènìyàn ní àìṣègbè pẹ̀lú.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.