Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

M’Cheyne Bible Reading Plan

The classic M'Cheyne plan--read the Old Testament, New Testament, and Psalms or Gospels every day.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
2 Ọba 13

Jehoahasi ọba Israẹli

13 Ní ọdún kẹtàlélógún ti Joaṣi ọmọ ọba Ahasiah ti Juda, Jehoahasi ọmọ Jehu di ọba Israẹli ní Samaria. Ó sì jẹ ọba fún ọdún mẹ́tà-dínlógún. Ó ṣe búburú níwájú Olúwa nípa títẹ̀lé ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, èyí tí ó ti fa Israẹli láti dá, kò sì yípadà kúrò nínú wọn. Bẹ́ẹ̀ ni ìbínú Olúwa ru sí àwọn ọmọ Israẹli, àti fún ìgbà pípẹ́, ó fi wọ́n pamọ́ sí abẹ́ agbára ọba Hasaeli ọba Siria àti Beni-Hadadi ọmọ rẹ̀.

Nígbà náà Jehoahasi kígbe ó wá ojúrere Olúwa, Olúwa sì tẹ́tí sí i. Nítorí ó rí bí ọba Siria ti ń ni Israẹli lára gidigidi. Olúwa pèsè Olùgbàlà fún Israẹli, wọ́n sì sá kúrò lọ́wọ́ agbára Siria. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli gbé nínú ilé ara wọn gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti wà tẹ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n wọn kò yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ ilé Jeroboamu, èyí tí ó ti fa Israẹli láti dá, wọ́n tẹ̀síwájú nínú rẹ̀, ère òrìṣà Aṣerah sì wà síbẹ̀ ní Samaria pẹ̀lú.

Kò sí ohùn kan tí wọ́n fi sílẹ̀ ní ti ọmọ-ogun Jehoahasi àyàfi àádọ́ta ọkùnrin ẹlẹ́ṣin, kẹ̀kẹ́ mẹ́wàá, àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọmọ-ogun ẹlẹ́ṣẹ̀, nítorí ọba Siria ti pa ìyókù run, ó sì ṣe wọ́n bí eruku nígbà pípa ọkà.

Fún ti ìyókù ìṣe Jehoahasi fún ìgbà, tí ó fi jẹ ọba, gbogbo ohun tí ó ṣe àti àṣeyọrí rẹ̀ ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli? Jehoahasi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. A sì sin ín sí Samaria. Jehoaṣi ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

Jehoaṣi ọba Israẹli

10 Ní ọdún kẹtà-dínlógójì tí Joaṣi ọba Juda, Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi di ọba Israẹli ní Samaria ó sì jẹ ọba fún ọdún mẹ́rìn-dínlógún. 11 Ó ṣe búburú ní ojú Olúwa, kò sì yípadà kúrò nínú ọ̀kankan nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati èyí tí ó ti ti Israẹli láti fà. Ó sì tẹ̀síwájú nínú wọn.

12 Fún ti ìyókù iṣẹ́ Jehoaṣi fún ìgbà tí ó fi jẹ ọba, gbogbo ohun tí ó ṣe, pẹ̀lú àṣeyọrí rẹ̀ pẹ̀lú ogun rẹ̀ sí Amasiah ọba Juda, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli? 13 Jehoaṣi sinmi pẹ̀lú àwọn baba a rẹ̀. Jeroboamu sì rọ́pò rẹ̀ lórí ìtẹ́. A sin Jehoaṣi sí Samaria pẹ̀lú àwọn ọba Israẹli.

14 Nísinsin yìí, Eliṣa ń jìyà lọ́wọ́ àìsàn, lọ́wọ́ èyí tí ó sì kú. Jehoaṣi ọba Israẹli lọ láti lọ wò ó, ó sì sọkún lórí rẹ̀. “Baba mi! Baba mi!” Ó sọkún. “Àwọn kẹ̀kẹ́ àti àwọn ọkùnrin ẹlẹ́ṣin Israẹli!”

15 Eliṣa wí pé, “Mú ọrun kan àti àwọn ọfà,” ó sì ṣe bẹ́ẹ̀. 16 “Mú ọrun ní ọwọ́ rẹ.” Ó wí fún ọba Israẹli. Nígbà tí ó ti mú u, Eliṣa mú ọwọ́ rẹ̀ lé ọwọ́ ọba.

17 “Ṣí fèrèsé apá ìlà-oòrùn,” ó wí, pẹ̀lú ó sì ṣí i: “Ta á!” Eliṣa wí, ó sì ta á. “Ọfà ìṣẹ́gun Olúwa; ọfà ìṣẹ́gun lórí Siria!” Eliṣa kéde. “Ìwọ yóò pa àwọn ará Siria run pátápátá ní Afeki.”

18 Nígbà náà ó wí pé, “Mú àwọn ọfà náà,” ọba sì mú wọn. Eliṣa wí fún un pé, “Lu ilẹ̀.” Ó lù ú lẹ́ẹ̀mẹ́ta, ó sì dáwọ́ dúró. 19 Ènìyàn Ọlọ́run sì bínú sí i, ó sì wí pé, “Ìwọ kò bá ti lu ilẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀márùnún tàbí ní ẹ̀ẹ̀mẹ́fà; Nígbà náà, ìwọ kò bá ti ṣẹ́gun Siria àti pa á run pátápátá ṣùgbọ́n Nísinsin yìí ìwọ yóò ṣẹ́gun rẹ̀ ní ẹ̀mẹ́ta péré.”

20 Eliṣa kú a sì sin ín.

Ẹgbẹ́ Àwọn ará Moabu máa ń wọ orílẹ̀-èdè ní gbogbo àmọ́dún. 21 Bí àwọn ọmọ Israẹli kan ti ń sin òkú ọkùnrin kan, lójijì wọ́n rí ẹgbẹ́ àwọn oníjadì: Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ju òkú ọkùnrin náà sínú ibojì Eliṣa. Nígbà tí ara ọkùnrin náà kan egungun Eliṣa, ó padà wá sí ayé, ó sì dúró ní ẹsẹ̀ rẹ̀.

22 Hasaeli ọba Siria ni Israẹli lára ní gbogbo àkókò tí Jehoahasi fi jẹ ọba. 23 Ṣùgbọ́n Olúwa ṣàánú fún wọn ó sì ní ìyọ́nú, ó sì fiyèsí wọn nítorí májẹ̀mú rẹ̀ pẹ̀lú Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu. Títí di ọjọ́ òní, kì í ṣe ìfẹ́ inú rẹ̀ láti pa wọ́n run tàbí lé wọn lọ níwájú rẹ̀.

24 Hasaeli ọba Siria kú, Beni-Hadadi ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba. 25 Nígbà náà, Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi gbà padà kúrò lọ́wọ́ Beni-Hadadi ọmọ Hasaeli àwọn ìlú tí ó ti gbà nínú ogun látọ̀dọ̀ baba rẹ̀ Jehoahasi. Ní ẹ̀ẹ̀mẹta, Jehoaṣi ṣẹ́gun rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó gba ìlú àwọn ọmọ Israẹli padà.

2 Timotiu 3

Ìwà àwọn ènìyàn ni ọjọ́ ìkẹyìn

Ṣùgbọ́n èyí ni kí o mọ̀: pé ní ìkẹyìn ọjọ́ ìgbà ewu yóò dé. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ti ara wọn, olùfẹ́ owó, afọ́nnu, agbéraga, asọ̀rọ̀ búburú, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìmọ́. Aláìnífẹ̀ẹ́, aláìlèdáríjì, abanijẹ́, aláìlè-kó-aràwọn-níjánu, òǹrorò, aláìnífẹ̀ẹ́ ohun rere, oníkúpani, alágídí, ọlọ́kàn gíga, olùfẹ́ fàájì ju olùfẹ́ Ọlọ́run lọ. Àwọn tí wọn ní àfarawé ìwà-bí-Ọlọ́run, ṣùgbọ́n tí wọn sẹ́ agbára rẹ̀; yẹra kúrò lọ́dọ̀ àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú.

Nítorí nínú irú èyí ni àwọn ti ń rákò wọ inú ilé, tí wọ́n sì ń di àwọn obìnrin aláìlọ́gbọ́n tí a di ẹ̀ṣẹ̀ rù ní ìgbèkùn, tí a sì ń fi onírúurú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ fà kiri Wọ́n ń fi ìgbà gbogbo kẹ́kọ̀ọ́, wọ́n kò sì lè dé ojú ìmọ̀ òtítọ́. (A)Ǹjẹ́ gẹ́gẹ́ bí Janesi àti Jamberi ti kọ ojú ìjà sí Mose náà ni wọ́n kọjú ìjà sí òtítọ́: àwọn ènìyàn tí inú wọn díbàjẹ́, àwọn ẹni ìtanù ní ti ọ̀ràn ìgbàgbọ́. Ṣùgbọ́n wọn kì yóò lọ síwájú ju bẹ́ẹ̀ lọ: Nítorí òmùgọ̀ wọn yóò farahàn fún gbogbo ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ti àwọn méjì yìí náà, ti yọrí si.

Ọ̀rọ̀ ìyànjú Paulu sí Timotiu

10 Ṣùgbọ́n ìwọ ti mọ ẹ̀kọ́ mi, ìgbésí ayé mi, ìpinnu, ìgbàgbọ́, ìpamọ́ra, ìfẹ́ sùúrù. 11 (B)Inúnibíni, ìyà; àwọn ohun tí ó dé bá mi ní Antioku, ní Ikoniomu ní Lysra; àwọn inúnibíni tí mo faradà: Olúwa sì gbà mi kúrò nínú gbogbo wọn. 12 Nítòótọ́, gbogbo àwọn tí ó fẹ́ máa gbé ìgbé ayé ìwà-bí-Ọlọ́run nínú Kristi Jesu yóò faradà inúnibíni 13 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn búburú, àti àwọn ẹlẹ́tàn yóò máa burú síwájú sí i, wọn ó máa tannijẹ, a ó sì máa tàn wọ́n jẹ. 14 Ṣùgbọ́n ìwọ dúró nínú nǹkan wọ̀nyí tí ìwọ ti kọ́, tí a sì ti jẹ́ kí ojú rẹ dá ṣáṣá sí, kí ìwọ sì mọ̀ ọ̀dọ̀ ẹni tí ìwọ gbé kọ́ wọn. 15 Àti pé láti ìgbà ọmọdé ni ìwọ ti mọ Ìwé Mímọ́, tí ó lè sọ ọ́ di ọlọ́gbọ́n sí ìgbàlà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jesu. 16 Gbogbo ìwé mímọ́ ni ó ní ìmísí Ọlọ́run tí ó sì ní èrè fún ẹ̀kọ́, fún ìbániwí, fún ìtọ́ni, fún ìkọ́ni tí ó wà nínú òdodo. 17 Kí ènìyàn Ọlọ́run lè pé, tí a ti múra sílẹ̀ pátápátá fun iṣẹ́ rere gbogbo.

Hosea 5-6

Ìdájọ́ n bọ̀ lórí Israẹli àti Juda

“Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yìn àlùfáà!
    Ẹ fetísílẹ̀ ẹ̀yin ọmọ Israẹli!
Ẹ gbọ́, ẹ̀yìn ilé ọba!
    Ìdájọ́ yìí kàn yín:
Ẹ ti jẹ́ ẹ̀bìtì ní Mispa
    àwọ̀n ti a nà sílẹ̀ lórí Tabori
Àwọn ọlọ̀tẹ̀ ti gbilẹ̀ nínú ìpànìyàn
    gbogbo wọn ni èmi ó bá wí,
Mo mọ ohun gbogbo nípa Efraimu
    Israẹli kò sì pamọ́ fún mi
Efraimu, ní báyìí ó ti ṣe àgbèrè
    Israẹli sì ti díbàjẹ́.

“Ìṣe wọn kò gbà wọ́n láààyè
    láti padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọn.
Ẹ̀mí àgbèrè wà ni ọkàn wọn,
    wọn kò sì mọ Olúwa.
Ìgbéraga Israẹli ń jẹ́rìí lé wọn;
    Àwọn ọmọ Israẹli, àti Efraimu pàápàá kọsẹ̀ nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
    Juda náà sì kọsẹ̀ pẹ̀lú wọn.
Nígbà tí wọ́n bá lọ pẹ̀lú agbo ẹran
    àti ọ̀wọ́ ẹran wọn láti wá Olúwa,
wọn kò ní rí i,
    ó ti yọ ara rẹ̀ kúrò láàrín wọn.
Wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Olúwa
    wọ́n sì bí àwọn àjèjì ọmọ.
Nísinsin yìí, ọdún oṣù tuntun wọn,
    ni yóò pa wọn run pẹ̀lú ìpín wọn.

“Fọn fèrè ní Gibeah,
    kí ẹ sì fun ìpè ní Rama.
Ẹ pariwo ogun ní Beti-Afeni
    máa wárìrì, ìwọ Benjamini.
Efraimu yóò di ahoro
    ní ọjọ́ ìbáwí
láàrín àwọn ẹ̀yà Israẹli
    Mo sọ ohun tí ó dájú.
10 Àwọn olórí Juda dàbí àwọn tí í
    máa yí òkúta ààlà kúrò.
Èmi ó tú ìbínú gbígbóná mi lé
    wọn lórí bí ìkún omi.
11 A ni Efraimu lára,
    A sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ ní ìdájọ́
    nítorí pé, ó pinnu láti tẹ̀lé òrìṣà
12 Mo dàbí kòkòrò aṣọ sí Efraimu
    Mo sì dàbí ìdin ara Juda.

13 “Nígbà ti Efraimu ri àìsàn rẹ̀,
    tí Juda sì rí ojú egbò rẹ̀
ni Efraimu bá tọ ará Asiria lọ,
    ó sì ránṣẹ́ sí ọba ńlá náà fún ìrànlọ́wọ́
Ṣùgbọ́n kò le è wò ó sàn
    bẹ́ẹ̀ ni kò le wo ojú egbò rẹ̀ jinná
14 Nítorí pé, èmi ó dàbí kìnnìún sí Efraimu,
    bí i kìnnìún ńlá sí ilé Juda.
Èmi ó fà wọ́n ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ èmi ó sì lọ;
    Èmi ó gbé wọn lọ, láìsí ẹni tí yóò gbà wọ́n sílẹ̀.
15 Nígbà náà ni èmi ó padà lọ sí ààyè mi
    títí di ìgbà tí wọn ó fi gbà pé àwọn jẹ̀bi
wọn yóò sì wá ojú mi
    nínú ìpọ́njú wọn, wọn ó fi ìtara wá mi.”

Àìronúpìwàdà Israẹli

“Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a padà sọ́dọ̀ Olúwa
ó ti fà wá ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ
    ṣùgbọ́n yóò mú wa láradá
Ó ti pa wá lára
    ṣùgbọ́n yóò dí ojú ọgbẹ́ wa.
Lẹ́yìn ọjọ́ méjì, yóò sọ wá jí
    ní ọjọ́ kẹta yóò mú wa padà bọ̀ sípò
    kí a ba à le wá gbé níwájú rẹ̀
Ẹ jẹ́ kí a mọ Olúwa
    Ẹ jẹ́ kí a tẹ̀síwájú láti mọ̀ ọ́n.
Gẹ́gẹ́ bí oòrùn ṣe ń yọ,
    Yóò jáde;
Yóò tọ̀ wá wá bí òjò
    bí òjò àkọ́rọ̀ ti ń bomirin ilẹ̀.”

“Kí ni èmi ó ṣe pẹ̀lú rẹ, Efraimu?
    Kí ni èmi ó ṣe pẹ̀lú rẹ, Juda?
Ìfẹ́ rẹ dàbí ìkùùkuu òwúrọ̀
    bí ìrì ìdájí tí ó kọjá lọ kíákíá.
Nítorí náà ni mo ṣe gé e yín sí wẹ́wẹ́ láti ọwọ́ àwọn wòlíì.
    Mo pa yín pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹnu mi
    Ìdájọ́ mi tàn bí i mọ̀nàmọ́ná lórí yín
(A)Nítorí àánú ni mo fẹ́, kì í ṣe ẹbọ;
    àti ìmọ̀ Ọlọ́run ju ọrẹ ẹbọ sísun lọ.
Bí i Adamu, wọ́n da májẹ̀mú
    wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ sí mi níbẹ̀.
Gileadi jẹ́ ìlú àwọn ènìyàn búburú
    tí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, a sí ti fi ẹ̀ṣẹ̀ bà á jẹ́.
Bí adigunjalè ṣe ń ba ní bùba de àwọn ènìyàn
    bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà, ń parapọ̀;
tí wọ́n sì ń pànìyàn lójú ọ̀nà tó lọ sí Ṣekemu,
    tí wọ́n sì ń dá ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti ni lójú.
10 Mo ti rí ohun tó ba ni lẹ́rù
    ní ilé Israẹli.
Níbẹ̀ Efraimu, fi ara rẹ̀ fún àgbèrè
    Israẹli sì di aláìmọ́.

11 “Àti fún ìwọ, Juda
    A ti yan ọjọ́ ìkórè rẹ.

“Nígbà tí mo bá fẹ́ dá ohun ìní àwọn ènìyàn mi padà,

Saamu 119:145-176

Kíkígbe fún ìgbàlà

145 Èmi kígbe pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi:
    dá mi lóhùn Olúwa,
    èmi yóò sì gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ.
146 Èmi kígbe pè ọ́; gbà mí
    èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́.
147 Èmi dìde ṣáájú àfẹ̀mọ́júmọ́ èmi ké fún ìrànlọ́wọ́;
    èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.
148 Ojú mi ṣáájú ìṣọ́ òru,
    nítorí kí èmi lè ṣe àṣàrò nínú ọ̀rọ̀ rẹ.
149 Gbọ́ ohùn mi ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ:
    pa ayé mi mọ́, Olúwa, gẹ́gẹ́ bí òfin rẹ.
150 Àwọn tí ń gbìmọ̀ ìlànà búburú wà ní tòsí,
    ṣùgbọ́n wọ́n jìnnà sí òfin rẹ.
151 Síbẹ̀ ìwọ wà ní tòsí, Olúwa,
    àti gbogbo àṣẹ rẹ jẹ́ òtítọ́.
152 Láti ọjọ́ pípẹ́ wá èmi ti kọ́ nínú òfin rẹ
    tí ìwọ ti fi ìdí wọn múlẹ̀ láéláé.

Pípa òfin mọ́ ni ìpọ́njú

153 Wo ìpọ́njú mi kí o sì gbà mí,
    nítorí èmi kò gbàgbé òfin rẹ.
154 Gba ẹjọ́ mi rò kí o sì rà mí padà;
    pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.
155 Ìgbàlà jìnnà sí àwọn ẹni búburú
    nítorí wọn kò wá àṣẹ rẹ.
156 Ìyọ́nú rẹ̀ tóbi, Olúwa;
    pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin rẹ.
157 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn ọ̀tá tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí mi,
    ṣùgbọ́n èmi kò tí ì yípadà kúrò nínú òfin rẹ.
158 Èmi wo àwọn ẹlẹ́tàn, inú mi sì bàjẹ́
    nítorí wọn kò gba ọ̀rọ̀ rẹ gbọ́.
159 Wo bí èmi ṣe fẹ́ràn ẹ̀kọ́ rẹ;
    pa ayé mi mọ́, Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ.
160 Òtítọ́ ni gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ;
    gbogbo òfin òdodo rẹ láéláé ni.
161 Àwọn alákòóso ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí,
    ṣùgbọ́n ọkàn mi wárìrì sí ọ̀rọ̀ rẹ.
162 Èmi yọ̀ nínú ìpinnu rẹ
    bí ẹni tí ó rí ìkógun púpọ̀.
163 Èmi kórìíra mo sì kọ èké ṣíṣe
    ṣùgbọ́n mo fẹ́ràn òfin rẹ.
164 Èmi yìn ọ́ ní ìgbà méje lójúmọ́
    nítorí òfin òdodo rẹ.
165 Àlàáfíà púpọ̀ wà fún àwọn tí ó ní ìfẹ́ sí òfin rẹ,
    kò sì ṣí ohun tí ó lè mú wọn kọsẹ̀.
166 Èmi yóò dúró de ìgbàlà rẹ, Olúwa,
    èmi yóò sì tẹ̀lé àṣẹ rẹ.
167 Èmi gba òfin rẹ gbọ́,
    nítorí mo fẹ́ràn wọn púpọ̀púpọ̀
168 Èmi ṣe ìgbọ́ràn sí ẹ̀kọ́ rẹ àti òfin rẹ,
    nítorí ìwọ mọ gbogbo ọ̀nà mi.
169 Jẹ́ kí igbe mi wá sí iwájú rẹ, Olúwa;
    fún mi ní òye gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
170 Jẹ́ kí ẹ̀bẹ̀ mi wá sí iwájú rẹ;
    gbà mí gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.
171 Ètè mi yóò sọ ìyìn jáde,
    nítorí ìwọ kọ́ mi ní ìlànà rẹ.
172 Jẹ́ kí ahọ́n mi kọ orin ọ̀rọ̀ rẹ,
    nítorí gbogbo àṣẹ rẹ jẹ́ òdodo.
173 Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ ṣetán láti ràn mí lọ́wọ́,
    nítorí èmi ti yan ẹ̀kọ́ rẹ.
174 Èmi wo ọ̀nà fún ìgbàlà rẹ, Olúwa,
    àti òfin rẹ jẹ́ dídùn inú mi.
175 Jẹ́ kí èmi wà láààyè ki èmi lè yìn ọ́,
    kí o sì jẹ́ kí òfin rẹ mú mi dúró.
176 Èmí ti ṣìnà bí àgùntàn tí ó
    sọnù, wá ìránṣẹ́ rẹ,
    nítorí èmi kò gbàgbé àṣẹ rẹ.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.