Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

M’Cheyne Bible Reading Plan

The classic M'Cheyne plan--read the Old Testament, New Testament, and Psalms or Gospels every day.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
1 Ọba 6

Solomoni kọ́ ilé náà

(A)Ní ìgbà tí ó pe ọ̀rìnlénírinwó ọdún (480) lẹ́yìn ìgbà tí àwọn ọmọ Israẹli ti jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, ní ọdún kẹrin ìjọba Solomoni lórí Israẹli, ní oṣù Sifi, tí ń ṣe oṣù kejì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé Olúwa.

Ilé náà tí Solomoni ọba kọ́ fún Olúwa sì jẹ́ ọgọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ogún ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú àti ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gíga. Ìloro níwájú tẹmpili ilé náà, ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn rẹ̀, ìbú ilé náà, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá láti iwájú ilé náà. Ó sì ṣe fèrèsé tí kò fẹ̀ fún ilé náà. Lára ògiri ilé náà ni ó bu yàrá yíká; àti tẹmpili àti ibi mímọ́ jùlọ ni ó sì ṣe yàrá yíká. Yàrá ìsàlẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní ìbú, ti àárín sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà ní ìbú, àti ẹ̀kẹta ìgbọ̀nwọ́ méje sì ni ìbú rẹ̀. Nítorí lóde ilé náà ni ó dín ìgbọ̀nwọ́ kọ̀ọ̀kan káàkiri, kí igi àjà kí ó má ba à wọ inú ògiri ilé náà.

Ní kíkọ́ ilé náà, òkúta tí a ti gbẹ́ sílẹ̀ kí a tó mú un wá ibẹ̀ nìkan ni a lò, a kò sì gbúròó òòlù tàbí àáké tàbí ohun èlò irin kan nígbà tí a ń kọ́ ọ lọ́wọ́.

Ẹnu-ọ̀nà yàrá ìsàlẹ̀ sì wà ní ìhà gúúsù ilé náà; wọ́n sì fi àtẹ̀gùn tí ó lórí gòkè sínú yàrá àárín, àti láti yàrá àárín bọ́ sínú ẹ̀kẹta. Bẹ́ẹ̀ ni ó kọ́ ilé náà, ó sì parí rẹ̀, ó sì bo ilé náà pẹ̀lú àwọn ìtí igi àti pákó kedari. 10 Ó sì kọ́ yàrá ẹ̀gbẹ́ sí gbogbo ilé náà. Gígùn ọ̀kọ̀ọ̀kan sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, ó sì so wọ́n mọ́ ilé náà pẹ̀lú ìtì igi kedari.

11 Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Solomoni wá wí pé: 12 “Ní ti ilé yìí tí ìwọ ń kọ́ lọ́wọ́, bí ìwọ bá tẹ̀lé àṣẹ mi, tí ìwọ sì ṣe ìdájọ́ mi, tí o sì pa òfin mi mọ́ láti máa ṣe wọ́n, Èmi yóò mú ìlérí tí mo ti ṣe fún Dafidi baba rẹ̀ ṣẹ nípa rẹ̀. 13 Èmi yóò sì máa gbé àárín àwọn ọmọ Israẹli, èmi kì ó sì kọ Israẹli ènìyàn mi.”

14 Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni kọ́ ilé náà, ó sì parí rẹ̀. 15 Ó sì fi pákó kedari tẹ́ ògiri ilé náà nínú, láti ilẹ̀ ilé náà dé àjà rẹ̀, ó fi igi bò wọ́n nínú, ó sì fi pákó firi tẹ́ ilẹ̀ ilé náà. 16 Ó pín ogún ìgbọ̀nwọ́ sí ẹ̀yìn ilé náà, láti ilẹ̀ dé àjà ilé ni ó fi pákó kedari kọ́, èyí ni ó kọ sínú, fún ibi tí a yà sí mímọ́ àní ibi mímọ́ jùlọ. 17 Ní iwájú ilé náà, ogójì (40) ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn rẹ̀ jẹ́. 18 Inú ilé náà sì jẹ́ kedari, wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà rẹ̀ pẹ̀lú ìrudí àti ìtànná. Gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ kedari; a kò sì rí òkúta kan níbẹ̀.

19 Ó sì múra ibi mímọ́ jùlọ sílẹ̀ nínú ilé náà láti gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa ka ibẹ̀. 20 Inú ibi mímọ́ náà sì jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ogún ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú, àti ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gíga. Ó sì fi kìkì wúrà bo inú rẹ̀ ó sì fi igi kedari bo pẹpẹ rẹ̀. 21 Solomoni sì fi kìkì wúrà bo inú ilé náà, ó sì tan ẹ̀wọ̀n wúrà dé ojú ibi mímọ́ jùlọ, ó sì fi wúrà bò ó. 22 Gbogbo ilé náà ni ó fi wúrà bò títí ó fi parí gbogbo ilé náà, àti gbogbo pẹpẹ tí ó wà níhà ibi mímọ́ jùlọ, ni ó fi wúrà bò.

23 Ní inú ibi mímọ́ jùlọ ni ó fi igi olifi ṣe kérúbù méjì, ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní gíga. 24 Apá kérúbù kìn-ín-ní sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gíga, àti apá kérúbù kejì ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún; ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá láti ṣóńṣó apá kan dé ṣóńṣó apá kejì. 25 Ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá sì ni kérúbù kejì pẹ̀lú, nítorí kérúbù méjèèjì jọ ara wọn ní ìwọ̀n ní títóbi àti títẹ̀wọ̀n bákan náà. 26 Gíga kérúbù kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá. 27 Ó sì gbé àwọn kérúbù náà sínú ilé ti inú lọ́hùn ún, pẹ̀lú ìyẹ́ apá wọn ní nínà jáde. Ìyẹ́ apá kérúbù kan sì kan ògiri kan, nígbà tí ìyẹ́ apá èkejì sì kan ògiri kejì, ìyẹ́ apá wọn sì kan ara wọn láàrín yàrá náà. 28 Ó sì fi wúrà bo àwọn kérúbù náà.

29 Lára àwọn ògiri tí ó yí ilé náà ká, nínú àti lóde, ó sì ya àwòrán àwọn kérúbù sí i àti ti igi ọ̀pẹ, àti ti ìtànná ewéko. 30 Ó sì tún fi wúrà tẹ́ ilẹ̀ ilé náà nínú àti lóde.

31 Nítorí ojú ọ̀nà ibi mímọ́ jùlọ ni ó ṣe ìlẹ̀kùn igi olifi sí pẹ̀lú àtẹ́rígbà àti òpó ìhà jẹ́ ìdámárùn-ún ògiri. 32 Àti lára ìlẹ̀kùn igi olifi náà ni ó ya àwòrán àwọn kérúbù, igi ọ̀pẹ àti ti ìtànná ewéko sí, ó sì fi wúrà bò wọ́n, ó sì tan wúrà sí ara àwọn kérúbù àti sí ara igi ọ̀pẹ. 33 Bẹ́ẹ̀ ni ó sì ṣe òpó igi olifi onígun mẹ́rin fún ìlẹ̀kùn ilé náà. 34 Ó sì tún fi igi firi ṣe ìlẹ̀kùn méjì, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ní ewé méjì tí ó yí sí ihò ìtẹ̀bọ̀. 35 Ó sì ya àwòrán kérúbù, àti ti igi ọ̀pẹ àti ti ìtànná ewéko sí ara wọn, ó sì fi wúrà bò ó, èyí tí ó tẹ́ sórí ibi tí ó gbẹ́.

36 Ó sì fi ẹsẹẹsẹ òkúta mẹ́ta gbígbẹ, àti ẹsẹ̀ kan ìtí kedari kọ́ àgbàlá ti inú lọ́hùn ún.

37 Ní ọdún kẹrin ni a fi ìpìlẹ̀ ilé Olúwa lé ilẹ̀, ní oṣù Sifi. 38 Ní ọdún kọkànlá ní oṣù Bulu, oṣù kẹjọ, a sì parí ilé náà jálẹ̀ jálẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ìpín rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí ó yẹ. Ó sì lo ọdún méje ní kíkọ́ ilé náà.

Efesu 3

Paulu jẹ́ oníwàásù sí àwọn aláìkọlà

Nítorí èyí náà ni èmi Paulu ṣe di òǹdè Jesu Kristi nítorí ẹ̀yin aláìkọlà.

(A)Lóòtítọ́ ẹ̀yin tilẹ̀ ti gbọ́ ti iṣẹ́ ìríjú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, tí a fi fún mi fún yín; bí ó ti ṣe pé nípa ìfihàn ni ó ti fi ohun ìjìnlẹ̀ hàn fún mi gẹ́gẹ́ bí mo ti kọ ṣáájú ni ṣókí, Nígbà tí ẹ̀yin bá kà á, nípa èyí tí ẹ̀yin o fi lè mọ òye mi nínú ìjìnlẹ̀ Kristi. Èyí tí a kò í tí ì fihàn àwọn ọmọ ènìyàn rí nínú ìran mìíràn gbogbo, bí a ti fi wọ́n hàn nísinsin yìí fún àwọn aposteli rẹ̀ mímọ́ àti àwọn wòlíì nípa Ẹ̀mí; (B)pé, àwọn aláìkọlà jẹ́ àjùmọ̀jogún àti ẹ̀yà ara kan náà, àti alábápín ìlérí nínú Kristi Jesu nípa ìhìnrere.

Ìránṣẹ́ èyí tí a fi mi ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí a fi fún mi, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ agbára rẹ̀. Fún èmi tí o kéré jùlọ nínú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́, ní a fi oore-ọ̀fẹ́ yìí fún, láti wàásù àwámárídìí ọ̀rọ̀ Kristi fún àwọn aláìkọlà; (C)àti láti mú kí gbogbo ènìyàn rí ohun tí iṣẹ́ ìríjú ohun ìjìnlẹ̀ náà jásí, èyí tí a ti fi pamọ́ láti ìgbà àtijọ́ nínú Ọlọ́run, ẹni tí ó dá ohun gbogbo nípa Jesu Kristi: 10 Kí a bá à lè fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ onírúurú ọgbọ́n Ọlọ́run hàn nísinsin yìí fún àwọn ìjòyè àti àwọn alágbára nínú àwọn ọ̀run, nípasẹ̀ ìjọ, 11 gẹ́gẹ́ bí ìpinnu ayérayé tí ó ti pinnu nínú Kristi Jesu Olúwa wa: 12 Nínú ẹni tí àwa ní ìgboyà, àti ọ̀nà pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé nípa ìgbàgbọ́ wa nínú rẹ̀. 13 Nítorí náà, mo bẹ̀ yín kí àárẹ̀ má ṣe mú yín ni gbogbo wàhálà mi nítorí yín, èyí tí ṣe ògo yín.

Àdúrà fún àwọn ará Efesu

14 Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń fi eékún mi kúnlẹ̀ fún Baba Olúwa wa Jesu Kristi. 15 Orúkọ ẹni tí a fi ń pe gbogbo ìdílé tí ń bẹ ni ọ̀run àti ní ayé. 16 Kí òun kí ó lè fi agbára rẹ̀ fún ẹni inú yín ní okun, nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́. 17 Kí Kristi lè máa gbé inú ọkàn yín nípa ìgbàgbọ́; pé bí ẹ ti ń fi gbòǹgbò múlẹ̀ tí ẹ sì ń fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìfẹ́; 18 kí ẹ̀yin lè ní agbára láti mọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́, ohun tí ìbú, àti gígùn, àti jíjìn, àti gíga ìfẹ́ Kristi jẹ́. 19 Àti láti mọ̀ ìfẹ́ Kristi yìí tí ó ta ìmọ̀ yọ, kí a lè fi gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ọlọ́run kún yín.

20 Ǹjẹ́ ẹni tí o lè ṣe lọ́pọ̀lọpọ̀ ju gbogbo èyí tí a ń béèrè tàbí tí a ń rò lọ, gẹ́gẹ́ bí agbára tí ń ṣiṣẹ́ nínú wa. 21 Òun ni kí a máa fi ògo fún nínú ìjọ àti nínú Kristi Jesu láti ìrandíran gbogbo àní, ayé àìnípẹ̀kun, Àmín.

Esekiẹli 36

Àsọtẹ́lẹ̀ kan sí àwọn òkè Israẹli

36 “Ọmọ ènìyàn, sọtẹ́lẹ̀ sí àwọn òkè gíga Israẹli kí o sì wí pé, ‘Ẹ̀yin òkè gíga Israẹli gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa. Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Àwọn ọ̀tá sọ nípa yín pé, “Háà! Àwọn ibi gíga ìgbàanì ti di ohun ìní wa.” ’ Nítorí náà, sọtẹ́lẹ̀ kí ó sì wí pé, ‘Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Nítorí pé wọn sọ ọ di ahoro, tí wọn sì ń dọdẹ rẹ ní gbogbo ọ̀nà kí ìwọ kí ó lè di ìní fún àwọn orílẹ̀-èdè tí ó kù, àti ohun ti àwọn ènìyàn ń sọ ọ̀rọ̀ ìríra àti ìdíbàjẹ́ sí, nítorí náà, Ẹ̀yin òkè gíga Israẹli gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Olódùmarè: Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí fún àwọn òkè gíga àti àwọn òkè kéékèèkéé, fún Àfonífojì ńlá àti Àfonífojì kéékèèkéé, fún àwọn ibi ìsọdahoro ìparun àti fún àwọn ìlú tí a ti kọ̀sílẹ̀ tí a ti kó tí àwọn orílẹ̀-èdè tí ó kù ní àyíká sì fi ṣe ẹlẹ́yà, èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Ní ìgbóná ọkàn ní mo sọ̀rọ̀ sí àwọn kèfèrí yòókù, àti sí Edomu, nítorí pẹ̀lú ìbínú àti ìjowú ní ọkàn wọn ni wọ́n sọ ilé mi di ohun ìní wọn, kí wọn kí o lè kó pápá oko tútù rẹ̀.’ Nítorí náà, sọtẹ́lẹ̀ nípa ilẹ̀ Israẹli náà kí o sì sọ sí àwọn òkè gíga náà àti àwọn òkè kéékèèkéé, sí àwọn Àfonífojì ńlá àti sí àwọn Àfonífojì kéékèèkéé: ‘Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Èmi sọ̀rọ̀ nínú ìrunú owú mi nítorí pé ìwọ ti jìyà ìfiṣẹ̀sín àwọn orílẹ̀-èdè. Nítorí náà, Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Èmi ṣe ìbúra nípa nína ọwọ́ mi sókè pé; àwọn orílẹ̀-èdè àyíká rẹ náà yóò jìyà ìfiṣẹ̀sín.

“ ‘Ṣùgbọ́n ìwọ, òkè gíga Israẹli, yóò mú ẹ̀ka àti èso fún àwọn ènìyàn mi Israẹli, nítorí wọn yóò wá sílé ní àìpẹ́ yìí. Èmi ń ṣe àníyàn fún ọ, èmi yóò sì fi rere wọ̀ ọ́; àwa yóò tu ọ́, àwa yóò sì gbìn ọ́, 10 èmi yóò sì sọ iye àwọn ènìyàn di púpọ̀ nínú rẹ àti gbogbo ilé Israẹli. Àwọn ìlú yóò di ibùgbé, a yóò sì tún àwọn ibi ìparun kọ́. 11 Èmi yóò sọ iye ènìyàn àti ẹran dì púpọ̀ nínú yín, wọn yóò sì so èso, wọn yóò sì di púpọ̀ yanturu. Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn máa gbé nínú rẹ bí ti àtẹ̀yìnwá, èmi yóò sì mú kí o ṣe rere ju ìgbà àtijọ́ lọ. Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ pé èmi ni Olúwa. 12 Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn, àní àwọn ènìyàn Israẹli, rìn lórí rẹ̀. Wọn yóò gbà ọ́, ìwọ yóò sì di ogún ìní wọn; ìwọ kì yóò sì gba àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ wọn mọ́.

13 “ ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Nítorí pé àwọn ènìyàn sọ fún ọ pé, “Ìwọ pa àwọn ènìyàn run, ìwọ sì gba àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè lọ́wọ́ wọn,” 14 nítorí náà ìwọ kì yóò pa àwọn ènìyàn run tàbí mú kì orílẹ̀-èdè di aláìlọ́mọ mọ́, ni Olúwa Olódùmarè wí. 15 Èmi kì yóò mú ki ó gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn láti ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mọ́, ìwọ kì yóò jìyà ọ̀rọ̀ ìfiṣẹ̀sín láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tàbí mú kí orílẹ̀-èdè rẹ ṣubú, ni Olúwa Olódùmarè wí.’ ”

16 Síwájú sí i ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá: 17 “Ọmọ ènìyàn, nígbà tí àwọn ènìyàn Israẹli: ń gbé ní ilẹ̀ wọn, wọ́n bà á jẹ́ nípa ìwà àti ìṣe wọn. Ìwà wọn dàbí nǹkan àkókò àwọn obìnrin ni ojú mi. 18 Nítorí náà mo tú ìbínú mi jáde sórí wọn nítorí wọn ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ àti nítorí pé wọ́n ti fi ère wọn ba a jẹ́. 19 Mo tú wọn ká sí àárín àwọn orílẹ̀-èdè, a sì fọ́n wọn ká sí àwọn ìlú; mo ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìwà àti ìṣe wọn. 20 Gbogbo ibi tí wọ́n lọ ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè ni wọn ti sọ orúkọ mímọ́ mi di aláìmọ́, nítorí tí a sọ nípa wọn pé, ‘Ìwọ̀nyí ni àwọn ènìyàn Olúwa, síbẹ̀ wọn ní láti fi ilẹ̀ náà sílẹ̀.’ 21 Orúkọ mímọ́ mi jẹ́ mi lógún, èyí tí ilé Israẹli sọ di aláìmọ́ ni àárín àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti lọ.

22 “Nítorí náà, sọ fún ilé Israẹli, ‘Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí: Kì í ṣe nítorí rẹ, ìwọ ilé Israẹli, ni èmi yóò ṣe ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí, ṣùgbọ́n nítorí orúkọ mímọ́ mi, èyí ti ìwọ ti sọ di aláìmọ́ ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ ti lọ. 23 Èmi yóò fi jíjẹ́ mímọ́ orúkọ ńlá mi, èyí tí a ti sọ di aláìmọ́ hàn ni àárín àwọn orílẹ̀-èdè, orúkọ tí ìwọ ti sọ di aláìmọ́ ni àárín wọn. Nígbà náà àwọn orílẹ̀-èdè yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa, ni Olúwa Olódùmarè wí, nígbà tí mo bá fi ara mi hàn ni mímọ́ nípasẹ̀ yín ni iwájú wọn.

24 “ ‘Nítorí èmi yóò mú yín jáde kúrò ni àwọn orílẹ̀-èdè náà; Èmi yóò ṣà yín jọ kúrò ní gbogbo àwọn ìlú náà; Èmi yóò sì mú yín padà sí ilẹ̀ ẹ̀yin tìkára yín. 25 Èmi yóò wọ́n omi tó mọ́ sí yín lára ẹ̀yin yóò sì mọ́; Èmi yóò sì fọ̀ yín mọ́ kúrò nínú gbogbo ìwà èérí yin gbogbo àti kúrò nínú gbogbo òrìṣà yin. 26 Èmi yóò fún yín ni ọkàn tuntun, èmi yóò sì fi ẹ̀mí tuntun sínú yín; Èmi yóò sì mú ọkàn òkúta kúrò nínú yín, èmi yóò sì fi ọkàn ẹran fún yín. 27 Èmi yóò fi ẹ̀mí mi sínú yín, èmi yóò sì mú ki ẹ tẹ̀lé àṣẹ mi, kí ẹ sì fiyèsí àti pa òfin mi mọ́. 28 Ẹ̀yin yóò sì máa gbé ilẹ̀ náà tí mo ti fi fún àwọn baba ńlá yín; ẹ̀yin yóò sì jẹ́ ènìyàn mi èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run yín. 29 Èmi yóò sì gbà yín kúrò nínú gbogbo ìwà àìmọ́ yín. Èmi yóò pèsè ọkà, èmi yóò sì mú kí ó pọ̀ yanturu, èmi kì yóò sì mú ìyàn wá sí orí yín. 30 Èmi yóò sọ èso àwọn igi yín àti ohun ọ̀gbìn oko yín di púpọ̀, nítorí kí ẹ̀yin kí ó má ṣe jìyà ìdójútì mọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè náà nítorí ìyàn. 31 (A)Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò rántí àwọn ọ̀nà búburú àti àwọn ìwà ìkà yín, ẹ̀yin yóò sì kórìíra ara yín fún ẹ̀ṣẹ̀ yín, ìwà tí kò bójúmu. 32 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé ń kò ṣe nǹkan wọ̀nyí nítorí yín, ni Olúwa Olódùmarè wí. Jẹ kí ojú kí ó tì yín, kí ẹ sì gba ẹ̀tẹ́ nítorí ìwà yín ẹ̀yin ilé Israẹli!

33 “ ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Ní ọjọ́ tí mo wẹ̀ yín kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín gbogbo, èmi yóò ṣe àtúnṣe àwọn ìlú yín, wọn yóò sì ṣe àtúnkọ́ ìwólulẹ̀. 34 Ilẹ̀ ahoro náà ní àwa yóò tún kọ́ ti kì yóò wà ní ahoro lójú àwọn tí ó ń gba ibẹ̀ kọjá mọ́. 35 Wọn yóò sọ wí pé, “Ilẹ̀ yìí tí ó ti wà ní ahoro tẹ́lẹ̀ ti dàbí ọgbà Edeni; àwọn ìlú tí ó wà ní wíwó lulẹ̀, ahoro tí a ti parun, ni àwa yóò mọdi sí tí yóò sì wà fún gbígbé ni ìsinsin yìí.” 36 Nígbà náà àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà ní àyíká yín tí ó kù yóò mọ̀ pé èmi Olúwa ti tún àwọn ohun tí ó bàjẹ́ kọ́, mo sì ti tún ohun tí ó di ìṣòfo gbìn. Èmi Olúwa ti sọ̀rọ̀, èmi yóò sì ṣe e?’

37 “Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè sọ: Lẹ́ẹ̀kan sí i èmi yóò yí sí ilé Israẹli, èmi yóò sì ṣe èyí fún wọn. Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn yín pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ bí àgùntàn, 38 Kí ó pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ bí ọ̀wọ́ ẹran fún ìrúbọ ní Jerusalẹmu ní àsìkò àjọ̀dún tí a yàn. Ìlú ti a parun yóò wá kún fún agbo àwọn ènìyàn. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.”

Saamu 86

Adúra ti Dafidi.

86 Gbọ́, Olúwa, kí o sì dá mi lóhùn,
    nítorí mo jẹ́ tálákà àti aláìní.
Dáàbò bò ayé mi, nítorí a ti yà mí sọ́tọ̀ fún ọ:
    ìwọ ni Ọlọ́run mi,
gbà ìránṣẹ́ rẹ là
    tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.
Ṣàánú fún mi, Olúwa,
    nítorí èmi ń pè ọ́ ní gbogbo ọjọ́.
Mú ayọ̀ wà fún ìránṣẹ́ rẹ,
    nítorí ìwọ, Olúwa,
    ni mo gbé ọkàn mí sókè sí.

Ìwọ ń dáríjì, ìwọ sì dára, Olúwa,
    ìwọ sì ṣàánú fún gbogbo àwọn tí ń ké pè ọ́,
Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa;
    tẹ́tí sí ẹkún mi fún àánú.
Ní ọjọ́ ìpọ́njú mi èmi yóò pè ọ́,
    nítorí ìwọ yóò dá mi lóhùn.

Nínú àwọn òrìṣà kò sí ẹni tí ó dàbí i rẹ, Olúwa:
    kò sí àwọn iṣẹ́ tí a lè fiwé tìrẹ.
Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ dá
    yóò wá, láti wá jọ́sìn níwájú rẹ, Olúwa;
    wọn ó mú ògo wà fún orúkọ rẹ̀.
10 Nítorí pé ìwọ tóbi, ìwọ sì ń ṣe ohun ìyanu;
    ìwọ nìkan ni Ọlọ́run.

11 Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, Olúwa,
    èmi ó sì máa rìn nínú òtítọ́ rẹ;
fún mi ní ọkàn tí kì í yapa,
    kí èmi kí ó ba lè bẹ̀rù orúkọ rẹ.
12 Èmi ó yìn ọ́, Olúwa Ọlọ́run mi, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi;
    èmi ó fògo fún orúkọ rẹ títí láé
13 Nítorí títóbi ni ìfẹ́ rẹ si mi;
    ìwọ ti gbà mí kúrò nínú ọ̀gbun isà òkú.

14 Àwọn onígbèéraga ń dojúkọ mí, Ọlọ́run;
    àti ìjọ àwọn alágbára ń wá
ọkàn mi kiri,
    wọn kò sì fi ọ́ pè.
15 Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, jẹ́ aláàánú àti Ọlọ́run olójúrere,
    Ó lọ́ra láti bínú, Ó sì pọ̀ ní ìfẹ́ àti òtítọ́.
16 Yípadà sí mi kí o sì ṣàánú fún mi;
    fún àwọn ènìyàn rẹ ní agbára
    kí o sì gba ọ̀dọ́mọkùnrin ìránṣẹ́bìnrin rẹ là.
17 Fi ààmì hàn mí fún rere,
    kí àwọn tí ó kórìíra mi lè ri,
kí ojú lè tì wọ́n, nítorí ìwọ Olúwa
    ni ó ti tù mí nínú.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.