Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

M’Cheyne Bible Reading Plan

The classic M'Cheyne plan--read the Old Testament, New Testament, and Psalms or Gospels every day.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
2 Samuẹli 22

Orin ìyìn Dafidi

22 Dafidi sì kọ ọ̀rọ̀ orin yìí sí Olúwa ní ọjọ́ tí Olúwa gbà á kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀, àti kúrò lọ́wọ́ Saulu. (A)Ó sì wí pé:

Olúwa ni àpáta mi, àti Olùgbàlà mi;
    Ọlọ́run mi, àpáta mi, nínú ẹni tí èmi ní ààbò,
    àti ìwo ìgbàlà mi, ibi ìsádi gíga mi.
Àti ibi ìlùmọ̀ mi, Olùgbàlà mi;
    ìwọ ni ó ti gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìwà ipá.

“Èmi ké pe Olúwa, tí ó yẹ láti máa yìn,
    ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.
Nígbà tí ìbìlù ìrora ikú yí mi káàkiri;
    tí àwọn ìṣàn ènìyàn búburú dẹ́rùbà mí.
Ọ̀já isà òkú yí mi káàkiri;
    ìkẹ́kùn ikú dojúkọ mí.

“Nínú ìpọ́njú mi, èmi ké pé Olúwa,
    èmi sì gbé ohùn mi sókè sí Ọlọ́run mi.
Ó sí gbóhùn mi láti tẹmpili rẹ̀
    igbe mí wọ etí rẹ̀.
Ilẹ̀ sì mì, ó sì wárìrì;
    ìpìlẹ̀ ọ̀run wárìrì,
    ó sì mì, nítorí tí ó bínú.
Èéfín ti ihò imú rẹ̀ jáde wá;
    Iná ajónirun ti ẹnu rẹ̀ jáde wá,
    ẹ̀yin iná bú jáde láti inú rẹ̀.
10 Ó tẹ orí ọ̀run ba pẹ̀lú, ó sì sọ̀kalẹ̀;
    òkùnkùn biribiri sì ń bẹ ní àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀.
11 Ó sì gun orí kérúbù, ó sì fò:
    a sì rí i lórí ìyẹ́ afẹ́fẹ́.
12 Ó sì fi òkùnkùn ṣe ibùjókòó yí ara rẹ̀, àti àgbájọ omi,
    àní ìṣúdudu ìkùùkuu àwọ̀ sánmọ̀.
13 Nípasẹ̀ ìmọ́lẹ̀ iwájú rẹ̀
    ẹ̀yín iná ràn.
14 Olúwa sán àrá láti ọ̀run wá,
    Ọ̀gá-ògo jùlọ sì fọhùn rẹ̀.
15 Ó sì ta ọfà, ó sì tú wọn ká;
    ó kọ mànàmànà, ó sì ṣẹ́ wọn.
16 Ìṣàn ibú Òkun sì fi ara hàn,
    ìpìlẹ̀ ayé fi ara hàn,
nípa ìbáwí Olúwa,
    nípa fífún èémí ihò imú rẹ̀.

17 “Ó ránṣẹ́ láti òkè wá, ó mú mi;
    ó fà mí jáde láti inú omi ńlá wá.
18 Ó gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá mi alágbára,
    lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra mi: nítorí pé wọ́n lágbára jù mí lọ.
19 Wọ́n wá láti borí mi lọ́jọ́ ìpọ́njú mi:
    ṣùgbọ́n Olúwa ni aláfẹ̀yìntì mi.
20 Ó sì mú mi wá sí ààyè ńlá:
    ó gbà mi, nítorí tí inú rẹ̀ dún sí mi.

21 Olúwa sán án fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi;
    ó sì san án fún mi gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi.
22 Nítorí pé èmi pa ọ̀nà Olúwa mọ́,
    èmi kò sì fi ìwà búburú yapa kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run mi.
23 Nítorí pé gbogbo ìdájọ́ rẹ̀ ni ó wà níwájú mi;
    àti ní ti òfin rẹ̀, èmi kò sì yapa kúrò nínú wọn.
24 Èmi sì wà nínú ìwà títọ́ sí í,
    èmi sì pa ara mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi.
25 Olúwa sì san fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi,
    gẹ́gẹ́ bí ìwà mímọ́ mi níwájú rẹ̀.

26 “Fún aláàánú ni ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ni aláàánú,
    àti fún ẹni ìdúró ṣinṣin ní òdodo ni ìwọ ó fi ara rẹ hàn ní ìdúró ṣinṣin ní òdodo.
27 Fún onínú funfun ni ìwọ fi ara rẹ hàn ní funfun;
    àti fún ẹni wíwọ́ ni ìwọ ó fi ara rẹ hàn ní wíwọ́.
28 Àwọn ènìyàn tí ó wà nínú ìyà ni ìwọ ó sì gbàlà;
    ṣùgbọ́n ojú rẹ wà lára àwọn agbéraga, láti rẹ̀ wọ́n sílẹ̀.
29 Nítorí ìwọ ni ìmọ́lẹ̀ mi, Olúwa;
    Olúwa yóò sì sọ òkùnkùn mi di ìmọ́lẹ̀.
30 Bẹ́ẹ̀ ni nítorí nípa rẹ̀ ni èmi ti la àárín ogun kọjá;
    nípa Ọlọ́run mi èmi ti fo odi kan.

31 “Ọlọ́run yìí, pípé ni ọ̀nà rẹ̀;
    ọ̀rọ̀ Olúwa ni a ti dánwò.
    Òun sì ni asà fún gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e.
32 Nítorí ta ni Ọlọ́run, bí kò ṣe Olúwa?
    Ta ni àpáta, bí kò ṣe Ọlọ́run wa.
33 Ọlọ́run alágbára ni ó fún mi ní agbára,
    ó sì sọ ọ̀nà mi di títọ́.
34 Ó ṣe ẹsẹ̀ mi bí ẹsẹ̀ abo àgbọ̀nrín;
    ó sì mú mi dúró ní ibi gíga mi.
35 Ó kọ́ ọwọ́ mi ní ogun jíjà;
    tó bẹ́ẹ̀ tí apá mi fa ọrun idẹ.
36 Ìwọ sì ti fún mi ní asà
    ìgbàlà rẹ̀, ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ sì ti sọ mí di ńlá.
37 Ìwọ sì sọ ìtẹ̀lẹ̀ di ńlá ní abẹ́ mi;
    tó bẹ́ẹ̀ tí ẹsẹ̀ mi kò fi yọ̀.

38 “Èmi ti lépa àwọn ọ̀tá mi, èmi sì ti run wọ́n,
    èmi kò pẹ̀yìndà títí èmi fi run wọ́n.
39 Èmi ti pa wọ́n run, èmi sì ti fọ́ wọn,
    wọn kò sì le dìde mọ́: wọ́n ṣubú lábẹ́ mi.
40 Ìwọ sì ti fi agbára dì mí ní àmùrè fún ìjà;
    àwọn tí ó ti dìde sí mi ni ìwọ sì ti tẹ̀ lórí ba fún mi.
41 Ìwọ sì mú àwọn ọ̀tá mi pẹ̀yìndà fún mi,
    èmi ó sì pa àwọn tí ó kórìíra mi run.
42 Wọ́n wò, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan láti gbà wọ́n;
    wọ́n wo Olúwa, ṣùgbọ́n kò dá àwọn lóhùn.
43 Nígbà náà ni èmi sì gún wọn wẹ́wẹ́ bí erùpẹ̀ ilẹ̀,
    èmi sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ bí ẹrẹ̀ ìta, èmi sì tẹ́ wọn gbọrọ.

44 “Ìwọ sì gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìjà àwọn ènìyàn mi,
    ìwọ pa mi mọ́ ki èmi lè ṣe olórí àwọn àjèjì orílẹ̀-èdè.
Àwọn ènìyàn tí èmi kò tí mọ̀ yóò máa sìn mí.
45     Àwọn àjèjì wá láti tẹríba fún mi;
    bí wọ́n bá ti gbúròó mi, wọ́n á sì gbọ́ tèmi.
46 Àyà yóò pá àwọn àlejò,
    wọ́n ó sì fi ìbẹ̀rù sá kúrò níbi kọ́lọ́fín wọn.

47 Olúwa ń bẹ́; olùbùkún sì ni àpáta mi!
    Gbígbéga sì ni Ọlọ́run àpáta ìgbàlà mi.
48 Ọlọ́run ni ẹni tí ń gbẹ̀san mi,
    àti ẹni tí ń rẹ àwọn ènìyàn sílẹ̀ lábẹ́ mi.
49     Àti ẹni tí ó gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.
Ìwọ sì gbé mi sókè ju àwọn tí ó kórìíra mi lọ;
    ìwọ sì gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọkùnrin oníwà ipá.
50 (B)Nítorí náà èmi ó fi ọpẹ́ fún ọ, Olúwa,
    láàrín àwọn àjèjì orílẹ̀-èdè: èmi ó sì kọrin sí orúkọ rẹ.

51 “Òun ni ilé ìṣọ́ ìgbàlà fún ọba rẹ̀;
    ó sì fi àánú hàn fún ẹni ààmì òróró rẹ̀,
    fún Dafidi, àti fún irú-ọmọ rẹ̀ títí láéláé.”

Galatia 2

Àwọn aposteli tẹ́wọ́ gba Paulu

(A)Lẹ́yìn ọdún mẹ́rìnlá, ni mo tún gòkè lọ sì Jerusalẹmu pẹ̀lú Barnaba, mo sì mú Titu lọ pẹ̀lú mi. Mo gòkè lọ nípa ohun ti a fihàn mi, mo fi ìhìnrere náà tí mo ń wàásù láàrín àwọn aláìkọlà yé àwọn tí ó jẹ́ ẹni ńlá nínú wọn, èyí i nì ní ìkọ̀kọ̀, kí èmi kí ó má ba á sáré, tàbí kí ó máa ba à jẹ́ pé mo ti sáré lásán. Ṣùgbọ́n a kò fi agbára mú Titu tí ó wà pẹ̀lú mi, ẹni tí í ṣe ara Giriki láti kọlà. Ọ̀rọ̀ yìí wáyé nítorí àwọn èké arákùnrin tí wọn yọ́ wọ inú àárín wa láti yọ́ òmìnira wa wò, èyí tí àwa ni nínú Kristi Jesu, kí wọn lè mú wa wá sínú ìdè. (B)Àwọn ẹni ti a kò fún ni àǹfààní láti gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn fún ìṣẹ́jú kan; kí ẹ̀yin kí o lè máa tẹ̀síwájú nínú òtítọ́ ìhìnrere náà.

(C)Ṣùgbọ́n ní ti àwọn tí ó dàbí ẹni pàtàkì—ohunkóhun tí ó wù kì wọn jásí, kò jẹ́ nǹkan kan fún mi; Ọlọ́run kò fi bí ẹnikẹ́ni ṣe rí ṣe ìdájọ́ rẹ̀—àwọn ènìyàn yìí kò fi ohunkóhun kún ọ̀rọ̀ mi. Ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, nígbà tí wọn rí i pé a tí fi ìhìnrere tí àwọn aláìkọlà le mi lọ́wọ́, bí a tí fi ìhìnrere tí àwọn onílà lé Peteru lọ́wọ́. Nítorí Ọlọ́run, ẹni tí ó ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ Peteru gẹ́gẹ́ bí aposteli sí àwọn Júù, òun kan náà ni ó ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi gẹ́gẹ́ bí aposteli sí àwọn aláìkọlà. Jakọbu, Peteru, àti Johanu, àwọn ẹni tí ó dàbí ọ̀wọ́n, fún èmi àti Barnaba ni ọwọ́ ọ̀tún ìdàpọ̀ nígbà tí wọ́n rí oore-ọ̀fẹ́ tí a fi fún mi, wọ́n sì gbà pé kí àwa náà tọ àwọn aláìkọlà lọ, nígbà ti àwọn náà lọ sọ́dọ̀ àwọn Júù. 10 Ohun gbogbo tí wọ́n béèrè fún ni wí pé, kí a máa rántí àwọn tálákà, ohun kan náà gan an tí mo ń làkàkà láti ṣe.

Paulu tako Peteru

11 (D)Ṣùgbọ́n nígbà tí Peteru wá sí Antioku, mo takò ó lójú ara rẹ̀, nítorí tí ó jẹ̀bi, mo sì bá a wí. 12 Nítorí pé kí àwọn kan tí ó ti ọ̀dọ̀ Jakọbu wá tó dé, ó ti ń ba àwọn aláìkọlà jẹun; Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé, ó fàsẹ́yìn, ó sì ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn aláìkọlà nítorí ó bẹ̀rù àwọn ti ó kọlà. 13 Àwọn Júù tí ó kù pawọ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ láti jùmọ̀ ṣe àgàbàgebè, tó bẹ́ẹ̀ tí wọn sì fi àgàbàgebè wọn si Barnaba lọ́nà.

14 Nígbà tí mo rí i pé wọn kò rìn déédé gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ ìhìnrere, mo wí fún Peteru níwájú gbogbo wọn pé, “Bí ìwọ, tí ì ṣe Júù ba ń rìn gẹ́gẹ́ bí ìwà àwọn kèfèrí, èéṣe tí ìwọ fi ń fi agbára mu àwọn keferi láti máa rìn bí àwọn Júù?

15 “Àwa tí i ṣe Júù nípa ìbí, tí kì i sí ì ṣe ‘aláìkọlà ẹlẹ́ṣẹ̀,’ 16 (E)Tí a mọ̀ pé a kò dá ẹnikẹ́ni láre nípa iṣẹ́ òfin, bí kò ṣe nípa ìgbàgbọ́ nínú Jesu Kristi, àní àwa pẹ̀lú gbà Jesu Kristi gbọ́, kí a bá a lè dá wa láre nípa ìgbàgbọ́ tí Kristi, kì í sì i ṣe nípa iṣẹ́ òfin: nítorí pé nípa iṣẹ́ òfin kò sí ènìyàn kan tí a ó dá láre.

17 “Ṣùgbọ́n nígbà tí àwa bá ń wá ọ̀nà láti rí ìdáláre nípa Kristi, ó di ẹ̀rí wí pé àwa pẹ̀lú jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, ǹjẹ́ èyí ha jásí wí pé Kristi ń ṣe ìránṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ bí? Kí a má rí ì! 18 Nítorí pé bí mo bá sì tún gbé àwọn ohun tí mo tí wó palẹ̀ ró, mo fi ara mi hàn bí arúfin.

19 “Nítorí pé nípa òfin, mo tí di òkú sí òfin, kí èmi lè wà láààyè sí Ọlọ́run. 20 (F)A ti kàn mí mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú Kristi, èmí kò sì wà láààyè mọ́, ṣùgbọ́n Kristi ń gbé inú mi wíwà tí mo sì wà láààyè nínú ara, mo wà láààyè nínú ìgbàgbọ́ ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí o fẹ́ mi, tí ó sì fi òun tìkára rẹ̀ fún mi. 21 Èmi kò ya oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run sí apá kan: nítorí pé bí a bá le ti ipasẹ̀ òfin jèrè òdodo, a jẹ́ pé Kristi kú lásán.”

Esekiẹli 29

Àsọtẹ́lẹ̀ òdì sí Ejibiti

29 (A)Ní ọjọ́ kejìlá, oṣù kẹwàá, ọdún kẹwàá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: “Ọmọ ènìyàn, kọjú sí Farao ọba Ejibiti kí ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí i àti sí gbogbo Ejibiti. Sọ̀rọ̀, kí ó sì wí pé: ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí:

“ ‘Èmi lòdì sí ọ, Farao ọba Ejibiti
    ìwọ ẹ̀mí búburú ńlá inú Òkun tí ó dùbúlẹ̀ sí
àárín àwọn odò ṣíṣàn rẹ
    èyí tí ó sọ wí pé, “Tèmi ni odò Naili;
    èmi ni ó sì ṣe é fún ara mi.”
Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ìwọ̀ mú ẹnu rẹ
    èmi yóò sì mú ẹja inú odò rẹ
gbogbo lẹ̀ mọ́ ìpẹ́ ara rẹ.
    Èmi yóò fà ọ́ síta kúrò láàrín àwọn odò rẹ,
    àti gbogbo ẹja odò rẹ yóò lẹ̀ mọ́ ìpẹ́ ara rẹ.
Èmi yóò sọ ọ́ nù sí aginjù
    ìwọ àti gbogbo ẹja inú odò rẹ:
ìwọ yóò ṣubú sí gbangba oko
    a kì yóò sì ṣà ọ́ jọ tàbí gbé ọ sókè.
Èmi ti fi ọ ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹranko igbó
    àti fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run láti jẹ.

Nígbà náà gbogbo àwọn olùgbé ni Ejibiti yóò mọ pé Èmi ni Olúwa.

“ ‘Ìwọ ti jẹ́ ọ̀pá ìyè fún ilé Israẹli. Nígbà tí wọn fi ọwọ́ agbára wọn dì ọ́ mú. Ìwọ fọ́, ìwọ sì ya gbogbo èjìká wọn; nígbà tí wọn fi ara tì ọ́, ìwọ sẹ́, ìwọ sì mú gbogbo ẹ̀gbẹ́ wọn gbọ̀n.

“ ‘Nítorí náà, èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: kéyèsi Èmi yóò mú idà kan wá sórí rẹ tí yóò sì gé ènìyàn àti ẹran kúrò nínú rẹ. Ilẹ̀ Ejibiti yóò di aginjù àti ahoro, nígbà náà ní wọn yóò sì mọ̀ wí pé èmi ní Olúwa.

“ ‘Nítorí tí ìwọ wí pé, “Tèmi ni odò Naili; Èmi ni mo ṣe é,” 10 Nítorí náà, mo lòdì sí ọ àti sí àwọn odò rẹ, èmi yóò sì mú kí ilẹ̀ Ejibiti di píparun àti ahoro, pátápátá, láti Migdoli lọ dé Siene, dé ààlà ilẹ̀ Kuṣi. 11 Kò sí ẹsẹ̀ ènìyàn tàbí tí ẹranko tí yóò gba ibẹ̀ kọjá; ẹni kankan kò ní gbé ibẹ̀ fún ogójì ọdún. 12 Èmi yóò sọ ilẹ̀ Ejibiti di ọ̀kan ní àárín àwọn ìlú tí ó di ahoro, fún ogójì ọdún, Èmi yóò sì fọ́n àwọn ara Ejibiti ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè, èmi yóò sì tú wọn ká sáàárín gbogbo ilẹ̀.

13 “ ‘Ṣùgbọ́n báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Ní òpin ogójì ọdún, èmi yóò ṣa àwọn ará Ejibiti jọ láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn níbi tí a fọ́n wọn ká sí. 14 Èmi yóò sì tún mú ìgbèkùn Ejibiti padà bọ̀, èmi yóò sì dá wọn padà sí ilẹ̀ Paturosi, ilẹ̀ àwọn baba ńlá wọn. Wọn yóò wà níbẹ̀ bí ìjọba tí a rẹ̀ sílẹ̀. 15 Ibẹ̀ yóò jẹ́ ìjọba tí ó rẹlẹ̀ jùlọ nínú àwọn ìjọba, kì yóò sì gbé ara rẹ̀ ga mọ́ sórí àwọn orílẹ̀-èdè: nítorí èmi ni ó dín wọn kù, tiwọn kì yóò fi ṣe olórí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù mọ́. 16 Ejibiti kí yóò sì jẹ orísun ìgbẹ́kẹ̀lé fún ilé Israẹli mọ́ ṣùgbọ́n, yóò jẹ́ ìrántí fún àìṣedéédéé wọn, nígbà tí yóò bá wò wọ́n fún ìrànlọ́wọ́. Nígbà náà, wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Olódùmarè.’ ”

Èrè Nebukadnessari

17 Ó sì ṣe ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kìn-ín-ní, ọdún kẹtà-dínlọ́gbọ̀n, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: 18 “Ọmọ ènìyàn, Nebukadnessari ọba Babeli mú kí ogun rẹ sin ìrú ńlá fún Tire. Gbogbo orí pá, àti gbogbo èjìká bó, síbẹ̀, òun àti àwọn ogun rẹ̀, kò rí owó ọ̀yà gbà láti Tire fún wa, fún ìrú ti a ti sìn. 19 Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Kíyèsi i, Èmi yóò fi Ejibiti fún Nebukadnessari ọba Babeli, òun yóò sì kó ọrọ̀ rẹ̀ lọ. Òun yóò bo ilé, yóò sì ṣe ìkógun ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí owó iṣẹ́ tí a san fún ológun rẹ̀. 20 Èmi ti fi Ejibiti fún un gẹ́gẹ́ bí èrè wàhálà rẹ̀ nítorí òun àti àwọn ológun rẹ ṣe é fún mi, ni Olúwa Olódùmarè wí.

21 “Ní ọjọ́ náà, èmi yóò mú kí ìwo Israẹli ru jáde, èmi yóò sì fún ọ ní ẹnu ọ̀rọ̀ ní àárín wọn. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.”

Saamu 78:1-37

Maskili ti Asafu.

78 Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ gbọ́ ẹ̀kọ́ mi;
    tẹ́tí rẹ sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi.
(A)Èmi ó la ẹnu mi ní òwe,
    èmi o sọ ohun ìkọ̀kọ̀, ohun ti ọjọ́ pípẹ́;
Ohun tí a ti gbọ́ tí a sì ti mọ̀,
    ohun tí àwọn baba wa ti sọ fún wa.
Àwa kì yóò pa wọ́n mọ́
    kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ,
ní fífi ìyìn Olúwa, àti ipa rẹ̀
    àti iṣẹ́ ìyanu tó ti ṣe hàn
fún ìran tí ń bọ̀.
Ó gbé ẹ̀rí kalẹ̀ ní Jakọbu
    o sì fìdí àṣẹ múlẹ̀ ní Israẹli,
èyí tí ó pàṣẹ fún àwọn baba ńlá wa
    láti kọ́ àwọn ọmọ wọn,
Nítorí náà, àwọn ìran tí ń bọ̀ yóò mọ̀ wọ́n
    bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ tí a kò tí ì bí
    tí yóò dìde tí wọn yóò sọ fún àwọn ọmọ wọn
Nígbà náà ni wọ́n ò fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sínú Ọlọ́run
    wọn kò sì ní gbàgbé iṣẹ́ Ọlọ́run
    ṣùgbọ́n wọn ó pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.
Kí wọn kí ó má ṣe dàbí àwọn baba ńlá wọn,
    ìran alágídí àti ọlọ́tẹ̀,
    ìran tí ọkàn wọn kò ṣọ òtítọ́ si olóore,
    àti ẹ̀mí ẹni tí kò bá Ọlọ́run dúró ṣinṣin.

Àwọn ọkùnrin Efraimu, tí ó há mọ́ ọ tí wọ́n mú ọrun,
    wọ́n yípadà ní ọjọ́ ogun
10 Wọn kò pa májẹ̀mú Ọlọ́run mọ́
    wọn sì kọ̀ láti máa gbé nínú òfin rẹ̀
11 Wọ́n gbàgbé ohun tí ó ti ṣe,
    àwọn ìyanu tí ó ti fihàn wọ́n.
12 Ó ṣe ìyanu níwájú àwọn baba wọn ní ilẹ̀ Ejibiti, ní agbègbè Ṣoani.
13 Ó pín Òkun ní yà, ó sì mú wọn kọjá
    Ó mù kí omi naà dúró bi odi gíga.
14 Ní ọ̀sán, ó fi ìkùùkuu àwọsánmọ̀ ṣe amọ̀nà wọn
    àti ní gbogbo òru pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ iná.
15 Ó sán àpáta ní aginjù
    ó sì fún wọn ní omi mímu lọ́pọ̀lọpọ̀
    bí ẹni pé láti inú ibú wá.
16 Ó mú ìṣàn omi jáde láti inú àpáta
    omi ṣíṣàn sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí odò.

17 Wọ́n sì tún tẹ̀síwájú láti dẹ́ṣẹ̀ sí i
    ní ìṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá-ògo ní aginjù.
18 Wọ́n mọ̀ ọ́n mọ̀ dán Ọlọ́run wò
    nípa bíbéèrè fún oúnjẹ tí wọn bẹ̀bẹ̀ fún
19 Wọ́n sọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run, wí pé
    “Ọlọ́run ha lè tẹ́ tábìlì ní aginjù?
20 Nígbà tí ó lu àpáta, omi tú jáde,
    odò sì sàn lọ́pọ̀lọpọ̀
ṣùgbọ́n òun ha lè fún wa lóúnjẹ
    ó ha le pèsè ẹran fún àwọn ènìyàn rẹ̀”
21 Nígbà tí Olúwa gbọ́ wọn, ó bínú gidigidi;
iná rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ sí Jakọbu,
ìbínú rẹ̀ sì rú sí Israẹli,
22 Nítorí wọn kò gba Ọlọ́run gbọ́,
    wọn kò sì gbẹ́kẹ̀lé ìgbàlà rẹ̀.
23 Síbẹ̀ ó pàṣẹ fún ìràwọ̀ ojú ọ̀run,
    ó sì ṣí ìlẹ̀kùn ọ̀run sílẹ̀;
24 (B)Ó rọ manna fún àwọn ènìyàn láti jẹ,
    ó fún wọn ní ọkà láti ọ̀run.
25 Àwọn ènìyàn jẹ oúnjẹ àwọn angẹli;
    Ó fún wọn ní oúnjẹ ní àjẹyó,
26 Ó mú afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn láti ọ̀run wá
    ó mú afẹ́fẹ́ gúúsù wá nípa agbára rẹ̀.
27 Ó rọ òjò ẹran sílẹ̀ sórí wọn bí erùpẹ̀ ilẹ̀,
    àti ẹyẹ abìyẹ́ gẹ́gẹ́ bí iyanrìn etí Òkun
28 Ó jẹ́ kí wọn jáde ní ibùdó wọn,
    yíká àgọ́ wọn.
29 Wọ́n jẹ, wọ́n sì yó jọjọ
    nítorí ó ti fún wọn ní ohun tí wọn fìtara bẹ̀bẹ̀ fún
30 Ṣùgbọ́n wọn kò kúrò nínú oúnjẹ tí wọn fìtara bẹ̀bẹ̀ fún,
    nígbà tí oúnjẹ wọn sì wà ní ẹnu wọn,
31 Ìbínú Ọlọ́run dìde sí wọn
    ó pa àwọn tí ó jùlọ nínú wọn,
    ó sì lu àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Israẹli bolẹ̀.

32 Nínú gbogbo ìwọ̀nyí, wọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ síwájú;
    nínú gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, wọ́n kò gbàgbọ́
33 O fi òpin sí ayé wọn nínú asán
    àti ọdún wọn nínú ìpayà.
34 Nígbàkígbà tí Ọlọ́run bá pa wọ́n,
    wọn yóò wá a kiri;
    wọn yóò fi ìtara yípadà sí i.
35 Wọ́n rántí pé Ọlọ́run ní àpáta wọn;
    wí pé Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo jùlọ ni olùràpadà àpáta wọn
36 Ṣùgbọ́n nígbà náà ni wọ́n yóò pọ́n ọn pẹ̀lú ẹnu wọ́n
    wọ́n fi ahọ́n wọ́n purọ́ fún un;
37 (C)Ọkàn wọn kò sòtítọ́ sí i,
    wọn kò jẹ́ olódodo sí májẹ̀mú rẹ̀.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.