Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

M’Cheyne Bible Reading Plan

The classic M'Cheyne plan--read the Old Testament, New Testament, and Psalms or Gospels every day.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
1 Samuẹli 27

Dafidi láàrín àwọn ara Filistini

27 Dafidi sì wí ní ọkàn ara rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ ni ìjọ kan ni èmi yóò ti ọwọ́ Saulu ṣègbé, kò sì sí ohun tí ó yẹ mí jù kí èmi yára sá àsálà lọ sórí ilẹ̀ àwọn Filistini: yóò sú Saulu láti máa tún wa mi kiri ní gbogbo agbègbè Israẹli: èmi a sì bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.”

Dafidi sì dìde, ó sì rékọjá, òun pẹ̀lú ẹgbẹ̀ta ọmọkùnrin tí o ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ sí Akiṣi, ọmọ Maoki, ọba Gati. Dafidi sì bá Akiṣi jókòó ní Gati, òun, àti àwọn ọmọkùnrin rẹ, olúkúlùkù wọn pẹ̀lú ará ilé rẹ̀; Dafidi pẹ̀lú àwọn aya rẹ̀ méjèèjì, Ahinoamu ará Jesreeli, àti Abigaili ará Karmeli aya Nabali. A sì sọ fún Saulu pé, Dafidi sálọ si Gati: òun kò sì tún wá á kiri mọ́.

Dafidi sì wí fún Akiṣi pé, “Bí ó bá jẹ́ pé èmi rí oore-ọ̀fẹ́ lójú rẹ̀, jẹ́ kí wọn ó fún mi ní ibìkan nínú àwọn ìletò wọ̀nyí; èmi yóò máa gbé ibẹ̀: èéṣe tí ìránṣẹ́ rẹ yóò sì máa bá ọ gbé ní ìlú ọba.”

Akiṣi sí fi Siklagi fún un ní ọjọ́ náà nítorí náà ni Siklagi fi dí ọba Juda títí ó fi dì òní yìí. Iye ọjọ́ tí Dafidi fi jókòó ní ìlú àwọn Filistini sì jẹ́ ọdún kan àti oṣù mẹ́rin.

Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì gòkè lọ, wọ́n sì gbé ogun ti àwọn ará Geṣuri, àti àwọn ará Gesri, àti àwọn ará Amaleki àwọn wọ̀nyí ni ó sì tí ń gbé ní ilẹ̀ náà, láti ìgbà àtijọ́, bí ó ti fẹ̀ lọ sí Ṣuri títí ó fi dé ilẹ̀ Ejibiti. Dafidi sì kọlu ilẹ̀ náà kò sì fi ọkùnrin tàbí obìnrin sílẹ̀ láààyè, ó sì kó àgùntàn, àti màlúù, àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àti ìbákasẹ, àti aṣọ, ó sì yípadà ó tọ Akiṣi wá.

10 Akiṣi sì bi í pé, “Níbo ni ẹ̀yin gbé rìn sí lónìí?” Dafidi sì dáhùn pé, “Sí ìhà gúúsù ti Juda ni, tàbí sí ìhà gúúsù ti Jerahmeeli,” tàbí “Sí ìhà gúúsù ti àwọn ará Keni.” 11 Dafidi kò sì dá ọkùnrin tàbí obìnrin sí láààyè, láti mú ìròyìn wá sí Gati, wí pé, “Ki wọn máa bá à sọ ọ̀rọ̀ wa níbẹ̀, pé, ‘Báyìí ni Dafidi ṣe’ ” Àti bẹ́ẹ̀ ni ìṣe rẹ̀, yóò sì rí ni gbogbo ọjọ́ ti yóò fi jókòó ni ìlú àwọn Filistini. 12 Akiṣi sì gba ti Dafidi gbọ́, wí pé, “Òun ti mú kí Israẹli àti àwọn ènìyàn rẹ̀ kórìíra rẹ̀ pátápátá, yóò si jẹ́ ìránṣẹ́ mi títí láé.”

1 Kọrinti 8

Oúnjẹ tí a fi rú ẹbọ sí òrìṣà

(A)Ní ìsinsin yìí, nípa tí oúnjẹ ti a fi rú ẹbọ sí òrìṣà, a mọ̀ pé gbogbo wa ni a ní ìmọ̀. Imọ̀ a máa fẹ́ mu ní gbéraga, ṣùgbọ́n ìfẹ́ ní gbé ni ró. (B)Bí ẹnikẹ́ni bá ró pé òun mọ ohun kan, kò tí ì mọ̀ bí ó ti yẹ kí ó mọ̀. (C)Ṣùgbọ́n ẹni tí ó fẹ́ràn Ọlọ́run nítòótọ́, òun ni ẹni tí Ọlọ́run mọ.

(D)Nítorí náà, ǹjẹ́ ó yẹ kí a jẹ àwọn oúnjẹ ti a fi rú ẹbọ sí àwọn òrìṣà bí? Láìṣe àní àní, gbogbo wá mọ̀ pé àwọn ère òrìṣà kì í ṣe Ọlọ́run rárá, ohun asán ni wọn ni ayé. A sì mọ̀ dájúdájú pé Ọlọ́run kan ṣoṣo ní ń bẹ, kò sì ṣí ọlọ́run mìíràn bí kò ṣe ọ̀kan ṣoṣo. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, à ní ọ̀pọ̀ ọlọ́run kéékèèkéé mìíràn ní ọ̀run àti ní ayé (gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ “ọlọ́run” ṣe wa náà ní ọ̀pọ̀ “olúwa” wa). (E)Ṣùgbọ́n fún àwa Ọlọ́run kan ní ó wa, Baba, lọ́wọ́ ẹni tí ó dá ohun gbogbo, àti ti ẹni tí gbogbo wa í ṣe, àti Olúwa kan ṣoṣo Jesu Kristi, nípasẹ̀ ẹni tí ohun gbogbo wà, àti àwa nípasẹ̀ rẹ̀.

(F)Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo ènìyàn lo mọ èyí: Ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn tí ó ti ń bọ̀rìṣà lọ́jọ́ tó ti pẹ́ títí di ìsinsin yìí jẹ ẹ́ bí ohun tí a fi rú ẹbọ sí òrìṣà; àti ẹ̀rí ọkàn wọn tí ó ṣe àìlera sì di aláìmọ́. (G)Ṣùgbọ́n oúnjẹ kò mú wa súnmọ́ Ọlọ́run, nítorí pé kì í ṣe bí àwa bá jẹun ni àwa burú jùlọ tàbí nígbà tí a kò jẹ ni àwa dára jùlọ.

(H)Ṣùgbọ́n ẹ máa kíyèsi ara gidigidi nípa ìlò òmìnira yín kí ẹ má ba à mú kí àwọn arákùnrin mìíràn tí í ṣe onígbàgbọ́, tí ọkàn wọn ṣe aláìlera, ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀. 10 Ẹ kíyèsára, nítorí bi ẹnìkan ba rí i ti ìwọ ti o ni ìmọ̀ bá jókòó ti oúnjẹ ní ilé òrìṣà, ǹjẹ́ òun kò ha ni mú ọkàn le, bi ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ bá ṣe aláìlera, láti jẹ oúnjẹ tí a fi rú ẹbọ sí òrìṣà? 11 (I)Nítorí náà, nípa ìmọ̀ rẹ ni arákùnrin aláìlera náà yóò ṣe ṣègbé, arákùnrin ẹni tí Kristi kú fún. 12 (J)Bí ẹ bá dẹ́ṣẹ̀ sí arákùnrin rẹ̀ tí ẹ sì ń pa ọkàn àìlera wọn lára, ẹ̀yìn ǹ dẹ́ṣẹ̀ sí Kristi jùlọ. 13 (K)Nítorí nà án, bí oúnjẹ bá mú arákùnrin mi kọsẹ̀, èmi kì yóò sì jẹ ẹran mọ́ títí láé, kí èmi má ba à mú arákùnrin mi kọsẹ̀.

Esekiẹli 6

Ìsọtẹ́lẹ̀ sí àwọn òkè Israẹli

Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá wí pé: “Ọmọ ènìyàn, dojúkọ àwọn òkè Israẹli; kí o sì sọtẹ́lẹ̀ lòdì sí wọn wí pé: ‘Ẹ̀yin òkè Israẹli, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Olódùmarè. Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí sí ẹ̀yin òkè ńlá àti àwọn òkè kéékèèkéé, sí àwọn odò ṣíṣàn àti sí Àfonífojì, èmi yóò mú idà wa sórí yín, èmí yóò sì pa ibi gíga yín run. Èmi yóò wó pẹpẹ yín lulẹ̀, èmi yóò sì fọ́ pẹpẹ tùràrí yín túútúú; èmi yóò sì pa àwọn ènìyàn yín síwájú àwọn òrìṣà wọn. Èmi yóò tẹ́ òkú àwọn ará Israẹli síwájú òrìṣà wọn, èmi yóò sì fọ́n egungun wọn yí pẹpẹ wọn ká. Gbogbo ibi tí ẹ ń gbé àti àwọn ibi gíga yín ni yóò di píparun, gbogbo pẹpẹ yín ni yóò di ahoro, àwọn òrìṣà yín yóò di fífọ́ túútúú, àwọn pẹpẹ tùràrí yín ni a ó gé lulẹ̀, gbogbo iṣẹ́ yín yóò parẹ́. Àwọn ènìyàn yín yóò ṣubú láàrín yín, ẹ ó sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.

“ ‘Ṣùgbọ́n èmi yóò dá àwọn kan sí nítorí pé díẹ̀ nínú yín ni yóò bọ́ lọ́wọ́ idà, nígbà tí a bá fọ́n yín ká sí gbogbo ilẹ̀ àti orílẹ̀-èdè. Àwọn ti ó bọ́ nínú yin yóò sì rántí mi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè níbi tí wọn yóò dìwọ́n ní ìgbèkùn lọ, nítorí wọ́n yóò máa rántí mi bí wọ́n ti bà mí lọ́kàn jẹ́ nípa àgbèrè wọn, tí ó yà wọ́n kúrò lọ́dọ̀ mi àti nípa ojú wọn tí ó ṣàfẹ́rí àwọn òrìṣà. Wọn yóò sì ṣú ara wọn nítorí ìwà ibi tí wọ́n ti hù nípa gbogbo ìríra wọn. 10 Wọn yóò sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa; àti pé kì í ṣe lásán ni mo ń lérí pé èmi yóò mú ìdààmú bá wọn.

11 “ ‘Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Pàtẹ́wọ́ kí o tún fẹsẹ̀ janlẹ̀, kí o wá kígbe síta pé, “Ó ṣe!” Ilé Israẹli yóò ṣubú nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn nítorí gbogbo ìwà ìríra búburú tí wọ́n hù. Wọn yóò ṣubú nípa idà àti ìyàn. 12 Ẹni tó wà lókèèrè yóò kú pẹ̀lú àjàkálẹ̀-ààrùn, àti ẹni tó wà nítòsí yóò ṣubú pẹ̀lú idà, ìyàn ni yóò pa ẹni tó bá ṣẹ́kù sílẹ̀. Báyìí ni èmi yóò ṣe mú ìbínú gbígbóná mi wá sórí wọn. 13 Wọn yóò sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa, nígbà tí òkú àwọn ènìyàn wọn bá wà níbẹ̀ láàrín òrìṣà wọn yí pẹpẹ wọn ká, lórí àwọn òkè gíga gbogbo, àti lórí góńgó òkè àti lábẹ́ igi tútù àti lábẹ́ igi óákù, níbi tí wọ́n ti ń fi tùràrí olóòórùn dídùn rú ẹbọ sí gbogbo òrìṣà wọn. 14 Èmi yóò na ọwọ́ mi jáde sí wọn láti mú kí ilẹ̀ náà ṣòfò, kí ó sì dahoro dé aṣálẹ̀ ìhà Dibila—ní gbogbo ibùgbé wọn. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.’ ”

Saamu 44

Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Maskili.

44 À ti fi etí wa gbọ́, Ọlọ́run
    àwọn baba wa tí sọ fún wa
ohun tí ìwọ ṣe ní ọjọ́ wọn,
    ní ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn.
Ìwọ fi ọwọ́ rẹ lé orílẹ̀-èdè jáde
    Ìwọ sì gbin àwọn baba wa;
Ìwọ run àwọn ènìyàn náà
    Ìwọ sì mú àwọn baba wa gbilẹ̀.
Kì í ṣe nípa idà wọn ni wọ́n gba ilẹ̀ náà,
    bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe apá wọn ní ó gbà wọ́n bí kò ṣe;
ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti, apá rẹ;
    àti ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ̀, nítorí ìwọ fẹ́ wọn.

Ìwọ ni ọba àti Ọlọ́run mi,
    ẹni tí ó pàṣẹ ìṣẹ́gun fún Jakọbu.
Nípasẹ̀ rẹ ni àwa ó bi àwọn ọ̀tá wa ṣubú;
    nípasẹ̀ orúkọ rẹ ni àwa ó tẹ àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí wa mọ́lẹ̀
Èmi kì yóò gbẹ́kẹ̀lé ọrun mi
    idà mi kì yóò mú ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá wá,
Ṣùgbọ́n ìwọ fún wa ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá wa,
    ìwọ sì ti dójúti àwọn tí ó kórìíra wa.
Nínú Ọlọ́run àwa ń ṣògo ní gbogbo ọjọ́,
    àwa ó sì yin orúkọ rẹ títí láé. Sela.

Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ìwọ ti kọ̀ wá, ìwọ sì ti dójútì wá;
    Ìwọ kò sì bá àwọn ọmọ-ogun wa jáde mọ́.
10 Ìwọ ti bá wa jà,
    ìwọ sì ti ṣẹ́gun wa níwájú àwọn ọ̀tá wa,
àwọn ọ̀tá wa ti gba ilẹ̀ wa,
    wọ́n sì fi ipá gba oko wa.
11 Ìwọ fi wá fún jíjẹ bí ẹran àgùntàn
    Ìwọ sì ti tú wa ká sí àárín àwọn kèfèrí.
12 Ìwọ ta àwọn ènìyàn rẹ fún owó kékeré,
    Ìwọ kò sì jẹ èrè kankan lórí iye tí ìwọ tà wọ́n.

13 Ìwọ sọ wá di ẹni ẹ̀sín ní ọ̀dọ̀ àwọn aládùúgbò wa,
    ẹlẹ́yà àti ẹni àbùkù sí àwọn tí ó yí wa ká.
14 Ìwọ ti sọ wá di ẹni ìfisọ̀rọ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè;
    àwọn ènìyàn ń mi orí wọn sí wa.
15 Ìdójútì mi ń bẹ pẹ̀lú mi ní gbogbo ọjọ́,
    ìtìjú sì bojú mi mọ́lẹ̀,
16 nítorí ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn
    ní ojú àwọn ọ̀tá àti olùgbẹ̀san.

17 Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ń ṣẹlẹ̀ sí wa,
    síbẹ̀ àwa kò gbàgbé rẹ
bẹ́ẹ̀ ni a kò ṣèké sí májẹ̀mú rẹ̀.
18 Ọkàn wa kò padà sẹ́yìn;
    bẹ́ẹ̀ ni ẹsẹ̀ wa kò yẹ̀ kúrò ní ọ̀nà rẹ̀.
19 Ṣùgbọ́n wọ́n kọlù wá,
    ìwọ sì sọ wá di ẹran ọdẹ fún àwọn ẹranko búburú,
tí wọn sì fi òkùnkùn biribiri bò wá mọ́lẹ̀.

20 Bí àwa bá ti gbàgbé orúkọ Ọlọ́run wa
    tàbí tí a na ọwọ́ wa sí ọlọ́run àjèjì.
21 Ǹjẹ́ Ọlọ́run kì yóò rí ìdí rẹ̀,
    níwọ̀n ìgbà tí ó mọ ohun ìkọ̀kọ̀ inú ọkàn?
22 (A)Síbẹ̀, nítorí rẹ̀ àwa da àyà kọ ikú, ní ojoojúmọ́
    a ń kà wá sí bí àgùntàn fún pípa.

23 Jí, Olúwa! Èéṣe tí ìwọ ń sùn?
    Dìde fúnrarẹ̀! Má ṣe kọ̀ wá sílẹ̀ láéláé.
24 Èéṣe tí ìwọ ń pa ojú rẹ mọ́
    tí ìwọ sì gbàgbé ìpọ́njú àti ìnira wa?

25 Nítorí a tẹrí ọkàn wa ba sínú eruku;
    ara wa sì dì mọ́ erùpẹ̀ ilẹ̀.
26 Dìde kí o sì ràn wá lọ́wọ́;
    rà wá padà nítorí ìfẹ́ rẹ tí ó dúró ṣinṣin.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.