Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

M’Cheyne Bible Reading Plan

The classic M'Cheyne plan--read the Old Testament, New Testament, and Psalms or Gospels every day.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
1 Samuẹli 26

Dafidi da ẹ̀mí Saulu sí lẹ́ẹ̀kejì

26 (A)Nígbà náà ni àwọn ará Sifi tọ Saulu wá sí Gibeah, wọn wí pé, “Dafidi kò ha fi ara rẹ̀ pamọ́ níbi òkè Hakila, èyí tí ó wà níwájú Jeṣimoni?”

Saulu sì dìde ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ijù Sifi ẹgbẹ̀ẹ́dógún àṣàyàn ènìyàn ni Israẹli sì pẹ̀lú rẹ̀ láti wá Dafidi ni ijù Sifi. Saulu sì pàgọ́ rẹ̀ ní ibi òkè Hakila tí o wà níwájú Jeṣimoni lójú ọ̀nà, Dafidi sì jókòó ni ibi ijù náà, ó sì rí pé Saulu ń tẹ̀lé òun ni ijù náà. Dafidi sì rán ayọ́lẹ̀wò jáde, ó sì mọ nítòótọ́ pé Saulu ń bọ̀.

Dafidi sì dìde, ó sì wá sí ibi ti Saulu pàgọ́ sí: Dafidi rí ibi tí Saulu gbé dùbúlẹ̀ sí, àti Abneri ọmọ Neri, olórí ogun rẹ̀: Saulu sì dùbúlẹ̀ láàrín àwọn kẹ̀kẹ́, àwọn ènìyàn náà sì pàgọ́ wọn yí i ká.

Dafidi sì dáhùn, ó sì wí fún Ahimeleki, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Hiti, àti fún Abiṣai ọmọ Seruiah ẹ̀gbọ́n Joabu, pé, “Ta ni yóò ba mi sọ̀kalẹ̀ lọ sọ́dọ̀ Saulu ni ibùdó?”

Abiṣai sì wí pé, “Èmi yóò ba ọ sọ̀kalẹ̀ lọ.”

Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi àti Abiṣai sì tọ àwọn ènìyàn náà wá lóru: sì wò ó, Saulu dùbúlẹ̀ ó sì ń sùn láàrín kẹ̀kẹ́, a sì fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ gúnlẹ̀ ni ibi tìmùtìmù rẹ̀: Abneri àti àwọn ènìyàn náà sì dùbúlẹ̀ yí i ká.

Abiṣai sì wí fún Dafidi pé, “Ọlọ́run ti fi ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́ lónìí: ǹjẹ́ èmi bẹ̀ ọ́, sá à jẹ́ kí èmi o fi ọ̀kọ̀ gún un mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kan, èmi kì yóò gun un lẹ́ẹ̀méjì.”

Dafidi sì wí fún Abiṣai pé, “Má ṣe pa á nítorí pé ta ni lè na ọwọ́ rẹ̀ sí ẹni ààmì òróró Olúwa kí ó sì wà láìjẹ̀bi?” 10 Dafidi sì wí pé, “Bí Olúwa tí ń bẹ Olúwa yóò pa á, tàbí ọjọ́ rẹ̀ yóò sì pé tí yóò kú, tàbí òun ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibi ìjà yóò sì ṣègbé níbẹ̀. 11 Olúwa má jẹ́ kí èmi na ọwọ́ mi sí ẹni ààmì òróró Olúwa: ǹjẹ́ èmi bẹ̀ ọ́, mú ọ̀kọ̀ náà tí ń bẹ níbi tìmùtìmù rẹ̀, àti ìgò omi kí a sì máa lọ.”

12 Dafidi sì mú ọ̀kọ̀ náà àti ìgò omi náà kúrò níbi tìmùtìmù Saulu: wọ́n sì bá tiwọn lọ, kò sì sí ẹnìkan tí ó rí i, tàbí tí ó mọ̀: kò sì sí ẹnìkan tí ó jí; gbogbo wọn sì sùn; nítorí pé oorun èjìká láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá ti ṣubú lù wọ́n.

13 Dafidi sì rékọjá sí ìhà kejì, ó sì dúró lórí òkè kan tí ó jìnnà réré; àlàfo kan sì wà láàrín méjì wọn: 14 Dafidi sì kọ sí àwọn ènìyàn náà àti sí Abneri ọmọ Neri wí pé, “Ìwọ kò dáhùn, Abneri?”

Nígbà náà ni Abneri sì dáhùn wí pé, “Ìwọ ta ni ń pe ọba?”

15 Dafidi sì wí fún Abneri pé, “Alágbára ọkùnrin kọ́ ni ìwọ bí? Ta ni ó sì dàbí ìwọ ni Israẹli? Ǹjẹ́ èéṣe tí ìwọ kò tọ́jú ọba Olúwa rẹ? Nítorí ẹnìkan nínú àwọn ènìyàn náà ti wọlé wá láti pa ọba olúwa rẹ. 16 Nǹkan tí ìwọ ṣe yìí kò dára. Bí Olúwa ti ń bẹ, o tọ́ kí ẹ̀yin ó kú, nítorí pé ẹ̀yin kò pa olúwa yín mọ́, ẹni ààmì òróró Olúwa. Ǹjẹ́ sì wo ibi tí ọ̀kọ̀ ọba gbé wà, àti ìgò omi tí ó ti wà níbi tìmùtìmù rẹ̀.”

17 Saulu sì mọ ohùn Dafidi, ó sì wí pé, “Ohùn rẹ ni èyí bí Dafidi ọmọ mi?”

Dafidi sì wí pé, “Ohùn mi ni, olúwa mi, ọba.” 18 Òun sì wí pé, “Nítorí kín ni olúwa mi ṣe ń lépa ìránṣẹ́ rẹ̀? Kín ni èmi ṣe? Tàbí ìwà búburú wo ni ó wà lọ́wọ́ mi. 19 Ǹjẹ́ èmi bẹ̀ ọ́, ọba, olúwa mi, gbọ́ ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ. Bí ó bá ṣe Olúwa bá ti rú ọ sókè sí mi, jẹ́ kí òun o gba ẹbọ; ṣùgbọ́n bí o bá sì ṣe pé ọmọ ènìyàn ni, ìfibú ni kí wọn ó jásí níwájú Olúwa; nítorí tí wọn lé mi jáde lónìí kí èmi má ba à ní ìpín nínú ilẹ̀ ìní Olúwa, wí pé, ‘Lọ sin àwọn ọlọ́run mìíràn.’ 20 Ǹjẹ́ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ mi ó sàn sílẹ̀ níwájú Olúwa; nítorí ọba Israẹli jáde láti wá ẹ̀mí mi bi ẹni ń dọdẹ àparò lórí òkè ńlá.”

21 Saulu sì wí pé, “Èmi ti dẹ́ṣẹ̀: yípadà, Dafidi ọmọ mi: nítorí pé èmi kì yóò wa ibi rẹ mọ́, nítorí tí ẹ̀mí mi sì ti ṣe iyebíye lójú rẹ lónìí: wò ó, èmi ti ń hùwà òmùgọ̀, mo sì ti ṣìnà jọjọ.”

22 Dafidi sì dáhùn, ó sì wí pé, “Wò ó, ọ̀kọ̀ ọba! Kí ó sì jẹ́ kí ọ̀kan nínú àwọn ọmọkùnrin rékọjá wá gbà á. 23 Olúwa o san án fún olúkúlùkù bí òdodo rẹ̀ àti bí òtítọ́ rẹ̀: nítorí pé Olúwa tí fi ọ lé mi lọ́wọ́ lónìí, ṣùgbọ́n èmi kò fẹ́ nawọ́ mi sí ẹni ààmì òróró Olúwa. 24 Sì wò ó, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀mí rẹ ti tóbi lónìí lójú mi, bẹ́ẹ̀ ni ki ẹ̀mí mi ó tóbi lójú Olúwa, kí ó sì gbà mí lọ́wọ́ ibi gbogbo.”

25 Saulu sì wí fún Dafidi pé, “Alábùkún fún ni ìwọ, Dafidi ọmọ mi: nítòótọ́ ìwọ yóò sì ṣe nǹkan ńlá, nítòótọ́ ìwọ yóò sì borí.”

Dafidi sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, Saulu sì yípadà sí ibùgbé rẹ̀.

1 Kọrinti 7

Ìgbéyàwó

Ní báyìí, nítorí àwọn ohun tí ẹ ṣe kọ̀wé: Ó dára fún ọkùnrin kí ó máa ṣe ni ìdàpọ̀ pẹ̀lú obìnrin. Ṣùgbọ́n nítorí àgbèrè pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ kí ọkùnrin kọ̀ọ̀kan gbéyàwó tirẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni kí obìnrin kọ̀ọ̀kan ní ọkọ tirẹ̀. Kí ọkùnrin kí ó fi gbogbo ẹ̀tọ́ ìyàwó rẹ̀ fún ún, kí ìyàwó fi gbogbo ẹ̀tọ́ ọkọ fún ọkọ rẹ̀. Aya kò láṣẹ lórí ara rẹ̀ mọ́, ara rẹ̀ ti di ti ọkọ rẹ̀. Bákan náà ni ọkùnrin tí ó gbéyàwó kò ní àṣẹ lórí ara rẹ̀ mọ́, ara rẹ̀ ti di ti ìyàwó rẹ̀. (A)Nítorí náà, ẹ má ṣe fi àwọn ẹ̀tọ́ tọkọtaya wọ̀nyí dun ara yín, bí kò ṣe nípa ìfìmọ̀ṣọ̀kan, kí ẹ̀yin lè fi ara yín fún àwẹ̀ àti àdúrà, kí ẹ̀yin sì tún jùmọ̀ pàdé, lẹ́yìn ìgbà náà, wọ́n gbọdọ̀ padà sọ́dọ̀ ara wọn kí Satani má ba à dán wọn wò nítorí àìlèmáradúró wọn. Mo sọ èyí fún un yín bí ìmọ̀ràn ní kì í ṣe bí àṣẹ. (B)Ó wù mí kí olúkúlùkù dàbí èmi, ṣùgbọ́n gbogbo ènìyàn kò le jẹ́ bákan náà, Ọlọ́run fún olúkúlùkù ènìyàn ní ẹ̀bùn tirẹ̀, ọ̀kan bí irú èyí àti èkejì bí irú òmíràn.

Nítorí náà, mo wí fún àwọn àpọ́n àti opó pé, ó sàn kí wọ́n kúkú wà gẹ́gẹ́ bí èmi tí wà. (C)Ṣùgbọ́n bí wọ́n kò bá lè mú ara dúró, kí wọ́n gbéyàwó tàbí kí wọ́n fẹ́ ọkọ, nítorí pé ó sàn láti gbéyàwó jù láti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ lọ.

10 Àwọn ti ó ti gbéyàwó àti àwọn tí ó lọ́kọ, ni mo fẹ́ pa á láṣẹ fún kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ mi ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Olúwa: “Obìnrin kò gbọdọ̀ kọ́ fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀.” 11 Ṣùgbọ́n tí ó bá fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀; jẹ́ kí ó wà láìní ọkọ mọ́, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí ó bá ọkọ rẹ̀ làjà, kí ọkọ kí ó má ṣe aya rẹ̀ sílẹ̀.

12 (D)Mo fẹ́ fi àwọn ìmọ̀ràn kan kún ún fún un yín, kì í ṣe àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Olúwa. Bí arákùnrin bá fẹ́ aya tí kò gbàgbọ́, tí aya náà sá á fẹ́ dúró tí ọkọ náà, ọkọ náà tí í ṣe onígbàgbọ́ kò gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀. 13 Tí ó bá sì jẹ́ obìnrin ló fẹ́ ọkọ tí kò gbàgbọ́, ṣùgbọ́n tí ọkọ náà ń fẹ́ kí obìnrin yìí dúró tí òun, aya náà kò gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀. 14 Nítorí pé ó ṣe é ṣe kí a lè mú ọkọ tí kò gba Kristi gbọ́ súnmọ́ Ọlọ́run nípa aya tí í ṣe onígbàgbọ́, a sì le mú ìyàwó tí kò gba Kristi gbọ́ súnmọ́ Ọlọ́run nípa ọkọ tí í ṣe onígbàgbọ́. Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ wọn yóò jẹ́ aláìmọ́. Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá kọ ara wọn sílẹ̀, ó ṣe é ṣe kí àwọn ọmọ wọn di mímọ́.

15 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin tí i ṣe aláìgbàgbọ́ náà bá fẹ́ láti lọ, jẹ́ kí ó máa lọ. Arákùnrin tàbí arábìnrin náà kò sí lábẹ́ ìdè mọ́; Ọlọ́run ti pè wá láti gbé ní àlàáfíà. 16 (E)Báwo ni ẹ̀yin aya ṣe le mọ̀ pé bóyá ẹ̀yin ni yóò gba ọkọ yín là? Bákan náà ni a lè wí nípa ọkọ tí í ṣe onígbàgbọ́ pé, kò sí ìdánilójú pé aya aláìgbàgbọ́ le yípadà láti di onígbàgbọ́ nípa dídúró ti ọkọ.

Ọ̀rọ̀ nípa ipò ti a wa

17 (F)Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí olúkúlùkù máa gbé ìgbé ayé tí Ọlọ́run ń fẹ́ yín fún, àti nínú èyí tí Olúwa pè é sí. Ìlànà àti òfin mi fún gbogbo ìjọ ni èyí. 18 (G)Ǹjẹ́ ọkùnrin kan ha ti kọlà nígbà tí a pè é? Kí ó má sì ṣe di aláìkọlà. Ǹjẹ́ ọkùnrin kan ha ti kọlà nígbà tí a pè é? Kí ó ma ṣe kọlà. 19 (H)Ìkọlà kò jẹ́ nǹkan àti àìkọlà kò jẹ́ nǹkan, bí kò ṣe pípa òfin Ọlọ́run mọ́. 20 Ó yẹ kí ẹnìkọ̀ọ̀kan máa ṣe iṣẹ́ tí ó ń ṣe tẹ́lẹ̀, kí Ọlọ́run tó pé é sínú ìgbàgbọ́ nínú Kristi.

21 Ǹjẹ́ ẹrú ni ọ́ bí nígbà ti a pè ọ́? Má ṣe kà á sí. Ṣùgbọ́n tí ìwọ bá le di òmìnira, kúkú ṣe èyí nì. 22 (I)Tí ó bá jẹ́ ẹrú, ti Olúwa sì pé ọ, rántí pé Kristi ti sọ ọ́ di òmìnira kúrò lọ́wọ́ agbára búburú ti ẹ̀ṣẹ̀. Tí ó bá sì ti pé ọ̀ nítòótọ́ tí ó sì ti di òmìnira, ó ti di ẹrú Kristi. 23 (J)A sì ti rà yín ní iye kan, nítorí náà ẹ má ṣe di ẹrú ènìyàn. 24 Ará, jẹ́ kí olúkúlùkù ènìyàn, nínú èyí tí a pè é, kí ó dúró nínú ọ̀kan náà pẹ̀lú Ọlọ́run.

Ọ̀rọ̀ nípa àwọn àpọ́n

25 Ṣùgbọ́n nípa ti àwọn wúńdíá: èmi kò ní àṣẹ kankan láti ọ̀dọ̀ Olúwa, ṣùgbọ́n mo wí fún yín ní ìdájọ́ bí ẹni tí ó rí àánú Olúwa gbà láti jẹ́ olódodo. 26 Nítorí náà mo rò pé èyí dára nítorí wàhálà ìsinsin yìí, èyí nì ni pé o dára fún ènìyàn kí ó wà bí o ṣe wà. 27 Ǹjẹ́ ó ti ṣe ẹlẹ́rìí láti fẹ́ ìyàwó. Ẹ má ṣe kọ ara yín sílẹ̀, nítorí èyí tí mo wí yìí. Ṣùgbọ́n tí o kò bá sì tí ìgbéyàwó, tàbí fẹ́ ọkọ, má ṣe sáré láti ṣe bẹ́ẹ̀ lákokò yìí. 28 Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá gbé ìyàwó ìwọ kò dẹ́ṣẹ̀, bí a bá gbé wúńdíá ní ìyàwó òun kò dẹ́ṣẹ̀. Ṣùgbọ́n irú àwọn tí ó bá gbé ìyàwó yóò dojúkọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàhálà nípa ti ara: ṣùgbọ́n èmi fẹ́ dá a yín sí.

29 (K)Òun ti mo ń wí ará, ni pé kúkúrú ni àkókò, láti ìsinsin yìí lọ, ẹni tí ó ni aya kí ó dàbí ẹni tí kò ní rí; 30 àwọn tí ń sọkún, bí ẹni pé wọn kò sọkún rí, àti àwọn tí ń yọ̀ bí ẹni pé wọn kò yọ̀ rí, àti àwọn tí ń rà bí ẹni pé wọn kò ní rí, 31 àti àwọn tó ń lo ohun ayé yìí, bí ẹni tí kò ṣe àṣejù nínú wọn: nítorí ìgbà ayé yìí ń kọjá lọ.

32 (L)Nínú gbogbo nǹkan tí ẹ bá ń ṣe ni mo tí fẹ́ kí ẹ sọ ara yín di òmìnira lọ́wọ́ àníyàn. Ọkùnrin tí kò ní ìyàwó le lo àkókò rẹ̀ láti fi ṣiṣẹ́ fún Olúwa, yóò sì má ronú bí ó ti ṣe le tẹ́ Olúwa lọ́rùn. 33 Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí ó bá tí ṣe ìgbéyàwó kò le ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí ó ní láti ronú àwọn nǹkan rẹ̀ nínú ayé yìí àti bí ó ti ṣe le tẹ́ aya rẹ̀ lọ́rùn, 34 dájúdájú, ìfẹ́ rẹ̀ pín sí ọ̀nà méjì. Bákan náà ló rí fún obìnrin tí a gbé ní ìyàwó àti wúńdíá. Obìnrin tí kò bá tí ì délé ọkọ a máa tọ́jú ohun tí ṣe ti Olúwa, kí òun lè jẹ́ mímọ́ ní ara àti ní ẹ̀mí. Ṣùgbọ́n ọmọbìnrin tí a bá ti gbé níyàwó, a máa ṣe ìtọ́jú ohun tí ṣe ti ayé, bí yóò ti ṣe le tẹ́ ọkọ rẹ̀ lọ́rùn. 35 Mo ń sọ èyí fún àǹfààní ara yín kì í ṣe láti dá yín lẹ́kun ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè gbé ní ọ̀nà tí ó tọ́ kí ẹ sì lè máa sin Olúwa láìsí ìyapa ọkàn.

36 Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun kò ṣe ohun tí ó yẹ sí wúńdíá rẹ̀ ti ìpòùngbẹ rẹ si pọ si, bí ó bá sí tọ́ bẹ́ẹ̀, jẹ́ kí ó ṣe bí ó tí fẹ́, òun kò dẹ́ṣẹ̀, jẹ́ kí wọn gbé ìyàwó. 37 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó dúró ṣinṣin ni ọkàn rẹ̀, tí kò ní àìgbọdọ̀ má ṣe, ṣùgbọ́n tí ó ní agbára lórí ìfẹ́ ara rẹ̀, tí ó sì ti pinnu ní ọkàn rẹ̀ pé, òun ó pa wúńdíá ọmọbìnrin òun mọ́, yóò ṣe rere. 38 Bẹ́ẹ̀ sì ní ẹni tí ó fi wúńdíá ọmọbìnrin fún ni ní ìgbéyàwó, ó ṣe rere; ṣùgbọ́n ẹni tí kò fi fún ni ní ìgbéyàwó ṣe rere jùlọ.

39 (M)A fi òfin dé obìnrin níwọ̀n ìgbà tí òun pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ wà láààyè, bí ọkọ rẹ̀ bá kú, ó ní òmìnira láti ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú ọkùnrin mìíràn, tí ó bá wù ú ó sì gbọdọ̀ jẹ́ ti Olúwa. 40 (N)Ṣùgbọ́n nínú èrò tèmi obìnrin náà yóò ní ayọ̀ púpọ̀, tí kò bá ṣe ìgbéyàwó mìíràn mọ́. Mo sì rò pé mo ń fún un yín ní ìmọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Ọlọ́run nígbà tí mo ń sọ nǹkan wọ̀nyí.

Esekiẹli 5

Idà n bọ̀ sórí Jerusalẹmu

“Báyìí, ọmọ ènìyàn, mú ìdá tí ó mú kí o sì fi ṣe abẹ ìfárí onígbàjámọ̀, kí o fi fá irun orí àti irùngbọ̀n rẹ. Fi irun yìí sórí ìwọ̀n kí o sì pín in. Nígbà tí ọjọ́ ìgbóguntì bá parí, sun ìdákan nínú ìdámẹ́ta irun yìí níná láàrín ìlú. Mú ìdákan nínú mẹ́ta kí o fi idà bù ú káàkiri ìlú. Kí o sì tú ìdákan yòókù ká sínú afẹ́fẹ́. Nítorí pé pẹ̀lú idà ni èmi yóò máa lé wọn ká. Ṣùgbọ́n mú díẹ̀ nínú irun yìí kí o sì ta á mọ́ etí aṣọ rẹ. Tún ju díẹ̀ nínú irun yìí sínú iná, kí o sun ún níná. Torí pé láti ibẹ̀ ni iná yóò ti jáde lọ sí gbogbo ilé Israẹli.

“Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Èyí ní Jerusalẹmu, tí mo gbé kalẹ̀ sí àárín àwọn orílẹ̀-èdè, pẹ̀lú àwọn ìlú gbogbo tí o yí i ká. Síbẹ̀ nínú ìwà búburú rẹ ó ti ṣọ̀tẹ̀ si òfin àti ìlànà mi ju àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ilẹ̀ tó yí i ká lọ. Ó ti kọ òfin mi sílẹ̀, o kò sì pa ìlànà mi mọ́.

“Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Nítorí pé ẹ̀yin ti ṣe àìgbọ́ràn ju àwọn orílẹ̀-èdè tó yí yín ká lọ, tí ẹ kò sì tẹ̀lé ìlànà mi tàbí kí o pa òfin mi mọ́. O kò tilẹ̀ túnṣe dáradára tó àwọn orílẹ̀-èdè tó yí ọ ká.

“Nítorí náà báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Èmi gan an lòdì sí ọ, Jerusalẹmu, èmi yóò sì jẹ ọ́ ní yà lójú àwọn orílẹ̀-èdè tó yí ọ ká. Nítorí gbogbo ohun ìríra rẹ, èmi yóò ṣe ohun tí n kò tí ì ṣe rí láàrín rẹ àti èyí tí n kò ní í ṣe irú rẹ̀ mọ́. 10 Nítorí náà láàrín rẹ àwọn baba yóò máa jẹ ọmọ wọn, àwọn ọmọ náà yóò máa jẹ baba wọn. Èmi yóò jẹ ọ́ ní yà, èmi yóò sì tú àwọn tó bá ṣẹ́kù ká sínú ẹ̀fúùfù. 11 Nítorí náà, Olúwa Olódùmarè wí pé, bí mo ṣe wà láààyè, nítorí pé ìwọ ti sọ ibi mímọ́ mi di àìmọ́ pẹ̀lú àwọn àwòrán ẹ̀gbin àti àwọn ohun ìríra rẹ, èmi yóò mú ojúrere mi kúrò lára rẹ, èmi kò ní í da ọ sí, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò wò ọ́ pẹ̀lú àánú mọ́. 12 Ìdámẹ́ta nínú àwọn ènìyàn rẹ yóò kú nípa àjàkálẹ̀-ààrùn tàbí kí ìyàn run wọ́n: ìdámẹ́ta yóò ṣubú nípa idà lẹ́yìn odi rẹ, èmi yóò sì tú ìdámẹ́ta yòókù ká sínú ẹ̀fúùfù, èmi yóò sì máa fi idà lé wọn.

13 “Ìbínú mi yóò sì dúró, bẹ́ẹ̀ ni ìbínú gbígbóná mi yóò sì rọlẹ̀, èmi yóò sì ti gba ẹ̀san mi. Nígbà tí mo bá sì parí ìbínú mi lórí wọn, wọn ó mọ̀ pé Èmi Olúwa ti sọ̀rọ̀ nínú ìtara mi.

14 “Èmi yóò fi ọ́ ṣòfò, èmi yóò sì sọ ọ́ di ẹ̀gàn fún àwọn orílẹ̀-èdè tó yí ọ ká, àti lójú àwọn tó ń kọjá 15 O ó wá di ẹ̀gàn, ẹ̀sín àti ẹ̀kọ̀ àti ohun ẹ̀rù àti ìyanu fún àwọn orílẹ̀-èdè tó yí ọ ká, nígbà tí mo bá fìyà jẹ ọ́ nínú ìbínú àti nínú ìbínú gbígbóná mi. Èmi Olúwa ni ó sọ bẹ́ẹ̀. 16 Nígbà tí èmi ó rán ọfà búburú ìyàn sí wọn, èyí tí yóò jẹ́ fún ìparun wọn. Èmí tí èmi yóò rán run yín. Èmí yóò sì sọ ìyàn di púpọ̀ fún yín. Èmí yóò sì ṣẹ́ ọ̀pá oúnjẹ yín. 17 Èmi yóò rán ìyàn àti ẹranko búburú sí i yín, wọn yóò fi yín sílẹ̀ ni àìlọ́mọ. Àjàkálẹ̀-ààrùn àti ìtàjẹ̀ sílẹ̀ yóò kọjá láàrín yín. Èmi yóò si mú idà wá sórí rẹ. Èmi Olúwa ló sọ bẹ́ẹ̀.”

Saamu 42-43

ÌWÉ KEJÌ

Saamu 42–72

Fún adarí orin. Maskili ti àwọn ọmọ Kora.

42 Bí àgbọ̀nrín ti ń mí hẹlẹ sí ipa odò omi,
    bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mi ń mí hẹlẹ sí ọ Ọlọ́run.
Òùngbẹ Ọlọ́run ń gbẹ ọkàn mi, fún Ọlọ́run alààyè.
    Nígbà wo ni èmi ó lọ bá Ọlọ́run?
Oúnjẹ mi ni omijé mi
    ní ọ̀sán àti ní òru,
    nígbà tí àwọn ènìyàn ń wí fún mi ní gbogbo ọjọ́ pé,
    “Ọlọ́run rẹ dà?”
Nígbà tí mo bá rántí nǹkan yìí,
    èmi tú ọkàn mi jáde nínú mi:
èmi ti bá ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn lọ,
    èmi bá wọn lọ sí ilé Ọlọ́run
pẹ̀lú ohùn ayọ̀ àti ìyìn,
    pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń pa ọjọ́ mímọ́ mọ́.

Èéṣe tí o fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mi?
    Èéṣe tí ara rẹ kò fi lélẹ̀ nínú mi?
Ìwọ ṣe ìrètí ní ti Ọlọ́run,
    nítorí èmi yóò sá à máa yìn ín,
    Olùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi.

Ọlọ́run mi, ọkàn mi ń rẹ̀wẹ̀sì nínú mi:
    nítorí náà, èmi ó rántí rẹ
láti ilẹ̀ Jordani wá,
    láti Hermoni láti òkè Mibsari.
Ibú omi ń pe ibú omi
    nípa híhó omi ṣíṣàn rẹ̀
gbogbo rírú omi àti bíbì omi rẹ̀
    bò mí mọ́lẹ̀.

Ní ọ̀sán ní Olúwa ran ìfẹ́ rẹ̀,
    àti ni àṣálẹ́ ni orin rẹ̀ wà pẹ̀lú mi
àdúrà sí Ọlọ́run ayé mi.

Èmi wí fún Ọlọ́run àpáta mi,
    “Èéṣe tí ìwọ fi gbàgbé mi?
Èéṣe tí èmi o fi máa rìn nínú ìbànújẹ́,
    nítorí ìnilára ọ̀tá?”
10 Bí ẹni pé idà egungun mi ni ẹ̀gàn tí
    àwọn ọ̀tá mi ń gàn mí,
Bí wọn ti ń béèrè ní gbogbo ọjọ́.
    “Níbo ni Ọlọ́run rẹ wà?”

11 Èéṣe tí ìwọ fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mi?
    Èéṣe tí ara rẹ kò fi lélẹ̀ nínú mi?
Fi ìrètí rẹ sínú Ọlọ́run,
    nítorí èmi yóò sì máa yìn ín, Òun ni
    Olùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi.
43 Dá mi láre, Ọlọ́run mi,
    kí o sì gba ọ̀rọ̀ mi rò lọ́dọ̀ àwọn aláìláàánú orílẹ̀-èdè:
yọ mí kúrò lọ́wọ́ ẹlẹ́tàn àti àwọn ènìyàn búburú.
Ìwọ ni Ọlọ́run ibi agbára mi.
    Èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mi sílẹ̀?
Èéṣe tí èmi yóò máa rìn nínú ìbìnújẹ́,
    nítorí ìnilára lọ́dọ̀ àwọn ọ̀tá?
Rán ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́ rẹ jáde,
    jẹ́ kí wọn ó máa dáàbò bò mí;
jẹ́ kí wọn mú mi wá sí òkè mímọ́ rẹ,
    sí ibi tí ìwọ ń gbé.
Nígbà náà ni èmi ó lọ sí ibi pẹpẹ Ọlọ́run,
    sí Ọlọ́run ayọ̀ mi àti ìdùnnú mi,
èmi yóò yìn ọ́ pẹ̀lú dùùrù,
    ìwọ Ọlọ́run, Ọlọ́run mi.

Èéṣe tí o fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mí?
    Èéṣe tí ó fi ń ru sókè nínú mi?
Fi ìrètí rẹ sínú Ọlọ́run,
    nítorí èmi yóò máa yìn ín, Òun ni
    Olùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.