M’Cheyne Bible Reading Plan
A yan Dafidi ní ọba Juda
2 Lẹ́yìn àkókò yìí, Dafidi wádìí lọ́wọ́ Olúwa. Ó sì béèrè pé, “Ṣé èmi lè gòkè lọ sí ọ̀kan lára àwọn ìlú Juda?”
Olúwa sì wí pé, “Gòkè lọ.”
Dafidi sì béèrè pé, “Ní ibo ni kí èmi kí ó lọ?”
Olúwa sì dá a lóhùn pé, “Sí Hebroni.”
2 Nígbà náà ni Dafidi gòkè lọ síbẹ̀ pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ méjì Ahinoamu ará Jesreeli, àti Abigaili obìnrin opó Nabali ti Karmeli. 3 Dafidi sì mú àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, olúkúlùkù pẹ̀lú ìdílé rẹ̀, wọ́n sì ń gbé ní Hebroni àti ìlú rẹ̀ mìíràn. 4 Nígbà náà àwọn ọkùnrin ará Juda wá sí Hebroni, níbẹ̀ ni wọ́n ti fi ààmì òróró yan Dafidi gẹ́gẹ́ bí ọba lórí ilé Juda.
Nígbà tí wọ́n sọ fún Dafidi pé, àwọn ọkùnrin ti Jabesi Gileadi ni ó sin òkú Saulu, 5 Dafidi rán oníṣẹ́ sí àwọn ọkùnrin Jabesi Gileadi láti sọ fún wọn pé, “Olúwa bùkún un yín fún fífi inú rere yín hàn sí Saulu ọ̀gá yín nípa sí sin ín. 6 Kí Olúwa kí ó fi inú rere àti òtítọ́ fún un yín, èmi náà yóò sì san oore yìí fún un yín, nítorí tí ẹ̀yin ti ṣe èyí. 7 Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ mú ara yín le, kí ẹ sì ní ìgboyà, nítorí Saulu ọba yín ti kú, ilé Juda sì ti fi ààmì òróró yàn mí ní ọba lórí wọn.”
Ogun láàrín ilé Dafidi àti Saulu
8 Lákòókò yìí, Abneri ọmọ Neri olórí ogun Saulu ti mú Iṣboṣeti ọmọ Saulu, ó sì mú un kọjá sí Mahanaimu. 9 Ó sì fi jẹ ọba lórí Gileadi Aṣuri àti Jesreeli àti lórí Efraimu àti lórí Benjamini àti lórí gbogbo Israẹli.
10 Iṣboṣeti ọmọ Saulu sì jẹ́ ọmọ ogójì ọdún nígbà tí ó jẹ ọba lórí Israẹli, ó sì jẹ ọba fún ọdún méjì. Ilé Juda sì ń tọ Dafidi lẹ́yìn. 11 Gbogbo àkókò tí Dafidi fi jẹ ọba ní Hebroni lórí ilé Juda sì jẹ́ ọdún méje àti oṣù mẹ́fà.
12 Abneri ọmọ Neri pẹ̀lú àwọn ọkùnrin ti Iṣboṣeti ọmọkùnrin Saulu kúrò ní Mahanaimu, wọ́n sì lọ sí Gibeoni. 13 Joabu ọmọ Seruiah pẹ̀lú àwọn ọkùnrin Dafidi jáde lọ láti lọ bá wọn ní adágún Gibeoni. Ẹgbẹ́ kan sì jókòó ní apá kan adágún, àti ẹgbẹ́ kejì ní apá kejì adágún.
14 Nígbà náà, Abneri sọ fún Joabu pé, “Jẹ́ kí díẹ̀ nínú àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yìí ó dìde láti bá ara wọn jà níwájú wa.”
Joabu sì dáhùn pé, “Ó dára, jẹ́ kí wọ́n ṣe é.”
15 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n dìde sókè, a sì kà wọ́n sí ọkùnrin méjìlá fún Benjamini àti Iṣboṣeti ọmọ Saulu àti méjìlá fún Dafidi. 16 Nígbà náà olúkúlùkù ọkùnrin gbá ẹnìkejì rẹ̀ mú ní orí, ó sì fi idà gún ẹnìkejì rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́, wọ́n sì ṣubú lulẹ̀ papọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ibẹ̀ ni Gibeoni ti à ń pè ni Helikatihu Hasurimu.
17 Ogun náà ní ọjọ́ náà gbóná. Àwọn ọmọkùnrin Dafidi sì ṣẹ́gun Abneri pẹ̀lú àwọn ọkùnrin Israẹli.
18 Àwọn ọmọkùnrin Seruiah mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ni ó wà níbẹ̀: Joabu, Abiṣai àti Asaheli. Nísinsin yìí ẹsẹ̀ Asaheli sì fẹ́rẹ̀ bí ẹsẹ̀ èsúró tí ó wà ní pápá. 19 Asaheli sì ń lépa Abneri, bí òun tí ń lọ kò sì yípadà sí ọ̀tún tàbí sí òsì láti máa tọ́ Abneri lẹ́yìn. 20 Abneri bojú wo ẹ̀yìn rẹ̀, Ó sì béèrè pé, “Ṣé ìwọ Asaheli ni?”
Ó dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni.”
21 Nígbà náà, Abneri sọ fún un pé, “Yípadà sí ọ̀tún tàbí òsì; mú ọ̀kan lára àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin kí o sì bọ́ ìhámọ́ra rẹ.” Ṣùgbọ́n Asaheli kọ̀ láti dẹ́kun lílépa rẹ̀.
22 Abneri tún kìlọ̀ fún Asaheli, “Dẹ́kun lílépa mi! Èéṣe tí èmi yóò fi lù ọ́ bolẹ̀? Báwo ni èmi yóò ti wo arákùnrin rẹ Joabu lójú?”
23 Ṣùgbọ́n ó sí kọ̀ láti padà, Abneri sì fi òdì ọ̀kọ̀ gún un lábẹ́ inú, ọ̀kọ̀ náà sì jáde ní ẹ̀yìn rẹ̀: òun sì ṣubú lulẹ̀ níbẹ̀, ó sì kú ní ibi kan náà; ó sí ṣe gbogbo ènìyàn tí ó dé ibi tí Asaheli gbé ṣubú si, tí ó sì kú, sì dúró jẹ́.
24 Joabu àti Abiṣai sì lépa Abneri: oòrùn sì wọ̀, wọ́n sì dé òkè ti Amima tí o wà níwájú Giah lọ́nà ijù Gibeoni. 25 Àwọn ọmọ Benjamini sì kó ara wọn jọ wọ́n tẹ̀lé Abneri, wọ́n sì wá di ẹgbẹ́ kan, wọ́n sì dúró lórí òkè kan.
26 Abneri sì pe Joabu, ó sì bi í léèrè pé, “Idà yóò máa parun títí láéláé bí? Ǹjẹ́ ìwọ kò ì tí ì mọ̀ pé yóò korò níkẹyìn? Ǹjẹ́ yóò ha ti pẹ́ tó kí ìwọ tó sọ fún àwọn ènìyàn náà, kí wọ́n dẹ́kun láti máa lépa arákùnrin wọn.”
27 Joabu sì wí pé, “Bí Ọlọ́run ti ń bẹ, bí kò ṣe bí ìwọ ti wí, nítòótọ́ ní òwúrọ̀ ni àwọn ènìyàn náà ìbá padà lẹ́yìn arákùnrin wọn.”
28 Joabu sì fọ́n ìpè, gbogbo ènìyàn sì dúró jẹ́ẹ́, wọn kò sì lépa Israẹli mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì tún jà mọ́.
29 Abneri àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì fi gbogbo òru náà rìn ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n sì kọjá Jordani, wọ́n sì rìn ní gbogbo Bitironi, wọ́n sì wá sí Mahanaimu.
30 Joabu sì dẹ́kun àti máa tọ Abneri lẹ́yìn: ó sì kó gbogbo àwọn ènìyàn náà jọ, ènìyàn mọ́kàn-dínlógún ni ó kú pẹ̀lú Asaheli nínú àwọn ìránṣẹ́ Dafidi. 31 Ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ Dafidi sì pa nínú àwọn ènìyàn Benjamini: nínú àwọn ọmọkùnrin Abneri; òjì-dín-nírínwó ènìyàn. 32 Wọ́n si gbé Asaheli wọ́n sì sin ín sínú ibojì baba rẹ̀ tí ó wà ní Bẹtilẹhẹmu. Joabu àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ fi gbogbo òru náà rìn, ilẹ̀ sì mọ́ wọn sí Hebroni.
Ìfẹ́
13 (A)Bí èmi tilẹ̀ lè sọ oríṣìíríṣìí èdè tí ènìyàn àti ti angẹli, tí n kò bá sì ní ìfẹ́, mo kàn ń pariwo bí ago lásán ni tàbí bí i kimbali olóhùn gooro. 2 (B)Bí mo bá ní ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀, tí mo sì ní òye gbogbo ohun ìjìnlẹ̀, àti gbogbo ìmọ̀, bí mo sì ni gbogbo ìgbàgbọ́ tó bẹ́ẹ̀ tí mo lè ṣí àwọn òkè ńlá nídìí, tí èmi kò sì ní ìfẹ́, èmi kò jẹ nǹkan kan. 3 Bí mo bá fi gbogbo nǹkan tí mo ní tọrẹ fún àwọn aláìní, tí mo sì fi ara mi fún ni láti sùn ṣùgbọ́n tí n kò ní ìfẹ́, kò ní èrè kan fún mi.
4 Ìfẹ́ a máa mú sùúrù, ìfẹ́ a máa ṣeun, ìfẹ́ kì í ṣe ìlara, ìfẹ́ kì í fẹ̀, ìfẹ́ kì í sọ̀rọ̀ ìgbéraga. 5 (C)Ìfẹ́ kì í hùwà àìtọ́, kì í wá ohun ara rẹ̀ nìkan. Ìfẹ́ kì í bínú fùfù, ìfẹ́ kì í fi búburú ọmọ ẹnìkejì sínú. 6 Inú ìfẹ́ kì í dùn sí àìṣòótọ́. Ṣùgbọ́n inú rẹ̀ a máa dùn nígbà gbogbo. 7 (D)A máa faradà ohun gbogbo sí òtítọ́, a máa gba ohun gbogbo gbọ́, a máa retí ohun gbogbo, a máa fàyàrán ohun gbogbo.
8 Ìfẹ́ kì í kùnà láé, kì í sì í yẹ̀ ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ ni, wọn yóò dópin, bí ó bá ṣe ẹ̀bùn ahọ́n ni, wọn yóò dákẹ́, bí ó bá ṣe pé ìmọ̀ ni yóò di asán. 9 Nítorí àwa mọ̀ ní apá kan, àwa sì sọtẹ́lẹ̀ ní apá kan. 10 Ṣùgbọ́n nígbà tí èyí ti o pé bá dé, èyí tí í ṣe tí apá kan yóò dópin. 11 Nígbà tí mó wà ni èwe, èmi á máa sọ̀rọ̀ bi èwe, èmi a máa mòye bí èwe, èmi a máa gbèrò bí èwe. Ṣùgbọ́n nígbà tí mó di ọkùnrin tán, mo fi ìwà èwe sílẹ̀. 12 Nítorí pé nísinsin yìí àwa ń ríran bàìbàì nínú dígí; nígbà náà a ó rí í lójúkojú. Nísinsin yìí mò mọ̀ pé ní apá kan; nígbà náà èmi o mọ̀ lẹ́kùnrẹ́rẹ́, kódà bí mo ti dí mí mọ̀ pẹ̀lú.
13 Ǹjẹ́ nísinsin yìí àwọn nǹkan mẹ́ta wọ̀nyí dúró: ìgbàgbọ́, ìrètí, àti ìfẹ́. Ṣùgbọ́n èyí tí o tóbi jù nínú wọn ni ìfẹ́.
Ìdájọ́ lórí àwọn àgbà Israẹli
11 Ẹ̀mí sì gbé mi sókè, ó mú mi lọ sí ẹnu-ọ̀nà ilé Olúwa èyí tó dojúkọ ìlà-oòrùn. Ní àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà yìí ni àwọn ọkùnrin mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n wá, mo rí Jaaṣaniah ọmọ Assuri àti Pelatiah ọmọ Benaiah, tí wọ́n jẹ́ ìjòyè àwọn ènìyàn. 2 Olúwa sì sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, àwọn ọkùnrin yìí ló ń pète ibi, wọ́n sì ń gbé ìmọ̀ràn búburú kalẹ̀ nínú ìlú. 3 Wọ́n ní, ‘Kò ha tí ì tó àsìkò láti kọ́lé? Ìlú yìí ni ìkòkò ìdáná, àwa sì ni ẹran’. 4 Nítorí náà sọtẹ́lẹ̀ nípa wọn; ọmọ ènìyàn, sọtẹ́lẹ̀.”
5 Ẹ̀mí Olúwa sì bà lé mi, ó sì wí pé, “Sọ̀rọ̀!” Báyìí ni Olúwa wí, Ohun tí ẹ ń sọ nìyìí, ilé Israẹli, mo mọ ohun tó wà lọ́kàn yín. 6 Ẹ̀yin ti sọ òkú yín di púpọ̀ nínú ìlú yìí, òkú sì ti kún gbogbo ìgboro rẹ̀.
7 “Torí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí, àwọn òkú tí ẹ fọn sílẹ̀ sí àárín yín ni ẹran, ìlú yìí sì ni ìkòkò ìdáná ṣùgbọ́n èmi yóò le yín jáde níbẹ̀. 8 Ẹ bẹ̀rù idà, èmi yóò sì mú idà wá sórí yín, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa Olódùmarè wí. 9 Èmi yóò lé yín jáde kúrò ní ìlú yìí, èmi yóò sì fà yín lé àjèjì lọ́wọ́, èmi yóò sì mú ìdájọ́ ṣẹ lé yín lórí. 10 Nípa idà ni ẹ̀yin yóò ṣubú, èmi yóò sì ṣe ìdájọ́ yín ní àwọn ààlà ìlú Israẹli. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa. 11 Ìlú yìí kò ní i jẹ́ ìkòkò ìdáná, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin náà kò sì ní jẹ́ ẹran nínú rẹ̀; Èmi yóò ṣe ìdájọ́ yín ní àwọn ààlà ìlú Israẹli. 12 Ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa, nítorí pé ẹ̀yin kò tẹ̀lé àṣẹ mi ẹ̀yin kò sì pa òfin mi mọ́, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti hùwà gẹ́gẹ́ bí àwọn aláìgbàgbọ́ orílẹ̀-èdè tó yí yín ká.”
13 Bí mo ṣe ń sọtẹ́lẹ̀ lọ́wọ́, Pelatiah ọmọ Benaiah kú. Mo sì dojúbolẹ̀, mo sì kígbe sókè pé, “Háà! OlúwaOlódùmarè! Ṣé ìwọ yóò ha pa ìyókù Israẹli run pátápátá ni?”
14 Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé: 15 “Ọmọ ènìyàn, àwọn arákùnrin rẹ, àní àwọn ará rẹ, àwọn ọkùnrin nínú ìbátan rẹ, àti gbogbo ilé Israẹli pátápátá, ni àwọn ará Jerusalẹmu ti wí fún pé, ‘Ẹ jìnnà sí Olúwa, àwa ni a fi ilẹ̀ yìí fún yín ní ìní.’
Ìlérí pé Israẹli yóò padà
16 “Nítorí náà, sọ fún àwọn tó wà ní ìgbèkùn pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti fọ́n wọn káàkiri orílẹ̀-èdè, síbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀, èmi yóò jẹ́ ibi mímọ́ fún wọn níbi tí wọ́n lọ.’
17 “Nítorí náà, wí pé: ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Èmi yóò kó wọn jọ kúrò láàrín àwọn orílẹ̀-èdè tí mo fọ́n wọn ká sí, Èmi yóò sì fún wọn ní ilẹ̀ Israẹli padà.’
18 “Wọn yóò padà síbẹ̀, wọn yóò sì mú gbogbo àwòrán ìríra rẹ̀ àti ìbọ̀rìṣà rẹ̀ kúrò. 19 (A)Èmi yóò fún wọn ní ọ̀kankan; èmi yóò sì fi ẹ̀mí tuntun sínú wọn; Èmi yóò mú ọkàn òkúta kúrò lára wọn, èmi yóò sì fún wọn ní ọkàn tó rọ̀ bí ara ẹran. 20 Kí wọn le tẹ̀lé àṣẹ mi, kí wọn sì le pa òfin mi mọ́. Wọ́n yóò jẹ́ ènìyàn mi, Èmi náà yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn. 21 Ṣùgbọ́n fún àwọn tí wọ́n ń fi gbogbo ọkàn wọn sin àwọn àwòrán ìríra àti àwọn òrìṣà, Èmi yóò mú ẹ̀san ohun tí wọ́n ṣe wá sí orí wọn bẹ́ẹ̀ ni Olúwa Olódùmarè wí.”
22 Àwọn kérúbù sì gbé ìyẹ́ wọn sókè pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn, ògo Ọlọ́run Israẹli sì wà lókè orí wọn. 23 Ògo Olúwa sì gòkè lọ kúrò láàrín ìlú, ó sì dúró lórí òkè tó wà ní ìlà-oòrùn ìlú náà. 24 Lẹ́yìn náà, ẹ̀mí gbé mi sókè, ó sì mú mi wá sí Kaldea lójú ìran, nípa ti ẹ̀mí Ọlọ́run sí ọ̀dọ̀ àwọn ti ìgbèkùn.
Bẹ́ẹ̀ ni ìran tí mo rí lọ kúrò ní ọ̀dọ̀ mi, 25 Mo sì sọ gbogbo ohun tí Olúwa fihàn mí fún àwọn tó wà ní ìgbèkùn.
Saamu ti Asafu
50 Olúwa, Ọlọ́run alágbára
sọ̀rọ̀ kí o sì pe ayé jọ
láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀.
2 Láti Sioni wá, pípé ni ẹwà,
Ọlọ́run tí ń tan ìmọ́lẹ̀
3 Ọlọ́run ń bọ̀,
bẹ́ẹ̀ ni kì yóò dákẹ́,
iná yóò máa jó níwájú rẹ̀,
àti ní àyíká rẹ̀ ni ẹ̀fúùfù líle yóò ti máa jà ká.
4 Yóò sì pe àwọn ọ̀run láti òkè wá jọ àti ayé,
kí o le máa ṣe ìdárò àwọn ènìyàn rẹ̀.
5 “Kó àwọn ènìyàn mímọ́ jọ fún mi
àwọn tí wọn fi ẹbọ dá májẹ̀mú fún mi.”
6 Àwọn ọ̀run yóò sì sọ̀rọ̀ òdodo rẹ̀,
Nítorí Ọlọ́run fúnrarẹ̀ ni onídàájọ́.
7 “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ènìyàn mi, èmi yóò si sọ̀rọ̀, ìwọ Israẹli, èmi yóò jẹ́rìí sí ọ:
èmi ní Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ.
8 Èmi kí yóò bá ọ wí
nítorí àwọn ìrúbọ rẹ,
tàbí ọrẹ ẹbọ sísun rẹ, èyí tí ó wà níwájú mi
ní ìgbà gbogbo.
9 Èmí kò fẹ́ kí ó mú akọ màlúù láti inú ilé tí o kọ́ fún un,
tàbí kí o mú òbúkọ láti
inú agbo ẹran rẹ̀
10 Nítorí gbogbo ẹran igbó ni tèmi
àti ẹran ọ̀sìn lórí ẹgbẹ̀rún òkè.
11 Èmi mọ gbogbo ẹyẹ ní orí àwọn òkè ńlá
àti gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà ní orí ilẹ̀ ni tèmi
12 Bí ebi tilẹ̀ ń pa mí, èmi kì yóò sọ fún ọ,
nítorí ayé ni tèmi àti ohun gbogbo
tí ó wa ní inú rẹ̀.
13 Ǹjẹ́ èmi yóò ha jẹ ẹran akọ màlúù tàbí
mú ẹ̀jẹ̀ òbúkọ?
14 “Rú ẹbọ ọpẹ́ sí Ọlọ́run,
kí o sì san ẹ̀jẹ́ rẹ fún Ọ̀gá-ògo.
15 Kí o sì pè mí ní ọjọ́ ìpọ́njú,
èmi yóò gbà ọ́, ìwọ yóò sì bu ọlá fún mi.”
16 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ fún àwọn, ènìyàn búburú:
“Kí ní ẹ̀tọ́ tí o ní tí ìwọ fi ń tún àwọn ìlànà mi sọ,
tàbí tí ìwọ sì ń sọ májẹ̀mú mi ní ẹnu rẹ?
17 Ìwọ kórìíra àṣẹ mi,
ìwọ sì ṣá ọ̀rọ̀ mí tì sí apá kan.
18 Nígbà tí ìwọ rí olè, ìwọ dára pọ̀ mọ́ ọn,
ìwọ sì da ara rẹ dé àwọn alágbèrè.
19 Ìwọ lo ẹnu rẹ fún aburú,
ìwọ sì ń fi ahọ́n rẹ pète ẹ̀tàn.
20 Ní ìgbà gbogbo ìwọ ń sọ̀rọ̀ sí arákùnrin rẹ,
ìwọ sì ń ba orúkọ ọmọ ìyá rẹ jẹ́.
21 Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ìwọ ti ṣe, mo sì dákẹ́;
ìwọ rò pé mo jẹ́ irú kan náà bí ìrẹ,
ṣùgbọ́n èmi yóò bá ọ wí,
èmi yóò sì fi ẹ̀sùn kàn ọ́ ní ojú ara rẹ.
22 “Ǹjẹ́ ìwọ ro èyí wò, ẹ̀yin tí ó gbàgbé Ọlọ́run.
Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ èmi yóò fa yin ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, láìsí ẹni tí yóò gbà yin sílẹ̀.
23 Ẹni tí ó ba ní ẹbọ ọrẹ-ọpẹ́ bu ọlá fún mi; kí ó sì tún ọ̀nà rẹ̀ ṣe,
kí èmi kí ó le fi ìgbàlà Ọlọ́run hàn án.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.