Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

M’Cheyne Bible Reading Plan

The classic M'Cheyne plan--read the Old Testament, New Testament, and Psalms or Gospels every day.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
2 Samuẹli 6

A gbé àpótí ẹ̀rí wá sí Jerusalẹmu

(A)Dafidi sì tún kó gbogbo àwọn akọni ọkùnrin ní Israẹli jọ, wọ́n sì jẹ́ ẹgbàá-mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Dafidi sì dìde, ó sì lọ àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ń bẹ́ lọ́dọ̀ rẹ́, láti Baalahi ní Juda wá, láti mú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run tí ibẹ̀ wá, èyí tí a ń pe orúkọ rẹ̀ ní orúkọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun tí ó jókòó láàrín àwọn kérúbù. Wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run náà gun kẹ̀kẹ́ tuntun kan, wọ́n sì mú un láti ilé Abinadabu wá, èyí tí ó wà ní Gibeah: Ussa àti Ahio, àwọn ọmọ Abinadabu sì ń dá kẹ̀kẹ́ tuntun náà. Wọ́n sì mú un láti ilé Abinadabu jáde wá, tí ó wà ní Gibeah, pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run: Ahio sì ń rìn níwájú àpótí ẹ̀rí náà. Dafidi àti gbogbo ilé Israẹli sì ṣiré níwájú Olúwa lára gbogbo onírúurú ohun èlò orin tí a fi igi arère ṣe àti lára ìlù haapu, ní ara tambori, sisitirumu àti lára kimbali.

Nígbà tí wọ́n dé sí ilẹ̀ ìpakà Nakoni, Ussa sì na ọwọ́ rẹ̀ sí àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, ó sì dìímú, nítorí tí màlúù kọsẹ̀. Ìbínú Olúwa sì ru sí Ussa; Ọlọ́run sì pa á níbẹ̀ nítorí ìṣísẹ̀ rẹ̀; níbẹ̀ ni ó sì kù ní ẹ̀bá àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run.

Inú Dafidi sì bàjẹ́ nítorí tí Olúwa gé Ussa kúrò: ó sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Pereṣi-Uṣa títí ó fi di òní yìí.

Dafidi sì bẹ̀rù Olúwa ní ọjọ́ náà, ó sì wí pé, “Àpótí ẹ̀rí Olúwa yóò ti ṣe tọ̀ mí wá?” 10 Dafidi kò sì fẹ́ mú àpótí ẹ̀rí Olúwa sọ́dọ̀ rẹ̀ sí ìlú Dafidi; ṣùgbọ́n Dafidi sì mú un yà sí ilé Obedi-Edomu ará Gitti. 11 Àpótí ẹ̀rí Olúwa sì gbé ní ilé Obedi-Edomu ará Gitti ní oṣù mẹ́ta; Olúwa sì bùkún fún Obedi-Edomu, àti gbogbo ilé rẹ̀.

12 (B)A sì rò fún Dafidi ọba pé, “Olúwa ti bùkún fún ilé Obedi-Edomu, àti gbogbo èyí tí í ṣe tirẹ̀, nítorí àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run.” Dafidi sì lọ, ó sì mú àpótí ẹ̀rí náà gòkè láti ilé Obedi-Edomu wá sí ìlú Dafidi pẹ̀lú ayọ̀. 13 Ó sì ṣe nígbà tí àwọn ènìyàn tí ó ru àpótí ẹ̀rí Olúwa bá sì ṣí ẹsẹ̀ mẹ́fà, òun a sì fi màlúù àti ẹran àbọ́pa rú ẹbọ. 14 Dafidi sì fi gbogbo agbára rẹ̀ jó níwájú Olúwa; Dafidi sì wọ efodu ọ̀gbọ̀. 15 Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi àti gbogbo ilé Israẹli sì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa gòkè wá, pẹ̀lú ìhó ayọ̀, àti pẹ̀lú ìró ìpè.

16 Bí àpótí ẹ̀rí Olúwa sì ti wọ ìlú Dafidi wá; Mikali ọmọbìnrin Saulu sì wo láti ojú fèrèsé, ó sì rí Dafidi ọba ń fò sókè ó sì ń jó níwájú Olúwa; òun sì kẹ́gàn rẹ̀ ní ọkàn rẹ̀.

17 Wọ́n sì mú àpótí ẹ̀rí Olúwa náà wá, wọ́n sì gbé e kalẹ̀ sípò rẹ̀ láàrín àgọ́ náà tí Dafidi pa fún un: Dafidi sì rú ẹbọ sísun àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ níwájú Olúwa. 18 Dafidi sì parí ìṣe ẹbọ sísun àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ náà, ó sì súre fún àwọn ènìyàn náà ní orúkọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun. 19 Ó sì pín fún gbogbo àwọn ènìyàn náà, àní fún gbogbo ọ̀pọ̀ ènìyàn Israẹli, àti ọkùnrin àti obìnrin; fún olúkúlùkù ìṣù àkàrà kan àti ekìrí ẹran kan, àti àkàrà díndín kan. Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì túká lọ, olúkúlùkù sí ilé rẹ̀.

Ẹ̀ṣẹ̀ Mikali

20 Dafidi sì yípadà láti súre fún àwọn ará ilé rẹ̀, Mikali ọmọbìnrin Saulu sì jáde láti wá pàdé Dafidi, ó sì wí pé, “Báwo ni ọba Israẹli ṣe ṣe ara rẹ̀ lógo bẹ́ẹ̀ lónìí, tí ó bọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ lónìí lójú àwọn ìránṣẹ́bìnrin àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn lásán tí ń bọ́ra rẹ̀ sílẹ̀.”

21 Dafidi sì wí fún Mikali pé, “Níwájú Olúwa ni, ẹni tí ó yàn mí fẹ́ ju baba rẹ lọ, àti ju gbogbo ìdílé rẹ lọ, láti fi èmi ṣe olórí àwọn ènìyàn Olúwa, àní lórí Israẹli, èmi ó sì súre níwájú Olúwa. 22 Èmi ó sì tún rẹ ara mi sílẹ̀ jú bẹ́ẹ̀ lọ, èmi ó sì ṣe aláìníyìn lójú ara mi, àti lójú àwọn ìránṣẹ́bìnrin náà ti ìwọ wí, lọ́dọ̀ wọn náà ni èmi ó sì ní ògo.”

23 Mikali ọmọbìnrin Saulu kò sì bí ọmọ, títí o fi di ọjọ́ ikú rẹ̀ nítorí tí ó sọ̀rọ̀-òdì yìí sí Dafidi.

1 Kọrinti 16

Ìkójọpọ̀ fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run

16 (A)Ǹjẹ́ ní ti ìdáwó fún àwọn ènìyàn mímọ́, bí mo tí wí fún àwọn ìjọ Galatia, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní kí ẹ ṣe. (B)Ní ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀, kí olúkúlùkù yín fi sínú ìṣúra lọ́dọ̀ ara rẹ̀ ni apá kan, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ṣe rere fún ún, ki ó má ṣe si ìkójọ nígbà tí mo bá dé. (C)Àti nígbà ti mo bá dé, àwọn ẹni tí ẹ bá yàn, àwọn ni èmi ó rán láti mú ẹ̀bùn yín gòkè lọ si Jerusalẹmu. Bí ó bá sì yẹ kí èmí lọ pẹ̀lú, wọn ó sì bá mi lọ.

Ìbéèrè ti ara ẹni

(D)Ṣùgbọ́n èmi yóò tọ̀ yin wá, nígbà tí èmí bá ti kọjá láàrín Makedonia: nítorí èmi yóò kọjá láàrín Makedonia. Bóyá èmi ó sì dúró pẹ̀lú yín, tàbí kí n tilẹ̀ lo àkókò òtútù, ki ẹ̀yin lé sìn mí ni ọ̀nà àjò mí, níbikíbi tí mo bá ń lọ. (E)Nítorí èmi kò fẹ́ kan ri yín kí èmi sì ṣe bẹ́ẹ̀ kọjá lọ; nítorí èmi ń retí àti dúró lọ́dọ̀ yín díẹ̀, bí Olúwa bá fẹ́ (F)Ṣùgbọ́n èmi yóò dúró ni Efesu títí dí Pentikosti. (G)Nítorí pé ìlẹ̀kùn ńlá láti ṣe iṣẹ́ gidi ṣí sílẹ̀ fún mí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ni àwọn ọ̀tá tí ń bẹ.

10 (H)Ǹjẹ́ bí Timotiu bá dé, ẹ jẹ́ kí ó wà lọ́dọ̀ yín láìbẹ̀rù: nítorí òun ń ṣé iṣẹ́ Olúwa, bí èmi pẹ̀lú ti ń ṣe. 11 Nítorí náà kí ẹnikẹ́ni má ṣe kẹ́gàn rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹ sín ín jáde lọ́nà àjò ni àlàáfíà, kí òun lè tọ̀ mí wá; nítorí tí èmí ń fi ojú sí ọ̀nà fún wíwá rẹ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin.

12 (I)Ṣùgbọ́n ní ti Apollo arákùnrin wa, mo bẹ̀ ẹ́ púpọ̀ láti tọ̀ yín wá pẹ̀lú àwọn arákùnrin: Ṣùgbọ́n kì í ṣe ìfẹ́ rẹ̀ rárá láti wà nísinsin yìí, ṣùgbọ́n òun yóò wá nígbà tí ààyè bá ṣí sílẹ̀ fún un.

13 (J)Ẹ máa ṣọ́ra, ẹ dúró ṣinṣin nínú ìgbàgbọ́, ẹ ṣe bi ọkùnrin tí ó ní ìgboyà, ẹ jẹ́ alágbára. 14 Ẹ máa ṣe ohun gbogbo nínú ìfẹ́.

15 Ǹjẹ́ mo bẹ̀ yín ará, ẹ ṣá mọ ilé Stefana pé, àwọn ni ẹni àkọ́kọ́ tó gba Jesu ní Akaia, àti pé, wọn sì tí fi ará wọn fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ àwọn ènìyàn mímọ́. 16 Kí ẹ̀yin tẹríba fún irú àwọn báwọ̀nyí, àti fún olúkúlùkù olùbáṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú wa tí ó sì ń ṣe làálàá. 17 Mo láyọ̀ fún wíwá Stefana àti Fortunatu àti Akaiku: nítorí èyí tí ó kù nípá tí yín wọ́n ti fi kún un. 18 Nítorí tí wọ́n tu ẹ̀mí mí lára àti tiyín: nítorí náà, ẹ máa gba irú àwọn ti ó rí bẹ́ẹ̀.

Ìkíni ìkẹyìn

19 (K)Àwọn ìjọ ni Asia kí í yín.

Akuila àti Priskilla kí í yín púpọ̀ nínú Olúwa, pẹ̀lú ìjọ tí ó wà ni ilé wọn.

20 (L)Gbogbo àwọn arákùnrin kí í yín.

Ẹ fi ìfẹnukonu mímọ́ kí ara yín.

21 (M)Ìkíni ti èmi Paulu, láti ọwọ́ èmi tìkára mi wá.

22 (N)Bí ẹnikẹ́ni kò bá ní ìfẹ́ Jesu Kristi Olúwa, jẹ́ kí ó dì ẹni ìfibú. Máa bọ Olúwa wa!

23 (O)Oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa kí ó wà pẹ̀lú yín!

24 Ìfẹ́ mi wá pẹ̀lú gbogbo yín nínú Kristi Jesu. Àmín.

Esekiẹli 14

Àwọn abọ̀rìṣà gba ìdálẹ́bi

14 Díẹ̀ nínú àwọn àgbàgbà Israẹli wá sọ́dọ̀ mi, wọ́n sì jókòó níwájú mi, Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá: “Ọmọ ènìyàn, àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ti gbé òrìṣà kalẹ̀ sínú ọkàn wọn, wọ́n sì gbé àwọn ohun tó lè mú wọn ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ síwájú wọn; Èmi yóò ha jẹ́ kí wọ́n béèrè lọ́wọ́ mi rárá bí? Nítorí náà, sọ fún wọn pé: ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Bí ẹnikẹ́ni ní ilé Israẹli tó gbé òrìṣà sí ọkàn rẹ̀, tó tún gbé ohun ìkọ̀sẹ̀ síwájú rẹ̀, tí ó sì wá sọ́dọ̀ wòlíì; Èmi Olúwa fúnra mi ni yóò dá ẹni tí ó wa lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà ìbọ̀rìṣà rẹ. Èmi yóò ṣe èyí láti gba ọkàn àwọn ará Israẹli tó ti tẹ̀lé òrìṣà wọn lọ padà sí ọ̀dọ̀ mi.’

“Nítorí náà sọ fún ilé Israẹli, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Ẹ ronúpìwàdà! Ẹ yípadà kúrò lọ́dọ̀ òrìṣà yín, kí ẹ̀yin sì kọ gbogbo ìwà ìríra yín sílẹ̀!

“ ‘Bí ẹnikẹ́ni ní ilé Israẹli tàbí àlejò tó ń gbé ní ilẹ̀ Israẹli, bá ya ara rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi, tó gbé òrìṣà rẹ̀ sí ọkàn rẹ̀, tó tún gbé ohun tó mú ni ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ síwájú rẹ, lẹ́yìn èyí tó tún lọ sọ́dọ̀ wòlíì láti béèrè nǹkan lọ́wọ́ mi! Èmi Olúwa fúnra ara mi ní èmi yóò dá a lóhùn. Èmi yóò lòdì si irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀ lọ́nà òdì, Èmi yóò sì fi i ṣe ààmì àti òwe. Èmi yóò sì gé e kúrò láàrín àwọn ènìyàn mi. Nígbà náà, ẹ̀yin yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.

“ ‘Bí wọ́n bá sì tan wòlíì náà láti sọtẹ́lẹ̀, Èmi Olúwa ló tan wòlíì náà, Èmi yóò nawọ́ sí i, èmi yóò sì pa á run kúrò láàrín àwọn ènìyàn mi Israẹli. 10 Wọn yóò ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ wọn—ìjìyà kan náà là ó fún wòlíì àti ẹni tó lọ béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀. 11 Kí ilé Israẹli má ba à ṣáko kúrò lọ́dọ̀ mi mọ, kí wọ́n má ba à fi gbogbo ìrékọjá ba ara wọn jẹ́ mọ́. Ṣùgbọ́n kí wọ́n le jẹ́ ènìyàn mi, kí Èmi náà sì le jẹ́ Ọlọ́run wọn, ni Olúwa Olódùmarè wí.’ ”

Àwọn aláìṣòdodo gba ìdájọ́

12 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: 13 “Ọmọ ènìyàn bí orílẹ̀-èdè kan bá dẹ́ṣẹ̀ sí mi nípa ìwà àìṣòdodo, èmi yóò nawọ́ mi jáde sí wọn, láti gé ìpèsè oúnjẹ wọn, èmi yóò rán ìyàn sí wọn, èmi yóò sì pa ènìyàn àti ẹranko inú rẹ̀, 14 bí àwọn ọkùnrin mẹ́ta yìí—Noa, Daniẹli àti Jobu tilẹ̀ wà nínú rẹ, kìkì ẹ̀mí ara wọn nìkan ni wọ́n lé fi òdodo wọn gbàlà, Olúwa Olódùmarè wí.

15 “Tàbí bí mo bá jẹ́ kí ẹranko búburú gba orílẹ̀-èdè náà kọjá, tí wọn sì bà á jẹ́ tó bẹ́ẹ̀ tí ó di ahoro, tí kò sí ẹni tó le gba ibẹ̀ kọjá torí ẹranko búburú yìí, 16 bí àwọn ọkùnrin mẹ́ta wọ̀nyí tilẹ̀ wà nínú rẹ̀, Olúwa Olódùmarè wí pé, wọn kì yóò gba ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin là: àwọn nìkan ni a ó gbàlà, ṣùgbọ́n ilẹ̀ náà yóò di ahoro.

17 “Tàbí tí mo bá mú idà kọjá láàrín orílẹ̀-èdè náà tí mo wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí idà kọjá láàrín ilẹ̀ náà,’ tí mo sì tú ìbínú gbígbóná lé wọn lórí nípa ìtàjẹ̀ sílẹ̀, tí mo pa ènìyàn àti ẹranko inú rẹ. 18 Bí àwọn ọkùnrin mẹ́ta yìí tilẹ̀ wà nínú rẹ̀, Olúwa Olódùmarè wí pé, Bí mo ti wà, wọn ki yóò gba ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin là, ṣùgbọ́n àwọn tìkára wọn nìkan ni a ó gbàlà.

19 “Tàbí bí mo rán àjàkálẹ̀-ààrùn si ilẹ̀ náà, ti mo si da ìrunú mi lé e lórí pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀, láti gé ènìyàn àti ẹranko kúrò nínú rẹ̀, 20 bó tilẹ̀ jẹ́ pé Noa, Daniẹli àti Jobu wà nínú rẹ, bí mo ti wà láààyè ni Olúwa Olódùmarè wí, wọn kò le gba ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin wọn lá. Ara wọn nìkan ni ìwà òdodo wọn lè gbàlà.

21 “Nítorí báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Báwo ni yóò ti burú tó nígbà tí mo bá rán ìdájọ́ kíkan mi mẹ́rin sórí Jerusalẹmu, èyí ni idà àti ìyàn, ẹranko búburú àti àjàkálẹ̀-ààrùn láti pa àwọn ènìyàn àti ẹranko inú rẹ̀! 22 Síbẹ̀, yóò ṣẹ́kù àwọn díẹ̀, àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin tí a ó kó jáde nínú rẹ̀. Wọn yóò wá bá yin, ẹ̀yin yóò rí ìwà àti ìṣe wọn, nígbà náà ni ẹ̀yin yóò rí ìtùnú nípa àjálù tí mo mú wá sórí Jerusalẹmu—àní gbogbo àjálù ní mo ti mú wá sórí rẹ̀. 23 Nígbà tí ẹ̀yin bá rí ìwà àti ìṣe wọn, a ó tù yín nínú, nítorí pé ẹ̀yin yóò mọ̀ pé èmi kò ṣe nǹkan kan láìnídìí, ni Olúwa Olódùmarè wí.”

Saamu 55

Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Maskili ti Dafidi.

55 Fi etí sí àdúrà mi, Ọlọ́run,
    Má ṣe fi ojú pa ẹ̀bẹ̀ mi rẹ́:
    Gbọ́ mi kí o sì dá mi lóhùn.
Èrò mi ń dà mí láàmú, èmi sì ń pariwo.
    Sí ohùn àwọn ọ̀tá ni,
    nítorí igbe àwọn ènìyàn búburú;
nítorí wọ́n mú ìjìyà wá sórí mi,
    wọ́n sì kẹ́gàn mi nínú ìbínú wọn.

Ọkàn mi wà nínú ìrora pẹ̀lú;
    ẹ̀rù ikú kọjú ìjà sí mi.
Ìbẹ̀rù àti ìwárìrì wa sí ara mi;
    ìbẹ̀rù ti bò mí mọ́lẹ̀.
Èmi sọ pé, “Èmi ìbá ní ìyẹ́ bí àdàbà!
    Èmi ìbá fò lọ kí n sì sinmi.
Èmi ìbá sálọ, jìnnà réré,
    kí ń sì dúró sí aginjù;
Èmi ìbá yára lọ́ si ibùgbé mi ní ibi ààbò,
    jìnnà kúrò nínú ìjì àti ẹ̀fúùfù líle.”

Da àwọn ẹni búburú láàmú, Olúwa, da ahọ́n wọn rú,
    nítorí èmi rí ìwà agbára àti ìjà ní ìlú náà.
10 Ọ̀sán àti òru ni wọ́n fi ń rìn gbogbo odi kiri;
    ìwà ìkà àti èébú wà láàrín rẹ̀.
11 Ìwà búburú ń bẹ ní àárín rẹ̀;
    ẹ̀tàn àti èké kò kúrò ní ìgboro rẹ̀.

12 Tí ọ̀tá bá tàbùkù mi,
    èmi yóò fi ara mọ́ ọn;
tí ọ̀tá bá gbé ara rẹ̀ ga sí mi,
    èmi ìbá sápamọ́ fún un.
13 Ṣùgbọ́n tí ó bá ṣe ìwọ, ọkùnrin bí ẹgbẹ́ mi,
    ẹlẹgbẹ́ mi, àti ọ̀rẹ́ tí ó súnmọ́ mi,
14 pẹ̀lú ẹni tí èmi ti jẹ ìgbádùn adùn ìdàpọ̀,
    bí a ṣe ń rìn pẹ̀lú àwùjọ ní ilé Ọlọ́run.

15 Kí ikú kí ó dé bá wọn,
    Kí wọn ó lọ láààyè sí isà òkú,
Jẹ́ kí wọn ó sọ̀kalẹ̀ sí ibojì pẹ̀lú ìpayà,
    nítorí tí ìwà búburú ń bẹ ní ibùjókòó wọn, àti nínú wọn.

16 Ṣùgbọ́n èmi pe Ọlọ́run;
    Olúwa yóò sì gbà mí.
17 Ní alẹ́, ní òwúrọ̀ àti ní ọ̀sán
    èmi sọkún jáde nínú ìpọ́njú,
    o sì gbọ́ ohùn mi.
18 Ó rà mí padà láìléwu
    kúrò nínú ogun tí ó dìde sí mi,
    nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó dìde sí mi.
19 Ọlọ́run yóò gbọ́, yóò sì pọ́n wọn lójú
    àní, ẹni tí ó ti jókòó láti ìgbàanì—Sela.
Nítorí tí wọn kò ní àyípadà,
    tí wọn kò sì bẹ̀rù Ọlọ́run.

20 Ọ̀rẹ́ mi yìí ti dalẹ̀ èmi ọ̀rẹ́ rẹ̀;
    ó ti ba májẹ̀mú rẹ̀ jẹ́.
21 Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ kúnná ju òrí-àmọ́,
    ṣùgbọ́n ogun wà ni àyà rẹ̀;
ọ̀rọ̀ rẹ̀ fẹ́lẹ́ ju òróró lọ,
    ṣùgbọ́n idà fífàyọ ní wọn.

22 (A)Gbé ẹrù rẹ lọ sí ọ̀dọ̀ Olúwa
    yóò sì mú ọ dúró;
òun kò ní jẹ́ kí olódodo ṣubú.
23 Ṣùgbọ́n ìwọ, Ọlọ́run, ni yóò mu àwọn ọ̀tá mi
    wá sí ihò ìparun;
Àwọn ẹni tí òǹgbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ àti ẹni ẹ̀tàn,
    kì yóò gbé ààbọ̀ ọjọ́ wọn.

Ṣùgbọ́n fún èmi, èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.