Read the Gospels in 40 Days
Jesu kọ́ Nikodemu
3 (A)Ọkùnrin kan sì wà nínú àwọn Farisi, tí a ń pè ní Nikodemu, ìjòyè kan láàrín àwọn Júù: 2 (B)Òun náà ní ó tọ Jesu wá ní òru, ó sì wí fún un pé, Rabbi, àwa mọ̀ pé olùkọ́ni láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ni ìwọ ń ṣe: nítorí pé kò sí ẹni tí ó lè ṣe iṣẹ́ ààmì wọ̀nyí tí ìwọ ń ṣe, bí kò ṣe pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀.
3 (C)Jesu dáhùn ó sì wí fún un pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, bí kò ṣe pé a tún ènìyàn bí, òun kò lè rí ìjọba Ọlọ́run.”
4 Nikodemu wí fún un pé, a ó ti ṣe lè tún ènìyàn bí nígbà tí ó di àgbàlagbà tan? Ó ha lè wọ inú ìyá rẹ̀ lọ nígbà kejì, kí a sì bí i?
5 (D)Jesu dáhùn wí pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, bí kò ṣe pé a fi omi àti Ẹ̀mí bí ènìyàn, òun kò lè wọ ìjọba Ọlọ́run. 6 (E)Èyí tí a bí nípa ti ara, ti ara ni; èyí tí a sì bí nípa ti Ẹ̀mí, ti Ẹ̀mí ni. 7 Kí ẹnu kí ó má ṣe yà ọ́, nítorí mo wí fún ọ pé, ‘A kò lè ṣe aláìtún yín bí.’ 8 (F)Afẹ́fẹ́ ń fẹ́ sí ibi tí ó gbé wù ú, ìwọ sì ń gbọ́ ìró rẹ̀, ṣùgbọ́n ìwọ kò mọ ibi tí ó gbé ti wá, àti ibi tí ó gbé ń lọ: gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ẹni tí a bí nípa ti Ẹ̀mí.”
9 Nikodemu dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Nǹkan wọ̀nyí yóò ti ṣe lè rí bẹ́ẹ̀?”
10 Jesu dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Ṣé olùkọ́ni ní Israẹli ni ìwọ ń ṣe, o kò sì mọ nǹkan wọ̀nyí? 11 (G)Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, Àwa ń sọ èyí tí àwa mọ̀, a sì ń jẹ́rìí èyí tí àwa ti rí; ẹ̀yin kò sì gba ẹ̀rí wa. 12 Bí mo bá sọ ohun ti ayé yìí fún yín, tí ẹ̀yin kò sì gbàgbọ́, ẹ̀yin ó ti ṣe gbàgbọ́ bí mo bá sọ ohun ti ọ̀run fún yín? 13 (H)Kò sì ṣí ẹni tí ó gòkè re ọ̀run bí kò ṣe ẹni tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, Ọmọ Ènìyàn tí ń bẹ ní ọ̀run. 14 (I)Bí Mose sì ti gbé ejò sókè ní aginjù, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni a kò le ṣe aláìgbé Ọmọ Ènìyàn sókè pẹ̀lú: 15 Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́, kí ó má bà á ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó le ní ìyè àìnípẹ̀kun.”
16 (J)“Nítorí Ọlọ́run fẹ́ aráyé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, tí ó fi ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo fún ni, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́, má bà á ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. 17 (K)Nítorí Ọlọ́run kò rán ọmọ rẹ̀ sí ayé láti dá aráyé lẹ́jọ́; ṣùgbọ́n kí a le ti ipasẹ̀ rẹ̀ gba aráyé là. 18 Ẹni tí ó bá gbà á gbọ́, a kò ní dá a lẹ́jọ́; ṣùgbọ́n a ti dá ẹni tí kò gbà á gbọ́ lẹ́jọ́ ná, nítorí tí kò gba orúkọ ọmọ kan ṣoṣo ti Ọlọ́run gbọ́. 19 (L)Èyí ni ìdájọ́ náà pé, ìmọ́lẹ̀ wá sí ayé, àwọn ènìyàn sì fẹ́ òkùnkùn ju ìmọ́lẹ̀ lọ, nítorí tí iṣẹ́ wọn burú. 20 Nítorí olúkúlùkù ẹni tí ó bá hùwà búburú ní ìkórìíra ìmọ́lẹ̀, kì í sì í wá sí ìmọ́lẹ̀, kí a má ṣe bá iṣẹ́ rẹ̀ wí. 21 (M)Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń sọ òtítọ́ ní í wá sí ìmọ́lẹ̀, kí iṣẹ́ rẹ̀ kí ó lè fi ara hàn pé a ṣe wọ́n nípa ti Ọlọ́run.”
Ẹ̀rí Johanu nípa Jesu
22 (N)Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jesu pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá sí ilẹ̀ Judea; ó sì dúró pẹ̀lú wọn níbẹ̀ ó sì ń ṣe ìtẹ̀bọmi fún ni. 23 Johanu pẹ̀lú sì ń ṣe ìtẹ̀bọmi ní Aenoni, ní agbègbè Salimu, nítorí tí omi púpọ̀ wà níbẹ̀: wọ́n sì ń wá, a sì ń tẹ̀ ẹ́ wọn bọ omi. 24 (O)Nítorí tí a kò tí ì sọ Johanu sínú túbú. 25 Nígbà náà ni iyàn kan wà láàrín àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu àti Júù kan nípa ti ìwẹ̀nù. 26 (P)Wọ́n sì tọ Johanu wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Rabbi, ẹni tí ó ti wà pẹ̀lú rẹ lókè odò Jordani, tí ìwọ ti jẹ́rìí rẹ̀, wò ó, òun tẹ àwọn ènìyàn bọ omi, gbogbo ènìyàn sì ń tọ̀ ọ́ wá.”
27 (Q)Johanu dáhùn ó sì wí pé, “Ènìyàn kò le rí nǹkan kan gbà, bí kò ṣe pé a bá ti fi fún ún láti ọ̀run wá. 28 (R)Ẹ̀yin fúnrayín jẹ́rìí mi pé mo wí pé, ‘Èmi kì í ṣe Kristi náà, ṣùgbọ́n pé a rán mi síwájú rẹ̀.’ 29 (S)Ẹni tí ó bá ni ìyàwó ni ọkọ ìyàwó; ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó tí ó dúró tí ó sì ń gbóhùn rẹ̀, ó ń yọ̀ gidigidi nítorí ohùn ọkọ ìyàwó; nítorí náà ayọ̀ mi yí di kíkún. 30 Òun kò lè ṣàì máa pọ̀ sí i, ṣùgbọ́n èmi kò lè ṣàìmá rẹlẹ̀.
31 (T)“Ẹni tí ó ti òkè wá ju gbogbo ènìyàn lọ; ẹni tí ó ti ayé wá ti ayé ni, a sì máa sọ ohun ti ayé. Ẹni tí ó ti ọ̀run wá ju gbogbo ènìyàn lọ. 32 (U)Ohun tí ó ti rí tí ó sì ti gbọ́ èyí náà sì ni òun ń jẹ́rìí rẹ̀; kò sì sí ẹni tí ó gba ẹ̀rí rẹ̀. 33 Ẹni tí ó gba ẹ̀rí rẹ̀ fi èdìdì dì í pé, olóòtítọ́ ni Ọlọ́run. 34 Nítorí ẹni tí Ọlọ́run ti rán ń sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: nítorí tí Ọlọ́run fi Ẹ̀mí fún un láìsí gbèdéke. 35 Baba fẹ́ Ọmọ, ó sì ti fi ohun gbogbo lé e lọ́wọ́ 36 (V)Ẹni tí ó bá gba Ọmọ gbọ́, ó ní ìyè àìnípẹ̀kun: ẹni tí kò bá sì gba Ọmọ gbọ́, kì yóò rí ìyè; nítorí ìbínú Ọlọ́run ń bẹ lórí rẹ̀.”
Jesu sọ̀rọ̀ pẹ̀lú obìnrin ara Samaria
4 (W)Àwọn Farisi sì gbọ́ pé, Jesu ni, ó sì ń ṣe ìtẹ̀bọmi fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn púpọ̀ ju Johanu lọ, 2 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jesu tìkára rẹ̀ kò ṣe ìtẹ̀bọmi bí kò ṣe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, 3 Ó fi Judea sílẹ̀, ó sì tún lọ sí Galili.
4 (X)Òun sì ní láti kọjá láàrín Samaria. 5 (Y)Nígbà náà ni ó dé ìlú Samaria kan, tí a ń pè ní Sikari, tí ó súnmọ́ etí ilẹ̀ oko tí Jakọbu ti fi fún Josẹfu, ọmọ rẹ̀. 6 Kànga Jakọbu sì wà níbẹ̀. Nítorí pé ó rẹ Jesu nítorí ìrìn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó jókòó létí kànga: ó sì jẹ́ ìwọ̀n wákàtí kẹfà ọjọ́.
7 Obìnrin kan, ará Samaria sì wá láti fà omi: Jesu wí fún un pé ṣe ìwọ yóò fún mi ni omi mu. 8 Nítorí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti lọ sí ìlú láti lọ ra oúnjẹ.
9 (Z)Obìnrin ará Samaria náà sọ fún un pé, “Júù ni ìwọ, obìnrin ará Samaria ni èmi. Èétirí tí ìwọ ń béèrè ohun mímu lọ́wọ́ mi?” (Nítorí tí àwọn Júù kì í bá àwọn ará Samaria ṣe pọ̀.)
10 (AA)Jesu dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Ìbá ṣe pé ìwọ mọ ẹ̀bùn Ọlọ́run, àti ẹni tí ó wí fún ọ pé, Fún mi ni omi mu, ìwọ ìbá sì ti béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, òun ìbá ti fi omi ìyè fún ọ.”
11 Obìnrin náà wí fún un pé, “Alàgbà, ìwọ kò ní igbá-ìfami tí ìwọ ó fi fà omi, bẹ́ẹ̀ ni kànga náà jì: Níbo ni ìwọ ó ti rí omi ìyè náà? 12 Ìwọ pọ̀ ju Jakọbu baba wa lọ bí, ẹni tí ó fún wa ní kànga náà, tí òun tìkára rẹ̀ si mu nínú rẹ̀, àti àwọn ọmọ rẹ̀, àti àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ̀?”
13 Jesu dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá mu nínú omi yìí, òǹgbẹ yóò sì tún gbẹ ẹ́: 14 (AB)Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá mu nínú omi tí èmi ó fi fún un, òǹgbẹ kì yóò gbẹ ẹ́ mọ́ láé; ṣùgbọ́n omi tí èmi ó fi fún un yóò di kànga omi nínú rẹ̀, tí yóò máa sun si ìyè àìnípẹ̀kun.”
15 (AC)Obìnrin náà sì wí fún u pé, “Alàgbà, fún mi ní omi yìí, kí òǹgbẹ kí ó má ṣe gbẹ mí, kí èmi kí ó má sì wá fa omi níbí mọ́.”
16 Jesu wí fún un pé, “Lọ pe ọkọ rẹ, kí ó sì padà wá sí ìhín yìí.”
17 Obìnrin náà dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Èmi kò ní ọkọ.”
Jesu wí fún un pé, “Ìwọ́ dáhùn dáradára pé, èmi kò ní ọkọ: 18 (AD)Nítorí tí ìwọ ti ní ọkọ márùn-ún rí; ọkùnrin tí ìwọ sì ní báyìí kì í ṣe ọkọ rẹ. Ohun tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán yìí, òtítọ́ ni.”
19 Obìnrin náà wí fún un pé, “Alàgbà, mo wòye pé, wòlíì ni ìwọ ń ṣe. 20 (AE)Àwọn baba wa sìn lórí òkè yìí; ẹ̀yin sì wí pé, Jerusalẹmu ni ibi tí ó yẹ tí à bá ti máa sìn.”
21 (AF)Jesu wí fún un pé, “Gbà mí gbọ́ obìnrin yìí, àkókò náà ń bọ̀, nígbà tí kì yóò ṣe lórí òkè yìí tàbí ní Jerusalẹmu ni ẹ̀yin ó máa sin Baba. 22 (AG)Ẹ̀yin ń sin ohun tí ẹ̀yin kò mọ̀: àwa ń sin ohun tí àwa mọ̀: nítorí ìgbàlà ti ọ̀dọ̀ àwọn Júù wá. 23 Ṣùgbọ́n àkókò ń bọ̀, ó sì dé tán nísinsin yìí, nígbà tí àwọn olùsìn tòótọ́ yóò máa sin Baba ní Ẹ̀mí àti ní òtítọ́: nítorí irú wọn ni Baba ń wá kí ó máa sin òun. 24 (AH)Ẹ̀mí ni Ọlọ́run: àwọn ẹni tí ń sìn ín kò lè ṣe aláìsìn ín ní Ẹ̀mí àti ní òtítọ́.”
25 Obìnrin náà wí fún un pé, mo mọ̀ pé, “Messia ń bọ̀ wá, tí a ń pè ní Kristi: Nígbà tí Òun bá dé, yóò sọ ohun gbogbo fún wa.”
26 (AI)Jesu sọ ọ́ di mí mọ̀ fún un pé, “Èmi ẹni tí ń bá ọ sọ̀rọ̀ yìí ni Òun.”
Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pẹ̀lú Jesu
27 Lákokò yí ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ dé, ẹnu sì yà wọ́n pé ó ń bá obìnrin sọ̀rọ̀: ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó wí pé, “Kí ni ìwọ ń wá?” tàbí “Èéṣe tí ìwọ fi ń bá a sọ̀rọ̀?”
28 Nígbà náà ni obìnrin náà fi ládugbó rẹ̀ sílẹ̀, ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n lọ sí ìlú, ó sì wí fún àwọn ènìyàn pé, 29 (AJ)“Ẹ wá wò ọkùnrin kan, ẹni tí ó sọ ohun gbogbo tí mo ti ṣe rí fún mi: èyí ha lè jẹ́ Kristi náà?” 30 Nígbà náà ni wọ́n ti ìlú jáde, wọ́n sì tọ̀ ọ́ wá.
31 Láàrín èyí, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń rọ̀ ọ́ wí pé, “Rabbi, jẹun.”
32 (AK)Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, “Èmi ní oúnjẹ láti jẹ, tí ẹ̀yin kò mọ̀.”
33 Nítorí náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń bi ara wọn lérè wí pé, “Ẹnìkan mú oúnjẹ fún un wá láti jẹ bí?”
34 (AL)Jesu wí fún wọn pé, “Oúnjẹ mi ni láti ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi, àti láti parí iṣẹ́ rẹ̀. 35 (AM)Ẹ̀yin kò ha wí pé, ‘Ó ku oṣù mẹ́rin, ìkórè yóò sì dé?’ Wò ó, mo wí fún un yín, Ẹ ṣí ojú yín sókè, kí ẹ sì wo oko; nítorí tí wọn ti pọ́n fún ìkórè. 36 Kódà báyìí, ẹni tí ó ń kórè ń gba owó ọ̀yà rẹ̀, ó si ń kó èso jọ sí ìyè àìnípẹ̀kun: kí ẹni tí ó ń fúnrúgbìn àti ẹni tí ń kórè lè jọ máa yọ̀ pọ̀. 37 (AN)Nítorí nínú èyí ni ọ̀rọ̀ náà fi jẹ́ òtítọ́: Ẹnìkan ni ó fúnrúgbìn, ẹlòmíràn ni ó sì ń kórè jọ. 38 Mo rán yín lọ kórè ohun tí ẹ kò ṣiṣẹ́ fún. Àwọn ẹlòmíràn ti ṣiṣẹ́, ẹ̀yin sì kórè èrè làálàá wọn.”
Ọ̀pọ̀ ara Samaria gbàgbọ́
39 Ọ̀pọ̀ àwọn ará Samaria láti ìlú náà wá sì gbà á gbọ́ nítorí ìjẹ́rìí obìnrin náà pé, “Ó sọ gbogbo ohun tí mo ti ṣe fún mi.” 40 Nítorí náà, nígbà tí àwọn ará Samaria wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n rọ̀ ọ́ pé, kí ó wà pẹ̀lú wọn: ó sì dúró fún ọjọ́ méjì. 41 Àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì gbàgbọ́ sí i nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀.
42 (AO)Wọ́n sì wí fún obìnrin náà pé, “Kì í ṣe nítorí ọ̀rọ̀ rẹ nìkan ni àwa ṣe gbàgbọ́: nítorí tí àwa tìkára wa ti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, àwa sì mọ̀ pé, nítòótọ́ èyí ni Kristi náà, Olùgbàlà aráyé.”
Jesu wo ọmọkùnrin ọlọ́lá san
43 Lẹ́yìn ọjọ́ méjì ó sì ti ibẹ̀ kúrò, ó lọ sí Galili. 44 (AP)Nítorí Jesu tìkára rẹ̀ ti jẹ́rìí wí pé, Wòlíì kì í ní ọlá ní ilẹ̀ òun tìkára rẹ̀. 45 Nítorí náà nígbà tí ó dé Galili, àwọn ará Galili gbà á, nítorí ti wọ́n ti rí ohun gbogbo tí ó ṣe ní Jerusalẹmu nígbà àjọ ìrékọjá; nítorí àwọn tìkára wọn lọ sí àjọ pẹ̀lú.
46 (AQ)Bẹ́ẹ̀ ni Jesu tún wá sí Kana ti Galili, níbi tí ó gbé sọ omi di wáìnì. Ọkùnrin ọlọ́lá kan sì wá, ẹni tí ara ọmọ rẹ̀ kò dá ní Kapernaumu. 47 Nígbà tí ó gbọ́ pé Jesu ti Judea wá sí Galili, ó tọ̀ ọ́ wá, ó sì ń bẹ̀ ẹ́, kí ó lè sọ̀kalẹ̀ wá kí ó mú ọmọ òun láradá: nítorí tí ó wà ní ojú ikú.
48 (AR)Nígbà náà ni Jesu wí fún un pé, “Bí kò ṣe pé ẹ̀yin bá rí ààmì àti iṣẹ́ ìyanu, ẹ̀yin kì yóò gbàgbọ́ láé.”
49 Ọkùnrin ọlọ́lá náà wí fún un pé, “Olúwa, sọ̀kalẹ̀ wá kí ọmọ mi tó kú.”
50 Jesu wí fún un pé, “Máa bá ọ̀nà rẹ lọ; ọmọ rẹ yóò yè.”
Ọkùnrin náà sì gba ọ̀rọ̀ Jesu gbọ́, ó sì kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. 51 Bí ó sì ti ń sọ̀kalẹ̀ lọ, àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pàdé rẹ̀, wọ́n sì wí fún un pé, ọmọ rẹ ti yè. 52 Nígbà náà ni ó béèrè wákàtí tí ara rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í yá lọ́wọ́ wọn, wọ́n sì wí fún un pé, “Ní àná, ní wákàtí keje ni ibà náà fi í sílẹ̀.”
53 (AS)Bẹ́ẹ̀ ni baba náà mọ̀ pé ní wákàtí kan náà ni, nínú èyí tí Jesu wí fún un pé “Ọmọ rẹ̀ yè.” Òun tìkára rẹ̀ sì gbàgbọ́, àti gbogbo ilé rẹ̀.
54 (AT)Èyí ni iṣẹ́ ààmì kejì tí Jesu ṣe nígbà tí ó ti Judea jáde wá sí Galili.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.