Read the Gospels in 40 Days
Jesu rán àádọ́rin ọmọ-ẹ̀yìn jáde
10 (A)Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Olúwa sì yan àádọ́rin ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn pẹ̀lú, ó sì rán wọn ní méjì méjì lọ ṣáájú rẹ̀, sí gbogbo ìlú àti ibi tí òun tìkára rẹ̀ yóò sì dé. 2 (B)Ó sì wí fún wọn pé, “Ìkórè pọ̀, ṣùgbọ́n àwọn alágbàṣe kò tó nǹkan, nítorí náà ẹ bẹ Olúwa ìkórè, kí ó lè rán àwọn alágbàṣe sínú ìkórè rẹ̀. 3 (C)Ẹ mú ọ̀nà yín pọ̀n: sá wò ó, èmi rán yín lọ bí ọ̀dọ́-àgùntàn sáàrín ìkookò. 4 Ẹ má ṣe mú àpò, ẹ má ṣe mú àpamọ́wọ́, tàbí bàtà: ẹ má sì ṣe kí ẹnikẹ́ni lọ́nà.
5 (D)“Ní ilékílé tí ẹ̀yin bá wọ̀, kí ẹ kọ́ wí pé, ‘Àlàáfíà fún ilé yìí!’ 6 Bí ọmọ àlàáfíà bá sì wà níbẹ̀, àlàáfíà yín yóò bà lé e: ṣùgbọ́n bí kò bá sí, yóò tún padà sọ́dọ̀ yín. 7 (E)Ẹ dúró sínú ilé náà, kí ẹ máa jẹ, kí ẹ sì máa mu ohunkóhun tí wọ́n bá fi fún yín; nítorí ọ̀yà alágbàṣe tọ́ sí i, Ẹ má ṣe lọ láti ilé dé ilé.
8 “Ìlúkílùú tí ẹ̀yin bá wọ̀, tí wọ́n bá sì gbà yín, ẹ jẹ ohunkóhun tí a bá gbé ka iwájú yín: 9 Ẹ sì mú àwọn aláìsàn tí ń bẹ nínú rẹ̀ láradá, kí ẹ sì wí fún wọn pé, ‘Ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀ sí yín!’ 10 Ṣùgbọ́n ní ìlúkílùú tí ẹ̀yin bá sì wọ̀, tí wọn kò bá sì gbà yín, nígbà tí ẹ̀yin bá sì jáde ní ìgboro ìlú náà, kí ẹ̀yin sì wí pé, 11 (F)‘Eruku ìlú yín tí ó kù sí wa lẹ́sẹ̀, a gbọ̀n ọ́n sílẹ̀ fún yín! Ṣùgbọ́n ẹ mọ èyí pé, ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀.’ 12 (G)Ṣùgbọ́n mo wí fún yín, yóò sàn fún Sodomu ní ọjọ́ náà, ju fún ìlú náà lọ.
13 (H)“Ègbé ni fún ìwọ, Koraṣini! Ègbé ni fún ìwọ Betisaida! Nítorí ìbá ṣe pé a ti ṣe iṣẹ́ agbára tí a ṣe nínú yín, ní Tire àti Sidoni, wọn ìbá ti ronúpìwàdà lọ́jọ́ pípẹ́ sẹ́yìn, wọn ìbá sì jókòó nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti nínú eérú. 14 Ṣùgbọ́n yóò sàn fún Tire àti Sidoni nígbà ìdájọ́ jù fún yín lọ. 15 Àti ìwọ, Kapernaumu, a ó ha gbé ọ ga dé òkè ọ̀run? A ó rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ dé isà òkú.
16 (I)“Ẹni tí ó bá gbọ́ tiyín, ó gbọ́ tèmi. Ẹni tí ó bá sì kọ̀ yín, ó kọ̀ mi. Ẹni tí ó bá sì kọ̀ mi, ó kọ ẹni tí ó rán mi.”
17 Àwọn àádọ́rin náà sì fi ayọ̀ padà, wí pé, “Olúwa, àwọn ẹ̀mí èṣù tilẹ̀ foríbalẹ̀ fún wa ní orúkọ rẹ.”
18 (J)Ó sì wí fún wọn pé, “Èmí rí Satani ṣubú bí mọ̀nàmọ́ná láti ọ̀run wá. 19 Kíyèsi i, èmí fún yín ní àṣẹ láti tẹ ejò àti àkéekèe mọ́lẹ̀, àti lórí gbogbo agbára ọ̀tá: kò sì ṣí ohun kan bí ó ti wù tí ó ṣe, tí yóò pa yín lára. 20 (K)Ṣùgbọ́n kí ẹ má ṣe yọ̀ nítorí èyí pé, àwọn ẹ̀mí ń foríbalẹ̀ fún yín; ṣùgbọ́n ẹ kúkú yọ̀, pé; a kọ̀wé orúkọ yín ní ọ̀run!”
21 (L)(M) Ní wákàtí kan náà Jesu yọ̀ nínú Ẹ̀mí mímọ́ ó sì wí pé, “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Baba, Olúwa ọ̀run àti ayé, pé, ìwọ pa nǹkan wọ̀nyí mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n àti amòye, ìwọ sì fi wọ́n hàn fún àwọn ọmọ ọwọ́: bẹ́ẹ̀ ni, Baba, bẹ́ẹ̀ ni ó sá à yẹ ní ojú rẹ.
22 (N)“Ohun gbogbo ni a ti fi fún mi láti ọ̀dọ̀ Baba mi; kò sì ṣí ẹni tí ó mọ ẹni tí ọmọ jẹ́, bí kò ṣe Baba; àti ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wu ọmọ láti fi í hàn fún.”
23 (O)Ó sì yípadà sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ní apá kan. Ó ní, “Ìbùkún ni fún ojú tí ń rí ohun tí ẹ̀yin ń rí. 24 Nítorí mo wí fún yín, ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì àti àwọn ọba ni ó ń fẹ́ láti rí ohun tí ẹ̀yin ń rí, wọn kò sì rí wọn, àti láti gbọ́ ohun tí ẹ̀yin ń gbọ́, wọn kò sì gbọ́ wọn.”
Òwe aláàánú ará Samaria
25 (P)(Q) Sì kíyèsi i amòfin kan dìde, ó ń dán an wò, ó ní, “Olùkọ́, kín ni èmi ó ṣe kí èmi lè jogún ìyè àìnípẹ̀kun?”
26 Ó sì bi í pé, “Kí ni a kọ sínú ìwé òfin? Báwo ni ìwọ sì ti kà á?”
27 (R)Ó sì dáhùn wí pé, “ ‘Kí ìwọ fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo agbára rẹ, àti gbogbo inú rẹ fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ’; àti, ‘ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ.’ ”
28 (S)Ó sì wí fún un pé, “Ìwọ́ dáhùn rere. Ṣe èyí, ìwọ ó sì yè.”
29 Ṣùgbọ́n ó ń fẹ́ láti da ara rẹ̀ láre, ó wí fún Jesu wí pé, “Ta ha sì ni ẹnìkejì mi?”
30 Jesu sì dáhùn ó wí pé, “Ọkùnrin kan ń ti Jerusalẹmu sọ̀kalẹ̀ lọ sí Jeriko, ó sì bọ́ sí ọwọ́ àwọn ọlọ́ṣà; wọ́n gbà á ní aṣọ, wọ́n sá a lọ́gbẹ́, wọ́n sì fi sílẹ̀ lọ ní àìpatán. 31 Ní kòńgẹ́ àkókò yìí ni àlùfáà kan sì ń sọ̀kalẹ̀ lọ lọ́nà náà. Nígbà tí ó sì rí i ó kọjá lọ níhà kejì. 32 Bẹ́ẹ̀ náà sì ni ọmọ Lefi kan pẹ̀lú, nígbà tí ó dé ibẹ̀, tí ó sì rí i, ó kọjá lọ níhà kejì. 33 (T)Ṣùgbọ́n ará Samaria kan, bí ó ti ń re àjò, ó dé ibi tí ó gbé wà; nígbà tí ó sì rí i, àánú ṣe é. 34 Ó sì tọ̀ ọ́ lọ, ó sì di ọgbẹ́ rẹ̀, ó da òróró àti ọtí wáìnì sí i, ó sì gbé e lé orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ti òun tìkára rẹ̀, ó sì mú un wá sí ilé èrò, a sì ń ṣe ìtọ́jú rẹ̀. 35 Nígbà tí ó sì lọ ní ọjọ́ kejì, ó fi owó idẹ méjì fún olórí ilé èrò ó sì wí fún un pé, ‘Máa tọ́jú rẹ̀; ohunkóhun tí ìwọ bá sì ná kún un, nígbà tí mo bá padà dé, èmi ó san án fún ọ.’
36 “Nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí, ta ni ìwọ rò pé ó jẹ́ ẹnìkejì ẹni tí ó bọ́ sí ọwọ́ àwọn ọlọ́ṣà?”
37 Ó sì dáhùn wí pé, “Ẹni tí ó ṣàánú fún un ni.”
Jesu sì wí fún un pé, “Lọ, kí o ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́!”
Ní ilé Marta àti Maria
38 (U)Ó sì ṣe, bí wọ́n ti ń lọ, o wọ ìletò kan, obìnrin kan tí a ń pè ní Marta sì gbà á sí ilé rẹ̀. 39 Ó sì ní arábìnrin kan tí a ń pè ní Maria tí ó sì jókòó lẹ́bàá ẹsẹ̀ Olúwa, tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. 40 Ṣùgbọ́n Marta ń ṣe ìyọnu ohun púpọ̀, ó sì tọ̀ ọ́ wá, ó wí pé, “Olúwa, ìwọ kò sì bìkítà sí ti arábìnrin mi pé ó fi mí sílẹ̀ láti máa nìkan ṣe ìránṣẹ́? Wí fún un kí ó ràn mí lọ́wọ́.”
41 (V)Ṣùgbọ́n Olúwa sì dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Marta, Marta, ìwọ ń ṣe àníyàn àti làálàá nítorí ohun púpọ̀. 42 Ṣùgbọ́n ohun kan ni a kò lè ṣe aláìní, Maria sì ti yan ipa rere náà tí a kò lè gbà lọ́wọ́ rẹ̀.”
Jesu ń kọ́ ẹ̀kọ́ nípa àdúrà
11 (W)Bí ó ti ń gbàdúrà ní ibi kan, bí ó ti dákẹ́, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Olúwa, kọ́ wa bí a ti ń gbàdúrà, bí Johanu ti kọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.”
2 (X)Ó sì wí fún wọn pé, “Nígbà tí ẹ̀yin bá ń gbàdúrà, ẹ máa wí pé:
“ ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run,
kí á bọ̀wọ̀ fún orúkọ yín.
Kí ìjọba yín dé, ìfẹ́ tiyín ni kí a ṣe,
bí i ti ọrun, bẹ́ẹ̀ ni ní ayé.
3 Fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lójoojúmọ́.
4 (Y)Kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá;
nítorí àwa tìkára wa pẹ̀lú a máa dáríjì olúkúlùkù ẹni tí ó jẹ wá ní gbèsè,
Má sì fà wá sínú ìdánwò, ṣùgbọ́n gbà wá lọ́wọ́ ẹni búburú ni.’ ”
5 (Z)Ó sì wí fún wọn pé, “Ta ni nínú yín tí yóò ní ọ̀rẹ́ kan, tí yóò sì tọ̀ ọ́ lọ láàrín ọ̀gànjọ́, tí yóò sì wí fún un pé, ‘Ọ̀rẹ́, yá mi ní ìṣù àkàrà mẹ́ta. 6 Nítorí ọ̀rẹ́ mi kan ti àjò dé sọ́dọ̀ mi, èmi kò sì ní nǹkan tí èmi ó gbé kalẹ̀ níwájú rẹ̀.’ 7 Tí òun ó sì gbé inú ilé dáhùn wí fún un pé, ‘Má yọ mí lẹ́nu: a ti sé ìlẹ̀kùn, àwọn ọmọ mi si ń bẹ lórí ẹní pẹ̀lú mi: èmi kò lè dìde fi fún ọ!’ 8 Mo wí fún yín, bí òun kò tilẹ̀ ti fẹ́ dìde kí ó fi fún un nítorí tí í ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n nítorí àwíìyánnu rẹ̀, yóò dìde, yóò sì fún un tó bí ó ti ń fẹ́.
9 (AA)(AB) “Èmí sì wí fún yín, ẹ béèrè, a ó sì fi fún un yín; ẹ wá kiri, ẹ̀yin ó sì rí; ẹ kànkùn, a ó sì ṣí i sílẹ̀ fún yín. 10 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá béèrè, ó rí gbà; ẹni tí ó sì ń wá kiri, ó rí; àti ẹni tí ó kànkùn ni a ó ṣí i sílẹ̀ fún.
11 “Ta ni baba nínú yín tí ọmọ rẹ̀ yóò béèrè àkàrà lọ́dọ̀ rẹ̀, tí yóò fún un ní òkúta? Tàbí bí ó béèrè ẹja, tí yóò fún un ní ejò? 12 Tàbí bí ó sì béèrè ẹ̀yin, tí yóò fún un ní àkéekèe? 13 Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin tí ó jẹ́ ènìyàn búburú bá mọ bí a ti í fi ẹ̀bùn dáradára fún àwọn ọmọ yín: mélòó mélòó ha ni Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ fún àwọn tí ó béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀!”
Jesu àti Beelsebulu
14 (AC)(AD) Ó sì ń lé ẹ̀mí èṣù kan jáde, tí ó sì yadi. Nígbà tí ẹ̀mí èṣù náà jáde, odi sọ̀rọ̀; ẹnu sì ya ìjọ ènìyàn. 15 Ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn nínú wọn wí pé, “Nípa Beelsebulu olórí àwọn ẹ̀mí èṣù ni ó fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.” 16 (AE)Àwọn ẹlòmíràn sì ń dán an wò, wọ́n ń fẹ́ ààmì lọ́dọ̀ rẹ̀ láti ọ̀run wá.
17 Ṣùgbọ́n òun mọ èrò inú wọn, ó wí fún wọn pé, “Gbogbo ìjọba tí ó ya ara rẹ̀ ní ipá, ni a ń sọ di ahoro; ilé tí ó sì ya ara rẹ̀ nípá yóò wó. 18 Bí Satani ba yapa sí ara rẹ̀, ìjọba rẹ̀ yóò ha ṣe dúró? Nítorí ẹ̀yin wí pé, nípa Beelsebulu ni èmi fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. 19 Bí ó ba ṣe pé nípa Beelsebulu ni èmi fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, nípa ta ni àwọn ọmọ yín fi ń lé wọn jáde, nítorí náà àwọn ni yóò ṣe onídàájọ́ yín. 20 Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe pé nípa ìka ọwọ́ Ọlọ́run ni èmi fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, ǹjẹ́ ìjọba Ọlọ́run dé bá yín tán.
21 “Nígbà tí alágbára ọkùnrin tí ó ni ìhámọ́ra bá ń ṣọ́ ààfin rẹ̀, ẹrù rẹ̀ yóò wà ní àlàáfíà. 22 Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹni tí ó ní agbára jù ú bá kọlù ú, tí ó sì ṣẹ́gun rẹ̀ a gba gbogbo ìhámọ́ra rẹ̀ tí ó gbẹ́kẹ̀lé lọ́wọ́ rẹ̀, a sì pín ìkógun rẹ̀.
23 (AF)“Ẹni tí kò bá wà pẹ̀lú mi, ó lòdì sí mi: ẹni tí kò bá sì bá mi kójọpọ̀, ó fọ́nká.
24 (AG)“Nígbà tí ẹ̀mí àìmọ́ bá jáde kúrò lára ènìyàn, a máa rìn kiri ní ibi gbígbẹ, a máa wá ibi ìsinmi; nígbà tí kò bá sì rí, a wí pé, ‘Èmi yóò padà lọ sí ilé mi ní ibi tí mo gbé ti jáde wá.’ 25 Nígbà tí ó bá sì dé, tí ó sì rí tí a gbá a, tí a sì ṣe é ní ọ̀ṣọ́. 26 Nígbà náà ni yóò lọ, yóò sì mú ẹ̀mí méje mìíràn tí ó burú ju òun tìkára rẹ̀ lọ wá: wọn yóò wọlé, wọn yóò sì máa gbé níbẹ̀: ìgbẹ̀yìn ọkùnrin náà yóò sì burú ju ìṣáájú rẹ̀ lọ.”
27 (AH)Bí ó ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí, obìnrin kan gbóhùn rẹ̀ sókè nínú ìjọ, ó sì wí fún un pé, “Ìbùkún ni fún inú tí ó bí ọ, àti ọmú tí ìwọ mu!”
28 Ṣùgbọ́n òun wí pé, nítòótọ́, kí ó kúkú wí pé, “Ìbùkún ni fún àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì pa á mọ́!”
Ààmì ti Jona
29 (AI)(AJ) Nígbà tí ìjọ ènìyàn sì ṣùjọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí wí pé, “Ìran búburú ni èyí: wọ́n ń wá ààmì; a kì yóò sì fi ààmì kan fún un bí kò ṣe ààmì Jona wòlíì! 30 Nítorí bí Jona ti jẹ́ ààmì fún àwọn ará Ninefe, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni Ọmọ ènìyàn yóò ṣe jẹ́ ààmì fún ìran yìí. 31 (AK)Ọbabìnrin gúúsù yóò dìde ní ọjọ́ ìdájọ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn ìran yìí, yóò sì dá wọn lẹ́bi: nítorí tí ó ti ìhà ìpẹ̀kun ayé wá láti gbọ́ ọgbọ́n Solomoni: sì kíyèsi i, ẹni tí ó pọ̀jù Solomoni lọ ń bẹ níhìn-ín yìí. 32 (AL)Àwọn ará Ninefe yóò dìde ní ọjọ́ ìdájọ́ pẹ̀lú ìran yìí, wọn ó sì dá a lẹ́bi: nítorí tí wọn ronúpìwàdà nípa ìwàásù Jona; sì kíyèsi i, ẹni tí ó pọ̀jù Jona lọ ń bẹ níhìn-ín yìí.
Òwe nípa fìtílà tí a tàn
33 (AM)“Kò sí ẹnìkan, nígbà tí ó bá tan fìtílà tan, tí gbé e sí ìkọ̀kọ̀, tàbí sábẹ́ òṣùwọ̀n, bí kò ṣe sórí ọ̀pá fìtílà, kí àwọn tí ń wọlé ba à lè máa rí ìmọ́lẹ̀. 34 (AN)Ojú ni fìtílà ara: bí ojú rẹ bá mọ́lẹ̀ kedere, gbogbo ara rẹ a mọ́lẹ̀; ṣùgbọ́n bí ojú rẹ bá ṣókùnkùn, ara rẹ pẹ̀lú a kún fún òkùnkùn. 35 Nítorí náà kíyèsi i, kí ìmọ́lẹ̀ tí ń bẹ nínú rẹ má ṣe di òkùnkùn. 36 Ǹjẹ́ bí gbogbo ara rẹ bá kún fún ìmọ́lẹ̀, tí kò ní apá kan tí ó ṣókùnkùn, gbogbo rẹ̀ ni yóò ní ìmọ́lẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí fìtílà bá fi ìtànṣán rẹ̀ fún ọ ní ìmọ́lẹ̀.”
Ègún mẹ́fà
37 (AO)Bí ó sì ti ń wí, Farisi kan bẹ̀ ẹ́ kí ó bá òun jẹun: ó sì wọlé, ó jókòó láti jẹun. 38 (AP)Nígbà tí Farisi náà sì rí i, ẹnu yà á nítorí tí kò kọ́kọ́ wẹ ọwọ́ kí ó tó jẹun.
39 (AQ)(AR) Olúwa sì wí fún un pé, “Ẹ̀yin Farisi a máa ń fọ òde ago àti àwopọ̀kọ́: ṣùgbọ́n, inú yín kún fún ìwà búburú àti ìrẹ́jẹ. 40 Ẹ̀yin aṣiwèrè, ẹni tí ó ṣe èyí tí ń bẹ lóde, òun kò ha ṣe èyí tí ń bẹ nínú pẹ̀lú? 41 (AS)Nípa ohun ti inú yin, ki ẹ̀yin kúkú máa ṣe ìtọrẹ àánú nínú ohun tí ẹ̀yin ní, sì kíyèsi i, ohun gbogbo ni ó di mímọ́ fún yín.
42 (AT)“Ṣùgbọ́n ègbé ni fún yín, ẹ̀yin Farisi, nítorí tí ẹ̀yin a máa san ìdámẹ́wàá minti àti irúgbìn, àti gbogbo ewébẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kọ ìdájọ́ àti ìfẹ́ Ọlọ́run: wọ̀nyí jẹ́ ohun tí ẹ gbọdọ̀ ṣe, láìsí fi àwọn ìyókù sílẹ̀ láìṣe.
43 (AU)“Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin Farisi, àgàbàgebè! Nítorí tí ẹ̀yin fẹ́ ipò ọlá nínú Sinagọgu, àti ìkíni ní ọjà.
44 (AV)“Ègbé ni fún un yín, (ẹ̀yin akọ̀wé àti ẹ̀yin Farisi àgàbàgebè) nítorí ẹ̀yin dàbí ibojì tí kò farahàn, tí àwọn ènìyàn sì ń rìn lórí rẹ̀ láìmọ̀.”
45 Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn amòfin dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Olùkọ́, nínú èyí tí ìwọ ń wí yìí ìwọ ń gan àwa pẹ̀lú.”
46 (AW)Ó sì wí pé, “Ègbé ni fún ẹ̀yin amòfin pẹ̀lú, nítorí tí ẹ̀yin di ẹrù tí ó wúwo láti rù lé ènìyàn lórí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin tìkára yín kò jẹ́ fi ìka yín kan ẹrù náà.
47 (AX)“Ègbé ni fún yín, nítorí tí ẹ̀yin kọ́ ibojì àwọn wòlíì, tí àwọn baba yín pa. 48 Ǹjẹ́ ẹ̀yin jẹ́ ẹlẹ́rìí, ẹ sì ní inú dídùn sí iṣẹ́ àwọn baba yín, nítorí tí wọn pa wọ́n, ẹ̀yin sì kọ́ ibojì wọn. 49 (AY)(AZ)Nítorí èyí ni ọgbọ́n Ọlọ́run sì ṣe wí pé, ‘Èmi ni ó rán àwọn wòlíì àti àwọn aposteli sí wọn, wọn ó sì ṣe inúnibíni sí wọn.’ 50 Kí a lè béèrè ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì gbogbo, tí a ti ta sílẹ̀ láti ìgbà ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé wá, lọ́wọ́ ìran yìí; 51 (BA)láti ẹ̀jẹ̀ Abeli wá, títí ó sì fi dé ẹ̀jẹ̀ Sekariah, tí ó ṣègbé láàrín pẹpẹ àti tẹmpili: lóòótọ́ ni mo wí fún yín ìran yìí ni yóò ru gbogbo ẹ̀bi àwọn nǹkan wọ̀nyí.
52 (BB)“Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin amòfin, nítorí tí ẹ̀yin ti mú kọ́kọ́rọ́ ìmọ̀ kúrò; ẹ̀yin tìkára yín kò wọlé, àwọn tí sì ń wọlé, ni ẹ̀yin ń dí lọ́wọ́.”
53 Bí ó ti ń lọ kúrò níbẹ̀, àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisi bẹ̀rẹ̀ sí bi í lọ́rọ̀ gidigidi, wọ́n sì ń yọ ọ́ lẹ́nu láti wí nǹkan púpọ̀. 54 Wọ́n ń ṣọ́ ọ, wọ́n ń wá ọ̀nà láti rí nǹkan gbámú lẹ́nu kí wọn bá à lè fi ẹ̀sùn kàn án.
Àwọn ìkìlọ̀ àti ọ̀rọ̀ ìyànjú
12 (BC)Ó sì ṣe, nígbà tí àìníye ìjọ ènìyàn péjọpọ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí wọn ń tẹ ara wọn mọ́lẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sísọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ máa ṣọ́ra yín nítorí ìwúkàrà àwọn Farisi tí í ṣe àgàbàgebè. 2 (BD)Kò sí ohun tí a bò, tí a kì yóò sì fihàn; tàbí tí ó pamọ́, tí a kì yóò mọ̀. 3 Nítorí náà ohunkóhun tí ẹ̀yin sọ ní òkùnkùn, ní gbangba ni a ó ti gbọ́ ọ; àti ohun tí ẹ̀yin bá sọ sí etí ní iyàrá, lórí òrùlé ni a ó ti kéde rẹ̀.
4 (BE)(BF) “Èmi sì wí fún yín ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn tí ó ń pa ara ènìyàn kú, lẹ́yìn èyí, wọn kò sì ní èyí tí wọ́n lè ṣe mọ́. 5 (BG)Ṣùgbọ́n èmi ó sì sọ ẹni tí ẹ̀yin ó bẹ̀rù fún yín: Ẹ bẹ̀rù ẹni tí ó lágbára lẹ́yìn tí ó bá pànìyàn tan, láti wọ́ ni lọ sí ọ̀run àpáàdì. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín òun ni kí ẹ bẹ̀rù. 6 Ológoṣẹ́ márùn-ún sá à ni a ń tà ní owó idẹ wẹ́wẹ́ méjì? A kò sì gbàgbé ọ̀kan nínú wọn níwájú Ọlọ́run? 7 (BH)Ṣùgbọ́n gbogbo irun orí yín ni a kà pé ṣánṣán. Nítorí náà kí ẹ má ṣe bẹ̀rù: ẹ̀yin ní iye lórí ju ológoṣẹ́ púpọ̀ lọ.
8 “Mo sì wí fún yín pẹ̀lú, Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ mi níwájú àwọn ènìyàn. Ọmọ ènìyàn yóò sì jẹ́wọ́ rẹ̀ níwájú àwọn angẹli Ọlọ́run: 9 (BI)Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sẹ́ mi níwájú ènìyàn, a ó sẹ́ ẹ níwájú àwọn angẹli Ọlọ́run. 10 (BJ)Àti ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀-òdì sí ọmọ ènìyàn, a ó dárí rẹ̀ jì í; ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀-òdì sí ẹ̀mí mímọ́, a kì yóò dárí rẹ̀ jì í.
11 (BK)“Nígbà tí wọ́n bá sì mú yin wá sí Sinagọgu, àti síwájú àwọn olórí, àti àwọn aláṣẹ, ẹ má ṣe ṣàníyàn pé, báwo tàbí ohun kín ni ẹ̀yin yóò fèsì rẹ̀ tàbí kín ni ẹ̀yin ó wí: 12 Nítorí Ẹ̀mí mímọ́ yóò kọ́ yín ní wákàtí kan náà ní ohun tí ó yẹ kí ẹ sọ.”
Ìtàn òmùgọ̀ ọlọ́rọ̀
13 Ọ̀kan nínú àwùjọ wí fún un pé, “Olùkọ́, sọ fún arákùnrin mi kí ó pín mi ní ogún.”
14 Ó sì wí fún un pé, “Ọkùnrin yìí, ta ni ó fi mí jẹ onídàájọ́ tàbí olùpíngún fún yín?” 15 (BL)Ó sì wí fún wọn pé, “Kíyèsára kí o sì máa ṣọ́ra nítorí ojúkòkòrò: nítorí ìgbésí ayé ènìyàn kò dúró lé ọ̀pọ̀ ohun tí ó ní.”
16 Ó sì pa òwe kan fún wọn pé, “Ilẹ̀ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ so ọ̀pọ̀lọpọ̀ èso. 17 Ó sì rò nínú ara rẹ̀ pé, ‘Èmi ó ti ṣe, nítorí tí èmi kò ní ibi tí èmi ó gbé kó èso mi jọ sí.’
18 “Ó sì wí pé, ‘Èyí ni èmi ó ṣe: èmi ó wó àká mi palẹ̀, èmi ó sì kọ́ èyí tí ó tóbi; níbẹ̀ ni èmi ó gbé to gbogbo èso àti ọrọ̀ mi jọ sí. 19 Èmi ó sì wí fún ọkàn mi pé, ọkàn, ìwọ ní ọrọ̀ púpọ̀ tí a tò jọ fún ọ̀pọ̀ ọdún; sinmi, máa jẹ, máa mu, máa yọ̀.’
20 (BM)“Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wí fún un pé, ‘Ìwọ aṣiwèrè, lóru yìí ni a ó béèrè ọkàn rẹ lọ́wọ́ rẹ; ǹjẹ́ ti ta ni nǹkan wọ̀nyí yóò ha ṣe, tí ìwọ ti pèsè sílẹ̀?’
21 “Bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó to ìṣúra jọ fún ara rẹ̀, tí kò sì ní ọrọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.”
Má ṣe ṣe àníyàn
22 (BN) Jesu sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Nítorí náà mo wí fún yín pé, ẹ má ṣe ṣe àníyàn nítorí ẹ̀mí yín pé, kín ni ẹ̀yin yóò jẹ tàbí nípa ara yin pe kín ni ẹyin o fi bora. 23 Ẹ̀mí sá à ju oúnjẹ lọ, ara sì ju aṣọ lọ. 24 (BO)Ẹ kíyèsi àwọn ẹyẹ ìwò: wọn kì í fúnrúgbìn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kórè: wọn kò ní àká, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní abà, Ọlọ́run sá à ń bọ́ wọn: mélòó mélòó ni tí ẹ̀yin fi sàn ju ẹyẹ lọ! 25 Ta ni nínú yín nípa àníyàn ṣíṣe tí ó lè fi ìgbọ̀nwọ́ kan kún ọjọ́ ayé rẹ̀? 26 Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin kò ti lè ṣe èyí tí ó kéré bí eléyìí, èéṣe tí ẹ̀yin fi ń ṣàníyàn nítorí ìyókù?
27 (BP)“Ẹ kíyèsi àwọn lílì bí wọ́n ti ń dàgbà; wọn kì í ṣiṣẹ́, wọn kì í rànwú; ṣùgbọ́n kí èmi wí fún yín, a kò ṣe Solomoni pàápàá lọ́ṣọ̀ọ́ ní gbogbo ògo rẹ̀ tó ọ̀kan nínú ìwọ̀nyí. 28 Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run bá wọ koríko igbó ní aṣọ tó bẹ́ẹ̀ èyí tí ó wà lónìí, tí a sì gbá a sínú iná lọ́la: mélòó mélòó ni yóò wọ̀ yín láṣọ, ẹ̀yin onígbàgbọ́ kékeré. 29 Kí ẹ má sì ṣe lé ohun tí ẹ ó jẹ, tàbí ohun tí ẹ ó mu, kí ẹ má sì ṣe ṣe àníyàn nínú ọkàn. 30 (BQ)Nítorí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni àwọn orílẹ̀-èdè ayé ń wá kiri: Baba yín sì mọ̀ pé, ẹ̀yin ń fẹ́ nǹkan wọ̀nyí. 31 Ṣùgbọ́n ẹ máa wá ìjọba Ọlọ́run, gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.
32 (BR)“Má bẹ̀rù, agbo kékeré; nítorí dídùn inú Baba yín ni láti fi ìjọba fún yín. 33 (BS)Ẹ ta ohun tí ẹ̀yin ní, kí ẹ sì tọrẹ àánú kí ẹ sì pèsè àpò fún ara yín, tí kì í gbó, ìṣúra ní ọ̀run tí kì í tán, ní ibi tí olè kò lè súnmọ́, àti ibi tí kòkòrò kì í bà á jẹ́. 34 Nítorí ní ibi tí ìṣúra yín gbé wà, níbẹ̀ ni ọkàn yín yóò gbé wà pẹ̀lú.
Ẹ máa ṣọ́nà
35 (BT)“Ẹ di àmùrè yín, kí fìtílà yín sì máa jó. 36 Kí ẹ̀yin tìkára yín dàbí ẹni tí ń retí olúwa wọn, nígbà tí òun ó padà ti ibi ìgbéyàwó dé: pé, nígbà tí ó bá dé, tí ó sì kànkùn, kí wọn lè ṣí i sílẹ̀ fún un lọ́gán. 37 (BU)Ìbùkún ni fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ náà nígbà tí olúwa náà bá dé tí yóò bá wọn tí wọn ń ṣọ́nà; lóòótọ́ ni mo wí fún yín, yóò di ara rẹ̀ ní àmùrè yóò sì mú wọn jókòó láti jẹun, yóò sì jáde wá láti ṣe ìránṣẹ́ fún wọn. 38 Bí olúwa wọn bá sì dé nígbà ìṣọ́ kejì, tàbí tí ó sì dé nígbà ìṣọ́ kẹta, tí ó sì bá wọn bẹ́ẹ̀, ìbùkún ni fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ náà. 39 (BV)Ṣùgbọ́n ẹ mọ èyí pé, baálé ilé ìbá mọ wákàtí tí olè yóò wá, (òun ìbá máa ṣọ́nà) kì bá tí jẹ́ kí a já wọ inú ilé òun. 40 Nítorí náà kí ẹ̀yin múra pẹ̀lú: Nítorí ọmọ ènìyàn ń bọ̀ ní wákàtí tí ẹ̀yin kò nírètí.”
41 Peteru sì wí pé, “Olúwa, ìwọ pa òwe yìí fún wa, tàbí fún gbogbo ènìyàn?”
42 (BW)(BX) Olúwa sì dáhùn wí pé, “Ta ni olóòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n ìríjú náà, tí olúwa rẹ̀ fi jẹ olórí agbo ilé rẹ̀, láti máa fi ìwọ̀n oúnjẹ wọ́n fún wọn ní àkókò? 43 Ìbùkún ni fún ọmọ ọ̀dọ̀ náà, nígbà tí olúwa rẹ̀ bá dé, tí yóò bá a kí ó máa ṣe bẹ́ẹ̀. 44 Lóòótọ́ ni mo wí fún yín yóò fi jẹ olórí ohun gbogbo tí ó ní. 45 Ṣùgbọ́n bí ọmọ ọ̀dọ̀ náà bá wí ní ọkàn rẹ̀, pé, ‘Olúwa mi fi ìgbà bíbọ̀ rẹ̀ falẹ̀!’ Tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í lu àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ àti sí mu àmupara: 46 Olúwa ọmọ ọ̀dọ̀ náà yóò dé ní ọjọ́ tí kò retí rẹ̀, àti ní wákàtí tí kò dábàá, yóò sì jẹ ẹ́ ní yà gidigidi, yóò sì yan ipò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́.
47 (BY)“Àti ọmọ ọ̀dọ̀ náà, tí ó mọ ìfẹ́ olúwa rẹ̀, tí kò sì múra sílẹ̀, tí kò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, òun ni a ó nà púpọ̀. 48 Ṣùgbọ́n èyí tí kò mọ̀, tí ó ṣe ohun tí ó yẹ sí lílù, òun ni a ó lù níwọ̀n. Nítorí ẹnikẹ́ni tí a fún ní púpọ̀, lọ́dọ̀ rẹ̀ ni a ó gbé béèrè púpọ̀: lọ́dọ̀ ẹni tí a bá gbé fi púpọ̀ sí, lọ́dọ̀ rẹ ni a ó gbé béèrè sí i.
Àlàáfíà kọ́ ṣùgbọ́n ìyapa
49 (BZ)“Iná ni èmi wá láti sọ sí ayé; kín ni èmi sì ń fẹ́ bí kò ṣe kí iná náà ti jo! 50 (CA)Ṣùgbọ́n èmi ní bamitiisi kan tí a ó fi bamitiisi mi; ara ti ń ni mí tó títí yóò fi parí! 51 (CB)Ẹ̀yin ṣe bí àlàáfíà ni èmi fi sí ayé? Mo wí fún yín, bẹ́ẹ̀ kọ́; ṣùgbọ́n bí kò ṣe ìyapa. 52 Nítorí láti ìsinsin yìí lọ, ènìyàn márùn-ún yóò wà ní ilé kan náà tí a ó yà ní ipa, mẹ́ta sí méjì, àti méjì sí mẹ́ta. 53 A ó ya baba nípa sí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àti ọmọ ọkùnrin sí baba; ìyá sí ọmọbìnrin, àti ọmọbìnrin sí ìyá rẹ̀, ìyá ọkọ sí ìyàwó ọmọ, àti ìyàwó ọmọ sí ìyá ọkọ rẹ̀.”
Ògbufọ̀ àwọn àkókò
54 (CC)Ó sì wí fún ìjọ ènìyàn pẹ̀lú pé, “Nígbà tí ẹ̀yin bá rí àwọsánmọ̀ tí ó ṣú ní ìhà ìwọ̀-oòrùn, lọ́gán ni ẹ̀yin yóò sọ pé, ‘Ọ̀wààrà òjò ń bọ̀,’ a sì rí bẹ́ẹ̀. 55 Nígbà tí afẹ́fẹ́ gúúsù bá ń fẹ́, ẹ̀yin á ní, ‘Oòrùn yóò mú,’ yóò sì ṣe bẹ́ẹ̀. 56 Ẹ̀yin àgàbàgebè! Ẹ̀yin le mòye ojú ọ̀run àti ti ayé. Èéha ti ṣe tí ẹ̀yin kò mọ àkókò yìí?
57 (CD)“Èéha ti ṣe tí ẹ̀yin tìkára yín kò fi ro ohun tí ó tọ́? 58 Nígbà tí ìwọ bá bá ọ̀tá rẹ lọ sọ́dọ̀ onídàájọ́, rí i pé o bá a parí ọ̀rọ̀ ní ọ̀nà kí ó má ba à fà ọ́ fún adájọ́, adájọ́ a fi ọ́ lé ẹ̀ṣọ́ lọ́wọ́, òun a sì tì ọ́ sínú túbú. 59 Kí èmi wí fún ọ, ìwọ kì yóò jáde kúrò níbẹ̀, títí ìwọ ó fi san ẹyọ owó kan tí ó kù!”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.