Read the Gospels in 40 Days
Ẹ̀ṣẹ̀, ìgbàgbọ́, àti iṣẹ́
17 (A)Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Kò le ṣe kí ohun ìkọ̀sẹ̀ máa wa: ṣùgbọ́n ègbé ni fún ẹni tí ó ti ipasẹ̀ rẹ̀ dé. 2 Ìbá sàn fún un kí a so ọlọ mọ́ ọn ní ọrùn, kí a sì gbé e jù sínú Òkun, ju kí ó mú ọ̀kan nínú àwọn kékeré wọ̀nyí kọsẹ̀. 3 (B)Ẹ máa kíyèsára yín.
“Bí arákùnrin rẹ bá ṣẹ̀, bá a wí; bí ó bá sì ronúpìwàdà, dáríjì ín. 4 Bí ó bá sì ṣẹ̀ ọ́ ní igba méje ní òòjọ́, tí ó padà tọ̀ ọ́ wá ní ìgbà méje ní òòjọ́ pé, ‘Mo ronúpìwàdà,’ dáríjì ín.”
5 (C)(D) Àwọn aposteli sì wí fún Olúwa pé, “Bù sí ìgbàgbọ́ wa.”
6 Olúwa sì wí pé, “Bí ẹ̀yin bá ní ìgbàgbọ́ bí hóró irúgbìn musitadi, ẹ̀yin yóò lè wí fún igi sikamine yìí pé, ‘di fi fà á tu, kí a sì gbìn ọ́ sínú Òkun,’ yóò sì gbọ́ tiyín.
7 “Ṣùgbọ́n ta ni nínú yín, tí ó ní ọmọ ọ̀dọ̀, tí ó ń tulẹ̀, tàbí tí ó ń bọ́ ẹran, tí yóò wí fún un lójúkan náà tí ó bá ti oko dé pé, ‘Lọ í jókòó láti jẹun’? 8 (E)Tí kì yóò kúkú wí fún un pé, ‘Pèsè ohun tí èmi yóò jẹ, sì di àmùrè, kí ìwọ kí ó máa ṣe ìránṣẹ́ fún mi, títí èmi ó fi jẹ kí èmi ó sì mu tán; lẹ́yìn náà ni ìwọ ó sì jẹ, tí ìwọ ó sì mu’? 9 Òun ó ha máa dá ọpẹ́ lọ́wọ́ ọmọ ọ̀dọ̀ náà, nítorí ó ṣe ohun tí a pàṣẹ fún un bí? Èmi kò rò bẹ́ẹ̀. 10 Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin pẹ̀lú, nígbà tí ẹ bá ti ṣe ohun gbogbo tí a pàṣẹ fún yín tán, ẹ wí pé, ‘Aláìlérè ọmọ ọ̀dọ̀ ni wá: èyí tí í ṣe iṣẹ́ wa láti ṣe, ní àwa ti ṣe.’ ”
Ìwòsàn adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá
11 (F)Ó sì ṣe, bí ó ti ń lọ sí Jerusalẹmu, ó kọjá láàrín Samaria Galili. 12 (G)Bí ó sì ti ń wọ inú ìletò kan lọ, àwọn ọkùnrin adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá pàdé rẹ̀, wọ́n dúró ní òkèrè: 13 (H)Wọ́n sì kígbe sókè, wí pé, “Jesu, Olùkọ́, ṣàánú fún wa.”
14 (I)Nígbà tí ó rí wọn, ó wí fún wọn pé, “Ẹ lọ í fi ara yín hàn fún àwọn àlùfáà.” Ó sì ṣe, bí wọ́n ti ń lọ, wọ́n sì di mímọ́.
15 Nígbà tí ọ̀kan nínú wọn rí i pé a mú Òun láradá ó padà, ó sì fi ohùn rara yin Ọlọ́run lógo. 16 Ó sì wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀, ó ń dúpẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀: ará Samaria ni òun í ṣe.
17 Jesu sì dáhùn wí pé, “Àwọn mẹ́wàá kí a sọ di mímọ́? Àwọn mẹ́sàn-án ìyókù ha dà? 18 A kò rí ẹnìkan tí ó padà wá fi ògo fún Ọlọ́run, bí kò ṣe àlejò yìí?” 19 (J)Ó sì wí fún un pé, “Dìde, kí o sì máa lọ: ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá.”
Bíbọ̀ ìjọba Ọlọ́run
20 (K)Nígbà tí àwọn Farisi bi í pé, nígbà wo ni ìjọba Ọlọ́run yóò dé, ó dá wọn lóhùn pé, “Ìjọba Ọlọ́run kì í wá pẹ̀lú ààmì: 21 Bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wí pé, ‘Kíyèsi i níhìn-ín!’ tàbí ‘Kíyèsi i lọ́hùn ún ni!’ sá à wò ó, ìjọba Ọlọ́run ń bẹ nínú yín.”
22 (L)Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ọjọ́ ń bọ̀, nígbà tí ẹ̀yin yóò fẹ́ láti rí ọ̀kan nínú ọjọ́ ọmọ ènìyàn, ẹ̀yin kì yóò sì rí i. 23 (M)Wọ́n sì wí fún yín pé, ‘Wò ó níhìn-ín;’ tàbí ‘Wò ó lọ́hùn ún!’ Ẹ máa lọ, ẹ má ṣe tẹ̀lé wọn. 24 (N)Nítorí gẹ́gẹ́ bí mọ̀nàmọ́ná ti í kọ ní apá kan lábẹ́ ọ̀run, tí sì í mọ́lẹ̀ ní apá kejì lábẹ́ ọ̀run: bẹ́ẹ̀ ni ọmọ ènìyàn yóò sì rí ní ọjọ́ rẹ̀. 25 (O)Ṣùgbọ́n kò lè ṣàìmá kọ́ jìyà ohun púpọ̀, kí a sì kọ̀ ọ́ lọ́dọ̀ ìran yìí.
26 (P)“Bí ó ti rí ní ọjọ́ Noa, bẹ́ẹ̀ ni yóò rí ní ọjọ́ ọmọ ènìyàn. 27 Wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n ń gbéyàwó, wọ́n sì ń fa ìyàwó fún ni, títí ó fi di ọjọ́ ti Noa wọ inú ọkọ̀ lọ, kíkún omi sì dé, ó sì run gbogbo wọn.
28 (Q)“Bí ó sì ti rí ní ọjọ́ Lọti; wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n ń rà, wọ́n ń tà, wọ́n ń gbìn, wọ́n ń kọ́lé; 29 Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ náà tí Lọti jáde kúrò ní Sodomu, òjò iná àti sulfuru rọ̀ láti ọ̀run wá, ó sì run gbogbo wọn.
30 “Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni yóò rí ní ọjọ́ náà tí Ọmọ ènìyàn yóò farahàn. 31 (R)Ní ọjọ́ náà, ẹni tí ó bá wà lórí ilé, tí ẹrù rẹ̀ sì ń bẹ ní ilẹ̀, kí ó má ṣe sọ̀kalẹ̀ láti wá kó o; ẹni tí ó bá sì wà ní oko, kí ó má ṣe padà sẹ́yìn. 32 (S)Ẹ rántí aya Lọti. 33 (T)Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wá àti gba ẹ̀mí rẹ̀ là yóò sọ ọ́ nù; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì sọ ọ́ nù yóò gbà á là. 34 (U)Mo wí fún yín, ní òru ọjọ́ náà, ènìyàn méjì yóò wà lórí àkéte kan; a ó mú ọ̀kan, a ó sì fi èkejì sílẹ̀. 35 Ènìyàn méjì yóò sì máa lọ ọlọ pọ̀; a ó mú ọ̀kan, a ó sì fi èkejì sílẹ̀. 36 Ènìyàn méjì yóò wà ní oko, a ó mú ọ̀kan, a ó sì fi èkejì sílẹ̀.”
37 (V)Wọ́n sì dá a lóhùn, wọ́n bi í pé, “Níbo, Olúwa?”
Ó sì wí fún wọn pé, “Níbi tí òkú bá gbé wà, níbẹ̀ pẹ̀lú ni igún ìkójọpọ̀ sí.”
Òwe ìforítì opó
18 (W)Ó sì pa òwe kan fún wọn láti fi yé wọn pe, ó yẹ kí a máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí a má sì ṣàárẹ̀; 2 Wí pé, “Onídàájọ́ kan wà ní ìlú kan, tí kò bẹ̀rù Ọlọ́run, tí kò sì ṣe ojúsàájú ènìyàn. 3 Opó kan sì wà ní ìlú náà, ó sì ń tọ̀ ọ́ wá, wí pé, ‘Gbẹ̀san mi lára ọ̀tá mi!’
4 “Lákọ̀ọ́kọ́ kò dá a lóhùn: ṣùgbọ́n níkẹyìn ó wí nínú ara rẹ̀ pé, ‘Bí èmi kò tilẹ̀ bẹ̀rù Ọlọ́run, tí èmi kò sì ṣe ojúsàájú ènìyàn, 5 Ṣùgbọ́n nítorí tí opó yìí ń yọ mí lẹ́nu, èmi ó gbẹ̀san rẹ̀, kí ó má ba à fi wíwá rẹ̀ nígbàkúgbà dá mi lágara.’ ”
6 (X)Olúwa sì wí pé, “Ẹ gbọ́ bí aláìṣòótọ́ onídàájọ́ ti wí! 7 (Y)Ọlọ́run kì yóò ha sì gbẹ̀san àwọn àyànfẹ́ rẹ̀, tí ń fi ọ̀sán àti òru kígbe pè é, tí ó sì mú sùúrù fún wọn? 8 Mo wí fún yín, yóò gbẹ̀san wọn kánkán! Ṣùgbọ́n nígbà tí Ọmọ Ènìyàn bá dé yóò ha rí ìgbàgbọ́ ní ayé bí?”
Òwe Farisi àti agbowó òde
9 Ó sì pa òwe yìí fún àwọn kan tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ara wọn pé, àwọn ni olódodo, tí wọ́n sì ń gan àwọn ẹlòmíràn; 10 Pé, “Àwọn ọkùnrin méjì gòkè lọ sí tẹmpili láti gbàdúrà, ọ̀kan jẹ́ Farisi, èkejì sì jẹ́ agbowó òde. 11 (Z)Èyí Farisi dìde, ó sì ń gbàdúrà nínú ara rẹ̀ báyìí pé, ‘Ọlọ́run mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, nítorí tí èmi kò rí bí àwọn ará ìyókù, àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà, aláìṣòótọ́, panṣágà, tàbí bí agbowó òde yìí. 12 (AA)Èmi ń gbààwẹ̀ lẹ́ẹ̀méjì ní ọ̀sẹ̀, mo ń san ìdámẹ́wàá ohun gbogbo tí mo ní.’
13 “Ṣùgbọ́n agbowó òde dúró lókèèrè, kò tilẹ̀ jẹ́ gbé ojú rẹ̀ sókè ọ̀run, ṣùgbọ́n ó lu ara rẹ̀ ní oókan àyà, ó wí pé, ‘Ọlọ́run ṣàánú fún mi, èmi ẹlẹ́ṣẹ̀!’
14 (AB)“Mo wí fún yín, ọkùnrin yìí sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ̀ ní ìdáláre ju èkejì lọ: nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga, òun ni a ó rẹ̀ sílẹ̀; ẹni tí ó bá sì rẹ̀ ara rẹ̀ sílẹ̀ òun ni a ó gbéga.”
Àwọn ọmọdé àti Jesu
15 (AC)Wọ́n sì gbé àwọn ọmọ ọwọ́ tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú, kí ó lè gbé ọwọ́ lé wọn; ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ rí i, wọ́n ń bá wọn wí. 16 Ṣùgbọ́n Jesu pè wọ́n sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ kékeré wá sọ́dọ̀ mi, ẹ má sì ṣe dá wọn lẹ́kun: nítorí tí irú wọn ni ìjọba Ọlọ́run. 17 Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹnikẹ́ni tí kò bá gbà ìjọba Ọlọ́run bí ọmọ kékeré, kì yóò wọ inú rẹ̀ bí ó ti wù kí ó rí.”
Ọlọ́rọ̀ alákòóso
18 (AD)(AE) Ìjòyè kan sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, wí pé, “Olùkọ́ rere, kín ni èmi ó ṣe tí èmi ó fi jogún ìyè àìnípẹ̀kun?”
19 Jesu wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń pè mí ní ẹni rere? Ẹni rere kan kò sí bí kò ṣe ẹnìkan, èyí sì ni Ọlọ́run. 20 (AF)Ìwọ mọ̀ àwọn òfin: ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà, ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn, ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe jalè, ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe jẹ́rìí èké, bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ.’ ”
21 Ó sì wí pé, “Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi ti pamọ́ láti ìgbà èwe mi wá.”
22 (AG)Nígbà tí Jesu sì gbọ́ èyí, ó wí fún un pé, “Ohun kan ni ó kù fún ọ síbẹ̀: lọ ta ohun gbogbo tí o ní, kí o sì pín in fún àwọn tálákà, ìwọ ó sì ní ìṣúra ní ọ̀run: sì wá, kí o máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”
23 Nígbà tí ó sì gbọ́ èyí, inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi: nítorí tí ó ní ọrọ̀ púpọ̀. 24 (AH)Nígbà tí Jesu rí i pé inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi, ó wí pé, “Yóò ti ṣòro tó fún àwọn tí ó ní ọrọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run! 25 Nítorí ó rọrùn fún ìbákasẹ láti gba ojú abẹ́rẹ́ wọlé jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run lọ.”
26 Àwọn tí ó sì gbọ́ wí pé, “Ǹjẹ́ ta ni ó ha lè là?”
27 (AI)Ó sì wí pé, “Ohun tí ó ṣòro lọ́dọ̀ ènìyàn kò ṣòro lọ́dọ̀ Ọlọ́run.”
28 (AJ)Peteru sì wí pé, “Sá wò ó, àwa ti fi ilé wa sílẹ̀, a sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn!”
29 Ó sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, kò sí ẹni tí ó fi ilé, tàbí aya, tàbí ará, tàbí òbí, tàbí ọmọ sílẹ̀, nítorí ìjọba Ọlọ́run, 30 Tí kì yóò gba ìlọ́po púpọ̀ sí i ní ayé yìí, àti ní ayé tí ń bọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun.”
Jesu tún sọ nípa ikú rẹ̀
31 (AK)Nígbà náà ni ó pe àwọn méjìlá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Sá wò ó, àwa ń gòkè lọ sí Jerusalẹmu, a ó sì mú ohun gbogbo ṣẹ, tí a ti kọ láti ọwọ́ àwọn wòlíì, nítorí Ọmọ Ènìyàn. 32 Nítorí tí a ó fi lé àwọn aláìkọlà lọ́wọ́, a ó fi ṣe ẹlẹ́yà, a ó sì fi ṣe ẹ̀sín, a ó sì tutọ́ sí i lára. 33 Wọn ó sì nà án, wọn ó sì pa á: ní ọjọ́ kẹta yóò sì jíǹde.”
34 Ọ̀kan nínú nǹkan wọ̀nyí kò sì yé wọn: ọ̀rọ̀ yìí sì pamọ́ fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì mọ ohun tí a wí.
Afọ́jú alágbe gba ìwòsàn
35 (AL)Bí ó ti súnmọ́ Jeriko, afọ́jú kan jókòó lẹ́bàá ọ̀nà ó ń ṣagbe: 36 Nígbà tí ó gbọ́ tí ọ̀pọ̀ ń kọjá lọ, ó béèrè pé, kín ni ìtumọ̀ èyí. 37 Wọ́n sì wí fún un pé, “Jesu ti Nasareti ni ó ń kọjá lọ.”
38 Ó sì kígbe pé, “Jesu, ìwọ ọmọ Dafidi, ṣàánú fún mi!”
39 Àwọn tí ń lọ níwájú bá a wí, pé, kí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́: ṣùgbọ́n òun sì kígbe sókè sí í pé, “Ìwọ Ọmọ Dafidi, ṣàánú fún mi!”
40 Jesu sì dúró, ó ní, kí á mú un tọ òun wá nígbà tí ó sì súnmọ́ ọn, ó bi í, 41 Wí pé, “Kí ni ìwọ ń fẹ́ kí èmi ṣe fún ọ?”
Ó sì wí pé, “Olúwa jẹ́ kí èmi ríran.”
42 (AM)Jesu sì wí fún un pé, “Ríran; ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá.” 43 Lójúkan náà ó sì ríran, ó sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó sì ń yin Ọlọ́run lógo àti gbogbo ènìyàn nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n fi ìyìn fún Ọlọ́run.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.