Read the Gospels in 40 Days
Ìkọ̀sílẹ̀
10 (A)(B) Nígbà náà, Jesu kúrò níbẹ̀, ó sì wá sí ẹkùn Judea níhà òkè odò Jordani. Àwọn ènìyàn sì tún tọ̀ ọ́ wá, bí i ìṣe rẹ̀, ó sì kọ́ wọn.
2 Àwọn Farisi kan tọ̀ ọ́ wá, láti dán an wò. Wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ ó ha tọ̀nà fún ènìyàn láti kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀?”
3 Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Kí ni Mose pàṣẹ fún un yín?”
4 (C)Wọ́n dáhùn pé, “Mose yọ̀ǹda fún wa láti kọ ìwé ìkọ̀sílẹ̀ fún un, kí a sì fi sílẹ̀.”
5 Ṣùgbọ́n Jesu dá wọn lóhùn, ó sì wí pé, “Nítorí líle àyà yín ni Mose fi kọ òfin yìí fun un yín. 6 (D)Ṣùgbọ́n láti ìgbà tí ayé ti ṣẹ̀, Ọlọ́run dá wọn ní akọ àti abo. 7 (E)Nítorí ìdí èyí, ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀ yóò sì fi ara mọ́ aya rẹ̀. 8 Òun àti ìyàwó rẹ̀ yóò di ara kan náà. Nítorí náà, wọn kì í túnṣe méjì mọ́ bí kò ṣe ẹyọ ọ̀kan ṣoṣo. 9 Nítorí náà ohun ti Ọlọ́run bá sọ dọ̀kan, ki ẹnikẹ́ni máa ṣe yà wọ́n.”
10 Lẹ́yìn náà, nígbà tí Jesu nìkan wà nínú ilé pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n tún béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ nípa ohun kan náà. 11 (F)Jesu túbọ̀ ṣe àlàyé fún wọn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ tí ó bá sì fẹ́ ẹlòmíràn, irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀ ṣe panṣágà sí obìnrin tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé níyàwó. 12 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, bí obìnrin kan bá kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀ tí ó sì fẹ́ ọkùnrin mìíràn, irú obìnrin bẹ́ẹ̀ ṣe panṣágà.”
Jesu àti àwọn ọmọdé
13 (G)Lẹ́yìn èyí, àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí í gbé àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ tọ Jesu wá kí ó lè súre fún wọn. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kígbe mọ́ àwọn tí ń gbé àwọn ọmọdé wọ̀nyí bọ̀ pé wọn kò gbọdọ̀ yọ Jesu lẹ́nu rárá. 14 Ṣùgbọ́n nígbà tí Jesu rí ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀, inú rẹ̀ kò dùn sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Nítorí náà, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọdé kékeré wá sọ́dọ̀ mi. Ẹ má ṣe dá wọn lẹ́kun nítorí pé irú wọn ni ìjọba Ọlọ́run. 15 Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹnikẹ́ni tí kò bá gba ìjọba Ọlọ́run bí ọmọ kékeré, kì yóò le è wọ inú rẹ̀.” 16 (H)Nígbà náà, Jesu gbé àwọn ọmọ náà lé ọwọ́ rẹ̀, ó gbé ọwọ́ lé orí wọn. Ó sì súre fún wọn.
Ọ̀dọ́mọkùnrin ọlọ́rọ̀
17 (I)(J) Bí Jesu ti bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò rẹ, ọkùnrin kan sáré wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó sì kúnlẹ̀, ó béèrè pé, “Olùkọ́ rere, kí ni èmi yóò ṣe láti jogún ìyè àìnípẹ̀kun?”
18 Jesu béèrè pé, Arákùnrin, “Èéṣe tí o fi ń pè mí ní ẹni rere? Ẹni rere kan kò sí Ọlọ́run nìkan ni ẹni rere. 19 (K)Ìwọ mọ àwọn òfin bí: Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn, ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà, ìwọ kò gbọdọ̀ jalè, ìwọ kò gbọdọ̀ purọ́, ìwọ kò gbọdọ̀ rẹ́ ọmọnìkejì jẹ, bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ.”
20 Ọkùnrin náà dáhùn pé, “Olùkọ́, gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi ń ṣe láti ìgbà èwe mi wá.”
21 (L)Jesu wò ó tìfẹ́tìfẹ́. Ó wí fún un pé, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ohun kan ló kù fún ọ láti ṣe, lọ nísinsin yìí, ta gbogbo nǹkan tí o ní, kí o sì pín owó náà fún àwọn aláìní ìwọ yóò sì ní ìṣúra ní ọ̀run, sì wá, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”
22 Nígbà tí ọkùnrin yìí gbọ́ èyí, ojú rẹ̀ korò, ó sì lọ pẹ̀lú ìbànújẹ́, nítorí pé ó ní ọrọ̀ púpọ̀.
23 Jesu wò ó bí ọkùnrin náà ti ń lọ. Ó yípadà, ó sì sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Àní, ohun ìṣòro ni fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run!”
24 Ọ̀rọ̀ yìí ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́nu. Jesu tún sọ fún wọn pé, “Ẹyin ọmọ yóò tí ṣòro tó fún àwọn tí ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ọrọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run. 25 Ó rọrùn fún ìbákasẹ láti gba ojú abẹ́rẹ́ wọlé jù fún ọlọ́rọ̀ kan láti wọ ìjọba ọ̀run.”
26 Ẹnu túbọ̀ ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sí i. Wọ́n béèrè wí pé, “Tí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ta ni nínú ayé ni ó lè ní ìgbàlà?”
27 Jesu wò wọ́n, ó sì wí fún wọn pé, “Ènìyàn ní èyí kò ṣe é ṣe fún ṣùgbọ́n kì í ṣe fún Ọlọ́run, nítorí ohun gbogbo ni ṣíṣe fún Ọlọ́run.”
28 (M)Nígbà náà ni Peteru kọjú sí Jesu, ó wí pé, “Àwa ti fi ohun gbogbo sílẹ̀, a sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.”
29 Jesu dáhùn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín pé, kò sí ẹnikẹ́ni tí ó fi ohunkóhun sílẹ̀ bí: ilé, tàbí àwọn arákùnrin, tàbí àwọn arábìnrin, tàbí ìyá, tàbí baba, tàbí àwọn ọmọ tàbí ohun ìní nítorí mi àti nítorí ìhìnrere, 30 (N)tí a kì yóò fún padà ní ọgọọgọ́rùn-ún àwọn ilé, tàbí arákùnrin, tàbí arábìnrin, tàbí ìyá, tàbí ọmọ, tàbí ilẹ̀, àti inúnibíni pẹ̀lú. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò jẹ́ tirẹ̀ ní ayé yìí àti pé ní ayé tó ń bọ̀ yóò ní ìyè àìnípẹ̀kun. 31 (O)Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn tí ó síwájú ni yóò di ẹni ìkẹyìn, àwọn tí ó sì kẹ́yìn yóò síwájú.”
Jesu tún sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ikú ara rẹ̀
32 (P)Nísinsin yìí, wọ́n wà lójú ọ̀nà sí Jerusalẹmu. Jesu sì ń lọ níwájú wọn, bí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ti ń tẹ̀lé e, ìbẹ̀rù kún ọkàn wọn. Ó sì tún mú àwọn méjìlá sí apá kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàlàyé ohun gbogbo tí a ó ṣe sí i fún wọn. 33 (Q)Ó sọ fún wọn pé, “Àwa ń gòkè lọ Jerusalẹmu, a ó sì fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin lọ́wọ́. Wọn ni yóò dá lẹ́bi ikú. Wọn yóò sì fà á lé ọwọ́ àwọn aláìkọlà. 34 (R)Wọn yóò fi ṣe ẹlẹ́yà, wọn yóò tutọ́ sí ní ara, wọn yóò nà pẹ̀lú pàṣán wọn. Wọn yóò sì pa, ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta yóò tún jíǹde.”
Ìbéèrè Johanu àti Jakọbu
35 (S)Lẹ́yìn èyí, Jakọbu àti Johanu, àwọn ọmọ Sebede wá sọ́dọ̀ Jesu. Wọ́n sì bá a sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, wọ́n wí pé, “Olùkọ́, inú wa yóò dùn bí ìwọ bá lè ṣe ohunkóhun tí a bá béèrè fún wa.”
36 Jesu béèrè pé, “Kí ni Ẹ̀yin ń fẹ́ kí èmi ó ṣe fún un yín?”
37 (T)Wọ́n bẹ̀bẹ̀ pé, “Jẹ́ kí ọ̀kan nínú wa jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ àti ẹnìkejì ní ọwọ́ òsì nínú ògo rẹ!”
38 (U)Ṣùgbọ́n Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ kò mọ ohun tí ẹ̀ ń béèrè! Ṣe ẹ lè mu nínú ago kíkorò tí èmi ó mú tàbí a lè bamitiisi yín pẹ̀lú irú ì bamitiisi ìjìyà tí a ó fi bamitiisi mi?”
39 (V)Àwọn méjèèjì dáhùn pé, “Àwa pẹ̀lú lè ṣe bẹ́ẹ̀.”
Jesu wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni ẹ̀yin ó mu ago ti èmi yóò mu, àti bamitiisi tí a sí bamitiisi mi ni a ó fi bamitiisi yín, 40 ṣùgbọ́n láti jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi àti ní ọwọ́ òsì mi kì ì ṣe ti èmi láti fi fún ni: bí kò ṣe fún àwọn ẹni tí a ti pèsè rẹ̀ sílẹ̀ fún.”
41 Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́wàá ìyókù gbọ́ ohun tí Jakọbu àti Johanu béèrè, wọ́n bínú. 42 (W)Nítorí ìdí èyí, Jesu pè wọ́n sọ́dọ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé, àwọn ọba àti àwọn kèfèrí ń lo agbára lórí àwọn ènìyàn. 43 (X)Ṣùgbọ́n láàrín yín ko gbọdọ̀ ri bẹ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ di olórí nínú yín gbọdọ̀ ṣe ìránṣẹ́. 44 Ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ di aṣáájú nínú yín gbọdọ̀ ṣe ìránṣẹ́ gbogbo yín. 45 (Y)Nítorí, Èmi, Ọmọ Ènìyàn kò wá sí ayé kí ẹ lè ṣe ìránṣẹ́ fún mi, ṣùgbọ́n láti lè ṣe ìránṣẹ́ fun àwọn ẹlòmíràn, àti láti fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà ọ̀pọ̀ ènìyàn.” 46 (Z)Wọ́n dé Jeriko, bí Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ àti ọ̀pọ̀ ènìyàn ti fẹ́ kúrò ní ìlú Jeriko, ọkùnrin afọ́jú kan, Bartimeu, ọmọ Timeu jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà ó ń ṣagbe.
Bartimeu afọ́jú gba ìwòsàn
47 (AA)Nígbà tí Bartimeu gbọ́ pé Jesu ti Nasareti wà nítòsí, o bẹ̀rẹ̀ sí kígbe lóhùn rara pé, “Jesu ọmọ Dafidi, ṣàánú fún mi.”
48 Àwọn tó wà níbẹ̀ kígbe mọ́ ọn pé, “Pa ẹnu rẹ mọ́.” Ṣùgbọ́n dípò kí ó pa ẹnu mọ́, ṣe ló ń kígbe lóhùn rara pé, “Jesu ọmọ Dafidi ṣàánú fún mi.”
49 Nígbà tí Jesu gbọ́ igbe rẹ̀, ó dẹ́sẹ̀ dúró lójú ọ̀nà, ó sì wí pé, “Ẹ pè é kí ó wá sọ́dọ̀ mi.”
Nítorí náà wọ́n pe ọkùnrin afọ́jú náà, wọ́n wí pé, “Tújúká! Dìde lórí ẹsẹ̀ rẹ! Ó ń pè ọ́.” 50 Lẹ́sẹ̀kan náà, Bartimeu bọ́ agbádá rẹ̀ sọnù, ó fò sókè, ó sì wá sọ́dọ̀ Jesu.
51 Jesu béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni ìwọ fẹ́ kí èmi kí ó ṣe fún ọ?”
Afọ́jú náà dáhùn pé, “Rabbi, jẹ́ kí èmi kí ó ríran.”
52 (AB)Jesu wí fún un pé, “Máa lọ, ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ láradá.” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ọkùnrin afọ́jú náà ríran ó sì ń tẹ̀lé Jesu lọ ní ọ̀nà.
Jesu fi ẹ̀yẹ wọ Jerusalẹmu bi ọba
11 (AC)Bí wọ́n ti súnmọ́ Betfage àti Betani ní ẹ̀yìn odi ìlú Jerusalẹmu, wọ́n dé orí òkè olifi. Jesu rán méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ síwájú. 2 Ó pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ lọ sí abúlé tó wà lọ́hùn ún nì. Nígbà tí ẹ bá sì wọlé, ẹ̀yin yóò rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí a so mọ́lẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò ì tí i gùn rí. Ẹ tú u, kí ẹ sì mú wá sí ibi yìí. 3 Bí ẹnikẹ́ni bá bi yín pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi ń ṣe èyí?’ Ẹ sọ fún un pé, ‘Olúwa ní í fi ṣe, yóò sì dá a padà síbí láìpẹ́.’ ”
4 (AD)Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì náà lọ bí ó ti rán wọn. Wọ́n rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà tí a so ní ẹnu-ọ̀nà lóde ní ìta gbangba, wọ́n sì tú u. 5 Bí wọ́n ti ń tú u, díẹ̀ nínú àwọn tí ó dúró níbẹ̀ bi wọ́n léèrè pé, “Ki ni ẹyin n ṣe, tí ẹ̀yin fi ń tú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ n nì?” 6 Wọ́n sì wí fún wọn gẹ́gẹ́ bí Jesu ti ní kí wọ́n sọ, wọ́n sì jọ̀wọ́ wọn lọ́wọ́ lọ. 7 (AE)Wọ́n fa ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà tọ Jesu wá. Wọ́n tẹ́ aṣọ wọn sí ẹ̀yìn rẹ̀, òun sì jókòó lórí rẹ̀. 8 Àwọn púpọ̀ tẹ́ aṣọ wọn sí ọ̀nà. Àwọn mìíràn ṣẹ́ ẹ̀ka igi, wọ́n sì fọ́n wọn sí ọ̀nà. 9 (AF)Àti àwọn tí ń lọ níwájú, àti àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn, gbogbo wọn sì ń kígbe wí pé,
“Hosana!”
“Olùbùkún ni ẹni náà tí ó ń bọ̀ wà ní orúkọ Olúwa!”
10 “Olùbùkún ni fún ìjọba tí ń bọ̀ wá, ìjọba Dafidi, baba wa!”
“Hosana lókè ọ̀run!”
11 (AG)Jesu wọ Jerusalẹmu ó sì lọ sí inú tẹmpili. Ó wo ohun gbogbo yíká fínní fínní. Ó sì kúrò níbẹ̀, nítorí pé ilẹ̀ ti ṣú. Ó padà lọ sí Betani pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá.
Jesu palẹ̀ tẹmpili mọ́
12 (AH)Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, bí wọ́n ti kúrò ní Betani, ebi ń pa Jesu. 13 Ó rí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan lọ́ọ̀ọ́kán tí ewé kún orí rẹ̀. Nígbà náà, ó lọ sí ìdí rẹ̀ láti wò ó bóyá ó léso tàbí kò léso. Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ewé lásán ni ó rí, kò rí èso lórí rẹ̀. Nítorí pé àkókò náà kì í ṣe àkókò tí igi ọ̀pọ̀tọ́ máa ń so. 14 Lẹ́yìn náà, Jesu pàṣẹ fún igi náà pé, “Kí ẹnikẹ́ni má ṣe jẹ èso lórí rẹ mọ́ títí láé.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbọ́ nígbà tí ó wí bẹ́ẹ̀.
15 (AI)Nígbà ti wọ́n padà sí Jerusalẹmu, ó wọ inú tẹmpili. Ó bẹ̀rẹ̀ sí nílé àwọn oníṣòwò àti àwọn oníbàárà wọn síta. Ó ti tábìlì àwọn tí ń pààrọ̀ owó nínú tẹmpili ṣubú. Bákan náà ni ó ti ìjókòó àwọn tí ń ta ẹyẹlé lulẹ̀. 16 Kò sì gba ẹnikẹ́ni láààyè láti gbé ẹrù ọjà títà gba inú tẹmpili wọlé. 17 (AJ)Gẹ́gẹ́ bí ó ti kọ́ wọn, ó wí pé, “Ṣé a kò ti kọ ọ́ pé: ‘Ilé àdúrà ni a o máa pe ilé mi, ní gbogbo orílẹ̀-èdè?’ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ibùgbé àwọn ọlọ́ṣà.”
18 Nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin gbọ́ ohun tí ó ti ṣe, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ń gbà èrò bí wọn yóò ti ṣe pa á. Wọ́n bẹ̀rù rògbòdìyàn tí yóò bẹ́ sílẹ̀, nítorí tí àwọn ènìyàn ní ìgbóná ọkàn sí ẹ̀kọ́ rẹ̀.
19 (AK)Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà, bí ìṣe wọn, Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ jáde kúrò ní ìlú Jerusalẹmu.
Igi ọ̀pọ̀tọ́ tí kò ní eṣo
20 (AL)Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, bí wọ́n ti ń kọjá lọ, wọ́n rí igi ọ̀pọ̀tọ́ tí Jesu fi bú. Wọ́n rí i pé ó ti gbẹ tigbòǹgbò tigbòǹgbò. 21 Peteru rántí pé Jesu ti bá igi náà wí. Nígbà náà ni ó sọ fún Jesu pé, “Rabbi, Wò ó! Igi ọ̀pọ̀tọ́ tí ìwọ fi bú ti gbẹ!”
22 Jesu sì dáhùn pé, “Ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, 23 Lóòótọ́ ni mò wí fún un yín, bí ẹnikẹ́ni bá wí fún òkè ‘ṣídìí, gbé ara rẹ sọ sínú Òkun’ ti kò sì ṣe iyèméjì nínú ọkàn rẹ̀ ṣùgbọ́n tí ó gbàgbọ́ pé ohun tí òun wí yóò ṣẹ, yóò rí bẹ́ẹ̀ fún un. 24 (AM)Torí náà, mo wí fún yín ohunkóhun tí ẹ bá béèrè fún nínú àdúrà, ẹ ní ìgbàgbọ́ pé, ó tí tẹ̀ yín lọ́wọ́, yóò sì jẹ́ tiyín. 25 (AN)Nígbà tí ẹ bá ń gbàdúrà, ẹ kọ́kọ́ dáríjì, bí ẹ̀yin bá ní ohunkóhun sí ẹnikẹ́ni, kí baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run bá à le dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tiyín náà jì yín. 26 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá dáríjì, Baba yín ti ń bẹ ni ọ̀run kí yóò dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín.”
27 (AO)Lẹ́yìn èyí, wọ́n tún padà sí Jerusalẹmu.
Ìbéèrè àṣẹ tí Jesu ní
Bí Jesu ti ń rìn kiri ni tẹmpili, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin pẹ̀lú àwọn àgbàgbà Júù wá sọ́dọ̀ rẹ̀. 28 Wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Àṣẹ wo ni ó fi ń ṣe nǹkan yìí? Ta ni ó sì fún ọ ni àṣẹ yìí láti máa ṣe nǹkan wọ̀nyí?”
29 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi yóò bi yín léèrè ọ̀rọ̀ kan, kí ẹ sì dá mi lóhùn, èmi yóò sọ fún yín àṣẹ tí èmi fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí.” 30 Ìtẹ̀bọmi Johanu láti ọ̀run wa ni, tàbí láti ọ̀dọ̀ ènìyàn? “Ẹ dá mi lóhùn!”
31 Wọ́n bá ara wọn jíròrò pé: “Bí a bá wí pé láti ọ̀run wá ni, òun ó wí pé, ‘nígbà tí ẹ mọ̀ bẹ́ẹ̀, èéṣe tí ẹ kò fi gbà à gbọ́?’ 32 Ṣùgbọ́n bí a bá wí pé, Láti ọ̀dọ̀ ènìyàn, wọ́n bẹ̀rù àwọn ènìyàn, nítorí pé gbogbo ènìyàn ló gbàgbọ́ pé wòlíì gidi ni Johanu.”
33 Nítorí náà, Wọ́n kọjú sí Jesu wọn sì dáhùn pé, “Àwa kò mọ̀.”
Nígbà náà ni Jesu wí pé, “Níwọ́n ìgbà tí ẹ kò lè dáhùn ìbéèrè mi, Èmi náà kì yóò sọ fún yín àṣẹ tí mo fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí.”
Òwe àwọn ayálégbé
12 (AP)Lẹ́yìn ìgbà tí Jesu pa àwọn olórí ẹ̀sìn lẹ́nu mọ́: ó bẹ̀rẹ̀ sí í fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ pé, “Ọkùnrin kan gbin ọgbà àjàrà kan. Ó ṣe ọgbà yìí ká, ó sì wá ibi ìfúntí wáìnì, ó sì kọ́ ilé ìṣọ́ sí i ó sì fi ṣe àgbàtọ́jú fún àwọn olùṣọ́gbà, ó sì lọ sí ìrìnàjò tí ó jìnnà. 2 Lákokò ìkórè, ọkùnrin náà rán ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ sí àwọn olùṣọ́gbà náà, kí ó gbà nínú èso ọgbà àjàrà náà lọ́wọ́ àwọn olùṣọ́gbà. 3 Ṣùgbọ́n àwọn àgbẹ̀ wọ̀n-ọn-nì lu ìránṣẹ́ ọkùnrin náà, wọ́n sì rán an padà lọ́wọ́ òfo. 4 Ó sì tún rán ọmọ ọ̀dọ̀ mìíràn sí wọn. Bí àwọn àgbẹ̀ ti tún rí ọmọ ọ̀dọ̀ tí ó rán sí wọn; wọ́n lù ú. Àní, wọ́n tilẹ̀ dá ọgbẹ́ sí i lórí, wọn rán an lọ ni ìtìjú. 5 Ó sì tún rán òmíràn, èyí n nì wọ́n sì pa, àti ọ̀pọ̀ mìíràn, wọ́n lu òmíràn wọ́n sì pa òmíràn.
6 “Ìránṣẹ́ kan ṣoṣo ló kù tí Baba olóko kò ì tí ì rán níṣẹ́, èyí ni ọmọ òun tìkára rẹ̀. Níkẹyìn ó ran an sí àwọn olùṣọ́gbà náà, pẹ̀lú èrò pé, ‘Wọn yóò bu ọlá fún ọmọ òun.’
7 “Ṣùgbọ́n àwọn olùṣọ́gbà wọ̀n-ọn-nì wí fún ara wọn pé, ‘Èyí yìí ni àrólé. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á, ogún rẹ̀ yóò sì jẹ́ tiwa.’ 8 Báyìí ni wọ́n mú ọmọ náà tí wọ́n pa á. Wọ́n sì wọ́ òkú rẹ̀ jáde kúrò nínú ọgbà àjàrà náà.
9 “Kí ni olúwa ọgbà àjàrà yóò ṣe nígbà tí ó bá gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Dájúdájú yóò pa àwọn ẹni ibi wọ̀nyí. Yóò sì gba àwọn olùtọ́jú mìíràn sínú oko rẹ̀. 10 (AQ)Tàbí ẹ̀yin kò ì tí ka ẹsẹ yìí nínú ìwé mímọ́:
“ ‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀
òun náà ni ó di pàtàkì igun ilé.
11 Èyí ni iṣẹ́ Olúwa
ó sì jẹ́ ìyàlẹ́nu lójú tiwa’?”
12 (AR)Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin pẹ̀lú àwọn àgbàgbà fẹ́ mú Jesu lákokò náà. Nítorí tí wọ́n mọ̀ pé àwọn ló ń pòwe mọ́ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀. Àwọn ni alágbàtọ́jú búburú nínú ìtàn rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹ̀rù ń bà wọ́n láti fọwọ́ kàn án nítorí pé wọ́n bẹ̀rù ìhùwàsí ọ̀pọ̀ ènìyàn tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Nítorí náà wọ́n fi í sílẹ̀ lọ.
Sísan owó orí fún Kesari
13 (AS)(AT) Ṣùgbọ́n wọ́n rán àwọn Farisi pẹ̀lú àwọn kan tí í ṣe ọmọ-ẹ̀yìn Herodu wá sọ́dọ̀ Jesu, láti fi ọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò, títí yóò fi sọ ohun kan kí wọn lè rí fi mú. 14 Bí wọn ti dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n wí pé: “Olùkọ́, àwa mọ̀ pé ìwọ máa ń sọ òtítọ́ láìsí ìbẹ̀rù ẹnikẹ́ni. Ṣùgbọ́n òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ìwọ máa ń kọ́ni. Nísinsin yìí, sọ fún wa, ó tọ́ tàbí kò tọ́ láti máa san owó orí fún Kesari?” 15 Kí àwa kí ó fi fún un, tàbí kí a máa fi fún un?
Ṣùgbọ́n Jesu mọ ìwà àgàbàgebè wọn. Ó sì wí pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi n fi èyí dán mi wo? Ẹ mú owó idẹ kan wá kí n wò ó.” 16 Nígbà tí wọ́n mú owó idẹ náà fún un, ó bi wọ́n léèrè pé, “Ẹ wò ó! Àwòrán àti orúkọ ta ni ó wà níbẹ̀?”
Wọ́n dáhùn pé, “Àwòrán àti orúkọ Kesari ni.”
17 (AU)Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ fi ohun tí ó bá jẹ́ ti Kesari fún Kesari. Ṣùgbọ́n ẹ fi ohun gbogbo tí í ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”
Ẹnu sì yà wọ́n gidigidi sí èsì rẹ̀.
Ìgbéyàwó ní àjíǹde
18 (AV)Àwọn Sadusi tún wá sọ́dọ̀ rẹ̀, àwọn wọ̀nyí kò gbàgbọ́ pé àjíǹde ń bẹ. Ìbéèrè wọn ni pé, 19 (AW)“Olùkọ́, Mose fún wa ní òfin pé: Nígbà tí ọkùnrin kan bá kú láìbí ọmọ, arákùnrin rẹ̀ gbọdọ̀ ṣú ìyàwó náà lópó kí wọn sì bímọ ní orúkọ ọkọ tí ó kú náà. 20 Ǹjẹ́ àwọn arákùnrin méje kan wà, èyí tí ó dàgbà jùlọ gbéyàwó, ó sì kú ní àìlọ́mọ. 21 Arákùnrin rẹ̀ kejì ṣú obìnrin tí ó fi sílẹ̀ lópó, láìpẹ́, òun pẹ̀lú tún kú láìbímọ. Arákùnrin kẹta tó ṣú obìnrin yìí lópó tún kú bákan náà láìbímọ. 22 Àwọn méjèèje sì ṣú u lópó, wọn kò sì fi ọmọ sílẹ̀. Ní ìkẹyìn gbogbo wọn, obìnrin náà kú pẹ̀lú. 23 Ǹjẹ́ ní àjíǹde, nígbà tí wọ́n bá jíǹde, aya ta ni yóò ha ṣe nínú wọn? Àwọn méjèèje ni ó sá ni ní aya?”
24 Jesu dáhùn ó wí fún wọn pé, “Kì í há ṣe nítorí èyí ni ẹ ṣe ṣìnà, pé ẹ̀yin kò mọ ìwé Mímọ́, tàbí agbára Ọlọ́run. 25 Nítorí pé, nígbà tí àwọn arákùnrin méje yìí àti obìnrin náà bá jí dìde nínú òkú, a kò ní ṣe ìgbéyàwó fún wọn. Wọn yóò dàbí àwọn angẹli tí ń bẹ ní ọ̀run. 26 (AX)Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, nípa bóyá àjíǹde yóò wà. Àbí ẹ̀yin kò ì tí ka ìwé Eksodu, nípa Mose àti pápá tí ń jó? Ọlọ́run sọ fún Mose pé, ‘Èmi ni Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki àti Ọlọ́run Jakọbu.’ 27 Òun kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú bí kò ṣe Ọlọ́run àwọn alààyè: nítorí ẹ̀yin ṣe àṣìṣe gidigidi.”
Òfin tí ó ga jùlọ
28 (AY)Ọ̀kan nínú àwọn olùkọ́ òfin ti ó dúró níbẹ̀ tí ó sì fetísílẹ̀ dáradára sí àròyé yìí ṣàkíyèsí pé, Jesu ti dáhùn dáradára. Òun pẹ̀lú sì béèrè lọ́wọ́ Jesu pé, “Nínú gbogbo òfin, èwo ló ṣe pàtàkì jùlọ?”
29 (AZ)Jesu dá ọkùnrin yìí lóhùn pé, “Èyí tó ṣe pàtàkì jùlọ nínú àwọn òfin ni èyí tí ó kà báyìí pé: ‘Gbọ́ Israẹli; Olúwa Ọlọ́run wa Olúwa kan ni. 30 Kí ìwọ kí ó fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo ẹ̀mí rẹ, àti gbogbo agbára rẹ fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ, èyí ní òfin kìn-ín-ní.’ 31 (BA)Èkejì ni pé: ‘Fẹ́ ọmọnìkejì rẹ.’ Kò sí òfin mìíràn tó ga ju méjèèjì yìí lọ.”
32 Olùkọ́ òfin náà dáhùn pé, “Olùkọ́, ìwọ sọ òtítọ́ nípa pé Ọlọ́run kan ni ó ń bẹ, àti pé kò sí òmíràn àfi òun nìkan. 33 (BB)Àti kí a fi gbogbo àyà, àti gbogbo òye, àti gbogbo ọkàn àti gbogbo agbára fẹ́ ẹ, àti fẹ́ ọmọnìkejì ẹni bí ara ẹni, ó ju gbogbo ẹbọ sísun, àti ẹbọ lọ.”
34 Jesu rí i dájú pé òye ọkùnrin yìí ga, nítorí náà, Jesu sọ fún un pé, “Arákùnrin, ìwọ kò jìnà sí à ti dé ìjọba Ọ̀run.” Láti ìgbà náà lọ, ẹnikẹ́ni kò tún béèrè ohun kan lọ́wọ́ Jesu.
Ọmọ ta ni Kristi ń ṣe?
35 (BC)Lẹ́yìn náà, nígbà tí Jesu ń kọ́ àwọn ènìyàn nínú tẹmpili, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èéṣe tí àwọn olùkọ́ òfin fi gbà wí pé Kristi náà ní láti jẹ́ ọmọ Dafidi? 36 (BD)Nítorí tí Dafidi tìkára rẹ̀, ti ń ti ipa Ẹ̀mí Mímọ́ sọ̀rọ̀ wí pé:
“ ‘Olúwa sọ fún Olúwa mi pé:
“Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi,
títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ
di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.” ’
37 Níwọ́n ìgbà tí Dafidi tìkára rẹ̀ pè é ní ‘Olúwa,’ Báwo ni ó túnṣe lè jẹ́ ọmọ rẹ̀?”
Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì fi ayọ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.
38 (BE)Ó sì wí fún wọn nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ pé, “Ẹ ṣọ́ra fun àwọn olùkọ́ òfin tí wọ́n fẹ́ láti máa wọ aṣọ gígùn káàkiri, tí wọ́n sì fẹ́ ìkíni ní ọjà, 39 àti ibùjókòó ọlá nínú Sinagọgu àti ipò ọlá níbi àsè. 40 Àwọn tí wọ́n jẹ ilé àwọn opó rún, tí wọ́n sì ń gbàdúrà gígùn fún àṣehàn, nítorí èyí, ìjìyà wọn yóò pọ̀ púpọ̀.”
Ọ̀rẹ́ opó
41 (BF)Jesu jókòó ní òdìkejì kọjú sí àpótí ìṣúra: ó ń wo ìjọ ènìyàn ti ń sọ owó sínú àpótí ìṣúra, ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́rọ̀ sì sọ púpọ̀ sí i. 42 Ṣùgbọ́n obìnrin opó kan wà, ó sì fi ààbọ̀ owó idẹ méjì síbẹ̀, tí ì ṣe ìdá méjì owó-babà kan sínú rẹ̀.
43 Jesu pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sọ fún wọn wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yin pé, tálákà opó yìí sọ sínú àpótí ìṣúra ju gbogbo àwọn ìyókù to sọ sínú rẹ lọ. 44 Nítorí pé, àwọn ìyókù mú nínú ọ̀pọ̀ ìní wọ́n, ṣùgbọ́n ní tirẹ̀, nínú àìní rẹ̀, ó sọ gbogbo ohun tí ó ní náà sílẹ̀ àní gbogbo ìní rẹ̀.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.