Add parallel Print Page Options

Fífi ayọ̀ wọlé

21 (A)Bí wọ́n ti súnmọ́ Jerusalẹmu, tí wọ́n dé itòsí ìlú Betfage ní orí òkè Olifi, Jesu sì rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì, Ó wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sí ìletò tó wà ni tòsí yín, ẹ̀yin yóò rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan ti wọ́n so pẹ̀lú ọmọ rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ẹ tú wọn, kí ẹ sì mú wọn wá fún mi. Bí ẹnikẹ́ni bá sì béèrè ìdí tí ẹ fi ń ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ sá à wí pé, Olúwa fẹ́ lo wọn, òun yóò sì rán wọn lọ.”

Èyí ṣẹlẹ̀ láti mú àsọtẹ́lẹ̀ wòlíì ṣẹ pé:

(B)“Ẹ sọ fún ọmọbìnrin Sioni pé,
    ‘Wò ó, ọba rẹ ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ,
ní ìrẹ̀lẹ̀, ó ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,
    àti lórí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.’ ”

Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà sí lọ, wọ́n ṣe bí Jesu ti sọ fún wọn Wọ́n sì mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà pẹ̀lú ọmọ rẹ̀, wọ́n tẹ́ aṣọ lé e, Jesu si jókòó lórí rẹ̀. (C)Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì tẹ́ aṣọ wọn sí ojú ọ̀nà níwájú rẹ̀, ẹlòmíràn ṣẹ́ ẹ̀ka igi wẹ́wẹ́ wọ́n sì tẹ́ wọn sí ojú ọ̀nà. (D)Ọ̀pọ̀ ènìyàn ń lọ níwájú rẹ̀ àti lẹ́yìn rẹ̀ pẹ̀lú ń kígbe pé,

“Hosana fún ọmọ Dafidi!”

“Olùbùkún ni fún ẹni tí ó ń bọ̀ ní orúkọ Olúwa!”

“Hosana ní ibi gíga jùlọ!”

Read full chapter

29 (A)Ó sì ṣe, nígbà tí ó súnmọ́ Betfage àti Betani ní òkè tí a ń pè ní òkè olifi, ó rán àwọn méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. 30 Wí pé, “Ẹ lọ sí ìletò tí ó kọjú sí yín; nígbà tí ẹ̀yin bá wọ̀ ọ́ lọ, ẹ̀yin ó rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí a so, tí ẹnikẹ́ni kò gùn rí: ẹ tú u, kí ẹ sì fà á wá. 31 Bí ẹnikẹ́ni bá sì bi yín pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń tú u?’ Kí ẹ̀yin wí báyìí pé, ‘Olúwa ń fẹ́ lò ó.’ ”

32 (B)Àwọn tí a rán sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n, wọ́n sì bá a gẹ́gẹ́ bí ó ti wí fún wọn. 33 Bí wọ́n sì ti ń tú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà, àwọn Olúwa rẹ̀ bi wọ́n pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń tu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà?”

34 (C)Wọ́n sì wí pé, “Olúwa fẹ́ lò ó.”

35 Wọ́n sì fà á tọ Jesu wá, wọ́n sì tẹ́ aṣọ sí ẹ̀yìn ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà, wọ́n sì gbé Jesu kà á. 36 (D)Bí ó sì ti ń lọ wọ́n tẹ́ aṣọ wọn sí ọ̀nà.

37 Bí ó sì ti súnmọ́ etí ibẹ̀ ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè olifi, gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn bẹ̀rẹ̀ sí í yọ̀, wọ́n sì fi ohùn rara yin Ọlọ́run, nítorí iṣẹ́ ńlá gbogbo tí wọ́n ti rí;

38 (E)Wí pé, “Olùbùkún ni ọba tí ó ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa!”

“Àlàáfíà ní ọ̀run, àti ògo ni òkè ọ̀run!”

Read full chapter