Add parallel Print Page Options

Fífi ayọ̀ wọlé

21 (A)Bí wọ́n ti súnmọ́ Jerusalẹmu, tí wọ́n dé itòsí ìlú Betfage ní orí òkè Olifi, Jesu sì rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì, Ó wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sí ìletò tó wà ni tòsí yín, ẹ̀yin yóò rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan ti wọ́n so pẹ̀lú ọmọ rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ẹ tú wọn, kí ẹ sì mú wọn wá fún mi. Bí ẹnikẹ́ni bá sì béèrè ìdí tí ẹ fi ń ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ sá à wí pé, Olúwa fẹ́ lo wọn, òun yóò sì rán wọn lọ.”

Èyí ṣẹlẹ̀ láti mú àsọtẹ́lẹ̀ wòlíì ṣẹ pé:

(B)“Ẹ sọ fún ọmọbìnrin Sioni pé,
    ‘Wò ó, ọba rẹ ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ,
ní ìrẹ̀lẹ̀, ó ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,
    àti lórí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.’ ”

Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà sí lọ, wọ́n ṣe bí Jesu ti sọ fún wọn Wọ́n sì mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà pẹ̀lú ọmọ rẹ̀, wọ́n tẹ́ aṣọ lé e, Jesu si jókòó lórí rẹ̀. (C)Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì tẹ́ aṣọ wọn sí ojú ọ̀nà níwájú rẹ̀, ẹlòmíràn ṣẹ́ ẹ̀ka igi wẹ́wẹ́ wọ́n sì tẹ́ wọn sí ojú ọ̀nà. (D)Ọ̀pọ̀ ènìyàn ń lọ níwájú rẹ̀ àti lẹ́yìn rẹ̀ pẹ̀lú ń kígbe pé,

“Hosana fún ọmọ Dafidi!”

“Olùbùkún ni fún ẹni tí ó ń bọ̀ ní orúkọ Olúwa!”

“Hosana ní ibi gíga jùlọ!”

Read full chapter

Jesu fi ẹ̀yẹ wọ Jerusalẹmu bi ọba

11 (A)Bí wọ́n ti súnmọ́ Betfage àti Betani ní ẹ̀yìn odi ìlú Jerusalẹmu, wọ́n dé orí òkè olifi. Jesu rán méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ síwájú. Ó pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ lọ sí abúlé tó wà lọ́hùn ún nì. Nígbà tí ẹ bá sì wọlé, ẹ̀yin yóò rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí a so mọ́lẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò ì tí i gùn rí. Ẹ tú u, kí ẹ sì mú wá sí ibi yìí. Bí ẹnikẹ́ni bá bi yín pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi ń ṣe èyí?’ Ẹ sọ fún un pé, ‘Olúwa ní í fi ṣe, yóò sì dá a padà síbí láìpẹ́.’ ”

(B)Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì náà lọ bí ó ti rán wọn. Wọ́n rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà tí a so ní ẹnu-ọ̀nà lóde ní ìta gbangba, wọ́n sì tú u. Bí wọ́n ti ń tú u, díẹ̀ nínú àwọn tí ó dúró níbẹ̀ bi wọ́n léèrè pé, “Ki ni ẹyin n ṣe, tí ẹ̀yin fi ń tú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ n nì?” Wọ́n sì wí fún wọn gẹ́gẹ́ bí Jesu ti ní kí wọ́n sọ, wọ́n sì jọ̀wọ́ wọn lọ́wọ́ lọ. (C)Wọ́n fa ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà tọ Jesu wá. Wọ́n tẹ́ aṣọ wọn sí ẹ̀yìn rẹ̀, òun sì jókòó lórí rẹ̀. Àwọn púpọ̀ tẹ́ aṣọ wọn sí ọ̀nà. Àwọn mìíràn ṣẹ́ ẹ̀ka igi, wọ́n sì fọ́n wọn sí ọ̀nà. (D)Àti àwọn tí ń lọ níwájú, àti àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn, gbogbo wọn sì ń kígbe wí pé,

“Hosana!”

“Olùbùkún ni ẹni náà tí ó ń bọ̀ wà ní orúkọ Olúwa!”

10 “Olùbùkún ni fún ìjọba tí ń bọ̀ wá, ìjọba Dafidi, baba wa!”

“Hosana lókè ọ̀run!”

Read full chapter

Jesu gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ Jerusalẹmu

12 (A)Ní ọjọ́ kejì nígbà tí ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó wá sí àjọ gbọ́ pé, Jesu ń bọ̀ wá sí Jerusalẹmu. 13 (B)Wọ́n mú imọ̀ ọ̀pẹ, wọ́n sì jáde lọ pàdé rẹ̀, wọ́n sì ń kígbe pé,

“Hosana!”

“Olùbùkún ni ẹni tí ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa!”

“Olùbùkún ni ọba Israẹli!”

14 Nígbà tí Jesu sì rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan, ó gùn ún; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé pé,

15 (C)“Má bẹ̀rù, ọmọbìnrin Sioni;
    Wò ó, ọba rẹ ń bọ̀ wá,
    o jókòó lórí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.”

16 (D)Nǹkan wọ̀nyí kò tètè yé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀: ṣùgbọ́n nígbà tí a ṣe Jesu lógo, nígbà náà ni wọ́n rántí pé, a kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí nípa rẹ̀ sí i.

17 Nítorí náà, ìjọ ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tí o pé Lasaru jáde nínú ibojì rẹ̀, tí ó sì jí i dìde kúrò nínú òkú, jẹ́rìí sí i. 18 Nítorí èyí ni ìjọ ènìyàn sì ṣe lọ pàdé rẹ̀, nítorí tí wọ́n gbọ́ pé ó ti ṣe iṣẹ́ ààmì yìí.

Read full chapter