Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Chronological

Read the Bible in the chronological order in which its stories and events occurred.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Ìfihàn 1-5

Ọ̀rọ̀ ìṣáájú

Ìfihàn ti Jesu Kristi, tí Ọlọ́run fi fún un, láti fihàn fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ohun tí kò le ṣàìṣẹ ní lọ́ọ́lọ́ọ́; ó sì ránṣẹ́, ó sì fi í hàn láti ọwọ́ angẹli rẹ̀ wá fún Johanu, ìránṣẹ́ rẹ̀: Ẹni tí ó jẹ́rìí ohun gbogbo tí ó rí—èyí ì ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti ẹ̀rí ti Jesu Kristi. Ẹni ìbùkún ni ẹni tí ń kà, àti àwọn tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ yìí, tí ó sì ń pa nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí a kọ sínú rẹ̀ mọ́: nítorí ìgbà kù sí dẹ̀dẹ̀.

Ọ̀rọ̀ ìkíni àti ìyìn

(A)Johanu,

Sí àwọn ìjọ méje tí ń bẹ ní Asia:

Oore-ọ̀fẹ́ fún yín, àti àlàáfíà, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ń bẹ, tí ó sì ti wà, tí ó sì ń bọ̀ wá; àti láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀mí méje tí ń bẹ níwájú ìtẹ́ rẹ̀; (B)àti láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi, ẹlẹ́rìí olóòtítọ́, àkọ́bí nínú àwọn òkú, àti aláṣẹ àwọn ọba ayé.

Ẹni tí ó fẹ́ wa, ẹni tí ó gbà wá kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, (C)tí ó sì ti fi wá jẹ ọba àti àlùfáà láti sin Ọlọ́run àti Baba rẹ; tirẹ̀ ni ògo àti ìjọba láé àti láéláé. Àmín.

(D)Kíyèsi i, o ń bọ̀ nínú àwọsánmọ̀;
    gbogbo ojú ni yóò sì rí i,
àti àwọn tí ó gún un ní ọ̀kọ̀ pẹ̀lú;
    àti gbogbo orílẹ̀-èdè ayé ni yóò sì máa pohùnréré ẹkún nítorí rẹ̀.
Bẹ́ẹ̀ náà ni! Àmín.

(E) “Èmi ni Alfa àti Omega,” ni Olúwa Ọlọ́run wí, “ẹni tí ó ń bẹ, tí ó ti wà, tí ó sì ń bọ̀ wá, alágbára.”

Ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí Ọmọ ènìyàn

Èmi, Johanu, arákùnrin yín àti alábápín pẹ̀lú yín nínú wàhálà àti ìjọba àti sùúrù tí ń bẹ nínú Jesu, wà ní erékúṣù tí a ń pè ní Patmo, nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti nítorí ẹ̀rí Jesu Kristi. 10 Mo wà nínú Ẹ̀mí ní ọjọ́ Olúwa, mo sì gbọ́ ohùn ńlá kan lẹ́yìn mi, bí ìró ìpè, 11 Ó ń wí pé, “Kọ́ ìwé rẹ̀, ohun tí ìwọ rí, kí ó sí fi ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ méje; sí Efesu, àti sí Smirna, àti sí Pargamu, àti sí Tiatira, àti sí Sardi, àti sí Filadelfia, àti sí Laodikea.”

12 Mo sì yí padà láti wo ohùn tí ń bá mi sọ̀rọ̀. Nígbà tí mo yípadà, mo rí ọ̀pá fìtílà wúrà méje; 13 (F)àti láàrín àwọn ọ̀pá fìtílà náà, ẹnìkan tí ó dàbí “ọmọ ènìyàn,” tí a wọ̀ ní aṣọ tí ó kanlẹ̀ dé ẹsẹ̀, tí a sì fi àmùrè wúrà dì ní ẹ̀gbẹ́. 14 Orí rẹ̀ àti irun rẹ̀ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú, ó funfun bí yìnyín; ojú rẹ̀ sì dàbí, ọwọ́ iná; 15 (G)Ẹsẹ̀ rẹ̀ sì dàbí idẹ dáradára, bí ẹni pé a dà á nínú ìléru; ohùn rẹ̀ sì dàbí ìró omi púpọ̀. 16 (H)Ó sì ní ìràwọ̀ méje ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀; àti láti ẹnu rẹ̀ wá ni idà olójú méjì mímú ti jáde: Ojú rẹ̀ sì dàbí oòrùn tí ó ń fi agbára rẹ̀ hàn.

17 (I)Nígbà tí mo rí i, mo wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀ bí ẹni tí ó kú. Ó sì fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ lé mi, ó ń wí fún mi pé, “Má ṣe bẹ̀rù. Èmi ni ẹni ìṣáájú àti ẹni ìkẹyìn. 18 Èmi ni ẹni tí ó ń bẹ láààyè, tí ó sì ti kú; sì kíyèsi i, èmi sì ń bẹ láààyè sí i títí láé! Mo sì ní kọ́kọ́rọ́ ikú àti ti ipò òkú lọ́wọ́.

19 “Kọ̀wé nítorí náà ohun tí ìwọ ti rí, àti ti ohun tí ń bẹ, àti ti ohun tí yóò hù lẹ́yìn èyí; 20 ohun ìjìnlẹ̀ tí ìràwọ̀ méje náà tí ìwọ rí ní ọwọ́ ọ̀tún mi, àti ọ̀pá wúrà fìtílà méje náà. Ìràwọ̀ méje ni àwọn angẹli ìjọ méje náà: àti ọ̀pá fìtílà méje náà ní àwọn ìjọ méje.

Sí ìjọ Efesu

“Sí angẹli ìjọ ní Efesu kọ̀wé:

Nǹkan wọ̀nyí ní ẹni tí ó mú ìràwọ̀ méje náà ni ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ wí, ẹni tí ń rìn ní àárín ọ̀pá wúrà fìtílà méje:

Èmi mọ iṣẹ́ rẹ, àti làálàá rẹ, àti ìfaradà rẹ, àti bí ara rẹ kò ti gba àwọn ẹni búburú: àti bí ìwọ sì ti dán àwọn tí ń pe ara wọn ní aposteli, tí wọ́n kì í sì í ṣe bẹ́ẹ̀ wo, tí ìwọ sì rí pé èké ni wọ́n; Tí ìwọ sì faradà ìyà, àti nítorí orúkọ mi tí ó sì rọ́jú, tí àárẹ̀ kò sì mú ọ.

Síbẹ̀ èyí ni mo rí wí sí ọ, pé, ìwọ ti fi ìfẹ́ ìṣáájú rẹ sílẹ̀. Rántí ibi tí ìwọ ti gbé ṣubú! Ronúpìwàdà, kí ó sì ṣe iṣẹ́ ìṣáájú; bí kò sì ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ó sì tọ̀ ọ́ wá, èmi ó sì ṣí ọ̀pá fìtílà rẹ̀ kúrò ní ipò rẹ̀, bí kò ṣe bí ìwọ bá ronúpìwàdà. Ṣùgbọ́n èyí ni ìwọ ní, pé ìwọ kórìíra ìṣe àwọn Nikolatani, èyí tí èmi pẹ̀lú sì kórìíra.

(J)Ẹni tí ó bá ní etí kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ. Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun ni èmi yóò fi èso igi ìyè nì fún jẹ, tí ń bẹ láàrín Paradise Ọlọ́run.

Sí Ìjọ ní Smirna

(K)“Àti sí angẹli ìjọ ní Smirna kọ̀wé:

Nǹkan wọ̀nyí ni ẹni tí í ṣe ẹni ìṣáájú àti ẹni ìkẹyìn wí, ẹni tí ó ti kú, tí ó sì tún yè:

Èmi mọ iṣẹ́ rẹ, àti ìpọ́njú, àti àìní rẹ—ṣùgbọ́n ọlọ́rọ̀ ni ọ́, èmi sì mọ ọ̀rọ̀-òdì tí àwọn tí ń wí pé, Júù ni àwọn tìkára wọn, tí wọn kì sì í ṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n tí wọ́n jẹ́ Sinagọgu ti Satani. 10 (L)Má ṣe bẹ̀rù ohunkóhun tí ìwọ ń bọ wá jìyà rẹ̀. Kíyèsi i, èṣù yóò gbé nínú yín jù sínú túbú, kí a lè dán yin wò; ẹ̀yin ó sì ní ìpọ́njú ní ọjọ́ mẹ́wàá: ìwọ ṣa ṣe olóòtítọ́ dé ojú ikú, èmi ó sì fi adé ìyè fún ọ.

11 Ẹni tí ó bá ní etí kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ. Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun kì yóò fi ara pa nínú ikú kejì.

Sí ìjọ ní Pargamu

12 “Àti sì angẹli ìjọ ni Pargamu kọ̀wé:

Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ẹni tí ó ní idà mímú olójú méjì.

13 Èmí mọ̀ ibi tí ìwọ ń gbé, àní ibi tí ìtẹ́ Satani wà. Síbẹ̀ ìwọ di orúkọ mi mú ṣinṣin. Ìwọ kò sì sẹ́ ìgbàgbọ́ nínú mi, pàápàá jùlọ ni ọjọ́ Antipa ẹlẹ́rìí mi, olóòtítọ́ ènìyàn, ẹni tí wọn pa láàrín yín, níbi tí Satani ń gbé.

14 (M)Ṣùgbọ́n mo ni nǹkan díẹ̀ wí sí ọ; nítorí tí ìwọ ní àwọn kan tí ó di ẹ̀kọ́ Balaamu mú síbẹ̀, ẹni tí ó kọ́ Balaki láti mú ohun ìkọ̀sẹ̀ wá síwájú àwọn ọmọ Israẹli, láti máa jẹ ohun tí a pa rú ẹbọ sí òrìṣà, àti láti máa ṣe àgbèrè. 15 Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ sì ní àwọn tí ó gbá ẹ̀kọ́ àwọn Nikolatani pẹ̀lú, ohun tí mo kórìíra. 16 Nítorí náà, ronúpìwàdà; bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ó tọ̀ ọ́ wá nísinsin yìí, èmí o sì fi idà ẹnu mi bá wọn jà.

17 (N)Ẹni tí ó bá létí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ; Ẹni tí o bá ṣẹ́gun ni èmi o fi manna tí ó pamọ́ fún, èmi ó sì fún un ni òkúta funfun kan, àti sára òkúta náà ni a kọ orúkọ tuntun kan, tí ẹnìkan kò mọ̀ bí kò ṣe ẹni tí ó gbà á.

Sí ìjọ ni Tiatira

18 (O)“Àti sí angẹli ìjọ ní Tiatira kọ̀wé:

Nǹkan wọ̀nyí ni Ọmọ Ọlọ́run wí, ẹni tí ojú rẹ̀ dàbí ọ̀wọ́-iná, tí ẹsẹ̀ rẹ̀ sì dàbí idẹ dáradára:

19 Èmi mọ̀ iṣẹ́, ìfẹ́, àti ìgbàgbọ́ àti ìsìn àti sùúrù rẹ̀; àti pé iṣẹ́ rẹ̀ ìkẹyìn ju tí ìṣáájú lọ.

20 (P)Ṣùgbọ́n èyí ni mo rí wí sí ọ: nítorí tí ìwọ fi ààyè sílẹ̀ fún obìnrin Jesebeli tí ó ń pe ara rẹ̀ ní wòlíì. Nípasẹ̀ ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó sì ń kọ́ àwọn ìránṣẹ́ mi, ó sì ń tàn wọ́n láti máa ṣe àgbèrè, àti láti máa jẹ ohun tí a pa rú ẹbọ sì òrìṣà. 21 Èmi fi àkókò fún un, láti ronúpìwàdà; ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ ronúpìwàdà àgbèrè rẹ̀. 22 Nítorí náà, èmi ó gbé e sọ sí orí àkéte ìpọ́njú, àti àwọn tí ń bá a ṣe panṣágà ni èmi ó fi sínú ìpọ́njú ńlá, bí kò ṣe bí wọ́n bá ronúpìwàdà iṣẹ́ wọn. 23 (Q)Èmi o pa àwọn ọmọ rẹ̀ run; gbogbo ìjọ ni yóò sì mọ̀ pé, èmi ni ẹni tí ń wádìí inú àti ọkàn: èmi ó sì fi fún olúkúlùkù yín gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.

24 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni mò ń sọ fún, ẹ̀yin ìyókù tí ń bẹ ní Tiatira, gbogbo ẹ̀yin tí kò ni ẹ̀kọ́ yìí, ti kò ì tí ì mọ̀ ohun tí wọn pè ni ohun ìjìnlẹ̀ Satani, èmi kò di ẹrù mìíràn rù yín: 25 Ṣùgbọ́n èyí tí ẹ̀yin ní, ẹ di mú ṣinṣin títí èmi ó fi dé.

26 (R)Ẹni tí ó bá sì ṣẹ́gun, àti tí ó sì ṣe ìfẹ́ mi títí dé òpin, èmi ó fún un láṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè: 27 ‘Òun ó sì máa fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn; gẹ́gẹ́ bí a ti ń fọ́ ohun èlò amọ̀kòkò ni a ó fọ́ wọn túútúú,’ gẹ́gẹ́ bí èmi pẹ̀lú tí gbà àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Baba mi. 28 Èmi yóò sì fi ìràwọ̀ òwúrọ̀ fún un. 29 Ẹni tí ó bá létí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.

Sí ìjọ ní Sardi

“Àti sí angẹli ìjọ ni Sardi kọ̀wé:

Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ẹni tí ó ni Ẹ̀mí méje Ọlọ́run, àti ìràwọ̀ méje wí pé:

Èmi mọ iṣẹ́ rẹ̀, àti pé ìwọ ní orúkọ pé ìwọ ń bẹ láààyè, ṣùgbọ́n ìwọ ti kú. Jí, kí o sì fi ẹsẹ̀ ohun tí ó kù múlẹ̀, tàbí tí ó ṣetán láti kú: Nítorí èmi kò rí iṣẹ́ rẹ ni pípé níwájú Ọlọ́run. Nítorí náà rántí bí ìwọ ti gbà, àti bí ìwọ ti gbọ́, kí o sì pa á mọ́, kí o sì ronúpìwàdà. Ǹjẹ́, bí ìwọ kò ba ṣọ́ra, èmi yóò dé sí ọ bí olè, ìwọ kì yóò sì mọ́ wákàtí tí èmi yóò dé sí ọ.

Ìwọ ní orúkọ díẹ̀ ní Sardi, tí kò fi aṣọ wọn yí èérí; wọn yóò sì máa ba mi rìn ní aṣọ funfun: nítorí wọ́n yẹ. (S)Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun, òun náà ni a ó fi aṣọ funfun wọ̀; èmi kì yóò pa orúkọ rẹ̀ kúrò nínú ìwé ìyè, ṣùgbọ́n èmi yóò jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀ níwájú Baba mi, àti níwájú àwọn angẹli rẹ̀. Ẹni tí ó ba létí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.

Sí ìjọ Filadelfia

(T)“Àti sí angẹli Ìjọ ni Filadelfia kọ̀wé:

Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ẹni tí ó jẹ́ mímọ́ náà wí, ẹni tí ó ṣe olóòtítọ́, ẹni tí ó ní kọ́kọ́rọ́ Dafidi, ẹni tí ó ṣí, tí kò sí ẹni tí yóò tì; ẹni tí o sì tì, tí kò sì ẹni tí yóò ṣí i:

Èmi mọ iṣẹ́ rẹ̀: kíyèsi i, mo gbe ìlẹ̀kùn tí ó ṣí kálẹ̀ níwájú rẹ̀, tí kò sí ẹni tí o lè tì í; pé ìwọ ni agbára díẹ̀, ìwọ sì pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, ìwọ kò sì sẹ́ orúkọ mi. (U)Kíyèsi i, èmi ó mú àwọn ti Sinagọgu Satani, àwọn tí wọ́n ń wí pé Júù ni àwọn, tí wọn kì í sì ṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n tí wọn ń ṣèké; kíyèsi i, èmi ó mú kí wọn wá wólẹ̀ níwájú ẹsẹ̀ rẹ̀, kí wọn sì mọ̀ pé èmi tí fẹ́ ọ. 10 Nítorí tí ìwọ tí pa ọ̀rọ̀ sùúrù mi mọ́, èmi pẹ̀lú yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú wákàtí ìdánwò, tí ń bọ̀ wá dé bá gbogbo ayé, láti dán àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé wò.

11 Kíyèsi i, èmi ń bọ̀ kánkán: di èyí ti ìwọ ní mú ṣinṣin, kí ẹnikẹ́ni má ṣe gba adé rẹ. 12 (V)Ẹni tí ó ba ṣẹ́gun, òun ni èmi ó fi ṣe ọ̀wọ́n nínú tẹmpili Ọlọ́run mi, òun kì yóò sì jáde kúrò níbẹ̀ mọ́: èmi ó sì kọ orúkọ Ọlọ́run mi sí i lára, àti orúkọ ìlú Ọlọ́run mi, tí i ṣe Jerusalẹmu tuntun, tí ó ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run mi wá: àti orúkọ tuntun ti èmi tìkára mi. 13 Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun ti Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.

Sí ìjọ Laodikea

14 (W)“Àti sí angẹli ìjọ ní Laodikea kọ̀wé:

Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ẹni tí ń jẹ́ Àmín wí, ẹlẹ́rìí olódodo àti olóòtítọ́, olórí ìṣẹ̀dá Ọlọ́run:

15 Èmi mọ̀ iṣẹ́ rẹ, pé ìwọ kò gbóná bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò tútù: èmi ìbá fẹ́ pé kí ìwọ kúkú tutù, tàbí kí ìwọ kúkú gbóná. 16 Ǹjẹ́ nítorí tí ìwọ lọ wọ́ọ́rọ́, tí o kò si gbóná, bẹ́ẹ̀ ni tí o kò tutù, èmi yóò pọ̀ ọ́ jáde kúrò ni ẹnu mi. 17 (X)Nítorí tí ìwọ wí pé, Èmi ní ọrọ̀, èmi sì ń pọ̀ sí i ni ọrọ̀, èmi kò sì ṣe aláìní ohunkóhun; tí ìwọ kò sì mọ̀ pé, òsì ni ìwọ, ẹni-ìkáàánú, tálákà, afọ́jú, àti ẹni ìhòhò: 18 Èmi fún ọ ni ìmọ̀ràn pé kí o ra wúrà lọ́wọ́ mi tí a ti dà nínú iná, kí ìwọ lè di ọlọ́rọ̀; àti aṣọ funfun, kí ìwọ lè fi wọ ara rẹ̀, àti kí ìtìjú ìhòhò rẹ̀ má ba hàn kí ìwọ sì fi ohun ìkunra kun ojú rẹ̀, kí ìwọ lè ríran.

19 (Y)Gbogbo àwọn ti èmi bá fẹ́ ni èmi ń bá wí, tí mo sì ń nà: nítorí náà, ní ìtara, kì ìwọ sì ronúpìwàdà. 20 Kíyèsi i, èmi dúró ni ẹnu ìlẹ̀kùn, èmi sì ń kànkùn, bí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ ohun mi, tí ó sì ṣí ìlẹ̀kùn, èmi yóò sì wọlé tọ̀ ọ́ wá, èmi yóò sì máa bá a jẹun, àti òun pẹ̀lú mi.

21 Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun ni èmi yóò fi fún láti jókòó pẹ̀lú mi lórí ìtẹ́ mi, bí èmi pẹ̀lú ti ṣẹ́gun, tí mo sì jókòó pẹ̀lú Baba mi lórí ìtẹ́ rẹ̀. 22 Ẹni tí ó bá létí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.”

Ìtẹ́ Ọ̀run

(Z)Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí èmi wò, sì kíyèsi i, ìlẹ̀kùn kan ṣí sílẹ̀ ní ọ̀run: Ohùn kìn-ín-ní tí mo gbọ́ bí ohùn ìpè tí ń bá mi sọ̀rọ̀, tí ó wí pé, “Gòkè wá níhìn-ín, èmi ó sì fi ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn èyí hàn ọ́.” (AA)Lójúkan náà, mo sì wà nínú Ẹ̀mí: sì kíyèsi i, a tẹ́ ìtẹ́ kan ní ọ̀run, ẹnìkan sì jókòó lórí ìtẹ́ náà. Ẹni tí ó sì jókòó náà dàbí òkúta jasperi àti kaneliani lójú. Ni àyíká ìtẹ́ náà ni òṣùmàrè kan wà tí ó dàbí òkúta emeradi lójú. Yí ìtẹ́ náà ká sì ni ìtẹ́ mẹ́rìnlélógún mìíràn; àti lórí àwọn ìtẹ́ náà mo rí àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún jókòó, tí a wọ̀ ni aṣọ àlà; adé wúrà sì wà ni orí wọn. (AB)Àti láti ibi ìtẹ́ náà ni ìró mọ̀nàmọ́ná àti ohùn àti àrá ti jáde wá: níwájú ìtẹ́ náà ni fìtílà iná méje sì ń tàn, èyí tí ń ṣe Ẹ̀mí méje ti Ọlọ́run. (AC)Àti láti ibi ìtẹ́ náà ni òkun bi dígí wà tí o dàbí kristali.

Àti yí ìtẹ́ náà ká ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan ni ẹ̀dá alààyè mẹ́rin tí ó kún fún ojú níwájú àti lẹ́yìn wọn. (AD)Ẹ̀dá kìn-ín-ní sì dàbí kìnnìún, ẹ̀dá kejì si dàbí ọmọ màlúù, ẹ̀dá kẹta sì ni ojú bi ti ènìyàn, ẹ̀dá kẹrin sì dàbí idì tí ń fò. (AE)Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, tí olúkúlùkù wọn ni ìyẹ́ mẹ́fà, kún fún ojú yíká ara àti nínú; wọn kò sì sinmi lọ́sàn àti lóru, láti wí pé:

“Mímọ́, mímọ́, mímọ́,
Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè,
tí ó ti wà, tí ó sì ń bẹ, tí ó sì ń bọ̀ wá!”

(AF)Nígbà tí àwọn ẹ̀dá alààyè náà bá sì fi ògo àti ọlá, àti ọpẹ́ fún ẹni tí o jókòó lórí ìtẹ́, tí o ń bẹ láààyè láé àti láéláé. 10 Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà yóò sì wólẹ̀ níwájú ẹni tí o jókòó lórí ìtẹ́, wọn yóò sì tẹríba fún ẹni tí ń bẹ láààyè láé àti láéláé, wọn yóò sì fi adé wọn lélẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà, wí pé:

11 “Olúwa àti Ọlọ́run, ìwọ ni o yẹ,
láti gba ògo àti ọlá àti agbára:
nítorí pé ìwọ ni o dá ohun gbogbo,
    àti nítorí ìfẹ́ inú rẹ̀ ni
    wọn fi wà tí a sì dá wọn.”

Ìwé àti Ọ̀dọ́-àgùntàn

(AG)Mo sì rí i ni ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà, ìwé kan ti a kọ nínú àti lẹ́yìn, ti a sì fi èdìdì méje dí. Mó sì rí angẹli alágbára kan, ó ń fi ohùn rara kéde pé, “Ta ni ó yẹ láti ṣí ìwé náà, àti láti tu èdìdì rẹ̀?” Kò sì ṣí ẹni kan ní ọ̀run, tàbí lórí ilẹ̀ ayé, tàbí nísàlẹ̀ ilẹ̀, tí ó le ṣí ìwé náà, tàbí ti o lè wo inú rẹ̀. Èmi sì sọkún gidigidi, nítorí tí a kò ri ẹnìkan tí o yẹ láti sí i àti láti ka ìwé náà, tàbí láti wo inú rẹ̀. (AH)Ọ̀kan nínú àwọn àgbà náà sì wí fún mi pé, “Má ṣe sọkún: kíyèsi i, kìnnìún ẹ̀yà Juda, Gbòǹgbò Dafidi, tí borí láti ṣí ìwé náà, àti láti tú èdìdì rẹ̀ méjèèje.”

(AI)Mo sì rí Ọ̀dọ́-Àgùntàn ni àárín ìtẹ́ náà, àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, àti ni àárín àwọn àgbà náà, Ọ̀dọ́-àgùntàn kan dúró bí èyí tí a ti pa, ó ní ìwo méje àti ojú méje, tí o jẹ́ Ẹ̀mí méje tí Ọlọ́run, tí a rán jáde lọ sì orí ilẹ̀ ayé gbogbo. Ó sì wá, o sì gbà á ìwé náà ni ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà. (AJ)Nígbà tí ó sì gba ìwé náà, àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, àti àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà wólẹ̀ níwájú Ọ̀dọ́-àgùntàn náà, olúkúlùkù wọn mú ohun èlò orin olókùn kan lọ́wọ́, àti ago wúrà tí ó kún fún tùràrí tí i ṣe àdúrà àwọn ènìyàn mímọ́. (AK)Wọn sì ń kọ orin tuntun kan, wí pé:

“Ìwọ ní o yẹ láti gba ìwé náà,
    àti láti ṣí èdìdì rẹ̀:
nítorí tí a tí pa ọ,
    ìwọ sì tí fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ṣe ìràpadà ènìyàn sí Ọlọ́run láti inú ẹ̀yà gbogbo,
    àti èdè gbogbo, àti inú ènìyàn gbogbo, àti orílẹ̀-èdè gbogbo wá:
10 (AL)Ìwọ sì tí ṣe wọ́n ni ọba àti àlùfáà sì Ọlọ́run wá:
    wọ́n sì ń jẹ ọba lórí ilẹ̀ ayé.”

11 (AM)Èmi sì wò, mo sì gbọ́ ohùn àwọn angẹli púpọ̀ yí ìtẹ́ náà ká, àti yí àwọn ẹ̀dá alààyè náà àti àwọn àgbà náà ká: Iye wọn sì jẹ́ ẹgbàárùn-ún ọ̀nà ẹgbàárùn-ún àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún. 12 Wọn ń wí lóhùn rara pé:

“Yíyẹ ni Ọ̀dọ́-àgùntàn náà tí a tí pa,
láti gba agbára,
àti ọ̀rọ̀ àti ọgbọ́n, àti ipá, àti ọlá,
àti ògo, àti ìbùkún.”

13 Gbogbo ẹ̀dá tí o sì ń bẹ ni ọ̀run, àti lórí ilẹ̀ ayé, àti nísàlẹ̀ ilẹ̀ àti irú àwọn tí ń bẹ nínú Òkun, àti gbogbo àwọn tí ń bẹ nínú wọn, ni mo gbọ́ tí ń wí pé,

“Kí a fi ìbùkún àti ọlá, àti ògo, àti agbára,
fún Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ àti fún Ọ̀dọ́-àgùntàn
        náà láé àti láéláé.”

14 Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà wí pé, “Àmín!” Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà wólẹ̀, wọn sì foríbalẹ̀ fún ẹni tí ń bẹ láààyè láé àti láéláé.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.