Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Chronological

Read the Bible in the chronological order in which its stories and events occurred.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
1 Kọrinti 9-11

Àwọn ẹ̀tọ́ aposteli

(A)Èmi kò ha ni òmìnira bí? Èmi kò ha ń ṣe aposteli bí? Èmi kò ha ti rí Jesu Olúwa bí? Ẹ̀yìn ha kọ́ ní èrè iṣẹ́ mi nínú Olúwa bí? Ní ìrònú àwọn ẹlòmíràn, èmi kì í ṣe aposteli. Dájúdájú aposteli ni mo jẹ́ fún un yín, tí n kì bá ṣe fún àwọn ẹlòmíràn. Nítorí èdìdì iṣẹ́ aposteli mi ni ẹ̀yin jẹ́ nínú Olúwa.

Èyí ni ìdáhùn mi sí àwọn tí ń béèrè ẹ̀tọ́ aposteli mi. (B)Ṣé a kò ní ẹ̀tọ́ láti máa jẹ àti láti máa mu bí? (C)Ṣé àwa kò ní ẹ̀tọ́ láti máa mú ìyàwó tí í ṣe onígbàgbọ́ káàkiri gẹ́gẹ́ bí àwọn aposteli mìíràn? Àti bí arákùnrin Olúwa, àti Kefa. (D)Ṣé èmi nìkan àti Barnaba, àwa kò ha ní agbára láti máa ṣiṣẹ́ bọ́ ara wa ni?

Ta ni ó ṣíṣẹ́ ológun tí ó sanwó ara rẹ̀? Ta ní gbin ọgbà àjàrà tí kì í jẹ nínú èso rẹ̀? Tàbí ta ní ń bọ ọ̀wọ́ ẹran tí kì í sí ì jẹ nínú wàrà ọ̀wọ́ ẹran? Èmi ha sọ nǹkan wọ̀nyí bí ènìyàn? Tàbí òfin kò wí bákan náà bì? (E)Nítorí nínú òfin tí Ọlọ́run fún Mose, ni a tí kọ ọ́ pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ di màlúù ti ń tẹ ọkà lẹ́nu.” Ǹjẹ́ màlúù ni Ọlọ́run n ṣe ìtọ́jú rẹ̀ bi? 10 (F)Dájúdájú ó sọ eléyìí fún wa pé, nítorí wa ni a ṣe kọ̀wé yìí kí ẹni tí ń tulẹ̀ lè máa tulẹ̀ ní ìrètí àti ẹni tí ń pakà lè ni ìrètí láti ní ìpín nínú ìkórè. 11 (G)Bí àwa ti fún irúgbìn ohun ti ẹ̀mí sínú ọkàn yín, ohun ńlá ha ni bí àwa ó ba ká ohun ti yín tí ṣe ti ara? 12 (H)Bí àwọn ẹlòmíràn bá ní ẹ̀tọ́ tí ìrànlọ́wọ́ sì wá láti ọ̀dọ̀ yín, àwa ha kọ́ ni ó tọ́ sí jù?

Ṣùgbọ́n àwa kò lo agbára yìí ṣùgbọ́n àwa faradà ohun gbogbo, kí àwa má ba à ṣe ìdènà fún ìhìnrere Kristi.

13 (I)Ǹjẹ́ ó yé e yín pé Ọlọ́run sọ fún àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ nínú tẹmpili pé kí wọ́n mú oúnjẹ tàbí àwọn ẹ̀bùn tí wọ́n mú wá fún òun, láti fi ṣe ìtọ́jú ara wọn? Àti àwọn tí ń dúró tí pẹpẹ wọn a máa ṣe àjọpín pẹ̀lú pẹpẹ. 14 (J)Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ti fi àṣẹ lélẹ̀ pé, àwọn tí ń wàásù ìhìnrere kí wọn sì máa jẹ́ nípa ìhìnrere.

15 (K)Síbẹ̀síbẹ̀ n kò ì tí ì lo irú àwọn ẹ̀tọ́ wọ̀nyí rí. Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì kọ ìwé yìí láti fi sọ fún un yín pé, mo fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í gbà irú nǹkan bẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ yín. Kí a sọ òtítọ́, ó sàn fún mi láti kú sínú ebi ju pé kí n sọ ògo tí mo ní láti wàásù nù. 16 Nítorí pé bí mo ti ń wàásù ìhìnrere, kì í ṣe ohun tí mo lè máa ṣògo lè. Èmi kò tilẹ̀ le è ṣe é ní, kí a tilẹ̀ sọ pé mo fẹ́ kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Ègbé ni fún mi tí mo bá kọ̀ láti wàásù ìhìnrere. 17 (L)Tó bá jẹ́ pé mò ń wàásù tinútinú mi, mo ní èrè kan, ṣùgbọ́n tí ń kò bá ṣe tinútinú mi, a ti fi iṣẹ́ ìríjú lé mi lọ́wọ́. 18 (M)Ní irú ipò báyìí, kín ni ẹ rò pé yóò jẹ èrè mi ni láti jẹ́? Èrè mi ní àgbàyanu ayọ̀ tí mo ń rí gbà nípa ìwàásù ìhìnrere láìgba owó lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, láìbéèrè ẹ̀tọ́ mi lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni.

19 Bí mo ti jẹ́ òmìnira tí ń kò sì darapọ̀ mọ́ ẹnikẹ́ni, mo sọ ara mi di ẹrú lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn, láti lè jèrè ọ̀pọ̀lọpọ̀ sí i. 20 (N)Nígbà tí mó wà lọ́dọ̀ àwọn Júù, mo dàbí ọ̀kan nínú wọn, kí wọn ba à lè tẹ́tí sí ìwàásù ìhìnrere mi àti ki n le jèrè wọn fún Kristi. Nígbà tí mo bá wà láàrín àwọn tó wà lábẹ́ òfin èmi kì í bá wọn jiyàn rárá (bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò sí lábẹ́ òfin), kí èmi lè jèrè àwọn ti ń bẹ lábẹ́ òfin. 21 (O)Nígbà tí mo bá wà láàrín àwọn tí kò sí lábẹ́ òfin, èmi náà yóò dàbí ẹni tí kò sí lábẹ́ òfin (èmi kì í ṣe aláìlófin sí Ọlọ́run, ṣùgbọ́n èmí ń bẹ lábẹ́ òfin Kristi), kí èmi le jèrè àwọn tí kò sí lábẹ́ òfin. 22 (P)Nígbà tí mo bá wà láàrín àwọn aláìlera, èmi náà yóò di aláìlera, kí èmi lé jèrè àwọn aláìlera. Mo di ohun gbogbo fún gbogbo ènìyàn, kí èmi ba à lè gba díẹ̀ là lábẹ́ bí ó ti wù kí ó rí. 23 Èmi sì ń ṣe ohun gbogbo nítorí ti ìhìnrere, kí èmi kí ó lè jẹ́ alábápín nínú rẹ̀ pẹ̀lú yín.

24 (Q)Ẹ̀yin kò mọ̀ pé, olúkúlùkù ẹni tí ó ní ipa nínú eré ìje ni ó máa ń sáré, ṣùgbọ́n ẹnìkan ṣoṣo ni ń gba ipò ẹ̀bùn tí ó ga jù. Nítorí náà, ẹ sá eré ìje yín kí ẹ ba à le borí. 25 (R)Gbogbo ẹni tí ó ń sáré ìje a máa lọ nínú ìsẹ́ra-ẹni tí ó lágbára. Wọ́n ń ṣe èyí láti gba adé ìdíbàjẹ́. Ṣùgbọ́n àwa ń sá eré ìje tiwa láti fi gba adé ọ̀run àìdíbàjẹ́ láéláé. 26 Nítorí náà, mo ń sá eré ìje lọ sójú ààmì, kì í ṣe bí ẹni ti kò dá lójú. Mò ń jà kí n lè borí, kì í ṣe bí ẹni tí ń bá afẹ́fẹ́ jà. 27 Ṣùgbọ́n èmi ń kó ara mi ní ìjánu, mo sì ń mú un wá sí abẹ́ ìtẹríba, pé lẹ́yìn tí mo ti wàásù fún àwọn ẹlòmíràn, nítorí ohunkóhun, kí èmi fún rara mi má ṣe di ẹni ìtanù fún ẹ̀bùn náà.

Ìkìlọ̀ láti inú ìtàn àwọn ọmọ Israẹli

10 (S)Nítorí èmi kò fẹ́ kí ẹ̀yin jẹ́ òpè si òtítọ́, ẹ̀yin arákùnrin ọ̀wọ́n, a kó gbọdọ̀ gbàgbé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn wa nínú aginjù. Ọlọ́run ṣamọ̀nà wọn nípa rírán ìkùùkuu síwájú wọn, ó sì sìn wọ́n la omi Òkun pupa já. (T)A lè pe eléyìí ní ìtẹ̀bọmi ti Mose nínú ìkùùkuu àti nínú omi Òkun. (U)Nípa iṣẹ́ ìyanu, gbogbo wọn jẹ oúnjẹ ẹ̀mí kan náà. (V)Wọ́n mu nínú omi tí Kristi fi fún wọn. Wọ́n mu omi ẹ̀mí láti inú àpáta tí ó ń tẹ̀lé wọn, àpáta náà ni Kristi. Ó wà pẹ̀lú wọn nínú aginjù náà, òun ni àpáta tí ń fi omi ẹ̀mí tu ọkàn lára. (W)Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni inú Ọlọ́run kò dún sí; nítorí a pa wọ́n run nínú aginjù.

(X)Àwọn nǹkan wọ̀nyí sì jásí àpẹẹrẹ fún àwa, kí a má ṣe ní ìfẹ́ sí àwọn ohun búburú gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn yìí ṣe ní ìfẹ́ si. (Y)Kí ẹ̀yin kí ó má ṣe jẹ́ abọ̀rìṣà gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Àwọn ènìyàn náà jókòó láti jẹ àti láti mu, wọ́n sì dìde dúró láti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́.” (Z)Bẹ́ẹ̀ ni kí àwa kí ó má ṣe ṣe àgbèrè gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíràn nínú wọn ti ṣe, tí ẹgbàá-mọ̀kànlá-lé-ẹgbẹ̀rún ènìyàn sì kú ní ọjọ́ kan. (AA)Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin má ṣe dán Olúwa wò, gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíràn nínú wọn ti dán an wò, tí a sì fi ejò run wọ́n. 10 (AB)Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó má ṣe kùn, gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíràn nínú wọ́n ṣe kùn, tí a sì ti ọwọ́ olùparun run wọ́n.

11 Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣẹlẹ̀ sí wọn bí àpẹẹrẹ fún wa, a sì kọ̀wé wọn fún ìkìlọ̀ fún wa, àwa ẹni tí ìgbẹ̀yìn ayé dé bá. 12 Nítorí náà, ẹni tí ó bá rò pé òun dúró, kí ó kíyèsára kí ó ma ba à ṣubú. 13 (AC)Kò sí ìdánwò kan tí ó ti bá yín, bí kò ṣe irú èyí tí ó mọ níwọ̀n fún ènìyàn, ṣùgbọ́n olódodo ni Ọlọ́run, ẹni ti kì yóò jẹ́ kí á dán an yín wò ju bí ẹ̀yin ti le gbà, ṣùgbọ́n tí yóò sì ṣe ọ̀nà àbáyọ pẹ̀lú nínú ìdánwò náà, kí ẹ̀yin ba à lè faradà á.

Oúnjẹ òrìṣà àti oúnjẹ alẹ́ Olúwa

14 (AD)Nítorí náà, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ sá fún ìbọ̀rìṣà. 15 Èmi ń sọ̀rọ̀ bí ọlọ́gbọ́n ènìyàn, ṣe ìdájọ́ fúnrarẹ̀ ohun tí mo sọ. 16 (AE)Ǹjẹ́ ago ìdúpẹ́ nípasẹ̀ èyí tí a ń dúpẹ́ fún, kì í ha ṣe jíjẹ́ alábápín ìdàpọ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ Kristi bí? Àkàrà tí a bù, kì í ha ṣe jíjẹ́ alábápín nínú ara Kristi bi? 17 Nítorí àkàrà kan ni ó ń bẹ, àwa tí a pọ̀ níye, tí a sì jẹ ara kan ń pín nínú àkàrà kan ṣoṣo.

18 (AF)Ẹ wo Israẹli nípa ti ara, àwọn tí ń jẹ ohun ẹbọ kò ha ṣe alábápín pẹpẹ bí? 19 Ǹjẹ́ kí ni mo ń wí? Ṣé pé ohun tí a fi rú ẹbọ sí òrìṣà jẹ́ nǹkan kan tàbí pé òrìṣà jẹ́ nǹkan kan? 20 (AG)Rárá, ṣùgbọ́n ohun tí mo ń wí ni pé, ohun tí àwọn aláìkọlà fi ń rú ẹbọ wọn fi fun àwọn ẹ̀mí èṣù. Dájúdájú kì í ṣe ìrúbọ sí Ọlọ́run. Èmi kò sì fẹ́ kí ẹnikẹ́ni nínú yín so ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ ẹ̀mí èṣù. 21 (AH)Ẹ̀yin kò lè mu nínú ago tí Olúwa àti ago ti èṣù lẹ́ẹ̀kan náà; ẹ̀yin kò le ṣe àjọpín ní tábìlì Olúwa, àti ni tábìlì ẹ̀mí èṣù lẹ́ẹ̀kan náà. 22 (AI)Kí ni ẹ̀ ń gbìyànjú láti ṣe? Àwa ha ń mú Olúwa jowú bí? Àwa ha ní agbára jù ú lọ bi?

Òmìnira àwọn onígbàgbọ́

23 (AJ)“Ohun gbogbo ni o yẹ fún mi,” ṣùgbọ́n kì í ṣe ohun gbogbo ni ó ní èrè. “Ohun gbogbo ni ó yẹ fún mi,” ṣùgbọ́n kì í ṣe ohun gbogbo ni ń gbe ni rò. 24 Má ṣe ronú nípa ara rẹ̀ nìkan; ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù máa wá rere ọmọnìkejì rẹ̀.

25 Jẹ ẹrankẹ́ran tí wọ́n bá ń tà lọ́jà. Má ṣe gbìyànjú láti wádìí lọ́wọ́ ẹni tí ń tà á nítorí ẹ̀rí ọkàn. 26 (AK)Nítorí “Ayé àti gbogbo nǹkan rere tí ń bẹ nínú rẹ̀, tí Olúwa ni wọ́n jẹ́.”

27 Bí ẹnikẹ́ni tí kì í bá ṣe onígbàgbọ́ ba pè yín sí ibi àsè láti jẹun, bá a lọ. Gba ìpè rẹ̀ tí ó bá tẹ́ ọ lọ́rùn. Jẹ ohunkóhun tí ó bá pèsè sílẹ̀ fún àsè náà, má ṣe béèrè ohunkóhun nípa rẹ̀ nítorí ẹ̀rí ọkàn. 28 (AL)Bí ẹnikẹ́ni bá sì kìlọ̀ fún un yín pé, “A ti fi ẹran yìí rú ẹbọ,” ẹ má ṣe jẹ́ ẹ nítorí ẹni ti o sọ fun ọ àti nítorí ẹ̀rí ọkàn. 29 Èmi ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀rí ọkàn ẹni tí ó sọ fún ọ kì í ṣe tirẹ̀. Nítorí kín ni a ó fi dá mi lẹ́jọ́ nítorí ẹ̀rí ọkàn ẹlòmíràn. 30 Bí èmi ba fi ọpẹ́ jẹ ẹ́, èéṣe tí a fì ń sọ̀rọ̀ mi ní búburú nítorí ohun tí èmi dúpẹ́ fún.

31 Nítorí náà tí ẹ̀yin bá jẹ tàbí tí ẹ bá mu tàbí ohunkóhun tí ẹ̀yin bá sè, e máa ṣe gbogbo rẹ̀ fún ògo Ọlọ́run. 32 (AM)Nítorí náà, má ṣe jẹ́ òkúta ìkọ̀sẹ̀ tí ó lè gbé ẹlòmíràn ṣubú ìbá à ṣe Júù tàbí Giriki tàbí ìjọ Ọlọ́run. 33 (AN)Bí mo ṣè n gbìyànjú láti tẹ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan lọ́rùn nínú gbogbo nǹkan tí mo bá ń ṣe láì wa ohun rere fún ara mi bí kò ṣe ti ènìyàn púpọ̀ kí ó lè ṣe é ṣe fún wọn láti le ní ìgbàlà. 11 (AO)Ẹ máa tẹ̀lé àpẹẹrẹ mi, gẹ́gẹ́ bí èmi náà ti ń tẹ̀lé àpẹẹrẹ Kristi.

Ìbámu nínú ìsìn

(AP)Èmí yìn yín fún rírántí mi nínú ohun gbogbo àti fún dídi gbogbo ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ ọ yín mú ṣinṣin gẹ́gẹ́ bí mo ṣe fi lélẹ̀ fún un yín. (AQ)Ṣùgbọ́n mo fẹ́ kí ẹ̀yin mọ̀ pé, Kristi ni orí olúkúlùkù ọkùnrin, orí obìnrin sì ni ọkọ rẹ̀ àti orí Kristi sì ní Ọlọ́run. Gbogbo ọkùnrin tó bá borí rẹ̀ nígbà tó bá ń gbàdúrà tàbí sọtẹ́lẹ̀ kò bọ̀wọ̀ fún orí rẹ̀. (AR)Bẹ́ẹ̀ náà ni obìnrin tí ó bá ń gbàdúrà tàbí tí ó bá ń sọtẹ́lẹ̀ láìbo orí rẹ̀, kò bu ọlá fún orí ara rẹ̀ nítorí ọ̀kan náà ni pẹ̀lú ẹni tí ó fárí. Ṣùgbọ́n tí obìnrin bá kọ̀ láti bo orí rẹ̀, ẹ jẹ́ kí ó gé irun rẹ̀. Bí ó bá sì jẹ́ nǹkan ìtìjú fún un láti gé irun orí rẹ́, nígbà náà kí ó fi gèlè bo orí rẹ̀.

(AS)Ṣùgbọ́n ọkùnrin kò ní láti fi nǹkan bo orí rẹ́ nígbà tí ó bá ń sìn, nítorí àwòrán àti ògo Ọlọ́run ni òun í ṣe, ṣùgbọ́n ògo ọkùnrin ni obìnrin í ṣe. (AT)Ọkùnrin kò ti inú obìnrin wá, ṣùgbọ́n a yọ obìnrin jáde lára ọkùnrin, (AU)bẹ́ẹ̀ ni a kò dá ọkùnrin fún àǹfààní obìnrin ṣùgbọ́n a da obìnrin fún ọkùnrin. 10 Nítorí ìdí èyí àti nítorí àwọn angẹli, ni obìnrin ṣe gbọdọ̀ ní ààmì àṣẹ rẹ̀ ní orí rẹ̀. 11 Ẹ rántí pé, nínú ètò Ọlọ́run obìnrin kò lè wà láìsí ọkùnrin, bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin kò lè wà láàsí obìnrin. 12 (AV)Lóòtítọ́ láti ara ọkùnrin ni a ti yọ obìnrin jáde bẹ́ẹ̀ sì ni ọkùnrin tipasẹ̀ obìnrin wa. Ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ohun gbogbo ti wà.

13 Kí ni ẹ̀yìn fúnrayín rò lórí ọ̀rọ̀ yìí? Ǹjẹ́ ó tọ̀nà fún obìnrin láti máa gbàdúrà Ọlọ́run ní gbangba láìbo orí rẹ̀ bí? 14 Ǹjẹ́ ìwà abínibí yín kò ha kọ́ yín pé, bí ọkùnrin bá ní irun gígùn, àbùkù ni ó jẹ́ fún un. 15 Ṣùgbọ́n bí obìnrin bá ní irun gígùn, ògo ni ó jẹ́ fún un nítorí irun gígùn tí a fi fún un jẹ́ ìbòrí fún un. 16 (AW)Ṣùgbọ́n tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ jiyàn lórí ọ̀rọ̀ yìí, ohun kan tí mo lè sọ sí gbogbo rẹ̀ ni pé, a kò ní ìlànà tí ó yàtọ̀ sí èyí tí mo ti sọ, pé obìnrin gbọdọ̀ fi gèlè bo orí rẹ̀ nígbà tí ó bá ń sọtẹ́lẹ̀ tàbí tí ó bá ń gbàdúrà láàrín ìjọ Ọlọ́run.

Oúnjẹ alẹ́ Olúwa

17 Nínú àwọn àlàkalẹ̀ èmi ko ni yìn yín nítorí pé bí ẹ bá péjọ kì í ṣe fún rere bí ko ṣe fún búburú. 18 (AX)Lọ́nà kìn-ín-ní, mo gbọ́ pe ìyapa máa ń wà láàrín yín ní ìgbà tí ẹ bá péjọpọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìjọ, mo sì gba èyí gbọ́ dé ààyè ibìkan. 19 Kò sí àní àní, ìyàtọ̀ gbọdọ̀ wa láàrín yín, kí àwọn tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run láàrín yín le farahàn kedere. 20 Nígbà tí ẹ bá pàdé láti jẹun, kì í ṣe oúnjẹ alẹ́ Olúwa ni ẹ máa ń jẹ. 21 Ṣùgbọ́n tí ara yín, nígbà tí ẹ bá fẹ́ jẹun, olúkúlùkù yín a máa sáré jẹ oúnjẹ rẹ̀ láìdúró de ẹnìkejì rẹ̀. Ebi a sì máa pa wọ́n, ẹlòmíràn wọ́n sì ń mu àmuyó àti àmupara. 22 Ṣé ẹ̀yin kò ní ilé tí ẹ ti lè jẹ, tí ẹ sì ti lè mu ni? Tàbí ẹ̀yin ń gan ìjọ Ọlọ́run ni? Ẹ̀yin sì ń dójútì àwọn aláìní? Kín ni kí èmi ó wí fún un yín? Èmi yóò ha yìn yín nítorí èyí? A! Rárá o. Èmi kọ́, n kò ní yìn yín.

23 Nítorí èyí tí èmi gbà lọ́wọ́ Olúwa ni mo ti fi fún un yin. Ní alẹ́ ọjọ́ tí Judasi fihàn, Olúwa Jesu Kristi mú àkàrà. 24 Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún àkàrà náà tan, ó bù ú, ó fi fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ gbà kí ẹ sì jẹ, èyí ní ara mi tí a fi fún un yín. Ẹ máa ṣe eléyìí ni rántí mi.” 25 (AY)Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ lẹ́yìn oúnjẹ alẹ́, ó sì mú ago wáìnì, ó sì wí pé, “Ago yìí ni májẹ̀mú tuntun nínú ẹ̀jẹ̀ mi, ẹ máa ṣe èyí, nígbàkígbà ti ẹ̀yìn bá ń mu ú, ní ìrántí mi.” 26 (AZ)Nítorí nígbàkúgbà tí ẹ bá ń jẹ lára àkàrà yìí, tí ẹ sì ǹ mu nínú ago yìí, ni ẹ tún sọ nípa ikú Olúwa. Ẹ máa ṣe eléyìí títí yóò fi padà dé.

27 Nítorí náà tí ẹnikẹ́ni bá jẹ lára àkàrà yìí, tí ẹ sì ń mu nínú ago Olúwa yìí, ní ọ̀nà tí kò bójúmu, yóò jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ sí ara àti ẹ̀jẹ̀ Olúwa. 28 Ìdí nìyìí tí ó fi yẹ kí ènìyàn yẹ ara rẹ̀ wò dáradára kí ó tó jẹ lára àkàrà nà án àti kí ó tó mu nínú ago náà. 29 Nítorí tí ẹ bá jẹ lára àkàrà, tí ẹ sì mu nínú ago láìyẹ, tí ẹ kò ronú ara Kristi àti nǹkan tí ó túmọ̀ sí, ẹ̀ ń jẹ, ẹ sì ń mú ẹ̀bi ìdájọ́ Ọlọ́run wá sórí ara yín. 30 Ìdí nìyìí tí ọ̀pọ̀ yín fi di ẹni tí kò lágbára mọ́, tí ọ̀pọ̀ yín sì ń ṣàìsàn, àwọn mìíràn nínú yín tilẹ̀ ti sùn. 31 Ṣùgbọ́n tí ẹ bá yẹ ara yín wò dáradára, kí ẹ tó jẹ ẹ́, a kì yóò dá yín lẹ́jọ́. 32 (BA)Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá dá wa lẹ́jọ́, láti ọwọ́ Olúwa ni a ti nà wá, kí a má ba à dá wa lẹ́bi pẹ̀lú ayé.

33 Nítorí náà, ẹ̀yin arákùnrin mi ọ̀wọ́n, nígbàkúgbà ti ẹ bá péjọ láti jẹ́ oúnjẹ alẹ́ Olúwa, tàbí fún ìsìn oúnjẹ alẹ́ Olúwa, ẹ dúró de ara yín. 34 (BB)Bí ebi bá ń pa ẹnikẹ́ni nínú yin, kí ó jẹun láti ilé wá, kí ó má ba á mú ìjìyà wá sórí ara rẹ̀ nígbà tí ẹ bá péjọ.

Tí mo bá dé, èmi yóò máa sọ̀rọ̀ lórí àwọn kókó-ọ̀rọ̀ ìyókù tí n kò ì ti fẹnu bà lẹ́sẹẹsẹ.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.