Chronological
Paulu gbèjà iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀
10 (A)Ṣùgbọ́n èmi Paulu fúnra mi fi inú tútù àti ìwà pẹ̀lẹ́ Kristi bẹ̀ yín, èmi ẹni ìrẹ̀lẹ̀ lójú yín nígbà tí mo wà láàrín yín, ṣùgbọ́n nígbà tí èmi kò sí, mo di ẹni ìgboyà sí yín. 2 (B)Ṣùgbọ́n èmi bẹ̀ yín pé nígbà tí mo wà láàrín yín, kí èmi ba à lè lo ìgboyà pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé náà, eléyìí tí mo ti fọkàn sí láti fi dojúkọ àwọn kan, ti ń funra sí wa bí ẹni tí ń rìn nípa ìlànà ti ayé yìí. 3 Nítorí pé, bí àwa tilẹ̀ n gbé nínú ayé, ṣùgbọ́n àwa kò jagun nípa ti ara. 4 Nítorí ohun ìjà wa kì í ṣe ti ara, ṣùgbọ́n ó lágbára nínú Ọlọ́run láti wó ibi gíga palẹ̀. 5 Àwa ń sọ gbogbo èrò àti gbogbo ohun gíga ti ń gbe ara rẹ̀ ga sí ìmọ̀ Ọlọ́run kalẹ̀, àwa sì ń di gbogbo èrò ní ìgbèkùn wá sí ìtẹríba fún Kristi. 6 (C)Àwa sì ti murá tan láti jẹ gbogbo àìgbọ́ràn ní yà, nígbà tí ìgbọ́ràn yín bá pé.
7 (D)Ẹ̀yin sì ń wo nǹkan gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti fihàn lóde. Bí ẹnikẹ́ni bá ní ìgboyà nínú ara rẹ̀, ti Kristi ni òun, kí ó tún rò lẹ́ẹ̀kan si pé, bí òun ti jẹ́ ti Kristi, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àwa pẹ̀lú jẹ́ ti Kristi. 8 Nítorí bí mo tilẹ̀ ń ṣògo bí ó ti wù mi nítorí agbára, tí Olúwa ti fi fún wá fún ìdàgbàsókè, dípò fífà yín ṣubú, ojú kí yóò tì mí. 9 Kí ó má ṣe dàbí ẹni pé èmi ń fi ìwé kíkọ dẹ́rùbà yín. 10 (E)Nítorí wọ́n wí pé, “Ìwé rẹ wúwo, wọn sì lágbára; ṣùgbọ́n ní ti ara ìrísí rẹ̀ jẹ aláìlera, ọ̀rọ̀ rẹ kò níláárí.” 11 Kí irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ mọ̀ pé, irú ẹni tí àwa jẹ́ nínú ọ̀rọ̀ nípa ìwé kíkọ nígbà tí àwa kò sí, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni àwa sì jẹ́ nínú iṣẹ́ pẹ̀lú nígbà ti àwa bá wà.
12 Nítorí pé àwa kò dáṣà láti ka ara wa mọ́, tàbí láti fi ara wa wé àwọn mìíràn nínú wọn tí ń yin ara wọn; ṣùgbọ́n àwọn fúnrawọn jẹ́ aláìlóye bí wọn ti ń fi ara wọn díwọ̀n ara wọ́n, tí wọ́n sì ń fi ara wọn wé ara wọn. 13 Ṣùgbọ́n àwa kò ṣògo rékọjá ààlà wa, ṣùgbọ́n nípa ààlà ìwọ̀n tí Ọlọ́run ti pín fún wa, èyí tí ó mú kí ó ṣe é ṣe láti dé ọ̀dọ̀ yín. 14 Nítorí àwa kò nawọ́ wa rékọjá rárá, bí ẹni pé àwa kò dé ọ̀dọ̀ yín: nítorí àwa tilẹ̀ dé ọ̀dọ̀ yín pẹ̀lú nínú ìhìnrere Kristi. 15 (F)Àwa kò ṣògo rékọjá ààlà wa, èyí nì, lórí iṣẹ́ ẹlòmíràn, ṣùgbọ́n àwa ní ìrètí pé, bí ìgbàgbọ́ yín ti ń dàgbà sí i, gẹ́gẹ́ bí ààlà wa, àwa ó dí gbígbéga lọ́dọ̀ yín sí i lọ́pọ̀lọpọ̀. 16 Kí a bá à lè wàásù ìhìnrere ní àwọn ìlú tí ń bẹ níwájú yín, kí a má sì ṣògo nínú ààlà ẹlòmíràn nípa ohun tí ó wà ní àrọ́wọ́tó. 17 (G)“Ṣùgbọ́n jẹ́ kí ẹni tí ó bá ń ṣògo, kí ó máa ṣògo nínú Olúwa.” 18 Nítorí kì í ṣe ẹni tí ń yin ara rẹ̀ ni ó ní ìtẹ́wọ́gbà, bí kò ṣe ẹni tí Olúwa bá yìn.
Paulu àti àwọn aposteli ẹlẹ́kọ̀ọ́ èké
11 (H)Mo rò wí pé ẹ ó faradà díẹ̀ nínú ìwà òmùgọ̀ mi ṣùgbọ́n bẹ́ẹ̀ ni, mo fẹ́ kí ẹ gbà mí láàyè. 2 (I)Nítorí pé èmi ń jowú lórí i yín bí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run: nítorí tí mo ti fì yín fún ọkọ kan, kí èmi bà á lè mú yín wá bí wúńdíá tí ó mọ́ sọ́dọ̀ Kristi. 3 (J)Ṣùgbọ́n ẹ̀rù ń bà mí, kí ó má bà á jẹ́ pé, bí ejò ti tan Efa jẹ́ nípasẹ̀ àrékérekè rẹ̀, a lè mú ọkàn yín ṣáko lọ kúrò nínú òtítọ́ yín àti ìfarajì fún Kristi. 4 (K)Nítorí bí ẹnìkan bá wá tí ó sì wàásù Jesu mìíràn, yàtọ̀ sí èyí tí a ti wàásù rí tàbí bí ẹ̀yin bá gba ẹ̀mí mìíràn, yàtọ̀ sí èyí tí ẹ ti gbà tàbí ìhìnrere mìíràn yàtọ̀ sí èyí tí ẹ ti gbà, tí ẹ sì ti yára tẹ́wọ́ gbà á.
5 (L)Nítorí mo rò pé èmi kò rẹ̀yìn nínú ohunkóhun sí àwọn àgbà Aposteli. 6 (M)Bí mo tilẹ̀ jẹ́ òpè nínú ọ̀rọ̀ sísọ, kì í ṣe nínú ìmọ̀; Ní ọ̀nàkọnà ni àwa ti fi èyí hàn dájúdájú fún yín nínú ohun gbogbo. 7 (N)Tàbí ẹ̀ṣẹ̀ ni mo dá bí èmi ti ń rẹ ara mí sílẹ̀ kí a lè gbé yín ga, nítorí tí mo wàásù ìhìnrere Ọlọ́run fún un yín lọ́fẹ̀ẹ́. 8 (O)Èmí ń ja ìjọ mìíràn ni olè nípa gbígba ìpèsè owó ki èmi bà á lè sìn yín. 9 Nígbà tí mo sì wà pẹ̀lú yín, tí mo sì ṣe aláìní, èmi kò dẹ́rù pa ẹnikẹ́ni: nítorí ohun tí mo ṣe aláìní ni àwọn ará tí ó ti Makedonia wá ti mú wá. Bẹ́ẹ̀ ni nínú ohun gbogbo mo pa ara mi mọ́ láti má ṣe jẹ́ ẹrù fún yín, èmi yóò sì pa ara mi mọ́ bẹ́ẹ̀. 10 (P)Ó jẹ́ òtítọ́, Kristi tí ń bẹ nínú mi pé kò sí ẹni tí ó lè dá mi lẹ́kun ìṣògo yìí ni gbogbo ẹkùn Akaia. 11 (Q)Nítorí kín ni? Nítorí èmi kò fẹ́ràn yín ni bí? Ọlọ́run mọ̀.
12 (R)Èmi yóò tẹ̀síwájú láti máa ṣe ohun ti èmi ń ṣe láti le mú ìjákulẹ̀ bá àwọn tí wọn ń wá ọ̀nà láti bá wa dọ́gba nínú èyí ti àwa ń ṣògo lé lórí. 13 Nítorí irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni àwọn èké Aposteli àwọn ẹni ti ń ṣiṣẹ́ ẹ̀tàn, tí ń pa wọ́n dà di aposteli Kristi. 14 Kì í sì í ṣe ohun ìyanu; nítorí Satani, tìkára rẹ̀ ń pa ara rẹ̀ dàbí angẹli ìmọ́lẹ̀. 15 Nítorí náà kì í ṣe ohun ńlá bí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú bá pa ara wọn dàbí àwọn ìránṣẹ́ òdodo; ìgbẹ̀yìn àwọn ẹni tí yóò rí gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn.
Paulu ṣògo nínú ìjìyà rẹ̀
16 Mo sì tún wí pé, kí ẹnikẹ́ni má ṣe rò pé òmùgọ̀ ni mí; ṣùgbọ́n bí bẹ́ẹ̀ bá ni, ẹ gbà mí bí òmùgọ̀ kí èmi lè gbé ara mi ga díẹ̀. 17 (S)Ohun tí èmi ń sọ, èmi kò sọ ọ́ nípa ti Olúwa, ṣùgbọ́n bí òmùgọ̀ nínú ìgbẹ́kẹ̀lé ìṣògo yìí. 18 Ọ̀pọ̀lọpọ̀, ni ó ń ṣògo nípa ti ara, èmi ó ṣògo pẹ̀lú. 19 (T)Nítorí ẹ̀yin fi inú dídùn gba àwọn òmùgọ̀ nígbà tí ẹ̀yin tìkára yín jẹ́ ọlọ́gbọ́n. 20 Nítorí ẹ̀yin faradà á bí ẹnìkan bá sọ yín dí òǹdè, bí ẹnìkan bá jẹ́ yín run, bí ẹnìkan bá gbà lọ́wọ́ yín, bí ẹnìkan bá gbé ara rẹ̀ ga, bí ẹnìkan bá gbá yín lójú. 21 Èmi ń wí lọ́nà ẹ̀gàn, bí ẹni pé àwa jẹ́ aláìlera!
Ṣùgbọ́n nínú ohunkóhun tí ẹnìkan ti ní ìgboyà, èmi ń sọ̀rọ̀ bí òmùgọ̀, èmi ní ìgboyà pẹ̀lú. 22 Heberu ni wọ́n bí? Bẹ́ẹ̀ ni èmi. Israẹli ni wọ́n bí? Bẹ́ẹ̀ ni èmi. Irú-ọmọ Abrahamu ní òun bí? Bẹ́ẹ̀ ni èmi. 23 (U)Ìránṣẹ́ Kristi ni wọ́n bí? Èmi ń sọ bí òmùgọ̀, mo ta wọ́n yọ; ní ti làálàá lọ́pọ̀lọpọ̀, ní ti pàṣán, mo rékọjá, ní ti túbú nígbàkúgbà, ní ti fífẹ́rẹ kú nígbà púpọ̀. 24 (V)Nígbà márùn-ún ni mo gba pàṣán ogójì dín ẹyọ kan lọ́wọ́ àwọn Júù. 25 (W)Nígbà mẹ́ta ni a fi ọ̀gọ̀ lù mí, ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni a sọ mí ní òkúta, ẹ̀ẹ̀mẹta ni ọkọ̀ ojú omi mi rì, ọ̀sán kan àti òru kan ni mo wà nínú ibú. 26 (X)Ní ìrìnàjò nígbàkúgbà, nínú ewu omi, nínú ewu àwọn ọlọ́ṣà, nínú ewu àwọn ará ìlú mi, nínú ewu àwọn aláìkọlà, nínú ewu ni ìlú, nínú ewu ní aginjù, nínú ewu lójú Òkun, nínú ewu láàrín àwọn èké arákùnrin. 27 (Y)Nínú làálàá àti ìrora, nínú ìṣọ́ òru nígbàkúgbà, nínú ebi àti òǹgbẹ, nínú àwẹ̀ nígbàkúgbà, nínú òtútù àti ìhòhò. 28 Pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí tí ó jẹ́ tí òde, ọ̀pọ̀ ni èyí tí ń wọn n dúró tì mí lójoojúmọ́, àní àníyàn fún gbogbo ìjọ. 29 (Z)Ta ni ó ṣe àìlera, tí èmi kò ṣe àìlera? Tàbí a mú kọsẹ̀, tí ara mi kò gbiná?
30 Bí èmi yóò bá ṣògo, èmi ó kúkú máa ṣògo nípa àwọn nǹkan tí ó jẹ́ ti àìlera mi. 31 Ọlọ́run àti Baba Olúwa wá Jesu Kristi, ẹni tí ó jẹ́ olùbùkún jùlọ láéláé mọ̀ pé èmi kò ṣèké. 32 (AA)Ní Damasku, baálẹ̀ tí ó wà lábẹ́ ọba Areta fi ẹgbẹ́ ogun ká ìlú àwọn ará Damasku mọ́, ó ń fẹ́ láti mú mi bí arúfin: 33 Láti ojú fèrèsé nínú agbọ̀n ni a sì ti sọ̀ mí kalẹ̀ lẹ́yìn odi, tí mo sì bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.
Ìṣípayá Paulu àti ẹ̀gún tí n bẹ lára rẹ̀
12 Èmi kò lè ṣàì ṣògo bí kò tilẹ̀ ṣe àǹfààní, nítorí èmi ó wà sọ nípa ìran àti ìṣípáyà ti Olúwa fihàn mí. 2 Èmi mọ ọkùnrin kan nínú Kristi ní ọdún mẹ́rìnlá sẹ́yìn, yálà nínú ara ni, èmi kò mọ̀; tàbí kúrò nínú ara, èmi kò mọ̀; Ọlọ́run mọ̀: a gbé irú ẹni náà lọ sí ọ̀run kẹta. 3 Bẹ́ẹ̀ ni èmi mọ irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀, yálà ní ara ni, tàbí kúrò nínú ara ni, èmi kò mọ̀: Ọlọ́run mọ̀. 4 (AB)Pé a gbé e lọ sókè sí Paradise, tí ó sì gbọ́ ọ̀rọ̀ tí a kò sì lè sọ, tí kò tọ́ fún ènìyàn láti máa sọ. 5 Nípa irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni èmi ó máa ṣògo: ṣùgbọ́n nípa ti èmi tìkára mi èmi kì yóò ṣògo, bí kò ṣe nínú àìlera mi. 6 Nítorí pé bi èmi tilẹ̀ ń fẹ́ máa ṣògo, èmi kì yóò jẹ́ òmùgọ̀; nítorí pé èmi yóò sọ òtítọ́: ṣùgbọ́n mo kọ̀, kí ẹnikẹ́ni máa bà à fi mí pè ju ohun tí ó rí tí èmi jẹ́ lọ, tàbí ju èyí tí ó gbọ́ lẹ́nu mi, 7 (AC)àti nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣípayá, kí èmi má ba à gbé ara mi ga rékọjá, a sì ti fi ẹ̀gún kan sí mi lára, ìránṣẹ́ Satani láti pọ́n mi lójú, kí èmi má bá a gbéraga rékọjá. 8 Nítorí nǹkan yìí ni mo ṣe bẹ Olúwa nígbà mẹ́ta pé, kí ó lé e kúrò lára mi. 9 Òun sì wí fún mi pé, “Oore-ọ̀fẹ́ mi tó fún ọ: nítorí pé a sọ agbára mi di pípé nínú àìlera.” Nítorí náà tayọ̀tayọ̀ ni èmi ó kúkú máa fi ṣògo nínú àìlera mi, kí agbára Kristi lè máa gbé inú mi. 10 (AD)Nítorí náà èmi ní inú dídùn nínú àìlera gbogbo, nínú ẹ̀gàn gbogbo, nínú àìní gbogbo, nínú inúnibíni gbogbo, nínú wàhálà gbogbo nítorí Kristi. Nítorí nígbà tí mo bá jẹ́ aláìlera, nígbà náà ni mo di alágbára.
Àníyàn Paulu nípa àwọn ará Kọrinti
11 (AE)Mo di òmùgọ̀ nípa ṣíṣògo; ẹ̀yin ní ó fi ipá mú mi ṣe é: nítorí tí ó tọ́ tí ẹ bá yìn mí: nítorí tí èmi kò rẹ̀yìn lóhunkóhun sí àwọn àgbà aposteli bí èmi kò tilẹ̀ jámọ́ nǹkan kan. 12 Ohun kan tí ó ṣe ààmì aposteli, iṣẹ́ ìyanu àti iṣẹ́ agbára ni wọ́n ṣe ní àárín yín pẹ̀lú sùúrù tó ga. 13 Nítorí nínú kín ni ohun tí ẹ̀yin ṣe rẹ̀yìn sí ìjọ mìíràn, bí kò ṣe ní ti pé èmi fúnra mi kó jẹ́ oníyọnu fún yín? Ẹ dárí àṣìṣe yìí jì mí.
14 Kíyèsi i, ìgbà kẹta yìí ni mo múra tan láti tọ̀ yín wá: èmi kì yóò sì jẹ́ oníyọnu fún yín nítorí tí èmi kò wá nǹkan yín, bí kò ṣe ẹ̀yin fúnrayín; nítorí tí kò tọ́ fún àwọn ọmọ láti máa to ìṣúra jọ fún àwọn òbí wọn, bí kò ṣe àwọn òbí fún àwọn ọmọ wọn. 15 Èmi ó sì fi ayọ̀ ná ohun gbogbo tí mo bá ní, èmi ó sì ná ara mi fún ọkàn yín nítòótọ́; bí mo bá fẹ́ yín lọ́pọ̀lọpọ̀, ó ha tọ́ kí ẹ̀yin kí ó fẹ́ràn mi díẹ̀ bí? 16 (AF)Ṣùgbọ́n ó dára bẹ́ẹ̀ tí èmi kò dẹ́rùbà yín: ṣùgbọ́n bí ọlọ́gbọ́n ènìyàn, èmi ń fi ọwọ́ ẹ̀rọ̀ mú yín. 17 Èmi ha rẹ́ yín jẹ nípa ẹnikẹ́ni nínú àwọn tí mo rán sí yín bi? 18 (AG)Mo bẹ Titu, mo sì rán arákùnrin kan pẹ̀lú rẹ̀; Titu ha rẹ́ yín jẹ bí? Nípa ẹ̀mí kan náà kọ́ ni àwa rìn bí? Ọ̀nà kan náà kọ́ ni àwa tọ̀ bí?
19 Ẹ̀yin ha rò pé àwa ń sọ nǹkan wọ̀nyí láti gbèjà ara wa níwájú yín bí? Ní iwájú Ọlọ́run ni àwa ń sọ̀rọ̀ nínú Kristi; ṣùgbọ́n àwa ń ṣe ohun gbogbo, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, láti gbé yín ró ni. 20 (AH)Nítorí ẹ̀rù ń bà mí pé, nígbà tí mo bá dé, èmi kì yóò bá yín gẹ́gẹ́ bí irú èyí tí mo fẹ́, àti pé ẹ̀yin yóò sì rí mi gẹ́gẹ́ bí irú èyí tí ẹ̀yin kò fẹ́: Kí ìjà, owú jíjẹ, ìbínú, ìpinyà, ìṣọ̀rọ̀-ẹni-lẹ́yìn, òfófó, ìgbéraga, ìrúkèrúdò, má ba à wà. 21 Àti nígbà tí mo bá sì padà dé, kí Ọlọ́run mí má bà à rẹ̀ mí sílẹ̀ lójú yín, àti kí èmi má ba à sọkún nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí ó tí ṣẹ̀ náà tí kò sì ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ ìwà èérí, àgbèrè, àti wọ̀bìà tí wọ́n ti hù.
Àwọn ìkìlọ̀ ìkẹyìn
13 (AI)Èyí ni ó dí ìgbà kẹta tí èmi ń tọ̀ yín wá. Ní ẹnu ẹlẹ́rìí méjì tàbí mẹ́ta ni a ó fi ìdí ọ̀rọ̀ gbogbo múlẹ̀. 2 Mo ti sọ fún yín ṣáájú, mo sì ń sọ fún yín tẹ́lẹ̀, bí ẹni pé mo wà pẹ̀lú yín nígbà kejì, àti bí èmi kò ti sí lọ́dọ̀ yín ní ìsinsin yìí, mo kọ̀wé sí àwọn tí ó ti ṣẹ̀ náà, àti sí gbogbo àwọn ẹlòmíràn, pé bí mo bá tún padà wá, èmi kì yóò dá wọn sí. 3 Níwọ́n bí ẹ̀yin tí ń wá ààmì Kristi ti ń sọ̀rọ̀ nínú mi, ẹni tí kì í ṣe àìlera sí yin, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ agbára nínú yín. 4 (AJ)Nítorí pé a kàn án mọ́ àgbélébùú nípa àìlera, ṣùgbọ́n òun wà láààyè nípa agbára Ọlọ́run. Nítorí àwa pẹ̀lú jásí aláìlera nínú rẹ̀, ṣùgbọ́n àwa yóò wà láààyè pẹ̀lú rẹ̀ nípa agbára Ọlọ́run sí yín.
5 Ẹ máa wádìí ara yín, bí ẹ̀yin bá wà nínú ìgbàgbọ́; ẹ máa dán ara yín wò. Tàbí ẹ̀yin fúnrayín kò mọ ara yín pé Jesu Kristi wá nínú yín? Àfi bí ẹ̀yin bá jẹ́ àwọn tí a tanù. 6 Ṣùgbọ́n mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, àwa kì í ṣe àwọn tí a tanù. 7 Ǹjẹ́ àwa ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, kì í ṣe nítorí kí àwa lè farahàn bí àwọn ti ó tayọ̀, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè máa ṣe èyí tí ó dára bí àwa tilẹ̀ dàbí àwọn tí a tanù. 8 Nítorí àwa kò lè ṣe ohun kan lòdì sí òtítọ́, bí kò ṣe fún òtítọ́. 9 Nítorí àwa ń yọ̀, nígbà ti àwa jẹ́ aláìlera, tí ẹ̀yin sì jẹ́ alágbára; èyí ni àwa sì ń gbàdúrà fún pẹ̀lú, àní pípé yín. 10 Ìdí nìyí ti mo ṣe kọ̀wé àwọn nǹkan wọ̀nyí nígbà tí èmi kò sí lọ́dọ̀ yín, pé nígbà tí mo bá dé kí èmi má ba à lo ìkanra ní lílo àṣẹ, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Olúwa ti fi fún mí, láti mú ìdàgbàsókè, kì í ṣe láti fà yín ṣubú.
Ìkíni ìkẹyìn
11 Ní àkótán, ará ó dì gbòóṣe, ẹ ṣe àtúnṣe ọ̀nà yín, ẹ tújúká, ẹ jẹ́ onínú kan, ẹ máa wà ní àlàáfíà, Ọlọ́run ìfẹ́ àti ti àlàáfíà yóò wà pẹ̀lú yín.
12 (AK)Ẹ fi ìfẹnukonu mímọ́ kí ara yín.
13 (AL)Gbogbo àwọn ènìyàn Ọlọ́run níbi kí i yín.
14 (AM)Oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa, àti ìfẹ́ Ọlọ́run, àti ìdàpọ̀ ti Èmí Mímọ́, kí ó wà pẹ̀lú gbogbo yín.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.