Chronological
Paulu kọjá ní Makedonia àti Giriki
20 Nígbà tí ariwo náà sí rọlẹ̀, Paulu ránṣẹ́ pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn, ó sì gbà wọ́n ní ìyànjú, ó dágbére fún wọn, ó dìde láti lọ sí Makedonia. 2 Nígbà tí ó sì tí la apá ìhà wọ̀nyí kọjá, tí ó sì ti fi ọ̀rọ̀ púpọ̀ gbà wọ́n ní ìyànjú, ó wá sí ilẹ̀ Giriki. 3 Ó sì dúró níbẹ̀ ní oṣù mẹ́ta, nígbà tí àwọn Júù sì dènà dè é, bí ó ti ń pète àti bá ọkọ̀ ojú omi lọ sí Siria, ó pinnu rẹ̀ láti gbà Makedonia padà lọ.
Ọ̀rọ̀ ìkíni Paulu sí àwọn àyànfẹ́
1 (A)Paulu, ìránṣẹ́ Jesu Kristi, ẹni tí a ti pè láti jẹ́ aposteli, tí a sì ti yà sọ́tọ̀ láti wàásù ìhìnrere Ọlọ́run, 2 ìhìnrere tí ó ti ṣe ìlérí tẹ́lẹ̀ rí láti ẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ nínú ìwé Mímọ́. 3 Ní ti Ọmọ rẹ̀, ẹni tí a bí láti inú irú-ọmọ Dafidi nípa ti ara, 4 ẹni tí a pinnu rẹ̀ láti jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run nínú agbára gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí ìwà mímọ́, nípa àjíǹde kúrò nínú òkú, àní Jesu Kristi Olúwa wa. 5 (B)Láti ọ̀dọ̀ ẹni tí àwa rí oore-ọ̀fẹ́ àti jíjẹ́ aposteli gbà, fún ìgbọ́ràn ìgbàgbọ́ láàrín gbogbo orílẹ̀-èdè, nítorí orúkọ rẹ̀. 6 Ẹ̀yin pẹ̀lú si wa lára àwọn tí a pè sọ́dọ̀ Jesu Kristi.
7 (C)Sí gbogbo àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run tí ó wà ní Romu tí a ti pè láti jẹ́ ènìyàn mímọ́:
Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa àti láti ọ̀dọ̀ Olúwa wa Jesu Kristi.
Ìfojúsọ́nà Paulu láti bẹ Romu wò
8 (D)Ní àkọ́kọ́, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nípasẹ̀ Jesu Kristi fún gbogbo yín, nítorí a ń ròyìn ìgbàgbọ́ yin káàkiri gbogbo ayé. 9 Ọlọ́run ṣá à ni ẹlẹ́rìí mi, ẹni tí èmí ń fi gbogbo ẹ̀mí mi sìn nínú ìhìnrere Ọmọ rẹ̀, bí ó ti ṣe pé ní àìsimi ni èmí ń rántí yín nígbà gbogbo nínú àdúrà mi 10 (E)nínú àdúrà mi ìgbà gbogbo; mo tún ń gbàdúrà wí pé nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run kí ọ̀nà ó ṣí fún mi láti wá sọ́dọ̀ yín.
11 Nítorí èmi ń fẹ́ gidigidi láti tọ̀ yín wá, kí èmi lè fún yín ní ẹ̀bùn ẹ̀mí díẹ̀, kí a bá a le sọ yín di alágbára nínú Olúwa, 12 èyí nì ni pé, kí a lè jẹ́ ìwúrí fún ara wa nípa ìgbàgbọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan wa. 13 (F)Mo fẹ́ kí ẹ mọ èyí, ẹ̀yin ará mi, pé mo ti gbìyànjú lọ́pọ̀ ìgbà láti tọ̀ yín wá, (ṣùgbọ́n ìdíwọ́ wà fún mi), kí èmi ki ó lè jèrè ọkàn díẹ̀ láàrín yín, gẹ́gẹ́ bí mo ti ní láàrín àwọn aláìkọlà yòókù.
14 (G)Nítorí mo jẹ́ ajigbèsè sí Giriki àti sí àwọn aláìgbédè tí kì í ṣe Giriki, sí àwọn ọlọ́gbọ́n àti sí àwọn aṣiwèrè. 15 Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń làkàkà láti wá sí Romu àti láti fi gbogbo agbára mi wàásù ìhìnrere Ọlọ́run sí i yín.
16 (H)Èmi kò tijú ìhìnrere Jesu, nítorí agbára Ọlọ́run ní ín ṣe láti gba gbogbo àwọn tí ó bá gbàgbọ́ là, ọ̀rọ̀ yìí ni a kọ́kọ́ wàásù sí àwọn Júù nìkan, ṣùgbọ́n nísinsin yìí fún àwọn Helleni pẹ̀lú. 17 (I)Nítorí nínú ìhìnrere ni òdodo Ọlọ́run ti farahàn, òdodo Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé Mímọ́ pé, “Olódodo yóò yè nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀.”
Ìbínú Ọlọ́run sí orílẹ̀ ayé
18 (J)Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi ìbínú rẹ̀ hàn láti ọ̀run wá sí gbogbo àìwà-bí-Ọlọ́run àti gbogbo àìṣòdodo ènìyàn, àwọn tí ń fi ìwà búburú dènà ìmọ̀ òtítọ́ lọ́dọ̀ ènìyàn. 19 Nítorí pé, nǹkan gbogbo tí a lè mọ nípa Ọlọ́run ni a ti fihàn fún wọn, nítorí Ọlọ́run ti fi í hàn fún wọn. 20 (K)Nítorí pé láti ìgbà dídá ayé, gbogbo ohun àìlèfojúrí rẹ̀: bí agbára ayérayé àti ìwà-bí-Ọlọ́run rẹ̀ ni a rí gbangba tí a sì ń fi òye ohun tí a dá mọ̀ ọ́n kí ènìyàn má ba à wá àwáwí.
21 (L)Lóòótọ́, wọn ní òye nípa Ọlọ́run dáradára, ṣùgbọ́n wọn kò yìn ín lógo bí Ọlọ́run, wọ́n kò sí dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀; wọ́n ń ro èrò asán, ọkàn aṣiwèrè wọn sì ṣókùnkùn. 22 Níwọ́n bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n pe ara wọn ní ọlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n wọ́n di òmùgọ̀ pátápátá, 23 (M)wọ́n sì yí ògo Ọlọ́run tí kì í díbàjẹ́ sí àwọn àwòrán ère bí i ti ènìyàn tí í díbàjẹ́ àti ti ẹyẹ, àti ti ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin àti ti ẹranko afàyàfà.
24 Nítorí náà Ọlọ́run fà wọ́n lé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn wọn lọ́wọ́ láti máa ṣe ohun ìríra pẹ̀lú ara wọn èyí tí kò tọ́. 25 Wọ́n yí òtítọ́ Ọlọ́run sí èké, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ láti máa sin ẹ̀dá dípò ẹlẹ́dàá—ẹni tí ìyìn tọ́ sí láéláé. Àmín.
26 Nítorí èyí yìí ni Ọlọ́run ṣe fi wọ́n fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́: nítorí àwọn obìnrin wọn tilẹ̀ ń yí ìṣẹ̀dá ìbáṣepọ̀ tí ó tọ̀nà, sí èyí tí kò tọ̀nà. 27 Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin pẹ̀lú, wọn a máa fi ìbálòpọ̀ obìnrin nípa ti ẹ̀dá sílẹ̀, wọn a máa fẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí ara wọn, ọkùnrin ń bá ọkùnrin ṣe èyí tí kò yẹ, wọ́n sì ǹ jẹ èrè ìṣìnà wọn nínú ara wọn bí ó ti yẹ sí.
28 Àti gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti kọ̀ láti gba Ọlọ́run nínú ìmọ̀ tí ó tọ́, Ọlọ́run fi wọ́n fún iyè ríra láti ṣe ohun tí kò tọ́ fún wọn láti ṣe: 29 Wọ́n kún fún onírúurú àìṣòdodo gbogbo, àgbèrè, ìkà, ojúkòkòrò, àrankàn; wọ́n kún fún ìlara, ìpànìyàn, ìjà, ìtànjẹ, ìwà búburú; wọ́n jẹ́ a fi-ọ̀rọ̀-kẹ́lẹ́-banijẹ́. 30 Asọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn, akórìíra Ọlọ́run, aláfojúdi, agbéraga, ahalẹ̀, aláròṣe ohun búburú, aṣàìgbọràn sí òbí, 31 aláìníyè nínú, ọ̀dàlẹ̀, aláìnígbàgbọ́, ọ̀dájú, aláìláàánú: 32 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n mọ ìlànà Ọlọ́run pé, ẹni tí ó bá ṣe irú nǹkan wọ̀nyí yẹ sí ikú, wọn kò ní inú dídùn sí àwọn nǹkan wọ̀nyí nìkan ṣùgbọ́n wọ́n ní inú dídùn sí àwọn tí ń ṣe wọ́n.
Ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run
2 (N)Nítorí náà, aláìríwí ni ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó jẹ́ tí ń dá ni lẹ́jọ́: nítorí nínú ohun tí ìwọ ń ṣe ìdájọ́ ẹlòmíràn, ìwọ ń dá ara rẹ lẹ́bi; nítorí ìwọ tí ń dájọ́ ń ṣe ohun kan náà nínú èyí tí ìwọ ń dá ni lẹ́jọ́. 2 Ṣùgbọ́n àwa mọ̀ pé ìdájọ́ Ọlọ́run jẹ́ òtítọ́ si gbogbo àwọn tí ó ń ṣe irú ohun báwọ̀nyí. 3 Nítorí bí ìwọ tí ń ṣe ènìyàn lásán bá ń ṣe ìdájọ́ àwọn tí ń ṣe irú ohun báwọ̀nyí, tí ìwọ tìkára rẹ ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ ro èyí pé ìwọ o yọ nínú ìdájọ́ Ọlọ́run bí? 4 (O)Tàbí ìwọ ń gàn ọrọ̀ oore àti ìpamọ́ra àti sùúrù rẹ̀? Ìwọ kò ha mọ̀ pé oore Ọlọ́run ni ó ń fà ọ́ lọ sì ìrònúpìwàdà?
5 Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí líle àti àìronúpìwàdà ọkàn rẹ̀, ìwọ ń to ìbínú jọ fún ara rẹ de ọjọ́ ìbínú àti ìfihàn ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run. 6 (P)Ọlọ́run yóò san án fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀: 7 Àwọn ẹni tí ń fi sùúrù nínú rere ṣíṣe, wá ògo àti ọlá àti àìdíbàjẹ́ ni yóò fi ìyè àìnípẹ̀kun fún. 8 Ṣùgbọ́n fún àwọn onímọ̀-tara-ẹni-nìkan, tí wọn kò sì gba òtítọ́ gbọ́, ṣùgbọ́n tí wọn ń tẹ̀lé ọ̀nà búburú, wọn yóò ní ìrírí ìrunú àti ìbínú rẹ̀. 9 Ìpọ́njú àti ìrora, yóò wà lórí olúkúlùkù ọkàn ènìyàn tí ń hùwà ibi: ti Júù ṣáájú, àti àwọn Helleni pẹ̀lú; 10 ṣùgbọ́n ògo, àti ọlá, àti àlàáfíà, fún olúkúlùkù ẹni tí ń hùwà rere, fún Júù, ṣáájú àti fún àwọn Helleni pẹ̀lú: 11 Nítorí Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú ènìyàn.
12 (Q)Gbogbo àwọn tí ó ṣẹ̀ ní àìlófin wọn ó sì ṣègbé láìlófin: àti iye àwọn tí ó ṣẹ̀ lábẹ́ òfin, àwọn ni a ó fi òfin dá lẹ́jọ́; 13 (R)Nítorí kì í ṣe àwọn olùgbọ́ òfin ni ẹni ìdáláre lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n àwọn olùṣe òfin ni a ó dá láre. 14 Nítorí nígbà tí àwọn aláìkọlà, tí kò ní òfin, bá ṣe ohun tí ó wà nínú òfin nípa ìwà ẹ̀dá, àwọn wọ̀nyí, jẹ́ òfin fún ara wọn bí wọn kò tilẹ̀ ní òfin. 15 Àwọn ẹni tí ó fihàn pé, a kọ̀wé iṣẹ́ òfin sí wọn lọ́kàn, tí ẹ̀rí ọkàn wọn pẹ̀lú sì tún ń jẹ́ wọn lẹ́rìí, àti pé, èrò ọkàn wọn tí ó jẹ́ ọ̀nà ìfinisùn, sì ń gbè wọ́n lẹ́yìn ní ìsinsin yìí. 16 (S)Èyí yóò farahàn ní ọjọ́ náà nígbà tí Ọlọ́run yóò tipasẹ̀ Jesu Kristi ṣe ìdájọ́ àwọn àṣírí ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìhìnrere mi.
Àwọn Júù àti òfin
17 Ṣùgbọ́n bí a bá ń pe ìwọ ní Júù, tí o sì sinmi lé òfin, tí o sì ń ṣògo nínú ìbálòpọ̀ rẹ̀ sí Ọlọ́run, 18 (T)tí o sì mọ ìfẹ́ rẹ̀, tí o sì fọwọ́sí ohun tí ó dára jùlọ, nítorí tí a ti kọ́ ọ ní òfin; 19 tí o sì dá ara rẹ lójú pé ìwọ ni amọ̀nà àwọn afọ́jú, ìmọ́lẹ̀ fún àwọn tí ó wà ni òkùnkùn, 20 (U)Olùkọ́ àwọn aláìmòye, olùkọ́ àwọn ọmọdé, ẹni tí ó ní ètò ìmọ̀ àti òtítọ́ òfin lọ́wọ́, 21 (V)Ǹjẹ́ ìwọ tí o ń kọ́ ẹlòmíràn, ìwọ kò kọ́ ara rẹ? Ìwọ tí ó ń wàásù kí ènìyàn má jalè, ìwọ ha ń jalè bí? 22 Ìwọ tí o wí pé, kí ènìyàn má ṣe panṣágà, ìwọ ń ṣe panṣágà bí? Ìwọ tí o kórìíra òrìṣà, ìwọ ń ja tẹmpili ní olè bí? 23 Ìwọ ti ń ṣògo nínú òfin, ìwọ ha ń bu Ọlọ́run ni ọlá kù nípa rírú òfin? 24 (W)Nítorí gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́, “Orúkọ Ọlọ́run sá à di ìsọ̀rọ̀-òdì sí láàrín àwọn aláìkọlà nítorí yín.”
25 (X)Nítorí ìkọlà ní èrè nítòótọ́, bí ìwọ bá pa òfin mọ́; ṣùgbọ́n bí ìwọ bá jẹ́ arúfin, ìkọlà rẹ di àìkọlà. 26 (Y)Nítorí náà bí àwọn aláìkọlà bá pa ìlànà òfin mọ́, a kì yóò ha kà wọ́n sí àwọn tí a kọ nílà bí? 27 (Z)Aláìkọlà nípa àdánidá, bí ó bá pa òfin mọ́, yóò dá ẹ̀bi fún ìwọ tí ó jẹ́ arúfin nípa ti àkọsílẹ̀ òfin àti ìkọlà.
28 (AA)Kì í ṣe èyí tí ó farahàn ní òde ni Júù, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe èyí tí ó farahàn ní ara ni ìkọlà: 29 (AB)Ṣùgbọ́n Júù ti inú ni Júù, àti ìkọlà sì ni ti ọkàn nínú ẹ̀mí tí kì í ṣe ti àkọsílẹ̀, ìyìn ẹni tí kò sí lọ́dọ̀ ènìyàn, bí kò ṣe lọ́dọ̀ Ọlọ́run.
Ìṣòtítọ́ Ọlọ́run
3 Ǹjẹ́ àǹfààní wo ní Júù ní? Tàbí kín ni èrè ilà kíkọ? 2 (AC)Púpọ̀ lọ́nà gbogbo; pàtàkì jùlọ ni pé àwọn ni a fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lé lọ́wọ́.
3 Ǹjẹ́ kí ha ni bí àwọn kan jẹ́ aláìgbàgbọ́? Àìgbàgbọ́ wọn yóò ha sọ òtítọ́ Ọlọ́run di asán bí? 4 (AD)Kí a má rí! Kí Ọlọ́run jẹ́ olóòtítọ́, àti olúkúlùkù ènìyàn jẹ́ èké; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:
“Kí a lè dá ọ láre nínú ọ̀rọ̀ rẹ,
ṣùgbọ́n kí ìwọ lè borí nígbà tí ìwọ bá wá sí ìdájọ́.”
5 (AE)Ṣùgbọ́n bí àìṣòdodo wa bá fi òdodo Ọlọ́run hàn, kín ni àwa ó wí? Ọlọ́run ha jẹ́ àìṣòdodo bí? Nígbà tí ó bá ń fi ìbínú rẹ̀ hàn (Mo fi ṣe àkàwé bí ènìyàn). 6 Kí a má rí i. Bí bẹ́ẹ̀ bá ni, Ọlọ́run yóò ha ṣe lè dájọ́ aráyé? 7 Nítorí bí òtítọ́ Ọlọ́run bá di púpọ̀ sí ìyìn rẹ̀ nítorí èké mi, èéṣe tí a fi ń dá mi lẹ́jọ́ bí ẹlẹ́ṣẹ̀? 8 (AF)Èéṣe tí a kò fi ṣe búburú kí rere lè jáde wá? Bí àwọn kan tí ń fi ẹnu àtẹ́ sọ wí pé a ń sọ bẹ́ẹ̀; ti àwọn kan sì ń tẹnumọ́ ọn pé a sọ; àwọn ẹni tí ìdálẹ́bi wọn tọ́.
Kò sí olóòtítọ́ kan
9 (AG)Ǹjẹ́ kí ha ni? Àwa ha sàn ju wọn lọ bí? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá: nítorí a fihàn ṣáájú pé àti àwọn Júù àti àwọn Giriki, gbogbo wọn ni ó wà lábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀; 10 (AH)Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:
“Kò sí ẹni tí í ṣe olódodo, kò sí ẹnìkan
11 Kò sí ẹni tí òye yé,
kò sí ẹni tí ó ń wá Ọlọ́run.
12 Gbogbo wọn ni ó ti yapa,
wọ́n jùmọ̀ di aláìlérè;
kò sí ẹni tí ń ṣe rere,
kò tilẹ̀ sí ẹnìkan.”
13 (AI)“Ibojì tí ó ṣí sílẹ̀ ní ọ̀fun wọn:
ahọ́n wọn n sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.”
“Oró paramọ́lẹ̀ ń bẹ lábẹ́ ètè wọn.”
14 (AJ)“Ẹnu ẹni tí ó kún fún èpè àti fún oró kíkorò.”
15 (AK)“Ẹsẹ̀ wọn yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀:
16 ìparun àti ìpọ́njú wà lọ́nà wọn.
17 Ọ̀nà àlàáfíà ni wọn kò sì mọ̀:”
18 (AL)“Ìbẹ̀rù Ọlọ́run kò sí níwájú wọn.”
19 (AM)Àwa sì mọ̀ pé ohunkóhun tí òfin bá wí, ó ń wí fún àwọn tí ó wà lábẹ́ òfin: kí gbogbo ẹnu bá à lè dákẹ́ àti kí a lè mú gbogbo aráyé wá sábẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run. 20 (AN)Nítorí pé nípa iṣẹ́ òfin, a kì yóò dá ẹnikẹ́ni láre níwájú rẹ̀: nítorí nípa òfin ni ìmọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ ti wá.
Ìṣòdodo nípa ìgbàgbọ́
21 (AO)Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, a ti fi òdodo Ọlọ́run hàn láìsí òfin, tí a ti ń jẹ́rìí sí nípa òfin àti nípa àwọn wòlíì; 22 (AP)Àní òdodo Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́ nínú Jesu Kristi, sí gbogbo ènìyàn àti gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́: nítorí tí kò sí ìyàtọ̀ láàrín Júù àti Helleni. 23 (AQ)Gbogbo ènìyàn ni ó ṣá ti ṣẹ̀, tí wọ́n sì kùnà ògo Ọlọ́run: 24 (AR)Àwọn ẹni tí a ń dá láre lọ́fẹ̀ẹ́ nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, nípa ìdáǹdè tí ó wà nínú Kristi Jesu: 25 Ẹni tí Ọlọ́run ti gbé kalẹ̀ láti jẹ́ ètùtù nípa ìgbàgbọ́ nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, láti fi òdodo rẹ̀ hàn nítorí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti kọjá, nínú ìpamọ́ra Ọlọ́run: 26 (AS)Láti fi òdodo rẹ̀ hàn ní ìgbà ìsinsin yìí: kí ó lè jẹ́ olódodo àti olùdáláre ẹni tí ó gba Jesu gbọ́.
27 Ọ̀nà ìṣògo dà? A ti mú un kúrò. Nípa òfin wo? Nípa iṣẹ́? Bẹ́ẹ̀ kọ́: Ṣùgbọ́n nípa òfin ìgbàgbọ́. 28 (AT)Nítorí náà a parí rẹ̀ sí pé nípa ìgbàgbọ́ ni a ń dá ènìyàn láre láìsí iṣẹ́ òfin. 29 (AU)Ọlọ́run àwọn Júù nìkan ha ni bí? Kì í ha ṣe ti àwọn aláìkọlà pẹ̀lú? Bẹ́ẹ̀ ni, ti àwọn aláìkọlà pẹ̀lú: 30 (AV)Bí ó ti jẹ́ pé Ọlọ́run kan ni, yóò dá àwọn akọlà láre nípa Ìgbàgbọ́ àti àwọn aláìkọlà nípa ìgbàgbọ́ wọn. 31 (AW)Àwa ha ń sọ òfin dasán nípa ìgbàgbọ́ bí? Kí a má rí i: ṣùgbọ́n a ń fi òfin múlẹ̀.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.