Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Chronological

Read the Bible in the chronological order in which its stories and events occurred.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
2 Kọrinti 5-9

Ibùgbé wa ọrun

Nítorí àwa mọ̀ pé, bi ilé àgọ́ wa ti ayé ba wó, àwa ní ilé kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ilé tí a kò fi ọwọ́ kọ́, ti ayérayé nínú àwọn ọ̀run. Nítorí nítòótọ́ àwa ń kérora nínú èyí, àwa sì ń fẹ́ gidigidi láti fi ilé wa ti ọ̀run wọ̀ wá. Bí ó bá ṣe pé a ti fi wọ̀ wá, a kì yóò bá wa ní ìhòhò. Nítorí àwa tí a ń bẹ nínú àgọ́ yìí ń kérora nítòótọ́, kì í ṣe nítorí tí àwa fẹ́ jẹ́ aláìwọṣọ, ṣùgbọ́n pé a ó wọ̀ wá ní aṣọ sí i, kí ìyè ba à lè gbé ara kíkú mì. Ǹjẹ́ ẹni tí ó ti pèsè wa fún nǹkan yìí ni Ọlọ́run, ẹni tí o sì ti fi Ẹ̀mí fún wa pẹ̀lú ni ẹ̀rí ìdánilójú ohun tí ń bọ̀.

Nítorí náà àwa ní ìgboyà nígbà gbogbo, àwa sì mọ̀ pé, nígbà tí àwa ń bẹ ní ilé nínú ara, àwa kò sí lọ́dọ̀ Olúwa. Àwa ń gbé nípa ìgbàgbọ́, kì í ṣe nípa rí rí. Mo ní, àwa ní ìgboyà, àwa sì ń fẹ́ kí a kúkú ti inú ara kúrò, kí a sì lè wà ní ilé lọ́dọ̀ Olúwa. Nítorí náà àwa ń ṣakitiyan, pé, bí àwa bá wà ní ilé tàbí bí a kò sí, kí àwa lè jẹ́ ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀. 10 Nítorí pé gbogbo wa ni ó gbọdọ̀ fi ara hàn níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Kristi; kí olúkúlùkù lè gbà èyí tí ó ṣe gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó tọ́ sí i nígbà tí ó wà nínú ara ìbá à ṣe rere tàbí búburú.

Iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìlàjà tí a yà sọ́tọ̀

11 Nítorí náà bí àwa ti mọ ẹ̀rù Olúwa, àwa ń yí ènìyàn lọ́kàn padà; ṣùgbọ́n a ń fi wá hàn fún Ọlọ́run; mo sì gbàgbọ́ pé, a sì ti fì wá hàn ní ọkàn yín pẹ̀lú. 12 (A)Nítorí àwa kò sì ní máa tún yin ara wá sí i yín mọ́, ṣùgbọ́n àwa fi ààyè fún yín láti máa ṣògo nítorí wa, kí ẹ lè ní ohun tí ẹ̀yin yóò fi dá wọn lóhùn, àwọn ti ń ṣògo lóde ara kì í ṣe ní ọkàn. 13 Nítorí náà bí àwa bá ń sínwín, fún Ọlọ́run ni: tàbí bí iyè wá bá ṣí pépé, fún yín ni. 14 (B)Nítorí ìfẹ́ Kristi ń rọ̀ wá, nítorí àwa mọ̀ báyìí pé, bí ẹnìkan bá kú fún gbogbo ènìyàn, ǹjẹ́ nígbà náà, gbogbo wọ́n ni ó ti kú. 15 Ó sì ti kú fún gbogbo wọn, pé kí àwọn tí ó wà láààyè má sì ṣe wà láààyè fún ara wọn mọ́, bí kò ṣe fún ẹni tí ó kú nítorí wọn, tí ó sì ti jíǹde.

16 Nítorí náà láti ìsinsin yìí lọ, àwa kò mọ ẹnìkan nípa ti ara mọ́; bí àwa tilẹ̀ ti mọ Kristi nípa ti ara, ṣùgbọ́n nísinsin yìí àwa kò mọ̀ ọ́n bẹ́ẹ̀ mọ́. 17 (C)Nítorí náà bí ẹnìkan bá wà nínú Kristi, ó di ẹ̀dá tuntun: ohun àtijọ́ ti kọjá lọ; kíyèsi i, ohun tuntun ti dé. 18 (D)Ohun gbogbo sì ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, ẹni tí ó sì tipasẹ̀ Jesu Kristi bá wa làjà sọ́dọ̀ ara rẹ̀, tí ó sì ti fi iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìlàjà fún wa. 19 Èyí ni pé, Ọlọ́run wà nínú Kristi, ó ń bá aráyé làjà sọ́dọ̀ ara rẹ̀, kò sí ka ìrékọjá wọn sí wọn lọ́rùn; ó sì ti fi ọ̀rọ̀ ìlàjà lé wa lọ́wọ́. 20 (E)Nítorí náà àwa ni ikọ̀ fún Kristi, bí ẹni pé Ọlọ́run ń ti ọ̀dọ̀ wa ṣìpẹ̀ fún yín: àwa ń bẹ̀ yín ní ipò Kristi, “Ẹ bá Ọlọ́run làjà,” 21 (F)Nítorí ó tí fi í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ nítorí wa, ẹni tí kò mọ ẹ̀ṣẹ̀kẹ́ṣẹ̀ rí: kí àwa lè di òdodo Ọlọ́run nínú rẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí alábáṣiṣẹ́pọ̀ nínú Ọlọ́run, ǹjẹ́, àwa ń rọ̀ yín kí ẹ má ṣe gba oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run lásán. (G)Nítorí o wí pé,

“Ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà mi, èmi tí gbọ́ ohùn rẹ,
    àti ọjọ́ ìgbàlà, èmi sì ti ràn ọ́ lọ́wọ́.”

Èmi wí fún ọ, nísinsin yìí ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà, nísinsin yìí ni ọjọ́ ìgbàlà.

Àwọn wàhálà Paulu

Àwa kò sì gbé ohun ìkọ̀sẹ̀ kankan si ọ̀nà ẹnikẹ́ni, ki iṣẹ́ ìránṣẹ́ wa má ṣe di ìṣọ̀rọ̀-òdì-sí. (H)Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, ni ọnà gbogbo, àwa ń fi ara wa hàn bí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ sùúrù, nínú ìpọ́njú, nínú àìní, nínú wàhálà, (I)nípa nínà, nínú túbú, nínú ìrúkèrúdò, nínú iṣẹ́ àṣekára, nínú àìsàn, nínú ìgbààwẹ̀. Nínú ìwà mímọ́, nínú ìmọ̀, nínú ìpamọ́ra, nínú ìṣeun, nínú Ẹ̀mí Mímọ́, nínú ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn. (J)Nínú ọ̀rọ̀ òtítọ́, nínú agbára Ọlọ́run, nínú ìhámọ́ra òdodo ní apá ọ̀tún àti ní apá òsì. Nípa ọlá àti ẹ̀gàn, nípa ìyìn búburú àti ìhìnrere: bí ẹlẹ́tàn, ṣùgbọ́n a jásí olóòtítọ́, (K)bí ẹni tí a kò mọ̀, ṣùgbọ́n a mọ̀ wá dájúdájú; bí ẹni tí ń kú lọ, ṣùgbọ́n a ṣì wà láààyè; bí ẹni tí a nà, ṣùgbọ́n a kò sì pa wá, 10 (L)bí ẹni tí ó kún fún ìbànújẹ́, ṣùgbọ́n àwa ń yọ̀ nígbà gbogbo; bí tálákà, ṣùgbọ́n àwa ń sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ dí ọlọ́rọ̀; bí ẹni tí kò ní nǹkan, ṣùgbọ́n àwa ni ohun gbogbo.

11 (M)Ẹ̀yin ará Kọrinti, a ti bá yín sọ òtítọ́ ọ̀rọ̀, a ṣí ọkàn wa páyà sí yín. 12 Àwa kò fa ìfẹ́ wa sẹ́hìn fún yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin fa ìfẹ́ yín sẹ́hìn kúrò lọ́dọ̀ wa. 13 Ní sísán padà, ní ọ̀nà tí ó dára, èmi ń sọ bí ẹni pé fún àwọn ọmọdé, ẹ̀yin náà ẹ ṣí ọkàn yín páyà pẹ̀lú.

Má ṣe dàpọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́

14 Ẹ má ṣe fi àìdọ́gba dàpọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́: nítorí ìdàpọ̀ kín ni òdodo ní pẹ̀lú àìṣòdodo? Ìdàpọ̀ kín ni ìmọ́lẹ̀ sì ní pẹ̀lú òkùnkùn? 15 Ìrẹ́pọ̀ kín ni Kristi ní pẹ̀lú Beliali? Tàbí ìpín wó ni ẹni tí ó gbàgbọ́ ní pẹ̀lú aláìgbàgbọ́? 16 (N)Ìrẹ́pọ̀ kín ni tẹmpili Ọlọ́run ní pẹ̀lú òrìṣà? Nítorí ẹ̀yin ní tẹmpili Ọlọ́run alààyè; gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti wí pé:

“Èmi á gbé inú wọn,
    èmi o sì máa rìn láàrín wọn,
èmi ó sì jẹ́ Ọlọ́run wọn,
    wọn yóò sì jẹ́ ènìyàn mi.”

17 (O)Nítorí náà,

“Ẹ jáde kúrò láàrín wọn,
    kí ẹ sì yá ara yín si ọ̀tọ̀,
    ni Olúwa wí.
Ki ẹ má ṣe fi ọwọ́ kan ohun àìmọ́;
    Èmi ó sì gbà yín.”

18 Àti,

(P)“Èmi o sì jẹ́ Baba fún yín,
    Ẹ̀yin ó sì jẹ́ ọmọkùnrin mi àti ọmọbìnrin mi!
    ní Olúwa Olódùmarè wí.”

Nítorí náà, ẹ̀yin olùfẹ́, bí a ti ní àwọn ìlérí wọ̀nyí, ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wá mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ara àti ti ẹ̀mí, kí a sọ ìwà mímọ́ dí pípé nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run.

Ayọ̀ Paulu

(Q)Ẹ gbà wá tọkàntọkàn; a kò fi ibi ṣe ẹnikẹ́ni, a kò ba ẹnikẹ́ni jẹ́, a kò rẹ́ ẹnikẹ́ni jẹ. (R)Èmi kò sọ èyí láti dá a yín lẹ́bi; nítorí mo tí wí ṣáájú pé, ẹ̀yin wà nínú ọkàn wa kí a lè jùmọ̀ kú, àti kí a lè jùmọ̀ wà láààyè. Mo ní ìgboyà ńlá láti bá yín sọ̀rọ̀; ìṣògo mí lórí yín pọ̀; mo kún fún ìtùnú, mo sì ń yọ̀ rékọjá nínú gbogbo ìpọ́njú wa.

(S)Nítorí pé nígbà tí àwa tilẹ̀ dé Makedonia, ara wá kò balẹ̀, ṣùgbọ́n a ń pọ́n wá lójú níhà gbogbo, ìjà ń bẹ lóde, ẹ̀rù ń bẹ nínú. (T)Ṣùgbọ́n ẹni tí ń tu àwọn onírẹ̀lẹ̀ nínú, àní Ọlọ́run, ó tù wá nínú nípa dídé tí Titu dé; Kì í sì i ṣe nípa dídé rẹ̀ nìkan ṣùgbọ́n nípa ìtùnú náà pẹ̀lú tí ẹ ti tù ú nínú, nígbà tí ó ròyìn fún wa ìfẹ́ àtọkànwá yín, ìbànújẹ́ yín, àti ìtara yín fún mi; bẹ́ẹ̀ ní mo sì túbọ̀ yọ̀.

(U)Nítorí pé, bí mo tilẹ̀ ba inú yín jẹ́ nípa ìwé tí mo kọ èmi kò kábámọ̀ mọ́, bí mo tilẹ̀ ti kábámọ̀ tẹ́lẹ̀ rí; nítorí tí mo wòye pé ìwé mi mú yín banújẹ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé fún ìgbà díẹ̀. Èmi yọ̀ nísinsin yìí, kì í ṣe nítorí tí a mú inú yín bàjẹ́, ṣùgbọ́n nítorí tí a mú inú yín bàjẹ́ sí ìrònúpìwàdà: nítorí ti a mú inú yín bàjẹ́ bí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run, kí ẹ̀yin má ṣe ti ipasẹ̀ wa pàdánù ní ohunkóhun. 10 Nítorí pé ìbànújẹ́ ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run a máa ṣiṣẹ́ ìrònúpìwàdà sí ìgbàlà tí kì í mú àbámọ̀ wá: ṣùgbọ́n ìbànújẹ́ ti ayé a máa ṣiṣẹ́ ikú. 11 Kíyèsi i, nítorí ohun kan náà yìí tí a mú yin banújẹ́ fún bí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run, irú ìmúraṣíṣẹ́ tí ó mú jáde nínú yín, wíwẹ ara yín mọ́ ńkọ́, ìbànújẹ́ ńkọ́, ìpayà ńkọ́, ìfojúṣọ́nà ńkọ́, ìtara ńkọ́, ìjẹ́ni-níyà ńkọ́. Nínú ohun ààmì kọ̀ọ̀kan yìí ni ẹ̀yin ti fi ara yín hàn bí aláìlẹ́bi nínú ọ̀ràn náà. 12 (V)Nítorí náà, bí mo tilẹ̀ tí kọ̀wé sí yín, èmi kò kọ ọ́ nítorí ẹni tí ó ṣe ohun búburú náà tàbí nítorí ẹni ti a fi ohun búburú náà ṣe, ṣùgbọ́n kí àníyàn yín nítorí wá lè farahàn níwájú Ọlọ́run. 13 Nítorí náà, a tí fi ìtùnú yín tù wá nínú.

Àti nínú ìtùnú wa, a yọ̀ gidigidi nítorí pé Titu ní ayọ̀, nítorí láti ọ̀dọ̀ gbogbo yín ni a ti tu ẹ̀mí rẹ̀ lára. 14 Bí mo tilẹ̀ ti lérí ohunkóhun fún ún nítorí yín, a kò dójútì mí; ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí àwa ti sọ ohun gbogbo fún yín ní òtítọ́, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ìlérí wá níwájú Titu sì jásí òtítọ́. 15 Ọkàn rẹ̀ sì fà gidigidi sí yín, bí òun ti ń rántí ìgbọ́ràn gbogbo yín, bí ẹ ti fi ìbẹ̀rù àti ìwárìrì tẹ́wọ́gbà á. 16 Mo yọ̀ nítorí pé ní ohun gbogbo, mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú yín.

Ọ̀rọ̀ ìyànjú lórí ìfifúnni

Pẹ̀lúpẹ̀lú, ará, àwa ń sọ fún yín ní ti oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí a fífún àwọn ìjọ Makedonia; Bí ó ti jẹ́ pé a dán wọn wò nípa ìpọ́njú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayọ̀ àti àìlódiwọ̀n àìní wọn ti kún àkúnwọ́sílẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ ìlawọ́ wọn. (W)Nítorí mo jẹ́rìí pé gẹ́gẹ́ bí agbára wọn, àní ju agbára wọn, wọ́n ṣe é láti ìfẹ́ inú ara wọn. (X)Wọ́n ń fi ẹ̀bẹ̀ púpọ̀ rọ̀ wá ní ti ẹ̀bùn àtinúwá yìí, láti ba à lè ní ìpín nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn mímọ́. Àti èyí, kì í ṣe bí àwa tí rò rí, ṣùgbọ́n wọ́n tètè kọ́ fi àwọn fúnrawọn fún Olúwa, àti fún wá, nípa ìfẹ́ Ọlọ́run. (Y)Tó bẹ́ẹ̀ tí àwa fi gba Titu níyànjú pé, bí ó tí bẹ̀rẹ̀ náà, bẹ́ẹ̀ ni kí ó sì parí ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ yìí nínú yín pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin ti pọ̀ lóhùn gbogbo, ní ìgbàgbọ́, àti ọ̀rọ̀ àti ìmọ̀, àti nínú iṣẹ́ ìhìnrere gbogbo, àti ní ìfẹ́ yín sí wa, ẹ rí i wí pé ẹ̀yin pọ̀ sí i nínú ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ yìí pẹ̀lú.

Kì í ṣe nípa àṣẹ ni mo fi ń sọ ọ́, ṣùgbọ́n kí a lè rí ìdí òtítọ́ ìfẹ́ yín pẹ̀lú, nípa iṣẹ́ ìhìnrere ẹlòmíràn. (Z)Nítorí ẹ̀yin mọ oore-ọ̀fẹ́ Olúwa wa Jesu Kristi, pé bí òun ti jẹ́ ọlọ́rọ̀ rí ṣùgbọ́n nítorí yín ó di tálákà kí a lè sọ yín di ọlọ́rọ̀ nípa àìní rẹ̀.

10 (AA)Àti nínú èyí ni mo fi ìmọ̀ràn mi fún yín: nítorí èyí ṣe àǹfààní fún yín, ẹ̀yin tí ó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ níwọ̀n ọdún tí ó kọjá, kì í ṣe láti ṣe nǹkan, ṣùgbọ́n láti fẹ́ pẹ̀lú. 11 Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ parí ṣíṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú; kí ó ba à lè ṣe pé, bí ìpinnu fún ṣíṣe ti wà, bẹ́ẹ̀ ni kí ìparí sì wà láti inú agbára yín. 12 Nítorí bí ìpinnu bá wà ṣáájú, ó jásí ìtẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí ohun tí ènìyàn bá ní, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun tí kò ní.

13 Nítorí èmi kò fẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn wà ní ìrọ̀rùn, kí ó sì jẹ́ ìpọ́njú fún yín, ṣùgbọ́n pé nípa mímú dọ́gba, 14 Ní àkókò yìí, pé kí àníṣẹ́kù yín lè ṣe déédé àìní wọn, kí àníṣẹ́kù tiwọn pẹ̀lú ba à lè ṣe déédé àìní yín: kí ìmúdọ́gba ba à lè wà. 15 (AB)Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Ẹni tí ó kó púpọ̀ kò ní púpọ̀ jù, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó kó ìwọ̀nba kò ní kéré jù.”

A rán Titu sí Kọrinti

16 Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ní fún Ọlọ́run ẹni tí ó fi ìtara àníyàn kan náà yìí sí ọkàn Titu fún yín. 17 Nítorí kì í ṣe pé òun gba ọ̀rọ̀ ìyànjú wa nìkan ni; ṣùgbọ́n bí òun ti ní ìtara púpọ̀, òun tìkára rẹ̀ tọ̀ yín wá, fúnrarẹ̀. 18 (AC)Àwa ti rán arákùnrin náà pẹ̀lú rẹ̀, ìyìn ẹni tí ó wà nínú ìhìnrere yíká gbogbo ìjọ. 19 (AD)Kì í sì í ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n ẹni tí a tí yàn wá pẹ̀lú láti ọ̀dọ̀ ìjọ láti máa bá wa rìn kiri nínú ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ yìí, tí àwa ń ṣe ìránṣẹ́ rẹ̀ fún ògo Olúwa àti ìmúra ìtara wa. 20 Àwa ń yẹra fún èyí, kí ẹnikẹ́ni má ba à rí wí sí wa ní ti ẹ̀bùn àtinúwá yìí tí àwa pín. 21 Àwa ń gbèrò ohun rere, kì í ṣe níwájú Olúwa nìkan, ṣùgbọ́n níwájú ènìyàn pẹ̀lú.

22 Àwa sì ti rán arákùnrin wa pẹ̀lú wọn, ẹni tí àwa rí dájú nígbà púpọ̀ pé ó ní ìtara nínú ohun púpọ̀, ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí ni ìtara rẹ̀ túbọ̀ pọ̀ sí i nípa ìfọkàntán ńlá tí ó ní sí yín. 23 Bí ẹnikẹ́ni bá béèrè ẹni tí Titu jẹ́, ẹlẹgbẹ́ àti olùbáṣiṣẹ́ mi ni, nítorí yín; tàbí ní ti àwọn arákùnrin wa ni ẹnikẹ́ni ń béèrè, ìránṣẹ́ ìjọ ni wọ́n jẹ́, àti ògo Kristi. 24 Nítorí náà ẹ fi ẹ̀rí ìfẹ́ yín hàn wọ́n níwájú ìjọ, àti ìṣògo wa nítorí yín.

(AE)Nísinsin yìí, nípa ti ìpín fún ni fún àwọn ènìyàn mímọ́, kò tún yẹ mọ́ fún mi láti kọ̀wé sí yin ju bẹ́ẹ̀ lọ. (AF)Nítorí mo mọ ìtara láti ṣe ìrànlọ́wọ́ yín, èyí tí mo ti ṣògo fún àwọn ará Makedonia nítorí yín, pé, àwọn ara Akaia ti múra tan níwọ̀n ọdún kan tí ó kọjá ìtara yín sì ti rú ọ̀pọ̀lọpọ̀ sókè. (AG)Ṣùgbọ́n mo ti rán àwọn arákùnrin, kí ìṣògo wa nítorí yín má ṣe jásí asán ní ti ọ̀ràn yìí; pé gẹ́gẹ́ bí mó ti wí, kí ẹ̀yin lè múra tẹ́lẹ̀. Kí ó má ba à jẹ́ pé, bí àwọn nínú ara Makedonia bá bá mi wá, tí wọ́n sì bá yín ní àìmúra sílẹ̀, ojú a sì tì wá kì í ṣe ẹ̀yin, ní ti ìgbẹ́kẹ̀lé yìí. Nítorí náà ni mo ṣe rò pé ó yẹ láti gba àwọn arákùnrin níyànjú, kí wọn kọ́kọ́ tọ̀ yín wá, kí ẹ sì múra ẹ̀bùn yín, tí ẹ ti ṣe ìlérí tẹ́lẹ̀ sílẹ̀, kí ó lè ti wà ní lẹ́bi ẹ̀bùn gidi, kí ó má sì ṣe dàbí ohun ti a fi ìkùnsínú ṣe.

Ìfúnrúgbìn tọkàntọkàn

Ṣùgbọ́n èyí ni mo wí pé: Ẹni tí ó bá fúnrúgbìn kín ún, kín ún ni yóò ká; ẹni tí ó bá sì fúnrúgbìn púpọ̀, púpọ̀ ni yóò ká. (AH)Kí olúkúlùkù ènìyàn ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu ní ọkàn rẹ̀; kì í ṣe àfi ìkùnsínú ṣe, tàbí ti àìgbọdọ̀ má ṣe; nítorí Ọlọ́run fẹ́ onínúdídùn ọlọ́rẹ. (AI)Ọlọ́run sì lè mú kí gbogbo oore-ọ̀fẹ́ máa bí sí i fún yín; kí ẹ̀yin tí ó ní ànító ohun gbogbo, nígbà gbogbo, lè máa pọ̀ sí i ní iṣẹ́ rere gbogbo. (AJ)Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ ọ pé:

“Ó tí fọ́nká; ó ti fi fún àwọn tálákà;
    Òdodo rẹ̀ dúró láéláé.”

10 (AK)Ǹjẹ́ ẹni tí ń fi irúgbìn fún afúnrúgbìn, àti àkàrà fún oúnjẹ, yóò fi irúgbìn fún un yín, yóò sì sọ ọ́ di púpọ̀, yóò sì mú èso òdodo yín bí sí i. 11 Bẹ́ẹ̀ ni a ó sọ yín di ọlọ́rọ̀ nínú ohun gbogbo, fún ìlawọ́ yín gbogbo tí ń ṣiṣẹ́ ọpẹ́ sí Ọlọ́run nípa wa.

12 Nítorí iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìsìn yìí kò kún ìwọ̀n àìní àwọn ènìyàn mímọ́ nìkan, ṣùgbọ́n ó túbọ̀ pọ̀ sí i nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọpẹ́ sí Ọlọ́run. 13 (AL)Nítorí ìdúró yin lábẹ́ ìdánwò iṣẹ́ ìsìn yìí, wọn yóò yin Ọlọ́run lógo fún ìgbọ́ràn yín ní gbígba ìhìnrere Kristi àti nípa ìlawọ́ ìdáwó yín fún wọn àti fún gbogbo ènìyàn. 14 Àti nínú àdúrà fún un yín, ọkàn wọn ń ṣe àfẹ́rí yín nítorí ọ̀pọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run ti ń bẹ nínú yín. 15 (AM)Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nítorí aláìlèfẹnusọ ẹ̀bùn rẹ̀!

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.