Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Chronological

Read the Bible in the chronological order in which its stories and events occurred.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Matiu 9-10

Jesu mú arọ láradá

(A)Jesu bọ́ sínú ọkọ̀, ó sì rékọjá odò lọ sí ìlú abínibí rẹ̀ (B)Àwọn ọkùnrin kan gbé arọ kan tọ̀ ọ́ wá lórí àkéte rẹ̀. Nígbà tí Jesu rí ìgbàgbọ́ wọn, ó wí fún arọ náà pé, “Ọmọ tújúká, a dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”

Nígbà yìí ni àwọn olùkọ́ òfin wí fún ara wọn pé, “Ọkùnrin yìí ń sọ̀rọ̀-òdì!”

Jesu sì mọ̀ èrò inú wọn, ó wí pé, “Nítorí kín ni ẹ̀yin ṣe ń ro búburú nínú yín? Èwo ni ó rọrùn jù: láti wí pé, ‘A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ;’ tàbí wí pé, ‘Dìde, kí o sì máa rìn?’ Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ pé Ọmọ Ènìyàn ní agbára ní ayé láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì ni.” Ó sì wí fún arọ náà pé, “Dìde, sì gbé àkéte rẹ, kí o sì máa lọ ilé rẹ.” Ọkùnrin náà sì dìde, ó sì lọ ilé rẹ̀. Nígbà tí ìjọ ènìyàn rí í ẹnu sì yà wọ́n, wọ́n yin Ọlọ́run lógo, ti ó fi irú agbára báyìí fún ènìyàn.

Ìpè Matiu

(C)Bí Jesu sì ti ń rékọjá láti ibẹ̀ lọ, o rí ọkùnrin kan ti à ń pè ní Matiu, ó jókòó ní ibùdó àwọn agbowó òde, ó sì wí fún un pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn,” Matiu sì dìde, ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

10 Ó sì ṣe, bí Jesu tí jókòó ti ó ń jẹun nínú ilé Matiu, sì kíyèsi i, ọ̀pọ̀ àwọn agbowó òde àti “ẹlẹ́ṣẹ̀” wá, wọ́n sì bá a jẹun pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. 11 Nígbà tí àwọn Farisi sì rí i, wọ́n wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “ ‘Èéṣe’ tí olùkọ́ yín fi ń bá àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun pọ̀?”

12 Ṣùgbọ́n nígbà tí Jesu gbọ́ èyí, ó wí fún wọn pé, “Àwọn tí ara wọ́n le kò wá oníṣègùn bí kò ṣe àwọn tí ara wọn kò dá. 13 Ṣùgbọ́n ẹ lọ kọ́ ohun ti èyí túmọ̀ sí: ‘Àánú ni èmi ń fẹ́, kì í ṣe ẹbọ;’ nítorí èmi kò wá láti pe àwọn olódodo, bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.”

Ìbéèrè nípa àwẹ̀ lọ́wọ́ Jesu

14 (D)Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu tọ̀ ọ́ wá láti béèrè wí pé, “Èéṣe tí àwa àti àwọn Farisi fi ń gbààwẹ̀, ṣùgbọ́n tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kò gbààwẹ̀?”

15 Jesu sì dáhùn pé, “Àwọn ọmọ ilé ìyàwó ha le máa ṣọ̀fọ̀, nígbà tí ọkọ ìyàwó ń bẹ lọ́dọ̀ wọn? Ṣùgbọ́n ọjọ́ ń bọ̀ nígbà tí a ó gba ọkọ ìyàwó lọ́wọ́ wọn; nígbà náà ni wọn yóò gbààwẹ̀.

16 “Kò sí ẹni tí ń fi ìrépé aṣọ tuntun lẹ ògbólógbòó ẹ̀wù; nítorí èyí tí a fi lẹ̀ ẹ́ yóò ya ní ojú lílẹ̀, aṣọ náà yóò sì ya púpọ̀ sì i ju ti ìṣáájú lọ. 17 Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí fi ọtí tuntun sínú ògbólógbòó ìgò-awọ; bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìgò-awọ yóò bẹ́, ọtí á sì tú jáde, ìgò-awọ á sì ṣègbé. Ṣùgbọ́n ọtí tuntun ni wọn í fi sínú ìgò-awọ tuntun àwọn méjèèjì a sì ṣe déédé.”

Ọmọbìnrin tó kú àti obìnrin onísun-ẹ̀jẹ̀

18 Bí ó ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí fún wọn, kíyèsi i, ìjòyè kan tọ̀ ọ́ wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀ wí pé, “Ọmọbìnrin mi kú nísinsin yìí, ṣùgbọ́n wá fi ọwọ́ rẹ̀ lé e, òun yóò sì yè.” 19 Jesu dìde ó sì bá a lọ àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.

20 Sì kíyèsi i, obìnrin kan ti ó ní ìsun ẹ̀jẹ̀ ní ọdún méjìlá, ó wá lẹ́yìn rẹ̀, ó fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀. 21 Nítorí ó wí nínú ara rẹ̀ pé, “Bí mo bá sá à le fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀, ara mi yóò dá.”

22 (E)Nígbà tí Jesu sì yí ara rẹ̀ padà tí ó rí i, ó wí pé, “Ọmọbìnrin, tújúká, ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradà.” A sì mú obìnrin náà láradá ni wákàtí kan náà.

23 Nígbà tí Jesu sí i dé ilé ìjòyè náà, ó bá àwọn afunfèrè àti ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó ń pariwo. 24 Ó wí fún wọn pé, “Ẹ máa lọ; nítorí ọmọbìnrin náà kò kú, sísùn ni ó sùn.” Wọ́n sì fi i rín ẹ̀rín ẹlẹ́yà. 25 Ṣùgbọ́n nígbà tí a ti àwọn ènìyàn jáde, ó wọ ilé, ó sì fà ọmọbìnrin náà ní ọwọ́ sókè; bẹ́ẹ̀ ni ọmọbìnrin náà sì dìde. 26 Òkìkí èyí sì kàn ká gbogbo ilẹ̀ náà.

Jesu wo afọ́jú àti odi sàn

27 (F)Nígbà tí Jesu sì jáde níbẹ̀, àwọn ọkùnrin afọ́jú méjì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, wọ́n ń kígbe sókè wí pé, “Ṣàánú fún wa, ìwọ ọmọ Dafidi.”

28 Nígbà tí ó sì wọ̀ ilé, àwọn afọ́jú náà tọ̀ ọ́ wá, Jesu bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin gbàgbọ́ pé mo le ṣe èyí?”

Wọn sì wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa, ìwọ lè ṣe é.”

29 Ó sì fi ọwọ́ bà wọ́n ní ojú, ó wí pé, “Kí ó rí fún yín gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ yín.” 30 Ojú wọn sì là; Jesu sì kìlọ̀ fún wọn gidigidi, wí pé, “Kíyèsi i, kí ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan kí ó mọ̀ nípa èyí.” 31 Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n lọ, wọ́n ròyìn rẹ̀ yí gbogbo ìlú náà ká.

32 (G)Bí wọ́n tí ń jáde lọ, wò ó wọ́n mú ọkùnrin odi kan tí ó ní ẹ̀mí èṣù tọ Jesu wá. 33 Nígbà tí a lé ẹ̀mí èṣù náà jáde, ọkùnrin tí ó ya odi sì fọhùn. Ẹnu sì ya àwọn ènìyàn, wọ́n wí pé, “A kò rí irú èyí rí ní Israẹli.”

34 Ṣùgbọ́n àwọn Farisi wí pé, “Agbára olórí àwọn ẹ̀mí èṣù ni ó fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.”

Àwọn Alágbàṣe Kéré

35 (H)Jesu sì rìn yí gbogbo ìlú ńlá àti ìletò ká, ó ń kọ́ni nínú Sinagọgu wọn, ó sì ń wàásù ìhìnrere ìjọba ọrun, ó sì ń ṣe ìwòsàn ààrùn àti gbogbo àìsàn ní ara àwọn ènìyàn. 36 (I)Nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ ènìyàn, àánú wọn ṣe é, nítorí àárẹ̀ mú wọn, wọn kò sì rí ìrànlọ́wọ́, bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́. 37 (J)Nígbà náà ni ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Lóòótọ́ ni ìkórè pọ̀ ṣùgbọ́n àwọn alágbàṣe kò tó nǹkan 38 Nítorí náà, ẹ gbàdúrà sí Olúwa ìkórè kí ó rán àwọn alágbàṣe sínú ìkórè rẹ̀.”

Jesu rán àwọn méjìlá jáde

10 (K)Jesu sì pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá sí ọ̀dọ̀; ó fún wọn ní àṣẹ láti lé ẹ̀mí àìmọ́ jáde àti láti ṣe ìwòsàn ààrùn àti àìsàn gbogbo.

Orúkọ àwọn aposteli méjèèjìlá náà ni wọ̀nyí:

ẹni àkọ́kọ́ ni Simoni ẹni ti a ń pè ni Peteru àti arákùnrin rẹ̀ Anderu;

Jakọbu[a] ọmọ Sebede àti arákùnrin rẹ̀ Johanu.

Filipi àti Bartolomeu;

Tomasi àti Matiu agbowó òde;

Jakọbu ọmọ Alfeu àti Taddeu;

Simoni ọmọ ẹgbẹ́ Sealoti, Judasi Iskariotu, ẹni tí ó da Jesu.

(L)Àwọn méjèèjìlá wọ̀nyí ni Jesu ran, ó sì pàṣẹ fún wọn pé: “Ẹ má ṣe lọ sì ọ̀nà àwọn kèfèrí, ẹ má ṣe wọ̀ ìlú àwọn ará Samaria Ẹ kúkú tọ̀ àwọn àgùntàn ilé Israẹli tí ó nù lọ. Bí ẹ̀yin ti ń lọ, ẹ máa wàásù yìí wí pé: ‘Ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀.’ Ẹ máa ṣe ìwòsàn fún àwọn aláìsàn, ẹ si jí àwọn òkú dìde, ẹ sọ àwọn adẹ́tẹ̀ di mímọ́, kí ẹ sì máa lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. Ọ̀fẹ́ ni ẹ̀yin gbà á, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fi fún ni.

“Ẹ má ṣe mú wúrà tàbí fàdákà tàbí idẹ sínú àpò ìgbànú yín; 10 Ẹ má ṣe mú àpò fún ìrìnàjò yín, kí ẹ má ṣe mú ẹ̀wù méjì, tàbí bàtà, tàbí ọ̀pá; oúnjẹ oníṣẹ́ yẹ fún un. 11 Ìlúkílùú tàbí ìletòkíletò tí ẹ̀yin bá wọ̀, ẹ wá ẹni ti ó bá yẹ níbẹ̀ rí, níbẹ̀ ni kí ẹ sì gbé nínú ilé rẹ̀ títí tí ẹ̀yin yóò fi kúrò níbẹ̀. 12 Nígbà tí ẹ̀yin bá sì wọ ilé kan, ẹ kí i wọn. 13 Bí ilé náà bá sì yẹ, kí àlàáfíà yín kí ó bà sórí rẹ̀; ṣùgbọ́n bí kò bá yẹ, kí àlàáfíà yín kí ó padà sọ́dọ̀ yín. 14 Bí ẹnikẹ́ni tí kò bá sì gbà yín, tàbí tí kò gba ọ̀rọ̀ yín, ẹ gbọn eruku ẹ̀ṣẹ̀ yín sílẹ̀ tí ẹ bá ń kúrò ní ilé tàbí ìlú náà. 15 Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, yóò sàn fún ìlú Sodomu àti Gomorra ní ọjọ́ ìdájọ́ ju àwọn ìlú náà lọ.

16 “Mò ń rán yín lọ gẹ́gẹ́ bí àgùntàn sáàrín ìkookò. Nítorí náà, kí ẹ ní ìṣọ́ra bí ejò, kí ẹ sì ṣe onírẹ̀lẹ̀ bí àdàbà. 17 (M)Ẹ ṣọ́ra lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn nítorí wọn yóò fi yín le àwọn ìgbìmọ̀ ìgbèríko lọ́wọ́ wọn yóò sì nà yín nínú Sinagọgu. 18 Nítorí orúkọ mi, a ó mú yín lọ síwájú àwọn baálẹ̀ àti àwọn ọba, bí ẹlẹ́rìí sí wọn àti àwọn aláìkọlà. 19 Nígbà tí wọ́n bá mú yín, ẹ má ṣe ṣàníyàn ohun tí ẹ ó sọ tàbí bí ẹ ó ṣe sọ ọ́. Ní ojú kan náà ni a ó fi ohun tí ẹ̀yin yóò sọ fún yín. 20 Nítorí pé kì í ṣe ẹ̀yin ni ó sọ ọ́, bí kò ṣe Ẹ̀mí Baba yín tí ń sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ yín.

21 (N)“Arákùnrin yóò sì fi arákùnrin fún pípa. Baba yóò fi àwọn ọmọ rẹ̀ fún ikú pa. Àwọn ọmọ yóò ṣọ̀tẹ̀ sí òbí wọn, wọn yóò sì mú kí a pa wọ́n. 22 Gbogbo ènìyàn yóò sì kórìíra yín nítorí mi, ṣùgbọ́n gbogbo ẹni tí ó bá dúró ṣinṣin dé òpin ni a ó gbàlà. 23 Nígbà tí wọn bá ṣe inúnibíni sì i yín ní ìlú kan, ẹ sálọ sì ìlú kejì. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹ̀yin kò tì í le la gbogbo ìlú Israẹli já tán kí Ọmọ Ènìyàn tó dé.

24 (O)“Akẹ́kọ̀ọ́ kì í ju olùkọ́ rẹ̀ lọ, bẹ́ẹ̀ ni ọmọ ọ̀dọ̀ kì í ju ọ̀gá rẹ̀ lọ. 25 Ó tọ́ fún akẹ́kọ̀ọ́ láti dàbí olùkọ́ rẹ̀ àti fún ọmọ ọ̀dọ̀ láti rí bí ọ̀gá rẹ̀. Nígbà tí wọ́n bá pe baálé ilé ní Beelsebulu, mélòó mélòó ni ti àwọn ènìyàn ilé rẹ̀!

26 (P)(Q) “Nítorí náà, ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn, nítorí kò sí ohun tó ń bọ̀ tí kò ní í fi ara hàn, tàbí ohun tó wà ní ìkọ̀kọ̀ tí a kò ní mọ̀ ni gbangba. 27 Ohun tí mo bá wí fún yín ní òkùnkùn, òun ni kí ẹ sọ ní ìmọ́lẹ̀. Èyí tí mo sọ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ sì etí yín ni kí ẹ kéde rẹ́ lórí òrùlé. 28 Ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn tí ó le pa ara nìkan; ṣùgbọ́n tí wọn kò lè pa ẹ̀mí. Ẹ bẹ̀rù Ẹni tí ó le pa Ẹ̀mí àti ara run ní ọ̀run àpáàdì. 29 Ológoṣẹ́ méjì kọ́ ni à ń tà ní owó idẹ wẹ́wẹ́ kan? Síbẹ̀ kò sí ọ̀kan nínú wọn tí yóò ṣubú lu ilẹ̀ lẹ́yìn Baba yin. 30 Àti pé gbogbo irun orí yín ni a ti kà pé. 31 Nítorí náà, ẹ má ṣe fòyà; ẹ̀yin ní iye lórí ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.

32 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ mi níwájú ènìyàn, òun náà ni èmi yóò jẹ́wọ́ rẹ̀ níwájú Baba mi ní ọ̀run. 33 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sẹ́ mí níwájú àwọn ènìyàn, òun náà ni èmi náà yóò sọ wí pé n kò mọ̀ níwájú Baba mi ní ọ̀run.

34 (R)“Ẹ má ṣe rò pé mo mú àlàáfíà wá sí ayé, Èmi kò mú àlàáfíà wá bí kò ṣe idà. 35 Nítorí èmi wá láti ya

“ ‘ọmọkùnrin ní ipa sí baba rẹ̀,
    ọmọbìnrin ní ipa sí ìyá rẹ̀,
àti aya ọmọ sí ìyakọ rẹ̀…
36     Ará ilé ènìyàn ni yóò sì máa ṣe ọ̀tá rẹ̀.’

37 (S)“Ẹni tí ó bá fẹ́ baba rẹ̀ tàbí ìyá rẹ̀ jù mí lọ, kò yẹ ní tèmi, ẹni tí ó ba fẹ́ ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin rẹ̀ jù mí lọ, kò yẹ ní tèmi; 38 Ẹni tí kò bá gbé àgbélébùú rẹ̀ kí ó tẹ̀lé mi kò yẹ ní tèmi. 39 Ẹni tí ó bá wa ẹ̀mí rẹ̀ yóò sọ ọ́ nù, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sọ ẹ̀mí rẹ̀ nú nítorí tèmi ni yóò rí i.

40 (T)“Ẹni tí ó bá gbà yín, ó gbà mí, ẹni tí ó bá sì gbà mí gba ẹni tí ó rán mi. 41 Ẹni tí ó ba gba wòlíì, nítorí pé ó jẹ́ wòlíì yóò jẹ èrè wòlíì, ẹni tí ó bá sì gba olódodo nítorí ti ó jẹ́ ènìyàn olódodo, yóò jẹ èrè olódodo. 42 Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ago omi tútù fún ọ̀kan nínú àwọn onírẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí mu nítorí tí ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, kò ní pàdánù èrè rẹ̀.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.