Chronological
Ìdánwò Jesu
4 (A)Nígbà náà ni Ẹ̀mí Mímọ́ darí Jesu sí ijù láti dán an wò láti ọwọ́ èṣù. 2 (B)Lẹ́yìn tí Òun ti gbààwẹ̀ ní ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, ebi sì ń pa á. 3 Nígbà náà ni olùdánwò tọ̀ ọ́ wá, ó wí pé, “Bí ìwọ bá ṣe Ọmọ Ọlọ́run, pàṣẹ kí òkúta wọ̀nyí di àkàrà.”
4 (C)Ṣùgbọ́n Jesu dáhùn pé, “A ti kọ ìwé rẹ̀ pé: ‘Ènìyàn kì yóò wà láààyè nípa àkàrà nìkan, bí kò ṣe nípa gbogbo ọ̀rọ̀ ti ó ti ẹnu Ọlọ́run jáde wá.’ ”
5 (D)Lẹ́yìn èyí ni èṣù gbé e lọ sí ìlú mímọ́ náà; ó gbé e lé ibi ṣóńṣó tẹmpili. 6 (E)Ó wí pé, “Bí ìwọ̀ bá jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run, bẹ́ sílẹ̀ fún ara rẹ. A sá à ti kọ̀wé rẹ̀ pé:
“ ‘Yóò pàṣẹ fún àwọn angẹli rẹ̀ nítorí tìrẹ
wọn yóò sì gbé ọ sókè ni ọwọ́ wọn
kí ìwọ kí ó má ba à fi ẹsẹ̀ rẹ gbún òkúta.’ ”
7 (F)Jesu sì dalóhùn, “A sá à ti kọ ọ́ pé: ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dán Olúwa Ọlọ́run rẹ wò.’ ”
8 Lẹ́ẹ̀kan sí i, èṣù gbé e lọ sórí òkè gíga, ó sì fi gbogbo ilẹ̀ ọba ayé àti gbogbo ògo wọn hàn án. 9 Ó sì wí fún un pé, “Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi yóò fi fún ọ, bí ìwọ bá foríbalẹ̀ tí o sì sìn mi.”
10 (G)Jesu wí fún un pé, “Padà kúrò lẹ́yìn mi, Satani! Nítorí a ti kọ ọ́ pé: ‘Olúwa Ọlọ́run rẹ ni kí ìwọ kí ó fi orí balẹ̀ fún, òun nìkan ṣoṣo ni kí ìwọ máa sìn.’ ”
11 (H)Nígbà náà ni èṣù fi í sílẹ̀ lọ, àwọn angẹli sì tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì ṣe ìránṣẹ́ fún un.
Jesu bẹ̀rẹ̀ sí wàásù
12 (I)Nígbà tí Jesu gbọ́ wí pé a ti fi Johanu sínú túbú ó padà sí Galili. 13 (J)Ó kúrò ní Nasareti, ó sì lọ í gbé Kapernaumu, èyí tí ó wà létí Òkun Sebuluni àti Naftali. 14 Kí èyí tí a ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu wòlíì Isaiah lè ṣẹ pé:
15 (K)“ìwọ Sebuluni àti ilẹ̀ Naftali
ọ̀nà tó lọ sí Òkun, ní ọ̀nà Jordani,
Galili ti àwọn kèfèrí.
16 Àwọn ènìyàn tí ń gbé ni òkùnkùn
tí ri ìmọ́lẹ̀ ńlá,
àti àwọn tó ń gbé nínú ilẹ̀ òjijì ikú
ni ìmọ́lẹ̀ tan fún.”
17 (L)Láti ìgbà náà lọ ni Jesu ti bẹ̀rẹ̀ sí wàásù: “Ẹ ronúpìwàdà, nítorí tí ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀.”
Pípe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àkọ́kọ́
18 (M)Bí Jesu ti ń rìn létí Òkun Galili, ó rí àwọn arákùnrin méjì, Simoni, ti à ń pè ní Peteru, àti Anderu arákùnrin rẹ̀. Wọ́n ń sọ àwọ̀n wọn sínú Òkun nítorí apẹja ni wọ́n. 19 Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ wá, ẹ máa tọ̀ mí lẹ́yìn èmi yóò sì sọ yín di apẹja ènìyàn.” 20 Lójúkan náà, wọ́n fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.
21 Bí ó sì ti kúrò ní ibẹ̀, ò rí àwọn arákùnrin méjì mìíràn, Jakọbu ọmọ Sebede àti Johanu, arákùnrin rẹ̀. Wọ́n wà nínú ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú Sebede baba wọn, wọ́n ń di àwọ̀n wọn, Jesu sì pè àwọn náà pẹ̀lú. 22 Lójúkan náà, wọ́n fi ọkọ̀ ojú omi àti baba wọn sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.
Jesu ṣe ìwòsàn
23 (N)Jesu sì rin káàkiri gbogbo Galili, ó ń kọ́ni ní Sinagọgu, ó ń wàásù ìhìnrere ti ìjọba ọ̀run, ó sì ń ṣe ìwòsàn ààrùn gbogbo àti àìsàn láàrín gbogbo ènìyàn. 24 Òkìkí rẹ̀ sì kàn yí gbogbo Siria ká; wọ́n sì gbé àwọn aláìsàn tí ó ní onírúurú ààrùn, àwọn tí ó ní ìnira ẹ̀mí èṣù, àti àwọn ti o ní wárápá àti àwọn tí ó ní ẹ̀gbà; ó sì wò wọ́n sàn. 25 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn láti Galili, Dekapoli, Jerusalẹmu, Judea, àti láti òkè odò Jordani sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.
Ìdánwò Jesu
4 (A)Jesu sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó padà ti Jordani wá, a sì ti ọwọ́ Ẹ̀mí darí rẹ̀ sí ijù; 2 (B)Ogójì ọjọ́ ni a fi dán an wò lọ́wọ́ èṣù. Kò sì jẹ ohunkóhun ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì: nígbà tí wọ́n sì parí, lẹ́yìn náà ni ebi wá ń pa á.
3 Èṣù sì wí fún un pé, “Bí ìwọ bá ṣe Ọmọ Ọlọ́run, pàṣẹ fún òkúta yìí kí ó di àkàrà.”
4 (C)Jesu sì dáhùn, ó wí fún un pé, “A ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Ènìyàn kì yóò wà láààyè nípa àkàrà nìkan.’ ”
5 Lójúkan náà, èṣù sì mú un lọ sí orí òkè gíga, ó sì fi gbogbo ilẹ̀ ọba ayé hàn án. 6 (D)Èṣù sì wí fún un pé, “Ìwọ ni èmi ó fi gbogbo agbára yìí àti ògo wọn fún: nítorí á sá ti fi fún mi. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wù mí, èmi a fi í fún. 7 Ǹjẹ́ bí ìwọ bá foríbalẹ̀ fún mi, gbogbo rẹ̀ ni yóò jẹ́ tìrẹ.”
8 (E)Jesu sì dáhùn ó sì wí fún un pé, “Kúrò lẹ́yìn mi, Satani, nítorí tí a kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ìwọ foríbalẹ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, òun nìkan ṣoṣo ni kí ìwọ kí ó sì máa sìn.’ ”
9 Èṣù sì mú un lọ sí Jerusalẹmu, ó sì gbé e lé ibi ṣóńṣó tẹmpili, ó sì wí fún un pé, “Bí ìwọ bá ṣe Ọmọ Ọlọ́run, bẹ́ sílẹ̀ fún ara rẹ láti ibí yìí: 10 (F)A sá ti kọ̀wé rẹ̀ pé:
“ ‘Yóò pàṣẹ fún àwọn angẹli rẹ̀ nítorí rẹ,
láti máa ṣe ìtọ́jú rẹ:
11 Àti pé ní ọwọ́ wọn ni wọn ó gbé ọ sókè,
kí ìwọ kí ó má ba à fi ẹsẹ̀ rẹ gbún òkúta.’ ”
12 (G)Jesu sì dáhùn ó wí fún un pé, “A ti kọ́ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dán Olúwa Ọlọ́run rẹ wò.’ ”
13 (H)Nígbà tí èṣù sì parí ìdánwò náà gbogbo, ó fi í sílẹ̀ lọ fun sá à kan.
A kọ Jesu ni Nasareti
14 (I)Jesu sì fi agbára Ẹ̀mí padà wá sí Galili: òkìkí rẹ̀ sì kàn kálẹ̀ ní gbogbo agbègbè tí ó yí i ká. 15 (J)Ó sì ń kọ́ni nínú Sinagọgu wọn; a ń yìn ín lógo láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn ènìyàn wá.
16 (K)Ó sì wá sí Nasareti, níbi tí a gbé ti tọ́ ọ dàgbà: bí ìṣe rẹ̀ ti rí, ó sì wọ inú Sinagọgu lọ ní ọjọ́ ìsinmi, ó sì dìde láti kàwé. 17 A sì fi ìwé wòlíì Isaiah fún un. Nígbà tí ó sì ṣí ìwé náà, ó rí ibi tí a gbé kọ ọ́ pé:
18 “Ẹ̀mí Olúwa ń bẹ lára mi,
Nítorí tí ó fi ààmì òróró yàn mí
láti wàásù ìhìnrere fún àwọn òtòṣì.
Ó ti rán mi wá láti wàásù ìdásílẹ̀ fún àwọn ìgbèkùn, àti
ìmúnríran fún àwọn afọ́jú,
àti láti jọ̀wọ́ àwọn tí a pa lára lọ́wọ́,
19 láti kéde ọdún ojúrere Olúwa.”
20 Ó sì pa ìwé náà dé, ó fi í fún ìránṣẹ́, ó sì jókòó. Gbogbo àwọn tí ó ń bẹ nínú Sinagọgu sì tẹjúmọ́ ọn. 21 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wí fún wọn pé, “Lónìí ìwé mímọ́ yìí ṣẹ ní etí yín.”
22 (L)Gbogbo wọn sì jẹ́rìí rẹ̀, háà sì ṣe wọ́n sí ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ tí ń jáde ní ẹnu rẹ̀, wọ́n sì wí pé, “Ọmọ Josẹfu kọ́ yìí?”
23 (M)Jesu sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni ẹ̀yin ó pa òwe yìí sí mi pé, ‘Oníṣègùn, wo ara rẹ̀ sàn! Àwọn ohun tí àwa gbọ́ pé o ti ọwọ́ rẹ ṣe ní Kapernaumu, ṣe é níhìn-ín yìí pẹ̀lú ní ilẹ̀ ara rẹ.’ ”
24 (N)Ó sì wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, kò sí wòlíì tí a tẹ́wọ́gbà ní ilẹ̀ baba rẹ̀. 25 (O)Ṣùgbọ́n mo wí fún un yín nítòótọ́, opó púpọ̀ ni ó wà ní Israẹli nígbà ọjọ́ wòlíì Elijah, nígbà tí ọ̀run fi sé ní ọdún mẹ́ta òun oṣù mẹ́fà, nígbà tí ìyàn ńlá fi mú ká ilẹ̀ gbogbo; 26 Kò sì sí ẹnìkan nínú wọn tí a rán Elijah sí, bí kò ṣe sí obìnrin opó kan ní Sarefati, ìlú kan ní Sidoni. 27 (P)Adẹ́tẹ̀ púpọ̀ ní sì ń bẹ ní Israẹli nígbà wòlíì Eliṣa; kò sì ṣí ọ̀kan nínú wọn tí a wẹ̀nùmọ́, bí kò ṣe Naamani ará Siria.”
28 Nígbà tí gbogbo àwọn tí ó wà nínú Sinagọgu gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, inú bi wọ́n gidigidi, 29 (Q)Wọ́n sì dìde, wọ́n tì í sóde sí ẹ̀yìn ìlú, wọ́n sì fà á lọ sí bèbè òkè níbi tí wọ́n gbé tẹ ìlú wọn dó, kí wọn bá à lè sọ sílẹ̀ ní ògèdèǹgbé. 30 (R)Ṣùgbọ́n ó kọjá láàrín wọn, ó bá tirẹ̀ lọ.
Jesu lé ẹ̀mí èṣù jáde
31 (S)Ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí Kapernaumu, ìlú kan ní Galili, ó sì ń kọ́ wọn ní ọjọ́ ìsinmi. 32 (T)Ẹnu sì yà wọ́n sí ẹ̀kọ́ rẹ̀: nítorí tàṣẹtàṣẹ ni ọ̀rọ̀ rẹ̀.
33 Ọkùnrin kan sì wà nínú Sinagọgu, ẹni tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́, ó kígbe ní ohùn rara, 34 “Ó wí pé, kín ni ṣe tàwa tìrẹ, Jesu ará Nasareti? Ìwọ́ wá láti pa wá run bí? Èmí mọ ẹni tí ìwọ í ṣe; Ẹni Mímọ́ Ọlọ́run.”
35 Jesu sì bá a wí gidigidi, ó wí fun pe, “Pa ẹnu rẹ mọ́, kí o sì jáde lára rẹ̀.” Nígbà tí ẹ̀mí èṣù náà sì gbé e ṣánlẹ̀ ní àwùjọ, ó jáde kúrò lára rẹ̀, kò sì pa á lára.
36 Ẹnu sì ya gbogbo wọn, wọ́n sì ń bá ara wọn sọ wí pé, “irú ẹ̀kọ́ kín ni èyí? Nítorí pẹ̀lú àṣẹ àti agbára ni ó fi bá àwọn ẹ̀mí àìmọ́ wí, wọ́n sì jáde kúrò.” 37 (U)Òkìkí rẹ̀ sì kàn níbi gbogbo ní agbègbè ilẹ̀ náà yíká.
Jesu wo ọ̀pọ̀ ènìyàn sàn
38 (V)Nígbà tí ó sì dìde kúrò nínú Sinagọgu, ó sì wọ̀ ilé Simoni lọ; ibà sì ti dá ìyá ìyàwó Simoni dùbúlẹ̀, wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ nítorí rẹ̀. 39 Ó sì súnmọ́ ọ, ó bá ibà náà wí; ibà sì náà sì fi sílẹ̀. O sì dìde lọ́gán, ó ń ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.
40 Nígbà tí oòrùn sì ń wọ̀, àwọn ènìyàn gbe àwọn aláìsàn, tó ní onírúurú àìsàn wá sọ́dọ̀ Jesu; ó sì fi ọwọ́ lé olúkúlùkù wọn, ó sì mú wọn láradá. 41 Àwọn ẹ̀mí èṣù sì jáde lára ẹni púpọ̀ pẹ̀lú, wọ́n ń kígbe, wí pé, “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run!” Ó sì ń bá wọn wí kò sì jẹ́ kí wọn kí ó fọhùn: nítorí tí wọ́n mọ̀ pé òun ni Kristi náà.
42 (W)Nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, Jesu sì jáde lọ, ó sì ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀. Ìjọ ènìyàn sì ń wá a kiri, wọ́n sì tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì dá a dúró, nítorí kí ó má ba à lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn. 43 Ṣùgbọ́n ó sì wí fún wọn pé, “Èmi kò lè ṣàìmá wàásù ìhìnrere ti ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ìlú mìíràn pẹ̀lú: nítorí náà ni a sá ṣe rán mi.” 44 (X)Ó sì ń wàásù nínú Sinagọgu ti Judea.
Ìpè àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àkọ́kọ́
5 (Y)Ó sì ṣe, nígbà tí ìjọ ènìyàn súnmọ́ ọn láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí ó sì dúró létí adágún Genesareti. 2 Ó rí ọkọ̀ méjì ti o wá létí adágún: èyí tí àwọn apẹja ti sọ̀kalẹ̀ kúrò nínú wọn, nítorí tí wọ́n ń fọ àwọ̀n wọn. 3 (Z)Ó sì wọ ọ̀kan nínú àwọn ọkọ̀ náà, tí í ṣe ti Simoni, ó sì bẹ̀ ẹ́ kí ó tì í sí ẹ̀yìn díẹ̀ kúrò ní ilẹ̀. Ó sì jókòó, ó sì ń kọ́ ìjọ ènìyàn láti inú ọkọ̀ náà.
4 Bí ó sì ti dákẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ, ó wí fún Simoni pé, “Tì í sí ibú, kí o sì ju àwọ̀n yín sí ìsàlẹ̀ fún àkópọ̀.”
5 (AA)Simoni sì dáhùn ó sì wí fún un pé, “Olùkọ́ni, gbogbo òru ni àwa fi ṣiṣẹ́, àwa kò sì mú nǹkan kan: ṣùgbọ́n nítorí ọ̀rọ̀ rẹ èmi ó ju àwọ̀n náà sí ìsàlẹ̀.”
6 Nígbà tí wọ́n sì ti ṣe èyí, wọ́n kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹja: àwọ̀n wọn sì ya. 7 Wọ́n sì pe àwọn ẹgbẹ́ wọn, tí ó wà nínú ọkọ̀ kejì, kí wọn kí ó wá ràn wọ́n lọ́wọ́. Wọ́n sì wá, wọ́n kó ẹja ọkọ̀ méjèèjì sì kún, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í rì.
8 Nígbà tí Simoni Peteru sì rí i, ó wólẹ̀ lẹ́bàá eékún Jesu, ó wí pé, “Lọ kúrò lọ́dọ̀ mi Olúwa; nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí.” 9 Ẹnu sì yà wọ́n, àti gbogbo àwọn tí ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀, fún àkópọ̀ ẹja tí wọ́n kó: 10 Bẹ́ẹ̀ ni Jakọbu àti Johanu àwọn ọmọ Sebede, tí ń ṣe alábákẹ́gbẹ́ Simoni.
Jesu sì wí fún Simoni pé, “Má bẹ̀rù; láti ìsinsin yìí lọ ìwọ ó máa mú ènìyàn.” 11 Nígbà tí wọ́n sì ti mú ọkọ̀ wọn dé ilẹ̀, wọ́n fi gbogbo rẹ̀ sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn lọ.
Ọkùnrin pẹ̀lú ẹ̀tẹ̀
12 (AB)Ó sì ṣe, nígbà tí Jesu wọ ọ̀kan nínú àwọn ìlú náà, kíyèsi i, ọkùnrin kan tí ẹ̀tẹ̀ bò wa síbẹ̀: nígbà tí ó rí Jesu, ó wólẹ̀, ó sì ń bẹ̀ ẹ́, wí pé, “Olúwa, bí ìwọ bá fẹ́, ìwọ lè sọ mí di mímọ́.”
13 Jesu sì na ọwọ́ rẹ̀, ó fi kàn án, ó ní, “Mo fẹ́, ìwọ di mímọ́!” Lójúkan náà ẹ̀tẹ̀ sì fi í sílẹ̀ lọ.
14 (AC)Ó sì kìlọ̀ fún u pé, “Kí ó má ṣe sọ fún ẹnìkan: ṣùgbọ́n kí ó lọ, kí ó sì fi ara rẹ̀ hàn fún àlùfáà, kí ó sì ta ọrẹ fún ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Mose ti pàṣẹ gẹ́gẹ́ bi ẹ̀rí fun wọn.”
15 (AD)Ṣùgbọ́n òkìkí rẹ̀ ń kàn kálẹ̀: tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì jùmọ̀ pàdé láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, àti láti gba ìwòsàn lọ́dọ̀ rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àìlera wọn. 16 (AE)Ṣùgbọ́n lọ́pọ̀ ìgbà ni Jesu a máa yẹra kúrò si ibi ìdákẹ́rọ́rọ́, òun á sì máa dá wà láti gbàdúrà.
Jesu wo arọ sàn
17 (AF)(AG) Ní ọjọ́ kan, bí ó sì ti ń kọ́ni, àwọn Farisi àti àwọn amòfin jókòó pẹ̀lú rẹ̀, àwọn tí ó ti àwọn ìletò Galili gbogbo, àti Judea, àti Jerusalẹmu wá: agbára Olúwa sì ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀ láti mú wọn láradá. 18 Sá à sì kíyèsi i, àwọn Ọkùnrin kan gbé ẹnìkan tí ó ní ààrùn ẹ̀gbà wà lórí àkéte: wọ́n ń wá ọ̀nà àti gbé e wọlé, àti láti tẹ́ ẹ síwájú Jesu. 19 Nígbà tí wọn kò sì rí ọ̀nà tí wọn ìbá fi gbé e wọlé nítorí ìjọ ènìyàn, wọ́n gbé e gun òkè àjà ilé lọ, wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ sí àárín èrò ti òun ti àkéte rẹ̀ níwájú Jesu.
20 (AH)Nígbà tí ó sì rí ìgbàgbọ́ wọn, ó wí pé, “Ọkùnrin yìí, a darí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”
21 (AI)Àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisi bẹ̀rẹ̀ sí í gbèrò wí pé, “Ta ni eléyìí tí ń sọ ọ̀rọ̀-òdì? Ta ni ó lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni bí kò ṣe Ọlọ́run nìkan ṣoṣo.”
22 Jesu sì mọ èrò inú wọn, ó dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ fi ń ro nǹkan wọ̀nyí nínú ọkàn yín? 23 Èwo ni ó yá jù: láti wí pé, ‘A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́,’ tàbí láti wí pé, ‘Dìde kí ìwọ sì máa rìn’? 24 Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè mọ̀ pé ọmọ ènìyàn ní agbára ní ayé láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni.” Ó wí fún ẹlẹ́gbà náà pé, “Mo wí fún ọ, dìde, sì gbé àkéte rẹ, kí o sì máa lọ sí ilé!” 25 Ó sì dìde lọ́gán níwájú wọn, ó gbé ohun tí ó dùbúlẹ̀ lé, ó sì lọ sí ilé rẹ̀, ó yin Ọlọ́run lógo. 26 Ẹnu sì ya gbogbo wọn, wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo, ẹ̀rù sì bà wọ́n, wọ́n ń wí pé, “Àwa rí ohun ìyanu lónìí.”
Ìpè Lefi
27 (AJ)Lẹ́hìn èyí, Jesu jáde lọ, ó sì rí agbowó òde kan tí à ń pè ní Lefi ó jókòó sí ibi tí ó ti ń gba owó òde, Jesu sì wí fún un pé “Tẹ̀lé mi,” 28 Lefi sì fi ohun gbogbo sílẹ̀ ó sì ń tẹ̀lé e.
29 Lefi sì ṣe àsè ńlá kan fún Jesu ní ilé rẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn agbowó òde àti àwọn mìíràn sì ń jẹun pẹ̀lú wọn. 30 (AK)Ṣùgbọ́n àwọn Farisi, àwọn olùkọ́ òfin tí ó jẹ́ ara wọn fi ẹ̀sùn kan àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pe “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń jẹun tí ẹ sì ń mú pẹ̀lú àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.”
31 Jesu dáhùn ó wí fún wọn pé, “Ẹni tí ara rẹ̀ le kò nílò oníṣègùn, bí kò ṣe ẹni tí ara rẹ̀ kò dá. 32 (AL)Èmí kò wá láti pe àwọn olódodo bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sí ìrònúpìwàdà.”
A béèrè nípa àwẹ̀ lọ́wọ́ Jesu
33 (AM)(AN) Wọ́n wí fún pé “Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu a máa gbààwẹ̀, wọn a sì máa gbàdúrà, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú sì ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àwọn Farisi ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ a máa jẹ, wọn a sì máa mu pẹ̀lú.”
34 Jesu sì dáhùn ó wí fún wọn pé, “Ǹjẹ́ ó ṣe é ṣe kí àwọn àlejò ọkọ ìyàwó máa gbààwẹ̀ nígbà tí ọkọ ìyàwó wà pẹ̀lú wọn bí? 35 Ṣùgbọ́n àkókò ń bọ̀ nígbà tí a ó gba ọkọ ìyàwó kúrò lọ́dọ̀ wọn, ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí ni wọn yóò gbààwẹ̀.”
36 Ó sì pa òwe yìí fún wọn wí pé: “Kò sí ẹni tó lè ya aṣọ tuntun kí ó sì rán mọ́, èyí tó ti gbó. Tí ó ba ṣe èyí, yóò ba aṣọ tuntun jẹ́, èyí tí ó tuntun náà kì yóò sì dọ́gba pẹ̀lú èyí tí ó ti gbó. 37 Àti wí pé, kò sí ẹni tí ó lè dá ọtí wáìnì tuntun sínú ògbólógbòó ìgò-awọ, tí ó bá ṣe èyí, wáìnì tuntun yóò fa awọ náà ya, wáìnì náà yóò dànù, awọ náà a sì bàjẹ́. 38 Nítorí náà, ó tọ́ kí á da wáìnì tuntun sínú awọ tuntun. 39 Kò sì ẹni tí yóò fẹ́ láti mu wáìnì tuntun lẹ́yìn tí ó bá ti mu ògbólógbòó tán, nítorí yóò wí pé, ‘Èyí tí ó jẹ́ ògbólógbòó dára jù.’ ”
15 (A)Johanu sì jẹ́rìí nípa rẹ̀, ó kígbe, ó sì wí pé, “Èyí ni ẹni tí mo sọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, ‘Ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn mi pọ̀jù mí lọ, nítorí òun ti wà ṣáájú mi.’ ” 16 (B)Nítorí láti inú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ ni gbogbo wa sì ti gba ìbùkún kún ìbùkún. 17 (C)Nítorí pé nípasẹ̀ Mose ni a ti fi òfin fún ni ṣùgbọ́n òun; oore-ọ̀fẹ́ àti òtítọ́ láti ipasẹ̀ Jesu Kristi wá. 18 (D)Kò sí ẹni tí ó rí Ọlọ́run rí, bí kò ṣe òun nìkan, àní ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo, ẹni tí òun pàápàá jẹ́ Ọlọ́run, tí ó sì wà ní ìbásepọ̀ tí ó súnmọ́ jùlọ pẹ̀lú baba, òun náà ni ó sì fi í hàn.
Johanu sọ pé òun kì í ṣe Kristi
19 (E)Èyí sì ni ẹ̀rí Johanu, nígbà tí àwọn Júù rán àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi láti Jerusalẹmu wá láti béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ ẹni tí òun ń ṣe. 20 (F)Òun kò sì kùnà láti jẹ́wọ́, ṣùgbọ́n òun jẹ́wọ́ wọ́ọ́rọ́wọ́ pé, “Èmi kì í ṣe Kristi náà.”
21 (G)Wọ́n sì bi í léèrè pé, “Ta ha ni ìwọ? Elijah ni ìwọ bí?”
Ó sì wí pé, “Èmi kọ́.”
“Ìwọ ni wòlíì náà bí?”
Ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́.”
22 Ní ìparí wọ́n wí fún un pé, “Ta ni ìwọ í ṣe? Fún wa ní ìdáhùn kí àwa kí ó lè mú èsì padà tọ àwọn tí ó rán wa wá lọ. Kí ni ìwọ wí nípa ti ara rẹ?”
23 (H)Johanu sì fi ọ̀rọ̀ wòlíì Isaiah fún wọn ní èsì pé, “Èmi ni ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù, ‘Ẹ ṣe ọ̀nà Olúwa ní títọ́.’ ”
24 Ọ̀kan nínú àwọn Farisi tí a rán 25 bi í léèrè pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń bamitiisi nígbà náà, bí ìwọ kì í bá ṣe Kristi, tàbí Elijah, tàbí wòlíì náà?”
26 (I)Johanu dá wọn lóhùn, wí pé, “Èmi ń fi omi bamitiisi: ẹnìkan dúró láàrín yín, ẹni tí ẹ̀yin kò mọ̀; 27 Òun náà ni ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn mi, okùn bàtà ẹni tí èmi kò tó láti tú.”
28 Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó ṣẹlẹ̀ ní Betani ní òdìkejì odò Jordani, níbi tí Johanu ti ń fi omi bamitiisi.
Jesu jẹ́ Ọ̀dọ́-Àgùntàn Ọlọ́run
29 (J)Ní ọjọ́ kejì, Johanu rí Jesu tí ó ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Wò ó, Ọ̀dọ́-àgùntàn Ọlọ́run, ẹni tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ! 30 Èyí ni ẹni tí mo ń sọ nígbà tí mo wí pé, ‘Ọkùnrin kan tí ń bọ̀ wá lẹ́yìn mi, tí ó pọ̀jù mí lọ, nítorí tí ó ti wà ṣáájú mi.’ 31 Èmi gan an kò sì mọ̀ ọ́n, ṣùgbọ́n ìdí tí mo fi wá ń fi omi ṣe ìtẹ̀bọmi ni kí a lè fi í hàn fún Israẹli.”
32 (K)Nígbà náà ni Johanu jẹ́rìí sí i pé: “Mo rí Ẹ̀mí sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá bí àdàbà, tí ó sì bà lé e. 33 Èmí kì bá tí mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe pé ẹni tí ó rán mi láti fi omi bamitiisi sọ fún mi pé, ‘Ọkùnrin tí ìwọ rí tí Ẹ̀mí sọ̀kalẹ̀ tí ó bà lé lórí ni ẹni tí yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ bamitiisi.’ 34 Èmi ti rí i, mo sì jẹ́rìí pé, èyí ni Ọmọ Ọlọ́run.”
Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu àkọ́kọ́
35 (L)Ní ọjọ́ kejì, Johanu dúró pẹ̀lú méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. 36 Nígbà tí ó sì rí Jesu bí ó ti ń kọjá lọ, ó wí pé, “Wò ó Ọ̀dọ́-àgùntàn Ọlọ́run!”
37 Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì náà sì gbọ́ ohun tí ó wí yìí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sì í tọ Jesu lẹ́yìn. 38 Nígbà náà ni Jesu yípadà, ó rí i pé wọ́n ń tọ òun lẹ́yìn, ó sì béèrè pé, “Kí ni ẹ̀yin ń wá?”
Wọ́n wí fún un pé, “Rabbi” (ìtumọ̀ èyí tí í ṣe Olùkọ́ni), “Níbo ni ìwọ ń gbé?”
39 Ó wí fún wọn pé, “Ẹ wá wò ó, ẹ̀yin yóò sì rí i.”
Wọ́n sì wá, wọ́n sì rí ibi tí ó ń gbé, wọ́n sì wà ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ náà. Ó jẹ́ ìwọ̀n wákàtí kẹwàá ọjọ́.
40 (M)Anderu arákùnrin Simoni Peteru jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn méjì tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Johanu, tí ó sì tọ Jesu lẹ́yìn. 41 (N)Ohun àkọ́kọ́ tí Anderu ṣe ni láti wá Simoni arákùnrin rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Àwa ti rí Messia” (ẹni tí ṣe Kristi). 42 (O)Ó sì mú un wá sọ́dọ̀ Jesu.
Jesu sì wò ó, ó wí pé, “Ìwọ ni Simoni ọmọ Jona: Kefa ni a ó sì máa pè ọ” (ìtumọ̀ èyí tí ṣe Peteru).
Jesu pe Filipi àti Natanaeli
43 (P)Ní ọjọ́ kejì Jesu ń fẹ́ jáde lọ sí Galili, ó sì rí Filipi, ó sì wí fún un pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”
44 Filipi gẹ́gẹ́ bí i Anderu àti Peteru, jẹ́ ará ìlú Betisaida. 45 (Q)Filipi rí Natanaeli, ó sì wí fún un pé, “Àwa ti rí ẹni náà tí Mose kọ nípa rẹ̀ nínú òfin àti ẹni tí àwọn wòlíì ti kọ̀wé rẹ̀—Jesu ti Nasareti, ọmọ Josẹfu.”
46 (R)Natanaeli béèrè pé, “Nasareti? Ohun rere kan ha lè ti ibẹ̀ jáde?”
Filipi wí fún un pé, “Wá wò ó.”
47 Jesu rí Natanaeli ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí nípa rẹ̀ pé, “Èyí ni ọmọ Israẹli tòótọ́, nínú ẹni tí ẹ̀tàn kò sí.”
48 Natanaeli béèrè pé, “Báwo ni ìwọ ti ṣe mọ̀ mí?”
Jesu sì dáhùn pé, “Èmi rí ọ nígbà tí ìwọ wà lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ kí Filipi tó pè ọ́.”
49 (S)Nígbà náà ni Natanaeli sọ ọ́ gbangba pé, “Rabbi, ìwọ ni ọmọ Ọlọ́run; Ìwọ ni ọba Israẹli.”
50 Jesu sì wí fún un pé, “Ìwọ gbàgbọ́ nítorí mo wí fún ọ pé mo rí ọ lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́. Ìwọ ó rí ohun tí ó pọ̀jù ìwọ̀nyí lọ.” 51 (T)Nígbà náà ni ó fi kún un pé, “Èmi wí fún yín nítòótọ́, ẹ̀yin yóò rí ọ̀run ṣí sílẹ̀, àwọn angẹli Ọlọ́run yóò sì máa gòkè, wọ́n ó sì máa sọ̀kalẹ̀ sórí Ọmọ Ènìyàn.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.