Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Chronological

Read the Bible in the chronological order in which its stories and events occurred.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Esekiẹli 9-12

Wọ́n pa àwọn abọ̀rìṣà

Mo gbọ́ ti ó kígbe ní ohùn rara pé, “Mú àwọn olùṣọ́ ìlú súnmọ́ itòsí, kí olúkúlùkù wọn mú ohun ìjà olóró lọ́wọ́.” Lójú ẹsẹ̀ ni ọkùnrin mẹ́fà jáde láti ẹnu-ọ̀nà òkè tó kọjú sí ìhà àríwá, olúkúlùkù pẹ̀lú ohun ìjà olóró lọ́wọ́ wọn. Ọkùnrin kan tó wọ aṣọ funfun gbòò wa láàrín wọn, pẹ̀lú ohun ìkọ̀wé lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Gbogbo wọn sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ idẹ.

Ògo Ọlọ́run Israẹli sì gòkè kúrò lórí kérúbù, níbi tó wà tẹ́lẹ̀ lọ sí ibi ìloro tẹmpili. Nígbà náà ni Olúwa pe ọkùnrin tó wọ aṣọ funfun náà tí ó sì ní ohun ìkọ̀wé lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. (A)Ó sì sọ fún un pé, “La àárín ìlú Jerusalẹmu já, kí ìwọ sì fi ààmì síwájú orí gbogbo àwọn tó ń kẹ́dùn, tó sì ń sọkún nítorí ohun ìríra tí wọn ń ṣe láàrín rẹ̀.”

Bí mo ṣe ń fetí sí èyí, O tún sọ fún àwọn yòókù pé, “Tẹ̀lé ọkùnrin náà lọ sí àárín ìlú láti pa láì dá sí àti láì ṣàánú rárá. Ẹ pa arúgbó àti ọ̀dọ́mọkùnrin, ẹ pa ọlọ́mọge, obìnrin àti ọmọ kéékèèkéé, ṣùgbọ́n ẹ má ṣe fi ọwọ́ kan àwọn tó ní ààmì. Ẹ bẹ̀rẹ̀ láti ibi mímọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn àgbàgbà tó wà níwájú tẹmpili.

Nígbà náà lo sọ fún wọn pé, “Ẹ sọ tẹmpili náà di àìmọ́, kí òkú sì kún àgbàlá náà. Ẹ lọ!” Wọ́n jáde síta, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í pa ènìyàn láàrín ìlú. Èmi nìkan ló ṣẹ́kù nígbà tí wọ́n lọ pa àwọn ènìyàn, mo dójú mi bolẹ̀, mo kígbe pé, “Háà! Olúwa Olódùmarè! Ìwọ yóò ha pa ìyókù Israẹli nípa dída ìbínú gbígbóná rẹ sórí Jerusalẹmu?”

Ó dá mi lóhùn pé, “Ẹ̀ṣẹ̀ ilé Israẹli àti Juda pọ gidigidi; ilé wọn kún fún ìtàjẹ̀ sílẹ̀ àti àìṣòótọ́. Wọ́n ní, ‘Olúwa tí kọ ilẹ̀ náà sílẹ̀; Olúwa kò sì rí wa.’ 10 Nítorí náà, èmi kò ní wò wọ́n pẹ̀lú àánú, èmi kò sì ní dá wọn sí, ṣùgbọ́n Èmi yóò dá ohun tí wọ́n ti ṣe padà sórí wọn.”

11 Ọkùnrin tí ó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀, tí ó ní ìwo tàdáwà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ròyìn pé, “Mo ti ṣe gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti pàṣẹ fún mi.”

Ògo kúrò nínú tẹmpili

10 (B)Mo sì wò ó, mo rí ohun kan tó dàbí òkúta safire nínú òfúrufú tó wà lókè orí kérúbù, ìrísí ohun yìí sì dàbí ìtẹ́. (C)Olúwa sì sọ fún ọkùnrin tó wọ aṣọ funfun pé, “Lọ sí àárín àwọn kẹ̀kẹ́ tó wà lábẹ́ kérúbù. Bu ẹyin iná tó kúnwọ́ rẹ láàrín kérúbù, kí o sì fọ́n sórí ìlú náà.” Ó sì lọ lójú mi.

Àwọn kérúbù dúró sí apá gúúsù tẹmpili nígbà tí ọkùnrin náà wọlé, ìkùùkuu sì bo inú àgbàlá. Ògo Olúwa sì kúrò lórí àwọn kérúbù, ó bọ́ sí ibi ìloro tẹmpili. Ìkùùkuu sì bo inú tẹmpili, àgbàlá sì kún fún ìmọ́lẹ̀ àti ògo Olúwa. A sì gbọ́ ariwo ìyẹ́ àwọn kérúbù yìí títí dé àgbàlá tó wà ní ìta gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí Ọlọ́run Olódùmarè (Eli-Ṣaddai) bá ń sọ̀rọ̀.

Nígbà tí Olúwa pàṣẹ fún ọkùnrin aláṣọ funfun yìí pé, “Mú iná láàrín àwọn kẹ̀kẹ́, láàrín àwọn kérúbù,” ó sì lọ dúró ṣẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn kẹ̀kẹ́ náà. Ọ̀kan nínú àwọn kérúbù sì nawọ́ sí ibi iná tó wà láàrín kérúbù yòókù. Ó mú lára rẹ, ó fi sínú ọwọ́ ọkùnrin aláṣọ funfun, òun náà gbà á, ó sì jáde lọ. (Ohun tó dàbí ọwọ́ ènìyàn wà lábẹ́ ìyẹ́ àwọn kérúbù yìí.)

Nígbà tí mo sì wò, kíyèsí i, àwọn kẹ̀kẹ́ mẹ́rin wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn kérúbù yìí, kẹ̀kẹ́ kọ̀ọ̀kan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kérúbù kọ̀ọ̀kan; ìrí àwọn kẹ̀kẹ́ yìí ń tàn yanran bí àwọ̀ òkúta berili. 10 Ní ti ìrísí wọn, gbogbo wọn jọra wọn; ọ̀kọ̀ọ̀kan rí bí ìgbà tí kẹ̀kẹ́ kan wà nínú kẹ̀kẹ́ mìíràn. 11 Nígbà tí wọ́n ń lọ, wọ́n tẹ̀lé ọ̀kan nínú ọ̀nà mẹ́rin tí àwọn kérúbù dojúkọ; àwọn kẹ̀kẹ́ náà kò yípadà bí àwọn kérúbù ti ń lọ. Àwọn kérúbù ń lọ sí ibi tí orí dojúkọ láì yà. 12 (D)Gbogbo ara wọn àti ẹ̀yìn, ọwọ́ wọn àti ìyẹ́ wọn, àti àwọn kẹ̀kẹ́ kún fún ojú yíkákiri kẹ̀kẹ́, tí àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ní. 13 Mo gbọ́ tí wọ́n pe àwọn kẹ̀kẹ́ yìí ni “kẹ̀kẹ́ àjà.” 14 (E)Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn kérúbù yìí ni ojú mẹ́rin: ojú èkínní jẹ́ ojú kérúbù, ojú kejì jẹ́ ti ènìyàn, ojú kẹta jẹ́ ti kìnnìún nígbà tí ojú kẹrin jẹ́ ti ẹyẹ idì.

15 A gbé àwọn kérúbù sókè. Èyí ni àwọn ẹ̀dá alààyè tí mo rí létí odò Kebari. 16 Bí àwọn kérúbù yìí bá ń lọ àwọn kẹ̀kẹ́ ẹgbẹ́ wọn náà yóò lọ; bẹ́ẹ̀ ni bí àwọn kérúbù bá tú ìyẹ́ wọn ká láti dìde nílẹ̀, àwọn kẹ̀kẹ́ yìí kò ní kúrò lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn. 17 Bí àwọn kérúbù bá dúró díẹ̀ àwọn kẹ̀kẹ́ náà yóò dúró jẹ́ẹ́; bí àwọn kérúbù bá dìde àwọn kẹ̀kẹ́ náà yóò dìde, nítorí pé ẹ̀mí àwọn ẹ̀dá alààyè yìí wà nínú wọn.

18 Ògo Olúwa kúrò níbi ìloro tẹmpili, ó sì dúró sórí àwọn kérúbù. 19 Àwọn kérúbù gbé ìyẹ́ wọn sókè, wọ́n sì fò kúrò nílẹ̀ lójú mi, wọ́n sì lọ pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ wọn lẹ́ẹ̀kan náà. Wọ́n dúró níbi ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà ìlà-oòrùn ilé Olúwa, ògo Ọlọ́run Israẹli sì wà lórí wọn.

20 Àwọn wọ̀nyí ni ẹ̀dá alààyè tí mo rí lábẹ́ Ọlọ́run Israẹli létí odò Kebari, mo sì mọ̀ pé kérúbù ni wọ́n. 21 Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ojú mẹ́rin àti ìyẹ́ mẹ́rin, lábẹ́ ìyẹ́ wọn ni ohun tó jọ ọwọ́ ènìyàn wà. 22 Àfiwé ojú àti ìrísí wọn rí bákan náà pẹ̀lú àwọn tí mo rí létí odò Kebari. Olúkúlùkù wọn sì ń lọ sí ọ̀kánkán tààrà.

Ìdájọ́ lórí àwọn àgbà Israẹli

11 Ẹ̀mí sì gbé mi sókè, ó mú mi lọ sí ẹnu-ọ̀nà ilé Olúwa èyí tó dojúkọ ìlà-oòrùn. Ní àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà yìí ni àwọn ọkùnrin mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n wá, mo rí Jaaṣaniah ọmọ Assuri àti Pelatiah ọmọ Benaiah, tí wọ́n jẹ́ ìjòyè àwọn ènìyàn. Olúwa sì sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, àwọn ọkùnrin yìí ló ń pète ibi, wọ́n sì ń gbé ìmọ̀ràn búburú kalẹ̀ nínú ìlú. Wọ́n ní, ‘Kò ha tí ì tó àsìkò láti kọ́lé? Ìlú yìí ni ìkòkò ìdáná, àwa sì ni ẹran’. Nítorí náà sọtẹ́lẹ̀ nípa wọn; ọmọ ènìyàn, sọtẹ́lẹ̀.”

Ẹ̀mí Olúwa sì bà lé mi, ó sì wí pé, “Sọ̀rọ̀!” Báyìí ni Olúwa wí, Ohun tí ẹ ń sọ nìyìí, ilé Israẹli, mo mọ ohun tó wà lọ́kàn yín. Ẹ̀yin ti sọ òkú yín di púpọ̀ nínú ìlú yìí, òkú sì ti kún gbogbo ìgboro rẹ̀.

“Torí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí, àwọn òkú tí ẹ fọn sílẹ̀ sí àárín yín ni ẹran, ìlú yìí sì ni ìkòkò ìdáná ṣùgbọ́n èmi yóò le yín jáde níbẹ̀. Ẹ bẹ̀rù idà, èmi yóò sì mú idà wá sórí yín, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa Olódùmarè wí. Èmi yóò lé yín jáde kúrò ní ìlú yìí, èmi yóò sì fà yín lé àjèjì lọ́wọ́, èmi yóò sì mú ìdájọ́ ṣẹ lé yín lórí. 10 Nípa idà ni ẹ̀yin yóò ṣubú, èmi yóò sì ṣe ìdájọ́ yín ní àwọn ààlà ìlú Israẹli. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa. 11 Ìlú yìí kò ní i jẹ́ ìkòkò ìdáná, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin náà kò sì ní jẹ́ ẹran nínú rẹ̀; Èmi yóò ṣe ìdájọ́ yín ní àwọn ààlà ìlú Israẹli. 12 Ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa, nítorí pé ẹ̀yin kò tẹ̀lé àṣẹ mi ẹ̀yin kò sì pa òfin mi mọ́, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti hùwà gẹ́gẹ́ bí àwọn aláìgbàgbọ́ orílẹ̀-èdè tó yí yín ká.”

13 Bí mo ṣe ń sọtẹ́lẹ̀ lọ́wọ́, Pelatiah ọmọ Benaiah kú. Mo sì dojúbolẹ̀, mo sì kígbe sókè pé, “Háà! OlúwaOlódùmarè! Ṣé ìwọ yóò ha pa ìyókù Israẹli run pátápátá ni?”

14 Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé: 15 “Ọmọ ènìyàn, àwọn arákùnrin rẹ, àní àwọn ará rẹ, àwọn ọkùnrin nínú ìbátan rẹ, àti gbogbo ilé Israẹli pátápátá, ni àwọn ará Jerusalẹmu ti wí fún pé, ‘Ẹ jìnnà sí Olúwa, àwa ni a fi ilẹ̀ yìí fún yín ní ìní.’

Ìlérí pé Israẹli yóò padà

16 “Nítorí náà, sọ fún àwọn tó wà ní ìgbèkùn pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti fọ́n wọn káàkiri orílẹ̀-èdè, síbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀, èmi yóò jẹ́ ibi mímọ́ fún wọn níbi tí wọ́n lọ.’

17 “Nítorí náà, wí pé: ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Èmi yóò kó wọn jọ kúrò láàrín àwọn orílẹ̀-èdè tí mo fọ́n wọn ká sí, Èmi yóò sì fún wọn ní ilẹ̀ Israẹli padà.’

18 “Wọn yóò padà síbẹ̀, wọn yóò sì mú gbogbo àwòrán ìríra rẹ̀ àti ìbọ̀rìṣà rẹ̀ kúrò. 19 (F)Èmi yóò fún wọn ní ọ̀kankan; èmi yóò sì fi ẹ̀mí tuntun sínú wọn; Èmi yóò mú ọkàn òkúta kúrò lára wọn, èmi yóò sì fún wọn ní ọkàn tó rọ̀ bí ara ẹran. 20 Kí wọn le tẹ̀lé àṣẹ mi, kí wọn sì le pa òfin mi mọ́. Wọ́n yóò jẹ́ ènìyàn mi, Èmi náà yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn. 21 Ṣùgbọ́n fún àwọn tí wọ́n ń fi gbogbo ọkàn wọn sin àwọn àwòrán ìríra àti àwọn òrìṣà, Èmi yóò mú ẹ̀san ohun tí wọ́n ṣe wá sí orí wọn bẹ́ẹ̀ ni Olúwa Olódùmarè wí.”

22 Àwọn kérúbù sì gbé ìyẹ́ wọn sókè pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn, ògo Ọlọ́run Israẹli sì wà lókè orí wọn. 23 Ògo Olúwa sì gòkè lọ kúrò láàrín ìlú, ó sì dúró lórí òkè tó wà ní ìlà-oòrùn ìlú náà. 24 Lẹ́yìn náà, ẹ̀mí gbé mi sókè, ó sì mú mi wá sí Kaldea lójú ìran, nípa ti ẹ̀mí Ọlọ́run sí ọ̀dọ̀ àwọn ti ìgbèkùn.

Bẹ́ẹ̀ ni ìran tí mo rí lọ kúrò ní ọ̀dọ̀ mi, 25 Mo sì sọ gbogbo ohun tí Olúwa fihàn mí fún àwọn tó wà ní ìgbèkùn.

Àpẹẹrẹ àwọn tó wà ní ìgbèkùn

12 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: (G)“Ọmọ ènìyàn, ìwọ ń gbé ní àárín ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn. Wọ́n lójú láti fi ríran, ṣùgbọ́n wọn kò ríran, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n létí láti fi gbọ́rọ̀ ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́rọ̀, torí pé ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn ni wọ́n.

“Nítorí náà, ọmọ ènìyàn, palẹ̀ ẹrù rẹ mọ́ láti lọ sí ìgbèkùn, ní ọ̀sán gangan ní ojú wọn, kúrò láti ibi tí ìwọ wà lọ sí ibòmíràn. Bóyá bí wọ́n bá rí ọ, wọn yóò sì ronú bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọlọ̀tẹ̀ ilé ni wọ́n. Di ẹrù ìgbèkùn rẹ lójú wọn ní ọ̀sán án gangan, nígbà tí ó bá sì di alẹ́, ní ojú wọn, máa lọ sí ìgbèkùn gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ó lọ ìgbèkùn ṣe máa ń ṣe. Dá ògiri lu ní ojú wọn, kí ìwọ sì gba ibẹ̀ kó ẹrù rẹ jáde. Gbé ẹrù rẹ lé èjìká ní ojú wọn, bo ojú rẹ, kí ìwọ má ba à rí ilẹ̀, sì ru ẹrù rẹ lọ ní alẹ́ nítorí pé mo fi ọ́ ṣe ààmì fún ilé Israẹli.”

Mo ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún mi. Mo kó ẹrù mi jáde ní ọ̀sán án láti lọ fun ìgbèkùn. Nígbà tó di ìrọ̀lẹ́, mo dá ògiri lu pẹ̀lú ọwọ́ mi. Mo sì gbe ẹrù mi lé èjìká nínú òkùnkùn ní ojú wọn.

Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: “Ọmọ ènìyàn, Ǹjẹ́ ọlọ̀tẹ̀ ilé Israẹli tilẹ̀ bi ọ́ pé, ‘Kí ni ohun tí o ń ṣe túmọ̀ sí?’

10 “Sọ fún wọn pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ yìí kan àwọn ọmọ-aládé Jerusalẹmu àti gbogbo ilé Israẹli tí ó wà ní àárín rẹ. 11 Sọ fún wọn pé, Èmi jẹ́ ààmì fún yín’.

“Gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe, bẹ́ẹ̀ ni a ó ṣe sí wọn. Wọn ó kó lọ sí ìgbèkùn. Gẹ́gẹ́ bí ẹni ti a dè ní ìgbèkùn.

12 “Ọmọ-aládé tí ó wà ní àárín wọn yóò di ẹrù rẹ̀ lé èjìká ní alẹ́ yóò sì jáde lọ, òun náà yóò da ògiri lu kí ó le gba ibẹ̀ jáde. Yóò sì bo ojú rẹ̀ kí ó má ba à rí ilẹ̀. 13 Èmi yóò ta àwọ̀n mi lé e lórí, yóò sì kó sínú okùn, Èmi yóò sì mú lọ sí Babeli, ní ilẹ̀ Kaldea, ṣùgbọ́n kò ní fojúrí ilẹ̀ náà ibẹ̀ ni yóò kú sí. 14 Gbogbo àwọn tó yí i ká láti ràn án lọ́wọ́ ọ̀pá ìtẹ̀lẹ̀ àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ ni Èmi yóò túká sí afẹ́fẹ́, èmi yóò sì tún fi idà lé wọn kiri.

15 “Wọn yóò sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa nígbà tí mo bá tú wọn ká ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè, tí mo sì fọ́n wọn ká sí ilẹ̀ káàkiri. 16 Ṣùgbọ́n èmi yóò ṣẹ́ díẹ̀ kù lára wọn, ní ọwọ́ idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn, kí wọn le jẹ́wọ́ gbogbo ìṣe ìríra wọn ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè yìí. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.”

17 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: 18 “Ọmọ ènìyàn, jẹ oúnjẹ rẹ pẹ̀lú ìwárìrì, sì mu omi rẹ pẹ̀lú ìwárìrì àti àìbalẹ̀ àyà. 19 Sọ fún àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí fún àwọn olùgbé Jerusalẹmu àti ilẹ̀ Israẹli pé: Pẹ̀lú àìbalẹ̀ àyà ni wọn yóò máa jẹun wọn, wọn yóò sì mu omi pẹ̀lú àìnírètí, kí ilẹ̀ wọn lè di ahoro torí ìwà ipá àwọn tó ń gbé ibẹ̀. 20 Ìlú tó jẹ́ ibùgbé ènìyàn tẹ́lẹ̀ yóò di òfo, ilẹ̀ náà yóò sì di ahoro. Ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.’ ”

21 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá pé: 22 “Ọmọ ènìyàn, irú òwe wo ni ẹ pa nílẹ̀ Israẹli pé: ‘A fa ọjọ́ gùn, gbogbo ìran di asán’? 23 Nítorí náà wí fún wọn pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Èmi yóò fi òpin sí òwe yìí, wọn kò ní ipa mọ́ ní Israẹli.’ Sọ fún wọn, ‘Ọjọ́ náà súnmọ́ tòsí nígbà tí gbogbo ìran àti ìsọtẹ́lẹ̀ yóò sì wá sí ìmúṣẹ. 24 Nítorí kò ní sí ìran asán tàbí àfọ̀ṣẹ tí ó ń pọ́n ni mọ́ ní àárín ilé Israẹli. 25 Ṣùgbọ́n Èmi Olúwa yóò sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ tí mo sọ yóò sì ṣẹ láì falẹ̀. Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí, ní àsìkò yín, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀ ilé ni Èmi yóò mú ọ̀rọ̀ yówù tí mo bá sọ ṣẹ.’ ”

26 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá pé: 27 “Ọmọ ènìyàn, ilé Israẹli ń wí pé, ‘Ìran ọjọ́ pípẹ́ ni ìwọ rí, ìwọ sì sọtẹ́lẹ̀ nípa àsìkò tó jìnnà réré.’

28 “Nítorí náà sọ fún wọn, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Kò sí ọ̀kan nínú ọ̀rọ̀ mi tí yóò sún síwájú mọ́; ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tí mo bá sọ yóò ṣẹ.’ ”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.