Chronological
Ẹ̀sìn àìṣòótọ́ kò níláárí
7 Èyí ni ọ̀rọ̀ tó tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa. 2 “Dúró ní ẹnu-ọ̀nà ilé Olúwa kí o sì kéde ọ̀rọ̀ yí:
“ ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀yin ará Juda tí ń gba ọ̀nà yí wọlé láti wá sin Olúwa. 3 Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí: Tún àwọn ọ̀nà yín ṣe, èmi yóò sì jẹ́ kí ẹ gbé ilẹ̀ yìí. 4 Má ṣe gba ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn gbọ́ kí ẹ sì wí pé, “Èyí ni tẹmpili Olúwa ilé tẹmpili Olúwa, ilé tẹmpili Olúwa!” 5 Bí ẹ̀yin bá tún ọ̀nà yín àti iṣẹ́ yín ṣe nítòótọ́, tí ẹ sì ń bá ara yín lò ní ọ̀nà tó tọ́. 6 Bí ẹ kò bá fi ara ni àwọn àlejò, àwọn ọmọ aláìní baba àti àwọn opó tí ẹ kò sì ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ní ibí yìí, bí ẹ kò bá sì tọ ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn sí ìpalára ara yín. 7 Nígbà náà ni èmi yóò jẹ́ kí ẹ gbé ìbí yìí, nílẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá yín títí láé. 8 Ẹ wò ó, ẹ ń gba ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn tí kò níláárí gbọ́.
9 “ ‘Ẹ̀yin yóò ha jalè, kí ẹ pànìyàn, kí ẹ ṣe panṣágà, kí ẹ búra èké, kí ẹ sun tùràrí sí Baali, kí ẹ sì tọ ọlọ́run mìíràn tí ẹ̀yin kò mọ̀ lọ? 10 Nígbà náà ni kí ó wá dúró ní iwájú nínú ilé yìí tí a fi orúkọ mi pè, “Kí ẹ wá wí pé àwa yè,” àwa yè láti ṣe gbogbo àwọn nǹkan ìríra wọ̀nyí bí? 11 (A)Ṣé ilé yìí, tí a fi orúkọ mi pè ti di ihò àwọn ọlọ́ṣà lọ́dọ̀ yín ni? Èmi ti ń wò ó! ni Olúwa wí.
12 “ ‘Ẹ lọ nísinsin yìí sí Ṣilo níbi ti mo kọ́ fi ṣe ibùgbé fún orúkọ mi, kí ẹ sì rí ohun tí mo ṣe sí i nítorí ìwà búburú Israẹli tí í ṣe ènìyàn mi. 13 Nígbà tí ẹ̀yin ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí ni èmi bá a yín sọ̀rọ̀ léraléra ni Olúwa wí ẹ̀yin kò gbọ́, èmi pè yín, ẹ̀yin kò dáhùn 14 Nítorí náà, èmi yóò ṣe ohun tí mo ṣe sí Ṣilo sí ilé náà tí a fi orúkọ mi pè, ilé tẹmpili nínú èyí tí ẹ ní ìgbẹ́kẹ̀lé, ààyè tí mo fún ẹ̀yin àti àwọn baba yín. 15 Èmi yóò tú kúrò ní iwájú mi gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe sí àwọn arákùnrin yín, àwọn ará Efraimu.’
16 “Nítorí náà má ṣe gbàdúrà fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí tàbí kí o bẹ̀bẹ̀ fún wọn; ma ṣe bẹ̀ mí, nítorí èmi kì yóò tẹ́tí sí ọ. 17 Ṣé ìwọ kò rí ohun tí wọ́n ń ṣe ní àwọn ìlú Juda àti ní òpópó Jerusalẹmu? 18 Àwọn ọmọ ṣa igi jọ, àwọn baba fi iná sí i, àwọn ìyá sì po ìyẹ̀fun láti ṣe àkàrà fún ayaba ọ̀run, wọ́n tú ẹbọ ọrẹ mímu sí àwọn ọlọ́run àjèjì láti ru bínú mi sókè. 19 Ṣùgbọ́n ṣe èmi ni wọ́n fẹ́ mú bínú? ni Olúwa wí. Ǹjẹ́ kì í ṣe pé wọ́n kúkú ń pa ara wọn lára sí ìtìjú ara wọn?
20 “ ‘Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Èmi yóò tú ìbínú àti ìrunú mi sí orílẹ̀ yìí ènìyàn àti ẹranko, igi, pápá àti èso orí ilẹ̀, yóò sì jó tí kò ní ṣe é pa.
21 “ ‘Èyí ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí: Tẹ̀síwájú kí ẹ kó ẹbọ sísun yín àti àwọn ẹbọ yòókù papọ̀ kí ẹ̀yin kí ó sì jẹ ẹran wọ́n fúnrayín. 22 Ní tòsí nígbà tí mo mú àwọn baba ńlá yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti tí mo sì bá wọn sọ̀rọ̀. N kò pàṣẹ fún wọn lórí ẹbọ sísun lásán. 23 Mo pàṣẹ fún wọn báyìí pé: Gbọ́ tèmi, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run yín ẹ̀yin yóò sì jẹ́ ènìyàn mi. Máa rìn ní ojú ọ̀nà tí mo pàṣẹ fún yín, kí ó lè dára fún yín. 24 Ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́, wọn kò sì fetísílẹ̀ dípò èyí wọ́n ń tẹ̀ sí ọ̀nà agídí ọkàn wọn. Dípò kí wọn tẹ̀síwájú wọ́n ń rẹ̀yìn. 25 Láti ìgbà tí àwọn baba ńlá yín ti jáde ní Ejibiti títí di òní, ni èmi ti ń rán àwọn ìránṣẹ́ mi, àwọn wòlíì sí yín. 26 Wọn kò gbọ́ wọn kò sì fetísílẹ̀. Wọ́n wa ọrùn le, wọn wa ọrùn kì, wọ́n sì hu ìwà ìbàjẹ́ ju àwọn baba ńlá wọn.’
27 “Nígbà tí ìwọ bá sọ gbogbo èyí fún wọn, wọn kì yóò gbọ́ tirẹ̀, nígbà tí ìwọ bá sì pè wọ́n, wọn kì yóò dáhùn. 28 Nítorí náà, sọ fún wọn pé ‘Èyí ni orílẹ̀-èdè tí kò gbọ́ ti Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ tàbí kí ó ṣe ìgbọ́ràn sí ìbáwí. Ọ̀rọ̀ òtítọ́ kò sí ní ètè wọn.
29 “ ‘Gé irun yín kí ẹ sì dàánù, pohùnréré ẹkún lórí òkè, nítorí Olúwa ti kọ ìran yìí tí ó wà lábẹ́ ìbínú rẹ̀ sílẹ̀.
Àfonífojì ìparun
30 “ ‘Àwọn ènìyàn Juda ti ṣe búburú lójú mi, ni Olúwa wí. Wọ́n ti to àwọn ère ìríra wọn jọ sí ilé tí a fi orúkọ mi pè wọ́n sì ti sọ ọ́ di àìmọ́. 31 Wọ́n ti kọ́ àwọn ibi gíga ti Tofeti ní Àfonífojì Beni-Hinnomu láti sun àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn nínú iná èyí tí èmi kò pàṣẹ tí kò sì wá sí ọkàn mi. 32 Nítorí náà kíyèsára ọjọ́ ń bọ̀, ni Olúwa wí, nígbà tí àwọn ènìyàn kò ní pè é ní Tafeti tàbí Àfonífojì ti Beni-Hinnomu; ṣùgbọ́n yóò ma jẹ Àfonífojì Ìparun, nítorí wọn yóò sin òkú sí Tofeti títí kò fi ní sí ààyè mọ́ 33 Nígbà náà ni òkú àwọn ènìyàn wọ̀nyí yóò di oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹranko ilẹ̀, kò sì ní sí ẹnìkan tí yóò dẹ́rùbà wọ́n. 34 (B)Èmi yóò mú òpin bá ìró ayọ̀ àti ìdùnnú àti ohùn àwọn tọkọtaya ní àwọn ìlú Juda àti ní ìgboro Jerusalẹmu, nítorí tí ilẹ̀ náà yóò di ahoro.
8 “ ‘Ní ìgbà náà ni Olúwa wí pé, wọn yóò mú egungun àwọn ọba Juda àti egungun àwọn ìjòyè, egungun àwọn àlùfáà àti egungun àwọn wòlíì àti egungun àwọn olùgbé Jerusalẹmu kúrò nínú ibojì. 2 A ó yọ wọ́n síta fún oòrùn àti òṣùpá àti gbogbo àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run tí wọ́n ti fẹ́ràn tí wọ́n sì ti sìn, àti àwọn tí wọ́n ti tọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti wá tí wọ́n sì ti foríbalẹ̀ fún. Kì yóò ṣà wọ́n jọ tàbí sìn wọ́n, wọn yóò dàbí ìdọ̀tí tó wà lórí ilẹ̀. 3 Níbikíbi tí mo bá lé wọn lọ, gbogbo àwọn ìyókù wọn yóò fẹ́ ikú ju ìyè lọ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.’
Ẹ̀ṣẹ̀ àti ìjìyà
4 “Wí fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“ ‘Bí ènìyàn bá ṣubú lulẹ̀
wọn kì í padà dìde bí? Nígbà tí
ènìyàn bá yà kúrò ní ọ̀nà rẹ,
kì í yí padà bí?
5 Èéṣe nígbà náà àwọn ènìyàn wọ̀nyí
fi yà kúrò lọ́nà rẹ̀? Kí ló dé tí Jerusalẹmu
fi yà kúrò ní gbogbo ìgbà?
Wọ́n rọ̀ mọ́ ẹ̀tàn, wọ́n kọ̀ láti yípadà.
6 Mo ti fetísílẹ̀ dáradára, wọn
kò sọ ohun tí ó tọ́. Kò sí ẹnìkan tó
ronúpìwàdà nínú ìwà búburú rẹ̀,
kí ó wí pé, “Kí ni mo ṣe?” Olúkúlùkù
ń tọ ọ̀nà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹṣin tó ń lọ sójú ogun.
7 Kódà, ẹyẹ àkọ̀ ojú ọ̀run mọ ìgbà
tirẹ̀, àdàbà, alápáǹdẹ̀dẹ̀ àti lékèélékèé
mọ àkókò ìṣípò padà wọn. Ṣùgbọ́n àwọn
ènìyàn mi kò mọ ohun tí Ọlọ́run wọn fẹ́.
8 “ ‘Báwo ni ẹ̀yin ṣe lè wí pé, “Àwa gbọ́n,
nítorí a ní òfin Olúwa,” nígbà
tí ó jẹ́ pé kálámù èké àwọn
akọ̀wé ti àwọn sọ ọ́ di ẹ̀tàn
9 Ojú yóò ti àwọn ọlọ́gbọ́n, a ó dà
wọ́n láàmú, wọn yóò sì kó sí ìgbèkùn.
Nítorí wọ́n ti kọ ọ̀rọ̀ Olúwa. Irú ọgbọ́n
wo ló kù tí wọ́n ní?
10 Nítorí náà, èmi yóò fi ìyàwó wọn fún
àwọn ọkùnrin mìíràn àti ilẹ̀ wọn
fún àwọn ẹlòmíràn láti èyí tó kéré
jù dé èyí tó dàgbà jù, gbogbo wọn
ni èrè àjẹjù ń jẹ lógún; àwọn wòlíì
àti àwọn àlùfáà pẹ̀lú ń hùwà ẹ̀tàn.
11 Wọ́n tọ́jú ọgbẹ́ àwọn ènìyàn mi gẹ́gẹ́
bí èyí tí kò jinlẹ̀.
“Àlàáfíà, àlàáfíà,” ni wọ́n ń wí,
nígbà tí kò sí àlàáfíà.
12 Ǹjẹ́ wọ́n tijú fún ìṣe ìríra wọn? Bẹ́ẹ̀ kọ́,
wọn kò ní ìtìjú rárá; wọn kò tilẹ̀ mọ
bí wọ́n ti ṣe ń tì jú. Nítorí náà
wọn yóò ṣubú pẹ̀lú àwọn tó ti ṣubú,
a ó sì wó wọ́n lulẹ̀ nígbà tí a bá bẹ̀ wọ́n wò,
ni Olúwa wí.
13 “ ‘Èmi yóò mú ìkórè wọn kúrò
ni Olúwa wí.
Kì yóò sí èso lórí igi àjàrà,
kì yóò sí ọ̀pọ̀tọ́ lórí igi, ewé wọn yóò sì rẹ̀ sílẹ̀.
Ohun tí mo ti fi fún wọn ni à ó gbà kúrò.’ ”
14 “Èéṣe tí àwa fi jókòó ní ibí yìí?
A kó ara wa jọ!
Jẹ́ kí a sálọ sí ìlú olódi
kí a sì ṣègbé síbẹ̀.
Nítorí tí Olúwa Ọlọ́run wa ti pinnu pé a ó ṣègbé.
Yóò sì fún wa ní omi onímájèlé mu,
nítorí àwa ti ṣẹ̀ sí i.
15 Àwa ń retí àlàáfíà,
kò sí ìre kan
tí ó wá ní ìgbà ìmúláradá
bí kò ṣe ìpayà nìkan.
16 Ìró ìfọn imú ẹṣin àwọn ọlọ̀tẹ̀
là ń gbọ́ láti Dani,
yíyan àwọn akọ ẹṣin
mú gbogbo ilẹ̀ wárìrì.
Wọ́n wá láti pa ilẹ̀ náà run,
gbogbo ohun tó wà níbẹ̀,
ìlú náà àti gbogbo olùgbé ibẹ̀.”
17 “Wò ó, èmi yóò rán àwọn ejò olóró sí àárín yín,
paramọ́lẹ̀ tí ẹ kò lè pa oró wọn,
yóò sì bù yín jẹ,”
ni Olúwa wí.
18 Olùtùnú mi, nígbà tí ìbànújẹ́ ọkàn mi
rẹ̀wẹ̀sì nínú mi.
19 Fetí sí ẹkún àwọn ènìyàn mi láti ilẹ̀ jíjìnnà wá:
“Olúwa kò ha sí ní Sioni bí?
Ọba rẹ̀ kò sí níbẹ̀ mọ́ ni?”
“Èéṣe tí wọ́n fi mú mi bínú pẹ̀lú ère wọn, pẹ̀lú àwọn
òrìṣà àjèjì tí wọn kò níláárí?”
20 “Ìkórè ti rékọjá,
ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ti parí
síbẹ̀ a kò gbà wá là.”
21 Níwọ́n ìgbà tí a pa àwọn ènìyàn mi run, èmi náà run pẹ̀lú,
èmi ṣọ̀fọ̀, ìrora sì mú mi káká.
22 Kò ha sí ìkunra ní Gileadi bí?
Kò ha sí àwọn oníṣègùn níbẹ̀?
Kí ló ha dé tí kò fi sí ìwòsàn
fún ọgbẹ́ àwọn ènìyàn mi?
9 Háà! Orí ìbá jẹ́ orísun omi
kí ojú mi sì jẹ́ orísun omijé!
Èmi yóò sì sọkún tọ̀sán tòru
nítorí ìparun àwọn ènìyàn mi.
2 Háà, èmi ìbá ní ni aginjù
ilé àgbàwọ̀ fún àwọn arìnrìn-àjò,
kí n ba à lè fi àwọn ènìyàn mi sílẹ̀
kí n sì lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn:
nítorí gbogbo wọn jẹ́ panṣágà
àjọ aláìṣòótọ́ ènìyàn.
3 Wọ́n ti pèsè ahọ́n wọn sílẹ̀
bí ọfà láti fi pa irọ́;
kì í ṣe nípa òtítọ́
ni wọ́n fi borí ní ilẹ̀ náà.
Wọ́n ń lọ láti inú ẹ̀ṣẹ̀ kan sí òmíràn;
wọn kò sì náání mi,
ní Olúwa wí.
4 Ṣọ́ra fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ;
má ṣe gbẹ́kẹ̀lé àwọn arákùnrin rẹ.
Nítorí pé oníkálùkù arákùnrin jẹ́ atannijẹ,
oníkálùkù ọ̀rẹ́ sì jẹ́ abanijẹ́.
5 Ọ̀rẹ́ ń dalẹ̀ ọ̀rẹ́. Kò sì ṣí ẹni
tó sọ òtítọ́, wọ́n ti kọ́ ahọ́n wọn
láti máa purọ́. Wọ́n sọ ara wọn
di onírẹ̀wẹ̀sì pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀
6 Ó ń gbé ní àárín ẹ̀tàn
wọ́n kọ̀ láti mọ̀ mí nínú
ẹ̀tàn wọn,
ni Olúwa wí.
7 Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Àwọn ọmọ-ogun wí:
“Wò ó, èmi dán wọn wo; nítorí pé
kí ni èmi tún le è ṣe? Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn mi?
8 Ahọ́n wọn dàbí ọfà olóró
ó ń sọ ẹ̀tàn; oníkálùkù sì ń
fi ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ̀ àlàáfíà sí
aládùúgbò rẹ̀; ní inú
ọkàn rẹ̀, ó dẹ tàkúté sílẹ̀.
9 Èmi kì yóò ha fi ìyà jẹ wọ́n nítorí èyí?”
ni Olúwa wí.
“Èmi kì yóò ha gbẹ̀san ara
mi lórí irú orílẹ̀-èdè yìí bí?”
10 Èmi yóò sì sọkún, pohùnréré
ẹkún fún àwọn òkè; àti ẹkún
ìrora lórí pápá oko aginjù wọ̀n-ọn-nì.
Nítorí wọ́n di ahoro, wọn kò sì
kọjá ní ibẹ̀. A kò sì gbọ́ igbe
ẹran ọ̀sìn, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run
sì ti sálọ, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ẹranko sì ti lọ.
11 “Èmi yóò sì sọ Jerusalẹmu di òkìtì
àlàpà àti ihò àwọn ìkookò.
Èmi ó sì sọ ìlú Juda di ahoro
tí ẹnikẹ́ni kò sì ní le è gbé.”
12 Ta ni ẹni náà tí ó ní ọgbọ́n láti mòye nǹkan wọ̀nyí? Ta ni Olúwa ti sọ èyí fún, tí ó sì lè ṣàlàyé rẹ̀? Èéṣe tí ilẹ̀ náà fi ṣègbé bí aginjù, tí ẹnìkankan kò sì le là á kọjá?
13 Olúwa sì wí pé, nítorí pé wọ́n ti kọ òfin mi sílẹ̀, èyí tí mo gbé kalẹ̀ níwájú wọn, wọn ṣe àìgbọ́ràn sí wọn, wọn kò sì rìn nínú òfin mi. 14 Dípò èyí, wọ́n ti tẹ̀lé agídí ọkàn wọn, wọ́n ti tẹ̀lé Baali gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn ṣe kọ́ wọn. 15 Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí, “Wò ó, Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn wọ̀nyí jẹ oúnjẹ kíkorò àti láti mu omi májèlé. 16 Èmi yóò sì tú wọn ká láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, nínú èyí tí àwọn tàbí àwọn baba wọn kò mọ̀. Èmi yóò sì lépa wọn pẹ̀lú idà títí èmi yóò fi pa wọ́n run.”
17 Èyí sì ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Àwọn ọmọ-ogun wí:
“Sá à wò ó nísinsin yìí! Ké sí obìnrin ti ń ṣọ̀fọ̀ nì kí ó wá;
sì ránṣẹ́ pe àwọn tí ó mòye nínú wọn.
18 Jẹ́ kí wọn wá kíákíá,
kí wọn wá pohùnréré ẹkún
lé wa lórí títí ojú wa yóò
fi sàn fún omijé tí omi yóò sì máa sàn àwọn ìpéǹpéjú wa
19 A gbọ́ igbe ìpohùnréré
ẹkún ní Sioni:
‘Àwa ti ṣègbé tó!
A gbọdọ̀ fi ilẹ̀ wa sílẹ̀,
nítorí pé àwọn ilé wa ti parun.’ ”
20 Nísinsin yìí, ẹ̀yin obìnrin ẹ gbọ́
ọ̀rọ̀ Olúwa. Ṣí etí yín sí
ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ. Kọ́ àwọn ọmọbìnrin
yín ní ìpohùnréré
ẹkún, kí ẹ sì kọ́ ara yín ní arò.
21 Ikú ti gba ojú fèrèsé wa wọlé
ó sì ti wọ odi alágbára wa
ó ti ké àwọn ọmọ kúrò ní
àdúgbò àti àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin
kúrò ní gbọ̀ngàn ìta gbangba.
22 Sọ pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“ ‘Òkú àwọn ènìyàn yóò ṣubú
bí ààtàn ní oko gbangba
àti bí ìbùkúnwọ́ lẹ́yìn olùkórè
láìsí ẹnìkankan láti kó wọn jọ.’ ”
23 Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“Má ṣe jẹ́ kí ọlọ́gbọ́n yangàn
nítorí agbára ọgbọ́n rẹ̀, tàbí alágbára
nítorí rẹ̀, tàbí ọlọ́rọ̀
nítorí ọrọ̀ rẹ̀.
24 (C)Ẹ jẹ́ kí ẹni tí ń
ṣògo nípa èyí nì wí pé
òun ní òye, òun sì mọ̀ mí
wí pé, èmi ni Olúwa tí ń
ṣe òtítọ́ ìdájọ́ àti òdodo
ní ayé nínú èyí ni mo ní
inú dídùn sí,”
Olúwa wí.
25 “Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “tí Èmi yóò fi ìyà jẹ gbogbo àwọn tí a kọ ilà fún nínú ara nìkan. 26 Ejibiti, Juda, Edomu, Ammoni, Moabu àti gbogbo àwọn tí ń gbé ní ọ̀nà jíjìn réré ní aginjù. Nítorí pé gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí jẹ́ aláìkọlà gbogbo àwọn ará ilé Israẹli sì jẹ́ aláìkọlà ọkàn.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.