1 Peteru 4:17
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
17 Nítorí ti ìgbà náà dé, tí ìdájọ́ yóò bẹ̀rẹ̀ láti ilé Ọlọ́run wá: bí ó bá sì tètè tí ọ̀dọ̀ wa bẹ̀rẹ̀, ìgbẹ̀yìn àwọn tí kò gba ìhìnrere Ọlọ́run yó ha ti rí?
Read full chapter
Ìfihàn 7:3
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
3 (A)wí pé, “Ẹ má ṣe pa ayé, tàbí Òkun, tàbí igi lára, títí àwa ó fi fi èdìdì sàmì sí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run wa ní iwájú wọn.”
Read full chapter
Ìfihàn 9:4
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
4 (A)A sì fún wọn pé ki wọn má ṣe pa koríko ilẹ̀ lára tàbí ohun tútù kan, tàbí igikígi kan; bí kò ṣe àwọn ènìyàn tí kò ni èdìdì Ọlọ́run ní iwájú wọn.
Read full chapter
Ìfihàn 14:1
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Ọ̀dọ́-àgùntàn àti ọ̀kẹ́ méje ó-lé-ẹgbàajì (144,000)
14 (A)Mo sì wo, si kíyèsi i, Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà dúró lórí Òkè Sioni, àti pẹ̀lú rẹ̀ ọ̀kẹ́ méje ó-lé-ẹgbàajì (144,000) ènìyàn; wọ́n ní orúkọ rẹ̀, àti orúkọ baba rẹ̀ tí a kọ sí iwájú orí wọn.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.