Book of Common Prayer
Saamu Dafidi. Ẹ̀bẹ̀.
38 Olúwa, Má ṣe bá mi wí nínú ìbínú rẹ,
bẹ́ẹ̀ ni kí o má ṣe fi ìyà jẹ mí nínú ìrunú rẹ̀.
2 Nítorí tí ọfà rẹ kàn mọ́ mi ṣinṣin,
ọwọ́ rẹ sì kì mí mọ́lẹ̀.
3 Kò sí ibi yíyè ní ara à mi, nítorí ìbínú rẹ;
kò sí àlàáfíà nínú egungun mi nítorí i ẹ̀ṣẹ̀ mi.
4 Nítorí àìṣedéédéé mi ti borí mi mọ́lẹ̀;
wọ́n tó ìwọ̀n bi àjàgà tí ó wúwo jù fún mi.
5 Ọgbẹ́ mi ń rùn ó sì díbàjẹ́
nítorí òmùgọ̀ mi.
6 Èmi ń jòwèrè, orí mi tẹ̀ ba gidigidi
èmi ń ṣọ̀fọ̀ rìn kiri ní gbogbo ọjọ́.
7 Nítorí ẹ̀gbẹ́ mi kún fún ìgbóná tí ń jóni
kò sì ṣí ibi yíyè ní ara mi,
8 Ara mi hù, a sì wó mi jẹ́gẹjẹ̀gẹ;
mo kérora nítorí ìrúkèrúdò àyà mi.
9 Olúwa, gbogbo ìfẹ́ mi ń bẹ níwájú rẹ;
ìmí ẹ̀dùn mi kò sápamọ́ fún ọ.
10 Àyà mi ń mí hẹlẹ, agbára mi yẹ̀ mí sílẹ̀;
bí ó ṣe ti ìmọ́lẹ̀ ojú mi ni, ó ti lọ kúrò lára mi.
11 Àwọn ọ̀rẹ́ mi àti àwọn ẹlẹgbẹ́ mi dúró lókèèrè réré kúrò níbi ìpọ́njú mi,
àwọn alábágbé mi, dúró lókèèrè.
12 Àwọn tí n wá ẹ̀mí mi dẹ okùn sílẹ̀ fún mi;
àti àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára ń sọ̀rọ̀ nípa ìparun,
wọ́n sì ń gbèrò ẹ̀tàn ní gbogbo ọjọ́.
13 Ṣùgbọ́n mo dàbí adití odi, èmi kò gbọ́ ọ̀rọ̀;
àti bí odi, tí kò le sọ̀rọ̀.
14 Nítòótọ́, mo rí bí ọkùnrin tí kò gbọ́rọ̀,
àti bí ẹnu ẹni tí kò sí ìjiyàn.
15 Ṣùgbọ́n sí ọ Olúwa, ìwọ ni mo dúró dè;
ìwọ ni, Olúwa Ọlọ́run mi, ẹni tí yóò dáhùn.
16 Nítorí tí mo gbàdúrà, “Gbóhùn mi, kí wọn má ba à yọ̀ mí;
nígbà tí ẹsẹ̀ mi bá yọ̀ wọn yóò máa gbé ara wọn ga sí mi.”
17 Nítorí tí mo ti ṣetán láti ṣubú,
ìrora mi sì wà pẹ̀lú mi nígbà gbogbo.
18 Mo jẹ́wọ́ ìrékọjá mi;
àánú sì ṣe mí fún ẹ̀ṣẹ̀ mi.
19 Àwọn tí ó jẹ́ ọ̀tá mi láìnídìí pàtàkì, wọ́n lágbára púpọ̀,
ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí ó kórìíra mi lọ́nà òdì.
20 Àwọn tí wọn ń fi ibi san rere fún mi
àwọn ni ọ̀tá mi
nítorí pé mò ń tọ ìre lẹ́yìn.
21 Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀, ìwọ Olúwa!
Ọlọ́run mi, Má ṣe jìnnà sí mi.
22 Yára láti ràn mí lọ́wọ́,
Olúwa, Olùgbàlà mi.
Àdúrà láti ní òye ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
25 Ọkàn mí lẹ̀ mọ́ erùpẹ̀;
ìwọ sọ mí di ààyè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
26 Èmi tún ọ̀nà mi ṣírò ìwọ sì dá mi lóhùn;
kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.
27 Jẹ́ kí n mọ ẹ̀kọ́ ìlànà rẹ:
nígbà náà ni èmi yóò ṣe àṣàrò iṣẹ́ ìyanu rẹ.
28 Ọkàn mi ń ṣe àárẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́;
fi agbára fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
29 Pa mí mọ́ kúrò nínú ọ̀nà ẹ̀tàn
fún mi ní oore-ọ̀fẹ́ nípa òfin rẹ.
30 Èmi ti yan ọ̀nà òtítọ́
èmi ti gbé ọkàn mi lé òfin rẹ.
31 Èmi yára di òfin rẹ mú. Olúwa
má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí.
32 Èmi sáré ní ipa ọ̀nà àṣẹ rẹ,
nítorí ìwọ, ti tú ọkàn mi sílẹ̀.
Ìlérí Ọlọ́run fún aláforítì
33 Kọ́ mi, Olúwa, láti tẹ̀lé àṣẹ rẹ;
nígbà náà ni èmi yóò pa wọ́n mọ́ dé òpin.
34 Fún mi ní òye, èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́
èmi yóò sì máa kíyèsi i pẹ̀lú ọkàn mi.
35 Fi ipa ọ̀nà àṣẹ rẹ hàn mí,
nítorí nínú rẹ̀ ni èmi rí inú dídùn.
36 Yí ọkàn mi padà sí òfin rẹ
kí ó má ṣe sí ojúkòkòrò mọ́.
37 Yí ojú mi padà kúrò láti máa wo ohun asán:
pa ọ̀nà mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
38 Mú ìlérí rẹ sẹ sí ìránṣẹ́ rẹ,
nítorí òfin rẹ dára.
39 Yí ẹ̀gàn mi padà tí mo bẹ̀rù
nítorí tí ìdájọ́ rẹ dára.
40 Kíyèsi i, ọkàn mi ti fà sí ẹ̀kọ́ rẹ!
Pa ayé mi mọ́ nínú òdodo rẹ.
Ìgbàlà láti inú òfin Ọlọ́run
41 Jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà wá bá mi, Olúwa,
ìgbàlà rẹ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ;
42 Nígbà náà ni èmi yóò dá
ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí mi lóhùn,
nítorí èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ.
43 Má ṣe gba ọ̀rọ̀ òtítọ́ láti ẹnu mi
nítorí èmi ti gbé ìrètí mi sínú àṣẹ rẹ
44 Èmi yóò máa gbọ́rọ̀ sí òfin rẹ nígbà gbogbo
láé àti láéláé.
45 Èmi yóò máa rìn káàkiri ní òmìnira,
nítorí èmi ti kígbe ẹ̀kọ́ rẹ jáde.
46 Èmi yóò sọ̀rọ̀ òfin rẹ níwájú àwọn ọba
ojú kì yóò sì tì mí,
47 Nítorí èmi ní inú dídùn nínú àṣẹ rẹ
nítorí èmi ní ìfẹ́ wọn.
48 Èmi gbé ọwọ́ mi sókè nítorí àṣẹ rẹ, èyí tí èmi fẹ́ràn,
èmi sì ń ṣe àṣàrò òfin rẹ̀.
Èdìdì keje àti àwo tùràrí
8 Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì keje, ìdákẹ́rọ́rọ́ sì wà ní ọ̀run níwọ̀n ààbọ̀ wákàtí kan.
2 Mo sì rí àwọn angẹli méje tí wọn dúró níwájú Ọlọ́run; a sì fi ìpè méje fún wọn.
3 (A)Angẹli mìíràn sì wá, ó sì dúró ti pẹpẹ, ó ní àwo tùràrí wúrà kan a sì fi tùràrí púpọ̀ fún un, láti máa fi kún àdúrà gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ lórí pẹpẹ, pẹpẹ wúrà tí ń bẹ níwájú ìtẹ́. 4 Àti èéfín tùràrí náà pẹ̀lú àdúrà àwọn ènìyàn mímọ́ sì gòkè lọ síwájú Ọlọ́run láti ọwọ́ angẹli náà wá. 5 (B)Angẹli náà sì mú àwo tùràrí náà, ó sì fi iná orí pẹpẹ kùn ún, ó sì dà á sórí ilẹ̀ ayé: A sì gbọ́ ohùn, àrá sì sán, mọ̀nàmọ́ná sì kọ, àti ilẹ̀-rírì.
Àwọn ìpè
6 Àwọn angẹli méje náà tí wọn ni ìpè méje sì múra láti fún wọn.
7 (C)Èkínní sì fọn ìpè tirẹ̀: Yìnyín àti iná, tí o dàpọ̀ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀, sì jáde, a sì dà wọ́n sórí ilẹ̀ ayé: ìdámẹ́ta ilẹ̀ ayé si jóná, ìdámẹ́ta àwọn igi sì jóná, àti gbogbo koríko tútù sì jóná.
8 (D)Angẹli kejì si fún ìpè tirẹ̀, a sì sọ ohun kan, bí òkè-ńlá tí ń jóná, sínú Òkun: ìdámẹ́ta Òkun si di ẹ̀jẹ̀; 9 àti ìdámẹ́ta àwọn ẹ̀dá tí ń bẹ nínú Òkun tí ó ni ẹ̀mí sì kú; àti ìdámẹ́ta àwọn ọkọ̀ si bàjẹ́.
10 (E)Angẹli kẹta sì fún ìpè tirẹ̀, ìràwọ̀ ńlá kan tí ń jó bí fìtílà sì bọ́ láti ọ̀run wá, ó sì bọ́ sórí ìdámẹ́ta àwọn odò ṣíṣàn, àti sórí àwọn orísun omi; 11 A sì ń pe orúkọ ìràwọ̀ náà ní Iwọ, ìdámẹ́ta àwọn omi sì di iwọ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sì tí ipa àwọn omi náà kú, nítorí tí a sọ wọn di kíkorò.
12 Angẹli kẹrin sì fún ìpè tirẹ̀, a sì kọlu ìdámẹ́ta oòrùn, àti ìdámẹ́ta òṣùpá, àti ìdámẹ́ta àwọn ìràwọ̀, ki ìdámẹ́ta wọn lè ṣókùnkùn, kí ọjọ́ má ṣe mọ́lẹ̀ fún ìdámẹ́ta rẹ̀, àti òru bákan náà.
13 Mo sì wò, mo sì gbọ́ idì kan tí ń fò ni àárín ọ̀run, ó ń wí lóhùn rara pé, “Ègbé, ègbé, fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé nítorí ohun ìpè ìyókù tí àwọn angẹli mẹ́ta tí ń bọ̀ wá yóò fún!”
17 Àwọn àádọ́rin náà sì fi ayọ̀ padà, wí pé, “Olúwa, àwọn ẹ̀mí èṣù tilẹ̀ foríbalẹ̀ fún wa ní orúkọ rẹ.”
18 (A)Ó sì wí fún wọn pé, “Èmí rí Satani ṣubú bí mọ̀nàmọ́ná láti ọ̀run wá. 19 Kíyèsi i, èmí fún yín ní àṣẹ láti tẹ ejò àti àkéekèe mọ́lẹ̀, àti lórí gbogbo agbára ọ̀tá: kò sì ṣí ohun kan bí ó ti wù tí ó ṣe, tí yóò pa yín lára. 20 (B)Ṣùgbọ́n kí ẹ má ṣe yọ̀ nítorí èyí pé, àwọn ẹ̀mí ń foríbalẹ̀ fún yín; ṣùgbọ́n ẹ kúkú yọ̀, pé; a kọ̀wé orúkọ yín ní ọ̀run!”
21 (C)(D) Ní wákàtí kan náà Jesu yọ̀ nínú Ẹ̀mí mímọ́ ó sì wí pé, “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Baba, Olúwa ọ̀run àti ayé, pé, ìwọ pa nǹkan wọ̀nyí mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n àti amòye, ìwọ sì fi wọ́n hàn fún àwọn ọmọ ọwọ́: bẹ́ẹ̀ ni, Baba, bẹ́ẹ̀ ni ó sá à yẹ ní ojú rẹ.
22 (E)“Ohun gbogbo ni a ti fi fún mi láti ọ̀dọ̀ Baba mi; kò sì ṣí ẹni tí ó mọ ẹni tí ọmọ jẹ́, bí kò ṣe Baba; àti ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wu ọmọ láti fi í hàn fún.”
23 (F)Ó sì yípadà sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ní apá kan. Ó ní, “Ìbùkún ni fún ojú tí ń rí ohun tí ẹ̀yin ń rí. 24 Nítorí mo wí fún yín, ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì àti àwọn ọba ni ó ń fẹ́ láti rí ohun tí ẹ̀yin ń rí, wọn kò sì rí wọn, àti láti gbọ́ ohun tí ẹ̀yin ń gbọ́, wọn kò sì gbọ́ wọn.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.