Book of Common Prayer
Ti Dafidi.
103 Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi; àti gbogbo ohun tí ó wà nínú mi, yín orúkọ rẹ̀ mímọ́.
2 Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi, kí o má ṣe gbàgbé gbogbo oore rẹ̀
3 Ẹni tí ó dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì ọ́
tí ó sì wo gbogbo ààrùn rẹ̀ sàn,
4 Ẹni tí ó ra ẹ̀mí rẹ padà kúrò nínú kòtò ikú
ẹni tí ó fi ìṣeun ìfẹ́ àti ìyọ́nú dé ọ ní adé,
5 Ẹni tí ó fi ohun dídára tẹ́ ọ lọ́rùn
kí ìgbà èwe rẹ̀ lè di ọ̀tún bí ti ẹyẹ idì.
6 Olúwa ń ṣe òdodo àti ìdájọ́ fún
gbogbo àwọn tí a ni lára.
7 Ó fi ọ̀nà rẹ̀ hàn fún Mose, iṣẹ́ rẹ̀ fun àwọn ọmọ Israẹli;
8 (A)Olúwa ni aláàánú àti olóore,
ó lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́.
9 Òun kì í bá ni wí ní ìgbà gbogbo
bẹ́ẹ̀ ni kì í pa ìbínú rẹ mọ́ láéláé;
10 Òun kì í ṣe sí wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ wa
bẹ́ẹ̀ ni kì í san án fún wa gẹ́gẹ́
bí àìṣedéédéé wa.
11 Nítorí bí ọ̀run ṣe ga sílẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ rẹ̀ tóbi sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.
12 Bí ìlà-oòrùn ti jìnnà sí ìwọ̀-oòrùn
bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú ìrékọjá wá jìnnà sí wa.
13 Bí baba ti ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ rẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀;
14 Nítorí tí ó mọ dídá wa,
ó rántí pé erùpẹ̀ ni wá.
15 Bí ó ṣe ti ènìyàn ni, ọjọ́ rẹ̀ dàbí koríko,
ó gbilẹ̀ bí ìtànná ewéko igbó;
16 Afẹ́fẹ́ fẹ́ kọjá lọ lórí rẹ̀,
kò sì rántí ibùjókòó rẹ̀ mọ́.
17 (B)Ṣùgbọ́n láti ayérayé ni ìfẹ́
Olúwa ti wà pẹ̀lú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
àti òdodo rẹ̀ wà láti ọmọdọ́mọ
18 Sí àwọn tí ó pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́
àti àwọn tí ó rántí òfin rẹ̀ láti ṣe wọ́n.
19 Olúwa ti pèsè ìtẹ́ rẹ̀ nínú ọ̀run,
ìjọba rẹ̀ ní ó sì borí ohun gbogbo.
20 Yin Olúwa, ẹ̀yin angẹli rẹ̀,
tí ó ní ipá, tí ó pa òfin ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́
21 Yin Olúwa, ẹ̀yin ogun ọ̀run rẹ̀ gbogbo,
ẹ̀yin ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀.
22 Yin Olúwa, gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ ní
ibi gbogbo ìjọba rẹ̀.
Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi.
Odò láti inú tẹmpili náà
47 (A)Ọkùnrin náà mú mi padà lọ sí àbáwọlé tẹmpili náà, mo sì rí omi tí ó ń tú jáde láti abẹ́ ìloro tẹmpili náà sí apá ìhà ìlà-oòrùn (nítorí tẹmpili náà dojúkọ ìhà ìlà-oòrùn) Omi náà ń tú jáde sí ìsàlẹ̀ láti abẹ́, ní ìhà gúúsù tẹmpili náà, ní ìhà gúúsù pẹpẹ. 2 Ó wá mú mi gba ojú ọ̀nà àríwá jáde, ó sì mú mi yí ìta ojú ọ̀nà ìta tí ó dojúkọ ìhà ìlà-oòrùn, omi náà sì ń sàn láti ìhà gúúsù wá.
3 Bí ọkùnrin náà ti lọ sí apá ìhà ìlà-oòrùn pẹ̀lú okùn wíwọ̀n nǹkan lọ́wọ́ rẹ̀, ó wọn ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́, ó sì mú mi gba ibi odò kan tí kò jì jù kókósẹ̀ lọ. 4 Ó sì wọn ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́ mìíràn kúrò, ó sì mú mi gba ibi odò tí ó jì ní ìwọ̀n orúnkún. Ó tún wọn ẹgbẹ̀rún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ mìíràn kúrò, ó sì mú mi gba odò tí ó dé ìbàdí. 5 Ó wọn ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́ mìíràn kúrò, ṣùgbọ́n nísinsin yìí odò tí ń kò lè kọjá rẹ̀ ni, Nítorí pé odò tí ó kún, ó sì jì tó èyí tí wọ́n le lúwẹ̀ẹ́ nínú rẹ̀ odò tí ẹnikẹ́ni kò le dá kọjá ni. 6 Ó bi mí léèrè pé: “Ọmọ ènìyàn, ǹjẹ́ o rí èyí?”
Lẹ́yìn náà, ó mú mi padà sí etí odò. 7 Nígbà tí mo dé ibẹ̀, mo rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì odò. 8 Ó sọ fún mi pé, “Odò yìí ń tú jáde sí ìhà ìlà-oòrùn, wọ́n sì ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n sì wọ inú Òkun lọ, a sì mú omi wọn láradá. 9 Àwọn ohun alààyè tí ó ń rákò yóò máa gbé ní ibikíbi tí odò ti ń sàn. Ẹja yóò pọ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀, nítorí pé odò ń sàn síbẹ̀, ó sì mú kí omi iyọ̀ tutù nini; nítorí náà níbi tí omi ti ń sàn, gbogbo nǹkan ni yóò wà ni ààyè. 10 Àwọn apẹja yóò dúró ní etí bèbè odò; láti En-Gedi títí dé En-Eglaimu ààyè yóò wa láti tẹ́ àwọ̀n wọn sílẹ̀. Oríṣìíríṣìí ẹja ni yóò wà gẹ́gẹ́ bí ẹja omi Òkun ńlá. 11 Ṣùgbọ́n ẹrẹ̀ àti àbàtà kò ní tòrò; àwa yóò fi wọn sílẹ̀ fún iyọ̀. 12 Àwọn igi eléso ní oríṣìíríṣìí ni yóò máa hù ní bèbè odò ní ìhà ìhín àti ní ìhà ọ̀hún. Ewé wọn kì yóò sì rọ, bẹ́ẹ̀ ní èso wọn kì yóò run, wọn yóò máa ṣe èso tuntun rẹ̀ ní oṣù nítorí pé omi láti ibi mímọ́ ń sàn sí wọn. Èso wọn yóò sì jẹ́ fún jíjẹ àti ewé wọn fún ìwòsàn.”
1 Ọ̀pọ̀ ènìyàn ni ó ti dáwọ́lé títo àwọn nǹkan wọ̀n-ọn-nì jọ lẹ́sẹẹsẹ, èyí tí ó ti múlẹ̀ ṣinṣin láàrín wa, 2 (A)àní gẹ́gẹ́ bí àwọn ìránṣẹ́ ọ̀rọ̀ náà, tí ó ṣe ojú wọn láti ìbẹ̀rẹ̀ ti fi lé wa lọ́wọ́. 3 (B)Nítorí náà, ó sì yẹ fún èmi pẹ̀lú, láti kọ̀wé sí ọ lẹ́sẹẹsẹ bí mo ti wádìí ohun gbogbo fínní fínní sí láti ìpilẹ̀ṣẹ̀, Teofilu ọlọ́lá jùlọ, 4 (C)kí ìwọ kí ó le mọ òtítọ́ ohun wọ̀n-ọn-nì, tí a ti kọ́ ọ.
Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Saamu. Orin.
67 Kí Ọlọ́run kí ó ṣàánú fún wa kí ó sì bùkún fún wa,
kí ó sì jẹ́ kí ojú rẹ̀ tàn yí wa ká,
2 kí ọ̀nà rẹ le di mí mọ̀ ní ayé,
ìgbàlà rẹ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.
3 Kí àwọn ènìyàn kí ó yìn ọ́, Ọlọ́run;
kí gbogbo ènìyàn kí ó yìn ọ́!
4 Kí orílẹ̀-èdè kí ó yọ̀, kí ó sì kọrin fún ayọ̀,
nítorí ìwọ fi òdodo darí àwọn ènìyàn,
ìwọ sì jẹ ọba àwọn orílẹ̀-èdè ní ayé.
5 Kí àwọn ènìyàn kí ó yìn ọ́, Ọlọ́run;
kí gbogbo ènìyàn kí ó yìn ọ́. Sela.
6 Nígbà náà ní ilẹ̀ yóò mú ìkórè rẹ̀ wá, Ọlọ́run,
Ọlọ́run wa, yóò bùkún fún wa.
7 Ọlọ́run yóò bùkún fún wa,
àti gbogbo òpin ilẹ̀ ayé yóò sì máa bẹ̀rù rẹ̀.
96 (A)Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa:
Ẹ kọrin sí Olúwa gbogbo ayé.
2 Ẹ kọrin sí Olúwa, yin orúkọ rẹ̀
ẹ sọ ti ìgbàlà rẹ̀ ní ọjọ́ dé ọjọ́
3 Ẹ sọ ti ògo rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè
àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ láàrín gbogbo ènìyàn.
4 Nítorí títóbi ní Olúwa ẹni tí ìyìn tọ́ sí;
òun ní o yẹ kí a bẹ̀rù ju gbogbo òrìṣà lọ
5 Nítorí asán ni gbogbo àwọn òrìṣà orílẹ̀-èdè
ṣùgbọ́n Olúwa dá àwọn ọ̀run
6 Ọlá àti ọláńlá wà ní iwájú rẹ̀
agbára àti ògo wà ní ibi mímọ́ rẹ̀.
7 Ẹ fi fún Olúwa, ẹ̀yin ìbátan ènìyàn
Ẹ fi agbára àti ògo fún Olúwa
8 Ẹ fi ògo tí ó tọ́ sí Olúwa fún un;
ẹ mú ọrẹ wá, kí ẹ sì wá sí àgbàlá rẹ̀
9 Ẹ máa sin Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́ rẹ̀;
ẹ wárìrì níwájú rẹ̀ gbogbo ayé.
10 Sọ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, “Olúwa jẹ ọba”
a fi ìdí ayé múlẹ̀, tí kò sì lè yí;
ẹni tí yóò fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ ènìyàn.
11 Jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó yọ̀, kí ayé sì pariwo
jẹ́ kí pápá Òkun kí ó hó pẹ̀lú ohun
gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀.
12 Jẹ́ kí oko kún fún ayọ̀
àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀:
nígbà náà ni gbogbo igi igbó yóò máa yọ̀
13 Wọn yóò kọrin níwájú Olúwa,
nítorí tí ó ń bọ̀ wá,
Ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayé
yóò fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé
àti ti àwọn ènìyàn ni yóò fi òtítọ́ rẹ̀ ṣe.
A mú Jesu lọ sí ọ̀run
1 (A)Nínú ìwé mi ìṣáájú, Teofilu, ni mo ti kọ ní ti ohun gbogbo tí Jesu bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àti kọ́ 2 títí ó fi di ọjọ́ tí a gbà á lọ sókè ọ̀run, lẹ́yìn tí ó ti ti ipa Ẹ̀mí Mímọ́ pàṣẹ fún àwọn aposteli tí ó yàn 3 Lẹ́yìn ìjìyà rẹ̀, ó fi ara rẹ̀ hàn fún wọn àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀rí tí ó dájú pé òun wà láààyè. Ó fi ara hàn wọ́n fún ogójì ọjọ́, ó sì sọ̀rọ̀ nípa ìjọba Ọlọ́run. 4 (B)Ní àkókò kan bí ó sì ti ń jẹun pẹ̀lú wọn, ó pàṣẹ yìí fún wọn: “Ẹ má ṣe kúrò ní Jerusalẹmu, ṣùgbọ́n ẹ dúró de ìlérí tí Baba mi ṣe ìlérí, èyí tí ẹ̀yin tí gbọ́ lẹ́nu mi. 5 Nítorí Johanu fi omi bamitiisi yín, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ díẹ̀ sí i, a o fi Ẹ̀mí Mímọ́ bamitiisi yín.”
6 Nítorí náà, nígbà tí wọ́n sì péjọpọ̀, wọn bi í léèrè pé, “Olúwa, láti ìgbà yí lọ ìwọ yóò ha mú ìjọba padà fún Israẹli bí?”
7 Ó sì wí fún wọn pé, “Kì í ṣe tiyín ni láti mọ àkókò tàbí ìgbà tí Baba ti yàn nípa àṣẹ òun tìkára rẹ̀. 8 (C)Ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò gba agbára, nígbà tí Ẹ̀mí Mímọ́ bá bà lé e yín: ẹ̀yin yóò sì máa ṣe ẹlẹ́rìí mi ni Jerusalẹmu, àti ní gbogbo Judea, àti ní Samaria, àti títí dé òpin ilẹ̀ ayé.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.