Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 137

137 Ní ẹ̀bá odò Babeli, níbẹ̀ ni àwa gbé jókòó
    àwa sì sọkún nígbà tí àwa rántí Sioni.
Àwa fi dùùrù wa kọ́ sí orí igi wílò,
    tí ó wà láàrín rẹ̀.
Nítorí pé níbẹ̀ ni àwọn
    tí ó kó wa ní ìgbèkùn béèrè orin lọ́wọ́ wa,
àti àwọn tí ó ni wá lára béèrè ìdárayá wí pé;
    ẹ kọ orin Sioni kan fún wa.

Àwa ó ti ṣe kọ orin
    Olúwa ní ilẹ̀ àjèjì
Jerusalẹmu, bí èmi bá gbàgbé rẹ
    jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó gbàgbé ìlò rẹ̀.
Bí èmi kò bá rántí rẹ,
    jẹ́ kí ahọ́n mi kí ó lẹ̀ mọ́ èrìgì mi;
bí èmi kò bá fi Jerusalẹmu ṣáájú
    olórí ayọ̀ mi gbogbo.

Olúwa rántí ọjọ́ Jerusalẹmu,
    lára àwọn ọmọ Edomu,
àwọn ẹni tí ń wí pé,
    “Wó o palẹ̀, wó o palẹ̀ dé ìpìlẹ̀ rẹ̀!”
Ìwọ, ọmọbìnrin Babeli, ẹni tí a ó parun;
    ìbùkún ni fún ẹni tí ó san án fún ọ
    bí ìwọ ti rò sí wa.
Ìbùkún ni fún ẹni tí ó mú ọmọ wẹ́wẹ́ rẹ
    tí ó sì fi wọ́n ṣán òkúta.

Saamu 144

Ti Dafidi.

144 Ìyìn sí Olúwa àpáta mi,
    ẹni tí ó kọ́ ọwọ́ mi fún ogun,
    àti ìka mi fún ìjà.
Òun ni Ọlọ́run ìfẹ́ mi àti odi alágbára mi,
    ibi gíga mi àti olùgbàlà mi, asà mi,
ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀lé,
    ẹni tí ó tẹrí àwọn ènìyàn ba lábẹ́ mi.

Olúwa, kí ni ènìyàn tí ìwọ fi ń ṣàníyàn fún un,
    tàbí ọmọ ènìyàn tí ìwọ fi ń ronú nípa rẹ̀?
Ènìyàn rí bí èmi;
    ọjọ́ rẹ̀ rí bí òjìji tí ń kọjá lọ.

Tẹ ọ̀run rẹ ba, Olúwa, kí o sì sọ̀kalẹ̀;
    tọ́ àwọn òkè ńlá wọn yóò sí rú èéfín.
Rán mọ̀nàmọ́ná kí ó sì fọ́n àwọn ọ̀tá ká;
    ta ọfà rẹ kí ó sì dà wọ́n rú.
Na ọwọ́ rẹ sílẹ̀ láti ibi gíga;
    gbà mí kí o sì yọ mí nínú ewu
kúrò nínú omi ńlá:
    kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ àjèjì.
Ẹnu ẹni tí ó kún fún èké
    ẹni tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ jẹ́ ìrẹ́jẹ.

Èmi yóò kọ orin tuntun sí ọ
    Ọlọ́run; lára ohun èlò orin
olókùn mẹ́wàá èmi yóò
    kọ orin sí ọ
10 Òun ni ó fi ìgbàlà fún àwọn ọba,
    ẹni tí ó gba Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ idà ìpanilára.

Lọ́wọ́ pípanirun. 11 Gbà mí kí o sì yọ mí nínú ewu
    kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ àjèjì
tí ẹnu wọn kún fún èké,
    tí ọwọ́ ọ̀tún wọn jẹ́ ọwọ́ ọ̀tún èké.

12 Kí àwọn ọmọkùnrin wa
    kí ó dàbí igi gbígbìn tí ó dàgbà ni ìgbà èwe wọn,
àti ọmọbìnrin wa yóò dàbí òpó ilé
    tí a ṣe ọ̀nà sí bí àfarawé ààfin.
13 Àká wa yóò kún
    pẹ̀lú gbogbo onírúurú oúnjẹ
àgùntàn wa yóò pọ̀ si ní ẹgbẹ̀rún,
    ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní oko wa:
14 Àwọn màlúù wa yóò ru ẹrù wúwo
    kí ó má sí ìkọlù,
kí ó má sí ìkólọ sí ìgbèkùn,
    kí ó má sí i igbe ìpọ́njú ní ìgboro wa.
15 Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn náà tí ó wà ní irú ipò bẹ́ẹ̀,
    Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn náà,
    tí ẹni tí Ọlọ́run Olúwa ń ṣe.

Saamu 104

104 Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi.

Olúwa Ọlọ́run mi, ìwọ tóbi jọjọ;
    ọlá àti ọláńlá ni ìwọ wọ̀ ní aṣọ.

Ìwọ fi ìmọ́lẹ̀ bo ara rẹ gẹ́gẹ́ bí aṣọ;
    ó tẹ ọ̀run bí títẹ́ ẹní
Ìwọ tí ó fi omi ṣe ìtì igi àjà ìyẹ̀wù rẹ.
    Ìwọ tí o ṣe àwọsánmọ̀ ní kẹ̀kẹ́ ogun rẹ
    ìwọ tí ó ń rìn lórí apá ìyẹ́ afẹ́fẹ́.
(A)Ó fi ẹ̀fúùfù ṣe àwọn ìránṣẹ́ rẹ,
    Ọ̀wọ́-iná ni àwọn olùránṣẹ́ rẹ.

O fi ayé gúnlẹ̀ lórí àwọn ìpìlẹ̀;
    tí a kò le è mì láéláé.
Ìwọ fi ibú omi bò ó mọ́lẹ̀ bí aṣọ;
    àwọn omi sì dúró lórí àwọn òkè ńlá.
Ṣùgbọ́n nípa ìbáwí rẹ ni àwọn omi lọ,
    nípa ohùn àrá rẹ ni wọ́n sálọ;
Wọ́n sàn kọjá lórí àwọn òkè,
    wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀,
    sí ibi tí ìwọ ti yàn fún wọn.
Ìwọ gbé òpin tí wọn kò lè kọjá rẹ̀ kálẹ̀;
    láéláé ni wọ́n kò ní lè bo ayé mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i.

10 Ìwọ mú kí ìsun da omi sí àwọn Àfonífojì;
    tí ó ń sàn láàrín àwọn òkè.
11 Wọ́n fún gbogbo àwọn ẹranko igbó ní omi
    àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ń pa òǹgbẹ wọn.
12 Àwọn ẹyẹ ojú òfúrufú tẹ́ ìtẹ́ wọn lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi
    wọ́n ń kọrin láàrín àwọn ẹ̀ka.
13 Ó bu omi rin àwọn òkè láti ìyẹ̀wù rẹ̀ wá;
    a tẹ́ ayé lọ́rùn nípa èso iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
14 Ó mú kí koríko hù jáde fún àwọn ẹranko láti jẹ
    àti àwọn ewébẹ̀ fún ènìyàn láti lò
    kí ó lè mú oúnjẹ jáde láti ilẹ̀ wá:
15 Ọtí wáìnì tí ó ń mú ọkàn ènìyàn yọ̀,
    òróró láti mú ojú rẹ̀ tan,
    àti àkàrà láti ra ọkàn rẹ̀ padà.
16 Àwọn igi Olúwa ni a bu omi rin dáradára,
    kedari ti Lebanoni tí ó gbìn.
17 Níbẹ̀ ní àwọn ẹyẹ ṣe ìtẹ́ wọn
    bí ó ṣe tí àkọ̀ ni, orí igi gíga ni ilé rẹ̀.
18 Àwọn òkè gíga ni ààbò fún àwọn ewúrẹ́ igbó;
    àti àwọn àlàpà jẹ́ ààbò fún àwọn ehoro.

19 Òṣùpá jẹ́ ààmì fún àkókò
    oòrùn sì mọ ìgbà tí yóò wọ̀.
20 Ìwọ mú òkùnkùn wá, ó sì di òru,
    nínú èyí tí gbogbo ẹranko igbó ń rìn kiri.
21 Kìnnìún ń bú ramúramù fún ohun ọdẹ wọn
    wọ́n sì ń wá oúnjẹ wọn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.
22 Oòrùn ràn, wọ́n sì kó ara wọn jọ,
    wọn padà lọ dùbúlẹ̀ sí ihò wọn.
23 Ọkùnrin jáde lọ sí iṣẹ́ wọn,
    àti sí làálàá rẹ̀ títí di àṣálẹ́.

24 Iṣẹ́ rẹ ti pọ̀ tó, Olúwa!
    Nínú ọgbọ́n ni ìwọ ṣe gbogbo wọn:
    ayé kún fún àwọn ìṣẹ̀dá á rẹ.
25 Bẹ́ẹ̀ ni Òkun yìí tí ó tóbi, tí ó sì ni ìbú,
    tí ó kún fún àwọn ẹ̀dá alààyè ní ìsàlẹ̀ láìníye
    ohun alààyè tí tóbi àti kékeré.
26 Níbẹ̀ ni ọkọ̀ ń lọ síwá sẹ́yìn,
    àti Lefitani, tí ìwọ dá láti ṣe àríyá nínú rẹ̀.

27 Àwọn wọ̀nyí ń wò ọ́
    láti fún wọn ní oúnjẹ wọn lákòókò rẹ̀.
28 Nígbà tí ìwọ bá fi fún wọn,
    wọn yóò kó jọ;
nígbà tí ìwọ bá la ọwọ́ rẹ̀,
    a tẹ́ wọn lọ́rùn pẹ̀lú ohun rere.
29 Nígbà tí ìwọ bá pa ojú rẹ mọ́
    ara kò rọ̀ wọ́n
nígbà tí ìwọ bá mú ẹ̀mí wọn lọ,
    wọn ó kú, wọn ó sì padà sí erùpẹ̀.
30 Nígbà tí ìwọ rán ẹ̀mí rẹ,
    ni a dá wọn,
    ìwọ sì tún ojú ayé ṣe.

31 Jẹ́ kí ògo Olúwa wà pẹ́ títí láé;
    kí inú Olúwa kí ó dùn ní ti iṣẹ́ rẹ̀
32 Ẹni tí ó wo ayé, tí ó sì wárìrì,
    ẹni tí ó fọwọ́ tọ́ àwọn òkè, tí wọ́n yọ èéfín.

33 Ní gbogbo ayé mi ní n ó kọrin sí Olúwa:
    èmi ó kọrin ìyìn sí Olúwa
níwọ̀n ìgbà tí mo wà láààyè.
34 Jẹ́ kí ẹ̀kọ́ mi kí ó tẹ́ ọ lọ́rùn
    bí mo ti ń yọ̀ nínú Olúwa.
35 Ṣùgbọ́n kí ẹlẹ́ṣẹ̀ kúrò láyé
    kí ènìyàn búburú má sì sí mọ́.

Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi.

Yin Olúwa.

Mika 5:1-4

Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Olùgbàlà láti Bẹtilẹhẹmu

Nísinsin yìí, kó àwọn ọ̀wọ́ ogun rẹ jọ,
    ìwọ ìlú ti o ni ọmọ-ogun,
nítorí ó ti fi gbógun dó tì wá.
    Wọn yóò fi ọ̀pá lu àwọn alákòóso Israẹli ní ẹ̀rẹ̀kẹ́.

“Ṣùgbọ́n ìwọ, Bẹtilẹhẹmu Efrata,
    bí ìwọ ti jẹ́ kékeré láàrín àwọn ẹ̀yà Juda,
nínú rẹ ni ẹni tí yóò jẹ́ olórí ní Israẹli
    yóò ti jáde tọ̀ mí wá,
ìjáde lọ rẹ̀ sì jẹ́ láti ìgbà àtijọ́,
    láti ìgbà láéláé.”

Nítorí náà Israẹli yóò di kíkọ̀sílẹ̀ pátápátá
    títí di àkókò tí ẹni tí ń rọbí yóò fi bí,
àti àwọn ìyókù arákùnrin rẹ̀ yóò fi padà
    láti darapọ̀ mọ́ àwọn Israẹli.

Òun yóò sì dúró,
    yóò sì máa ṣe olùṣọ́-àgùntàn àwọn agbo ẹran rẹ̀ ní agbára Olúwa,
    ní ọláńlá orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ̀.
Wọn yóò sì wà láìléwu,
    nítorí nísinsin yìí ni títóbi rẹ
    yóò sì dé òpin ayé.

Mika 5:10-15

10 “Ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí,

“Èmi yóò pa àwọn ẹṣin rẹ̀ run kúrò láàrín rẹ
    èmi yóò sì pa àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ run.
11 Èmi yóò sì pa ilẹ̀ ìlú ńlá rẹ̀ run,
    èmi ó sì fa gbogbo ibi gíga rẹ̀ ya.
12 Èmi yóò gé ìwà àjẹ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ̀,
    ìwọ kì yóò sì ní aláfọ̀ṣẹ mọ́.
13 Èmi yóò pa àwọn ère fínfín rẹ̀ run,
    àti ọwọ́n rẹ̀ kúrò láàrín rẹ̀;
ìwọ kì yóò sì le è foríbalẹ̀
    fún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ mọ́.
14 Èmi yóò fa ère Aṣerah tu kúrò láàrín rẹ̀,
    èmi yóò sì pa ìlú ńlá rẹ̀ run.
15 Èmi yóò gbẹ̀san ní ìbínú àti ìrunú
    lórí àwọn orílẹ̀-èdè tí kò ti tẹríba fún mi.”

Ìṣe àwọn Aposteli 25:13-27

Festu wádìí ọ̀rọ̀ níwájú ọba Agrippa

13 Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan, Agrippa ọba, àti Bernike sọ̀kalẹ̀ wá sì Kesarea láti kí Festu. 14 Bí wọ́n sì tí wà níbẹ̀ lọ́jọ́ púpọ̀, Festu mú ọ̀ràn Paulu wá síwájú ọba, wí pé, “Feliksi fi ọkùnrin kan sílẹ̀ nínú túbú. 15 Ẹni tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà àwọn Júù fi sùn nígbà tí mo wà ni Jerusalẹmu, wọ́n ń fẹ́ kí èmi ó dá a lẹ́bi ikú.

16 “Àwọn ẹni tí mo sì dá lóhùn pé, kì í ṣe àṣà àwọn ará Romu láti dá ẹnikẹ́ni lẹ́bi, kí ẹni tí a fi sùn náà tó ko àwọn olùfisùn rẹ̀ lójú, láti lè ri ààyè wí tí ẹnu rẹ̀, nítorí ọ̀ràn tí a kà sí i lọ́rùn, 17 Nítorí náà nígbà tí wọ́n jùmọ̀ wá sí ìhín yìí, èmi kò fi ọ̀rọ̀ náà falẹ̀ rara, níjọ́ kejì mo jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́, mo sì pàṣẹ pé kí a mú ọkùnrin náà wá. 18 Nígbà tí àwọn olùfisùn náà dìde, wọn kò ka ọ̀ràn búburú irú èyí tí mo rò sí i lọ́rùn. 19 Ṣùgbọ́n wọ́n ní ọ̀ràn kan sí i, ní ti ìsìn wọn, àti ní ti Jesu kan tí o tí kú, tí Paulu tẹnumọ́ pé ó wà láààyè. 20 Bí èmi kò sì tí mọ̀ bí a tí ń ṣe ìwádìí nǹkan wọ̀nyí, mo bí i lérè pé ṣe ó ń fẹ́ lọ sì Jerusalẹmu, kí a sì ṣe ẹjọ́ nǹkan wọ̀nyí níbẹ̀. 21 Ṣùgbọ́n nígbà tí Paulu fi ọ̀ràn rẹ lọ Augustu, pé kí a pa òun mọ́ fún ìdájọ́ rẹ̀, mo pàṣẹ pe kí a pa á mọ́ títí èmi o fi lè rán an lọ sọ́dọ̀ Kesari.”

22 Agrippa wí fún Festu pé, “Èmi pẹ̀lú fẹ́ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ọkùnrin náà tìkára mi,”

Ó sì wí pé, “Ní ọ̀la ìwọ ó gbọ́ ọ.”

Paulu níwájú Agrippa

23 Ní ọjọ́ kejì, tí Agrippa àti Bernike wọ ilé ẹjọ́ ti àwọn ti ẹ̀ṣọ́ púpọ̀ pẹ̀lú àwọn olórí ogun àti àwọn ènìyàn ńlá ní ìlú, Festu pàṣẹ, wọ́n sì mú Paulu jáde. 24 Festu sì wí pé, “Agrippa ọba, àti gbogbo ẹ̀yin ènìyàn tí ó wà níhìn-ín pẹ̀lú wa, ẹ̀yin rí ọkùnrin yìí, nítorí ẹni tí gbogbo ìjọ àwọn Júù tí fi ẹ̀bẹ̀ béèrè lọ́wọ́ mi ni Jerusalẹmu àti Kesarea níhìn-ín yìí, tí wọ́n ń kígbe pé, kò yẹ fún un láti wà láààyè mọ́. 25 Ṣùgbọ́n èmi rí i pe, kò ṣe ohun kan tí ó yẹ sí ikú, bí òun tìkára rẹ̀ sí tí fi ọ̀ràn rẹ̀ lọ Augustu, mo tí pinnu láti rán an lọ. 26 Ṣùgbọ́n èmi kò ri ohun kan dájúdájú láti kọ̀wé sí olúwa mi. Nítorí náà ni mo ṣe mú un jáde wá síwájú yín, àní síwájú rẹ ọba Agrippa, kí o fi jẹ́ pé lẹ́yìn tí a ba tí ṣe ìwádìí rẹ̀, èmi yóò lè rí ohun tí èmi yóò kọ. 27 Nítorí tí kò tọ́ ní ojú mi láti rán òǹdè, kí a má sì sọ ọ̀ràn tí a kà sí i lọ́rùn.”

Luku 8:16-25

Àtùpà lórí tábìlì

16 (A)“Kò sí ẹnikẹ́ni, nígbà tí ó bá tán fìtílà tan, tí yóò fi ohun èlò bò ó mọ́lẹ̀, tàbí tí yóò gbé e sábẹ́ àkéte; bí kò ṣe kí ó gbé e ka orí ọ̀pá fìtílà, kí àwọn tí ń wọ ilé lè rí ìmọ́lẹ̀. 17 (B)Nítorí kò sí ohun tí ó fi ara sin, tí a kì yóò fihàn, tàbí ohun tí a fi pamọ́, ti a kì yóò sì mọ̀ kí ó sì yọ sí gbangba. 18 (C)Ǹjẹ́ kí ẹ̀yin máa kíyèsára bí ẹ̀yin ti ń gbọ́: nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ní, lọ́wọ́ rẹ̀ ni a ó sì gba èyí tí ó ṣe bí òun ní.”

Àwọn ìyá àti arákùnrin Jesu

19 (D)Nígbà náà ní ìyá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọn kò sì lè súnmọ́ ọn nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn. 20 Wọ́n sì wí fún un pé, “Ìyá rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ dúró lóde, wọn fẹ́ rí ọ.”

21 (E)Ó sì dáhùn wí fún wọn pé, “Ìyá mi àti àwọn arákùnrin mi ni àwọn wọ̀nyí tí wọ́n ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń ṣe é.”

Jesu bá rírú omi okun wí

22 (F)Ní ọjọ́ kan, ó sì wọ ọkọ̀ ojú omi kan lọ òun pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. O sì wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí a rékọjá lọ sí ìhà kejì adágún.” Wọ́n sì ṣíkọ̀ láti lọ. 23 Bí wọ́n sì ti ń lọ, ó sùn; ìjì ńlá sì dé, ó ń fẹ́ lójú adágún; omi si wọ inú ọkọ, wọ́n sì wà nínú ewu.

24 (G)Wọ́n sì tọ̀ ọ́ wá wọ́n sì jí i, wí pé, “Olùkọ́, Olùkọ́, àwa yóò ṣègbé!”

Nígbà náà ni ó dìde, ó sì bá ìjì líle àti ríru omi wí; wọ́n sì dúró, ìdákẹ́rọ́rọ́ sì dé. 25 Ó sì wí fún wọn pé, “Ìgbàgbọ́ yín dà?”

Bí ẹ̀rù ti ń ba gbogbo wọn, tí hà sì ń ṣe wọ́n, wọ́n ń bi ara wọn pé, “Irú ọkùnrin wo ni èyí, nítorí ó bá ìjì líle àti ríru omi wí, wọ́n sì gbọ́ tirẹ̀?”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.