Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 146-147

146 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Fi ìyìn fún Olúwa, ìwọ ọkàn mi.

Èmi yóò yin Olúwa ní gbogbo ayé mi;
    Èmi yóò kọrin ìyìn sí Ọlọ́run, níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láààyè.
Ẹ má ṣe ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn ọmọ-aládé,
    àní, ọmọ ènìyàn,
    lọ́wọ́ ẹni tí kò sí ìrànlọ́wọ́.
Ẹ̀mí rẹ jáde lọ, ó padà sí erùpẹ̀:
    Ní ọjọ́ náà gan, èrò wọn yóò di òfo:
Ìbùkún ni fún ẹni tí
    Ọlọ́run Jakọbu ń ṣe ìrànlọ́wọ́ rẹ̀
    tí ìrètí rẹ̀ wà nínú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀.

Ẹni tí ó dá ọ̀run àti ayé,
    òkun àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn,
    ẹni tí ó pa òtítọ́ mọ́ títí ayé.
Ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ àwọn tí a ni lára
    tí ó fi oúnjẹ fún àwọn tí ebi ń pa
Olúwa, tú àwọn oǹdè sílẹ̀ (ẹlẹ́wọ̀n)
    Olúwa mú àwọn afọ́jú ríran,
Olúwa, gbé àwọn tí a rẹ̀ sílẹ̀ ga,
    Olúwa fẹ́ràn àwọn olódodo.
Olúwa ń dá ààbò bo àwọn àlejò
    ó sì ń dá àwọn aláìní baba àti opó sí
    ṣùgbọ́n ó ba ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú jẹ́.

10 Olúwa jẹ ọba títí láé;
    Ọlọ́run rẹ, ìwọ Sioni, àti fún gbogbo ìran.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
147 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Nítorí ohun rere ni láti máa kọrin ìyìn sí Ọlọ́run wa,
    ó yẹ láti kọrin ìyìn sí i!

Olúwa kọ́ Jerusalẹmu;
    Ó kó àwọn Israẹli tí a lé sọnù jọ.
Ó wo àwọn tí ọkàn wọ́n bàjẹ́ sàn
    ó sì di ọgbẹ́ wọ́n.
Ó ka iye àwọn ìràwọ̀
    ó sì pe ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní orúkọ
Títóbi ni Olúwa wa ó sì pọ̀ ní agbára
    òye rẹ̀ kò sì ní òpin.
Olúwa wa pẹ̀lú àwọn onírẹ̀lẹ̀
    bẹ́ẹ̀ ni ó rẹ̀ àwọn ènìyàn búburú sílẹ̀.

Fi ọpẹ́ kọrin sí Olúwa
    fi ohun èlò orin olókùn yin Ọlọ́run.

Ó fi ìkùùkuu bo àwọ̀ sánmọ̀
    ó rọ òjò sí orílẹ̀ ayé
    ó mú kí koríko hù lórí àwọn òkè
Ó pèsè oúnjẹ fún àwọn ẹranko
    àti fún àwọn ọmọ ẹyẹ ìwò ní ìgbà tí wọ́n bá ń ké.

10 Òun kò ní inú dídùn nínú agbára ẹṣin
    bẹ́ẹ̀ ni Òun kò ní ayọ̀ sí ẹ̀ṣẹ̀ ọkùnrin
11 Olúwa ni ayọ̀ nínú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
    sí àwọn tí ó ní ìrètí nínú àánú rẹ̀.

12 Yin Olúwa, ìwọ Jerusalẹmu
    yin Ọlọ́run rẹ, ìwọ Sioni.

13 Nítorí tí ó ti mú ọ̀pá ìdábùú ibodè rẹ̀ lágbára;
    Òun sì ti bùkún fún àwọn ọmọ rẹ̀ nínú rẹ
14 Òun jẹ́ kí àlàáfíà wà ní àwọn ẹnu ibodè rẹ̀
    òun sì fi jéró dáradára tẹ́ ọ lọ́rùn.

15 Òun sì rán àṣẹ rẹ̀ sí ayé
    ọ̀rọ̀ rẹ̀ sáré tete.
16 Ó fi yìnyín fún ni bi irun àgùntàn
    ó sì fọ́n ìrì dídì ká bí eérú
17 Ó rọ òjò yìnyín rẹ̀ bí òkúta wẹ́wẹ́
    ta ni ó lè dúró níwájú òtútù rẹ̀
18 Ó rán ọ̀rọ̀ rẹ̀ jáde ó sì mú wọn yọ̀
    ó mú kí afẹ́fẹ́ rẹ̀ fẹ́
    ó sì mú odò rẹ̀ sàn.

19 Ó sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ di mí mọ̀ fún Jakọbu
    àwọn òfin àti ìlànà rẹ̀ fún Israẹli
20 Òun kó tí ṣe irú èyí sí orílẹ̀-èdè kan rí, Bí ó ṣe ti ìdájọ́ rẹ̀
    wọn ko mọ òfin rẹ̀.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Saamu 111-113

111 Ẹ máa yin Olúwa.

Èmi yóò máa yin Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi,
    ní àwùjọ àwọn olóòtítọ́, àti ní ìjọ ènìyàn.

Iṣẹ́ Olúwa tóbi, àwọn tí ó ní inú dídùn, ń ṣe àṣàrò nínú rẹ̀.
Iṣẹ́ rẹ̀ ni ọláńlá àti ògo:
    àti òdodo rẹ̀ dúró láéláé.
Ó ti ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, láti máa rántí:
    Olúwa ni olóore-ọ̀fẹ́ àti pé ó kún fún àánú.
Ó ti fi oúnjẹ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀:
    òun ń rántí májẹ̀mú rẹ̀.

Ó ti fihan àwọn ènìyàn rẹ̀ agbára iṣẹ́ rẹ̀
    láti fún wọn ní ilẹ̀ ìlérí ní ìní
Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ jẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́;
    gbogbo òfin rẹ̀ sì dájú.
Wọ́n dúró láé àti láé,
    ní òtítọ́ àti òdodo ni a ṣe wọ́n.
Ó rán ìràpadà sí àwọn ènìyàn rẹ̀:
    ó pàṣẹ májẹ̀mú rẹ̀ títí láé:
    Mímọ́ àti ọ̀wọ̀ ni orúkọ rẹ̀.

10 Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọgbọ́n:
    òye dáradára ni yóò máa ṣe òfin rẹ̀,
    ìyìn rẹ̀ dúró láé.
112 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run,
    tí ó ní inú dídùn ńlá sí àwọn òfin rẹ̀.

Irú-ọmọ rẹ̀ yóò jẹ́ alágbára ní ayé:
    ìran àwọn olóòtítọ́ ni a ó bùkún fún.
Ọlá àti ọrọ̀ yóò wà nínú ilé rẹ̀;
    òdodo rẹ̀ sì dúró láé.
Fún olóòótọ́ ni ìmọ́lẹ̀ yóò tàn fún ní òkùnkùn:
    olóore-ọ̀fẹ́ àti aláàánú àti òdodo.
Ènìyàn rere fi ojúrere hàn,
    a sì wínni;
    ìmòye ni yóò máa fi la ọ̀nà iṣẹ́ rẹ̀.

Dájúdájú a kì yóò le yí ní ipò padà láéláé:
    olódodo ni a ó máa ṣe ìrántí rẹ láéláé.
Òun kì yóò béèrè ìyìn búburú:
    ọkàn rẹ̀ ti dúró, ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa.
Ó ti mú ọkàn rẹ̀ gbilẹ̀, ẹ̀rù kí yóò bà á,
    títí yóò fi rí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀.
(A)Ó ti pín ká, ó ti fi fún àwọn olùpọ́njú;
    Nítorí òdodo rẹ̀ dúró láé;
    ìwo rẹ̀ ní a ó gbé sókè pẹ̀lú ọlá.

10 Ènìyàn búburú yóò ri, inú wọn yóò sì bàjẹ́,
    yóò sì pa eyín keke, yó sì yọ dànù:
    èròǹgbà ọkàn ènìyàn búburú ni yóò ṣègbé.
113 Ẹ máa yin Olúwa.

Yìn ín ẹ̀yin ìránṣẹ́ Olúwa,
ẹ yin orúkọ Olúwa.
Fi ìbùkún fún orúkọ Olúwa láti
    ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.
Láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀
    orúkọ Olúwa ni kí a máa yìn.

Olúwa ga lórí gbogbo orílẹ̀-èdè,
    àti ògo rẹ̀ lórí àwọn ọ̀run.
Ta ló dàbí Olúwa Ọlọ́run wa,
    tí ó gbé ní ibi gíga.
Tí ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ láti wò
    òun tí ó ń bẹ lọ́run, àti nínú ayé!

Ó gbé òtòṣì dìde láti inú erùpẹ̀, àti pé
    ó gbé aláìní sókè láti inú ààtàn wá.
Kí ó le mú un jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé
    àní pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé àwọn ènìyàn rẹ̀.
Ó mú àgàn obìnrin gbé inú ilé,
    àti láti jẹ́ aláyọ̀ ìyá fún àwọn ọmọ rẹ̀.

Ẹ yin Olúwa.

Mika 6:1-8

Ọlọ́run pe Israẹli níjà

Ẹ fi etí sí ohun tí Olúwa wí:

“Dìde dúró, bẹ ẹ̀bẹ̀ fún ẹjọ́ rẹ níwájú òkè ńlá;
    sì jẹ́ kí àwọn òkè kéékèèkéé gbọ́ ohun tí ó fẹ́ wí.

“Gbọ́, ìwọ òkè ńlá, ẹ̀sùn Olúwa;
    gbọ́, ìwọ ìpìlẹ̀ ilé ayérayé.
Nítorí Olúwa ń bá àwọn ènìyàn rẹ̀ wíjọ́;
    òun yóò sì bá Israẹli rojọ́.

“Ẹ̀yin ènìyàn mi, kí ni mo ṣe fún yín?
    Àti nínú kí ni mo ti dá yin lágara? Dá mi lóhùn.
Nítorí èmi mú un yín gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti wá,
    mo sì rà yín padà láti ilẹ̀ ẹrú wá.
Mo rán Mose láti darí yín,
    bákan náà mo rán Aaroni àti Miriamu síwájú rẹ̀.
Ìwọ ènìyàn mi,
    rántí ohun tí Balaki ọba Moabu gbèrò
    àti ohun tí Balaamu ọmọ Beori dáhùn.
Rántí ìrìnàjò rẹ̀ láti Ṣittimu dé Gilgali,
    kí ìwọ ba le mọ òdodo Olúwa.”

Kí ni èmi yóò ha mú wá síwájú Olúwa
    tí èmi ó fi tẹ ara mi ba níwájú Ọlọ́run gíga?
Kí èmi ha wá sí iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun,
    pẹ̀lú ọmọ màlúù ọlọ́dún kan?
Ǹjẹ́ Olúwa yóò ní inú dídùn sí ẹgbẹgbàarùn-ún àgbò,
    tàbí sí ẹgbẹgbàarùn-ún ìṣàn òróró?
Èmi yóò ha fi àkọ́bí mi sílẹ̀ fún ìré-òfin-kọjá mi,
    èso inú ara mi fún ẹ̀ṣẹ̀ ọkàn mi?
Ó ti fihàn ọ́, ìwọ ènìyàn, ohun tí ó dára,
    àti ohun tí Olúwa ń béèrè lọ́wọ́ rẹ?
Bí kò ṣe láti ṣe òtítọ́, kí o sì fẹ́ràn àánú,
    àti kí o rìn ní ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run rẹ̀.

1 Kọrinti 4:9-16

(A)Nítorí mo rò pé Ọlọ́run ń fi àwa aposteli hàn ní ìkẹyìn bí ẹni tí a dá lẹ́bi ikú bí àwọn, nítorí tí a fi wá ṣe ìran wò fún àwọn ènìyàn àti àwọn angẹli àti gbogbo ayé. 10 (B)Àwa jẹ́ aṣiwèrè nítorí Kristi, ṣùgbọ́n ẹ̀yin jẹ́ ọlọ́gbọ́n nínú Kristi! Àwa jẹ́ aláìlera, ṣùgbọ́n ẹ̀yin jẹ́ alágbára! Ẹ̀yin jẹ́ ẹni àyẹ́sí, àwa jẹ ẹni ẹ̀gàn! 11 (C)Títí di wákàtí yìí ni a ń rìn kiri nínú ebi àti òǹgbẹ, a n wọ aṣọ àkísà, tí a sì ń lù wa, tí a kò sì ní ibùgbé kan. 12 (D)Tí a ń fi ọwọ́ ara wa ṣiṣẹ́, wọn ń gàn wa, àwa ń súre, wọn ń ṣe inúnibíni sí wa, àwa ń forítì i. 13 Wọn ń kẹ́gàn wa, àwa ń bẹ̀bẹ̀. Títí di ìsinsin yìí ni a ti wà bí ohun ẹ̀gbin ayé, bí orí àkìtàn gbogbo ayé.

14 Èmi kò kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí láti fi dójútì yín, ṣùgbọ́n láti kìlọ̀ fún un yín bí àwọn ọmọ mi tí mo yàn fẹ́. 15 (E)Nítorí bí ẹ̀yin tilẹ̀ ní ẹgbàárùn-ún olùkọ́ni nínú Kristi, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò ni baba púpọ̀; nítorí nínú Kristi Jesu ni mo jẹ́ baba fún un yín nípasẹ̀ ìhìnrere. 16 Nítorí náà mo bẹ̀ yín, ẹ máa ṣe àfarawé mi.

Matiu 15:21-28

21 (A)Jesu sì ti ibẹ̀ kúrò lọ sí Tire àti Sidoni. 22 Obìnrin kan láti Kenaani, tí ó ń gbé ibẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ó ń bẹ̀bẹ̀, ó sì kígbe pé, “Olúwa, ọmọ Dafidi, ṣàánú fún mi; ọmọbìnrin mi ní ẹ̀mí èṣù ti ń dá a lóró gidigidi.”

23 Ṣùgbọ́n Jesu kò fún un ní ìdáhùn, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì gbà á níyànjú pé, “Lé obìnrin náà lọ, nítorí ó ń kígbe tọ̀ wá lẹ́yìn.”

24 (B)Ó dáhùn pé, “Àgùntàn ilẹ̀ Israẹli tí ó nù nìkan ni a rán mi sí.”

25 (C)Obìnrin náà wá, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó bẹ̀bẹ̀ sí i pé, “Olúwa ṣàánú fún mi.”

26 Ó sì dáhùn wí pé, “Kò tọ́ kí a gbé oúnjẹ àwọn ọmọ fún àwọn ajá.”

27 Obìnrin náà sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, síbẹ̀síbẹ̀ àwọn ajá a máa jẹ èrúnrún tí ó ti orí tábìlì olówó wọn bọ́ sílẹ̀.”

28 (D)Jesu sì sọ fún obìnrin náà pé, “Ìgbàgbọ́ ńlá ni tìrẹ! A sì ti dáhùn ìbéèrè rẹ.” A sì mú ọmọbìnrin rẹ̀ láradá ní wákàtí kan náà.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.