Book of Common Prayer
Ti Dafidi.
25 Olúwa,
ìwọ ni mo gbé ọkàn mi sókè sí.
2 Ọlọ́run, èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ;
Má ṣe jẹ́ kí ojú ó tì mí
Má ṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi ó yọ̀ mí.
3 Ẹni tí ó dúró tì ọ́
ojú kì yóò tì í,
àwọn tí ń ṣẹ̀ láìnídìí
ni kí ojú kí ó tì.
4 Fi ọ̀nà rẹ hàn mí, Olúwa,
kọ mi ní ipa tìrẹ;
5 ṣe amọ̀nà mi nínú òtítọ́ ọ̀ rẹ, kí o sì kọ́ mi,
Nítorí ìwọ ni Ọlọ́run ìgbàlà mi;
ìwọ ni mo dúró tì ní gbogbo ọjọ́.
6 Rántí, Olúwa àánú àti ìfẹ́ ẹ̀ rẹ̀ ńlá,
torí pé wọ́n ti wà ní ìgbà àtijọ́
7 Má ṣe rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ìgbà èwe mi
tàbí ìrékọjá mi;
gẹ́gẹ́ bí i ìfẹ́ ẹ rẹ̀ rántí mi
nítorí tí ìwọ dára, Ìwọ! Olúwa.
8 Rere àti ẹni ìdúró ṣinṣin ní Olúwa:
nítorí náà, ó kọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ọ̀nà náà.
9 Ó ṣe amọ̀nà àwọn onírẹ̀lẹ̀ ni ohun tí ó dára,
ó sì kọ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀ ní ọ̀nà rẹ̀.
10 Gbogbo ipa ọ̀nà Olúwa ni ìfẹ́ àti òdodo tí ó dúró ṣinṣin,
fún àwọn tí ó pa májẹ̀mú àti ẹ̀rí rẹ̀ mọ́.
11 Nítorí orúkọ rẹ, Olúwa,
dárí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí, nítorí tí ó tóbi.
12 Àwọn wo ni ó bẹ̀rù Olúwa?
Yóò kọ́ wọn ní ọ̀nà èyí tí wọn yóò yàn.
13 Wọn yóò lo ọjọ́ wọn nínú àlàáfíà,
àwọn ọmọ wọn yóò sì gba ilẹ̀ náà.
14 Olúwa fi ọkàn tán, àwọn tí o bẹ̀rù u rẹ̀;
ó sọ májẹ̀mú rẹ̀ di mí mọ̀ fún wọn.
15 Ojú mi gbé sókè sọ́dọ̀ Olúwa,
nítorí pé yóò yọ ẹsẹ̀ mi kúrò nínú àwọ̀n náà.
16 Yípadà sí mi, kí o sì ṣe oore fún mi;
nítorí pé mo nìkan wà, mo sì di olùpọ́njú.
17 Tì mí lẹ́yìn kúrò nínú ìpọ́njú àyà mi;
kí o sì fà mí yọ kúrò nínú ìpọ́njú mi.
18 Kíyèsi ìjìyà àti wàhálà mi,
kí o sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi jì.
19 Kíyèsi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀tá mi,
tí wọn kórìíra mi pẹ̀lú ìwà ìkà wọn.
20 Pa ọkàn mi mọ́, kí o sì gbà mí sílẹ̀;
Má ṣe jẹ́ kí a fi mí sínú ìtìjú,
nítorí pé ìwọ ni ibi ìsádi mi.
21 Jẹ́ kí òtítọ́ inú àti ìdúró ṣinṣin kí ó pa mí mọ́;
nítorí pé mo dúró tì ọ́.
22 Ra Israẹli padà, Ìwọ Ọlọ́run,
nínú gbogbo ìṣòro rẹ̀!
Fún adarí orin. Ní ti ohun orin “Ní ti ikú ọmọ.” Saamu ti Dafidi.
9 Èmi ó yìn ọ́, Olúwa, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi;
Èmi ó sọ ti ìyanu rẹ gbogbo.
2 Inú mi yóò dùn, èmi yóò sì yọ̀ nínú rẹ;
Èmi ó kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ, Ìwọ Ọ̀gá-Ògo jùlọ.
3 Àwọn ọ̀tá mi pẹ̀yìndà;
Wọ́n kọsẹ̀ wọn sì ṣègbé níwájú rẹ.
4 Nítorí ìwọ ti di òtítọ́ àti ọ̀ràn mi mú;
ìwọ ti jókòó lórí ìtẹ́ rẹ, láti ṣe ìdájọ́ òdodo.
5 Ìwọ ti bá orílẹ̀-èdè wí, Ìwọ sì ti pa ẹni búburú run;
Ìwọ ti yọ orúkọ wọn kúrò láé àti láéláé.
6 Ìparun àìlópin ti borí àwọn ọ̀tá,
Ìwọ ti fa àwọn ìlú wọn tu;
àní ìrántí wọn sì ti ṣègbé.
7 Olúwa jẹ ọba títí láé;
ó ti gbé ìtẹ́ rẹ̀ kalẹ̀ fún ìdájọ́.
8 (A)Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ ayé ní òdodo;
yóò ṣe àkóso ènìyàn pẹ̀lú òdodo.
9 Olúwa ni ààbò fún àwọn tí a ni lára,
ibi ìsádi ní àkókò ìpọ́njú.
10 Àwọn tí ó mọ orúkọ rẹ yóò gbẹ́kẹ̀lé ọ,
nítorí, Olúwa, kò kọ àwọn tó ń wá a sílẹ̀.
11 Kọ orin ìyìn sí Olúwa, tí o ń jẹ ọba ní Sioni;
kéde láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ohun tí ó ṣe.
12 Nítorí ẹni tí ó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ rántí;
òun kò kọ ẹkún àwọn tí a pọ́n lójú.
13 Olúwa, wo bí àwọn ọ̀tá ṣe ń ṣe inúnibíni sí mi!
Ṣàánú, kí o sì gbé mí sókè kúrò ní ẹnu-ọ̀nà ikú,
14 Kí èmi kí ó lè sọ ti ìyìn rẹ
ni ẹnu-ọ̀nà àwọn ọmọbìnrin Sioni
àti láti máa yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ.
15 Àwọn orílẹ̀-èdè ti jì sí kòtò tí wọn ti gbẹ́;
ẹsẹ̀ wọn ni àwọ̀n tí wọ́n dẹ sílẹ̀ kọ́.
16 A mọ Olúwa nípa òdodo rẹ̀;
àwọn ènìyàn búburú ni a dẹ́kun mú nípa iṣẹ́ ọwọ́ wọn.
17 Àwọn ènìyàn búburú ni a ó dà sí isà òkú,
àti gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó gbàgbé Ọlọ́run.
18 Ṣùgbọ́n àwọn aláìní ni a kò ní gbàgbé láéláé,
ìrètí àwọn ti ó tálákà ni a kì yóò gbàgbé láéláé.
19 Dìde, Olúwa, má ṣe jẹ́ kí ènìyàn borí;
Jẹ́ kí a ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè ni iwájú rẹ.
20 Lù wọ́n pẹ̀lú ìpayà, Olúwa;
jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè mọ̀ pé ènìyàn lásán ni wọ́n. Sela.
Saamu ti Dafidi
15 Olúwa, ta ni yóò máa ṣe àtìpó nínú àgọ́ rẹ?
Ta ni yóò máa gbé ní òkè mímọ́ rẹ?
2 Ẹni tí ń rìn déédé
tí ó sì ń sọ òtítọ́,
láti inú ọkàn rẹ̀;
3 tí kò fi ahọ́n rẹ̀ sọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn,
tí kò ṣe ibi sí aládùúgbò rẹ̀
tí kò sì sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí ẹnìkejì rẹ̀,
4 ní ojú ẹni tí ènìyànkénìyàn di gígàn
ṣùgbọ́n ó bọ̀wọ̀ fún àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa,
Ẹni tí ó búra sí ibi ara rẹ̀
àní tí kò sì yípadà,
5 tí ó ń yá ni lówó láìsí èlé
tí kò sì gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lòdì sí aláìlẹ́ṣẹ̀.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe èyí
ni a kì yóò mì láéláé.
Ọ̀kẹ́ méje-olé-ẹgbàá-méjì èdìdì ìwé
7 (A)Lẹ́yìn èyí ni mo rí angẹli mẹ́rin dúró ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé, wọ́n di afẹ́fẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé mú, kí ó má ṣe fẹ́ sórí ilẹ̀, tàbí sórí Òkun, tàbí sára igikígi. 2 Mo sì rí angẹli mìíràn tí ó ń ti ìhà ìlà-oòrùn gòkè wá, ti òun ti èdìdì Ọlọ́run alààyè lọ́wọ́ rẹ. Ó sì kígbe ní ohùn rara sí àwọn angẹli mẹ́rin náà tí a fi fún un láti pa ayé, àti Òkun, lára, 3 (B)wí pé, “Ẹ má ṣe pa ayé, tàbí Òkun, tàbí igi lára, títí àwa ó fi fi èdìdì sàmì sí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run wa ní iwájú wọn.” 4 Mo sì gbọ́ iye àwọn tí a fi èdìdì sàmì si: Àwọn tí a sàmì sí jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó-lé-ẹgbàajì láti inú gbogbo ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli wá.
5 Láti inú ẹ̀yà Juda a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá-mẹ́fà (12,000).
Láti inú ẹ̀yà Reubeni a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá-mẹ́fà (12,000).
Láti inú ẹ̀yà Gadi a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá-mẹ́fà (12,000).
6 Láti inú ẹ̀yà Aṣeri a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá-mẹ́fà (12,000).
Láti inú ẹ̀yà Naftali a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá-mẹ́fà (12,000).
Láti inú ẹ̀yà Manase a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá-mẹ́fà (12,000).
7 Láti inú ẹ̀yà Simeoni a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá-mẹ́fà (12,000).
Láti inú ẹ̀yà Lefi a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá-mẹ́fà (12,000).
Láti inú ẹ̀yà Isakari a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá-mẹ́fà (12,000).
8 Láti inú ẹ̀yà Sebuluni, a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá-mẹ́fà (12,000).
Láti inú ẹ̀yà Josẹfu a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá-mẹ́fà (12,000).
Láti inú ẹ̀yà Benjamini a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá-mẹ́fà (12,000).
Ìtakò àwọn ará Samaria
51 (A)Nígbà tí ọjọ́ àti gbà á sókè ń súnmọ́, ó pinnu láti lọ sí Jerusalẹmu. 52 (B)Ó sì rán àwọn ìránṣẹ́ lọ sí iwájú rẹ̀. Nígbà tí wọ́n sì lọ wọ́n wọ ìletò kan tí í ṣe ti ará Samaria láti pèsè sílẹ̀ dè é. 53 Wọn kò sì gbà á, nítorí pé ó ń lọ sí Jerusalẹmu. 54 (C)Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ Jakọbu àti Johanu sì rí i, wọ́n ní, “Olúwa wa, jẹ́ kí a pe iná láti ọ̀run wá, kí a sì pa wọ́n run, bí Elijah ti ṣe?” 55 Ṣùgbọ́n Jesu yípadà, ó sì bá wọn wí, ó ní, ẹ̀yin kò mọ irú ẹ̀mí tí ń bẹ nínú yín 56 Nítorí ọmọ ènìyàn kò wá láti pa ẹ̀mí ènìyàn run, bí kò ṣe láti gbà á là. Wọ́n sì lọ sí ìletò mìíràn.
Ìpinnu láti tọ Jesu lẹ́yìn
57 (D)Bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà, ọkùnrin kan wí fún un pé, “Olúwa, Èmi ń fẹ́ láti máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn ní ibikíbi tí ìwọ bá ń lọ.”
58 Jesu sì wí fún un pé, “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ní ìtẹ́; ṣùgbọ́n ọmọ ènìyàn kò ní ibi tí yóò fi orí rẹ̀ lé.”
59 Ó sì wí fún ẹlòmíràn pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”
Ṣùgbọ́n èyí wí fún un pé, “Olúwa, jẹ́ kí èmi lọ sìnkú baba mi ná.”
60 Jesu sì wí fún un pé, “Jẹ́ kí àwọn òkú máa sìnkú ara wọn: ṣùgbọ́n ìwọ lọ kí o sì máa wàásù ìjọba Ọlọ́run.”
61 (E)Ẹlòmíràn sì wí fún un pé, “Olúwa, èmi yóò tọ̀ ọ́ lẹ́yìn ṣùgbọ́n jẹ́ kí n kọ́kọ́ lọ dágbére fún àwọn ará ilé mi.”
62 Jesu sì wí fún un pé, “Kò sí ẹni, tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ lé ohun èlò ìtulẹ̀, tí ó sì wo ẹ̀yìn, tí ó yẹ fún ìjọba Ọlọ́run.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.