Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Ìránṣẹ́ Olúwa náà
42 (A)“Ìránṣẹ́ mi nìyìí, ẹni tí mo gbéró,
àyànfẹ́ mi nínú ẹni tí mo láyọ̀;
Èmi yóò fi Ẹ̀mí mi sínú rẹ̀
òun yóò sì mú ìdájọ́ wá sórí àwọn orílẹ̀-èdè.
2 Òun kì yóò pariwo tàbí kígbe sókè,
tàbí kí ó gbóhùn rẹ̀ sókè ní òpópónà.
3 Koríko odò títẹ̀ kan ni òun kì yóò fọ́,
àti òwú-fìtílà tí ń jó tan an lọ lòun kì yóò fẹ́ pa.
Ní òdodo ni yóò mú ìdájọ́ wá;
4 òun kì yóò kọsẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni kò ní rẹ̀wẹ̀sì
títí tí yóò fi fi ìdájọ́ múlẹ̀ ní ayé.
Nínú òfin rẹ̀ ni àwọn erékùṣù yóò fi ìrètí wọn sí.”
5 (B)Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run wí
Ẹni tí ó dá àwọn ọ̀run tí ó sì tẹ́ wọ́n sóde,
tí ó tẹ́ ilẹ̀ ayé àti ohun gbogbo tí ó jáde nínú wọn,
Ẹni tí ó fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní èémí
àti ẹ̀mí fún gbogbo àwọn tí ń rìn nínú rẹ̀:
6 (C)“Èmi, Olúwa, ti pè ọ́ ní òdodo;
Èmi yóò di ọwọ́ rẹ mú.
Èmi yóò pa ọ́ mọ́, n ó sì ṣe ọ́
láti jẹ́ májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn
àti ìmọ́lẹ̀ fún àwọn aláìkọlà
7 (D)láti la àwọn ojú tí ó fọ́,
láti tú àwọn òǹdè kúrò nínú túbú
àti láti tú sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀wọ̀n
àwọn tí ó jókòó nínú òkùnkùn.
8 “Èmi ni Olúwa; orúkọ mi nìyìí!
Èmi kì yóò fi ògo mi fún ẹlòmíràn
tàbí ìyìn mi fún ère òrìṣà.
9 Kíyèsi i, àwọn nǹkan àtijọ́ ti wáyé,
àti àwọn nǹkan tuntun ni mo ti wí pé;
kí wọn tó hù jáde
mo ti kéde rẹ̀ fún ọ.”
5 Ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ, ìwọ Olúwa, ó ga dé ọ̀run,
òtítọ́ ọ̀ rẹ ga dé àwọsánmọ̀.
6 Òdodo rẹ dàbí àwọn òkè Ọlọ́run,
àwọn ìdájọ́ rẹ dàbí ibú ńlá;
ìwọ gba ẹranko àti ènìyàn là, Olúwa.
7 Báwo ni ìṣeun ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ ti tó! Ọlọ́run!
Kí gbogbo ọmọ ènìyàn le sá sí abẹ́ òjìji ìyẹ́ rẹ.
8 Àsè ilé rẹ yóò tẹ́ wọn lọ́rùn gidigidi;
ìwọ yóò sì mú wọn mu nínú odò inú dídùn rẹ.
9 Nítorí pé pẹ̀lú rẹ ni orísun ìyè wà:
nínú ìmọ́lẹ̀ rẹ ni àwa yóò rí ìmọ́lẹ̀.
10 Mú ìṣeun ìfẹ́ ẹ̀ rẹ sí àwọn tí ó mọ̀ ọ́n
àti ìgbàlà rẹ sí àwọn tí ó ní ìdúró ṣinṣin ọkàn!
11 Má ṣe jẹ́ kí ẹsẹ̀ agbéraga kí ó wá sí orí mi,
kí o má sì jẹ́ kí ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú sí mi ní ipò.
Ẹ̀jẹ̀ ti Kristi
11 Ṣùgbọ́n nígbà tí Kristi dé bí olórí àlùfáà àwọn ohun rere tí ń bọ̀, nípasẹ̀ àgọ́ tí o tóbi ti ó sì pé ju ti ìṣáájú, (èyí tí a kò fi ọwọ́ dá, èyí yìí ni, tí kì í ṣe ti ẹ̀dá yìí), 12 Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ àti ọmọ màlúù, ṣùgbọ́n nípa ẹ̀jẹ̀ òun tìkára rẹ̀, o wọ ibi mímọ́ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, lẹ́yìn tí ó ti rí ìdáǹdè àìnípẹ̀kun gbà fún wa. 13 (A)Nítorí bí ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ àti ti akọ màlúù àti eérú ẹgbọrọ abo màlúù tí a fi wọ́n àwọn tí a ti sọ di aláìmọ́ ba ń sọ ni di mímọ́ fún ìwẹ̀nùmọ́ ara: 14 mélòó mélòó ni ẹ̀jẹ̀ Kristi, ẹni, nípa Ẹ̀mí ayérayé, tí ó fi ara rẹ̀ rú ẹbọ sí Ọlọ́run láìní àbàwọ́n, yóò wẹ èérí ọkàn yín nù kúrò nínú òkú iṣẹ́ láti sin Ọlọ́run alààyè?
15 Àti nítorí èyí ni ó ṣe jẹ́ alárinà májẹ̀mú tuntun pé bí ikú ti ń bẹ fún ìdáǹdè àwọn ìrékọjá ti o tí wà lábẹ́ májẹ̀mú ìṣáájú, kí àwọn tí a ti pè lè rí ìlérí ogún àìnípẹ̀kun gbà.
A fi ààmì òróró yàn Jesu ni Betani
12 (A)Nítorí náà, nígbà tí àjọ ìrékọjá ku ọjọ́ mẹ́fà, Jesu wá sí Betani, níbi tí Lasaru wà, ẹni tí ó ti kú, tí Jesu jí dìde kúrò nínú òkú. 2 Wọ́n sì ṣe àsè alẹ́ fún un níbẹ̀: Marta sì ń ṣe ìránṣẹ́: ṣùgbọ́n Lasaru Jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí ó jókòó níbi tábìlì rẹ̀. 3 Nígbà náà ni Maria mú òróró ìkunra nadi, òṣùwọ̀n lítà kan, àìlábùlà, olówó iyebíye, ó sì ń fi kun Jesu ní ẹsẹ̀, ó sì ń fi irun orí rẹ̀ nu ẹsẹ̀ rẹ̀ nù. Ilé sì kún fún òórùn ìkunra náà.
4 (B)Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Judasi Iskariotu, ọmọ Simoni ẹni tí yóò fi í hàn, wí pé, 5 “Èéṣe tí a kò ta òróró ìkunra yìí ní ọ̀ọ́dúnrún owó idẹ kí a sì fi fún àwọn tálákà?” 6 (C)Ṣùgbọ́n ó wí èyí, kì í ṣe nítorí tí ó náání àwọn tálákà; ṣùgbọ́n nítorí tí ó jẹ́ olè, òun ni ó ni àpò, a sì máa jí ohun tí a fi sínú rẹ̀ láti fi ran ara rẹ lọ́wọ́.
7 (D)Nígbà náà ni Jesu wí pé, “Ẹ fi í sílẹ̀, ó ṣe é sílẹ̀ de ọjọ́ ìsìnkú mi. 8 Nígbà gbogbo ni ẹ̀yin sá à ní tálákà pẹ̀lú yín; ṣùgbọ́n èmi ni ẹ kò ní nígbà gbogbo.”
9 Nítorí náà, ìjọ ènìyàn nínú àwọn Júù ni ó mọ̀ pé ó wà níbẹ̀; wọ́n sì wá, kì í ṣe nítorí Jesu nìkan, ṣùgbọ́n kí wọn lè rí Lasaru pẹ̀lú, ẹni tí ó ti jí dìde kúrò nínú òkú. 10 (E)Ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà gbìmọ̀ kí wọn lè pa Lasaru pẹ̀lú; 11 Nítorí pé nípasẹ̀ rẹ̀ ni ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù jáde lọ, wọ́n sì gbà Jesu gbọ́.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.