Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Fún adarí orin. Tí ohùn “Má ṣe parun.” Saamu ti Asafu. Orin.
75 A fi ìyìn fún ọ, Ọlọ́run,
a yìn ọ́, nítorí orúkọ rẹ súnmọ́ tòsí;
àwọn ènìyàn ń sọ ti ìyanu rẹ.
2 Ìwọ wí pé, “Mo yan àkókò ìyàsọ́tọ̀;
Èmi ni ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ òdodo.
3 Nígbà tí ayé àti àwọn ènìyàn ibẹ̀ wárìrì,
Èmi ni mo di òpó rẹ̀ mú ṣinṣin.
4 Èmí wí fún àwọn agbéraga pé
Ẹ má ṣe gbéraga mọ́;
àti sí ènìyàn búburú;
Ẹ má ṣe gbé ìwo yín sókè.
5 Ẹ má ṣe gbe ìwo yín sókè sí ọ̀run;
ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọrùn líle.”
6 Nítorí ìgbéga kò ti ìlà-oòrùn wá
tàbí ní ìwọ̀-oòrùn,
bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe láti gúúsù wá.
7 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni olùdájọ́;
Ó ń rẹ ẹnìkan sílẹ̀, ó sì ń gbé ẹlòmíràn ga.
8 Ní ọwọ́ Olúwa ni ago kan wà,
ọtí wáìnì náà sì pọ́n, ó kún fún àdàlú,
ó fún ọtí àdàlú tí a pò mọ́ òórùn dídùn tí ó tú jáde,
àwọn ènìyàn búburú ayé gbogbo mú u pátápátá.
9 Ṣùgbọ́n èmi, ó máa ròyìn rẹ títí láé;
Èmi ó kọrin ìyìn sí Ọlọ́run Jakọbu.
10 Èmi ó gé ìwo gbogbo ènìyàn búburú,
Ṣùgbọ́n ìwo àwọn olódodo ni a ó gbéga.
12 “Èmi kì yóò fi ẹ̀yà ara Lefitani,
tàbí ipá rẹ, tàbí ìhámọ́ra rẹ tí ó ní ẹwà pamọ́.
13 Ta ni yóò lè rídìí aṣọ àpáta rẹ̀?
Tàbí ta ni ó lè súnmọ́ ọ̀nà méjì eyín rẹ̀?
14 Ta ni ó lè ṣí ìlẹ̀kùn iwájú rẹ̀?
Àyíká ẹ̀yin rẹ ni ìbẹ̀rù ńlá.
15 Ìpẹ́ lílé ní ìgbéraga rẹ̀;
ó pàdé pọ̀ tímọ́tímọ́ bí ààmì èdìdì.
16 Èkínní fi ara mọ́ èkejì tó bẹ́ẹ̀
tí afẹ́fẹ́ kò lè wọ àárín wọn.
17 Èkínní fi ara mọ́ èkejì rẹ̀;
wọ́n lè wọ́n pọ̀ tí a kò lè mọ̀ wọ́n.
18 Nípa sí sin rẹ̀ ìmọ́lẹ̀ á mọ́,
ojú rẹ̀ a sì dàbí ìpéǹpéjú òwúrọ̀.
19 Láti ẹnu rẹ ni ọ̀wọ́-iná ti jáde wá,
ìpẹ́pẹ́ iná a sì ta jáde.
20 Láti ihò imú rẹ ni èéfín ti jáde wá,
bí ẹni pé láti inú ìkòkò tí a fẹ́ iná ìfèéfèé lábẹ́ rẹ̀.
21 Èémí rẹ̀ tiná bọ ẹ̀yin iná,
ọ̀wọ́-iná sì ti ẹnu rẹ̀ jáde.
22 Ní ọrùn rẹ̀ ní agbára kù sí,
àti ìbànújẹ́ àyà sì padà di ayọ̀ níwájú rẹ̀.
23 Jabajaba ẹran rẹ̀ dìjọ pọ̀,
wọ́n múra gírí fún ara wọn, a kò lè sí wọn ní ipò.
24 Àyà rẹ̀ dúró gbagidi bí òkúta,
àní, ó le bi ìyá ọlọ.
25 Nígbà tí ó bá gbé ara rẹ̀ sókè, àwọn alágbára bẹ̀rù;
nítorí ìbẹ̀rù ńlá, wọ́n dààmú.
26 Ọ̀kọ̀ tàbí idà, tàbí ọfà,
ẹni tí ó ṣá a kò lè rán an.
27 Ó ká irin sí ibi koríko gbígbẹ
àti idẹ si bi igi híhù.
28 Ọfà kò lè mú un sá;
òkúta kànnakánná lọ́dọ̀ rẹ̀ dàbí àgékù koríko.
29 Ó ka ẹṣin sí bí àgékù ìdì koríko;
ó rẹ́rìn-ín sí mímì ọ̀kọ̀.
30 Òkúta mímú ń bẹ nísàlẹ̀ abẹ́ rẹ̀,
ó sì tẹ́ ohun mímú ṣóńṣó sórí ẹrẹ̀.
31 Ó mú ibú omi hó bí ìkòkò;
ó sọ̀ agbami Òkun dàbí kólòbó ìkunra.
32 Ó mú ipa ọ̀nà tan lẹ́yìn rẹ̀;
ènìyàn a máa ka ibú sí ewú arúgbó.
33 Lórí ilẹ̀ ayé kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ̀,
tí a dá láìní ìbẹ̀rù.
34 Ó bojú wo ohun gíga gbogbo,
ó sì nìkan jásí ọba lórí gbogbo àwọn ọmọ ìgbéraga.”
Jesu wẹ ẹsẹ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀
13 (A)Ǹjẹ́ kí àjọ ìrékọjá tó dé, nígbà tí Jesu mọ̀ pé, wákàtí rẹ̀ dé tan, tí òun ó ti ayé yìí kúrò lọ sọ́dọ̀ Baba, fífẹ́ tí ó fẹ́ àwọn tirẹ̀ tí ó wà ní ayé, ó fẹ́ wọn títí dé òpin.
2 (B)Bí wọ́n sì ti ń jẹ oúnjẹ alẹ́, tí èṣù ti fi í sí ọkàn Judasi Iskariotu ọmọ Simoni láti fi í hàn; 3 Tí Jesu sì ti mọ̀ pé Baba ti fi ohun gbogbo lé òun lọ́wọ́, àti pé lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni òun ti wá, òun sì ń lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run; 4 Ó dìde ní ìdí oúnjẹ alẹ́, ó sì fi agbádá rẹ̀ lélẹ̀ ní apá kan; nígbà tí ó sì mú aṣọ ìnura, ó di ara rẹ̀ ní àmùrè. 5 (C)Lẹ́yìn náà, ó bu omi sínú àwokòtò kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í máa wẹ ẹsẹ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì ń fi aṣọ ìnura tí ó fi di àmùrè nù wọ́n.
6 Nígbà náà ni ó dé ọ̀dọ̀ Simoni Peteru, òun sì wí fún un pé, “Olúwa, ìwọ yóò ha wẹ ẹsẹ̀ mi?”
7 Jesu dá a lóhùn, ó sì wí fún un pé, “Ohun tí èmi ń ṣe ni ìwọ kò mọ̀ nísinsin yìí; ṣùgbọ́n yóò yé ọ ní ìkẹyìn.”
8 (D)Peteru wí fún un pé, “Ìwọ kì yóò wẹ̀ ẹsẹ̀ mi láé.”
Jesu sì dalóhùn pé, “Bí èmi kò bá wẹ̀ ọ́, ìwọ kò ní ìpín ní ọ̀dọ̀ mi.”
9 Simoni Peteru wí fún ún pé, “Olúwa, kì í ṣe ẹsẹ̀ mi nìkan, ṣùgbọ́n àti ọwọ́ àti orí mi pẹ̀lú.”
10 Jesu wí fún un pé, “Ẹni tí a wẹ̀ kò tún fẹ́ ju kí a ṣan ẹsẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó mọ́ níbi gbogbo: ẹ̀yin sì mọ́, ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo yín.” 11 (E)Nítorí tí ó mọ ẹni tí yóò fi òun hàn; nítorí náà ni ó ṣe wí pé, kì í ṣe gbogbo yín ni ó mọ́.
12 Nítorí náà lẹ́yìn tí ó wẹ ẹsẹ̀ wọn tán, tí ó sì ti mú agbádá rẹ̀, tí ó tún jókòó, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin mọ ohun tí mo ṣe sí yín bí? 13 Ẹ̀yin ń pè mí ní ‘Olùkọ́’ àti ‘Olúwa,’ ẹ̀yin wí rere; bẹ́ẹ̀ ni mo jẹ́. 14 Ǹjẹ́ bí èmi tí í ṣe Olúwa àti olùkọ́ yín bá wẹ ẹsẹ̀ yín, ó tọ́ kí ẹ̀yin pẹ̀lú sì máa wẹ ẹsẹ̀ ara yín. 15 (F)Nítorí mo fi àpẹẹrẹ fún yín, kí ẹ̀yin lè máa ṣe gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe sí yín. 16 (G)Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ọmọ ọ̀dọ̀ kò tóbi ju ọ̀gá rẹ̀ lọ, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí a rán kò tóbi ju ẹni tí ó rán an lọ. 17 (H)Bí ẹ̀yin bá mọ nǹkan wọ̀nyí, alábùkún fún ni yín, bí ẹ̀yin bá ń ṣe wọ́n!
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.