Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 55:1-15

Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Maskili ti Dafidi.

55 Fi etí sí àdúrà mi, Ọlọ́run,
    Má ṣe fi ojú pa ẹ̀bẹ̀ mi rẹ́:
    Gbọ́ mi kí o sì dá mi lóhùn.
Èrò mi ń dà mí láàmú, èmi sì ń pariwo.
    Sí ohùn àwọn ọ̀tá ni,
    nítorí igbe àwọn ènìyàn búburú;
nítorí wọ́n mú ìjìyà wá sórí mi,
    wọ́n sì kẹ́gàn mi nínú ìbínú wọn.

Ọkàn mi wà nínú ìrora pẹ̀lú;
    ẹ̀rù ikú kọjú ìjà sí mi.
Ìbẹ̀rù àti ìwárìrì wa sí ara mi;
    ìbẹ̀rù ti bò mí mọ́lẹ̀.
Èmi sọ pé, “Èmi ìbá ní ìyẹ́ bí àdàbà!
    Èmi ìbá fò lọ kí n sì sinmi.
Èmi ìbá sálọ, jìnnà réré,
    kí ń sì dúró sí aginjù;
Èmi ìbá yára lọ́ si ibùgbé mi ní ibi ààbò,
    jìnnà kúrò nínú ìjì àti ẹ̀fúùfù líle.”

Da àwọn ẹni búburú láàmú, Olúwa, da ahọ́n wọn rú,
    nítorí èmi rí ìwà agbára àti ìjà ní ìlú náà.
10 Ọ̀sán àti òru ni wọ́n fi ń rìn gbogbo odi kiri;
    ìwà ìkà àti èébú wà láàrín rẹ̀.
11 Ìwà búburú ń bẹ ní àárín rẹ̀;
    ẹ̀tàn àti èké kò kúrò ní ìgboro rẹ̀.

12 Tí ọ̀tá bá tàbùkù mi,
    èmi yóò fi ara mọ́ ọn;
tí ọ̀tá bá gbé ara rẹ̀ ga sí mi,
    èmi ìbá sápamọ́ fún un.
13 Ṣùgbọ́n tí ó bá ṣe ìwọ, ọkùnrin bí ẹgbẹ́ mi,
    ẹlẹgbẹ́ mi, àti ọ̀rẹ́ tí ó súnmọ́ mi,
14 pẹ̀lú ẹni tí èmi ti jẹ ìgbádùn adùn ìdàpọ̀,
    bí a ṣe ń rìn pẹ̀lú àwùjọ ní ilé Ọlọ́run.

15 Kí ikú kí ó dé bá wọn,
    Kí wọn ó lọ láààyè sí isà òkú,
Jẹ́ kí wọn ó sọ̀kalẹ̀ sí ibojì pẹ̀lú ìpayà,
    nítorí tí ìwà búburú ń bẹ ní ibùjókòó wọn, àti nínú wọn.

Jobu 8

Bilidadi

Ìgbà náà ni Bilidadi, ará Ṣuhi, sì dáhùn wí pé:

“Ìwọ yóò ti máa sọ nǹkan wọ̀nyí pẹ́ tó?
    Tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ yóò sì máa bí ẹ̀fúùfù ńlá?
Ọlọ́run a ha máa yí ìdájọ́ po bí?
    Tàbí Olódùmarè a máa gbé ẹ̀bi fún aláre?
Nígbà tí àwọn ọmọ rẹ̀ ṣẹ̀ sí i,
    ó sì gbá wọn kúrò nítorí ìrékọjá wọn.
Bí ìwọ bá sì ké pe Ọlọ́run ní àkókò,
    tí ìwọ sì gbàdúrà ẹ̀bẹ̀ sí Olódùmarè.
Ìwọ ìbá jẹ́ mímọ, kí ó sì dúró ṣinṣin:
    ǹjẹ́ nítòótọ́ nísinsin yìí òun yóò tají fún ọ,
    òun a sì sọ ibùjókòó òdodo rẹ di púpọ̀.
Ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ ìbá tilẹ̀ kéré si í,
    bẹ́ẹ̀ ìgbẹ̀yìn rẹ ìbá pọ̀ sí i gidigidi.

“Èmi bẹ̀ ọ́ ǹjẹ́, béèrè lọ́wọ́ àwọn ará ìgbà nì
    kí o sì kíyèsi ìwádìí àwọn baba wọn.
Nítorí pé ọmọ-àná ni àwa, a kò sì mọ nǹkan,
    nítorí pé òjìji ni ọjọ́ wa ni ayé.
10 Àwọn kì yóò wa kọ ọ́, wọn kì yóò sì sọ fún ọ?
    Wọn kì yóò sì sọ̀rọ̀ láti inú òye wọn jáde wá?
11 Papirusi ha lè dàgbà láìní ẹrẹ̀
    tàbí eèsún ha lè dàgbà láìlómi?
12 Nígbà tí ó wà ní tútù, tí a kò ké e lulẹ̀,
    ó rọ dànù, ewéko gbogbo mìíràn hù dípò rẹ̀
13 Bẹ́ẹ̀ ni ipa ọ̀nà gbogbo àwọn tí ó gbàgbé Ọlọ́run,
    bẹ́ẹ̀ ni ìrètí àwọn àgàbàgebè yóò di òfo.
14 Àbá ẹni tí a ó kèé kúrò,
    àti ìgbẹ́kẹ̀lé ẹni tí ó dàbí ilé aláǹtakùn.
15 Yóò fi ara ti ilé rẹ̀, ṣùgbọ́n kì yóò lè dúró,
    yóò fi di ara rẹ̀ mú ṣinṣin ṣùgbọ́n kì yóò lè dúró pẹ́.
16 Ó tutù bí irúgbìn tí a bomirin níwájú oòrùn,
    ẹ̀ka rẹ̀ sì yọ jáde nínú ọgbà rẹ̀.
17 Gbòǹgbò rẹ̀ ta yí ebè ká,
    ó sì wó ibi òkúta wọ̀n-ọn-nì.
18 Bí ó bá sì pa á run kúrò ní ipò rẹ̀,
    nígbà náà ni ipò náà yóò sọ, ‘Èmi kò ri ọ rí!’
19 Kíyèsi i, ayé rẹ̀ gbẹ dànù
    àti láti inú ilẹ̀ ní irúgbìn òmíràn yóò hù jáde wá.

20 “Kíyèsi i, Ọlọ́run kì yóò ta ẹni òtítọ́ nù,
    bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ran oníwà búburú lọ́wọ́
21 títí yóò fi fi ẹ̀rín kún ọ ní ẹnu,
    àti ètè rẹ pẹ̀lú ìhó ayọ̀,
22 ìtìjú ní a o fi bo àwọn tí ó kórìíra rẹ̀,
    àti ibùjókòó ènìyàn búburú kì yóò sí mọ́.”

1 Kọrinti 7:1-9

Ìgbéyàwó

Ní báyìí, nítorí àwọn ohun tí ẹ ṣe kọ̀wé: Ó dára fún ọkùnrin kí ó máa ṣe ni ìdàpọ̀ pẹ̀lú obìnrin. Ṣùgbọ́n nítorí àgbèrè pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ kí ọkùnrin kọ̀ọ̀kan gbéyàwó tirẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni kí obìnrin kọ̀ọ̀kan ní ọkọ tirẹ̀. Kí ọkùnrin kí ó fi gbogbo ẹ̀tọ́ ìyàwó rẹ̀ fún ún, kí ìyàwó fi gbogbo ẹ̀tọ́ ọkọ fún ọkọ rẹ̀. Aya kò láṣẹ lórí ara rẹ̀ mọ́, ara rẹ̀ ti di ti ọkọ rẹ̀. Bákan náà ni ọkùnrin tí ó gbéyàwó kò ní àṣẹ lórí ara rẹ̀ mọ́, ara rẹ̀ ti di ti ìyàwó rẹ̀. (A)Nítorí náà, ẹ má ṣe fi àwọn ẹ̀tọ́ tọkọtaya wọ̀nyí dun ara yín, bí kò ṣe nípa ìfìmọ̀ṣọ̀kan, kí ẹ̀yin lè fi ara yín fún àwẹ̀ àti àdúrà, kí ẹ̀yin sì tún jùmọ̀ pàdé, lẹ́yìn ìgbà náà, wọ́n gbọdọ̀ padà sọ́dọ̀ ara wọn kí Satani má ba à dán wọn wò nítorí àìlèmáradúró wọn. Mo sọ èyí fún un yín bí ìmọ̀ràn ní kì í ṣe bí àṣẹ. (B)Ó wù mí kí olúkúlùkù dàbí èmi, ṣùgbọ́n gbogbo ènìyàn kò le jẹ́ bákan náà, Ọlọ́run fún olúkúlùkù ènìyàn ní ẹ̀bùn tirẹ̀, ọ̀kan bí irú èyí àti èkejì bí irú òmíràn.

Nítorí náà, mo wí fún àwọn àpọ́n àti opó pé, ó sàn kí wọ́n kúkú wà gẹ́gẹ́ bí èmi tí wà. (C)Ṣùgbọ́n bí wọ́n kò bá lè mú ara dúró, kí wọ́n gbéyàwó tàbí kí wọ́n fẹ́ ọkọ, nítorí pé ó sàn láti gbéyàwó jù láti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ lọ.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.