Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 39

Fún adarí orin. Fún Jedutuni. Saamu Dafidi.

39 Mo wí pé, “èmi yóò ṣọ́ ọ̀nà mi
    kí èmi kí ó má fi ahọ́n mi ṣẹ̀;
èmi yóò fi ìjánu kó ara mi ní ẹnu
    níwọ̀n ìgbà tí ènìyàn búburú bá ń bẹ ní iwájú mi.”
Mo fi ìdákẹ́ ya odi;
    mo tilẹ̀ pa ẹnu mi mọ́ kúrò nínú ọ̀rọ̀ rere;
ìbànújẹ́ mi sì pọ̀ sí i.
    Àyà mi gbóná ní inú mi.
Nígbà tí mo ń ṣàṣàrò, iná ràn;
    nígbà náà ni mo fi ahọ́n mi sọ̀rọ̀:

Olúwa, jẹ́ kí èmi kí ó mọ òpin mi,
    àti ìwọ̀n ọjọ́ mi, bí ó ti rí
    kí èmi kí o le mọ ìgbà tí mó ní níhìn-ín.
Ìwọ ti ṣe ayé mi
    bí ìbú àtẹ́lẹwọ́,
ọjọ́ orí mi sì dàbí asán
    ní iwájú rẹ:
Dájúdájú olúkúlùkù ènìyàn nínú
    ìjókòó rere rẹ̀ jásí asán pátápátá. Sela.

“Nítòótọ́ ni olúkúlùkù ń rìn kiri bí òjìji.
    Nítòótọ́ ni wọ́n ń yọ ara wọn lẹ́nu lórí asán;
wọ́n ń kó ọrọ̀ jọ,
    wọn kò sì mọ ẹni tí yóò ko lọ.

“Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí,
    Olúwa,
kín ni mo ń dúró dè?
    Ìrètí mí ń bẹ ní ọ̀dọ̀ rẹ.
Gbà mí lọ́wọ́ ìrékọjá mi gbogbo.
    Kí o má sì sọ mí di ẹni ẹ̀gàn
àwọn ènìyàn búburú.
Mo dákẹ́ jẹ́ẹ́;
    èmi kò sì ya ẹnu mi,
nítorí wí pé ìwọ ni ó ṣe é.
10 Mú pàṣán rẹ kúrò ní ara mi;
    èmí ṣègbé tán nípa lílù ọwọ́ rẹ.
11 Ìwọ fi ìbáwí kìlọ̀
    fún ènìyàn nítorí ẹ̀ṣẹ̀,
ìwọ a mú ẹwà rẹ parun
    bí kòkòrò aṣọ;
nítòótọ́ asán ni ènìyàn gbogbo.

12 “Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa,
    kí o sì fetí sí igbe mi;
kí o má ṣe di etí rẹ sí ẹkún mi
    nítorí àlejò ni èmi lọ́dọ̀ rẹ
àti àtìpó, bí gbogbo àwọn baba mi ti rí.
13 Dá mi sí, kí èmi lè ní agbára,
    kí èmi tó lọ kúrò níhìn-ín yìí,
    àti kí èmi ó tó ṣe aláìsí.”

Jobu 28:12-29:10

12 Ṣùgbọ́n níbo ni á ó gbé wá ọgbọ́n rí,
    níbo sì ni òye ń gbe?
13 Ènìyàn kò mọ iye rẹ̀,
    bẹ́ẹ̀ ni a kò le è rí i ní ilẹ̀ àwọn alààyè.
14 Ọ̀gbun wí pé, “Kò sí nínú mi”;
    omi Òkun sì wí pé, “Kò si nínú mi.”
15 A kò le è fi wúrà rà á,
    bẹ́ẹ̀ ni a kò le è fi òṣùwọ̀n wọn fàdákà ní iye rẹ̀.
16 A kò le è fi wúrà ofiri,
    tàbí òkúta óníkìsì iyebíye, tàbí òkúta Safire díye lé e.
17 Wúrà àti òkúta kristali kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀;
    bẹ́ẹ̀ ni a kò le è fi ohun èlò wúrà ṣe pàṣípàrọ̀ rẹ̀.
18 A kò lè dárúkọ iyùn tàbí òkúta jasperi;
    iye ọgbọ́n sì ju iyùn lọ.
19 Òkúta topasi ti Kuṣi kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀;
    bẹ́ẹ̀ ni a kò le fi wúrà dáradára díwọ̀n iye rẹ̀.

20 Níbo ha ni ọgbọ́n ti jáde wá?
    Tàbí níbo ni òye ń gbé?
21 A rí i pé, ó fi ara sinko kúrò ní ojú àwọn alààyè gbogbo,
    ó sì fi ara sin fún ẹyẹ ojú ọ̀run.
22 Ibi ìparun àti ikú wí pé,
    àwa ti fi etí wa gbúròó rẹ̀.
23 Ọlọ́run ni ó mọ òye ipa ọ̀nà rẹ̀,
    òun ni ó sì mọ ibi tí ó ń gbé.
24 Nítorí pé ó wòye dé òpin ayé,
    ó sì rí gbogbo ìsàlẹ̀ ọ̀run,
25 Láti dà òṣùwọ̀n fún afẹ́fẹ́,
    ó sì fi òṣùwọ̀n wọ́n omi.
26 Nígbà tí ó pàṣẹ fún òjò,
    tí ó sì la ọ̀nà fún mọ̀nàmọ́ná àrá,
27 Nígbà náà ni ó rí i, ó sì sọ ọ́ jáde;
    ó pèsè rẹ̀ sílẹ̀, ó sì ṣe ìwádìí rẹ̀ rí.
28 Àti fún ènìyàn ni ó wí pé,
    “Kíyèsi i, ẹ̀rù Olúwa èyí ni ọgbọ́n,
    àti láti jáde kúrò nínú ìwà búburú èyí ni òye.”

Jobu rántí ìbùkún rẹ̀ àtẹ̀yìnwá

29 Pẹ̀lúpẹ̀lú, Jobu sì tún tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé:

“Háà! ìbá ṣe pé èmi wà bí ìgbà oṣù tí ó kọjá,
    bí ọjọ́ tí Ọlọ́run pa mí mọ́;
Nígbà tí fìtílà rẹ tàn sí mi ní orí,
    àti nípa ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ èmi rìn nínú òkùnkùn já;
Bí mo ti rí nígbà ọ̀dọ́ mi,
    nígbà tí ọ̀rẹ́ Ọlọ́run tímọ́tímọ́ bùkún ilé mi
Nígbà tí Olódùmarè wà pẹ̀lú mi,
    nígbà tí àwọn ọmọ mi wà yí mi ká;
Nígbà tí èmi fi òrí-àmọ́ n wẹ ìṣísẹ̀ mi,
    àti tí apata ń tú ìṣàn òróró jáde fún mi wá.

“Nígbà tí mo jáde la àárín ìlú lọ sí ẹnu ibodè,
    nígbà tí mo tẹ́ ìtẹ́ mi ní ìgboro,
Nígbà náà ni àwọn ọmọkùnrin rí mi,
    wọ́n sì sápamọ́, àwọn àgbà dìde dúró ní ẹsẹ̀ wọn;
Àwọn ọmọ-aládé dákẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ,
    wọn a sì fi ọwọ́ wọn lé ẹnu;
10 Àwọn ọlọ́lá dákẹ́,
    ahọ́n wọn sì lẹ̀ mọ́ èrìgì ẹnu wọn.

Ìfihàn 8:1-5

Èdìdì keje àti àwo tùràrí

Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì keje, ìdákẹ́rọ́rọ́ sì wà ní ọ̀run níwọ̀n ààbọ̀ wákàtí kan.

Mo sì rí àwọn angẹli méje tí wọn dúró níwájú Ọlọ́run; a sì fi ìpè méje fún wọn.

(A)Angẹli mìíràn sì wá, ó sì dúró ti pẹpẹ, ó ní àwo tùràrí wúrà kan a sì fi tùràrí púpọ̀ fún un, láti máa fi kún àdúrà gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ lórí pẹpẹ, pẹpẹ wúrà tí ń bẹ níwájú ìtẹ́. Àti èéfín tùràrí náà pẹ̀lú àdúrà àwọn ènìyàn mímọ́ sì gòkè lọ síwájú Ọlọ́run láti ọwọ́ angẹli náà wá. (B)Angẹli náà sì mú àwo tùràrí náà, ó sì fi iná orí pẹpẹ kùn ún, ó sì dà á sórí ilẹ̀ ayé: A sì gbọ́ ohùn, àrá sì sán, mọ̀nàmọ́ná sì kọ, àti ilẹ̀-rírì.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.