Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 26

Ti Dafidi.

26 Ṣe ìdájọ́ mi, Olúwa,
    nítorí tí mo ti ń rìn nínú ìwà òtítọ́ ọ̀ mi,
mo sì ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa
    Ǹjẹ́ ẹsẹ̀ mi kì yóò yẹ̀.
Wádìí mi wò, Ìwọ Olúwa, kí o sì dán mi wò,
    dán àyà àti ọkàn mi wò;
Nítorí ìfẹ́ ẹ̀ rẹ tí ó dúró ṣinṣin ń bẹ níwájú mi,
    èmí sì ti rìn nínú òtítọ́ rẹ.

Èmi kò jókòó pẹ̀lú aláìṣòótọ́,
    bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò bá àwọn àgàbàgebè wọlé;
Èmi ti kórìíra àwùjọ àwọn ènìyàn búburú
    èmi kì yóò sì bá àwọn ènìyàn ìkà jókòó.
Èmí ó wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́ṣẹ̀,
    bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì yí pẹpẹ rẹ ká Olúwa.
Èmi yóò kọrin sókè àní orin ọpẹ́,
    èmi yóò sì máa sọ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀.

Háà Olúwa, èmí ń fẹ́ ilé rẹ níbi tí ìwọ ń gbé,
    àní níbi tí ògo rẹ̀ wà.
Má ṣe gbá mi dànù pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,
    tàbí ẹ̀mí mi pẹ̀lú àwọn ọkùnrin tí òǹgbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ,
10 Àwọn tí ọwọ́ wọn kún fún ìwà ibi,
    tí ọwọ́ ọ̀tún wọn kún fún àbẹ̀tẹ́lẹ̀.
11 Ṣùgbọ́n èmi ó máa rìn nínú ìwà títọ́;
    rà mí padà, kí o sì ṣàánú fún mi.

12 Ẹsẹ̀ mi dúró lórí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú;
    nínú ìjọ ńlá èmi yóò fi ìbùkún fún Olúwa.

Jobu 2:11-3:26

Ọ̀rẹ́ Jobu mẹ́ta

11 Nígbà tí àwọn ọ̀rẹ́ Jobu mẹ́ta gbúròó gbogbo ibi tí ó bá a, wọ́n wá, olúkúlùkù láti ibùjókòó rẹ̀; Elifasi, ara Temani àti Bilidadi, ará Ṣuhi, àti Sofari, ará Naama: nítorí pé wọ́n ti dájọ́ ìpàdé pọ̀ láti bá a ṣọ̀fọ̀, àti láti ṣìpẹ̀ fún un. 12 Nígbà tí wọ́n gbójú wọn wò ní òkèrè réré, tí wọ́n kò sì mọ̀ ọ́n, wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sọkún: olúkúlùkù sì fa aṣọ ìgúnwà rẹ̀ ya, wọ́n sì ku erùpẹ̀ sí ojú ọ̀run, wọ́n sì tẹ́ orí gbà á. 13 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n jókòó tì í ní inú erùpẹ̀ ní ọjọ́ méje ti ọ̀sán ti òru, ẹnikẹ́ni kò sì bá a sọ ọ̀rọ̀ kan, nítorí tí wọ́n ti rí i pé ìbànújẹ́ rẹ̀ pọ̀ jọjọ.

Jobu ráhùn sí Ọlọ́run

Ẹ̀yìn èyí ní Jobu yanu, ó sì fi ọjọ́ ìbí rẹ̀ ré Jobu sọ, ó sì wí pé:

(A)“Kí ọjọ́ tí a bí mi kí ó di ìgbàgbé,
    àti òru ni, nínú èyí tí a wí pé, ‘A lóyún ọmọkùnrin kan!’
Kí ọjọ́ náà kí ó já si òkùnkùn,
    kí Ọlọ́run kí ó má ṣe kà á sí láti ọ̀run wá;
    bẹ́ẹ̀ ni kí ìmọ́lẹ̀ kí ó má ṣe mọ́ sí i.
Kí òkùnkùn àti òjìji ikú fi ṣe ti ara wọn;
    kí àwọsánmọ̀ kí ó bà lé e;
    kí ìṣúdudu ọjọ́ kí ó pa láyà.
Kí òkùnkùn kí ó ṣú bo òru náà biribiri,
    kí ó má ṣe yọ pẹ̀lú ọjọ́ ọdún náà:
    kí a má ṣe kà a mọ́ iye ọjọ́ oṣù.
Kí òru náà kí ó yàgàn;
    kí ohun ayọ̀ kan kí ó má ṣe wọ inú rẹ̀ lọ.
Kí àwọn tí í fi ọjọ́ gégùn ún kí o fi gégùn ún,
    tí wọ́n mura tán láti ru Lefitani sókè.
Kí ìràwọ̀ òwúrọ̀ ọjọ́ rẹ̀ kí ó ṣókùnkùn;
    kí ó má wá ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n kí ó máa mọ́ sí i,
    bẹ́ẹ̀ ni kí ó má ṣe rí àfẹ̀mọ́júmọ́
10 Nítorí tí kò sé ìlẹ̀kùn inú ìyá mi,
    láti pa ìbànújẹ́ rẹ́ ní ojú mi.

11 “Èéṣe tí èmi kò fi kú láti inú wá,
    tàbí tí èmi kò kú ní ìgbà tí mo ti inú jáde wá?
12 Èéṣe tí orúnkún wá pàdé mi,
    tàbí ọmú tí èmi yóò mu?
13 Ǹjẹ́ nísinsin yìí èmi ìbá ti dùbúlẹ̀ jẹ́ẹ́;
    èmi ìbá ti sùn, èmi ìbá ti sinmi
14 pẹ̀lú àwọn ọba àti ìgbìmọ̀ ayé
    tí wọ́n mọ ilé fún ara wọn wá dùbúlẹ̀ nínú ìsọdahoro.
15 Tàbí pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé
    tí ó ní wúrà, tí wọ́n sì fi fàdákà kun ilé wọn
16 Tàbí bí ọlẹ̀ tí a sin, èmi kì bá ti sí:
    bí ọmọ ìṣunú tí kò rí ìmọ́lẹ̀?
17 Níbẹ̀ ni ẹni búburú ṣíwọ́ ìyọnilẹ́nu,
    níbẹ̀ ni ẹni àárẹ̀ wà nínú ìsinmi.
18 Níbẹ̀ ni àwọn ìgbèkùn sinmi pọ̀,
    wọn kò gbóhùn amúnisìn mọ́.
19 Àti èwe àti àgbà wà níbẹ̀,
    ẹrú sì di òmìnira kúrò lọ́wọ́ olówó rẹ̀.

Jobu kígbe nínú ìrora rẹ̀

20 “Nítorí kí ni a ṣe fi ìmọ́lẹ̀ fún òtòṣì,
    àti ìyè fún ọlọ́kàn kíkorò,
21 tí wọ́n dúró de ikú, ṣùgbọ́n òun kò wá,
    tí wọ́n wá a jù ìṣúra tí a bò mọ́lẹ̀ pamọ́ lọ.
22 Ẹni tí ó yọ̀ gidigidi,
    tí inú wọ́n sì dùn nígbà tí wọ́n wá ibojì òkú rí?
23 Kí ni a fi ìmọ́lẹ̀ fún ẹni
    tí ọ̀nà rẹ̀ fi ara pamọ́ fún,
    tí Ọlọ́run sì ṣọgbà dí mọ́ ká?
24 Nítorí pé èémí-ẹ̀dùn wà ṣáájú oúnjẹ mi;
    ìkérora mi sì tú jáde bí omi.
25 Nítorí pé ohun náà tí mo bẹ̀rù gidigidi ni ó dé bá mi yìí,
    àti ohun tí mo fòyà rẹ̀ bá mi ó sì ṣubú lù mí.
26 Èmi wà láìní àlàáfíà, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ní ìsinmi;
    bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ni ìfàyàbalẹ̀, bí kò ṣe ìdààmú.”

Galatia 3:23-29

23 Ṣùgbọ́n kí ìgbàgbọ́ tó dé, a ti pa wá mọ́ lábẹ́ òfin, a sì sé wa mọ́ de ìgbàgbọ́ tí a ń bọ̀ wá fihàn. 24 Nítorí náà òfin ti jẹ́ olùtọ́jú láti mú ènìyàn wá sọ́dọ̀ Kristi, kí a lè dá wa láre nípa ìgbàgbọ́. 25 Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí ìgbàgbọ́ ti dé, àwa kò sí lábẹ́ olùtọ́jú mọ́.

Ọmọ Ọlọ́run

26 Nítorí pé ọmọ Ọlọ́run ni gbogbo yín, nípa ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jesu. 27 Nítorí pé iye ẹ̀yin tí a ti bamitiisi sínú Kristi ti gbé Kristi wọ̀. 28 (A)Kò le sí Júù tàbí Giriki, ẹrú tàbí òmìnira, ọkùnrin tàbí obìnrin nítorí pé ọ̀kan ni nínú Kristi Jesu. 29 Bí ẹ̀yin bá sì jẹ́ ti Kristi, ǹjẹ́ ẹ̀yin ní irú-ọmọ Abrahamu, àti àrólé gẹ́gẹ́ bí ìlérí.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.