Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 128

Orin fún ìgòkè.

Ìbẹ̀rù Olúwa dára

128 Ìbùkún ni fún gbogbo ẹni tí ó bẹ̀rù Olúwa:
    tí ó sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀
Nítorí tí ìwọ yóò jẹ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ
    ìbùkún ni fún ọ; yóò sì dára fún ọ
Obìnrin rẹ yóò dàbí àjàrà rere
    eléso púpọ̀ ní àárín ilé rẹ;
    àwọn ọmọ rẹ yóò dàbí igi olifi tí ó yí tábìlì rẹ ká.
Kíyèsi i pé, bẹ́ẹ̀ ni a ó bùsi i fún ọkùnrin náà,
    tí ó bẹ̀rù Olúwa.

Olúwa kí ó bùsi i fún ọ láti Sioni wá,
    kí ìwọ kí ó sì máa rí ìre
Jerusalẹmu ní ọjọ́ ayé rẹ gbogbo.
    Bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó sì máa rí àti ọmọdọ́mọ rẹ.
Láti àlàáfíà lára Israẹli.

Oniwaasu 5

Dídúró nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run

Ṣọ́ ìrìn rẹ nígbà tí o bá lọ sí ilé Ọlọ́run. Kí ìwọ kí ó sì múra láti gbọ́ ju àti ṣe ìrúbọ aṣiwèrè, tí kò mọ̀ wí pé òun ń ṣe búburú.

Má ṣe yára pẹ̀lú ẹnu un rẹ,
    má sọ ohunkóhun níwájú Ọlọ́run
Ọlọ́run ń bẹ ní ọ̀run
    ìwọ sì wà ní ayé,
    nítorí náà jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ mọ ní ìwọ̀n
Gẹ́gẹ́ bí àlá tí ń wá, nígbà tí ìlépa púpọ̀ wà
    bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ nígbà tí ọ̀rọ̀ bá pọ̀jù.

Nígbà tí o bá ṣe ìlérí sí Ọlọ́run, má ṣe pẹ́ ní mímúṣẹ, kò ní inú dídùn sí òmùgọ̀, mú ìlérí rẹ sẹ. Ó sàn láti má jẹ́ ẹ̀jẹ́, ju wí pé kí a jẹ́ ẹ̀jẹ́ kí a má mu ṣẹ lọ. Má ṣe jẹ́ kí ẹnu rẹ tì ọ́ sínú ẹ̀ṣẹ̀. Má sì ṣe sọ fún òjíṣẹ́ ilé ìsìn pé “Àṣìṣe ni ẹ̀jẹ́ mi.” Kí ló dé tí Ọlọ́run fi le è bínú sí ọ, kí ó sì ba iṣẹ́ ọwọ́ rẹ jẹ́? Asán ni ọ̀pọ̀ àlá àti ọ̀rọ̀ púpọ̀. Nítorí náà dúró nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run.

Asán ni ọrọ̀ jẹ́

Bí o bá rí tálákà tí wọ́n ń ni lára ní ojú púpọ̀, tí a sì ń fi òtítọ́ àti ẹ̀tọ́ rẹ̀ dù ú, má ṣe jẹ́ kí ó yà ọ́ lẹ́nu láti rí irú nǹkan bẹ́ẹ̀, nítorí pé ẹni tí ó wà ní ipò gíga máa ń mọ́ òṣìṣẹ́ tí ó wà lábẹ́ rẹ̀ lójú ni, síbẹ̀ àwọn kan sì wà tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn méjèèjì. Gbogbo wọn ni ó ń pín èrè tí wọ́n bá rí lórí ilẹ̀, àní ọba pàápàá ń jẹ èrè lórí oko.

10 Ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ owó kì í ní owó ànító,
    ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ sí ọrọ̀ kì í ní ìtẹ́lọ́rùn
    pẹ̀lú èrè tí ó ń wọlé fún un.

11 Bí ẹrù bá ti ń pọ̀ sí i
    náà ni àwọn tí ó ń jẹ ẹ́ yóò máa pọ̀ sí i
Èrè e kí ni wọ́n sì jẹ́ sí ẹni tí ó ni nǹkan bí kò ṣe pé,
    kí ó máa mú inú ara rẹ dùn nípa rí rí wọn?

12 Oorun alágbàṣe a máa dùn,
    yálà ó jẹun kékeré ni tàbí ó jẹun púpọ̀,
ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀
    kì í jẹ́ kí ó sùn rárá.

13 Mo ti rí ohun tí ó burú gidigidi lábẹ́ oòrùn

ọrọ̀ tí a kó pamọ́ fún ìparun ẹni tó ni nǹkan.
14     Tàbí ọrọ̀ tí ó sọnù nípa àìrí ojúrere,
nítorí wí pé bí ó bá ní ọmọkùnrin
    kò sí ohun tí yóò fi sílẹ̀ fún un.
15 Ìhòhò ni ènìyàn wá láti inú ìyá rẹ̀,
    bí ó sì ṣe wá, bẹ́ẹ̀ ni yóò kúrò
kò sí ohunkóhun nínú iṣẹ́ rẹ̀
    tí ó le mú ní ọwọ́ rẹ̀.

16 Ohun búburú gbá à ni eléyìí pàápàá:

Bí ènìyàn ṣe wá, ni yóò lọ
    kí wá ni èrè tí ó jẹ
    nígbà tí ó ṣe wàhálà fún afẹ́fẹ́?
17 Ó ń jẹ nínú òkùnkùn ní gbogbo ọjọ́ ọ rẹ̀,
    pẹ̀lú iyè ríra tí ó ga, ìnira àti ìbínú.

18 Nígbà náà ni mo wá rí i dájú pé, ó dára, ó sì tọ̀nà fún ènìyàn láti jẹ, kí ó mu, kí ó sì ní ìtẹ́lọ́rùn nínú iṣẹ́ wàhálà rẹ̀ lábẹ́ oòrùn, ní àkókò ọjọ́ ayé díẹ̀ tí Ọlọ́run ti fi fún un, nítorí ìpín rẹ̀ ni èyí. 19 Síwájú sí, nígbà tí Ọlọ́run fún ẹnikẹ́ni ní ọrọ̀ àti ohun ìní, tí ó sì fún un lágbára láti gbádùn wọn, láti gba ìpín rẹ̀ kí inú rẹ̀ sì dùn sí iṣẹ́ rẹ—ẹ̀bùn Ọlọ́run ni èyí. 20 Ó máa ń ronú lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan nípa ọjọ́ ayé rẹ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan nítorí pé Ọlọ́run ń pa á mọ́ pẹ̀lú inú dídùn ní ọkàn rẹ̀.

Johanu 8:21-38

21 (A)Nítorí náà ó tún wí fún wọn pé, “Èmi ń lọ, ẹ̀yin yóò sì wá mi, ẹ ó sì kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín: ibi tí èmi gbé ń lọ, ẹ̀yin kì yóò lè wá.”

22 Nítorí náà àwọn Júù wí pé, “Òun ó ha pa ara rẹ̀ bí? Nítorí tí ó wí pé, ‘Ibi tí èmi gbé ń lọ, ẹ̀yin kì yóò lè wá’?”

23 (B)Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ti ìsàlẹ̀ wá; èmi ti òkè wá; ẹ̀yin jẹ́ ti ayé yìí; èmi kì í ṣe ti ayé yìí. 24 (C)Nítorí náà ni mo ṣe wí fún yín pé, ẹ ó kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín: nítorí bí kò ṣe pé ẹ bá gbàgbọ́ pé èmi ni, ẹ ó kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín.”

25 Nítorí náà wọ́n wí fún un pé, “Ta ni ìwọ jẹ́?”

Jesu sì wí fún un pé, “Èmi ni èyí tí mo ti wí fún yín ní àtètèkọ́ṣe. 26 Mo ní ohun púpọ̀ láti sọ, àti láti ṣe ìdájọ́ nípa yín: ṣùgbọ́n olóòtítọ́ ni ẹni tí ó rán mi, ohun tí èmi sì ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá, wọ̀nyí ni èmi ń sọ fún aráyé.”

27 Kò yé wọn pé ti Baba ni ó ń sọ fún wọn. 28 (D)Lẹ́yìn náà Jesu wí fún wọn pé, “Nígbà tí ẹ mọ̀ pé, nígbà tí ẹ bá gbé Ọmọ ènìyàn sókè, nígbà náà ni ẹ ó mọ̀ pé èmi ni àti pé èmi kò dá ohunkóhun ṣe fún ara mi; ṣùgbọ́n bí Baba ti kọ́ mi, èmí ń sọ nǹkan wọ̀nyí. 29 Ẹni tí ó rán mí sì ń bẹ pẹ̀lú mi: kò fi mí sílẹ̀ ní èmi nìkan; nítorí tí èmi ń ṣe ohun tí ó wù ú nígbà gbogbo.” 30 (E)Bí ó ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí, ọ̀pọ̀ ènìyàn gbà á gbọ́.

Àwọn ọmọ Abrahamu

31 (F)Nítorí náà Jesu wí fún àwọn Júù tí ó gbà á gbọ́, pé, “Bí ẹ bá tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ mi ẹ ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi nítòótọ́. 32 (G)Ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì sọ yín di òmìnira.”

33 (H)Wọ́n dá a lóhùn pé, “Irú-ọmọ Abrahamu ni àwa jẹ́, àwa kò sì ṣe ẹrú fún ẹnikẹ́ni rí láé; ìwọ ha ṣe wí pé, ‘Ẹ ó di òmìnira’?”

34 (I)Jesu dá wọn lóhùn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀, ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ ni. 35 (J)Ẹrú kì í sì í gbé ilé títí láé: ọmọ ní ń gbé ilé títí láé 36 Nítorí náà, bí Ọmọ bá sọ yín di òmìnira ẹ ó di òmìnira nítòótọ́. 37 Mo mọ̀ pé irú-ọmọ Abrahamu ni ẹ̀yin jẹ́; ṣùgbọ́n ẹ ń wá ọ̀nà láti pa mí nítorí ọ̀rọ̀ mi kò rí ààyè nínú yín. Jesu sọ ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ nípa ara rẹ̀. 38 Ohun tí èmi ti rí lọ́dọ̀ Baba ni mo sọ: ẹ̀yin pẹ̀lú sì ń ṣe èyí tí ẹ̀yin ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ baba yín.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.