Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 73:21-28

21 Nígbà tí inú mi bàjẹ́
    àti ọkàn mi ṣì korò,
22 Mo jẹ́ aṣiwèrè àti aláìlóye;
    mo jẹ́ ẹranko ní iwájú rẹ.

23 Síbẹ̀ mo wà pẹ̀lú rẹ nígbà gbogbo;
    ìwọ di ọwọ́ ọ̀tún mi mú.
24 Ìwọ fi ìmọ̀ràn rẹ tọ́ mi
    ní ìkẹyìn ìwọ ó mú mi lọ sí inú ògo
25 Ta ni mo ní ní ọ̀run, bí kò ṣe ìwọ?
    Àti ní ayé kò sí ohun tí mo fẹ́ lẹ́yìn rẹ.
26 Ara mi àti ọkàn mi le è kùnà
    ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni agbára ẹ̀mí mi
    àti ìpín mi títí láé.

27 Àwọn tí ó jìnnà sí ọ yóò ṣègbé
    ìwọ ti pa gbogbo wọn run;
tí ń ṣe àgbèrè kiri kúrò lọ́dọ̀ rẹ
28 Ṣùgbọ́n ní ti èmi, ó dára láti súnmọ́ Ọlọ́run
    Èmi ti fi Olúwa Olódùmarè ṣe ààbò mi;
    Kí èmi ó lè máa sọ̀rọ̀ iṣẹ́ rẹ.

Òwe 25

Àwọn òwe mìíràn ti Solomoni

25 Wọ̀nyí ni àwọn òwe mìíràn tí Solomoni pa,

    tí àwọn ọkùnrin Hesekiah ọba Juda dà kọ.

Ògo Ọlọ́run ní láti fi ọ̀rọ̀ kan pamọ́;
    láti rí ìdí ọ̀rọ̀ kan ni ògo àwọn ọba.

Bí ọ̀run ṣe ga tó tí ayé sì jì
    bẹ́ẹ̀ ni ó ṣòro láti mọ èrò ọkàn ọba.

Mú ìdàrọ́ kúrò lára fàdákà
    ohun èlò yóò sì jáde fún alágbẹ̀dẹ fàdákà
Mú ènìyàn búburú kúrò níwájú ọba
    a ó sì fìdí ìtẹ́ rẹ múlẹ̀ nípasẹ̀ òdodo.

Má ṣe gbé ara rẹ ga níwájú ọba,
    má sì ṣe jìjàdù ààyè láàrín àwọn ènìyàn pàtàkì
Ó sàn kí ó wí fún ọ pé, “Gòkè wá síhìn-ín”
    ju wí pé kí ó dójútì ọ́ níwájú ènìyàn pàtàkì.

Ohun tí o ti fi ojú ara rẹ rí
    má ṣe kánjú gbé e lọ sílé ẹjọ́ nítorí kí ni ìwọ yóò ṣe ní ìgbẹ̀yìn
    bí aládùúgbò rẹ bá dójútì ọ́?

Bí o bá ń ṣe àwíjàre rẹ níwájú aládùúgbò rẹ,
    má ṣe tú àṣírí tí ẹlòmíràn ní lọ́dọ̀ rẹ,
10 àìṣe bẹ́ẹ̀ ẹni tí ó gbọ́ ọ le dójútì ọ́
    orúkọ búburú tí ìwọ bá sì gba kì yóò tán láéláé.

11 Ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò tí ó yẹ
    ó dàbí èso wúrà nínú àpẹẹrẹ fàdákà.
12 Bí i yẹtí wúrà tàbí ohun ọ̀ṣọ́ ti wúrà dáradára
    ni ìbáwí ọlọ́gbọ́n fún etí tí ó bá fetísílẹ̀.

13 Bí títutù òjò yìnyín ní àsìkò ìkórè
    ni ìránṣẹ́ tí ó jẹ́ olóòtítọ́ sí àwọn tí ó rán an
    ó ń tu ọ̀gá rẹ̀ nínú.
14 Bí ojú ṣíṣú àti afẹ́fẹ́ láìsí òjò
    ni ènìyàn tí ń yangàn nípa ẹ̀bùn tí kò fún ni.

15 Nípa sùúrù a lè yí ọba lọ́kàn padà
    ahọ́n tí ń sọ̀rọ̀ rírọ̀ sí egungun.

16 Bí ìwọ bá rí oyin, jẹ ẹ́ ní ìwọ̀nba
    bí o bá jẹ ẹ́ jù, ìwọ yóò sì bì í.
17 Má ṣe máa lọ sí ilé aládùúgbò rẹ nígbà gbogbo
    tàbí kí ó máa lọ síbẹ̀ lálọ jù, yóò sì kórìíra rẹ.

18 Bí ọ̀pá, idà tàbí ọ̀kọ̀ tí ó mú
    ni ènìyàn tí ó jẹ́rìí èké lòdì sí aládùúgbò rẹ̀.

19 Bí eyín tí ó bàjẹ́ tàbí ẹsẹ̀ tí ó rọ
    ni ìgbẹ́kẹ̀lé lórí aláìṣòótọ́ ní àsìkò ìdààmú.
20 Bí ẹni tí ó bọ́ra kalẹ̀ ní ọjọ́ tí òtútù mú,
    tàbí, bí ọtí kíkan tí a dà sí ojú ọgbẹ́,
    ní ẹni tí ń kọ orin fún ẹni tí ọkàn rẹ̀ bàjẹ́.

21 (A)Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ;
    bí òǹgbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mú.
22 Nípa ṣíṣe báyìí, ìwọ yóò wa ẹ̀yín iná lé e lórí
    Olúwa yóò sì san ọ ní ẹ̀san rẹ̀ fún ọ.

23 Bí afẹ́fẹ́ gúúsù ti í mú òjò wá,
    bí ahọ́n tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀yìn ṣe ń mú ojú ìbínú wá.

24 Ó sàn láti gbé ní ibi igun kan lórí òrùlé
    ju láti bá aya oníjà gbé ilé pọ̀.

25 Bí omi tútù sí ọkàn tí ń ṣe àárẹ̀
    ni ìròyìn ayọ̀ láti ọ̀nà jíjìn.

26 Bí ìsun tí ó di àbàtà tàbí kànga tí omi rẹ̀ bàjẹ́
    ni olódodo tí ó fi ààyè gba ènìyàn búburú.

27 Kò dára láti jẹ oyin àjẹjù,
    bẹ́ẹ̀ ni kò pọ́n ni lé láti máa wá ọlá fún ara ẹni.

28 Bí ìlú tí odi rẹ̀ ti wó lulẹ̀
    ni ènìyàn tí kò le kó ara rẹ̀ ní ìjánu.

Kolose 3:1-11

Àwọn òfin fún ìgbé ayé ìwà mímọ́

(A)Níwọ́n ìgbà tí a ti jí yín dìde pẹ̀lú Kristi ẹ máa ṣàfẹ́rí àwọn nǹkan tí ń bẹ lókè, níbi tí Kristi gbé wà tí ó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run. Ẹ máa ronú àwọn ohun tí ń bẹ lókè kì í ṣe àwọn nǹkan tí ń bẹ ní ayé. Nítorí ẹ̀yin ti kú, a sì fi ìyè yín pamọ́ pẹ̀lú Kristi nínú Ọlọ́run. Nígbà tí Kristi, ẹni tí í ṣe ìyè yín yóò farahàn, nígbà náà ni ẹ̀yin pẹ̀lú yóò farahàn pẹ̀lú rẹ̀ nínú ògo.

Ẹ máa pa ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ ní ayé run: àgbèrè, panṣágà, ìwà àìmọ́, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti ìwọra, nítorí pé ìwọ̀nyí jásí ìbọ̀rìṣà. Lórí àwọn wọ̀nyí ni ìbínú Ọlọ́run ń bọ̀ wá. Ẹ máa ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí tẹ́lẹ̀ nígbà tí ìgbé ayé yín sì jẹ́ apá kan ayé yìí. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ gbọdọ̀ fi àwọn wọ̀nyí sílẹ̀: ìbínú, ìrunú, àrankàn, fífi ọ̀rọ̀-kẹ́lẹ́-ba-tẹni-jẹ́ àti ọ̀rọ̀ èérí kúrò ní ètè yín. Ẹ má ṣe purọ́ fún ara yín, níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti bọ́ ògbólógbòó ara yín pẹ̀lú ìṣe rẹ̀ sílẹ̀, 10 (B)tí ẹ sì ti gbé ìgbé ayé tuntun wọ̀, èyí tí a sọ di tuntun nínú ìmọ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àwòrán ẹni tí ó dá a. 11 Níbi tí kò gbé sí Giriki tàbí Júù, ìkọlà tàbí aláìkọlà, aláìgbédè, ara Skitia, ẹrú tàbí òmìnira, ṣùgbọ́n Kristi ni ohun gbogbo nínú ohun gbogbo.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.