Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
ÌWÉ KÌN-ÍN-NÍ
Saamu 1–41
1 (A)Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà,
tí kò rìn ní ìmọ̀ àwọn ènìyàn búburú,
ti kò dúró ní ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,
tàbí tí kò sì jókòó ní ibùjókòó àwọn ẹlẹ́gàn.
2 Ṣùgbọ́n ayọ̀ inú rẹ̀ wà nínú òfin Olúwa
àti nínú òfin rẹ̀ ni ó ń ṣe àṣàrò ní ọ̀sán àti òru.
3 Ó dàbí igi tí a gbìn sí etí odò tí ń sàn,
tí ń so èso rẹ̀ jáde ní àkókò rẹ̀
tí ewé rẹ̀ kì yóò rẹ̀.
Ohunkóhun tí ó dáwọ́lé, ni yóò máa yọrí sí rere.
4 Kò le rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn ènìyàn búburú!
Wọn yóò dàbí ìyàngbò ọkà
tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ dànù.
5 Nítorí náà àwọn ènìyàn búburú kì yóò le è dìde dúró ní ìdájọ́,
bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kì yóò le è dúró ní àwùjọ àwọn olódodo.
6 Nítorí Olúwa ń ṣọ́ ọ̀nà àwọn olódodo,
ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ni yóò ṣègbé.
18 “Àwọn nǹkan mẹ́ta wà tí ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún mi,
mẹ́rin tí kò yé mi:
19 Ipa ẹyẹ idì ní òfúrufú
ipa ejò lórí àpáta
ipa ọkọ̀ ojú omi lójú agbami Òkun
àti ipa ọ̀nà ọkùnrin tí ó mú wúńdíá lọ́wọ́.
20 “Èyí ni ọ̀nà alágbèrè obìnrin
ó jẹun ó sì nu ẹnu rẹ̀
ó sì wí pé, N kò ṣe ohunkóhun tí kò tọ́.
21 “Lábẹ́ nǹkan mẹ́ta ni ilé ayé ti ń wárìrì
lábẹ́ ohun mẹ́rin ni kò ti lè mí fín ín.
22 Ìránṣẹ́ tí ó di ọba
aláìgbọ́n tí ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ
23 Obìnrin tí gbogbo ènìyàn kórìíra tí ó sì wá lọ́kọ
ìránṣẹ́bìnrin tí ó gbọkọ mọ́ ọ̀gá rẹ̀ lọ́wọ́.
24 “Àwọn ohun mẹ́rin ló kéré láyé
síbẹ̀ wọ́n gbọ́n gidigidi;
25 Àwọn èèrà jẹ́ aláìlágbára ẹ̀dá,
síbẹ̀ wọ́n kó oúnjẹ wọn pamọ́ ní àsìkò òjò
26 Ehoro jẹ́ aláìlágbára ẹ̀dá;
síbẹ̀ wọ́n ń ṣe ihò wọn sí ibi pálapàla àpáta;
27 àwọn eṣú kò ní ọba,
síbẹ̀ gbogbo wọ́n ń jáde lọ ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́
28 Ọmọnílé fi ọwọ́ rẹ̀ dì mú,
síbẹ̀ a ń rí i ní ààfin ọba.
29 “Àwọn ohun mẹ́ta ní ń bẹ tí ń rìn rere,
ohun mẹ́rin ni ó dára púpọ̀ ní ìrìn rírìn:
30 Kìnnìún, alágbára láàrín ẹranko tí kì í sá fún ohunkóhun
31 Ẹsin tí a dì lẹ́gbẹ̀ẹ́;
àti òbúkọ,
àti ọba láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.
32 “Bí ìwọ bá ti hùwà aṣiwèrè nípa gbígbé ara rẹ ga,
tàbí tí o bá ti gbèrò ibi,
da ọwọ́ rẹ bo ẹnu rẹ!
33 Nítorí bí fífún omi ọmú tí í mú wàrà wá,
tí fífún imú sì ń mú ẹ̀jẹ̀ jáde,
bẹ́ẹ̀ ni rírú ìbínú sókè í mú ìjà wá.”
Gbogbo Israẹli tòótọ́ ni yóò ní ìgbàlà
25 (A)Ará, èmi kò ṣá fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó wà ní òpè ní ti ohun ìjìnlẹ̀ yìí, kí ẹ̀yin má ba á ṣe ọlọ́gbọ́n ní ojú ara yín, pé ìfọ́jú bá Israẹli ní apá kan, títí kíkún àwọn Kèfèrí yóò fi dé. 26 (B)Bẹ́ẹ̀ ni a ó sì gba gbogbo Israẹli là, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:
“Ní Sioni ni Olùgbàlà yóò ti jáde wá,
yóò sì yìí àìwà-bí-Ọlọ́run kúrò lọ́dọ̀ Jakọbu.
27 (C)Èyí sì ni májẹ̀mú mi pẹ̀lú wọn.
Nígbà tí èmi yóò mú ẹ̀ṣẹ̀ wọn kúrò.”
28 Nípa ti ìhìnrere, ọ̀tá ni wọ́n nítorí yín; bí ó sì ṣe ti ìyànfẹ́ ni, olùfẹ́ ni wọ́n nítorí ti àwọn baba. 29 Nítorí àìlábámọ̀ ni ẹ̀bùn àti ìpè Ọlọ́run. 30 Nítorí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin kò ti gba Ọlọ́run gbọ́ rí, ṣùgbọ́n nísinsin yìí tí ẹ̀yin rí àánú gbà nípa àìgbàgbọ́ wọn. 31 Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àwọn wọ̀nyí tí ó ṣe àìgbọ́ràn nísinsin yìí, kí àwọn pẹ̀lú bá le rí àánú gbà nípa àánú tí a fihàn yín. 32 (D)Nítorí Ọlọ́run sé gbogbo wọn mọ́ pọ̀ sínú àìgbàgbọ́, kí ó le ṣàánú fún gbogbo wọn.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.