Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 125

Orin fún ìgòkè.

125 Àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa yóò dàbí òkè Sioni,
    tí a kò lè ṣí ní ìdí, bí kò ṣe pé ó dúró láéláé
Bí òkè ńlá ti yí Jerusalẹmu ká,
    bẹ́ẹ̀ ni Olúwa yí ènìyàn ká
    láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.

Nítorí tí ọ̀pá àwọn ènìyàn búburú
    kì yóò bà lé ìpín àwọn olódodo;
kí àwọn olódodo kí ó máa ba à
    fi ọwọ́ wọn lé ẹ̀ṣẹ̀.

Olúwa ṣe rere fún àwọn ẹni rere,
    àti fún àwọn tí àyà wọn dúró ṣinṣin.
Bí ó ṣe ti irú àwọn tí wọn yà sí ipa ọ̀nà wíwọ́ wọn;
    Olúwa yóò jẹ́ kí wọn lọ pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.

Ṣùgbọ́n àlàáfíà yóò wà lórí Israẹli.

Òwe 8:1-31

Ọgbọ́n n fi ìpè síta

(A)Ǹjẹ́ ọgbọ́n kò ha ń kígbe síta?
    Òye kò ha ń gbé ohùn rẹ sókè?
Ní ibi gíga ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà
    ní ìkóríta, ní ó dúró;
Ní ẹgbẹ́ ibodè tí ó wọ ìlú,
    ní ẹnu ibodè ni ó ń kígbe sókè:
Sí i yín ẹ̀yin ènìyàn, ní mo ń kígbe pè;
    Mo gbé ohun mi sókè sí gbogbo ènìyàn,
Ẹ̀yin aláìmọ̀kan, ẹ kọ́gbọ́n;
    ẹ̀yin aṣiwèrè, ẹ gba òye.
Ẹ gbọ́, nítorí tí èmi ó sọ̀rọ̀ ohun iyebíye;
    Èmí ṣí ètè mi láti sọ ohun tí ó tọ́,
Ẹnu mi ń sọ ohun tí í ṣe òtítọ́,
    nítorí ètè mi kórìíra ibi.
Gbogbo ọ̀rọ̀ ẹnu mi ni ó tọ́,
    kò sí èyí tí ó jẹ́ ẹ̀tàn tàbí àyídáyidà níbẹ̀
Fún olóye gbogbo rẹ̀ ni ó tọ̀nà;
    wọ́n jẹ́ aláìlẹ́gàn fún gbogbo ẹni tí ó ní ìmọ̀.
10 Yan ẹ̀kọ́ mi dípò fàdákà,
    ìmọ̀ dípò o wúrà àṣàyàn,
11 Nítorí ọgbọ́n ṣe iyebíye jù iyùn lọ,
    kò sí ohun tí ọkàn rẹ̀ fẹ́ tí a sì le fiwé e.

12 “Èmi, ọgbọ́n ń gbé pẹ̀lú òye;
    mo ní ìmọ̀ àti ọgbọ́n-inú.
13 Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìkórìíra ibi
    mo kórìíra ìgbéraga àti agídí,
    ìwà ibi àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.
14 Ìmọ̀ràn àti ọgbọ́n tí ó yè kooro jẹ́ tèmi
    mo ní òye àti agbára.
15 Nípasẹ̀ mi ni ọba ń ṣàkóso
    tí àwọn aláṣẹ sì ń ṣe òfin tí ó dára
16 Nípasẹ̀ mi àwọn ọmọ-aládé ń ṣàkóso
    àti gbogbo ọlọ́lá tí ń ṣàkóso ilẹ̀ ayé.
17 Mo fẹ́ràn àwọn tí ó fẹ́ràn mi
    àwọn tí ó sì wá mi rí mi.
18 Lọ́dọ̀ mi ni ọrọ̀ àti ọlá wà
    ọrọ̀ tí í tọ́jọ́ àti ìgbéga rere.
19 Èso mi dára ju wúrà dáradára lọ;
    ohun tí mò ń mú wá ju àṣàyàn fàdákà lọ.
20 Mò ń rìn ní ọ̀nà òdodo,
    ní ojú ọ̀nà òtítọ́,
21 Mò ń fi ọrọ̀ fún gbogbo àwọn tí ó fẹ́ràn mi
    mo sì ń mú kí ilé ìṣúra wọn kún.

22 “Èmi ni Olúwa kọ́kọ́ dá nínú iṣẹ́ rẹ̀.
    Ṣáájú àwọn iṣẹ́ rẹ̀ àtijọ́;
23 A ti yàn mí láti ayérayé,
    láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, kí ayé tó bẹ̀rẹ̀.
24 Nígbà tí kò tí ì sí Òkun, ni a ti bí mi
    nígbà tí kò tí ì sí ìsun tí ó ní omi nínú;
25 kí a tó fi àwọn òkè sí ipò wọn,
    ṣáájú àwọn òkè ni a ti bí mi,
26 kí ó tó dá ilẹ̀ ayé tàbí àwọn oko rẹ̀
    tàbí èyíkéyìí nínú eruku ayé.
27 Mo wà níbẹ̀ nígbà tí ó fi àwọn ọ̀run sí ipò wọn,
    nígbà tí ó fi òṣùwọ̀n àyíká sórí ibú omi,
28 Nígbà tí ó ṣẹ̀dá òfúrufú lókè
    tí ó sì fi orísun ibú omi sí ipò rẹ̀ láì le è yẹsẹ̀,
29 Nígbà tí ó ṣe ààlà fún omi Òkun
    kí omi má ba à kọjá ààlà àṣẹ rẹ̀,
    àti nígbà tí ó pààlà ìpìlẹ̀ ayé.
30 Nígbà náà èmi ni gbẹ́nàgbẹ́nà ẹ̀gbẹ́ rẹ̀
    mo kún fún inú dídùn lójoojúmọ́,
    mo ń yọ̀ nígbà gbogbo níwájú rẹ̀.
31 Mo ń yọ̀ nínú gbogbo àgbáyé tí ó dá
    mo sì ní inú dídùn sí àwọn ọmọ ènìyàn.

Matiu 15:21-31

21 (A)Jesu sì ti ibẹ̀ kúrò lọ sí Tire àti Sidoni. 22 Obìnrin kan láti Kenaani, tí ó ń gbé ibẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ó ń bẹ̀bẹ̀, ó sì kígbe pé, “Olúwa, ọmọ Dafidi, ṣàánú fún mi; ọmọbìnrin mi ní ẹ̀mí èṣù ti ń dá a lóró gidigidi.”

23 Ṣùgbọ́n Jesu kò fún un ní ìdáhùn, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì gbà á níyànjú pé, “Lé obìnrin náà lọ, nítorí ó ń kígbe tọ̀ wá lẹ́yìn.”

24 (B)Ó dáhùn pé, “Àgùntàn ilẹ̀ Israẹli tí ó nù nìkan ni a rán mi sí.”

25 (C)Obìnrin náà wá, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó bẹ̀bẹ̀ sí i pé, “Olúwa ṣàánú fún mi.”

26 Ó sì dáhùn wí pé, “Kò tọ́ kí a gbé oúnjẹ àwọn ọmọ fún àwọn ajá.”

27 Obìnrin náà sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, síbẹ̀síbẹ̀ àwọn ajá a máa jẹ èrúnrún tí ó ti orí tábìlì olówó wọn bọ́ sílẹ̀.”

28 (D)Jesu sì sọ fún obìnrin náà pé, “Ìgbàgbọ́ ńlá ni tìrẹ! A sì ti dáhùn ìbéèrè rẹ.” A sì mú ọmọbìnrin rẹ̀ láradá ní wákàtí kan náà.

Jesu bọ́ ẹgbàajì ènìyàn

29 (E)Jesu ti ibẹ̀ lọ sí Òkun Galili. Ó gun orí òkè, o sì jókòó níbẹ̀. 30 Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn sì tọ̀ ọ́ wá, àti àwọn arọ, afọ́jú, amúnkùn ún, odi àti ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn mìíràn. Wọ́n gbé wọn kalẹ̀ lẹ́sẹ̀ Jesu. Òun sì mú gbogbo wọn láradá. 31 Ẹnu ya ọ̀pọ̀ ènìyàn nígbà tí wọ́n rí àwọn odi tó ń sọ̀rọ̀, amúnkùn ún tó di alára pípé, arọ tí ó ń rìn àti àwọn afọ́jú tí ó ríran. Wọ́n sì ń fi ìyìn fún Ọlọ́run Israẹli.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.