Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Fún adarí orin. Ní ohùn “Má ṣe parun.” Ti Dafidi. Miktamu. Nígbà tí ó sá níwájú Saulu lọ sínú ihò òkúta.
57 Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run, ṣàánú fún mi,
nítorí nínú rẹ ni ààbò ọkàn mí wà.
Èmi o fi ààbò mí sí ibi ìyẹ́ apá rẹ
títí tí ewu yóò fi kọjá lọ.
2 Mo kígbe sókè sí Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo jùlọ,
sí Ọlọ́run tó ń pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́ fún mi.
3 Òun yóò ránṣẹ́ láti ọ̀run wá,
yóò sì gbà mí, bí ẹni tí ń fẹ́ gbé mi mì
tilẹ̀ ń kẹ́gàn mi.
Ọlọ́run yóò rán àánú rẹ̀ àti òdodo rẹ̀ jáde.
4 Mo wà ní àárín àwọn kìnnìún;
mo dùbúlẹ̀ ni abẹ́ àwọn ẹ̀dá búburú,
àwọn ènìyàn tí eyín wọn dàbí ọ̀kọ̀ àti ọfà
ẹni tí ahọ́n rẹ̀ jẹ́ idà mímú.
5 Kí a yìn ọ́ Ọlọ́run, ju ọ̀run lọ,
kí ògo rẹ kò ju ti gbogbo ayé lọ.
6 Wọ́n ti ta àwọ̀n sílẹ̀ fún ẹsẹ̀ mi:
a tẹ orí ọkàn mi ba nínú ìtìjú,
wọ́n gbẹ́ kòtò sí ọ̀nà mi:
ṣùgbọ́n wọ́n ti jì síbẹ̀ fún ara wọn.
7 (A)Ọkàn mi ti múra Ọlọ́run;
ọkàn mi ti múra, èmi ó kọrin, èmi ó si máa kọrin ìyìn.
8 Jí, ìwọ ọkàn mi!
Jí, ohun orin èlò àti dùùrù!
Èmi tìkára mi, yóò sì jí ní kùtùkùtù.
9 Èmi ó máa yìn ọ́, Olúwa, láàrín àwọn orílẹ̀-èdè;
èmi ó máa kọrin sí ọ láàrín àwọn ènìyàn.
10 Nítorí títóbi ní ìfẹ́ rẹ, tí ó dé ọ̀run;
òtítọ́ rẹ tàn dé àwọsánmọ̀.
11 Gbígbéga ni ọ́, Ọlọ́run, ju àwọn ọ̀run lọ;
kí ògo rẹ kí ó ju gbogbo ayé lọ.
Joabu bá Dafidi wí gidigidi
19 A sì rò fún Joabu pe, “Wò ó, ọba ń sọkún, ó sì ń gbààwẹ̀ fún Absalomu.” 2 Ìṣẹ́gun ọjọ́ náà sì di àwẹ̀ fún gbogbo àwọn ènìyàn náà, nítorí àwọn ènìyàn náà gbọ́ ní ọjọ́ náà bí inú ọba ti bàjẹ́ nítorí ọmọ rẹ̀. 3 Àwọn ènìyàn náà sì yọ́ lọ sí ìlú ní ọjọ́ náà gẹ́gẹ́ bí àwọn bí ènìyàn tí a dójútì ṣe máa ń yọ́ lọ nígbà tí wọ́n bá sá lójú ìjà. 4 Ọba sì bo ojú rẹ̀, ọba sì kígbe ní ohùn rara pé, “Á à! Ọmọ mi Absalomu! Absalomu ọmọ mi, ọmọ mi!”
5 Joabu sì wọ inú ilé tọ ọba lọ, ó sì wí pé, “Ìwọ dójúti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ lónìí, àwọn tí ó gba ẹ̀mí rẹ̀ là lónìí, àti ẹ̀mí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àti ti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀, àti àwọn aya rẹ̀, àti ẹ̀mí àwọn obìnrin rẹ. 6 Nítorí pé ìwọ fẹ́ àwọn ọ̀tá rẹ, ìwọ sì kórìíra àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. Nítorí tí ìwọ wí lónìí pé, Ìwọ kò náání àwọn ọmọ ọba tàbí àwọn ìránṣẹ́; èmi sì rí lónìí pé, ìbá ṣe pé Absalomu wà láààyè, kí gbogbo wa sì kú lónìí, ǹjẹ́ ìbá dùn mọ́ ọ gidigidi. 7 Sì dìde nísinsin yìí, lọ, kí o sì sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ: nítorí pé èmi fi Olúwa búra, bí ìwọ kò bá lọ, ẹnìkan kì yóò bá ọ dúró ni alẹ́ yìí: èyí ni yóò sì burú fún ọ ju gbogbo ibi tí ojú rẹ ti ń rí láti ìgbà èwe rẹ wá títí ó fi di ìsinsin yìí.”
8 Ọba sì dìde, ó sì jókòó ní ẹnu-ọ̀nà, Wọ́n sì wí fún gbogbo àwọn ènìyàn náà pé, “Wò ó, ọba jókòó ní ẹnu-ọ̀nà.” Gbogbo ènìyàn sì wá sí iwájú ọba.
Nítorí pé, Israẹli ti sá, olúkúlùkù sí àgọ́ rẹ̀.
Àwọn àgbà mú Dafidi ọba padà
9 Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì ń bà ara wọn jà nínú gbogbo ẹ̀yà Israẹli, pé, “ọba ti gbà wá là lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, ó sì ti gbà wá kúrò lọ́wọ́ àwọn Filistini; òun sì wá sá kúrò ní ìlú nítorí Absalomu. 10 Absalomu, tí àwa fi jẹ ọba lórí wa sì kú ní ogun: ǹjẹ́ èéṣe tí ẹ̀yin fi dákẹ́ tí ẹ̀yin kò sì sọ̀rọ̀ kan láti mú ọba padà wá?”
11 Dafidi ọba sì ránṣẹ́ sí Sadoku, àti sí Abiatari àwọn àlùfáà pé, “Sọ fún àwọn àgbàgbà Juda, pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin fi kẹ́yìn láti mú ọba padà wá sí ilé rẹ̀? Ọ̀rọ̀ gbogbo Israẹli sì ti dé ọ̀dọ̀ ọba àní ní ilé rẹ̀. 12 Ẹ̀yin ni ara mi, ẹ̀yin ni egungun mi, àti ẹran-ara mi: èéṣì ti ṣe tí ẹ̀yin fi kẹ́yìn láti mú ọba padà wá.’ 13 Kí ẹ̀yin sì wí fún Amasa pé, ‘Egungun àti ẹran-ara mi kọ́ ni ìwọ jẹ́ bí? Kí Ọlọ́run ó ṣe bẹ́ẹ̀ sí mi àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú, bí ìwọ kò ba ṣe olórí ogun níwájú mi títí, ní ipò Joabu.’ ”
14 Òun sì yí gbogbo àwọn ọkùnrin Juda lọ́kàn padà àní bí ọkàn ènìyàn kan; wọ́n sì ránṣẹ́ sí ọba, pé, “Ìwọ padà àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ.” 15 Ọba sì padà, o sì wá sí odò Jordani.
Juda sì wá sí Gilgali láti lọ pàdé ọba, àti láti mú ọba kọjá odò Jordani.
Ọba dáríjì Ṣimei
16 Ṣimei ọmọ Gera, ará Benjamini ti Bahurimu, ó yára ó sì bá àwọn ọkùnrin Juda sọ̀kalẹ̀ láti pàdé Dafidi ọba. 17 Ẹgbẹ̀rún ọmọkùnrin sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nínú àwọn ọmọkùnrin Benjamini, Ṣiba ìránṣẹ́ ilé Saulu, àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àti ogún ìránṣẹ́ sì pẹ̀lú rẹ̀; wọ́n sì gòkè odò Jordani ṣáájú ọba. 18 Ọkọ̀ èrò kan ti rékọjá láti kó àwọn ènìyàn ilé ọba sí òkè, àti láti ṣe èyí tí ó tọ́ lójú rẹ̀.
Ṣimei ọmọ Gera wólẹ̀. Ó sì dojúbolẹ̀ níwájú ọba, bí ó tí gòkè odò Jordani.
35 (A)Jesu wí fún wọn pé, “Èmi ni oúnjẹ ìyè: ẹnikẹ́ni tí ó bá tọ̀ mí wá, ebi kì yóò pa á; ẹni tí ó bá sì gbà mí gbọ́, òǹgbẹ kì yóò gbẹ ẹ́ mọ́ láé. 36 Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé, Ẹ̀yin ti rí mi, ẹ kò sì gbàgbọ́. 37 (B)Gbogbo èyí tí Baba fi fún mi, yóò tọ̀ mí wá; ẹni tí ó bá sì tọ̀ mí wá, èmi kì yóò tà á nù, bí ó tí wù kó rí. 38 (C)Nítorí èmi sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá, kì í ṣe láti máa ṣe ìfẹ́ ti èmi fúnra mi, bí kò ṣe ìfẹ́ ti ẹni tí ó rán mi. 39 (D)Èyí sì ni ìfẹ́ Baba tí ó rán mi pé ohun gbogbo tí o fi fún mi, kí èmi má ṣe sọ ọ̀kan nù nínú wọn, ṣùgbọ́n kí èmi lè jí wọn dìde níkẹyìn ọjọ́. 40 (E)Èyí sì ni ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi, pé ẹnikẹ́ni tí ó bá wo ọmọ, tí ó bá sì gbà á gbọ́, kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun: Èmi ó sì jí i dìde níkẹyìn ọjọ́.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.