Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
16 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ fún àwọn, ènìyàn búburú:
“Kí ní ẹ̀tọ́ tí o ní tí ìwọ fi ń tún àwọn ìlànà mi sọ,
tàbí tí ìwọ sì ń sọ májẹ̀mú mi ní ẹnu rẹ?
17 Ìwọ kórìíra àṣẹ mi,
ìwọ sì ṣá ọ̀rọ̀ mí tì sí apá kan.
18 Nígbà tí ìwọ rí olè, ìwọ dára pọ̀ mọ́ ọn,
ìwọ sì da ara rẹ dé àwọn alágbèrè.
19 Ìwọ lo ẹnu rẹ fún aburú,
ìwọ sì ń fi ahọ́n rẹ pète ẹ̀tàn.
20 Ní ìgbà gbogbo ìwọ ń sọ̀rọ̀ sí arákùnrin rẹ,
ìwọ sì ń ba orúkọ ọmọ ìyá rẹ jẹ́.
21 Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ìwọ ti ṣe, mo sì dákẹ́;
ìwọ rò pé mo jẹ́ irú kan náà bí ìrẹ,
ṣùgbọ́n èmi yóò bá ọ wí,
èmi yóò sì fi ẹ̀sùn kàn ọ́ ní ojú ara rẹ.
22 “Ǹjẹ́ ìwọ ro èyí wò, ẹ̀yin tí ó gbàgbé Ọlọ́run.
Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ èmi yóò fa yin ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, láìsí ẹni tí yóò gbà yin sílẹ̀.
23 Ẹni tí ó ba ní ẹbọ ọrẹ-ọpẹ́ bu ọlá fún mi; kí ó sì tún ọ̀nà rẹ̀ ṣe,
kí èmi kí ó le fi ìgbàlà Ọlọ́run hàn án.”
Ọmọ náà kú
15 Natani sì lọ sí ilé rẹ̀ Olúwa sì fi ààrùn kọlu ọmọ náà tí obìnrin Uriah bí fún Dafidi, ó sì ṣe àìsàn púpọ̀. 16 Dafidi sì bẹ Ọlọ́run nítorí ọmọ náà, Dafidi sì gbààwẹ̀, ó sì wọ inú ilé lọ, ó sì dùbúlẹ̀ lórí ilé ni òru náà. 17 Àwọn àgbàgbà ilé rẹ̀ sì dìde tọ̀ ọ́ lọ, láti gbé e dìde lórí ilé: ó sì kọ̀, kò sì bá wọn jẹun.
18 Ní ọjọ́ keje, ọmọ náà sì kú. Àwọn ìránṣẹ́ Dafidi sì bẹ̀rù láti wí fún un pé, ọmọ náà kú: nítorí tí wọ́n wí pé, “Kíyèsi i, nígbà tí ọmọ náà ń bẹ láààyè, àwa sọ̀rọ̀ fún un, òun kọ̀ si gbọ́ ohùn wa! Ǹjẹ́ yóò ti ṣe ara rẹ̀ ní èṣe tó, bí àwa bá wí fún un pé, ọmọ náà kú.”
19 Nígbà tí Dafidi sì rí pé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, Dafidi sì kíyèsi i, pé ọmọ náà kú: Dafidi sì béèrè lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ọmọ náà kú bí?”
Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Ó kú.”
20 Dafidi sì dìde ní ilẹ̀, ó sì wẹ̀, ó fi òróró pa ara, ó sì pààrọ̀ aṣọ rẹ̀, ó sì wọ inú ilé Olúwa lọ, ó sì wólẹ̀ sin: ó sì wá sí ilé rẹ̀ ó sì béèrè, wọ́n sì gbé oúnjẹ kalẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì jẹun.
21 Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì bí léèrè pé, “Kí ni èyí tí ìwọ ṣe yìí? Nítorí ọmọ náà nígbà tí ó ń bẹ láààyè ìwọ gbààwẹ̀, o sì sọkún; ṣùgbọ́n nígbà tí ọmọ náà kú, ó dìde ó sì jẹun.”
22 Ó sì wí pé, “Nígbà tí ọmọ náà ń bẹ láààyè, èmi gbààwẹ̀, èmi sì sọkún: nítorí tí Èmi wí pé, ‘Ta ni ó mọ̀ bí Ọlọ́run ó ṣàánú mi, kí ọmọ náà le yè.’ 23 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó ti kú, nítorí kín ni èmi ó ṣe máa gbààwẹ̀? Èmi ha tún lè mú un padà bí? Èmi ni yóò tọ̀ ọ́ lọ, òun kì yóò sì tún tọ̀ mí wá.”
Batṣeba sì tún bí ọmọ mìíràn tí a pè ní Solomoni
24 Dafidi sì ṣìpẹ̀ fún Batṣeba aya rẹ̀, ó sì wọlé tọ̀ ọ́, ó sì bá a dàpọ̀: òun sì bí ọmọkùnrin kan, Dafidi sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Solomoni: Olúwa sì fẹ́ ẹ. 25 Ó sì rán Natani wòlíì, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jedidiah, nítorí Olúwa.
Gbígbé ìgbé ayé gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìmọ́lẹ̀
17 Ǹjẹ́ èyí ni mo ń wí, tí mo sì ń jẹ́rìí nínú Olúwa pé, láti ìsinsin yìí lọ, kí ẹ̀yin má ṣe rìn mọ́, àní gẹ́gẹ́ bí àwọn aláìkọlà ti ń rìn nínú ìrònú asán wọn. 18 Òye àwọn ẹni tí ó ṣókùnkùn, a sì yà wọ́n nínú ìyè Ọlọ́run nítorí àìmọ̀ tí ń bẹ nínú wọn, nítorí líle ọkàn wọn. 19 Àwọn ẹni tí ọkàn wọn le rékọjá, tí wọ́n sì ti fi ara wọn fún wọ̀bìà, láti máa fi ìwọra ṣiṣẹ́ ìwà èérí gbogbo.
20 Ṣùgbọ́n a kò fi Kristi kọ́ yín bẹ́ẹ̀. 21 Bí ó bá ṣe pé nítòótọ́ ni ẹ ti gbóhùn rẹ̀ ti a sì ti kọ́ yín nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ ti ń bẹ nínú Jesu. 22 Pé, ní tì ìwà yín àtijọ́, kí ẹ̀yin bọ́ ògbólógbòó ọkùnrin nì sílẹ̀, èyí tí ó díbàjẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ẹ̀tàn; 23 Kí ẹ sì di tuntun ni ẹ̀mí inú yín; 24 kí ẹ sì gbé ọkùnrin tuntun ni wọ̀, èyí tí a dá ni àwòrán Ọlọ́run nínú òdodo àti ìwà mímọ́ ti òtítọ́.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.