Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 11

Fún adarí orin. Ti Dafidi.

11 Ìgbẹ́kẹ̀lé mi wà nínú Olúwa.
    Báwo ní ẹ̀yin ó ṣe sọ fún ọkàn mi pé:
    “Fò gẹ́gẹ́ bi ẹyẹ lọ si orí òkè rẹ.
Wò ó nítorí náà, ènìyàn búburú fa ọfà rẹ̀;
    wọn ti fi ọfà wọn sí ojú okùn
láti tafà níbi òjìji
    sí àyà ẹni ìdúró ṣinṣin.
Nígbà tí ìpìlẹ̀ bá bàjẹ́
    kí ni olódodo yóò ṣe?”

Olúwa ń bẹ nínú tẹmpili mímọ́ rẹ̀;
    Olúwa ń bẹ lórí ìtẹ́ rẹ̀ ní ọ̀run.
Ó ń wo àwọn ọmọ ènìyàn;
    ojú rẹ̀ ń yẹ̀ wọ́n wò.
Olúwa ń yẹ olódodo wò,
    ṣùgbọ́n ènìyàn búburú àti àwọn tí o fẹ́ ìwà ipá
    ni ọkàn rẹ̀ kórìíra.
Sí orí àwọn ènìyàn búburú ni yóò rọ̀jò
    ẹ̀yín iná àti imí-ọjọ́ tí ń jó;
    àti ìjì gbígbóná ní yóò jẹ ìpín wọn.

Nítorí, olódodo ní Olúwa,
    o fẹ́ràn òdodo;
    ẹni ìdúró ṣinṣin yóò sì rí i.

1 Ọba 6:15-38

15 Ó sì fi pákó kedari tẹ́ ògiri ilé náà nínú, láti ilẹ̀ ilé náà dé àjà rẹ̀, ó fi igi bò wọ́n nínú, ó sì fi pákó firi tẹ́ ilẹ̀ ilé náà. 16 Ó pín ogún ìgbọ̀nwọ́ sí ẹ̀yìn ilé náà, láti ilẹ̀ dé àjà ilé ni ó fi pákó kedari kọ́, èyí ni ó kọ sínú, fún ibi tí a yà sí mímọ́ àní ibi mímọ́ jùlọ. 17 Ní iwájú ilé náà, ogójì (40) ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn rẹ̀ jẹ́. 18 Inú ilé náà sì jẹ́ kedari, wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà rẹ̀ pẹ̀lú ìrudí àti ìtànná. Gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ kedari; a kò sì rí òkúta kan níbẹ̀.

19 Ó sì múra ibi mímọ́ jùlọ sílẹ̀ nínú ilé náà láti gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa ka ibẹ̀. 20 Inú ibi mímọ́ náà sì jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ogún ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú, àti ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gíga. Ó sì fi kìkì wúrà bo inú rẹ̀ ó sì fi igi kedari bo pẹpẹ rẹ̀. 21 Solomoni sì fi kìkì wúrà bo inú ilé náà, ó sì tan ẹ̀wọ̀n wúrà dé ojú ibi mímọ́ jùlọ, ó sì fi wúrà bò ó. 22 Gbogbo ilé náà ni ó fi wúrà bò títí ó fi parí gbogbo ilé náà, àti gbogbo pẹpẹ tí ó wà níhà ibi mímọ́ jùlọ, ni ó fi wúrà bò.

23 Ní inú ibi mímọ́ jùlọ ni ó fi igi olifi ṣe kérúbù méjì, ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní gíga. 24 Apá kérúbù kìn-ín-ní sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gíga, àti apá kérúbù kejì ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún; ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá láti ṣóńṣó apá kan dé ṣóńṣó apá kejì. 25 Ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá sì ni kérúbù kejì pẹ̀lú, nítorí kérúbù méjèèjì jọ ara wọn ní ìwọ̀n ní títóbi àti títẹ̀wọ̀n bákan náà. 26 Gíga kérúbù kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá. 27 Ó sì gbé àwọn kérúbù náà sínú ilé ti inú lọ́hùn ún, pẹ̀lú ìyẹ́ apá wọn ní nínà jáde. Ìyẹ́ apá kérúbù kan sì kan ògiri kan, nígbà tí ìyẹ́ apá èkejì sì kan ògiri kejì, ìyẹ́ apá wọn sì kan ara wọn láàrín yàrá náà. 28 Ó sì fi wúrà bo àwọn kérúbù náà.

29 Lára àwọn ògiri tí ó yí ilé náà ká, nínú àti lóde, ó sì ya àwòrán àwọn kérúbù sí i àti ti igi ọ̀pẹ, àti ti ìtànná ewéko. 30 Ó sì tún fi wúrà tẹ́ ilẹ̀ ilé náà nínú àti lóde.

31 Nítorí ojú ọ̀nà ibi mímọ́ jùlọ ni ó ṣe ìlẹ̀kùn igi olifi sí pẹ̀lú àtẹ́rígbà àti òpó ìhà jẹ́ ìdámárùn-ún ògiri. 32 Àti lára ìlẹ̀kùn igi olifi náà ni ó ya àwòrán àwọn kérúbù, igi ọ̀pẹ àti ti ìtànná ewéko sí, ó sì fi wúrà bò wọ́n, ó sì tan wúrà sí ara àwọn kérúbù àti sí ara igi ọ̀pẹ. 33 Bẹ́ẹ̀ ni ó sì ṣe òpó igi olifi onígun mẹ́rin fún ìlẹ̀kùn ilé náà. 34 Ó sì tún fi igi firi ṣe ìlẹ̀kùn méjì, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ní ewé méjì tí ó yí sí ihò ìtẹ̀bọ̀. 35 Ó sì ya àwòrán kérúbù, àti ti igi ọ̀pẹ àti ti ìtànná ewéko sí ara wọn, ó sì fi wúrà bò ó, èyí tí ó tẹ́ sórí ibi tí ó gbẹ́.

36 Ó sì fi ẹsẹẹsẹ òkúta mẹ́ta gbígbẹ, àti ẹsẹ̀ kan ìtí kedari kọ́ àgbàlá ti inú lọ́hùn ún.

37 Ní ọdún kẹrin ni a fi ìpìlẹ̀ ilé Olúwa lé ilẹ̀, ní oṣù Sifi. 38 Ní ọdún kọkànlá ní oṣù Bulu, oṣù kẹjọ, a sì parí ilé náà jálẹ̀ jálẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ìpín rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí ó yẹ. Ó sì lo ọdún méje ní kíkọ́ ilé náà.

Johanu 15:16-25

16 (A)Kì í ṣe ẹ̀yin ni ó yàn mí, ṣùgbọ́n èmi ni ó yàn yín, mo sì fi yín sípò, kí ẹ̀yin kí ó lè lọ, kí ẹ sì so èso, àti kí èso yín lè dúró; kí ohunkóhun tí ẹ bá béèrè lọ́wọ́ Baba ní orúkọ mi, kí ó lè fi í fún yín. 17 Nǹkan wọ̀nyí ni mo pàṣẹ fún yín pé, kí ẹ̀yin kí ó fẹ́ràn ara yín.

Ayé kórìíra àwọn ọmọ-ẹ̀yìn

18 (B)“Bí ayé bá kórìíra yín, ẹ mọ̀ pé, ó ti kórìíra mi ṣáájú yín. 19 Ìbá ṣe pé ẹ̀yin ń ṣe ti ayé, ayé ìbá fẹ́ yin bi àwọn tirẹ̀; gẹ́gẹ́ bi o ṣe ri tí ẹ̀yin kì ń ṣe ti ayé, ṣùgbọ́n èmi ti yàn yín kúrò nínú ayé, nítorí èyí ni ayé ṣe kórìíra yín. 20 (C)Ẹ rántí ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fún yín pé, ‘Ọmọ ọ̀dọ̀ kò tóbi ju olúwa rẹ̀ lọ.’ Bí wọ́n bá ti ṣe inúnibíni sí mi, wọ́n ó ṣe inúnibíni sí yín pẹ̀lú: bí wọ́n bá ti pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, wọ́n ó sì pa tiyín mọ́ pẹ̀lú. 21 Ṣùgbọ́n gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n yóò ṣe sí yín, nítorí orúkọ mi, nítorí tí wọn kò mọ ẹni tí ó rán mi. 22 (D)Ìbá ṣe pé èmi kò ti wá kí n sì ti bá wọn sọ̀rọ̀, wọn kì bá tí ní ẹ̀ṣẹ̀: ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n di aláìríwí fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn. 23 Ẹni tí ó bá kórìíra mi, ó kórìíra Baba mi pẹ̀lú. 24 Ìbá ṣe pé èmi kò ti ṣe iṣẹ́ wọ̀n-ọn-nì láàrín wọn tí ẹlòmíràn kò ṣe rí, wọn kì bá tí ní ẹ̀ṣẹ̀: ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n sì rí, wọ́n sì kórìíra èmi àti Baba mi. 25 (E)Ṣùgbọ́n èyí rí bẹ́ẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí a kọ nínú òfin wọn kí ó lè ṣẹ pé, ‘Wọ́n kórìíra mi ní àìnídìí.’

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.