Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Ìmúpadàbọ̀sípò Israẹli
8 (A)Ohun tí Olúwa wí nìyìí:
“Ní àkókò ojúrere mi, èmi yóò dá ọ lóhùn,
àti ní ọjọ́ ìgbàlà, èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́;
Èmi yóò pa ọ́ mọ́, n ó sì ṣe ọ́
láti jẹ́ májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn,
láti mú ilẹ̀ padà bọ̀ sípò
àti láti ṣe àtúnpín ogún rẹ̀ tí ó ti dahoro,
9 Láti sọ fún àwọn ìgbèkùn pé, ‘Ẹ jáde wá’
àti fún àwọn tí ó wà nínú òkùnkùn pé, ‘Ẹ gba òmìnira!’
“Wọn yóò máa jẹ ní ẹ̀bá ọ̀nà
àti koríko tútù lórí òkè aláìléwéko.
10 (B)Ebi kì yóò pa wọ́n bẹ́ẹ̀ ni òǹgbẹ kì yóò gbẹ wọ́n,
tàbí kí ooru inú aṣálẹ̀ tàbí oòrùn kí ó pa wọ́n.
Ẹni tí ó ṣàánú fún wọn ni yóò máa tọ́ wọn,
tí yóò sì mú wọn lọ sí ibi orísun omi.
11 Èmi yóò sọ gbogbo àwọn òkè-ńlá mi di ojú ọ̀nà
àti gbogbo òpópónà mi ni a ó gbé sókè.
12 Kíyèsi i, wọn yóò wá láti ọ̀nà jíjìn
àwọn díẹ̀ láti àríwá àti àwọn díẹ̀
láti ìwọ̀-oòrùn,
àwọn díẹ̀ láti ẹkùn Siene.”
13 (C)Ẹ hó fún ayọ̀, ẹyin ọ̀run;
yọ̀, ìwọ ilẹ̀ ayé;
bú sórin, ẹ̀yin òkè ńlá!
Nítorí Olúwa tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú
yóò sì ṣàánú fún àwọn ẹni
tí a ń pọ́n lójú.
14 Ṣùgbọ́n Sioni sọ pé, “Olúwa ti kọ̀ mí sílẹ̀,
Olúwa ti gbàgbé è mi.”
15 “Ǹjẹ́ abiyamọ ha le gbàgbé ọmọ ọmú rẹ̀
kí ó má sì ṣàánú fún ọmọ rẹ̀ tí ó ti bí?
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun le gbàgbé
Èmi kì yóò gbàgbé rẹ!
16 Kíyèsi i, mo ti kọ ọ́ sí àtẹ́lẹwọ́ mi
ògiri rẹ wà níwájú mi nígbà gbogbo.
Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi.
131 Olúwa àyà mi kò gbéga,
bẹ́ẹ̀ ni ojú mi kò gbé sókè:
bẹ́ẹ̀ ni èmi kò fi ọwọ́ mi lé ọ̀ràn ńlá,
tàbí lé ohun tí ó ga jù mí lọ
2 Nítòótọ́ èmi mú ọkàn mi sinmi,
mo sì mú un dákẹ́ jẹ́ẹ́,
bí ọmọ tí a ti ọwọ́ ìyá rẹ̀ gbà ní ẹnu ọmú:
ọkàn mi rí gẹ́gẹ́ bí ọmọ tí a já ní ẹnu ọmú.
3 Israẹli, ìwọ ní ìrètí ní ti Olúwa
láti ìsinsin yìí lọ àti láéláé.
Àwọn aposteli Kristi
4 (A)Nítorí náà, ṣe ló yẹ kí ènìyàn máa wò wá gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ àti ìríjú tí a fún ni oore-ọ̀fẹ́ láti mọ Kristi tí a fún ní oore-ọ̀fẹ́ láti mọ àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run. 2 Òun kan náà tí ó tọ́ fún ìríjú, ni kí ó jẹ́ olóòtítọ́. 3 Ṣùgbọ́n ohun kíkíní ni fún mi pé, kí ẹ máa ṣe ìdájọ́ mi, tàbí kí a máa ṣe ìdájọ́ nípa ìdájọ́ ènìyàn; nítòótọ́, èmi kò tilẹ̀ dá ara mi lẹ́jọ́. 4 (B)Nítorí tí ẹ̀rí ọkàn mi kò dá mi ní ẹ̀bi; ṣùgbọ́n a kò ti ipa èyí dá mi láre, ṣùgbọ́n Olúwa ni ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ mi. 5 (C)Nítorí náà, kí ẹ má ṣe ṣe ìdájọ́ ohunkóhun, kí Olúwa tó padà dé, ẹni tí yóò mú ohunkóhun tí ó fi ara sin wá sí ìmọ́lẹ̀, tí yóò sì fi ìmọ̀ ọkàn ènìyàn hàn, nígbà náà ni olúkúlùkù yóò sì ní ìyìn tirẹ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.
24 (A)“Kò sì í ẹnìkan tí ó lè sin ọ̀gá méjì. Òun yóò yà kórìíra ọ̀kan tí yóò fẹ́ràn èkejì, tàbí kí ó fi ara mọ́ ọ̀kan kí ó sì yan èkejì ní ìpọ̀sí. Ẹ̀yin kò lè sin Ọlọ́run àti owó papọ̀.
Ẹ má ṣe àníyàn
25 (B)“Nítorí náà, mo wí fún yín, ẹ má ṣe ṣe àníyàn nípa ẹ̀mí yín, ohun tí ẹ ó jẹ àti èyí tí ẹ ó mu; tàbí nípa ara yín, ohun tí ẹ ó wọ̀. Ṣé ẹ̀mí kò ha ṣe pàtàkì ju oúnjẹ lọ tàbí ara ni kò ha ṣe pàtàkì ju aṣọ lọ? 26 Ẹ wo àwọn ẹyẹ ojú ọrun; wọn kì í gbìn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kórè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kójọ sínú àká, síbẹ̀ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run ń bọ́ wọn. Ẹ̀yin kò ha níye lórí jù wọ́n lọ bí? 27 Ta ni nínú gbogbo yín nípa àníyàn ṣíṣe ti ó lè fi ìṣẹ́jú kan kún ọjọ́ ayé rẹ̀?
28 “Kí ni ìdí ti ẹ fi ń ṣe àníyàn ní ti aṣọ? Ẹ wo bí àwọn lílì tí ń bẹ ní igbó ti ń dàgbà. Wọn kì í ṣiṣẹ́ bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í rànwú. 29 Bẹ́ẹ̀ ni mo wí fún yín pé, a kò ṣe Solomoni lọ́ṣọ̀ọ́ nínú gbogbo ògo rẹ̀ tó ọ̀kan nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí. 30 Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run bá wọ koríko igbó ní aṣọ bẹ́ẹ̀, èyí tí ó wà níhìn-ín lónìí ti a sì gbà sínú iná lọ́la, kò ha ṣe ni ṣe yín lọ́ṣọ̀ọ́ tó bẹ́ẹ̀ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ̀yin tí ìgbàgbọ́ yín kéré? 31 Nítorí náà, ẹ má ṣe ṣe àníyàn kí ẹ sì máa wí pé, ‘Kí ni àwa yóò jẹ?’ Tàbí ‘Kí ni àwa yóò mu?’ Tàbí ‘Irú aṣọ wo ni àwa yóò wọ̀?’ 32 Nítorí àwọn kèfèrí ń fi ìwọra wá àwọn nǹkan wọ̀nyí bẹ́ẹ̀ ni Baba yín ní ọ̀run mọ̀ dájúdájú pé ẹ ní ìlò àwọn nǹkan wọ̀nyí. 33 Ṣùgbọ́n, ẹ kọ́kọ́ wá ìjọba Ọlọ́run ná àti òdodo rẹ̀, yóò sì fi gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí kún un fún yín pẹ̀lú. 34 Nítorí náà, ẹ má ṣe àníyàn ọ̀la, ọ̀la ni yóò ṣe àníyàn ara rẹ̀. Wàhálà ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ti tó fún un.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.