Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 46

Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Gẹ́gẹ́ bí ti alamoti. b Orin.

46 Ọlọ́run ni ààbò àti agbára wa
    ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ ní ìgbà ìpọ́njú.
Nítorí náà àwa kì yóò bẹ̀rù, bí a tilẹ̀ ṣí ayé ní ìdí,
    tí òkè sì ṣubú sínú Òkun.
Tí omi rẹ̀ tilẹ̀ ń hó tí ó sì ń mì
    tí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ń mì pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ̀. Sela.

Odò ńlá kan wà tí ṣíṣàn rẹ̀ mú inú ìlú Ọlọ́run dùn,
    ibi mímọ́, níbi ti Ọ̀gá-ògo ń gbé.
Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀, kò ní yẹ̀:
    Ọlọ́run yóò ràn án lọ́wọ́ ní kùtùkùtù òwúrọ̀.
Àwọn orílẹ̀-èdè ń bínú, àwọn ilẹ̀ ọba ṣubú,
    ó gbé ohun rẹ̀ sókè, ayé yọ̀.

Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun wà pẹ̀lú wa,
    Ọlọ́run Jakọbu ni ààbò wa.

Ẹ wá wo iṣẹ́ Olúwa
    irú ahoro tí ó ṣe ní ayé.
O mú ọ̀tẹ̀ tán de òpin ilẹ̀ ayé
    ó ṣẹ́ ọrun, ó sì gé ọ̀kọ̀ sí méjì
ó fi kẹ̀kẹ́ ogun jóná
10 Ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ní Ọlọ́run.
A ó gbé mi ga nínú àwọn orílẹ̀-èdè
    A ó gbé mi ga ní ayé.

11 Ọlọ́run alágbára wà pẹ̀lú wa
    Ọlọ́run Jakọbu sì ni ààbò wa.

Gẹnẹsisi 3

Ìṣubú ènìyàn

(A)Ejò sá à ṣe alárékérekè ju àwọn ẹranko igbó yòókù tí Olúwa Ọlọ́run dá lọ. Ó sọ fún obìnrin náà pé, “Ǹjẹ́ òtítọ́ ha ni Ọlọ́run wí pé, ‘Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ èso èyíkéyìí lára àwọn igi tí ó wà nínú ọgbà’?”

Obìnrin náà dá ejò lóhùn pé, “Àwa lè jẹ lára àwọn èso igi tí ó wà nínú ọgbà, ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ pé, ‘Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ lára èso igi tí ó wà láàrín ọgbà, ẹ kò sì gbọdọ̀ fi ọwọ́ kàn án, bí ẹ̀yin bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin yóò kùú.’ ”

(B)Ejò wí fún obìnrin náà pé, “Ẹ̀yin kì yóò kú ikúkíkú kan.” “Nítorí Ọlọ́run mọ̀ wí pé, bí ẹ̀yin bá jẹ nínú rẹ̀, ojú yín yóò là, ẹ̀yin yóò sì dàbí Ọlọ́run, ẹ̀yin yóò sì mọ rere yàtọ̀ sí búburú.”

Nígbà tí obìnrin náà rí i wí pé èso igi náà dára fún oúnjẹ àti pé, ó sì dùn ún wò, àti pé ó ń mú ni ní ọgbọ́n, ó mú díẹ̀ níbẹ̀, ó sì jẹ ẹ́. Ó sì mú díẹ̀ fún ọkọ rẹ̀, ẹni tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, òun náà sì jẹ ẹ́. Nígbà náà ni ojú àwọn méjèèjì sì là, wọ́n sì mọ̀ pé àwọn wà ní ìhòhò; wọ́n sì rán ewé ọ̀pọ̀tọ́ pọ̀, wọ́n sì fi bo ara wọn.

Nígbà náà ni ọkùnrin náà àti aya rẹ̀ gbọ́ ìró Olúwa Ọlọ́run bí ó ti ń rìn nínú ọgbà, nígbà tí ojú ọjọ́ tura, wọ́n sì fi ara pamọ́ kúrò níwájú Olúwa Ọlọ́run sí àárín àwọn igi inú ọgbà. Ṣùgbọ́n Olúwa Ọlọ́run ké pe ọkùnrin náà pé, “Níbo ni ìwọ wà?”

10 Ó dáhùn pé, “Mo gbúròó rẹ̀ nínú ọgbà, ẹ̀rù sì bà mí, nítorí pé, mo wà ní ìhòhò, mo sì fi ara pamọ́.”

11 Ọlọ́run wí pé, “Ta ni ó wí fún ọ pé ìhòhò ni ìwọ wà? Ṣé ìwọ ti jẹ nínú èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀ ni?”

12 Ọkùnrin náà wí pé, “Obìnrin tí ìwọ fi fún mi, ni ó fún mi nínú èso igi náà, mo sì jẹ ẹ́.”

13 (C)Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run wí pé, “Èwo ni èyí tí ìwọ ṣe yìí?”

Obìnrin náà dáhùn pé, “Ejò ni ó tàn mí jẹ, mo sì jẹ ẹ́.”

14 (D)Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run wí fún ejò náà pé, “Nítorí tí ìwọ ti ṣe èyí,

“Ègún ni fún ọ ju gbogbo ohun ọ̀sìn
    àti gbogbo ẹranko igbó tókù lọ!
Àyà rẹ ni ìwọ yóò fi máa wọ́,
    ìwọ yóò sì máa jẹ erùpẹ̀ ilẹ̀
    ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.
15 (E)Èmi yóò sì fi ọ̀tá
    sí àárín ìwọ àti obìnrin náà,
    àti sí àárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ obìnrin náà;
òun yóò fọ́ orí rẹ,
    ìwọ yóò sì bù ú jẹ ní gìgísẹ̀.”

16 Ọlọ́run wí fún obìnrin náà pé:

“Èmi yóò fi kún ìrora rẹ ní àkókò ìbímọ;
    ni ìrora ni ìwọ yóò máa bí ọmọ.
Ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ ni ìfẹ́ rẹ yóò máa fà sí,
    òun ni yóò sì máa ṣe àkóso rẹ.”

17 (F)Ọlọ́run sì wí fún Adamu pé, “Nítorí pé ìwọ fetí sí aya rẹ, ìwọ sì jẹ nínú èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀,’

“Ègún ni fún ilẹ̀ nítorí rẹ;
    nínú ọ̀pọ̀ làálàá ni ìwọ yóò jẹ nínú rẹ̀,
    ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.
18 Ilẹ̀ yóò sì hu ẹ̀gún àti èṣùṣú fún ọ,
    ewéko igbó ni ìwọ yóò sì máa jẹ.
19 Nínú òógùn ojú rẹ
    ni ìwọ yóò máa jẹun
títí tí ìwọ yóò fi padà sí ilẹ̀,
    nítorí inú ilẹ̀ ni a ti mú ọ jáde wá;
erùpẹ̀ ilẹ̀ sá à ni ìwọ,
    ìwọ yóò sì padà di erùpẹ̀.”

20 Adamu sì sọ aya rẹ̀ ní Efa nítorí òun ni yóò di ìyá gbogbo alààyè.

21 Olúwa Ọlọ́run, sì dá ẹ̀wù awọ fún Adamu àti aya rẹ̀, ó sì fi wọ̀ wọ́n. 22 (G)Olúwa Ọlọ́run sì wí pé, “Ọkùnrin náà ti dàbí ọ̀kan lára wa, ó mọ rere àti búburú. A kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ó na ọwọ́ rẹ̀ kí ó mú lára èso igi ìyè kí ó sì jẹ, kí ó sì wà láààyè títí láéláé.” 23 Nítorí náà, Olúwa Ọlọ́run lé e kúrò nínú ọgbà Edeni láti lọ máa ro ilẹ̀ nínú èyí tí a ti mú un jáde wá. 24 Lẹ́yìn tí ó ti lé ènìyàn jáde tán, ó fi àwọn Kérúbù àti idà iná tí ó ń kọ mọ̀nàmọ́ná síwájú àti sẹ́yìn láti ṣọ́ ọ̀nà tí ó lọ sí ibi igi ìyè, ní ìhà ìlà-oòrùn ọgbà Edeni.

Matiu 7:1-6

Ṣíṣe ìdájọ́ ẹnìkejì

(A)“Ẹ má ṣe dá ni lẹ́jọ́, kí a má bà dá yín lẹ́jọ́. Nítorí irú ìdájọ́ tí ẹ̀yin bá ṣe, òun ni a ó sì ṣe fún yín; irú òṣùwọ̀n tí ẹ̀yin bá fi wọ́n, òun ni a ó sì fi wọ́n fún yín.

(B)“Èétiṣe tí ìwọ fi ń wo ẹ̀rún igi tí ń bẹ ní ojú arákùnrin rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ kò kíyèsi ìtì igi tí ń bẹ ní ojú ara rẹ? Tàbí ìwọ ó ti ṣe wí fún arákùnrin rẹ pé, ‘Jẹ́ kí èmi yọ ẹ̀rún igi tí ń bẹ ni ojú rẹ,’ sì wò ó ìtì igi ń bẹ ní ojú ìwọ tìkára rẹ. Ìwọ àgàbàgebè, tètè kọ́ yọ ìtì igi jáde kúrò ní ojú ara rẹ ná, nígbà náà ni ìwọ yóò sì tó ríran kedere láti yọ ẹ̀rún igi tí ń bẹ ní ojú arákùnrin rẹ kúrò.

“Ẹ má ṣe fi ohun mímọ́ fún ajá jẹ, ẹ má sì ṣe sọ ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye yín fún ẹlẹ́dẹ̀, bí ẹ̀yin bá ṣe bẹ́ẹ̀ kí wọ́n má bà fi ẹsẹ̀ tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀, wọn a sì yí padà sí yín, wọn a sì bù yín jẹ.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.