Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi.
131 Olúwa àyà mi kò gbéga,
bẹ́ẹ̀ ni ojú mi kò gbé sókè:
bẹ́ẹ̀ ni èmi kò fi ọwọ́ mi lé ọ̀ràn ńlá,
tàbí lé ohun tí ó ga jù mí lọ
2 Nítòótọ́ èmi mú ọkàn mi sinmi,
mo sì mú un dákẹ́ jẹ́ẹ́,
bí ọmọ tí a ti ọwọ́ ìyá rẹ̀ gbà ní ẹnu ọmú:
ọkàn mi rí gẹ́gẹ́ bí ọmọ tí a já ní ẹnu ọmú.
3 Israẹli, ìwọ ní ìrètí ní ti Olúwa
láti ìsinsin yìí lọ àti láéláé.
22 Olúwa kórìíra ètè tí ń parọ́
ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí àwọn olóòtítọ́.
23 Ènìyàn olóye fi ìmọ̀ rẹ̀ pamọ́ sínú ara rẹ̀
ṣùgbọ́n ọkàn ènìyàn búburú ń gbé ìwà òmùgọ̀ jáde.
24 Ọwọ́ àìṣọ̀lẹ yóò jẹ ọba
ṣùgbọ́n ọ̀lẹ ṣíṣe a máa yọrí sí ẹrú ṣíṣe.
25 Ìbànújẹ́ ní ọkàn ènìyàn ní dorí rẹ̀ kodò
ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere a máa mú kó yọ̀.
26 Olódodo ènìyàn máa ń ṣọ́ra láti dọ́rẹ̀ẹ́
ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ń mú wọn ṣìnà.
27 Ọ̀lẹ ènìyàn kò sun ẹran tí ó pa lóko ọdẹ
ṣùgbọ́n ẹni tí kì í ṣe ọ̀lẹ máa ń díwọ̀n ohun ìní rẹ̀.
28 Ní ọ̀nà àwọn olódodo ni ìyè wà
ní ọ̀nà náà ni àìkú wà.
Timotiu àti Epafiroditu
19 Mo ni ìrètí nínú Jesu Olúwa, láti rán Timotiu sí yín ni àìpẹ́ yìí, kí èmi pẹ̀lú lè ni ìfọ̀kànbalẹ̀ nígbà tí mo bá gbúròó yín. 20 Nítorí èmi kò ni ẹlòmíràn tí ó dàbí rẹ̀, tí yóò máa fi tinútinú ṣe àníyàn yín. 21 Nítorí gbogbo wọn ni ó tọ́jú nǹkan ti ara wọn, kì í ṣe àwọn nǹkan ti Jesu Kristi. 22 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin mọ̀ pé Timotiu pegedé, gẹ́gẹ́ bí ọmọ lọ́dọ̀ baba rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó sì ti ń bá mi ṣiṣẹ́ pọ̀, nínú iṣẹ́ ìhìnrere. 23 Nítorí náà, mo ní ìrètí láti rán sí yín ní àìpẹ́ tí mo bá wòye bí yóò ti rí fún mi. 24 Ṣùgbọ́n mo ní gbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa, pé èmi tìkára mi pẹ̀lú yóò wá ní àìpẹ́.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.