Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 107:1-7

ÌWÉ KARÙN-ÚN

Saamu 107–150

107 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun;
    nítorí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé.

Jẹ́ kí àwọn ẹni ìràpadà Olúwa kí ó wí báyìí, àwọn
    ẹni tí ó rà padà kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá,
Àwọn tí ó kójọ láti ilẹ̀ wọ̀n-ọn-nì
    láti ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn,
    láti àríwá àti Òkun wá.

Wọ́n ń rìn káàkiri ní aginjù ní ibi tí ọ̀nà kò sí,
    wọn kò rí ọ̀nà lọ sí ìlú níbi tí
    wọn ó máa gbé
Ebi ń pa wọn, òǹgbẹ gbẹ wọ́n,
    ó sì rẹ ọkàn wọn nínú wọn.
Ní ìgbà náà, wọ́n kígbe sókè
    Olúwa nínú ìdààmú wọn,
ó sì yọ wọ́n kúrò nínú ìrora wọn
Ó fi ọ̀nà títọ́ hàn wọ́n sí ìlú
    tí wọn lè máa gbé

Saamu 107:33-37

33 Ó sọ odò di aginjù,
    àti orísun omi di ilẹ̀ gbígbẹ.
34 Ilẹ̀ eléso di aṣálẹ̀
    nítorí ìwà búburú àwọn tí ó wà nínú rẹ̀;
35 O sọ aginjù di adágún omi àti
    ilẹ̀ gbígbẹ di orísun omi
36 Níbẹ̀ ó mú ẹni tí ebi ń pa wà,
    wọ́n sì pilẹ̀ ibi tí wọn ó máa gbé
37 Wọn fún irúgbìn, wọ́n sì gbin ọgbà àjàrà
    tí yóò máa so èso tí ó dára;

Joṣua 2:15-24

15 Nígbà náà ní ó fi okùn sọ̀ wọ́n kalẹ̀ ní ojú u fèrèsé, nítorí ilé tí ó ń gbé wà ní ara odi ìlú. 16 Ó sì ti sọ fún wọn pé, “Ẹ lọ sí orí òkè, kí ẹ sì fi ara pamọ́ níbẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta kí àwọn tí ń lépa yín má ba à rí i yín títí tí wọn yóò fi darí. Lẹ́yìn náà kí ẹ máa bá ọ̀nà yín lọ.”

17 Àwọn arákùnrin náà sì sọ fún un pé, “Kí ọrùn un wa ba à lè mọ́ kúrò nínú ìbúra tí ìwọ mú wa bú yìí. 18 Nígbà tí àwa bá wọ ilé è rẹ, ìwọ yóò so okùn aláwọ̀ aró yìí sí ojú fèrèsé èyí tí ìwọ fi sọ̀ wá kalẹ̀, kí ìwọ kí ó mú baba rẹ, ìyá rẹ, àwọn arákùnrin in rẹ àti gbogbo ìdílé è rẹ kí wọ́n wá sí inú ilé è rẹ. 19 Bí ẹnikẹ́ni bá jáde sí ìta láti inú ilé è rẹ sí inú ìgboro ìlú, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóò sì wà ní orí ara rẹ̀; ẹ̀bi rẹ̀ yóò sì wà lórí i rẹ̀. Fún ẹnikẹ́ni tí ó bá wà nínú ilé pẹ̀lú rẹ, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóò wà ní orí i wa bí ẹnikẹ́ni bá fi ọwọ́ kàn án. 20 Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá sọ ohun tí àwa ń ṣe, àwa yóò bọ́ nínú ìbúra tí ìwọ mú wa bú.”

21 Ó dáhùn pé, “Ó dára bẹ́ẹ̀. Ẹ jẹ́ kí ó rí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin tí sọ.”

Ó sì rán wọn lọ wọ́n sì lọ. Ó sì so okùn òdòdó náà sí ojú fèrèsé.

22 Nígbà tí wọ́n kúrò, wọ́n sì lọ sí orí òkè wọ́n sì dúró ní ibẹ̀ ní ọjọ́ mẹ́ta, títí àwọn alépa fi wá wọn ní gbogbo ọ̀nà wọ́n sì padà láìrí wọn. 23 Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin méjì náà padà. Wọ́n sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, wọ odò, wọ́n sì wá sí ọ̀dọ̀ Joṣua ọmọ Nuni wọ́n sì sọ fún un gbogbo ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí wọn. 24 Wọ́n sì sọ fún Joṣua, “Nítòótọ́ ni Olúwa tí fi gbogbo ilẹ̀ náà lé wa lọ́wọ́; gbogbo olùgbé ilẹ̀ náà ni ìbẹ̀rùbojo ti mú nítorí i wa.”

Matiu 23:13-28

13 (A)“Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin olùkọ́ òfin àti Farisi, ẹ̀yin àgàbàgebè! Ẹ̀yin sé ìjọba ọ̀run mọ́ àwọn ènìyàn nítorí ẹ̀yin tìkára yín kò wọlé, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò jẹ́ kí àwọn tí ó fẹ́ wọlé ó wọlé.

14 “Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin olùkọ́ òfin àti Farisi, ẹ̀yin àgàbàgebè! Nítorí ẹ̀yin jẹ ilé àwọn opó run, àti nítorí àṣehàn, ẹ̀ ń gbàdúrà gígùn, nítorí náà ni ẹ̀yin yóò ṣe jẹ̀bi púpọ̀.

15 (B)“Ègbé ni fún yín ẹ̀yin olùkọ́ òfin àti Farisi, ẹ̀yin àgàbàgebè! Nítorí ẹ̀yin rin yí ilẹ̀ àti Òkun ká láti yí ẹnìkan lọ́kàn padà, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ń sọ ọ́ di ọmọ ọ̀run àpáàdì ní ìlọ́po méjì ju ẹ̀yin pàápàá.

16 (C)“Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin afọ́jú ti ń fi ọ̀nà han afọ́jú! Tí ó wí pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó ba fi tẹmpili búra kò sí nǹkan kan, ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá fi wúrà inú tẹmpili búra, ó di ajigbèsè.’ 17 Ẹ̀yin aláìmòye afọ́jú: èwo ni ó ga jù, wúrà tàbí tẹmpili tí ó ń sọ wúrà di mímọ́? 18 Àti pé, Ẹnikẹ́ni tó bá fi pẹpẹ búra, kò jámọ́ nǹkan, ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni tí ó ba fi ẹ̀bùn tí ó wà lórí rẹ̀ búra, ó di ajigbèsè. 19 Ẹ̀yin aláìmòye afọ́jú wọ̀nyí! Èwo ni ó pọ̀jù: ẹ̀bùn tí ó wà lórí pẹpẹ ni tàbí pẹpẹ fúnrarẹ̀ tí ó sọ ẹ̀bùn náà di mímọ́? 20 Nítorí náà ẹnikẹ́ni tí ó bá ń fi pẹpẹ búra, ó fi í búra àti gbogbo ohun tí ó wà lórí rẹ̀. 21 Àti pé, ẹni tí ó bá fi tẹmpili búra, ó fi í búra àti ẹni tí ń gbé inú rẹ̀. 22 Àti pé, ẹni tí ó bá sì fi ọ̀run búra, ó fi ìtẹ́ Ọlọ́run àti ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ búra.

23 (D)“Ègbé ni fún yín ẹ̀yin olùkọ́ òfin àti Farisi, ẹ̀yin àgàbàgebè! Nítorí ẹ̀yin ń gba ìdámẹ́wàá minti, dili àti kumini, ẹ̀yin sì ti fi ohun tí ó ṣe pàtàkì jùlọ nínú òfin sílẹ̀ láìṣe, ìdájọ́, àánú àti ìgbàgbọ́: Wọ̀nyí ni ó tọ́ tí ẹ̀yin ìbá ṣe, ẹ̀yin kò bá fi wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀ láìṣe. 24 Ẹ̀yin afọ́jú tó ń fi afọ́jú mọ̀nà! Ẹ tu kòkòrò-kantíkantí tó bọ́ sì yín lẹ́nu nù, ẹ gbé ìbákasẹ mì.

25 (E)“Ègbé ni fún yín ẹ̀yin Farisi àti ẹ̀yin olùkọ́ òfin, ẹ̀yin àgàbàgebè. Ẹ̀yin ń fọ òde ago àti àwo ṣùgbọ́n inú rẹ̀ kún fún ìrẹ́jẹ àti ẹ̀gbin gbogbo. 26 Ìwọ afọ́jú Farisi, tètè kọ́ fọ inú ago àti àwo, gbogbo ago náà yóò sì di mímọ́.

27 (F)“Ègbé ni fún yín ẹ̀yin Farisi àti ẹ̀yin olùkọ́ òfin, ẹ̀yin àgàbàgebè. Ẹ dàbí ibojì funfun tí ó dára ní wíwò, ṣùgbọ́n tí ó kún fún egungun ènìyàn àti fún ẹ̀gbin àti ìbàjẹ́. 28 Ẹ̀yin gbìyànjú láti farahàn bí ènìyàn mímọ́, olódodo, lábẹ́ aṣọ mímọ́ yín ni ọkàn tí ó kún fún ìbàjẹ́ pẹ̀lú oríṣìíríṣìí àgàbàgebè àti ẹ̀ṣẹ̀ wà.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.